Ìrànlọ́wọ́ Ń Bọ̀ Lọ́nà Fáwọn Tí Ìyàn Mú!
Ìrànlọ́wọ́ Ń Bọ̀ Lọ́nà Fáwọn Tí Ìyàn Mú!
O LÈ béèrè pé: ‘Irú ìyàn wo nìyẹn?’ Ìyàn oúnjẹ tẹ̀mí ni o! Wòlíì Hébérù ìgbàanì kan sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìyàn yìí pé: “‘Wò ó! Àwọn ọjọ́ ń bọ̀,’ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, ‘èmi yóò sì rán ìyàn sí ilẹ̀ náà dájúdájú, ìyàn, tí kì í ṣe fún oúnjẹ, àti òùngbẹ, tí kì í ṣe fún omi, bí kò ṣe fún gbígbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà.’” (Ámósì 8:11) Nítorí àtiṣèrànwọ́ fáwọn tí ìyàn tẹ̀mí náà mú ni àwọn méjìdínláàádọ́ta tí wọ́n jẹ́ ọmọ kíláàsì kejìléláàádọ́fà ti Watchtower Bible School of Gilead, tó wà ní Patterson, New York, ṣe ń lọ sí ilẹ̀ mọ́kàndínlógún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní kọ́ńtínẹ́ǹtì márùn-ún àtàwọn erékùṣù òkun.
Wọ́n ti gbára dì dáadáa, kì í ṣe pẹ̀lú ẹran àti ọkà o, àmọ́ pẹ̀lú ìmọ̀, ìrírí àti ìdánilẹ́kọ̀ọ́. Fún odindi oṣù márùn-ún gbáko ni wọ́n fi kópa nínú ìjìnlẹ̀ ẹ̀kọ́ Bíbélì tá a ṣètò rẹ̀ láti fún ìgbàgbọ́ wọn lókun fún iṣẹ́ ìsìn míṣọ́nnárì nílẹ̀ òkèèrè. Ní March 9, 2002, àwọn ẹgbẹ̀rún márùn-ún, ọgọ́rùn-ún márùn-ún, àti mẹ́rìnléláàádọ́ta [5,554] èèyàn tó pésẹ̀ síbi ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege náà fi tayọ̀tayọ̀ tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́.
Stephen Lett, tó ń sìn gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, fi ọ̀yàyà bẹ̀rẹ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà. Ó kí ọ̀pọ̀ àlejò tó wá láti àwọn ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lágbàáyé káàbọ̀ lọ́nà àkànṣe. Ẹ̀yìn ìyẹn ló bẹ̀rẹ̀ sí fi ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pé, “Ẹ̀yin ni ìmọ́lẹ̀ ayé” ṣàpèjúwe iṣẹ́ àwọn míṣọ́nnárì lọ́la náà. (Mátíù 5:14) Ó ṣàlàyé pé: ‘Nígbà tẹ́ ẹ bá débi iṣẹ́ tá a yàn fún yín, ẹ ó “tan ìmọ́lẹ̀” sí onírúurú iṣẹ́ àgbàyanu Jèhófà, nípa jíjẹ́ kí àwọn ọlọ́kàntútù rí ẹwà Jèhófà àti àwọn ète rẹ̀.’ Arákùnrin Lett rọ àwọn míṣọ́nnárì náà láti fi ìmọ́lẹ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run túdìí àṣírí òkùnkùn ẹ̀kọ́ èké, kí wọ́n sì tọ́ àwọn tó ń wá òtítọ́ sọ́nà.
Níní Ẹ̀mí Tó Dára Ń Jẹ́ Kéèyàn Ṣe Àṣeyọrí
Lẹ́yìn tí alága parí ọ̀rọ̀ tó fi ṣí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà, Baltasar Perla, tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka ti Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, sọ èyí tó jẹ́ àkọ́kọ́ nínú ọ̀wọ́ àwọn ọ̀rọ̀ tó wà fún ríran àwọn tó ti kẹ́kọ̀ọ́ yege náà lọ́wọ́ kí wọ́n lè di míṣọ́nnárì tó kẹ́sẹ járí. Ó sọ̀rọ̀ lórí kókó náà, “Ẹ Jẹ́ Onígboyà àti Alágbára, Kí Ẹ sì Gbé Ìgbésẹ̀.” (1 Kíróníkà 28:20) Sólómọ́nì Ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ bàǹtàbanta kan tí kò tíì ṣe irú rẹ̀ rí—ìyẹn ni pé kí ó kọ́ tẹ́ńpìlì sí Jerúsálẹ́mù. Sólómọ́nì gbé ìgbésẹ̀, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, ó kọ́ tẹ́ńpìlì náà. Nígbà tí Arákùnrin Perla ń ṣàlàyé bí ọ̀rọ̀ yìí ṣe kan kíláàsì náà, ó sọ pé: ‘Ẹ ti gba iṣẹ́ tuntun, ti dídi míṣọ́nnárì, ẹ sì ní láti jẹ́ onígboyà àti alágbára.’ Láìsí àní-àní, ìdánilójú náà pé Jèhófà kò ní kọ̀ wọ́n sílẹ̀ tàbí kí ó fi wọ́n sílẹ̀ bí wọn ò bá ti kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, fi àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà lọ́kàn balẹ̀ gan-an ni. Arákùnrin Perla mórí àwùjọ wú nígbà tó parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú ìrírí ara rẹ̀, ó ní: ‘Ẹ lè ṣe àṣeyọrí gan-an gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì. Àwọn míṣọ́nnárì ló kọ́ èmi àti ìdílé mi lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́!’
“Gbára Lé Jèhófà Láti Ṣàṣeyọrí” ni àkòrí ọ̀rọ̀ tí Samuel Herd, tí òun náà jẹ́ ọ̀kan lára Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso sọ. Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà fẹ́ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ míṣọ́nnárì tí wọ́n máa fi ìgbésí ayé wọn ṣe, àṣeyọrí wọn sì sinmi lórí àjọṣe àárín àwọn àti Jèhófà. Arákùnrin Herd gbà wọ́n níyànjú pé: ‘Ẹ ti gba ìmọ̀ kún ìmọ̀ nínú Bíbélì nípasẹ̀ ẹ̀kọ́ tí ẹ gbà ní Gílíádì. Ẹ ti ń fi tayọ̀tayọ̀ gbà á. Àmọ́ nísinsìnyí, kí ẹ bàa lè ṣe àṣeyọrí ní ti gidi, ẹ ní láti bẹ̀rẹ̀ sí fúnni ní ohun tí ẹ ti kọ́.’ (Ìṣe 20:35) Àwọn míṣọ́nnárì náà yóò láǹfààní láti ṣe èyí bí wọ́n ṣe ń ‘tú ara wọn jáde’ nítorí àwọn ẹlòmíràn.—Fílípì 2:17.
Ọ̀rọ̀ ìdágbére wo ni àwọn olùkọ́ náà máa sọ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́? Mark Noumair gbé àkòrí ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó pè ní, “Jókòó Jẹ́ẹ́ Títí Tó O Fi Máa Rí Ibi Tí Ọ̀ràn Náà Yóò Já Sí,” ka ìwé Rúùtù 3:18. Olùbánisọ̀rọ̀ náà lo àpẹẹrẹ Náómì àti Rúùtù láti gba àwọn tó ti kẹ́kọ̀ọ́ yege níyànjú pé kí wọ́n ní ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún nínú ìṣètò tí ètò àjọ Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé ti gbé kalẹ̀, kí wọ́n sì bọ̀wọ̀ fún ọlá àṣẹ àtọ̀runwá. Arákùnrin Noumair sọ ọ̀rọ̀ tó wọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà lọ́kàn ṣinṣin nígbà tó sọ pé: ‘Àwọn ìgbà míì lè wà tí o ò ní mọ ìdí tí wọ́n fi ṣe àwọn ìpinnu kan tó kàn ọ́ tàbí tó o lè gbà tọkàntọkàn pé ọ̀nà mìíràn ló yẹ kí wọ́n gbà ṣe ohun kan. Kí lo máa ṣe? Ṣé wàá dìde tí wàá sì ṣe ìfẹ́ inú rẹ ni tàbí wàá “jókòó jẹ́ẹ́,” tí wàá fọkàn tán ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run, pẹ̀lú ìgbẹ́kẹ̀lé pé, bí àkókò ti ń lọ, ohun tó dára ni yóò tibẹ̀ jáde.’ (Róòmù 8:28) Láìsí àní-àní, ìmọ̀ràn rẹ̀ pé ‘kí wọ́n pọkàn pọ̀ sórí mímú kí ire Ìjọba náà tẹ̀ síwájú, kí wọ́n máa wo ohun tí ètò àjọ Jèhófà ń ṣe dípò tí wọn ó fi máa wo ìwà àwọn èèyàn,’ yóò wúlò gan-an fún àwọn míṣọ́nnárì lọ́la wọ̀nyí nínú iṣẹ́ wọ́n nílẹ̀ òkèèrè.
Wallace Liverance, tí òun fúnra rẹ̀ jẹ́ míṣọ́nnárì tẹ́lẹ̀, tó sì ti di olùkọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì báyìí, ló sọ apá tó kẹ́yìn nínú ọ̀wọ́ àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi ṣí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà. Àkòrí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni “Ẹ Pọkàn Pọ̀, Ẹ Dúró Nínú Iṣẹ́ Ìsìn Ọlọ́run.” Ó fi hàn pé rírí ìṣubú Bábílónì àti kíka ohun tí Jeremáyà sọ tẹ́lẹ̀ ló jẹ́ kí Dáníẹ́lì fòye mọ̀ pé ìdáǹdè àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò nígbèkùn ti sún mọ́lé. (Jeremáyà 25:11; Dáníẹ́lì 9:2) Dáníẹ́lì mọ̀ pé Jèhófà ní àkókò tí ó yàn kalẹ̀, ìyẹn sì ràn án lọ́wọ́ láti pọkàn pọ̀ sórí ìmúṣẹ ète Ọlọ́run. Ní ìyàtọ̀ pátápátá síyẹn, ńṣe làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ayé ọjọ́ wòlíì Hágáì sọ pé: “Àkókò kò tíì tó.” (Hágáì 1:2) Wọn ò fọkàn sí àkókò tí wọ́n wà rárá, fàájì ni wọ́n ń bá kiri, wọ́n pa iṣẹ́ tá a tìtorí rẹ̀ dá wọn nídè kúrò ní Bábílónì tì, ìyẹn títún tẹ́ńpìlì náà kọ́. Arákùnrin Liverance parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Nítorí náà, ẹ pọkàn pọ̀ nípa fífi ète Jèhófà sọ́kàn ní gbogbo ìgbà.”
Lawrence Bowen, ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì ló bójú tó apá tó ní àkòrí náà, “Jèhófà Ń Bù Kún Àwọn Tó Ń Lo Ọ̀rọ̀ Náà Tí Ó Yè.” (Hébérù 4:12) Ìrírí táwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ní nínú iṣẹ́ ìsìn pápá ni apá yìí dá lé lórí. Ó fi hàn wọ́n bí Jèhófà ṣe ń bù kún àwọn tó ń lo Bíbélì nígbà tí wọ́n bá ń wàásù àti nígbà tí wọ́n bá ń kọ́ni. Olùdarí apá yìí tọ́ka sí i pé Jésù Kristi fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fún gbogbo àwọn òjíṣẹ́ Ọlọ́run: ‘Jésù sọ ni kedere pé ohun tí òun ń fi kọ́ni kò pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ òun, bí kò ṣe látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.’ Àwọn olóòótọ́ ọkàn mọ̀ pé òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọ́n sì tẹ́wọ́ gbà á. (Jòhánù 7:16, 17) Bọ́rọ̀ ṣe rí lónìí gan-an nìyẹn.
Ẹ̀kọ́ Gílíádì Ń Múni Gbára Dì fún Iṣẹ́ Rere Gbogbo
Ẹ̀yìn ìyẹn ni Richard Abrahamson àti Patrick LaFranca, tí wọ́n ti wà ní Bẹ́tẹ́lì tipẹ́, fọ̀rọ̀ wá àwọn mẹ́fà tó ti kẹ́kọ̀ọ́ yege ní Gílíádì, tí wọ́n sì ń sìn ní onírúurú apá iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún báyìí, lẹ́nu wò. Ó jẹ́ nǹkan ìṣírí gan-an fún kíláàsì kejìléláàádọ́fà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ yege láti gbọ́ pé lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún táwọn mẹ́fà yẹn ti kẹ́kọ̀ọ́ yege, wọ́n ń bá a lọ ní lílo ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n gbà ní Gílíádì nínú kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ṣíṣe ìwádìí, àti wíwà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn nínú iṣẹ́ wọn.
Theodore Jaracz, tó jẹ́ ọ̀kan lára Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ló sọ lájorí ọ̀rọ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà. “Ohun Tá A Ṣàṣeyọrí Rẹ̀ Nípa Fífarada Ìkórìíra Sátánì” ni àkòrí ọ̀rọ̀ ọ̀hún. Láti oṣù márùn-ún sẹ́yìn ni àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ti ń gbé ní àyíká onífẹ̀ẹ́, tó jẹ́ ti ìṣàkóso Ọlọ́run. Àmọ́, inú ayé ọ̀tá là ń gbé, gẹ́gẹ́ bá a ṣe ṣàlàyé fún wọn nínú kíláàsì. Àwọn èèyàn Jèhófà ń dojú kọ àtakò káàkiri ayé. (Mátíù 24:9) Nípa lílo àwọn ìtàn Bíbélì bíi mélòó kan, Arákùnrin Jaracz là á mọ́lẹ̀ pé ‘ńṣe ni Èṣù dìídì dójú sọ wá. A gbọ́dọ̀ jẹ́ kí àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà lágbára sí i, kí a sì ní okun láti kojú àwọn àdánwò náà.’ (Jóòbù 1:8; Dáníẹ́lì 6:4; Jòhánù 15:20; Ìṣípayá 12:12, 17) Arákùnrin Jaracz parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ nípa sísọ pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò dẹ́kun kíkórìíra àwa èèyàn Ọlọ́run, síbẹ̀ ‘kò sí ohun ìjà yòówù tí wọ́n bá ṣe sí wa, tí yóò ṣe àṣeyọrí, gẹ́gẹ́ bí Aísáyà 54:17 ṣe sọ. Jèhófà yóò rí sí i pé a dá wa nídè ní àkókò tó wù ú àti ní ọ̀nà tó bá fẹ́.’
Nítorí pé àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ yege ní kíláàsì kejìléláàádọ́fà náà ti “gbára dì pátápátá,” ó dájú pé wọn ó ṣe gudugudu méje àti yààyàà mẹ́fà láti ṣèrànwọ́ fáwọn tí ìyàn oúnjẹ tẹ̀mí mú láwọn ilẹ̀ tí wọn ó ti sìn. (2 Tímótì 3:16, 17) À ń hára gàgà láti gbọ́ ìròyìn nípa bí wọ́n ṣe ń fún àwọn èèyàn tó wà láwọn ilẹ̀ wọ̀nyí ní ìhìn afúnnilókun náà.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 23]
ÌSỌFÚNNI NÍPA KÍLÁÀSÌ
Iye àwọn orílẹ̀-èdè tí a ṣojú fún: 6
Iye àwọn orílẹ̀-èdè tí a yàn wọ́n sí: 19
Iye àwọn akẹ́kọ̀ọ́: 48
Ìpíndọ́gba ọjọ́ orí: 33.2
Ìpíndọ́gba ọdún nínú òtítọ́: 15.7
Ìpíndọ́gba ọdún nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún: 12.2
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Kíláàsì Kejìléláàádọ́fà Tó Kẹ́kọ̀ọ́ Yege Nílé Ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead
Nínú ìlà àwọn orúkọ tí ń bẹ nísàlẹ̀ yìí, nọ́ńbà kọ̀ọ̀kan jẹ́ láti iwájú lọ sẹ́yìn, a sì to orúkọ láti ọwọ́ òsì sí ọwọ́ ọ̀tún lórí ìlà kọ̀ọ̀kan.
(1) Parotte, M.; Hooker, E.; Anaya, R.; Reynolds, J.; Gesualdi, K.; Gonzalez, J. (2) Robinson, C.; Phillips, B.; Maidment, K.; Moore, I.; Noakes, J.; Barnett, S. (3) Stires, T.; Palmer, B.; Yang, C.; Groothuis, S.; Groppe, T.; Bach, C. (4) Anaya, R.; Soukoreff, E.; Stewart, K.; Simozrag, N.; Simottel, C.; Bach, E. (5) Stewart, R.; Yang, H.; Gilfeather, A.; Harris, R.; Barnett, D.; Parotte, S. (6) Maidment, A.; Moore, J.; Groothuis, C.; Gilfeather, C.; Noakes, S.; Stires, T. (7) Gesualdi, D.; Groppe, T.; Soukoreff, B.; Palmer, G.; Phillips, N.; Simottel, J. (8) Harris, S.; Hooker, P.; Gonzalez, J.; Simozrag, D.; Reynolds, D.; Robinson, M.