“Wọ́n Lọ Sísàlẹ̀”
“Wọ́n Lọ Sísàlẹ̀”
“Omi ríru bẹ̀rẹ̀ sí bò wọ́n; wọ́n lọ sísàlẹ̀ inú ibú bí òkúta.”
ÀWỌN ọ̀rọ̀ yẹn ni Mósè àtàwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ nígbà tí wọ́n ń kọrin ayọ̀ lẹ́yìn ìdáǹdè wọn ní Òkun Pupa, nígbà tí Íjíbítì ọ̀tá tí ń lépa wọn ṣègbé—ìyẹn Fáráò àti ẹgbẹ́ ogun rẹ̀.—Ẹ́kísódù 15:4, 5.
Ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n gidi ló jẹ́ fún ẹnikẹ́ni tí ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn bá ṣojú rẹ̀. Kò sẹ́ni tó lè ṣàyà gbàǹgbà pe Jèhófà níjà, tàbí tó lè fọwọ́ pa idà rẹ̀ lójú, tí ẹ̀mí onítọ̀hún ò ní lọ sí i. Àmọ́, ìwọ̀nba oṣù díẹ̀ péré lẹ́yìn náà làwọn ògúnná gbòǹgbò kan ní Ísírẹ́lì—ìyẹn Kórà, Dátánì, Ábírámù, àti àádọ́ta-lé-rúgba [250] ìsọ̀ǹgbè wọn—ṣàyà gbàǹgbà fojú di ọlá àṣẹ tí Ọlọ́run fún Mósè àti Áárónì.—Númérì 16:1-3.
Jèhófà ní kí Mósè kìlọ̀ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n ta kété sí àgọ́ àwọn ọlọ̀tẹ̀ wọ̀nyẹn. Dátánì àti Ábírámù, ti àwọn ti agboolé wọn, sọ pé tinú àwọn làwọn máa ṣe. Mósè wá kéde pé Jèhófà fúnra Rẹ̀ ni yóò jẹ́ kí àwọn èèyàn náà rí i kedere pé àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ti “hùwà àìlọ́wọ̀ sí [Òun].” Gbàrà tó parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni Jèhófà mú kí ilẹ̀ ibi tí wọ́n dúró sí lanu. “Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú Ṣìọ́ọ̀lù láàyè, àti gbogbo àwọn tí ó jẹ́ tiwọn, ilẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí bò wọ́n mọ́lẹ̀.” Kórà àtàwọn ọlọ̀tẹ̀ yòókù ńkọ́? “Iná . . . jáde wá láti ọ̀dọ̀ Jèhófà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí jó àádọ́ta-lérúgba ọkùnrin tí ń sun tùràrí run.”—Númérì 16:23-35; 26:10.
Fáráò àti ẹgbẹ́ ogun rẹ̀, àtàwọn ọlọ̀tẹ̀ wọ̀nyẹn ní aginjù, gbogbo wọn ló ṣègbé nítorí pé wọ́n fojú di ọlá àṣẹ Jèhófà, àti nítorí pé wọn ò gbà pé Ọlọ́run bìkítà fáwọn èèyàn rẹ̀. Nítorí náà, ó jẹ́ ọ̀ràn kánjúkánjú pé kí gbogbo ẹni tó bá fẹ́ ààbò Jèhófà ní àwọn ọjọ́ yánpọnyánrin yìí kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, kí wọ́n sì ṣègbọràn sí i gẹ́gẹ́ bí “Ẹni Gíga Jù Lọ” àti “Olódùmarè.” Bí wọ́n ti ń ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n á máa fi ọ̀rọ̀ ìṣírí Jèhófà sọ́kàn, pé: “Ẹgbẹ̀rún yóò ṣubú àní lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ; kì yóò sún mọ́ ọ. Kìkì ojú rẹ ni ìwọ yóò máa fi wò ó, tí ìwọ yóò sì rí, àní ẹ̀san iṣẹ́ àwọn ẹni burúkú. Nítorí tí ìwọ wí pé: ‘Jèhófà ni ibi ìsádi mi,’ ìwọ ti fi Ẹni Gíga Jù Lọ ṣe ibùgbé rẹ.”—Sáàmù 91:1, 7-9.