Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Máa Fi Ìwà Rere Kristẹni Kọ́ Ara Rẹ Àtàwọn Ẹlòmíràn

Máa Fi Ìwà Rere Kristẹni Kọ́ Ara Rẹ Àtàwọn Ẹlòmíràn

Máa Fi Ìwà Rere Kristẹni Kọ́ Ara Rẹ Àtàwọn Ẹlòmíràn

“Ǹjẹ́ ìwọ, ẹni tí ń kọ́ ẹlòmíràn, kò kọ́ ara rẹ?”—RÓÒMÙ 2:21.

1, 2. Kí làwọn ìdí tó fi yẹ kó o fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?

 ÌDÍ pọ̀ tó fi yẹ kó o máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ó dájú pé wàá fẹ́ mọ ohun náà gan-an tó wà nínú rẹ̀. Wàá fẹ́ mọ̀ nípa àwọn èèyàn, ìṣẹ̀lẹ̀, àwọn ibì kan àtàwọn nǹkan míì tó sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Wàá fẹ́ mọ ẹ̀kọ́ òtítọ́ yàtọ̀ sí àwọn ẹ̀kọ́ èké, bíi Mẹ́talọ́kan tàbí iná ọ̀run àpáàdì. (Jòhánù 8:32) Ó tún yẹ kó o fẹ́ láti túbọ̀ mọ Jèhófà dunjú, kó o lè túbọ̀ dà bíi rẹ̀, kó o sì máa rin ọ̀nà tó tọ́ lójú rẹ̀.—1 Àwọn Ọba 15:4, 5.

2 Ìdí mìíràn, tó sì ṣe pàtàkì, tó fi yẹ kó o máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni kí o lè gbára dì láti kọ́ àwọn ẹlòmíràn—àwọn aráalé rẹ, ojúlùmọ̀ rẹ, kódà àwọn àjèjì pàápàá. Ṣíṣe èyí pọn dandan fún Kristẹni tòótọ́. Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, . . . ẹ máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ fún yín mọ́.”—Mátíù 28:19, 20.

3, 4. Èé ṣe tó fi jẹ́ ohun iyì fún ọ láti ṣègbọràn sí àṣẹ Jésù pé ká máa kọ́ni?

3 Kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nítorí àtifẹ́ fi kọ́ àwọn ẹlòmíràn jẹ́ ohun tó mọ́yán lórí téèyàn lè máa lépa, ó sì lè fúnni láyọ̀ tó kún rẹ́rẹ́. Tipẹ́tipẹ́ ni iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ ti jẹ́ iṣẹ́ tó gbayì. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encarta Encyclopedia, sọ pé: “Láàárín àwọn Júù, ọ̀pọ̀ àgbàlagbà ló ka àwọn olùkọ́ sí àwọn tí ń tọ́ni sọ́nà ìgbàlà. Wọ́n sì máa ń rọ àwọn ọmọdé pé kí wọ́n máa bọ̀wọ̀ fún olùkọ́ wọn, àní ju àwọn òbí wọn lọ.” Ó jẹ́ ohun tó gbayì gidigidi kí àwọn Kristẹni kọ́kọ́ kọ́ ara wọn, nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kí wọ́n tó lọ máa kọ́ ẹlòmíràn.

4 “Àwọn èèyàn tó ń ṣiṣẹ́ olùkọ́ pọ̀ ju àwọn tí ń ṣe gbogbo iṣẹ́ yòókù lọ. Nǹkan bíi mílíọ̀nù méjìdínláàádọ́ta èèyàn, lọ́kùnrin àti lóbìnrin, ló ń ṣiṣẹ́ olùkọ́ jákèjádò ayé.” (The World Book Encyclopedia) Ojúṣe tíṣà ni láti kọ́ àwọn ọ̀dọ́. Ó sì lè ní ipa tí kò kéré lórí ọjọ́ iwájú wọn. Ìyọrísí rẹ̀ tilẹ̀ tún nasẹ̀ kọjá ìyẹn, bó o bá ń tẹ̀ lé àṣẹ Jésù pé ká máa kọ́ àwọn ẹlòmíràn; ohun tó o kọ́ wọn lè nípa lórí ọjọ́ ọ̀la wọn ayérayé. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tẹnu mọ́ èyí nígbà tó gba Tímótì níyànjú pé: “Máa fiyè sí ara rẹ nígbà gbogbo àti sí ẹ̀kọ́ rẹ. Dúró nínú nǹkan wọ̀nyí, nítorí nípa ṣíṣe èyí, ìwọ yóò gba ara rẹ àti àwọn tí ń fetí sí ọ là.” (1 Tímótì 4:16) Bẹ́ẹ̀ ni o, ohun tí ò ń kọ́ni wé mọ́ ìgbàlà.

5. Èé ṣe tí iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ táwọn Kristẹni ń ṣe fi jẹ́ èyí tó gbayì jù lọ?

5 Ọba Aláṣẹ ayé òun ọ̀run, Olódùmarè, ló pa á láṣẹ, tó sì lànà pé kó o kọ́ ara rẹ, lẹ́yìn náà kó o wá máa kọ́ àwọn ẹlòmíì. Ìyẹn nìkan ti tó láti mú kí iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ yìí gbayì ju iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ mìíràn, ì báà jẹ́ kíkọ́ni ní àwọn ẹ̀ka ẹ̀kọ́ àkọ́bẹ̀rẹ̀, tàbí ẹ̀kọ́ iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́, tàbí ẹ̀kọ́ iṣẹ́ ìṣègùn pàápàá. Iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ táwọn Kristẹni ń ṣe wé mọ́ kíkọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti máa fara wé Kristi Jésù, Ọmọ Ọlọ́run, kí wọ́n sì máa kọ́ àwọn ẹlòmíràn láti ṣe bẹ́ẹ̀.—Jòhánù 15:10.

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Kọ́ Ara Rẹ?

6, 7. (a) Kí nìdí tó fi yẹ ká kọ́kọ́ kọ́ ara wa? (b) Báwo làwọn Júù ọ̀rúndún kìíní ṣe kùnà gẹ́gẹ́ bí olùkọ́?

6 Kí nìdí tí wọ́n fi sọ pé ká kọ́kọ́ kọ́ ara wa ná? Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, a ò lè kọ́ àwọn ẹlòmíì dáadáa bí a kò bá kọ́kọ́ kọ́ ara wa. Pọ́ọ̀lù tẹnu mọ́ kókó yìí nínú ọ̀rọ̀ kan tí ń ró kìì lọ́kàn ẹni, tó ní ìtumọ̀ wíwúwo fáwọn Júù ayé ìgbà yẹn, tó sì kan àwa Kristẹni gbọ̀ngbọ̀n lóde òní. Pọ́ọ̀lù béèrè pé: “Ǹjẹ́ ìwọ, ẹni tí ń kọ́ ẹlòmíràn, kò kọ́ ara rẹ? Ìwọ, ẹni tí ń wàásù pé ‘Má jalè,’ ìwọ ha ń jalè bí? Ìwọ, ẹni tí ń sọ pé ‘Má ṣe panṣágà,’ ìwọ ha ń ṣe panṣágà bí? Ìwọ, ẹni tí ń fi ìkórìíra tẹ̀gàntẹ̀gàn hàn sí àwọn òrìṣà, ìwọ ha ń ja àwọn tẹ́ńpìlì lólè bí? Ìwọ, ẹni tí ń yangàn nínú òfin, ǹjẹ́ ìwọ nípasẹ̀ ríré tí o ń ré Òfin kọjá ha ń tàbùkù sí Ọlọ́run bí?”—Róòmù 2:21-23.

7 Nípa lílo ìbéèrè mọ̀ọ́nú, Pọ́ọ̀lù mẹ́nu kan ìwà àìtọ́ méjì tí Òfin Mẹ́wàá dìídì kà léèwọ̀, ìyẹn ni: Má jalè, má ṣe panṣágà. (Ẹ́kísódù 20:14, 15) Àwọn Júù kan nígbà ayé Pọ́ọ̀lù ń yangàn pé àwọn ní Òfin Ọlọ́run. A ‘fi ọ̀rọ̀ ẹnu fún wọn ní ìtọ́ni láti inú Òfin, wọ́n sì gbà pé àwọn ni afinimọ̀nà fún àwọn afọ́jú àti ìmọ́lẹ̀ fún àwọn tí ó wà nínú òkùnkùn, olùkọ́ àwọn ọmọ kéékèèké.’ (Róòmù 2:17-20) Àmọ́ alágàbàgebè làwọn kan nínú wọn. Nítorí pé wọ́n ń jalè, wọ́n sì ń ṣe panṣágà lábẹ́lẹ̀. Wọ́n ń tàbùkù sí Òfin àti sí Ọlọ́run tó ṣòfin. Ìwọ náà kò ní ṣàìgbà pé wọn ò tóótun láti kọ́ àwọn ẹlòmíràn; àní wọn ò kọ́ ara wọn.

8. Ọ̀nà wo ló ṣeé ṣe kí àwọn Júù kan nígbà ayé Pọ́ọ̀lù gbà máa “ja àwọn tẹ́ńpìlì lólè”?

8 Pọ́ọ̀lù mẹ́nu kan jíja àwọn tẹ́ńpìlì lólè. Ó ha lè jẹ́ pé àwọn Júù kan ń ṣe bẹ́ẹ̀ ní ti gidi ni bí? Kí ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn? Ká sòótọ́, nítorí àìsí ìsọfúnni púpọ̀ lórí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí, a ò lè sọ pàtó bí àwọn Júù kan ṣe “ja àwọn tẹ́ńpìlì lólè.” Kó tó dìgbà yẹn, akọ̀wé ìlú Éfésù kéde pé àwọn alábàákẹ́gbẹ́ Pọ́ọ̀lù kì í ṣe “ọlọ́ṣà tẹ́ńpìlì,” tó fi hàn pé ó kéré tán àwọn èèyàn kan ronú pé ẹ̀sùn yẹn ṣeé fi kan àwọn Júù. (Ìṣe 19:29-37) Ó ha lè jẹ́ pé wọ́n ń lo àwọn ohun iyebíye tí àwọn ajagunṣẹ́gun tàbí àwọn onítara ẹ̀sìn kó nínú àwọn tẹ́ńpìlì abọ̀rìṣà, tàbí kó jẹ́ pé wọ́n ń ta nǹkan wọ̀nyí? Ohun tí Òfin Ọlọ́run sọ ni pé kí wọ́n ba wúrà àti fàdákà ara àwọn òrìṣà jẹ́, wọn ò gbọ́dọ̀ mú un lò. (Diutarónómì 7:25) a Ó kúkú lè jẹ́ àwọn Júù tó tàpá sófin Ọlọ́run, tí wọ́n ń lo àwọn ohun tó wá látinú tẹ́ńpìlì abọ̀rìṣà tàbí tí wọ́n fi ń ṣòwò ni Pọ́ọ̀lù ń bá wí.

9. Àwọn ìwà àìtọ́ wo làwọn kan ń hù ní tẹ́ńpìlì Jerúsálẹ́mù tí kò fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ sí jíja tẹ́ńpìlì lólè?

9 Yàtọ̀ síyẹn, Josephus ròyìn nǹkan ìtìjú tí àwọn Júù mẹ́rin, tí òléwájú wọ́n jẹ́ olùkọ́ Òfin, ṣe nílùú Róòmù. Àwọn mẹ́rin yìí lọ tan obìnrin ará Róòmù kan, tó jẹ́ aláwọ̀ṣe Júù jẹ, pé kí ó kó wúrà àtàwọn nǹkan ìní rẹ̀ mìíràn wá, kí àwọ́n bá a fi ta tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù lọ́rẹ. Gbàrà tí wọ́n gba nǹkan wọ̀nyí lọ́wọ́ rẹ̀, ńṣe ni wọ́n sọ ìṣúra yìí di tara wọn—tí kò yàtọ̀ sí jíja tẹ́ńpìlì lólè. b Àwọn mìíràn ń ṣe ohun tí kò yàtọ̀ sí jíja tẹ́ńpìlì Ọlọ́run lólè nípa fífi àwọn ẹran tó lábùkù rúbọ àti nípa títa àwọn nǹkan ní ọ̀wọ́n gógó ní àgbègbè tẹ́ńpìlì, tí wọ́n wá tipa bẹ́ẹ̀ sọ tẹ́ńpìlì di “hòrò àwọn ọlọ́ṣà.”—Mátíù 21:12, 13; Málákì 1:12-14; 3:8, 9.

Máa Kọ́ni Ní Ìwà Rere Kristẹni

10. Kí ni kókó pàtàkì tí kò yẹ ká gbójú fò dá nínú ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù ní Róòmù 2:21-23?

10 Ẹ má ṣe jẹ́ kí ohun yòówù tí Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa jíjalè, ṣíṣe panṣágà àti jíja àwọn tẹ́ńpìlì lólè ní ọ̀rúndún kìíní, mú wa gbójú fo kókó pàtàkì inú ọ̀rọ̀ rẹ̀ dá. Ó béèrè pé: “Ǹjẹ́ ìwọ, ẹni tí ń kọ́ ẹlòmíràn, kò kọ́ ara rẹ?” Ó yẹ fún àfiyèsí pé àwọn àpẹẹrẹ tí Pọ́ọ̀lù tọ́ka sí jẹ mọ́ ọ̀ràn ìwà rere. Níhìn-ín àpọ́sítélì náà kò darí àfiyèsí sí àwọn ẹ̀kọ́ tàbí ìtàn kan látinú Bíbélì. Kíkọ́ ara ẹni àti kíkọ́ àwọn ẹlòmíràn tí Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ rẹ̀ wé mọ́ ìwà rere Kristẹni.

11. Kí nìdí tó fi yẹ kó o fiyè sí ìwà rere Kristẹni bó o ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?

11 Ká máa fi ẹ̀kọ́ inú Róòmù 2:21-23 sílò túmọ̀ sí pé ká kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìwà rere Kristẹni látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kí ìwà wa bá ohun tí à ń kọ́ mu. Lẹ́yìn náà, ká máa kọ́ àwọn ẹlòmíràn láti ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́. Nítorí náà, bó o ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, máa fi gbogbo ara kíyè sí àwọn ohun tó jẹ mọ́ ìlànà Jèhófà, tí a gbé ìwà rere Kristẹni kà. Máa ṣàṣàrò lórí ìmọ̀ràn àti ẹ̀kọ́ tó o bá rí kọ́ nínú Bíbélì. Lẹ́yìn náà fìgboyà fi ohun tí o kọ́ sílò. Lóòótọ́ sì ni pé ṣíṣe bẹ́ẹ̀ gba ìgboyà àti ìpinnu. Torí pé àwọn ẹ̀dá aláìpé kì í pẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí ṣàwáwí, tí wọ́n á bẹ̀rẹ̀ sí wí àwíjàre pé ohun tó ṣẹlẹ̀ ló jẹ́ káwọn tẹ ìlànà ìwà rere Kristẹni lójú. Àwọn Júù tí ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù bá wí kò kẹ̀rẹ̀ nínú lílo irú ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ bẹ́ẹ̀, láti fi wí àwíjàre tàbí láti fi ṣi àwọn ẹlòmíràn lọ́nà. Àmọ́ o, ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù fi hàn pé èèyàn ò gbọ́dọ̀ fojú pa ìwà rere Kristẹni rẹ́ tàbí kéèyàn pa á tì torí pé kò wọ̀ fún òun.

12. Báwo ni ìwà rere àti ìwà búburú ṣe ń nípa lórí orúkọ Jèhófà Ọlọ́run, kí sì nìdí tó fi dáa láti máa rántí kókó yìí?

12 Àpọ́sítélì náà tẹnu mọ́ ìdí pàtàkì tó fi yẹ láti kẹ́kọ̀ọ́ ìlànà ìwà rere inú Bíbélì, kó o sì máa fi sílò. Ìwà búburú àwọn Júù mú ẹ̀gàn bá Jèhófà, ìyẹn ni Bíbélì fi sọ pé: “Ìwọ, ẹni tí ń yangàn nínú òfin, ǹjẹ́ ìwọ nípasẹ̀ ríré tí o ń ré Òfin kọjá ha ń tàbùkù sí Ọlọ́run bí? Nítorí ‘orúkọ Ọlọ́run ni a ń sọ̀rọ̀ òdì sí ní tìtorí yín láàárín àwọn orílẹ̀-èdè.’” (Róòmù 2:23, 24) Bákan náà ló rí lónìí. Bá a bá tàpá sí ìwà rere Kristẹni, a ó tàbùkù sí Ẹni tó gbé ìlànà ìwà rere náà kalẹ̀. Lódìkejì ẹ̀wẹ̀, bá a bá rọ̀ mọ́ ìlànà Ọlọ́run, yóò mú iyì àti ọlá wá bá a. (Aísáyà 52:5; Ìsíkíẹ́lì 36:20) Ríronú lórí èyí lè jẹ́ kí o túbọ̀ dúró ṣinṣin bó o bá dojú kọ àdánwò tàbí àwọn ipò tó lè mú kó rọrùn gan-an láti fọwọ́ dẹngbẹrẹ mú ìwà rere Kristẹni. Nǹkan mìíràn tún wà tí ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù kọ́ wa. Yàtọ̀ sí pé ìwọ alára mọ̀ pé ìwà rẹ lè nípa lórí orúkọ Ọlọ́run, bó o ṣe ń kọ́ àwọn ẹlòmíràn, jẹ́ kí wọ́n rí i pé bí wọ́n ṣe ń fi ìlànà ìwà rere tí wọ́n ń kọ́ sílò yóò nípa lórí orúkọ Jèhófà. Kì í wulẹ̀ ṣe kìkì pé ìwà rere Kristẹni ń mú ìtẹ́lọ́rùn àti ìlera wá nìkan ni. Ó tún ń nípa lórí orúkọ Ẹni tó gbé ìlànà ìwà rere náà kalẹ̀, tó sì fẹ́ ká máa tẹ̀ lé e.—Sáàmù 74:10; Jákọ́bù 3:17.

13. (a) Báwo ni Bíbélì ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ nínú ọ̀ràn ìwà rere? (b) Sọ kókó tó wà nínú ìmọ̀ràn inú 1 Tẹsalóníkà 4:3-7.

13 Ìwà rere tún máa ń nípa lórí àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú. O lè rí òtítọ́ yìí nínú àwọn àpẹẹrẹ tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó fi ìjẹ́pàtàkì títẹ̀lé ìlànà ìwà rere Ọlọ́run hàn wá, tó sì jẹ́ ká mọ ohun tó máa jẹ́ àbájáde ṣíṣàì tẹ̀ le e. (Jẹ́nẹ́sísì 39:1-9, 21; Jóṣúà 7:1-25) O tún lè rí àwọn ìmọ̀ràn tó sọjú abẹ níkòó lórí ọ̀ràn ìwà rere, bí èyí tó sọ pé: “Èyí ni ohun tí ìfẹ́ Ọlọ́run jẹ́, sísọ yín di mímọ́, pé kí ẹ ta kété sí àgbèrè; pé kí olúkúlùkù yín mọ bí yóò ti ṣèkáwọ́ ohun èlò tirẹ̀ nínú ìsọdimímọ́ àti ọlá, kì í ṣe nínú ìdálọ́rùn olójúkòkòrò fún ìbálòpọ̀ takọtabo irúfẹ́ èyí tí àwọn orílẹ̀-èdè wọnnì pẹ̀lú tí kò mọ Ọlọ́run ní; pé kí ẹnì kankan má ṣe lọ títí dé àyè ṣíṣe ìpalára fún àti rírakakalé àwọn ẹ̀tọ́ arákùnrin rẹ̀ nínú ọ̀ràn yìí, . . . nítorí Ọlọ́run kò pè wá pẹ̀lú ìyọ̀ǹda fún ìwà àìmọ́, bí kò ṣe ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ìsọdimímọ́.”—1 Tẹsalóníkà 4:3-7.

14. Àwọn ìbéèrè wo lo lè bi ara rẹ nípa ìmọ̀ràn tó wà nínú 1 Tẹsalóníkà 4:3-7?

14 Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo èèyàn ló lè rí i kedere látinú àyọkà yìí pé ìwà àìmọ́ takọtabo ń rú òfin ìwà rere Kristẹni. Ṣùgbọ́n òye rẹ lè túbọ̀ kún rẹ́rẹ́ nípa àyọkà yìí. Àwọn àyọkà kan máa ń ṣí àǹfààní sílẹ̀ fún kíkẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ àti ṣíṣe àṣàrò, tí yóò sì wá jẹ́ kéèyàn ní ìjìnlẹ̀ òye. Bí àpẹẹrẹ, o lè ronú lórí ohun tí Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé ṣíṣe àgbèrè lè súnni dórí “ṣíṣe ìpalára fún àti rírakakalé àwọn ẹ̀tọ́ arákùnrin rẹ̀ nínú ọ̀ràn yìí.” Àwọn ẹ̀tọ́ wo ló wé mọ́ ọn, báwo sì ni títúbọ̀ lóye èyí ṣe lè mú kó o rọ̀ mọ́ ìwà rere Kristẹni? Báwo ni àbájáde irú ìwádìí bẹ́ẹ̀ ṣe lè mú kó túbọ̀ rọrùn fún ọ láti kọ́ àwọn ẹlòmíràn, kí o sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti máa bọlá fún Ọlọ́run?

Máa Kẹ́kọ̀ọ́ Kí O Lè Di Olùkọ́

15. Àwọn ohun èlò wo lo lè lò láti fi kọ́ ara rẹ nígbà tó o bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́?

15 Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní àwọn ohun èèlò tí wọ́n fi ń ṣe ìwádìí lórí àwọn ìbéèrè tàbí ìṣòro tó bá dìde, bí wọ́n ṣe ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè kọ́ ara wọn tàbí àwọn ẹlòmíràn lẹ́kọ̀ọ́. Ohun èlò kan tó wà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ èdè ni Watch Tower Publications Index. Bó bá wà lédè rẹ, o lè fi wá ìsọfúnni nínú àwọn ìtẹ̀jáde tá a gbé ka Bíbélì, èyí táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde. O lè fi àwọn àkòrí wá ìsọfúnni nínú rẹ̀ tàbí kó o lọ wo ibi tá a to ẹsẹ Bíbélì sí. Ohun èlò míì tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ní ọ̀pọ̀ èdè ni Watchtower Library. Ètò ìsọfúnni orí kọ̀ǹpútà yìí tó wà lórí CD-ROM (ike pẹlẹbẹ tá à ń fi kọ̀ǹpútà lò), ní ọ̀pọ̀ ìtẹ̀jáde tá a lè lò lórí kọ̀ǹpútà. Ohun èlò yìí jẹ́ kó ṣeé ṣe láti ṣèwádìí lórí àwọn ẹṣin ọ̀rọ̀ kan àti láti rí ìsọfúnni nípa àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan. Bí ohun èlò méjèèjì yìí tàbí èyíkéyìí nínú wọ́n bá wà lárọ̀ọ́wọ́tó rẹ, máa lò wọ́n déédéé bó o ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láti lè fi kọ́ àwọn ẹlòmíràn.

16, 17. (a) Ibo lo ti lè rí àlàyé tí ń lani lóye lórí ẹ̀tọ́ tá a mẹ́nu kàn nínú 1 Tẹsalóníkà 4:6? (b) Ní àwọn ọ̀nà wo ni ṣíṣe àgbèrè fi lè jẹ́ rírakakalé ẹ̀tọ́ àwọn ẹlòmíràn?

16 Ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ tá a tọ́ka sí lókè yìí yẹ̀ wò, èyíinì ni 1 Tẹsalóníkà 4:3-7. Ìbéèrè dìde nípa ẹ̀tọ́. Ẹ̀tọ́ ta ni? Báwo sì ni a ṣe lè ra kaka lé ẹ̀tọ́ wọ̀nyẹn? Tó o bá lo àwọn ohun èlò ìṣèwádìí tá a mẹ́nu kàn yìí, ó ṣeé ṣe kó o rí àwọn àlàyé kan tí ń lani lóye lórí ẹsẹ wọ̀nyí. Àní ó ṣeé ṣe kó o rí àlàyé lórí àwọn ẹ̀tọ́ tí Pọ́ọ̀lù mẹ́nu kàn. O lè ka irú àlàyé bẹ́ẹ̀ nínú Insight on the Scriptures, Ìdìpọ̀ Kìíní, ojú ìwé 863 àti 864; Alaafia ati Ãbò Tõtọ—Lati Orisun Wo?, ojú ìwé 145; Ilé-Ìṣọ́nà, November 15, 1989, ojú ìwé 31.

17 Bó o ṣe ń wádìí jinlẹ̀ sí i, wàá rí i pé ìtẹ̀jáde wọ̀nyẹn fi hàn pé òótọ́ pọ́ńbélé lọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù. Ẹni tó bá ń ṣe àgbèrè ń dẹ́ṣẹ̀ sí Ọlọ́run. Ó sì lè kó oríṣiríṣi àrùn. (1 Kọ́ríńtì 6:18, 19; Hébérù 13:4) Ẹni tó bá ń ṣe àgbèrè ń ra kaka lé onírúurú ẹ̀tọ́ obìnrin tí wọ́n jọ dá ẹ̀ṣẹ̀ náà. Ó jẹ́ kí ó pàdánù ipò ìwà mímọ́ àti ẹ̀rí ọkàn rere rẹ̀. Bí kò bá tíì lọ́kọ, ọkùnrin yìí ti ra kaka lé ẹ̀tọ́ rẹ̀ láti jẹ́ wúńdíá títí ó máa fi wọlé ọkọ. Ọkùnrin yìí sì tún ra kaka lé ẹ̀tọ́ tí ọkọ rẹ̀ lọ́la ní láti retí kí ìyàwó tí òun máa fẹ́ jẹ́ wúńdíá. Ó ṣe ìpalára fún àwọn òbí obìnrin náà àti ọkọ rẹ̀, bí ó bá ti lọ́kọ. Ọkùnrin oníṣekúṣe yìí fi ẹ̀tọ́ láti ní orúkọ rere du ìdílé ara rẹ̀. Bí ọkùnrin náà bá jẹ́ ara ìjọ Kristẹni, ó mú ẹ̀gàn wá bá a, ó ba orúkọ rere ìjọ jẹ́.—1 Kọ́ríńtì 5:1.

18. Báwo lo ṣe lè jàǹfààní látinú ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lórí ìwà rere Kristẹni?

18 Ǹjẹ́ irú àwọn àlàyé bẹ́ẹ̀ nípa ẹ̀tọ́ kò wá jẹ́ kí òye ẹsẹ yẹn yé ọ yékéyéké? Ó dájú pé irú ìkẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀ ṣàǹfààní lọ́pọ̀lọpọ̀. Bó o ṣe ń ṣe é nìṣó, ńṣe lò ń kọ́ ara rẹ. Òye rẹ yóò túbọ̀ jinlẹ̀ sí i nípa bí ìsọfúnni látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ti jẹ́ òótọ́ tó, tí ó sì lágbára tó. Ńṣe lò ń jẹ́ kí ìpinnu rẹ túbọ̀ lágbára sí i láti rọ̀ mọ́ ìwà rere Kristẹni láìfi àdánwò èyíkéyìí tó bá yọjú pè. Sì ronú nípa bí wàá ṣe di olùkọ́ tó túbọ̀ dáńgájíá! Bí àpẹẹrẹ, nígbà tó o bá ń kọ́ àwọn ẹlòmíràn ní òtítọ́ Bíbélì, o lè ṣe àlàyé kínníkínní nípa 1 Tẹsalóníkà 4:3-7, kí o tipa bẹ́ẹ̀ fi kún òye wọn, kí wọ́n sì túbọ̀ máa fojú ribiribi wo ìwà rere Kristẹni. Nípa báyìí, ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ lè jẹ́ kí ìwọ àti ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn máa bọlá fún Ọlọ́run. Àpẹẹrẹ kan ṣoṣo sì rèé o, látinú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn ará Tẹsalóníkà. Àwọn ìhà mìíràn tún wà tí ìwà rere Kristẹni pín sí. Àpẹẹrẹ àti ìmọ̀ràn sì pọ̀ nínú Bíbélì tá a lè fi tì wọ́n lẹ́yìn, èyí tó o lè kẹ́kọ̀ọ́, tó o lè fi sílò, tó o sì lè fi kọ́ni.

19. Èé ṣe tó fi ṣe pàtàkì pé kó o rọ̀ mọ́ ìwà rere Kristẹni?

19 Kò sí àní-àní pé ọgbọ́n ń bẹ nínú rírọ̀ mọ́ ìwà rere Kristẹni. Jákọ́bù 3:17 sọ pé “ọgbọ́n tí ó wá láti òkè,” látọ̀dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run tìkára rẹ̀, “a kọ́kọ́ mọ́ níwà.” Ní kedere, èyí tọ́ka sí ìjẹ́pàtàkì títẹ̀lé ìlànà ìwà rere Ọlọ́run. Àní sẹ́, Jèhófà ń béèrè pé kí àwọn tó bá fẹ́ ṣojú fún òun nínú kíkọ́ni ní Bíbélì jẹ́ àpẹẹrẹ rere “nínú ìwà mímọ́.” (1 Tímótì 4:12) Bí àwọn ọmọ ẹ̀yìn ìjímìjí, bíi Pọ́ọ̀lù àti Tímótì, ṣe gbé ìgbé-ayé wọn fi hàn pé wọ́n mọ́ níwà; wọ́n yàgò fún ìṣekúṣe, àní Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Kí a má tilẹ̀ mẹ́nu kan àgbèrè àti ìwà àìmọ́ onírúurú gbogbo tàbí ìwà ìwọra láàárín yín, gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ àwọn ènìyàn mímọ́; bẹ́ẹ̀ náà ni ìwà tí ń tini lójú tàbí ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ tàbí ìṣẹ̀fẹ̀ rírùn.”—Éfésù 5:3, 4.

20, 21. Kí nìdí tó o fi fara mọ́ ohun tí àpọ́sítélì Jòhánù kọ nínú 1 Jòhánù 5:3?

20 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìlànà ìwà rere tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe pàtó, tó sì sọjú abẹ níkòó, síbẹ̀ kì í ṣe ẹrù tí ń wọni lọ́rùn. Èyí dá Jòhánù lójú, ìyẹn àpọ́sítélì tó pẹ́ jù lọ láyé. Nítorí ìrírí tó ní ní ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún tó lò láyé, ó mọ̀ pé ìwà rere Kristẹni kì í pani lara. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó dáa, ó ṣàǹfààní, ó sì ń mérè wá. Jòhánù tẹnu mọ́ èyí, nígbà tó kọ̀wé pé: “Nítorí èyí ni ohun tí ìfẹ́ fún Ọlọ́run túmọ̀ sí, pé kí a pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́; síbẹ̀ àwọn àṣẹ rẹ̀ kì í ṣe ẹrù ìnira.”—1 Jòhánù 5:3.

21 Àmọ́, ṣàkíyèsí pé Jòhánù kò sọ pé ìdí tí ṣíṣègbọràn sí Ọlọ́run nípa títẹ̀lé ìwà rere Kristẹni fi dára jù lọ ni pé títẹ̀lé e ń yọ wá nínú ìṣòro, tí àìtẹ̀lé e ì bá kó wa sí. Ó sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà nígbà tó là á mọ́lẹ̀ pé títẹ̀lé e jẹ́ ẹ̀rí ìfẹ́ wa fún Jèhófà Ọlọ́run, pé títẹ̀lé e jẹ́ àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ láti fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ká sòótọ́, kíkọ́ ara ẹni tàbí àwọn ẹlòmíì láti nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run wé mọ́ títẹ́wọ́gba ìlànà gíga rẹ̀, ká sì máa fi sílò. Àní sẹ́, ó túmọ̀ sí fífi ìwà rere Kristẹni kọ́ ara wa àtàwọn ẹlòmíràn.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Josephus sọ pé àwọn Júù kò tàbùkù sí àwọn nǹkan mímọ́, ó tún òfin Ọlọ́run sọ lọ́nà yìí: “Kí ẹnikẹ́ni má ṣe ṣáátá òrìṣà táwọn ìlú mìíràn ń bọ, bẹ́ẹ̀ ni kí wọ́n má ṣe ja àwọn tẹ́ńpìlì ilẹ̀ òkèèrè lólè, kí wọ́n má sì lọ kó ìṣúra tí wọ́n ti yà sí mímọ́ fún òrìṣà èyíkéyìí.” (Ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa.)—Jewish Antiquities, Ìwé Kẹrin, orí kẹjọ, ìpínrọ̀ kẹwàá.

b Jewish Antiquities, Ìwé Kejìdínlógún, orí kẹta, ìpínrọ̀ karùn-ún.

Ǹjẹ́ O Rántí?

• Kí nìdí tó fi yẹ ká kọ́ ara wa jinlẹ̀ ká tó lọ máa kọ́ àwọn ẹlòmíràn?

• Báwo ni ìwà wa ṣe lè nípa lórí orúkọ Jèhófà?

• Ẹ̀tọ́ àwọn wo lẹni tó ń ṣe àgbèrè ń ra kaka lé?

• Kí ni ìpinnu rẹ nípa ìwà rere Kristẹni?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]

“Àwọn àṣẹ rẹ̀ kì í ṣe ẹrù ìnira”