Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Gbígbé Àwọn Èrò Èké Nípa Ikú Yẹ̀ Wò

Gbígbé Àwọn Èrò Èké Nípa Ikú Yẹ̀ Wò

Gbígbé Àwọn Èrò Èké Nípa Ikú Yẹ̀ Wò

JÁLẸ̀ ìtàn ni ọ̀rọ̀ nípa ikú ti ń dààmú àwọn èèyàn, tó sì ń kóni láyà sókè. Síwájú sí i, àwọn nǹkan míì tó ń dá kún ìbẹ̀rù ikú ni ẹ̀kọ́ èké àtàwọn àṣà tó wọ́pọ̀ àtàwọn ìgbàgbọ́ kan tó ti ta gbòǹgbò lọ́kàn kálukú. Ohun tí ọ̀ràn ká máa bẹ̀rù ikú fi jẹ́ ìṣòro ni pé ó lè ba ayọ̀ ìgbésí ayé èèyàn jẹ́, ó sì lè jẹ́ kéèyàn parí èrò sí pé ìgbésí ayé ò nítumọ̀.

Àwọn ẹ̀sìn tó lókìkí pàápàá ló ń fi àwọn èrò èké kan tó ti tàn kálẹ̀ nípa ikú kọ́ àwọn èèyàn. Jẹ́ ká fi òtítọ́ Bíbélì wéra pẹ̀lú ẹ̀kọ́ èké wọ̀nyí, kí o sì rí i bóyá òye tó o ní nípa ikú lè túbọ̀ ṣe kedere sí i.

Èrò Èké Kìíní: Ikú jẹ́ àdámọ́ni láti fòpin sí ìwàláàyè ẹ̀dá.

Ìwé náà, Death—The Final Stage of Growth, sọ pé: “Ikú . . . jẹ́ apá tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀ nínú ìgbésí ayé wa.” Irú ọ̀rọ̀ yìí túmọ̀ sí pé ikú jẹ́ àdámọ́ni, tó gbọ́dọ̀ fòpin sí ìwàláàyè gbogbo ẹ̀dá alààyè. Ìyọrísí rẹ̀ ni pé irú ìgbàgbọ́ yìí ti jẹ́ kí ọ̀pọ̀ èèyàn pa ìwà ọmọlúwàbí tì, kí wọ́n sì máa jayé ìjẹkújẹ.

Àmọ́ ṣé lóòótọ́ ni ikú jẹ́ àdámọ́ni láti fòpin sí ìwàláàyè ẹ̀dá? Kì í ṣe gbogbo olùwádìí ló gbà bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Calvin Harley, tó ti kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ nípa ohun tó ń mú kéèyàn darúgbó, sọ nígbà kan tí wọ́n ń fọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò pé òun ò gbà pé “ńṣe la dá ikú mọ́” ẹ̀dá ènìyàn. William Clark tó jẹ́ onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa agbára ìdènà àrùn, sọ pé: “Ikú kì í ṣe àdámọ́ni.” Seymour Benzer, tó ń ṣiṣẹ́ ní California Institute of Technology, sì fi ìrònújinlẹ̀ sọ pé “kò yẹ kí dídarúgbó dà bí ọwọ́ aago tí ń yí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ ipò kan tá à ń retí láti yí padà.”

Nígbà táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì bá ṣàyẹ̀wò bá a ṣe dá ènìyàn, ìyàlẹ́nu gbáà ló máa ń jẹ́ fún wọn. Ohun tí wọ́n ṣàwárí ni pé àwọn agbára àti ànímọ́ tá a ní pọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ ju ohun tá a lè lò tán láàárín àádọ́rin sí ọgọ́rin ọdún tí à ń lò láyé. Fún àpẹẹrẹ, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti rí i pé agbára ìrántí ọpọlọ èèyàn kò kéré. Olùwádìí kan ṣírò rẹ̀ pé ọpọlọ wa lè gba ìsọfúnni tí “yóò kún ìwé tí ó tó ogún mílíọ̀nù, tó jẹ́ nǹkan bí iye ìwé tó wà ní ibi ìkówèésí tó tóbi jù lọ lágbàáyé.” Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ kan nípa ètò iṣan inú ọpọlọ gbà pé nígbà ayé èèyàn, kìkì ìpín bíńtín nínú agbára tí ọpọlọ ní lèèyàn lè lò. Ó wá yẹ ká béèrè pé, ‘Èé ṣe tá a fi ní ọpọlọ tó lágbára tó yẹn, tó sì wá jẹ́ pé tí-ń-tín lára rẹ̀ là ń lò nígbà ayé wa?’

Tún ronú nípa bí àyà èèyàn ṣe máa ń já nígbà tó bá ronú kan ikú! Fún àwọn èèyàn tó pọ̀ jù lọ, ikú ọkọ, aya tàbí ti ọmọ ẹni jẹ́ àjálù tí ń múni lọ́kàn gbọgbẹ́. Àní àwọn kan lè máà bọ́ lọ́wọ́ àròdùn ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn ikú olólùfẹ́ wọn. Kódà àwọn tó sọ pé ikú jẹ́ àdámọ́ni mọ̀ pé ó ṣòro láti gba kámú pé tí àwọn bá ti kú, gbogbo rẹ̀ parí nìyẹn. Ìwé ìròyìn British Medical Jornal sọ̀rọ̀ nípa “èrò tó wọ́pọ̀ láàárín àwọn ògbógi pé kò sẹ́ni tó fẹ́ kú.”

Nítorí bí ọ̀ràn ikú ṣe ń rí lára èèyàn, àti agbára ìrántí àti ẹ̀kọ́ kíkọ́ téèyàn ní, àti ìfẹ́ rẹ̀ àtọkànwá láti máa wà láàyè nìṣó, ǹjẹ́ kò ṣe kedere pé ńṣe la dá èèyàn láti wà láàyè títí láé? Bẹ́ẹ̀ ni, Ọlọ́run kò dá ikú mọ́ èèyàn. Kàkà bẹ́ẹ̀ ó dá èèyàn láti máa wà láàyè títí lọ gbére ni. Wo ohun tí Ọlọ́run sọ nípa ọjọ́ iwájú àwọn ẹ̀dá ènìyàn àkọ́kọ́. Ó ní: “Ẹ máa so èso, kí ẹ sì di púpọ̀, kí ẹ sì kún ilẹ̀ ayé, kí ẹ sì ṣèkáwọ́ rẹ̀, kí ẹ sì máa jọba lórí ẹja òkun àti àwọn ẹ̀dá tí ń fò ní ojú ọ̀run àti olúkúlùkù ẹ̀dá alààyè tí ń rìn lórí ilẹ̀ ayé.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:28) Ẹ ò rí i pé ọjọ́ iwájú alárinrin, tí kò lópin nìyẹn jẹ́!

Èrò Èké Kejì: Ọlọ́run máa ń fi ikú pa àwọn èèyàn kó lè mú wọn lọ sọ́run.

Ìyá kan tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n tó ń kú lọ, tí yóò sì fi ọmọ mẹ́ta sáyé, sọ fún àlùfáà Kátólíìkì kan pé: “Mi ò fẹ́ kí o wá sọ fún mi pé bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ ẹ nìyẹn. . . . Ọ̀rọ̀ yẹn máa ń run mí nínú.” Àmọ́ ṣebí ohun tí ọ̀pọ̀ ẹ̀sìn fi ń kọ́ni nípa ikú nìyẹn—pé ńṣe làwọn èèyàn lọ ń jẹ́ Ọlọ́run nípè.

Ṣé Ẹlẹ́dàá wá rorò tó bẹ́ẹ̀ ni, tí yóò fi máa fikú pa wá, nígbà tó mọ̀ pé nǹkan ìbànújẹ́ ni ikú jẹ́ fún wa? Rárá o, Ọlọ́run inú Bíbélì kì í ṣe bẹ́ẹ̀. Ìwé 1 Jòhánù 4:8 sọ pé: “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” Ṣàkíyèsí pé kò sọ pé Ọlọ́run ìfẹ́ tàbí pé Ọlọ́run jẹ́ onífẹ̀ẹ́, ṣùgbọ́n ó sọ pé Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́. Ìfẹ́ Ọlọ́run jinlẹ̀, ó jẹ́ aláìlábùlà, ó jẹ́ pípé, àní ó hàn nínú gbogbo ìwà àti ìṣe rẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tá a fi lè sọ pé òun gan-an alára ni ìfẹ́. Ọlọ́run yìí kì í dá ẹ̀mí àwọn èèyàn légbodò láti mú wọn lọ sọ́run.

Ẹ̀sìn èké ti tan ọ̀pọ̀ èèyàn jẹ nípa ibi tí àwọn òkú ń lọ àti ipò tí wọ́n wà. Bí wọ́n ṣe ń lo àwọn èdè kan, bí ọ̀run rere, ọ̀run àpáàdì, pọ́gátórì, Limbo, ṣòroó lóye. Àwọn èdè wọ̀nyẹn àtàwọn mìíràn tí wọ́n máa ń lò tilẹ̀ ń kó jìnnìjìnnì bá àwọn èèyàn. Àmọ́ Bíbélì sọ fún wa pé àwọn òkú kò mọ nǹkan kan; ipò tí wọ́n wà kò fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ sí tẹni tó sùn. (Oníwàásù 9:5, 10; Jòhánù 11:11-14) Ìyẹn ló fi jẹ́ pé kò sídìí fún dídààmú nípa ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí wa lẹ́yìn ikú, níwọ̀n bí a kì í ti í dààmú tá a bá rí ẹni tó ń sun oorun àsùnwọra. Jésù sọ̀rọ̀ nípa àkókò kan tí “gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí” yóò “jáde wá” sí àkọ̀tun ìwàláàyè nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé.—Jòhánù 5:28, 29; Lúùkù 23:43.

Èrò Èké Kẹta: Ọlọ́run ń mú àwọn ọmọ kéékèèké lọ sọ́run láti sọ wọ́n di áńgẹ́lì.

Elisabeth Kübler-Ross, tó ṣe ìwádìí nípa ipò àwọn tó ní àìsàn tó máa yọrí sí ikú, tọ́ka sí èrò mìíràn tó wọ́pọ̀ láàárín àwọn tí kò fọ̀ràn ẹ̀sìn ṣeré. Nígbà tó ń ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ sẹ́nì kan, ó ní “kò bọ́gbọ́n mu láti sọ fún ọmọ kékeré tí ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò rẹ̀ kú pé Ọlọ́run fẹ́ràn àwọn ọmọ kékeré gan-an ló jẹ́ kó mú Johnny àbúrò rẹ lọ sọ́run.” Ńṣe ni irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ ń tàbùkù sí Ọlọ́run, ó sì lòdì sí ànímọ́ àti ìwà rẹ̀. Dókítà Kübler-Ross ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Nígbà tí ọmọdébìnrin yìí dàgbà, inú kò yéé bí i sí Ọlọ́run, ó sì fa ìsoríkọ́ tó mú ìdààmú ọpọlọ lọ́wọ́ nígbà tí ọmọ tirẹ̀ kékeré kú ní ọgbọ̀n ọdún lẹ́yìn náà.”

Kí nìdí tí Ọlọ́run á fi gba ẹ̀mí ọmọ kan láti lè ní áńgẹ́lì kan sí i—bíi pé ọmọ náà wúlò fún Ọlọ́run ju bó ṣe wúlò fáwọn òbí rẹ̀? Bó bá jẹ́ òótọ́ ni Ọlọ́run ń gba ẹ̀mí àwọn ọmọ, ǹjẹ́ ìyẹn ò ní sọ Ẹlẹ́dàá di òǹrorò àti onímọtara-ẹni-nìkan? Láti fi hàn pé irú èrò bẹ́ẹ̀ kò bọ́ sí i rárá, Bíbélì sọ pé: “Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ìfẹ́ ti wá.” (1 Jòhánù 4:7) Ǹjẹ́ Ọlọ́run ìfẹ́ lè fa àdánù tí àwa ẹlẹ́ran ara pàápàá kà sí ìwà òǹrorò?

Kí wá nìdí táwọn ọmọdé fi ń kú? Ara ohun tó ń fà á lohun tí Oníwàásù 9:11 sọ, pé: “Ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀ ni ó ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wọn.” Sáàmù 51:5 sì sọ fún wa pé gbogbo wa jẹ́ aláìpé àti ẹlẹ́ṣẹ̀ látinú oyún, àti pé àtúbọ̀tán gbogbo èèyàn, lọ́wọ́ tá a wà yìí, ni ikú lóríṣiríṣi ọ̀nà. Nígbà míì, ikú máa ń pa oyún inú pàápàá, tí a ó fi bí i lókùú. Nínú àwọn ọ̀ràn mìíràn, àwọn ipò tí apá ò ká tàbí jàǹbá ló ń fa ikú ọmọdé. Ọlọ́run kọ́ ló ń mú irú àtúbọ̀tán bẹ́ẹ̀ wá.

Èrò Èké Kẹrin: À ń dá àwọn kan lóró lẹ́yìn ikú.

Ọ̀pọ̀ ẹ̀sìn ló ń kọ́ni pé àwọn olubi á lọ sí ọ̀run àpáàdì níbi tí a ó ti máa dá wọn lóró títí láé. Ǹjẹ́ ẹ̀kọ́ yìí bọ́gbọ́n mu, ǹjẹ́ ó tiẹ̀ bá Ìwé Mímọ́ mu? Ọjọ́ orí èèyàn kì í sábàá gùn ju àádọ́rin tàbí ọgọ́rin ọdún lọ. Ká gbà pé ẹnì kan tiẹ̀ hùwà búburú tí a ò rírú rẹ̀ rí jálẹ̀ ọjọ́ ayé rẹ̀, ṣé ìdálóró ayérayé ló wá yẹ onítọ̀hún? Rárá o. Kò bá ìdájọ́ òdodo mu láti dá ẹnì kan lóró títí láé fún ẹ̀ṣẹ̀ tó dá láàárín ìwọ̀nba ọjọ́ ayé rẹ̀ kúkúrú.

Ọlọ́run nìkan ló lè sọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ikú. Ó sì ti sọ ọ́ nínú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ohun tí Bíbélì sọ rèé: “Bí [ẹranko] ti ń kú, bẹ́ẹ̀ ni [èèyàn] ń kú; ẹ̀mí kan ṣoṣo sì ni gbogbo wọ́n ní . . . Ibì kan náà ni gbogbo wọ́n ń lọ. Inú ekuru ni gbogbo wọ́n ti wá, gbogbo wọ́n sì ń padà sí ekuru.” (Oníwàásù 3:19, 20) Ibí yìí kò sọ̀rọ̀ nípa ọ̀run àpáàdì. Inú ekuru làwọn èèyàn ń padà sí nígbà tí wọ́n bá kú, ìyẹn ni pé wọ́n á di aláìsí.

Téèyàn bá wà láàyè ló lè mọ̀ pé à ń dá òun lóró. Ǹjẹ́ àwọn òkú mọ nǹkan kan? Lẹ́ẹ̀kan sí i, Bíbélì dá wa lóhùn pé: “Àwọn alààyè mọ̀ pé àwọn yóò kú; ṣùgbọ́n ní ti àwọn òkú, wọn kò mọ nǹkan kan rárá, wọn kò sì ní owó ọ̀yà mọ́, nítorí pé a ti gbàgbé ìrántí wọn.” (Oníwàásù 9:5) Òkú tí “kò mọ nǹkan kan rárá” kò lè máa joró níbì kankan.

Èrò Èké Karùn-ún: Ikú lòpin gbogbo ìrìn àjò ẹ̀dá.

Nígbà tá a bá kú, a ti di aláìsí nìyẹn. Àmọ́ kò wá túmọ̀ sí pé kò sí ìrètí kankan mọ́. Jóòbù olóòótọ́ mọ̀ pé sàréè, ìyẹn Ṣìọ́ọ̀lù, lòun máa lọ tí òun bá kú. Ṣùgbọ́n gbọ́ àdúrà tó gbà sí Ọlọ́run. Ó ní: “Ì bá ṣe pé ìwọ yóò fi mí pa mọ́ sínú Ṣìọ́ọ̀lù, pé ìwọ yóò pa mí mọ́ ní ìkọ̀kọ̀ títí ìbínú rẹ yóò fi yí padà, pé ìwọ yóò yan àkókò kan kalẹ̀ fún mi, kí o sì rántí mi! Bí abarapá ènìyàn bá kú, ó ha tún lè wà láàyè bí? . . . Ìwọ yóò pè, èmi fúnra mi yóò sì dá ọ lóhùn.”—Jóòbù 14:13-15.

Jóòbù gbà gbọ́ pé bóun bá jẹ́ olóòótọ́ dójú ikú, Ọlọ́run á rántí òun, á sì jí òun dìde nígbà tákòókò bá tó. Ìgbàgbọ́ gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ayé ọjọ́un nìyẹn. Jésù alára sọ pé òótọ́ ni, ó sì fi hàn pé Ọlọ́run yóò lo òun láti jí àwọn òkú dìde. Ọ̀rọ̀ tí Kristi alára sọ, fún wa ní ìdánilójú yìí, pé: “Wákàtí náà ń bọ̀, nínú èyí tí gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò gbọ́ ohùn [Jésù], wọn yóò sì jáde wá, àwọn tí wọ́n ṣe ohun rere sí àjíǹde ìyè, àwọn tí wọ́n sọ ohun búburú dàṣà sí àjíǹde ìdájọ́.”—Jòhánù 5:28, 29.

Láìpẹ́ láìjìnnà, Ọlọ́run yóò mú gbogbo ìwà ibi kúrò, yóò sì mú ayé tuntun wá lábẹ́ ìjọba ọ̀run. (Sáàmù 37:10, 11; Dáníẹ́lì 2:44; Ìṣípayá 16:14, 16) Gbogbo ilẹ̀ ayé yóò wá di Párádísè, tí àwọn tí ń sin Ọlọ́run yóò máa gbé. A kà á nínú Bíbélì pé: “Mo gbọ́ tí ohùn rara láti orí ìtẹ́ náà wí pé: ‘Wò ó! Àgọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú aráyé, yóò sì máa bá wọn gbé, wọn yóò sì máa jẹ́ ènìyàn rẹ̀. Ọlọ́run fúnra rẹ̀ yóò sì wà pẹ̀lú wọn. Yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.’”—Ìṣípayá 21:3, 4.

A Óò Bọ́ Lọ́wọ́ Ìbẹ̀rù

Mímọ̀ tó o bá mọ̀ nípa àjíǹde, tó o tún mọ̀ nípa Ẹni tó ṣe ètò yìí lè tù ọ́ nínú. Jésù ṣèlérí pé: “Ẹ ó . . . mọ òtítọ́, òtítọ́ yóò sì dá yín sílẹ̀ lómìnira.” (Jòhánù 8:32) Èyí kan bíbọ́ lọ́wọ́ ìbẹ̀rù ikú. Jèhófà nìkan ló lè gbà wá lọ́wọ́ ọjọ́ ogbó àti ikú, kí ó sì fún wa ní ìyè ayérayé. Ǹjẹ́ o lè gba ìlérí Ọlọ́run gbọ́? Bẹ́ẹ̀ ni, o lè gbà á gbọ́ torí pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kò ní ṣaláì ṣẹ. (Aísáyà 55:11) A gbà ọ́ níyànjú pé kí o túbọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ète Ọlọ́run fáráyé. Inú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò dùn láti ràn ọ́ lọ́wọ́.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 6]

Ohun tí ọ̀ràn ká máa bẹ̀rù ikú fi jẹ́ ìṣòro ni pé ó lè ba ayọ̀ ìgbésí ayé èèyàn jẹ́

[Àtẹ Ìsọfúnnni tó wà ní ojú ìwé 7]

ÀWỌN ÈRÒ ÈKÉ TÓ WỌ́PỌ̀ NÍPA IKÚ KÍ NI ÌWÉ MÍMỌ́ WÍ?

● Ikú jẹ́ àdámọ́ni láti fòpin sí Jẹ́nẹ́sísì 1:28; 2:17;

ìwàláàyè ẹ̀dá Róòmù 5:12

● Ọlọ́run máa ń fi ikú pa àwọn Jóòbù 34:15; Sáàmù 37:11, 29;

èèyàn kó lè mú wọn lọ sọ́run 115:16

● Ọlọ́run ń mú àwọn ọmọ kéékèèké Sáàmù 51:5; 104:1, 4;

lọ sọ́run láti sọ wọ́n di áńgẹ́lì Hébérù 1:7, 14

● À ń dá àwọn kan lóró lẹ́yìn ikú Sáàmù 146:4; Oníwàásù 9:5,

10; Róòmù 6:23

● Ikú lòpin gbogbo ìrìn àjò ẹ̀dá Jóòbù 14:14, 15; Jòhánù 3:16;

17:3; Ìṣe 24:15

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Mímọ òótọ́ nípa ikú ń gbà wá lọ́wọ́ ìbẹ̀rù

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 5]

Barrators—Giampolo/The Doré Illustrations For Dante’s Divine Comedy/Dover Publications Inc.