Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Lẹ́tà Mẹ́rin Tó Dúró fún Orúkọ Ọlọ́run Wà Nínú Ìtumọ̀ Septuagint

Lẹ́tà Mẹ́rin Tó Dúró fún Orúkọ Ọlọ́run Wà Nínú Ìtumọ̀ Septuagint

Lẹ́tà Mẹ́rin Tó Dúró fún Orúkọ Ọlọ́run Wà Nínú Ìtumọ̀ Septuagint

LẸ́TÀ mẹ́rin náà lédè Hébérù, יהוה (YHWH), ló dúró fún orúkọ Ọlọ́run náà, Jèhófà. Ó ti pẹ́ gan-an táwọn èèyàn ti ń sọ pé lẹ́tà mẹ́rin náà kò fara hàn nínú àwọn ẹ̀dà Septuagint. Ìdí nìyẹn táwọn kan fi jiyàn pé àwọn tó kọ Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì kò lo orúkọ Ọlọ́run nínú ìwé wọn nígbà tí wọ́n ń fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù.

Onírúurú àwárí tí wọ́n ṣe ní ohun tó lé ní ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn fi hàn pé orúkọ Ọlọ́run wà nínú ìtumọ̀ Septuagint. Ìwé kan sọ pé: “Rírí i dájú pé orúkọ mímọ́ Ọlọ́run wà bó ṣe wà gẹ́lẹ́, wà ní góńgó ẹ̀mí àwọn Júù tó jẹ́ Hélénì tó ń túmọ̀ Bíbélì ti èdè Hébérù sí èdè Gíríìkì débi pé, ńṣe ni wọ́n ṣe àdàkọ àwọn lẹ́tà mẹ́rin náà gan-an sínú ẹ̀dà ti èdè Gíríìkì.”

Àjákù ìwé tá a fi òrépèté ṣe, tá a fi hàn lápá òsì yìí wulẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn bíi mélòó kan tó ṣì wà. Àjákù tí wọ́n rí nílùú Oxyrhynchus, ilẹ̀ Íjíbítì, tí wọ́n sì fún ní nọ́ńbà náà 3522, ni wọ́n sọ pé ó ti wà láti ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa. a Gígùn rẹ̀ jẹ́ nǹkan bíi sẹ̀ǹtímítà méje lóròó àti sẹ̀ǹtímítà mẹ́wàá ààbọ̀ níbùú. Ọ̀rọ̀ inú ìwé Jóòbù 42:11, 12 ló sì wà nínú rẹ̀. Lẹ́tà mẹ́rin náà tá a fi èdè Hébérù ìgbàanì kọ, ló wà ní àkámọ́ nínú fọ́tò yìí. b

Nítorí náà, ǹjẹ́ orúkọ Ọlọ́run wà nínú àwọn ẹ̀dà Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì ti ìjímìjí? Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ nì, George Howard, sọ pé: “Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé wọ́n ṣì ń kọ lẹ́tà mẹ́rin náà tó dúró fún orúkọ Ọlọ́run sínú àwọn ẹ̀dà Bíbélì ti èdè Gíríìkì [ìyẹn Septuagint] tó para pọ̀ jẹ́ Ìwé Mímọ́ ti ṣọ́ọ̀ṣì ìjímìjí, ó bọ́gbọ́n mu láti gbà gbọ́ pé nígbà táwọn tó kọ Májẹ̀mú Tuntun ń fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Ìwé Mímọ́, wọ́n rí i dájú pé àwọn lo lẹ́tà mẹ́rin náà tó dúró fún orúkọ Ọlọ́run nínú Bíbélì.” Ó dà bíi pé kété lẹ́yìn náà làwọn adàwékọ wá fi àwọn ọ̀rọ̀ arọ́pò bíi Kyʹri·os (Olúwa) àti The·osʹ (Ọlọ́run) rọ́pò orúkọ Ọlọ́run.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Kí o lè rí ìsọfúnni síwájú sí i lórí àwọn ìwé tí wọ́n fi òrépèté ṣe, tí wọ́n ti rí nílùú Oxyrhynchus, wo Ilé-Ìṣọ́nà, February 15, 1992, ojú ìwé 26 sí 28.

b Láti rí àwọn ibòmíràn tí orúkọ Ọlọ́run ti fara hàn nínú àwọn ìtumọ̀ èdè Gíríìkì ìgbàanì, wo àsomọ́ nọnba 1C nínú Bíbélì Atọ́ka ti Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, lédèe Gẹ̀ẹ́sì.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 30]

Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda Egypt Exploration Society