Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Ère Ìjọsìn—Ibi Tí Wọ́n Ti Bẹ̀rẹ̀

Àwọn Ère Ìjọsìn—Ibi Tí Wọ́n Ti Bẹ̀rẹ̀

Àwọn Ère Ìjọsìn—Ibi Tí Wọ́n Ti Bẹ̀rẹ̀

“Àwọn ère ìjọsìn jẹ́ ọ̀nà kan láti fà wá sún mọ́ ìwà rere àti ìjẹ́mímọ́ Ọlọ́run àti àwọn Ẹni Mímọ́ Rẹ̀.”—BÍṢỌ́Ọ̀BÙ ÀGBÀ ỌSIRÉLÍÀ FÚN ÌJỌ Ọ́TỌ́DỌ́Ọ̀SÌ TI GÍRÍÌSÌ

NÍ ỌJỌ́ kan tí oòrùn mú ganrín-ganrín nínú oṣù August, ìtànṣán oòrùn náà tàn yòò sórí àtẹ̀gùn tí wọ́n fi sìmẹ́ǹtì ṣe, èyí tó lọ sí ilé àwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé tí wọ́n ń pè ní “Ìyá Ọlọ́run Mímọ́ Jù Lọ,” ní erékùṣù Tínos, ní Òkun Aegean. Oòrùn gbígbóná janjan náà kò kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn olùfọkànsìn arìnrìn-àjò onísìn ti Ìjọ Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ilẹ̀ Gíríìsì tí iye wọ́n ju ẹgbẹ̀rún lọ́nà mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25,000], tí wọ́n ń tiraka láti dé ibi tí ère ìyá Jésù tí wọ́n ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ jìngbìnnì náà wà.

Ọ̀dọ́mọbìnrin kan tó jẹ́ arọ, tó dájú pé ó ń jẹ̀rora, tó sì hàn pé ó ti gbékú tà, ń rákò lórí eékún rẹ̀ tó ń ṣẹ̀jẹ̀ ṣùrù ṣùrù. Ìyá arúgbó kan tó ti rẹ̀ tẹnutẹnu wà nítòsí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó ti rìnrìn àjò wá láti ìpẹ̀kun kejì orílẹ̀-èdè náà, ó sì rọra ń wọ́ ara rẹ̀ lọ. Ọkùnrin oníhàáragàgà kan tá á ti máa sún mọ́ ẹni àádọ́ta ọdún wà níbẹ̀ tó ń làágùn yọ̀bọ̀ bó ti ń fi ìkánjú gbìyànjú láti gba àárín èrò tí ń tira wọn kọjá. Góńgó wọn ni láti fẹnu ko ère Màríà náà lẹ́nu, kí wọ́n sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀.

Kò sí iyèméjì rárá pé tọkàntara làwọn tí kò fi ọ̀ràn ẹ̀sìn ṣeré wọ̀nyí fẹ́ fi jọ́sìn Ọlọ́run. Àmọ́, mélòó lára wọn ló mọ̀ pé jíjúbà àwọn ère ìsìn jẹ́ àwọn àṣà tó ti wà ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ṣáájú ẹ̀sìn Kristẹni?

Ère Ìjọsìn Gbòde Kan

Ibi gbogbo ni ère ìjọsìn wà láwọn ilẹ̀ tó jẹ́ ti Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì. Nínú àwọn ṣọ́ọ̀ṣì, àwọn ère Jésù, ti Màríà, àti ti ọ̀pọ̀ “ẹni mímọ́” ni wọ́n kó sí ibi tí gbogbo èèyàn ti lè rí wọn. Àwọn onísìn sábà máa ń bọlá fún àwọn ère wọ̀nyí nípa fífẹnu kò wọ́n lẹ́nu, fífín tùràrí, àti títan àbẹ́là. Láfikún sí i, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ẹlẹ́sìn Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ló níbi tí wọ́n kó àwọn ère ìjọsìn jọ sí nínú ilé wọn, ibẹ̀ ni wọ́n sì ti máa ń gbàdúrà. Àwọn Kristẹni ẹlẹ́sìn Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì sábà máa ń sọ pé ìgbà táwọn bá jọ́sìn ère ìsìn làwọn máa ń rí i pé àwọn túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run. Ọ̀pọ̀ gbà gbọ́ pé oore ọ̀fẹ́ Ọlọ́run wà lára àwọn ère ìjọsìn, wọ́n sì ní agbára láti ṣe iṣẹ́ ìyanu.

Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ìyàlẹ́nu fún irú àwọn onígbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ láti gbọ́ pé àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní kò fara mọ́ lílo àwọn ère nínú ìjọsìn. Ìwé náà, Byzantium, sọ pé: “Nítorí pé àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ti kórìíra ìbọ̀rìṣà látìgbà tí wọ́n ti wà nínú ìsìn àwọn Júù ni wọn ò ṣe fara mọ́ jíjúbà àwòrán àwọn ẹni mímọ́ rárá.” Ìwé kan náà sọ pé: “Láti Ọ̀rúndún Karùn-ún síwájú ni àwọn ère ìjọsìn . . . ti di ohun tó wọ́pọ̀ nínú ìjọsìn tí wọ́n ń ṣe ní gbangba àti èyí tí wọ́n ń ṣe lábẹ́lé.” Tí kì í bá ṣe inú ìsìn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní ló ti wá, ibo wá ni lílo àwọn ère nínú ìjọsìn ti bẹ̀rẹ̀?

Wíwá Ibi Tó Ti Bẹ̀rẹ̀ Rí

Olùwádìí nì, Vitalij Ivanovich Petrenko, kọ̀wé pé: “Lílo àwọn ère àtàwọn àṣà tó wé mọ́ ọn ti bẹ̀rẹ̀ látọjọ́ tó ti pẹ́ ṣáájú sànmánì Kristẹni, ó sì ‘wá látinú àṣà kèfèrí.’” Ọ̀pọ̀ òpìtàn ló fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n sọ pé jíjọ́sìn àwọn ère bẹ̀rẹ̀ látinú ìsìn Bábílónì, Íjíbítì, àti ti ilẹ̀ Gíríìsì ìgbàanì. Bí àpẹẹrẹ, bí ère gbígbẹ́ ni àwọn ère ìjọsìn ṣe rí ní ilẹ̀ Gíríìsì ìgbàanì. Àwọn èèyàn sì gbà gbọ́ pé agbára tó ju ti ẹ̀dá lọ ń bẹ lára àwọn ère wọ̀nyí. Wọ́n gbà gbọ́ pé kì í ṣe ọwọ́ lásán ni wọ́n fi ṣe àwọn kan lára àwọn ère wọ̀nyí, bí kò ṣe pé ńṣe ni wọ́n já bọ́ látòkè ọ̀run. Nígbà tí wọ́n bá ń ṣe àwọn ayẹyẹ tó jẹ́ àkànṣe, wọ́n máa ń gbé irú àwọn ère tí wọ́n ń lò fún ìjọsìn bẹ́ẹ̀ káàkiri ìlú, tí wọ́n á sì wá rúbọ sí wọn. Petrenko sọ pé: “Àwọn tó jẹ́ onítara-ìsìn gbà pé ọlọ́run àjúbàfún ni ère táwọn ń lò fún ìjọsìn jẹ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti gbìyànjú . . . láti fìyàtọ̀ sáàárín ọlọ́run àjúbàfún yìí àti ère rẹ̀.

Báwo ni irú èrò àtàwọn àṣà bẹ́ẹ̀ ṣe rọ́nà wọnú ẹ̀sìn Kristẹni? Olùwádìí kan náà ṣàkíyèsí pé, ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún lẹ́yìn ikú àwọn àpọ́sítélì Kristi, àgàgà ní Íjíbítì, “ni àwọn ẹ̀kọ́ Kristẹni wá di ‘àmúlùmálà ìgbàgbọ́ kèfèrí’—èyí tó bẹ̀rẹ̀ látinú àṣà àti ìgbàgbọ́ àwọn ará Íjíbítì, Gíríìkì, àwọn Júù, àwọn ará Ìlà Oòrùn àtàwọn ará Róòmù, èyí tí wọ́n yí mọ́ ìgbàgbọ́ àti àṣà Kristẹni.” Nítorí ìdí èyí, “àwọn Kristẹni tó ka ara wọn sí ọ̀jáfáfá gbé [àmúlùmálà ìgbàgbọ́] kalẹ̀, wọ́n lo àwọn àmì kèfèrí, wọ́n sì sọ ọ́ di àmì tuntun, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àmì náà ò ṣaláì ní ọ̀ràn ìbọ̀rìṣà nínú.”

Láìpẹ́, àwọn ère ìjọsìn di ohun táwọn èèyàn ń lò nínú ọ̀ràn ẹ̀sìn lábẹ́lé àti ní gbangba. Nínú ìwé náà, The Age of Faith, òpìtàn Will Durant ṣàpèjúwe bí èyí ṣe bẹ̀rẹ̀, ó ní: “Bí iye àwọn ẹni mímọ́ tí wọ́n ń jọ́sìn ṣe ń pọ̀ sí i, ìṣòro dídá wọn mọ̀ àti rírántí wọn wá ń yọjú; bí wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ sí ya ọ̀pọ̀ àwòrán wọn àti ti Màríà nìyẹn. Ní ti Kristi ní tirẹ̀, wọn ò wulẹ̀ yà á bí wọ́n ṣe rò pé Ó rí nìkan, àmọ́ àgbélébùú Rẹ̀ di ohun tí wọ́n ń júbà fún—kódà, ó di oògùn ìṣọ́ra fáwọn aláìmọ̀kan. Nítorí pé oníkálùkù ló láǹfààní àtironú bó ṣe fẹ́, kó sì ya àwòrán tó wù ú, ló jẹ́ kí wọ́n sọ àwọn ohun tó jẹ mọ́ àwọn ẹni mímọ́, àwọn àwòrán, àtàwọn ère wọn di ohun àjúbàfún; táwọn èèyàn ń forí balẹ̀ níwájú wọn, tí wọ́n ń fẹnu kò wọ́n lẹ́nu, tí wọ́n ń tan àbẹ́là síwájú wọn, tí wọ́n ń fín tùràrí níwájú wọn, tí wọ́n ń fi òdòdó dé wọn ládé, tí wọ́n sì ń retí iṣẹ́ ìyanu látọ̀dọ̀ wọn. . . . Léraléra làwọn baba ìjọ àtàwọn ìgbìmọ̀ Ṣọ́ọ̀ṣì máa ń ṣàlàyé pé àwọn ère wọ̀nyẹn kì í ṣe àwọn ọlọ́run, pé wọ́n wulẹ̀ jẹ́ ìránnilétí ni; síbẹ̀ àwọn èèyàn ò fẹ́ mọ̀ pé ìyàtọ̀ wà níbẹ̀.”

Lóde òní, ọ̀pọ̀ àwọn tó ń lo àwọn ère ìjọsìn ló máa ń jiyàn bákan náà pé àwọn wulẹ̀ ń bọlá fáwọn ère wọ̀nyẹn ni—pé àwọn kì í jọ́sìn wọn. Wọn tiẹ̀ lè sọ pé àwọn àwòrán ìsìn jẹ́ ohun èlò tó bójú mu—kódà tó jẹ́ kòṣeémánìí—nínú jíjọ́sìn Ọlọ́run. Bóyá ohun tíwọ náà rò nìyẹn. Àmọ́, ìbéèrè náà ni pé, Kí ni èrò Ọlọ́run nípa èyí? Ṣé pé bíbọlá fún ère ìsìn lè túmọ̀ sí jíjọ́sìn rẹ̀? Ǹjẹ́ irú àṣà bẹ́ẹ̀ lè ní ewu tí kò hàn síta?

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Kí Ni Ère Ìjọsìn?

Onírúurú ère ìjọsìn ló wà. Àwọn ère kan wà tí a mọ. Àwọn kan sì wà tí a gbẹ́. Àwọn wọ̀nyí ni ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń lò nínú ìjọ Kátólíìkì. Àwọn àwòrán tún wà tó jẹ́ ti Kristi, ti Màríà, ti “àwọn ẹni mímọ́,” ti àwọn áńgẹ́lì, ti àwọn èèyàn, àti ti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú Bíbélì, tàbí ti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wà nínú ìtàn Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì. Orí ọpọ́n onígi ni wọ́n sábà máa ń ya àwọn àwòrán náà sí.

Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì wí, “nínú àwọn Ère àwọn Ẹni Mímọ́, àwòrán náà kì í jọ ti ènìyàn ẹlẹ́ran ara àti ẹ̀jẹ̀ lásán.” Kì í sábàá “ní òjìji, tàbí ohunkóhun tá a fi lè dá ọ̀sán àti òru mọ̀ yàtọ̀.” Ohun táwọn èèyàn tún gbà gbọ́ ni pé “agbára Ọlọ́run wà” lára igi àti ọ̀dà tí wọ́n fi ṣe ère ìjọsìn.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

A ṣàwárí pe lílo àwọn ère pilẹ̀ wá látinú àwọn àṣà kèfèrí

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]

© AFP/CORBIS