Ẹ̀kọ́ Àríkọ́gbọ́n Látinú Ìtàn Róòmù
Ẹ̀kọ́ Àríkọ́gbọ́n Látinú Ìtàn Róòmù
“GẸ́GẸ́ bí ènìyàn, bí mo bá ti bá àwọn ẹranko ẹhànnà jà ní Éfésù.” Àwọn kan rò pé ọ̀rọ̀ tá a fà yọ látinú 1 Kọ́ríńtì 15:32 túmọ̀ sí pé ẹjọ́ tí wọ́n dá àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ni pé kí ó lọ jà ní pápá ìwòran ní Róòmù. Yálà ó jà níbẹ̀ tàbí kò jà níbẹ̀, ìjà àjàkú akátá wọ́pọ̀ láwọn pápá ìwòran ayé ọjọ́un. Kí ni ìtàn sọ fún wa nípa pápá ìwòran àtohun tó ń ṣẹlẹ̀ níbẹ̀?
Gẹ́gẹ́ bí Kristẹni, a máa ń fẹ́ kí ẹ̀rí ọkàn wa bá èrò Jèhófà mu. Èyí sì lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣèpinnu lórí àwọn eré ìnàjú òde òní. Bí àpẹẹrẹ, gbé ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ìwà ipá yẹ̀ wò. Èyí hàn kedere nínú ọ̀rọ̀ wọ̀nyí: “Má ṣe ìlara ọkùnrin oníwà ipá, bẹ́ẹ̀ ni kí o má yan èyíkéyìí nínú àwọn ọ̀nà rẹ̀.” (Òwe 3:31) Ìmọ̀ràn yẹn ló tọ́ àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ sọ́nà, nígbà tí ọ̀pọ̀ èèyàn tó yí wọn ká lọ ń wo ìdíje táwọn ará Róòmù ti ń ja ìjà àjàkú akátá. Ẹ jẹ́ ká gbé ohun tó ń ṣẹlẹ̀ níbi eré wọ̀nyẹn yẹ̀ wò, ká wo ẹ̀kọ́ pàtàkì tí àwọn Kristẹni òde òní lè rí kọ́.
Àwọn eléré méjì tó dìhámọ́ra fẹ́ jà ní pápá ìwòran kan ní Róòmù. Bí wọ́n ṣe kọ́kọ́ ń ju ìdà fìrìfìrì, tó ń ba apata tí wọ́n gbé dání, làwọn èrò ìwòran tí eré náà ti wọ̀ lára ń sa ẹni tí wọ́n fẹ́ràn jù lọ lára àwọn eléré náà ní mẹ́sàn-án mẹ́wàá. Ìjà àjàkú akátá ni. Láìpẹ́ ẹni tó fara pa, tí kò lè jà mọ́, juwọ́ sílẹ̀, ó sì kúnlẹ̀, láti fi hàn pé òun túúbá. Ó wá ń bẹ̀bẹ̀ fún ojú àánú. Ariwo sọ gèè. Àwọn kan nínú èrò ń sọ pé kó ṣíjú àánú wò ó. Àwọn mìíràn ní kó pa á. Gbogbo èèyàn ń retí kí olú ọba sọ̀rọ̀. Bó ṣe ń fetí sí ohun táwọn èrò ń wí, ó lè ní kí wọ́n dá ẹ̀mí ẹni tí wọ́n ṣẹ́gun sí, tàbí kí ó dorí àtàǹpàkò rẹ̀ kọlẹ̀, tó túmọ̀ sí pé pípa ni kí wọ́n pa á.
Àwọn ará Róòmù kúndùn lílọ wo ìjà wọ̀nyí. Ó lè yà ọ́ lẹ́nu láti mọ̀ pé ibi ìsìnkú àwọn èèyàn jàǹkànjàǹkàn ni wọ́n ti kọ́kọ́ ń ja irú ìjà bẹ́ẹ̀. Ohun tá a gbọ́ ni pé àwọn elédè Oscan àti ẹ̀yà Samnite tó wà níbi tá a mọ̀ sí àárín gbùngbùn Ítálì báyìí ló kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ irú ìdíje yìí tó ń ní fífi ènìyàn rúbọ nínú. Ẹ̀mí àwọn òkú ni wọ́n ń fi ẹbọ náà tù lójú. Ohun tí wọ́n ń pe irú ìjà bẹ́ẹ̀ ni munus, tàbí “ẹ̀bùn.” Èyí tó kọ́kọ́ wà lákọọ́lẹ̀ nínú ìjà tí wọ́n jà ní Róòmù wáyé lọ́dún 264 ṣááju Sànmánì Tiwa, nígbà táwọn mẹ́fà múra wọn ní méjìméjì, tí wọ́n sì fìjà pẹẹ́ta ní ọjà màlúù. Ìjà méjìlélógún ni wọ́n jà níbi ìsìnkú Marcus Aemilius Lepidus. Ọgọ́fà èèyàn ló dojú kọra wọn ní méjìméjì níbi ìsìnkú Publius Licinius. Lọ́dún 65 ṣááju Sànmánì Tiwa, òjì-lé-lẹ́gbẹ̀ta èèyàn ni Julius Caesar ní kí wọ́n lọ fìjà pẹẹ́ta ní méjìméjì ní pápá ìwòran.
Òpìtàn nì, Keith Hopkins, sọ pé: “Àwọn olóṣèlú máa ń lo ìgbà ìsìnkú àwọn èèyàn jàǹkànjàǹkàn láti fi polongo ara wọn. Ìjà wọ̀nyí níbi ìsìnkú sì wé mọ́ ọ̀ràn òṣèlú . . . nítorí pé àwọn aráàlú tí ń dìbò nífẹ̀ẹ́ àtimáa wo ìjà wọ̀nyẹn. Ohun tó tiẹ̀ ṣẹlẹ̀ ni pé, ìdí tí ìjà náà fi túbọ̀ gbajúmọ̀ kò ṣẹ̀yìn dídíje tí àwọn èèyàn jàǹkànjàǹkàn tó ń kánjú àtidé ipò ọlá ń bára wọn díje nínú ọ̀ràn òṣèlú.” Nígbà tí Ọ̀gọ́sítọ́sì wà lórí òye (ìyẹn ọdún 27 ṣááju Sànmánì Tiwa títí dé ọdún 14 Sànmánì Tiwa), ìjà munus ti di ẹ̀bùn ńlá—láti fi dá àwọn gbáàtúù lára yá—èyí tí àwọn onípò àṣẹ tó jẹ́ ọlọ́rọ̀ ń ṣètò kí wọ́n lè túbọ̀ gbajúmọ̀ nínú ọ̀ràn ìṣèlú.
Àwọn Oníjà Náà àti Ètò Ìdálẹ́kọ̀ọ́ Wọn
O lè béèrè pé, ‘Àwọn wo ló ń ja ìjà àjàkú akátá yìí?’ Tóò, wọ́n lè jẹ́ ẹrú, tàbí ọ̀daràn tí wọ́n ti dájọ́ ikú fún, àwọn tí wọ́n kó lẹ́rú lójú ogun, tàbí àwọn tí kì í ṣẹrú, àmọ́ tí ìháragàgà tàbí ìrètí àtidi olókìkí àti ọlọ́rọ̀ gbà lọ́kàn. Gbogbo wọn ń gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ ní iléèwé tó dà bí ọgbà ẹ̀wọ̀n. Ìwé náà, Giochi e spettacoli (Eré Ìdárayá àti Èrò Ìwòran) ròyìn pé àwọn oníjà tó ń gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ “ni àwọn ẹ̀ṣọ́ máa ń ṣọ́ tọwọ́tẹsẹ̀, pẹ̀lú ìkálọ́wọ́kò lójú méjèèjì, àtàwọn òfin líle koko gan-an, àti ìyà mímúná . . . Ọwọ́ líle tí wọ́n fi ń mú wọn yìí sábà máa ń fa ìpara-ẹni, rúkèrúdò àti ìṣọ̀tẹ̀.” Ilé ẹ̀kọ́ ìjà àjàkú-akátá tó tóbi jù lọ ní Róòmù ní àwọn yàrá kótópó tó gba ẹgbẹ̀rún èèyàn. Kálukú ló ní irú ìjà tó ń kọ́. Àwọn kan ń fi ìhámọ́ra, apata àti idà jà. Àwọn mìíràn ń fi àwọ̀n àti ọkọ̀ oníga mẹ́ta jà. Àwọn míì sì rèé, ńṣe là ń kọ́ wọn láti bá àwọn ẹranko ẹhànnà jà, nínú eré olókìkí tí wọ́n ń pè ní eré ọdẹ. Àbí ìyẹn gan-an ni Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ ni?
Àwọn onígbọ̀wọ́ eré wọ̀nyí lè wá ìrànlọ́wọ́ lọ sọ́dọ̀ àwọn oníṣòwò, tó máa ń kó àwọn ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún tàbí méjìdínlógún jọ, tí wọ́n á sì máa kọ́ wọn láti di alájàkú-akátá. Òwò tí ń mówó wọlé gan-an ni ṣíṣe fàyàwọ́ àwọn èèyàn fún eré yìí. Eré kan tó hẹ̀rẹ̀ǹtẹ̀, tí Trajan fi ṣayẹyẹ ìjagunmólú rẹ̀, ní àwọn oníjà tó tó ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá
àtàwọn ẹranko ẹhànnà tó tó ẹgbẹ̀rún mọ́kànlá nínú.Bí Ọjọ́ Kan Ṣe Máa Ń Rí Ní Pápá Ìwòran
Àárọ̀ ni wọ́n máa ń ṣe eré ọdẹ ní pápá ìwòran. Wọ́n lè kó onírúurú ẹranko ẹhànnà wá sí pápá ìwòran. Àwọn èrò máa ń gbádùn wíwo ìjà akọ màlúù àti béárì. Ńṣe ni wọ́n máa ń so àwọn méjèèjì pọ̀, tí wọ́n á máa jà títí ọ̀kan á fi kú. Lẹ́yìn náà ni ọdẹ kan á wa pa ẹranko tó pa ìkejì rẹ̀. Àwọn ìjà tó tún wọ́pọ̀ ni dídẹ kìnnìún sí ẹkùn, tàbí dídẹ erin sí béárì. Láìka iye tó máa ná wọn sí, àwọn ọdẹ máa ń fi bí àwọn ṣe gbówọ́ tó hàn nígbà tí wọ́n bá fẹ́ pa àwọn ẹranko tí wọ́n kó wá láti igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ ọba náà—àwọn ẹranko bí àmọ̀tẹ́kùn, àgbáǹréré, erinmi, àgùnfọn, pẹnlẹpẹ̀, ràkúnmí, ìkookò, ìmàdò àti ẹtu.
Àwọn onírúurú àrà tí wọ́n máa ń dá ní pápá ìwòran náà tún ń jẹ́ kí eré wọ̀nyí jẹ́ mánigbàgbé. Wọ́n máa ń lo òkúta, kòtò omi àti igi láti jẹ́ kí ibẹ̀ dà bí inú ẹgàn. Nínú àwọn pápá ìwòran kan, bí idán ló máa ń rí nígbà táwọn ẹranko náà bá jáde síta. Ẹ̀rọ agbé-nǹkan-ròkè tí ń bẹ lábẹ́lẹ̀, tó ní àwọn ilẹ̀kùn títì, ló máa ń gbé wọn wá sórí pápá láti abẹ́lẹ̀. Àìmọ irú àrà tí ẹranko kan yóò dá nígbà tó bá dójú agbo tún ń jẹ́ kí eré náà gba àwọn èèyàn lọ́kàn. Ṣùgbọ́n ó jọ pé ohun tó ń wú àwọn èèyàn lórí jù lọ nínú eré ọdẹ ni ìwà òǹrorò inú eré náà.
Pípa ló wá kù báyìí. Wọ́n máa ń fẹ́ kó kúrò ní ọ̀ràn eré lásán. Àwọn kan ṣe eré onítàn kan tó jẹ́ pé àwọn kan lára àwọn tó ṣeré náà kú ní ti gidi.
Tó bá di ọ̀sán, ìsọ̀rí-ìsọ̀rí àwọn oníjà tí wọ́n dì-káká dì-kuku, tí wọ́n ti kọ́ onírúurú ìjà tó yàtọ̀ síra, á wá bẹ̀rẹ̀ sí bára wọn jà. Àwọn míì lára àwọn tó ń gbé àwọn tó kú sójú agbo máa ń múra bí irúnmọlẹ̀.
Ipa Tó Ń Ní Lórí Òǹwòran
Kò sí bí ìjà yìí ṣe le tó, tó máa mú kí àwọn èrò ìwòran sọ pé ó tó gẹ́ẹ́. Ìyẹn ni wọ́n fi ń da kòbókò bo àwọn oníjà, tí wọ́n á sì máa fi irin gbígbóná jó wọn lára, láti túbọ̀ lé wọn lóró. Àwọn èrò á máa kígbe pé: “Kí ló dé tó ń bẹ̀rù idà? Kí ló dé tó ń ṣá a bí ẹni tọ́wọ́ rẹ̀ rọ? Kí ló dé tí kò [kúkú] kú? Ẹ kẹ́gba bò ó, kó lè jà dáadáa! Kí wọ́n máa fi idà ṣá ara wọn nígbá àyà jọ̀ọ́!” Seneca, òṣèlú ará Róòmù nì, kọ̀wé pé ní àkókò ìsinmi kan, ìfilọ̀ dún pé: “A óò gé orí àwọn kan ní àkókò ìsinmi yìí kí ọwọ́ má bàa dilẹ̀ pátápátá!”
Abájọ tí Seneca fi sọ pé nígbà tóun bá wo eré wọ̀nyẹn tán, òun á wá “túbọ̀ di òǹrorò àti ẹhànnà.” Òótọ́ ọ̀rọ̀ tí òǹwòran yẹn sọ gbèrò o. Ṣé kì í ṣe ohun kan náà ló ń ṣẹlẹ̀ sáwọn kan tó ń wo àwọn eré kan lóde òní, àbí kì í ṣe pé àwọn náà ń “túbọ̀ di òǹrorò àti ẹhànnà” ni?
Àwọn kan sọ pé àwọn tiẹ̀ dúpẹ́ pé àwọn padà wálé. Nígbà tẹ́nì kan tó wá wòran gbẹ́nu ní ìgbékúgbèé sí Domitian, olú ọba náà ní kí wọ́n wọ́ ọ
kúrò ní ìjókòó rẹ̀, kí wọ́n sọ ọ́ sẹ́nu àwọn ajá. Àìsí àwọn ọ̀daràn fún pípa ló jẹ́ kí Caligula pàṣẹ pé kí wọ́n lọ kó àwọn kan lára èrò ìwòran, kí wọ́n sì sọ wọ́n sẹ́nu àwọn ẹranko ẹhànnà. Nígbà tí ẹ̀rọ orí ìtàgé kò ṣiṣẹ́ bí Kíláúdíù ṣe fẹ́, ló bá pàṣẹ pé kí àwọn tó ń tún un ṣe bọ́ sójú agbo kí wọ́n lọ jà.Ìtara òdì àwọn òǹwòran tún máa ń fa àjálù àti ìjà ìgboro. Wọ́n ròyìn pé gbọ̀ngàn ńlá kan ní àríwá Róòmù wó pa ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn. Rògbòdìyàn bẹ́ sílẹ̀ nígbà tí eré kan ń lọ lọ́wọ́ nílùú Pompeii lọ́dún 59 Sànmánì Tiwa. Tacitus ròyìn pé nígbà tí ìjà náà bẹ́ láàárín àwọn ọmọ onílùú àtàwọn tó wá bá wọn díje láti ìlú òdìkejì, ńṣe ni wọ́n kọ́kọ́ ń bú ara wọn. Ìgbà tó yá ńṣe ni wọ́n ń sọ̀kò lu ara wọn. Nígbà tọ́ràn ọ̀hún wá dójú ẹ̀ tán, ńṣe ni wọ́n yọ idà síra wọn. Wọ́n ṣá àwọn kan lọ́gbẹ́ yánnayànna, ọ̀pọ̀ sì kú.
Ẹ̀kọ́ Àríkọ́gbọ́n Tó Ṣe Kedere
Ìpàtẹ kan tí wọ́n ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yìí (Sangue e arena, “Ẹ̀jẹ̀ àti Yanrìn”) ní Gbọ̀ngàn Ìwòran tó wà ní Róòmù ránni létí àwọn ohun tó jọ munus lóde òní. Lọ́nà tó gba àfiyèsí, ó fi àwọn fíìmù kan hàn nípa bíbá akọ màlúù jà, ẹ̀ṣẹ́ kíkàn, àwọn jàǹbá burúkú nínú àwọn eré tí wọ́n ń fi ọkọ̀ àti alùpùpù sá, àwọn ìjà àjàkú akátá láàárín àwọn eléré ìdárayá, àti ìjà ìgboro láàárín àwọn òǹwòran. Àwòrán tí wọ́n fi parí fíìmù náà ni ti Gbọ̀ngàn Ìwòran náà. Kí lo rò pé àwọn tó wá síbi ìpàtẹ yìí máa parí èrò sí? Mélòó lára wọn ló máa fèyí kọ́gbọ́n?
Àwọn eré ìdárayá kan tó wọ́pọ̀ láwọn ilẹ̀ kan lóde òní ni ìjà láàárín ajá, àkùkọ, akọ màlúù àtàwọn eré ìdárayá mìíràn tó kún fún ìwà ipá. Àwọn eléré ìdárayá tí ń fi ọkọ̀ àtàwọn ohun ìrìnnà sáré àsápajúdé ń fi ẹ̀mí ara wọn wewu nítorí àtimórí èrò ìwòran wú. Tún rántí àwọn eré orí tẹlifíṣọ̀n ojoojúmọ́. Ìwádìí ní àwọn ilẹ̀ tó ti gòkè àgbà fi hàn pé ọmọdé tó sábà máa ń wo tẹlifíṣọ̀n ti lè rí ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ìpànìyàn àti ọ̀kẹ́ márùn-ún ìwà jàgídíjàgan nígbà tó máa fi pé ọmọ ọdún mẹ́wàá.
Tertullian, tó jẹ́ òǹkọ̀wé ní ọ̀rúndún kẹta sọ pé eré táwọn èèyàn lọ ń wò “kò sí níbàámu pẹ̀lú ẹ̀sìn tòótọ́ àti ìgbọràn tòótọ́ sí Ọlọ́run tòótọ́.” Ó ka àwọn tó lọ ń wo eré wọ̀nyẹn sí agbódegbà àwọn tó ń pààyàn níbi àwọn eré náà. Lónìí ńkọ́? Ẹnì kan lè béèrè pé, ‘Mo ha kúndùn wíwo ìtàjẹ̀sílẹ̀, ìpànìyàn tàbí ìwà ipá lórí tẹlifíṣọ̀n tàbí lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì bí?’ Ó tún yẹ ká rántí Sáàmù 11:5 tó sọ pé: “Jèhófà tìkára rẹ̀ ń ṣàyẹ̀wò olódodo àti ẹni burúkú, dájúdájú, ọkàn Rẹ̀ kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó bá nífẹ̀ẹ́ ìwà ipá.”
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 28]
Ìjà Láti Fi “Tu Àwọn Òkú Lójú”
Nígbà tí Tertullian, òǹkọ̀wé tó gbé ayé ní ọ̀rúndún kẹta, ń sọ̀rọ̀ nípa ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ìjà náà, ó sọ pé: “Àwọn ará ìgbàanì rò pé ńṣe làwọn ń fi irú eré yìí júbà àwọn òkú, àgàgà lẹ́yìn tí wọ́n fi ìwà òǹrorò tí wọ́n kà sí ti ayé ọ̀làjú kún un. Láyé àtijọ́, nítorí ìgbàgbọ́ náà pé ẹ̀jẹ̀ èèyàn la fi ń ṣètùtù fún ọkàn àwọn òkú, ńṣe ni wọ́n ń fi àwọn òǹdè tàbí àwọn ahẹrẹpẹ ẹrú tí wọ́n rà rúbọ nígbà ìsìnkú. Lẹ́yìn náà, wọ́n ronú pé á dáa láti sọ ọ́ di eré ìdárayá kí wọ́n lè fi bo ìwà ibi wọn mọ́lẹ̀. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé lẹ́yìn tí wọ́n bá ti fún àwọn òǹdè náà ní ìdánilẹ́kọ̀ọ́ lórí lílo àwọn ohun ìjà tó wà láyé ìgbà yẹn, kí wọ́n lè mọ̀ ọ́n lò dáadáa—ohun tí wọ́n kọ́ wọn ni láti mọ èèyàn pa!—wọ́n á wá pa àwọn alára ní itẹ́ lọ́jọ́ ìsìnkú. Nítorí náà, ìpànìyàn làwọn ará ìgbà yẹn fi ń tu ara wọn nínú nígbà téèyàn bá kú. Bí munus ṣe bẹ̀rẹ̀ nìyẹn. Àmọ́ nígbà tó yá, bí eré wọ̀nyẹn ṣe túbọ̀ ń lárinrin sí i náà ni ìwà òǹrorò tí wọ́n ń hù nínú rẹ̀ túbọ̀ ń gogò sí i; nítorí pé ayẹyẹ náà kò lè dùn, àyàfi bí àwọn ẹranko ẹhànnà pẹ̀lú bá láǹfààní láti fa àwọn èèyàn ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ. Ohun tí wọ́n fi tu àwọn òkú lójú ni wọ́n kà sí ààtò ìsìnkú.”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
Àṣíborí àtohun táwọn eléré fi ń bo ojúgun láyé ọjọ́un
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Àwọn Kristẹni ìgbàanì kórìíra eré oníwà ipá. Ìwọ ńkọ́?
[Àwọn Credit Line]
Ẹ̀ṣẹ́ kíkàn: Dave Kingdon/Index Stock Photography; ọkọ̀ tó rún wómúwómú: AP Photo/Martin Seppala
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 26]
Phoenix Art Museum, Arizona/Bridgeman Art Library