Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Ìwọ Jẹ́ Obìnrin Títayọ Lọ́lá”

“Ìwọ Jẹ́ Obìnrin Títayọ Lọ́lá”

“Ìwọ Jẹ́ Obìnrin Títayọ Lọ́lá”

Ọmọbìnrin Móábù kan la gbóríyìn fún báyìí. Opó kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Rúùtù ni. Ó jẹ́ aya ọmọ obìnrin Ísírẹ́lì kan tó ń jẹ́ Náómì. Rúùtù gbé ilẹ̀ Ísírẹ́lì ní nǹkan bí ẹgbẹ̀ẹ́dógún [3000] ọdún sẹ́yìn, lákòókò táwọn onídàájọ́ ń ṣàkóso, ó sì ní orúkọ tó ta yọ lọ́lá. (Rúùtù 3:11) Báwo ló ṣe dẹni tó ní orúkọ rere yìí? Ta ló lè jàǹfààní nínú àpẹẹrẹ rẹ̀?

Kì í ṣe ẹni tí ń “jẹ oúnjẹ ìmẹ́lẹ́.” Rúùtù máa ń ṣíṣẹ́ fún ọ̀pọ̀ wákàtí, ó sì ṣe iṣẹ́ àṣekára nídìí pípèéṣẹ́ ní pápá. Ó jẹ́ aláápọn tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ táwọn èèyàn fi gbóríyìn fún un. Kódà nígbà tí wọ́n fẹ́ dín iṣẹ́ tó ń ṣe kù, kò dẹwọ́ rárá, ó tiẹ̀ ṣe é kọjá ibi tí wọ́n rò pé agbára rẹ̀ mọ. Lọ́nà títayọ, ó bá ohun tí Bíbélì sọ nípa aya tó yẹ fún ìyìn, tó dáńgájíà, tó si jẹ́ aláápọn mu wẹ́kú.—Òwe 31:10-31; Rúùtù 2:7, 15-17.

Àwọn ànímọ́ tẹ̀mí tí Rúùtù ní—ìyẹn ìwà ìrẹ̀lẹ̀ rẹ̀, ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ àti ìfẹ́ adúróṣinṣin rẹ̀—ni olórí ohun tó jẹ́ kó ní orúkọ rere lọ́dọ̀ gbogbo èèyàn. Ó fi àwọn òbí rẹ̀ àti ìlú rẹ̀ sílẹ̀. Ó rọ̀ mọ́ Náómì láìfi bẹ́ẹ̀ sí ìrètí pé ó máa rí ìfọ̀kànbalẹ̀ téèyàn ń ní nílé ọkọ. Lákòókò kan náà, Rúùtù fi ìfẹ́ àtọkànwá láti sin Jèhófà, Ọlọ́run ìyá ọkọ rẹ̀ hàn. Nígbà tí Ìwé Mímọ́ ń sọ nípa bó ṣe jẹ́ ọmọlúwàbí tó, ó sọ pé ó “sàn fún [Náómì] ju ọmọkùnrin méje lọ.”—Rúùtù 1:16, 17; 2:11, 12; 4:15.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Rúùtù gba ìyìn fún bó ṣe ta yọ lọ́lá lágbo àwọn èèyàn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, síbẹ̀ ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ ni bí Ọlọ́run ṣe fi ojú rere wo àwọn ànímọ́ rẹ̀, tó sì fi àǹfààní jíjẹ́ ìyá ńlá fún Jésù Kristi dá a lọ́lá. (Mátíù 1:5; 1 Pétérù 3:4) Àpẹẹrẹ àtàtà mà ni Rúùtù jẹ́ o, kì í ṣe fáwọn obìnrin Kristẹni nìkan, àmọ́ fún gbogbo ẹni tó bá sọ pé òun ń jọ́sìn Jèhófà!