Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ní Inú Dídùn Sí Òdodo Jèhófà

Ní Inú Dídùn Sí Òdodo Jèhófà

Ní Inú Dídùn Sí Òdodo Jèhófà

“Ẹni tí ń lépa òdodo àti inú-rere-onífẹ̀ẹ́ yóò rí ìyè, òdodo àti ògo.”—ÒWE 21:21.

1. Ọ̀nà wo làwọn èèyàn ń tọ̀ lóde òní tó ti yọrí sí jàǹbá?

 “Ọ̀NÀ kan wà tí ó dúró ṣánṣán lójú ènìyàn, ṣùgbọ́n àwọn ọ̀nà ikú ni òpin rẹ̀ ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀.” (Òwe 16:25) Ẹ ò rí i pé bó ṣe rí gan-an ni òwe Bíbélì yìí ṣe ṣàpèjúwe ọ̀nà tí ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn ń tọ̀ lóde òní! Ní gbogbo gbòò, kìkì ohun tó bá sáà ti dáa lójú àwọn èèyàn ni wọ́n máa ń fẹ́ ṣe, láìka ohun kòṣeémánìí táwọn ẹlòmíràn nílò sí. (Òwe 21:2) Wọ́n máa ń sọ pé àwọn ń pa òfin àti ìlànà orílẹ̀-èdè àwọn mọ́, àmọ́ wọ́n lè gbọ̀nà ẹ̀bùrú nígbàkigbà tí àyè rẹ̀ bá yọ. Àbájáde rẹ̀ ni àwùjọ tó pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ, tí wọn ò ti gbọ́ra wọn yé, tí ìdààmú sì bá wọn.—2 Tímótì 3:1-5.

2. Kí la nílò ní kíákíá fún ire ìran ènìyàn?

2 Fún àǹfààní tiwa—àti fún àlàáfíà àti ààbò gbogbo ènìyàn—a nílò òfin àti ìlànà tó tọ́ tó sì yẹ ní kíákíá, ìyẹn èyí tí gbogbo èèyàn múra tán láti tẹ́wọ́ gbà, kí wọ́n sì pa mọ́. Ó dájú pé kò sí òfin tàbí ìlànà tí ẹ̀dá ènìyàn kan lè gbé kalẹ̀, bó ti wù kí onítọ̀hún gbọ́n tó tàbí bó ti wù kó ṣeé fọkàn tán tó, tó lè kúnjú ìwọ̀n yẹn. (Jeremáyà 10:23; Róòmù 3:10, 23) Bí irú ìlànà bẹ́ẹ̀ bá wà, ibo la ti lè rí i, báwo sì ni yóò ṣe rí? Tàbí kẹ̀, ìbéèrè tó tún ṣe pàtàkì jùyẹn ni pé, Bí irú ìlànà bẹ́ẹ̀ bá wà, ṣé inú rẹ̀ yóò dùn sí i, ṣé wàá sì máa pa á mọ́ láìjanpata?

Rírí Ìlànà Òdodo

3. Ta ló tóótun jù lọ láti fún wa ní ìlànà tó ṣètẹ́wọ́gbà, tó sì ṣàǹfààní fún gbogbo èèyàn, èé sì ti ṣe?

3 Ká tó lè rí ìlànà tí gbogbo èèyàn máa tẹ́wọ́ gbà, tá á sì ṣe kálukú láǹfààní, ẹni tí a óò yíjú sí ni ẹnì kan tí ọ̀ràn ẹ̀yà, àṣà ìbílẹ̀, àti àwọn ààlà ìpínlẹ̀ ò kàn, ìyẹn ẹni tí ó bọ́ lọ́wọ́ àìpé àti kùdìẹ̀-kudiẹ ẹ̀dá. Láìsí àní-àní, ẹnì kan ṣoṣo tó tóótun láti ṣe èyí ni Ẹlẹ́dàá alágbára gbogbo náà, Jèhófà Ọlọ́run, ẹni tó polongo pé: “Gẹ́gẹ́ bí ọ̀run ti ga ju ilẹ̀ ayé, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀nà mi ga ju ọ̀nà yín, bẹ́ẹ̀ sì ni ìrònú mi ga ju ìrònú yín.” (Aísáyà 55:9) Síwájú sí i, Bíbélì ṣàpèjúwe Jèhófà gẹ́gẹ́ bí “Ọlọ́run ìṣòtítọ́, ẹni tí kò sí àìṣèdájọ́ òdodo lọ́dọ̀ rẹ̀; olódodo àti adúróṣánṣán ni.” (Diutarónómì 32:4) Ibi púpọ̀ nínú Bíbélì la ti rí gbólóhùn tó sọ pé “olódodo ni Jèhófà.” (Ẹ́kísódù 9:27; 2 Kíróníkà 12:6; Sáàmù 11:7; 129:4; Ìdárò 1:18) Dájúdájú, ọ̀dọ̀ Jèhófà la ti lè rí ìlànà tó ga jù lọ nítorí pé òun jẹ́ olóòótọ́, aláìṣègbè, àti olódodo.

4. Kí ni ọ̀rọ̀ náà “òdodo” túmọ̀ sí?

4 Ká sọ tòótọ́, kì í ṣe gbogbo èèyàn ló nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ náà “òdodo” lóde òní. Àní ojú burúkú ni ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn fi ń wo àwọn tó bá gbà pé àwọn jẹ́ olódodo ju àwọn mìíràn lọ, wọ́n tiẹ̀ máa ń pẹ̀gàn wọn pàápàá, tí wọ́n á máa pè wọn ní olódodo àṣelékè, tàbí agbawèrèmẹ́sìn. Àmọ́ ṣá o, lójú ìwòye Bíbélì, jíjẹ́ “olódodo” túmọ̀ sí “jíjẹ́ olóòótọ́, adúróṣánṣán, oníwà funfun; jíjẹ́ aláìlábààwọ́n, aláìlẹ́ṣẹ̀; jíjẹ́ ẹni tó fara mọ́ òfin Ọlọ́run tàbí ìlànà ìwà rere rẹ̀; jíjẹ́ ẹni tí ń hùwà lọ́nà ẹ̀tọ́ àti àìṣègbè.” Ǹjẹ́ inú rẹ kò ní dùn sí òfin tàbí ìlànà tó bá ní irú àwọn ànímọ́ àtàtà wọ̀nyí nínú?

5. Ṣàpèjúwe ànímọ́ náà òdodo gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe ṣàlàyé rẹ̀.

5 Ní ti ànímọ́ náà òdodo, ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia Judaica sọ pé: “Òdodo kì í ṣe ohun tó fara sin, àmọ́ ó dá lórí ṣíṣe ohun tí ó tọ́ àti ohun tí ó yẹ nínú gbogbo àjọṣe wa.” Fún àpẹẹrẹ, òdodo Ọlọ́run kì í wulẹ̀ ṣe ànímọ́ tó wà ní inú lọ́hùn-ún tàbí ànímọ́ tó jẹ́ tirẹ̀ nìkan bíi jíjẹ́ tí ó jẹ́ mímọ́ àti bí kò ṣe ní àléébù. Dípò ìyẹn, ó jẹ́ ànímọ́ tó ń fi irú ẹni tó jẹ́ gan-an hàn láwọn ọ̀nà tí ó tọ́, tí ó sì yẹ. A lè sọ pé gbogbo ohun tí Jèhófà bá ṣe àti gbogbo ohun tó bá ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá ló jẹ́ òdodo nítorí pé òun jẹ́ mímọ́, tí kò sì ní àbùkù kankan. Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti wí, “Olódodo ni Jèhófà ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀, ó sì jẹ́ adúróṣinṣin nínú gbogbo iṣẹ́ rẹ̀.”—Sáàmù 145:17.

6. Kí ni Pọ́ọ̀lù sọ nípa àwọn Júù kan tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ nígbà ayé rẹ̀, èé sì ti ṣe?

6 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tẹnu mọ́ kókó yìí nínú lẹ́tà tó kọ sí àwọn Kristẹni tó wà ní Róòmù. Ó kọ̀wé nípa àwọn Júù kan tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ pé: “Nítorí . . . pé wọn kò mọ òdodo Ọlọ́run, ṣùgbọ́n tí wọ́n ń wá ọ̀nà láti gbé tiwọn kalẹ̀, wọn kò fi ara wọn sábẹ́ òdodo Ọlọ́run.” (Róòmù 10:3) Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi sọ pé irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ “kò mọ òdodo Ọlọ́run”? Ṣé a ò fi Òfin kọ́ wọn ni, ìyẹn ìlànà òdodo Ọlọ́run? Ó dájú pé a fi kọ́ wọn. Àmọ́, èyí tó pọ̀ jù nínú wọn ló ń wo òdodo bí ìwà funfun ti ara ẹni, tí wọ́n gbà pé èèyàn lè ní nípa fífi ìṣọ́ra pa gbogbo àwọn ìlànà ẹ̀sìn mọ́ látòkè délẹ̀, dípò tí wọn ì bá fi máa wò ó gẹ́gẹ́ bí ìlànà tí wọn yóò fi mọ bó ṣe yẹ kí wọ́n máa bá àwọn èèyàn ẹlẹgbẹ́ wọn lò. Wọ́n ò mọ ohun tí àìṣègbè àti òdodo túmọ̀ sí rárá, bíi tàwọn aṣáájú ìsìn ọjọ́ Jésù.—Mátíù 23:23-28.

7. Báwo ni òdodo Jèhófà ṣe rí?

7 Ní ìyàtọ̀ pátápátá síyẹn, òdodo Jèhófà hàn kedere, a sì ń rí i nínú gbogbo ìṣe rẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé òdodo rẹ̀ kò sọ pé kó gbójú fo ẹ̀ṣẹ̀ àwọn olùrélànàkọjá, ìyẹn kò wá sọ ọ́ di Ọlọ́run tí kì í gba tẹni rò, tó ń fagbára múni ṣe ohun téèyàn ò fẹ́ ṣe, tó yẹ ká máa bẹ̀rù, ká sì máa sá fún. Dípò ìyẹn, òdodo rẹ̀ ti pèsè ọ̀nà tí ìran ènìyàn fi lè tọ̀ ọ́ lọ, kí wọ́n sì bọ́ lọ́wọ́ àbájáde búburú ti ẹ̀ṣẹ̀. Òun ló fi bá a mu wẹ́kú pe Jèhófà ní “Ọlọ́run òdodo àti Olùgbàlà.”—Aísáyà 45:21.

Òdodo àti Ìgbàlà

8, 9. Àwọn ọ̀nà wo ni Òfin náà gbà fi òdodo Ọlọ́run hàn?

8 Ẹ jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò Òfin tí Ọlọ́run tipasẹ̀ Mósè fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ká lè lóye bí òdodo Ọlọ́run ṣe tan mọ́ ìgbàlà rẹ̀ tó jẹ́ ìgbésẹ̀ onífẹ̀ẹ́. Kò sí iyèméjì pé Òfin náà jẹ́ òdodo. Nígbà tí Mósè ń sọ̀rọ̀ ìdágbére, ó rán àwọn ọmọ Ísírẹ́lì létí pé: “Orílẹ̀-èdè ńlá wo ni ó sì wà, tí ó ní àwọn ìlànà òdodo àti àwọn ìpinnu ìdájọ́ bí gbogbo òfin yìí tí mo ń fi sí iwájú yín lónìí?” (Diutarónómì 4:8) Ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún lẹ́yìn náà ni Dáfídì Ọba Ísírẹ́lì polongo pé: “Àwọn ìpinnu ìdájọ́ Jèhófà jẹ́ òótọ́; òdodo ni wọ́n látòkè délẹ̀.”—Sáàmù 19:9.

9 Òfin náà ni Jèhófà lò láti jẹ́ kí ọ̀pá ìdíwọ̀n pípé rẹ̀ fún rere àti búburú ṣe kedere. Òfin náà sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ní láti hùwà, kì í ṣe lórí ọ̀ràn ẹ̀sìn nìkan, àmọ́ nínú iṣẹ́ ajé wọn, nínú àjọṣe láàárín ọkọ àti aya, lórí ọ̀ràn oúnjẹ àti ìmọ́tótó àti lórí ọ̀ràn ìdájọ́. Òfin náà tún sọ nípa ìyà tó máa jẹ àwọn tó bá rú u, kódà ó sọ pé wọ́n lè dájọ́ ikú féèyàn nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ kan. a Àmọ́, ṣé àwọn ohun òdodo tí Ọlọ́run béèrè wọ̀nyẹn, gẹ́gẹ́ bó ti wà nínú Òfin, jẹ́ ohun tó le koko jù, tó sì ni àwọn èèyàn náà lára, tí kò jẹ́ kí wọ́n ní òmìnira àti ayọ̀ mọ́, bí ọ̀pọ̀ èèyàn ṣe ń sọ lónìí?

10. Báwo ni àwọn òfin Jèhófà ṣe rí lára àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà?

10 Àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ń rí ayọ̀ ńláǹlà nínú àwọn òfin àti àṣẹ òdodo rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, kì í ṣe pé Dáfídì Ọba wulẹ̀ mọ̀ pé àwọn ìpinnu ìdájọ́ Jèhófà jẹ́ òtítọ́ àti òdodo nìkan ni, gẹ́gẹ́ bí a ti ṣàlàyé tẹ́lẹ̀, àmọ́ ó tún ní ìfẹ́ àtọkànwá àti ìmọrírì fún wọn. Ohun tó kọ nípa òfin àti ìpinnu ìdájọ́ Jèhófà ni pé: “Wọ́n yẹ ní fífẹ́ ju wúrà, bẹ́ẹ̀ ni, ju ọ̀pọ̀ wúrà tí a yọ́ mọ́; wọ́n sì dùn ju oyin àti oyin ṣíṣàn ti inú afárá. Pẹ̀lúpẹ̀lù, a ti kìlọ̀ fún ìránṣẹ́ rẹ nípasẹ̀ wọn; èrè ńlá wà nínú pípa wọ́n mọ́.”—Sáàmù 19:7, 10, 11.

11. Báwo ni Òfin náà ṣe jẹ́ “akọ́nilẹ́kọ̀ọ́ . . . tí ń sinni lọ sọ́dọ̀ Kristi”?

11 Ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún lẹ́yìn náà ni Pọ́ọ̀lù wá tọ́ka sí iṣẹ́ pàtàkì kan tí Òfin náà ṣe. Nínú lẹ́tà rẹ̀ sí àwọn ará Gálátíà, ó kọ̀wé pé: “Òfin ti di akọ́nilẹ́kọ̀ọ́ wa tí ń sinni lọ sọ́dọ̀ Kristi, kí a lè polongo wa ní olódodo nítorí ìgbàgbọ́.” (Gálátíà 3:24) Nígbà ayé Pọ́ọ̀lù, akọ́nilẹ́kọ̀ọ́ jẹ́ ìránṣẹ́ tàbí ẹrú nínú agbo ilé ńlá kan. Ojúṣe rẹ̀ ni láti dáàbò bo àwọn ọmọ, kó sì máa kó wọn lọ síléèwé. Bákan náà ni Òfin ṣe ń dáàbò bo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò lọ́wọ́ ìwàkiwà àti ìsìnkusìn àwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká. (Diutarónómì 18:9-13; Gálátíà 3:23) Kò tán síbẹ̀ o, Òfin náà jẹ́ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ ipò ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n wà àti bí wọ́n ṣe nílò ìdáríjì àti ìgbàlà. (Gálátíà 3:19) Ètò ẹbọ rírú fi hàn pé wọ́n nílò ẹbọ ìràpadà, ó sì jẹ́ àpẹẹrẹ alásọtẹ́lẹ̀ tí yóò mú kí wọ́n dá Mèsáyà tòótọ́ náà mọ̀. (Hébérù 10:1, 11, 12) Nítorí náà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà fi òdodo rẹ̀ hàn nípasẹ̀ Òfin, ó ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí pé ó ní ire àwọn ènìyàn náà àti ìgbàlà wọn ayérayé lọ́kàn.

Àwọn Tí Ọlọ́run Kà sí Olódodo

12. Kí ni ì bá jẹ́ èrè àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ká ní wọ́n kíyè sára láti pa Òfin náà mọ́?

12 Níwọ̀n bí Òfin tí Jèhófà gbé kalẹ̀ ti jẹ́ òdodo ní gbogbo ọ̀nà, ṣíṣe ìgbọràn sí i ì bá ti jẹ́ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ìdúró òdodo níwájú Ọlọ́run. Nígbà tó kù díẹ̀ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ Ilẹ̀ Ìlérí ni Mósè rán wọn létí pé: “Yóò . . . túmọ̀ sí òdodo fún wa, pé àwa kíyè sára láti pa gbogbo àṣẹ yìí mọ́ níwájú Jèhófà Ọlọ́run wa, gẹ́gẹ́ bí ó ti pàṣẹ fún wa gan-an.” (Diutarónómì 6:25) Láfikún, Jèhófà ti ṣèlérí pé: “Kí ẹ . . máa pa àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ mi àti àwọn ìpinnu ìdájọ́ mi mọ́, èyí tí ó jẹ́ pé, bí ènìyàn bá pa wọ́n mọ́, ẹni náà yóò sì wà láàyè nípasẹ̀ wọn. Èmi ni Jèhófà.”—Léfítíkù 18:5; Róòmù 10:5.

13. Ǹjẹ́ a lè sọ pe ohun tí Jèhófà ṣe kò bá ìdájọ́ òdodo mu nítorí sísọ tí ó sọ pé káwọn èèyàn òun pa Òfin òdodo òun mọ́? Ṣàlàyé.

13 Ó ṣeni láàánú pé, gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè kan, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kùnà “láti pa gbogbo àṣẹ yìí mọ́ níwájú Jèhófà,” wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ pàdánù àwọn ìbùkún tá a ṣèlérí náà. Wọ́n kùnà láti pa gbogbo àṣẹ Ọlọ́run mọ́, nítorí pé Òfin Ọlọ́run pé ṣùgbọ́n àwọn jẹ́ aláìpé. Ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé ohun tí Ọlọ́run ṣe kò bá ìdájọ́ òdodo mu ni tàbí pé aláìṣòdodo ni Ọlọ́run? Rárá o. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Kí wá ni àwa yóò wí? Àìṣèdájọ́ òdodo ha wà pẹ̀lú Ọlọ́run bí? Kí èyíinì má ṣe rí bẹ́ẹ̀ láé!” (Róòmù 9:14) Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé àwọn kan wà tí Ọlọ́run ti kà sí olódodo kó tó di pé ó fún wọn ní Òfin àti lẹ́yìn tó fún wọn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé aláìpé àti ẹlẹ́ṣẹ̀ ni wọ́n. Lára irú àwọn olùbẹ̀rù Ọlọ́run bẹ́ẹ̀ ni Nóà, Ábúráhámù, Jóòbù, Ráhábù, àti Dáníẹ́lì. (Jẹ́nẹ́sísì 7:1; 15:6; Jóòbù 1:1; Ìsíkíẹ́lì 14:14; Jákọ́bù 2:25) Ìbéèrè tó wá dìde ni pé: Kí nìdí tí Ọlọ́run fi ka àwọn wọ̀nyí sí olódodo?

14. Kí ni ohun tí Bíbélì ń wí nígbà tó bá pe ẹ̀dá ènìyàn ní “olódodo”?

14 Nígbà tí Bíbélì bá pe ẹnì kan ní “olódodo,” kò túmọ̀ sí pé irú ẹni bẹ́ẹ̀ kò ní ẹ̀ṣẹ̀ tàbí pé ó jẹ́ ẹni pípé. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó túmọ̀ sí ṣíṣe ojúṣe ẹni níwájú Ọlọ́run àti èèyàn. Bí àpẹẹrẹ, a pe Nóà ní “olódodo” àti “aláìní-àléébù láàárín àwọn alájọgbáyé rẹ̀” nítorí pé ó “bẹ̀rẹ̀ sí ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí Ọlọ́run ti pa láṣẹ fún un. Ó ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́.” (Jẹ́nẹ́sísì 6:9, 22; Málákì 3:18) Sekaráyà àti Èlísábẹ́tì, tí wọ́n jẹ́ òbí Jòhánù Olùbatisí, “jẹ́ olódodo níwájú Ọlọ́run nítorí rírìn láìlẹ́bi ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo àṣẹ àti àwọn ohun tí òfin Jèhófà béèrè.” (Lúùkù 1:6) Ẹnì kan tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì, ìyẹn ọ̀gá ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Ítálì, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Kọ̀nílíù, la pè ní “ọkùnrin tí ó jẹ́ olódodo, tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run.”—Ìṣe 10:22.

15. Kí ni òdodo wé mọ́?

15 Síwájú sí i, òdodo ẹ̀dá ènìyàn wé mọ́ ohun tó wà lọ́kàn ẹni—ìyẹn ni ìgbàgbọ́ àti ìmọrírì àti ìfẹ́ téèyàn ní fún Jèhófà àtàwọn ìlérí rẹ̀—kì í wulẹ̀ ṣe kìkì ṣíṣe ohun tí Ọlọ́run béèrè. Ìwé Mímọ́ sọ pé Ábúráhámù “ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà; òun sì bẹ̀rẹ̀ sí kà á sí òdodo fún un.” (Jẹ́nẹ́sísì 15:6) Kì í ṣe pé Ábúráhámù gbà gbọ́ pé Ọlọ́run wà nìkan ni, àmọ́ ó tún nígbàgbọ́ nínú ìlérí tó ṣe nípa “irú ọmọ” náà. (Jẹ́nẹ́sísì 3:15; 12:2; 15:5; 22:18) Irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ àti iṣẹ́ tó bá ìgbàgbọ́ náà rìn ni Jèhófà fi lè ní àjọṣe pẹ̀lú Ábúráhámù àtàwọn olóòótọ́ mìíràn, tó sì bù kún wọn, bí wọ́n tilẹ̀ jẹ́ aláìpé.—Sáàmù 36:10; Róòmù 4:20-22.

16. Kí ni ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà náà ti yọrí sí?

16 Lékè gbogbo rẹ̀, òdodo ẹ̀dá èèyàn sinmi lórí ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé nípa àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní pé: “A . . . ń polongo wọn ní olódodo gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ nípasẹ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí [Ọlọ́run] nípasẹ̀ ìtúsílẹ̀ nípa ìràpadà tí Kristi Jésù san.” (Róòmù 3:24) Àwọn tá a yàn láti jẹ́ àjùmọ̀jogún pẹ̀lú Kristi nínú Ìjọba ọ̀run ni Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa wọn. Àmọ́ ẹbọ ìràpadà Jésù tún fún ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn láǹfààní láti ní ìdúró òdodo níwájú Ọlọ́run. Nínú ìran kan, àpọ́sítélì Jòhánù rí “ogunlọ́gọ̀ ńlá, tí ẹnì kankan kò lè kà, . . . wọ́n dúró níwájú ìtẹ́ àti níwájú Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà, wọ́n wọ aṣọ funfun.” Aṣọ funfun wọn fi hàn pé wọ́n mọ́ tónítóní, wọ́n sì jẹ́ olódodo níwájú Ọlọ́run nítorí pé “wọ́n . . . ti fọ aṣọ wọn, wọ́n sì ti sọ wọ́n di funfun nínú ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.”—Ìṣípayá 7:9, 14.

Jẹ́ Kí Òdodo Jèhófà Máa Múnú Rẹ Dùn

17. Àwọn ìgbésẹ̀ wo la gbọ́dọ̀ gbé bá a ṣe ń lépa òdodo?

17 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ti fi tìfẹ́tìfẹ́ pèsè Jésù Kristi, Ọmọ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà tá a fi lè ní ìdúró òdodo níwájú rẹ̀, síbẹ̀ kì í ṣe pé èèyàn máa ṣàdédé ní ìdúró òdodo ọ̀hún. Èèyàn ní láti lo ìgbàgbọ́ nínú ìràpadà náà, kó mú ìgbésí ayé rẹ̀ bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu, kó ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà, kó sì ṣe ìrìbọmi. Lẹ́yìn náà, onítọ̀hún ní láti máa lépa òdodo, àtàwọn ànímọ́ tẹ̀mí yòókù. Tímótì tó jẹ́ Kristẹni tó ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́, tó sì ní ìrètí ìpè ti ọ̀run ni Pọ́ọ̀lù gbà níyànjú pé: “Máa lépa òdodo, fífọkànsin Ọlọ́run, ìgbàgbọ́, ìfẹ́, ìfaradà, inú tútù.” (1 Tímótì 6:11; 2 Tímótì 2:22) Jésù náà tẹ́nu mọ́ bó ṣe yẹ ká máa sapá nìṣó, nígbà tó sọ pé: “Ẹ máa bá a nìṣó, nígbà náà, ní wíwá ìjọba náà àti òdodo Rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́.” A lè máa ṣiṣẹ́ àṣekára láti wá ìbùkún Ìjọba Ọlọ́run, àmọ́ ṣé bẹ́ẹ̀ náà la ṣe ń ṣiṣẹ́ àṣekára láti lépa àwọn ọ̀nà òdodo Jèhófà?—Mátíù 6:33.

18. (a) Èé ṣe tí kò fi rọrùn láti lépa òdodo? (b) Ẹ̀kọ́ wo la lè kọ́ nínú àpẹẹrẹ Lọ́ọ̀tì?

18 Ká sọ tòótọ́, kò rọrùn láti lépa òdodo. Ìdí èyí ni pé gbogbo wa la jẹ́ aláìpé, ìwà àìṣòdodo sì ni ọkàn wa sábà máa ń fà sí. (Aísáyà 64:6) Ìyẹn nìkan kọ́ o, àwọn tó yí wa ká tún jẹ́ àwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ ka ọ̀nà òdodo Jèhófà sí. Ipò tá a wà jọ ti Lọ́ọ̀tì gan-an, ẹni tó gbé nílùú ńlá Sódómù tó kún fún ìwà ibi. Àpọ́sítélì Pétérù ṣàlàyé ìdí tí Jèhófà fi rí i pé ó yẹ kí òun gba Lọ́ọ̀tì là nínú ìparun tó ń bọ̀ sórí ìlú náà. Pétérù sọ pé: “Ohun tí ọkùnrin olódodo yẹn rí, tí ó sì gbọ́ nígbà tí ó ń gbé láàárín wọn láti ọjọ́ dé ọjọ́ ń mú ọkàn òdodo rẹ̀ joró nítorí àwọn ìṣe àìlófin wọn.” (2 Pétérù 2:7, 8) Òun ló fi dáa kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa béèrè pé: ‘Ǹjẹ́ ọkàn mi máa ń fà sí àwọn ìwà pálapàla tá à ń rí láyìíká wa? Ṣé àwọn eré ìnàjú tàbí eré ìdárayá oníwà ipá tó pọ̀ lọ jàra lóde òní kò fi bẹ́ẹ̀ burú lójú mi? Àbí ńṣe ni irú ìwà àìṣòdodo bẹ́ẹ̀ ń mú ọkàn mi joró bó ṣe mú ọkàn Lọ́ọ̀tì joró?’

19. Àwọn ìbùkún wo ló lè jẹ́ tiwa bá a bá ní inú dídùn sí òdodo Ọlọ́run?

19 Ní àwọn ọjọ́ líle koko tí kò dáni lójú wọ̀nyí, níní inú dídùn sí òdodo Jèhófà ń jẹ́ kéèyàn ní ìfọ̀kànbalẹ̀ àti ààbò. Nígbà tá a gbé ìbéèrè náà dìde pé: “Jèhófà, ta ni yóò jẹ́ àlejò nínú àgọ́ rẹ? Ta ni yóò máa gbé ní òkè ńlá mímọ́ rẹ?” Dáfídì Ọba dáhùn pé: “Ẹni tí ń rìn láìlálèébù, tí ó sì ń fi òdodo ṣe ìwà hù.” (Sáàmù 15:1, 2) Bí a bá ń lépa òdodo Ọlọ́run, tí a sì ní inú dídùn sí i, a óò ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú rẹ̀, a ó sì máa gbádùn ojú rere àti ìbùkún rẹ̀ nìṣó. Nípa bẹ́ẹ̀, a óò máa gbé ìgbésí ayé aláyọ̀, àwọn èèyàn á máa fi ọ̀wọ̀ wa wọ̀ wá, ọkàn wa á sì balẹ̀. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Ẹni tí ń lépa òdodo àti inú-rere-onífẹ̀ẹ́ yóò rí ìyè, òdodo àti ògo.” (Òwe 21:21) Síwájú sí i, sísa gbogbo ipá wa láti ṣe ohun tí ó tọ́ àti ohun tó yẹ nínú gbogbo ìgbòkègbodò wa yóò túmọ̀ sí àjọṣe aláyọ̀ lọ́tùn-ún lósì àti ìgbésí ayé tó túbọ̀ dára sí i—ní ti ìwà rere àti nípa tẹ̀mí. Onísáàmù náà polongo pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tí ń pa ìdájọ́ òdodo mọ́, àwọn tí ń ṣe òdodo ní gbogbo ìgbà.”—Sáàmù 106:3.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé lórí bí Òfin Mósè ṣe gbòòrò tó, wo àpilẹ̀kọ náà, “Some Features of the Law Covenant” [Àwọn Apákan nìnu Májẹ̀mú Òfin] tó wà ní ojú ìwé 214 sí 220 nínú Apá Kejì ìwé Insight on the Scriptures, tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.

Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?

• Kí ni òdodo?

• Báwo ni ìgbàlà ṣe tan mọ́ òdodo Ọlọ́run?

• Kí ni Ọlọ́run máa ń wò lára àwọn èèyàn tó fi ń kà wọ́n sí olódodo?

• Báwo la ṣe lè ní inú dídùn sí òdodo Jèhófà?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Dáfídì Ọba ní ìfẹ́ àtọkànwá sí òfin Ọlọ́run

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Ọlọ́run ka Nóà, Ábúráhámù, Sekaráyà àti Èlísábẹ́tì, àti Kọ̀nílíù sí olódodo. Ǹjẹ́ o mọ̀dí tó fi rí bẹ́ẹ̀?