Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ǹjẹ́ ó bójú mu kí Kristẹni òjíṣẹ́ lọ sọ ọ̀rọ̀ ìsìnkú ẹni tó pa ara rẹ̀?

Olúkúlùkù Kristẹni òjíṣẹ́ ló máa dá pinnu bóyá ẹ̀rí ọkàn òun máa gba òun láyè láti lọ sọ ọ̀rọ̀ ìsìnkú ẹni tó jọ pé ó pa ara rẹ̀. Nígbà tó bá ń ṣèpinnu, ó yẹ kó ronú lórí àwọn ìbéèrè bí: Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo pípa ara ẹni? Ṣé ó dìídì fọwọ́ ara rẹ̀ para rẹ̀ ni? Ṣé ìdààmú ọpọlọ tàbí ìmí ẹ̀dùn ló jẹ́ kó para rẹ̀? Ojú wo làwọn ará àdúgbò ibẹ̀ fi ń wo pípa ara ẹni?

Gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, a fẹ́ mọ ojú tí Jèhófà fi ń wo pípa ara ẹni. Ẹ̀mí ènìyàn ṣeyebíye, ó sì jẹ́ ohun mímọ́ lójú Jèhófà. (Jẹ́nẹ́sísì 9:5; Sáàmù 36:9) Kéèyàn mọ̀ọ́mọ̀ para rẹ̀ là ń pè ní fífọwọ́-ara-ẹni-para-ẹni. Ó sì jẹ́ ohun tó burú jáì lójú Ọlọ́run. (Ẹ́kísódù 20:13; 1 Jòhánù 3:15) Ǹjẹ́ òtítọ́ yìí fagi lé sísọ ọ̀rọ̀ ìsìnkú ẹni tó para rẹ̀?

Ẹ jẹ́ ká gbé ọ̀ràn Sọ́ọ̀lù Ọba Ísírẹ́lì yẹ̀ wò. Nígbà tó rí i pé òun ò lè mórí bọ́ nínú ogun tó bá àwọn Filísínì jà gbẹ̀yìn, dípò kó jẹ́ káwọn ọ̀tá òun pa òun nípa ìyà, ńṣe ni “Sọ́ọ̀lù mú idà náà, ó sì ṣubú lé e.” Nígbà táwọn Filísínì rí òkú rẹ̀, wọ́n dè é mọ́ odi ìlú Bẹti-ṣánì. Nígbà táwọn ará Jabẹṣi-gílíádì gbọ́ ohun táwọn ará Filísínì ṣe, wọ́n lọ gbé òkú náà, wọ́n sì sun ún níná. Wọ́n wá kó egungun rẹ̀, wọ́n lọ sin ín. Wọ́n tiẹ̀ gbààwẹ̀ ọjọ́ méje, tó jẹ́ ààtò ọ̀fọ̀ ṣíṣe láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. (1 Sámúẹ́lì 31:4, 8-13; Jẹ́nẹ́sísì 50:10) Nígbà tí Dáfídì, ẹni àmì òróró Jèhófà, gbọ́ ohun táwọn ará Jabẹṣi-gílíádì ṣe, ohun tó sọ ni pé: “Kí Jèhófà bù kún yín, nítorí pé ẹ ṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́ yìí sí olúwa yín, sí Sọ́ọ̀lù, ní ti pé ẹ sin ín. Wàyí o, kí Jèhófà lo inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti ìṣeégbẹ́kẹ̀lé sí yín.” (2 Sámúẹ́lì 2:5, 6) Àkọsílẹ̀ tó ní ìmísí yìí kò sọ pé a bá àwọn ará Jabẹṣi-gílíádì wí nítorí pé wọ́n ṣe ohun tá a lè pè ní ààtò ìsìnkú fún Sọ́ọ̀lù Ọba. Fi èyí wé ọ̀ràn àwọn tá ò ṣe ààtò ìsìnkú fún nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. (Jeremáyà 25:32, 33) Kristẹni òjíṣẹ́ kan lè gbé ìtàn Sọ́ọ̀lù yẹ̀ wò nígbà tó bá fẹ́ pinnu bóyá òun lè sọ àsọyé ìsìnkú ẹni tó para rẹ̀.

Òjíṣẹ́ náà tún lè ronú lórí ìdí tá a fi ń sọ àsọyé ìsìnkú. Láìdàbí àwọn tó gba àìleèkú ọkàn gbọ́, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í ṣe ààtò ìsìnkú nítorí ẹ̀kọ́ èké náà pé olóògbé náà ti lọ sí ọ̀run alákeji. Kàkà kí ó jẹ́ fún àǹfààní olóògbé náà, ìdí pàtàkì fún ṣíṣe ààtò ìsìnkú ni láti tu àwọn tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ nínú, ká sì sọ nípa ipò àwọn òkú fáwọn tó wà níbẹ̀. (Oníwàásù 9:5, 10; 2 Kọ́ríńtì 1:3-5) Ìdí pàtàkì mìíràn tá a fi ń sọ àsọyé ìsìnkú ni láti ran gbogbo àwọn tó pésẹ̀ lọ́wọ́ láti ronú lórí bí ìwàláàyè ṣe kúrú tó. (Oníwàásù 7:2) Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ níbi ìsìnkú ẹni tó para rẹ̀ máa ṣiṣẹ́ fún ète wọ̀nyí?

Lóòótọ́, àwọn kan lè ronú pé ẹni náà fọwọ́ ara rẹ̀ para rẹ̀, nígbà tó mọ̀ dájú pé ńṣe lòun ń dẹ́ṣẹ̀ sí Jèhófà. Ṣùgbọ́n ǹjẹ́ ó sábà máa ń ṣeé ṣe láti rí àrídájú irú èrò bẹ́ẹ̀? Ó ha lè jẹ́ pé kò mọ̀gbà tóun ṣe bẹ́ẹ̀ ni bí? Àwọn kan tó gbìdánwò láti para wọn máa ń pèrò dà, tí wọn á sì jáwọ́ nínú ṣíṣe bẹ́ẹ̀. Èèyàn ò lè kú tán kó wá máa ronú pìwà dà ohun tó ṣe.

Kókó pàtàkì mìíràn ni ìdààmú ọpọlọ àti ìmí ẹ̀dùn tó máa ń mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn para wọn. Láìsí àní-àní, a lè sọ pé ohun tó le ju ẹ̀mí wọn ló sún wọn para wọn. Àwọn ìròyìn kan ṣírò rẹ̀ pé ìpíndọ́gba mẹ́sàn-án nínú mẹ́wàá àwọn tó para wọn ló máa ń ní àwọn ìṣòro tó jẹ mọ́ ọ̀ràn ọpọlọ, ìmí ẹ̀dùn tàbí tí oògùn líle ti di bára kú fún. Ǹjẹ́ Jèhófà yóò dárí ji àwọn tó fọwọ́ ara wọn para wọn nínú irú ipò yìí? A ò lè sọ bóyá olóògbé náà dá ẹ̀ṣẹ̀ tí kò ní ìdáríjì lójú Jèhófà. Kristẹni òjíṣẹ́ lè gbé ipò ìlera olóògbé náà yẹ̀ wò bó ṣe ń ronú nípa bóyá kóun sọ àsọyé ìsìnkú ẹni náà tó para rẹ̀.

Kókó kan tún wà tó yẹ ká gbé yẹ̀ wò: Ojú wo làwọn ará àdúgbò ibẹ̀ fi ń wo ìpara ẹni àti ikú onítọ̀hún? Kókó yìí ní pàtàkì yẹ fún àfiyèsí àwọn alàgbà, tó jẹ́ pé orúkọ rere ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò náà ló jẹ wọ́n lógún. Bí wọ́n bá ronú lórí ìhà táwọn ará àdúgbò kọ sí ọ̀ràn ìpara ẹni, àgàgà ti ẹni tó para rẹ̀ yìí, àwọn alàgbà lè pinnu pé àwọn ò ní lọ́wọ́ sí irú ètò ìsìnkú bẹ́ẹ̀ ní gbangba tàbí kí wọ́n ṣe é nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba.

Síbẹ̀ náà, bí wọ́n bá pe Kristẹni òjíṣẹ́ kan pé kó wá báwọn sọ ọ̀rọ̀ ìsìnkú náà, ó lè pinnu pé òun gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan lè ṣe bẹ́ẹ̀ ní tòun. Bó bá pinnu láti sọ àsọyé náà, ó gbọ́dọ̀ ṣọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀, kí ó má là á mọ́lẹ̀ pé ó ṣeé ṣe kí onítọ̀hún ní àjíǹde tàbí kí ó máà ní àjíǹde. Ọwọ́ Jèhófà ni ìrètí ọjọ́ ọ̀la èyíkéyìí fún àwọn òkú wà. Kò sẹ́ni tó lè sọ bóyá olóògbé náà yóò jíǹde tàbí kò ní jíǹde. Òjíṣẹ́ náà lè jẹ́ kí ọ̀rọ̀ òun dá lórí kìkì àwọn òtítọ́ Bíbélì nípa ikú, kó sì tu àwọn tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ nínú.