A Wẹ̀ Wá Mọ́ Láti Jẹ́ Èèyàn Fún Iṣẹ́ Àtàtà
A Wẹ̀ Wá Mọ́ Láti Jẹ́ Èèyàn Fún Iṣẹ́ Àtàtà
“Ẹ jẹ́ kí a wẹ ara wa mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀gbin ti ẹran ara àti ti ẹ̀mí, kí a máa sọ ìjẹ́mímọ́ di pípé nínú ìbẹ̀rù Ọlọ́run.”—2 KỌ́RÍŃTÌ 7:1.
1. Kí ni Jèhófà béèrè lọ́wọ́ àwọn tó ń sìn ín?
“TA NÍ lè gun orí òkè ńlá Jèhófà, ta sì ni ó lè dìde ní ibi mímọ́ rẹ̀?” Dáfídì Ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì ló gbé ìbéèrè amúnironújinlẹ̀ yẹn dìde nípa ìjọsìn tí Jèhófà tẹ́wọ́ gbà. Ó wá fúnra rẹ̀ dáhùn pé: “Ẹni tí ó jẹ́ ọlọ́wọ́ mímọ́, tí ó sì mọ́ ní ọkàn-àyà, ẹni tí kò gbé ọkàn Mi lọ sínú kìkì ohun tí kò ní láárí, tí kò sì búra ẹ̀tàn.” (Sáàmù 24:3, 4) Kéèyàn tó lè rí ìtẹ́wọ́gbà Jèhófà, ẹni tó jẹ́ mímọ́ látòkè délẹ̀, onítọ̀hún gbọ́dọ̀ jẹ́ mímọ́. Jèhófà ti kọ́kọ́ rán ìjọ Ísírẹ́lì létí pé: “Kí ẹ . . . sọ ara yín di mímọ́, kí ẹ sì jẹ́ mímọ́, nítorí pé èmi jẹ́ mímọ́.”—Léfítíkù 11:44, 45; 19:2.
2. Báwo ni Pọ́ọ̀lù àti Jákọ́bù ṣe tẹnu mọ́ bí ìjẹ́mímọ́ ti ṣe pàtàkì tó nínú ìjọsìn tòótọ́?
2 Ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún lẹ́yìn náà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ tó wà nílùú Kọ́ríńtì, tó kún fún ìwàkiwà, ó ní: “Níwọ̀n bí a ti ní ìlérí wọ̀nyí, ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹ jẹ́ kí a wẹ ara wa mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀gbin ti ẹran ara àti ti ẹ̀mí, kí a máa sọ ìjẹ́mímọ́ di pípé nínú ìbẹ̀rù Ọlọ́run.” (2 Kọ́ríńtì 7:1) Èyí tún tẹ kókó náà mọ́ni lọ́kàn pé kéèyàn tó lè ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Ọlọ́run, kí ó sì rí àwọn ìbùkún tó ṣèlérí gbà, onítọ̀hún ní láti jẹ́ mímọ́, láìní ẹ̀gbin àti ìwà pálapàla kankan nípa ti ara àti nípa tẹ̀mí. Bákan náà, nígbà tí Jákọ́bù ọmọ ẹ̀yìn ń kọ̀wé nípa ìjọsìn tí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà, ó sọ pé: “Ọ̀nà ìjọsìn tí ó mọ́, tí ó sì jẹ́ aláìlẹ́gbin ní ojú ìwòye Ọlọ́run àti Baba wa ni èyí: láti máa bójú tó àwọn ọmọ òrukàn àti àwọn opó nínú ìpọ́njú wọn, àti láti pa ara ẹni mọ́ láìní èérí kúrò nínú ayé.”—Jákọ́bù 1:27.
3. Kí ìjọsìn wa tó lè ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún Ọlọ́run, kí ló yẹ kó ká wa lára jù lọ?
3 Níwọ̀n bí mímọ́ tónítóní àti wíwà láìlẹ́gbin ti ṣe pàtàkì gan-an nínú ìjọsìn tòótọ́, ohun tó yẹ kí ó ká ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ rí ojú rere Ọlọ́run lára jù lọ ni pé kí òun kúnjú ìwọ̀n nínú èyí. Àmọ́, nítorí pé ìlànà àti èrò àwọn èèyàn yàtọ̀ síra gan-an lórí ọ̀ràn ìmọ́tónítóní lóde òní, a ní láti mọ ohun tí Jèhófà kà sí mímọ́ àti ohun tó tẹ́wọ́ gbà, ká sì máa tẹ̀ lé e. Ó yẹ ká wádìí ohun tí Ọlọ́run ń béèrè lọ́wọ́ àwọn olùjọsìn rẹ̀ nínú ọ̀ràn yìí, ká sì mọ ohun tó ti ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n le máa wà ní mímọ́ tónítóní, kí wọ́n si jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún un.—Sáàmù 119:9; Dáníẹ́lì 12:10.
Wíwà ní Mímọ́ Tónítóní fún Ìjọsìn Tòótọ́
4. Ṣàlàyé ojú ìwòye Bíbélì nípa ìjẹ́mímọ́.
4 Ohun tí wíwà ní mímọ́ tónítóní wulẹ̀ túmọ̀ sí fún ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ni pé kéèyàn máà ní ìdọ̀tí tàbí àbààwọ́n kankan lára. Àmọ́, ọ̀rọ̀ Hébérù àti ti Gíríìkì bíi mélòó kan tá a lò fún wíwà ní mímọ́ tónítóní nínú Bíbélì, fi hàn pé ìjẹ́mímọ́ kì í wulẹ̀ ṣe nípa ti ara nìkan, àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà ó máa ń jẹ́ nípa ti ìwà híhù àti nípa tẹ̀mí. Abájọ tí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Bíbélì kan fi sọ pé: “‘Mímọ́ tónítóní’ àti ‘jíjẹ́ aláìmọ́’ jẹ́ àwọn ọ̀rọ̀ tí kò fi bẹ́ẹ̀ ní í ṣe pẹ̀lú ọ̀ràn ìmọ́tótó lásán, àmọ́ tó jẹ́ pé ọ̀ràn ìsìn gan-an ló wà fún. Nítorí ìdí èyí, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo apá ìgbésí ayé ni ọ̀ràn ‘ìjẹ́mímọ́’ kàn.”
5. Báwo ni àwọn ìlànà tí Òfin Mósè gbé kalẹ̀ lórí ọ̀ràn ìjẹ́mímọ́ nínú ìgbésí ayé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe rìn jìnnà tó?
5 Òfin Mósè tilẹ̀ ní àwọn àṣẹ àti ìlànà tó kan gbogbo apá ìgbésí ayé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó to ohun tó jẹ́ mímọ́, ohun tó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, àti ohun tí kò ṣe ìtẹ́wọ́gbà lẹ́sẹẹsẹ. Fún àpẹẹrẹ, ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìtọ́ni nípa ohun mímọ́ àti aláìmọ́ wà nínú Léfítíkù orí 11 sí 15. Àwọn ẹranko kan jẹ́ aláìmọ́, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò sì gbọ́dọ̀ jẹ wọ́n. Ọmọ bíbí yóò sọ obìnrin kan di aláìmọ́ fún àkókò kan pàtó. Bákan náà ni àwọn àrùn kan tí ń ba awọ ara jẹ́, àgàgà àrùn ẹ̀tẹ̀, àti ohun tó ń ti ẹ̀yà ara ìbímọ ọkùnrin àti obìnrin sun jáde tún ń sọni di aláìmọ́. Òfin tún sọ ohun tí wọ́n ní láti ṣe bí èèyàn bá di aláìmọ́. Fún àpẹẹrẹ, nínú Númérì 5:2, a kà pé: “Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n rán gbogbo àwọn adẹ́tẹ̀ jáde kúrò ní ibùdó àti gbogbo àwọn tí ó ní àsunjáde àti gbogbo àwọn tí ọkàn tí ó ti di olóògbé ti sọ di aláìmọ́.”
6. Kí nìdí tá a fi fún wọn láwọn òfin lórí ìjẹ́mímọ́?
6 Ó dájú pé òfin wọ̀nyí àtàwọn òfin mìíràn látọ̀dọ̀ Jèhófà kún fún òye jíjinlẹ̀ nípa ọ̀ràn ìṣègùn àti ètò ìṣiṣẹ́ ara, tó jẹ́ pé ẹ̀yìn-ọ̀-rẹyìn làwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ tóó mọ̀ nípa wọn, àwọn èèyàn náà sì jàǹfààní nígbà tí wọ́n pa á mọ́. Àmọ́, àwọn òfin wọ̀nyí kò wà fún kìkì ọ̀ràn ìlera tàbí fún ìlànà ìṣègùn nìkan. Wọ́n jẹ́ ara ìjọsìn tòótọ́. Bí àwọn òfin náà ṣe kan ìgbésí ayé ojoojúmọ́ àwọn ènìyàn—lórí jíjẹ, bíbímọ, àjọṣepọ̀ nínú ìdílé àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ—wulẹ̀ fi kókó náà hàn pé gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run wọn, Jèhófà ní ẹ̀tọ́ láti pinnu ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́ fún wọn nínú gbogbo apá ìgbésí ayé wọn, tí wọ́n ti yà sí mímọ́ pátápátá fún Jèhófà.—Diutarónómì 7:6; Sáàmù 135:4.
7. Ìbùkún wo ni orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì yóò rí gbà bí wọ́n bá pa Òfin náà mọ́?
7 Májẹ̀mú Òfin náà tún dáàbò bo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò lọ́wọ́ àwọn ìwà tí ń sọni di aláìmọ́ táwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká ń hù. Nípa fífi ìṣòtítọ́ pa Òfin náà mọ́, títí kan gbogbo ohun téèyàn ní láti ṣe kó tó lè wà ní mímọ́ tónítóní lójú Jèhófà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò tóótun láti sin Ọlọ́run wọn àti láti rí ìbùkún rẹ̀ gbà. Látàrí èyí, Jèhófà sọ fún orílẹ̀-èdè náà pé: “Bí ẹ̀yin yóò bá ṣègbọràn délẹ̀délẹ̀ sí ohùn mi, tí ẹ ó sì pa májẹ̀mú mi mọ́ ní ti gidi, dájúdájú, nígbà náà, ẹ̀yin yóò di àkànṣe dúkìá mi nínú gbogbo àwọn ènìyàn yòókù, nítorí pé, gbogbo ilẹ̀ ayé jẹ́ tèmi. Ẹ̀yin fúnra yín yóò sì di ìjọba àwọn àlùfáà àti orílẹ̀-èdè mímọ́ fún mi.”—Ẹ́kísódù 19:5, 6; Diutarónómì 26:19.
8. Èé ṣe tó fi yẹ káwọn Kristẹni òde òní kọbi ara sí ohun tí Òfin sọ nípa ìjẹ́mímọ́?
8 Níwọ̀n bí Jèhófà ti fi irú àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ bẹ́ẹ̀ kún Òfin náà, kí ó lè tọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ́nà láti wà ní mímọ́ tónítóní, kí wọ́n sì jẹ́ ẹni ìtẹ́wọ́gbà fún un, ǹjẹ́ kò ní dáa káwọn Kristẹni òde òní fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò bí wọ́n ṣe kúnjú ìwọ̀n nínú ọ̀ràn yìí? Bí àwọn Kristẹni kò tilẹ̀ sí lábẹ́ Òfin, wọ́n gbọ́dọ̀ máa rántí àlàyé Pọ́ọ̀lù pé, gbogbo ohun tó wà nínú Òfin “jẹ́ òjìji àwọn nǹkan tí ń bọ̀, ṣùgbọ́n ohun gidi náà jẹ́ ti Kristi.” (Kólósè 2:17; Hébérù 10:1) Bí Jèhófà Ọlọ́run, ẹni tó sọ pé “èmi kò yí padà,” bá ka wíwà ní mímọ́ tónítóní àti jíjẹ́ aláìlẹ́gbin sí ohun tó ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀ nínú ìjọsìn tòótọ́ nígbà yẹn lọ́hùn-ún, àwa lónìí gbọ́dọ̀ fojú pàtàkì wo ọ̀ràn wíwà ní mímọ́ nípa tara, nípa ti ìwà híhù, àti nípa tẹ̀mí, bí a bá fẹ́ kí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà wá, kí ó sì bù kún wa.—Málákì 3:6; Róòmù 15:4; 1 Kọ́ríńtì 10:11, 31.
Ìjẹ́mímọ́ Nípa Tara Ń Fi Wá Sípò Ìtẹ́wọ́gbà
9, 10. (a) Èé ṣe tí ìjẹ́mímọ́ nípa tara fi ṣe pàtàkì fún Kristẹni? (b) Ọ̀rọ̀ wo làwọn èèyàn sábà máa ń sọ nípa àpéjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà?
9 Ṣé ìjẹ́mímọ́ nípa tara ṣì kó apá pàtàkì nínú ìjọsìn tòótọ́? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìjẹ́mímọ́ nípa tara nìkan kò sọ ẹnì kan di olùjọ́sìn tòótọ́ lójú Ọlọ́run, síbẹ̀ ó yẹ kí olùjọ́sìn tòótọ́ jẹ́ mímọ́ nípa tara bí ipò tó wà bá ṣe yọ̀ǹda fún un tó. Pàápàá lóde òní, tí ọ̀pọ̀ èèyàn ò fi bẹ́ẹ̀ kọbi ara sí ìmọ́tótó ara, ti aṣọ, tàbí ti àyíká wọn, àwọn tó bá jẹ́ afínjú làwọn tó wà láyìíká máa ń fi ṣèran wò. Èyí sì lè mú àbájáde rere wá, gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù ṣe sọ fún àwọn Kristẹni tó wà ní Kọ́ríńtì pé: “Kò sí ọ̀nà kankan tí àwa gbà jẹ́ okùnfà èyíkéyìí fún ìkọ̀sẹ̀, kí a má bàa rí àléébù sí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa; ṣùgbọ́n lọ́nà gbogbo, a ń dámọ̀ràn ara wa fún ìtẹ́wọ́gbà gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ Ọlọ́run.”—2 Kọ́ríńtì 6:3, 4.
10 Léraléra ni àwọn lọ́gàálọ́gàá lẹ́nu iṣẹ́ ọba máa ń gbóríyìn fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nítorí bí wọ́n ṣe mọ́ tónítóní, tí wọ́n wà létòlétò, tí ìwà àti ìṣe wọn sì jẹ́ èyí tó ń fi ọ̀wọ̀ hàn, àgàgà láwọn àpéjọ ńlá tí wọ́n máa ń ṣe. Bí àpẹẹrẹ, ìwé ìròyìn La Stampa sọ nípa àpéjọ tí wọ́n ṣe ní ẹkùn-ìpínlẹ̀ Savona, Ítálì pé: “Ohun tó kọ́kọ́ ń gba àfiyèsí èèyàn ní gbàrà tó bá bẹ̀rẹ̀ sí rin ilẹ̀ àpéjọ náà kiri ni ìmọ́tótó àti ìwàlétòlétò àwọn tó ń lo ibẹ̀.” Lẹ́yìn àpéjọ táwọn Ẹlẹ́rìí ṣe ní pápá ìṣeré kan nílùú São Paulo, Brazil, ọ̀gá kan tó ń ṣiṣẹ́ ní pápá ìṣeré náà sọ fún ẹni tó ń bójú tó ọ̀ràn ìmọ́tótó ibẹ̀ pé: “Láti ìsinsìnyí lọ, a fẹ́ kí ibi eré ìdárayá yìí máa wà ní mímọ́ tónítóní lọ́nà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà ṣe é.” Ọ̀gá mìíràn ní pápá ìṣeré náà sọ pé: “Nígbà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá fẹ́ háyà ibi ìṣeré yìí, tiwa ni ká kàn ti rí sí i pé àwọn ọjọ́ tí wọ́n bá sọ pé àwọn fẹ́ lò ó kò yẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, kò sí nǹkan mìíràn tó tún ń bà wá lẹ́rù.”
11, 12. (a) Ìlànà Bíbélì wo ló yẹ ká fi sọ́kàn nípa ọ̀ràn ìmọ́tótó? (b) Àwọn ìbéèrè wo la lè gbé dìde nípa ìwà wa àti ọ̀nà ìgbésí ayé wa?
11 Bí ìmọ́tótó àti ìwàlétòlétò níbi ìjọsìn wa bá lè jẹ́ orísun ìyìn fún Ọlọ́run tí à ń sìn, ó dájú pé fífi àwọn ànímọ́ wọ̀nyí hàn nínú ìgbésí ayé wa ṣe pàtàkì bákan náà. Àmọ́ ṣá o, tá a bá wà nílé ara wa, a lè máa ronú pé ohun tó bá wù wá la lè ṣe. Tó bá sì kan ọ̀ràn aṣọ àti ìmúra, dájúdájú a lómìnira àtiyan ohun tó bá wa lára mu, tó sì wù wá! Síbẹ̀, gbogbo èyí ló ní ibi tí òmìnira náà mọ. Rántí pé nígbà ìjíròrò lórí yíyàn láti jẹ irú àwọn oúnjẹ kan, Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ fún àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ pé: “Ẹ máa ṣọ́ra kí ọlá àṣẹ yín yìí, lọ́nà kan ṣáá, má di ohun ìkọ̀sẹ̀ fún àwọn tí ó jẹ́ aláìlera.” Ó wá mẹ́nu kan ìlànà pàtàkì kan pé: “Ohun gbogbo ni ó bófin mu; ṣùgbọ́n kì í ṣe ohun gbogbo ni ó ṣàǹfààní. Ohun gbogbo ni ó bófin mu; ṣùgbọ́n kì í ṣe ohun gbogbo ní ń gbéni ró.” (1 Kọ́ríńtì 8:9; 10:23) Báwo ni ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù ṣe kàn wá nínú ọ̀ràn ìmọ́tótó?
12 Ó bọ́gbọ́n mu káwọn èèyàn retí pé kí òjíṣẹ́ Ọlọ́run wà ní mímọ́ tónítóní, kí ó sì wà létòlétò nínú ọ̀nà ìgbésí ayé rẹ̀. Nítorí náà, ó yẹ ká rí i dájú pé bí ilé wa àti àyíká rẹ̀ ṣe rí kò ní jẹ́ káwọn èèyàn bẹnu àtẹ́ lu ohun tá a sọ pé a jẹ́, ìyẹn òjíṣẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Irú ẹ̀rí wo ni ilé wa ń jẹ́ nípa wa àti nípa ìgbàgbọ́ wa? Ǹjẹ́ ó ń fi hàn pé lóòótọ́ la fẹ́ gbé nínú ayé tuntun òdodo tó mọ́ tónítóní, tó sì wà létòlétò, èyí tá à ń fi taratara sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ fáwọn ẹlòmíràn? (2 Pétérù 3:13) Bákan náà ni ìrísí wa, yálà nígbà tá a bá ń ṣe fàájì tàbí nígbà tá a bá wà lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́, lè bu ẹwà kún ìhìn rere tí à ń wàásù rẹ̀ tàbí kó tàbùkù sí i. Bí àpẹẹrẹ, kíyè sí ọ̀rọ̀ yìí tí oníròyìn kan kọ ní Mẹ́síkò pé: “Ní ti tòótọ́, àwọn ọ̀dọ́ ló pọ̀ jù lọ nínú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ohun tí wọ́n sì fi tayọ ni bí wọ́n ṣe ń gẹ irun wọn, ìmọ́tótó wọn, àti bí wọ́n ṣe ń múra dáadáa.” Ẹ ò rí i pé nǹkan ayọ̀ ló jẹ́ láti ní irú àwọn ọ̀dọ́ bẹ́ẹ̀ láàárín wa!
13. Kí la lè ṣe láti rí i dájú pé gbogbo apá ìgbésí ayé wa ojoojúmọ́ ló mọ́ tónítóní, tó sì wà létòlétò?
13 Ká sọ tòótọ́, kì í sábà rọrùn láti rí i dájú pé ara wa, ohun ìní wa, àti ilé wa wà ní mímọ́ àti létòlétò ní gbogbo ìgbà. Ohun tá a nílò kì í ṣe ọ̀pọ̀ ẹ̀rọ tó lágbára tó sì gbówó lórí, bí kò ṣe wíwéwèé dáradára, ká sì sapá gidigidi. A gbọ́dọ̀ ṣètò àkókò fún mímú kí ara wa, aṣọ wa, ilé wa, ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ wa, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ wà ní mímọ́ tónítóní. Jíjẹ́ kí ọwọ́ wa dí nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, lílọ sí ìpàdé, àti ìdákẹ́kọ̀ọ́—láfikún sí bíbójútó àwọn ojúṣe mìíràn nínú ìgbésí ayé ojoojúmọ́—kò sọ pé kí a má wà ní mímọ́ tónítóní, kí a sì jẹ́ ẹni ìtẹ́wọ́gbà lójú Ọlọ́run àti èèyàn. Ìlànà tí gbogbo wa mọ̀ bí ẹní mowó pé “ohun gbogbo ni ìgbà tí a yàn kalẹ̀ wà fún” tún kan apá tí à ń wí yìí nínú ìgbésí ayé wa.—Oníwàásù 3:1.
Ọkàn Tí Ó Jẹ́ Aláìlẹ́gbin
14. Èé ṣe tá a fi lè sọ pé ìjẹ́mímọ́ ní ti ìwà híhù àti nípa tẹ̀mí tiẹ̀ ṣe pàtàkì ju ìjẹ́mímọ́ tara pàápàá?
14 Bó ti ṣe pàtàkì tó láti kọbi ara sí ìjẹ́mímọ́ ti ara náà ló túbọ̀ ṣe pàtàkì láti kọbi ara sí ìjẹ́mímọ́ nípa ti ìwà híhù àti nípa tẹ̀mí. A dórí ìparí èrò yìí nítorí a rántí pé kì í ṣe jíjẹ́ aláìmọ́ nípa tara ló mú kí Jèhófà kọ Ísírẹ́lì sílẹ̀, bí kò ṣe nítorí ìwà búburú wọn àti ipò tẹ̀mí wọn tó dìdàkudà. Jèhófà tipasẹ̀ wòlíì Aísáyà sọ fún wọn pé nítorí jíjẹ́ tí wọ́n jẹ́ “orílẹ̀-èdè tí ó kún fún ẹ̀ṣẹ̀, àwọn ènìyàn tí ìṣìnà ti wọ̀ lọ́rùn,” ẹbọ wọn, àjọyọ̀ òṣùpá tuntun àti sábáàtì wọn, kódà àdúrà wọn pàápàá ti sú òun. Kí ni wọ́n ní láti ṣe kí wọ́n lè padà rí ojú rere Ọlọ́run? Jèhófà sọ pé: “Ẹ wẹ̀; ẹ jẹ́ kí ara yín mọ́; ẹ mú búburú ìbánilò yín kúrò ní iwájú mi; ẹ ṣíwọ́ ṣíṣe búburú.”—Aísáyà 1:4, 11-16.
15, 16. Kí ni Jésù sọ pé ó ń sọ ènìyàn di ẹlẹ́gbin, báwo la sì ṣe lè jàǹfààní nínú ọ̀rọ̀ Jésù?
15 Láti túbọ̀ mọrírì bí ìjẹ́mímọ́ ní ti ìwà híhù àti tẹ̀mí ti ṣe pàtàkì tó, ẹ jẹ́ ká ronú lórí ohun tí Jésù sọ nígbà táwọn Farisí àtàwọn akọ̀wé sọ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ jẹ́ aláìmọ́ nítorí pé wọn ò wẹ ọwọ́ wọn kí wọ́n tó jẹun. Jésù tọ́ wọn sọ́nà nípa sísọ pé: “Kì í ṣe ohun tí ó wọ ẹnu ni ó ń sọ ènìyàn di ẹlẹ́gbin; ṣùgbọ́n ohun tí ó jáde wá láti ẹnu ni ó ń sọ ènìyàn di ẹlẹ́gbin.” Jésù wá ṣàlàyé pé: “Àwọn ohun tí ń jáde láti ẹnu ń jáde láti inú ọkàn-àyà, ohun wọnnì sì ní ń sọ ènìyàn di ẹlẹ́gbin. Fún àpẹẹrẹ, láti inú ọkàn-àyà ni àwọn èrò burúkú ti ń wá, ìṣìkàpànìyàn, panṣágà, àgbèrè, olè jíjà, àwọn èké gbólóhùn ẹ̀rí, àwọn ọ̀rọ̀ òdì. Ìwọ̀nyí ni àwọn ohun tí ń sọ ènìyàn di ẹlẹ́gbin; ṣùgbọ́n láti fi ọwọ́ tí a kò wẹ̀ jẹun kì í sọ ènìyàn di ẹlẹ́gbin.”—Mátíù 15:11, 18-20.
16 Kí la lè rí kọ́ nínú ọ̀rọ̀ Jésù? Ohun tí Jésù ń sọ ni pé ìwà búburú, ìwà pálapàla, àti àwọn ìwà àìmọ́ máa ń wá látinú èrò burúkú, èrò pálapàla, àti èrò àìmọ́ tó wà nínú ọkàn. Gẹ́gẹ́ bí Jákọ́bù ọmọ ẹ̀yìn ṣe sọ ọ́ ló rí, pé, “olúkúlùkù ni a ń dán wò nípa fífà á jáde àti ríré e lọ nípasẹ̀ ìfẹ́-ọkàn òun fúnra rẹ̀.” (Jákọ́bù 1:14, 15) Nítorí náà, bí a kò bá fẹ́ kó sínú ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo tí Jésù mẹ́nu kàn wọ̀nyẹn, a gbọ́dọ̀ fa ìtẹ̀sí èyíkéyìí tó lè mú wa ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ tu kúrò nínú ọkàn wa. Ìyẹn túmọ̀ sí pé a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra nípa irú ìwé tí à ń kà, ohun tí à ń wò, àti àwọn ọ̀rọ̀ tí à ń gbọ́. Lóde òní, nítorí pé àwọn èèyàn ní òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ, tí àwọn òǹkọ̀wé sì láǹfààní láti kọ ohun tó wù wọ́n, àwọn ilé iṣẹ́ eré ìnàjú àti ti ìpolówó ọjà ń gbé ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ orin àti àwòrán síta láti tẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ lọ́rùn. A gbọ́dọ̀ pinnu pé a ò ní jẹ́ kí irú èròkérò bẹ́ẹ̀ ta gbòǹgbò lọ́kàn wa láé. Kókó tó wà níbẹ̀ ni pé tá a bá fẹ́ múnú Ọlọ́run dùn, tá a sì fẹ́ kó tẹ́wọ́ gbà wá, a gbọ́dọ̀ máa wà lójúfò ní gbogbo ìgbà kí a lè ní ọkàn-àyà tí ó mọ́ tónítóní.—Òwe 4:23.
A Wẹ̀ Wá Mọ́ fún Iṣẹ́ Àtàtà
17. Èé ṣe ti Jèhófà fi sọ àwọn ènìyàn rẹ̀ di mímọ́?
17 Ìbùkún àti ààbò gidi ló jẹ́ pé, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, a lè ní ìdúró mímọ́ níwájú rẹ̀. (2 Kọ́ríńtì 6:14-18) Àmọ́, a tún mọ̀ pé ó ní ìdí kan pàtó tí Jèhófà fi sọ àwọn èèyàn rẹ̀ di mímọ́. Pọ́ọ̀lù sọ fún Títù pé Kristi Jésù “fi ara rẹ̀ fúnni nítorí wa kí ó bàa lè dá wa nídè kúrò nínú gbogbo onírúurú ìwà àìlófin, kí ó sì wẹ àwọn ènìyàn tí wọ́n jẹ́ tirẹ̀ lákànṣe mọ́ fún ara rẹ̀, àwọn onítara fún iṣẹ́ àtàtà.” (Títù 2:14) Gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn tá a ti wẹ̀ mọ́, iṣẹ́ wo ló yẹ ká máa ṣe tìtaratìtara?
18. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a jẹ́ onítara fún iṣẹ́ àtàtà?
18 Lákọ̀ọ́kọ́ ná, a gbọ́dọ̀ lo ara wa tokuntokun láti kéde ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fún gbogbo èèyàn. (Mátíù 24:14) Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, à ń nawọ́ ìrètí náà sáwọn èèyàn níbi gbogbo pé wọ́n lè wà láàyè títí láé nínú ayé tí kò ti ní sí ìbàyíkájẹ́. (2 Pétérù 3:13) Iṣẹ́ àtàtà wa tún kan fífi èso ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run hàn nínú ìgbésí ayé wa ojoojúmọ́, ká sì tipa bẹ́ẹ̀ máa yin Baba wa ọ̀run lógo. (Gálátíà 5:22, 23; 1 Pétérù 2:12) A ò sì ní gbàgbé àwọn tí kò sí nínú òtítọ́, tí ìjábá tàbí àwọn àjálù líle koko mìíràn bá. A ń fi ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù sọ́kàn pé: “Ní ti gidi, nígbà náà, níwọ̀n ìgbà tí a bá ní àkókò tí ó wọ̀ fún un, ẹ jẹ́ kí a máa ṣe ohun rere sí gbogbo ènìyàn, ṣùgbọ́n ní pàtàkì sí àwọn tí ó bá wa tan nínú ìgbàgbọ́.” (Gálátíà 6:10) Gbogbo irú oore bẹ́ẹ̀, tí à ń ṣe látinú ọkàn mímọ́ pẹ̀lú ète rere, ń mú inú Ọlọ́run dùn gan-an.—1 Tímótì 1:5.
19. Àwọn ìbùkún wo ló ń dúró dè wá bí a bá ń bá a lọ láti jẹ́ mímọ́ nípa ti ara, ní ti ìwà híhù àti nípa tẹ̀mí?
19 Gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Ẹni Gíga Jù Lọ náà, a ò ní gbàgbé ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Mo fi ìyọ́nú Ọlọ́run pàrọwà fún yín, ẹ̀yin ará, pé kí ẹ fi ara yín fún Ọlọ́run ní ẹbọ ààyè, mímọ́, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ pẹ̀lú agbára ìmọnúúrò yín.” (Róòmù 12:1) Ǹjẹ́ kí a máa bá a lọ láti mọyì jíjẹ́ ẹni tí Jèhófà wẹ̀ mọ́, kí a sì máa sa gbogbo ipá wa láti máa jẹ́ mímọ́ nípa ti ara, ní ti ìwà híhù, àní nípa tẹ̀mí. Kì í ṣe kìkì pé ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yóò jẹ́ káwọn èèyàn bọ̀wọ̀ fún wa, ká sì tún jẹ́ aláyọ̀ nísinsìnyí nìkan ni, àmọ́ yóò tún jẹ́ ká rí i nígbà tí “àwọn ohun àtijọ́”—ìyẹn ètò búburú ẹlẹ́gbin ti ìsinsìnyí—yóò kọjá lọ nígbà tí Ọlọ́run bá “sọ ohun gbogbo di tuntun.”—Ìṣípayá 21:4, 5.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Èé ṣe tá a fi fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní òfin tó pọ̀ rẹpẹtẹ lórí ọ̀ràn ìjẹ́mímọ́?
• Báwo ni jíjẹ́ mímọ́ nípa tara ṣe ń mú kí ìwàásù wa túbọ̀ fani mọ́ra?
• Kí nìdí tí ìjẹ́mímọ́ ní ti ìwà híhù àti nípa tẹ̀mí fi ṣe pàtàkì ju ìjẹ́mímọ́ nípa tara pàápàá?
• Báwo la ṣe lè fi hàn pé “onítara fún iṣẹ́ àtàtà” ni wá?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Jíjẹ́ mímọ́ nípa tara ń mú kí ìwàásù wa túbọ̀ fani mọ́ra
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
Jésù kìlọ̀ pé àwọn èrò burúkú máa ń múni hu ìwà burúkú
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Gẹ́gẹ́ bí àwọn èèyàn tá a wẹ̀ mọ́, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ onítara fún iṣẹ́ àtàtà