Rírí Òtítọ́ Níbi Tí A Kò Retí Rárá
Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn
Rírí Òtítọ́ Níbi Tí A Kò Retí Rárá
ÌFẸ́ Ọlọ́run ni pé “kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là, kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.” (1 Tímótì 2:3, 4) Nítorí ìdí èyí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti tẹ ọ̀kẹ́ àìmọye Bíbélì àtàwọn ìwé tá a fi ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jáde, wọ́n sì ti pín wọn káàkiri. Nígbà mìíràn, àwọn ìtẹ̀jáde wọ̀nyí ti ran àwọn olóòótọ́ ọkàn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ láwọn ọ̀nà tá ò retí rárá. Látàrí èyí, àwọn olùpòkìkí Ìjọba Ọlọ́run nílùú Freetown, Sierra Leone, ròyìn ìrírí tó tẹ̀ lé e yìí.
Osman ni ọmọkùnrin tí wọ́n bí ṣìkejì nínú ìdílé kan tó ní ọmọ mẹ́sàn-án. Nítorí pé agboolé onísìn ni agboolé wọn, gbogbo ìgbà ló máa ń tẹ̀ lé bàbá rẹ̀ lọ jọ́sìn. Àmọ́, ohun tí ẹ̀sìn Osman fi ń kọ́ni nípa ọ̀run àpáàdì ń dà á láàmú gan-an ni. Ó ń ṣe é ní kàyéfì bí Ọlọ́run aláàánú ṣe lè máa fi iná dá àwọn ẹni ibi lóró. Kò sí èyí tó tẹ́ Osman lọ́rùn nínú gbogbo àlàyé tí wọ́n ṣe fún un láti jẹ́ kó lóye ẹ̀kọ́ ọ̀run àpáàdì.
Lọ́jọ́ kan, nígbà tí Osman ti pé ẹni ogún ọdún, ó rí ìwé aláwọ̀ búlúù kan nínú àwọn ìdọ̀tí tí wọ́n kó sínú garawa kan tí wọ́n máa ń dalẹ̀ sí. Nítorí pé ó fẹ́ràn ìwé kíkà, bó ṣe mú un nìyẹn, tó gbọ̀n ọ́n nù, tó sì rí àkọlé náà—Otitọ ti Nsinni Lọ si Iye Aiyeraiye, a lára rẹ̀.
Osman wá bẹ̀rẹ̀ sí ronú pé, ‘Òtítọ́ wo ni wọ́n ń sọ̀rọ̀ rẹ̀?’ Osman fẹ́ mọ ohun tó wà nínú rẹ̀. Nítorí náà, ó mú ìwé náà lọọlé, bó ṣe gbé ìwé náà, ó kà á látìbẹ̀rẹ̀ dópin kó tó dìde. Tẹ́ ẹ bá rí i bínú rẹ̀ ṣe dùn tó nígbà tó kà á pé Ọlọ́run ní orúkọ tó ń jẹ́—ìyẹn ni Jèhófà! (Sáàmù 83:18) Osman tún kà á pé ìfẹ́ ni olórí ànímọ́ Ọlọ́run, àti pé èrò fífi iná dá àwọn èèyàn lóró pàápàá jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí fún Un. (Jeremáyà 32:35; 1 Jòhánù 4:8) Níkẹyìn, Osman kà á pé Jèhófà kò ní pẹ́ mú Párádísè orí ilẹ̀ ayé wá, níbi tí àwọn èèyàn ti máa wà láàyè títí láé. (Sáàmù 37:29; Ìṣípayá 21:3, 4) Àgbàyanu òtítọ́ mà lèyí o látọ̀dọ̀ Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́ àti aláàánú! Osman wá fi ìmọrírì àtọkànwá dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó jẹ́ kí òun rí òtítọ́ níbi tí òun kò retí rárá.
Ní ọjọ́ bíi mélòó kan lẹ́yìn ìyẹn, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan, Osman rí Gbọ̀ngàn Ìjọba àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó sì lọ bá wọn ṣe ìpàdé fún ìgbà àkọ́kọ́. Nígbà tó wà níbẹ̀, ó bẹ Ẹlẹ́rìí kan kó wá máa bá òun ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Láìfi gbogbo àtakò tí ìdílé rẹ̀ gbé dìde pè, Osman tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí, ó sì ṣe ìrìbọmi. (Mátíù 10:36) Lónìí, ó ń sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà nínú ìjọ. Ohun ìyanu gbáà ló jẹ́, pé gbogbo èyí bẹ̀rẹ̀ látorí rírí ìtẹ̀jáde Bíbélì kan he nínú garawa tí wọ́n ń dalẹ̀ sí!
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde lọ́dún 1968.