Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jèhófà Fi Ìmọ́lẹ̀ Bu Ẹwà Kún Àwọn Èèyàn Rẹ̀

Jèhófà Fi Ìmọ́lẹ̀ Bu Ẹwà Kún Àwọn Èèyàn Rẹ̀

Jèhófà Fi Ìmọ́lẹ̀ Bu Ẹwà Kún Àwọn Èèyàn Rẹ̀

“Dìde, ìwọ obìnrin, tan ìmọ́lẹ̀ jáde, nítorí pé ìmọ́lẹ̀ rẹ ti dé, àní ògo Jèhófà sì ti tàn sára rẹ.”—AÍSÁYÀ 60:1.

1, 2. (a) Ipò wo ni aráyé wà? (b) Ta ní ń bẹ nídìí òkùnkùn aráyé?

 “ÁÀ, ẹ wo bí ì bá ti dára tó ká ní Aísáyà tàbí Pọ́ọ̀lù Mímọ́ wà láàyè lónìí!” Harry Truman tó jẹ́ ààrẹ Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ló dárò bẹ́ẹ̀ ní àwọn ọdún 1940 lọ́hùn-ún. Kí nìdí tó fi sọ bẹ́ẹ̀? Ńṣe ló rí i pé ayé ìgbà tòun nílò àwọn atọ́nisọ́nà tó dáńgájíá lórí ìwà rere. Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, ayé ṣẹ̀ṣẹ̀ bọ́ nínú Ogun Àgbáyé Kejì ni, èyí tó jẹ́ àkókò tí nǹkan dà rú jù lọ ní ọ̀rúndún ogún. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ogun ọ̀hún parí, ayé kò ní àlàáfíà rárá. Gbogbo nǹkan ṣì dojú rú. Àní sẹ́, ọdún kẹtàdínlọ́gọ́ta rèé lẹ́yìn tí ogun náà ti parí, síbẹ̀ inú òkùnkùn biribiri layé ṣì wà. Ká ní Ààrẹ Truman ṣì wà láyé ni, ó dájú pé yóò rí i pé a ṣì ń fẹ́ àwọn èèyàn bí Aísáyà tàbí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó jẹ́ atọ́nisọ́nà lórí ìwà rere.

2 Bóyá Ààrẹ Truman mọ̀ pé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa irú òkùnkùn tó bo aráyé yìí, tí ó sì kìlọ̀ nípa rẹ̀ nínú àwọn ìwé rẹ̀, a ò lè sọ. Bí àpẹẹrẹ, ó kìlọ̀ fáwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ pé: “Àwa ní gídígbò kan, kì í ṣe lòdì sí ẹ̀jẹ̀ àti ẹran ara, bí kò ṣe lòdì sí àwọn alákòóso, lòdì sí àwọn aláṣẹ, lòdì sí àwọn olùṣàkóso ayé òkùnkùn yìí, lòdì sí àwọn agbo ọmọ ogun ẹ̀mí burúkú ní àwọn ibi ọ̀run.” (Éfésù 6:12) Ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù yìí fi hàn pé kì í ṣe kìkì pé ó mọ̀ nípa òkùnkùn tẹ̀mí tó bó ayé nìkan ni, ṣùgbọ́n ó tún mọ̀ pẹ̀lú pé agbo àwọn ẹ̀mí èṣù alágbára, tó pè ní “àwọn olùṣàkóso ayé,” ní ń bẹ nídìí rẹ̀. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àwọn ẹ̀mí alágbára ní ń bẹ nídìí òkùnkùn ayé, ǹjẹ́ àrà kankan wà tí ẹ̀dá ènìyàn lásánlàsàn lè dá láti mú un kúrò?

3. Láìfi òkùnkùn tó bo aráyé pè, kí ni Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ fún àwọn olóòótọ́?

3 Aísáyà pẹ̀lú sọ̀rọ̀ nípa òkùnkùn tó bo aráyé. (Aísáyà 8:22; 59:9) Ṣùgbọ́n, nígbà tí Aísáyà ń sọ̀rọ̀ nípa ọjọ́ wa, ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé nínú òkùnkùn yìí pàápàá, Jèhófà yóò jẹ́ kí ojú ọjọ́ mọ́lẹ̀ kedere fáwọn tó bá fẹ́ràn ìmọ́lẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, bí Pọ́ọ̀lù àti Aísáyà fúnra wọn kò bá tiẹ̀ sí láyé mọ́, ọ̀rọ̀ onímìísí tí wọ́n kọ wà nílẹ̀ fún ìtọ́sọ́nà wa. Ẹ jẹ́ ká gbé ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà tó wà nínú orí ọgọ́ta ìwé rẹ̀ yẹ̀ wò, ká lè mọ bó ṣe ṣàǹfààní tó fáwọn tó fẹ́ràn Jèhófà.

Obìnrin Kan Nínú Asọtẹ́lẹ̀ Náà Tan Ìmọ́lẹ̀

4, 5. (a) Kí ni Jèhófà pàṣẹ pé kí obìnrin kan ṣe, ìlérí wo sì ni Jèhófà ṣe? (b) Ìsọfúnni alárinrin wo ló wà nínú Aísáyà orí ọgọ́ta?

4 Àwọn ọ̀rọ̀ àkọ́kọ́ nínú Aísáyà orí ọgọ́ta ní í ṣe pẹ̀lú obìnrin kan tí inú rẹ̀ bà jẹ́ gidigidi. Ńṣe ló nà gbalaja sílẹ̀ẹ́lẹ̀ nínú òkùnkùn biribiri. Lójijì, ìmọ́lẹ̀ tàn yòò, òkùnkùn sì para dà, Jèhófà wá ké sí i pé: “Dìde, ìwọ obìnrin, tan ìmọ́lẹ̀ jáde, nítorí pé ìmọ́lẹ̀ rẹ ti dé, àní ògo Jèhófà sì ti tàn sára rẹ.” (Aísáyà 60:1) Àkókò tó wàyí kí obìnrin náà gbéra nílẹ̀, kí ó sì gbé ìmọ́lẹ̀, ìyẹn ògo, Ọlọ́run yọ. Kí nìdí? A rí ìdáhùn ní ẹsẹ tó tẹ̀ lé e, ó ní: “Wò ó! òkùnkùn pàápàá yóò bo ilẹ̀ ayé, ìṣúdùdù nínípọn yóò sì bo àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè; ṣùgbọ́n Jèhófà yóò tàn sára rẹ, a ó sì rí ògo rẹ̀ lára rẹ.” (Aísáyà 60:2) Nígbà tí obìnrin yẹn ṣe bí Jèhófà ṣe wí, a mú un dá a lójú pé ìyọrísí rẹ̀ yóò kọyọyọ. Jèhófà sọ pé: “Dájúdájú, àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì lọ sínú ìmọ́lẹ̀ rẹ, àwọn ọba yóò sì lọ sínú ìtànyòò tí ó wá láti inú ìtànjáde rẹ.”—Aísáyà 60:3.

5 Ọ̀rọ̀ alárinrin tó wà nínú ẹsẹ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí jẹ́ ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ àti àkópọ̀ ohun tó wà nínú ìyókù ìwé Aísáyà orí ọgọ́ta. Ó sọ tẹ́lẹ̀ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sí obìnrin kan tí àsọtẹ́lẹ̀ náà sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, ó sì ṣàlàyé bá a ṣe lè máa wà nínú ìmọ́lẹ̀ Jèhófà bó tilẹ̀ jẹ́ pé òkùnkùn bo aráyé. Àmọ́, kí ni àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ inú ẹsẹ mẹ́ta àkọ́kọ́ wọ̀nyí túmọ̀ sí?

6. Ta ni obìnrin tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú Aísáyà orí ọgọ́ta, àwọn wo ló sì ń ṣojú fún un lórí ilẹ̀ ayé?

6 Síónì ni obìnrin tí Aísáyà 60:1-3 ń sọ̀rọ̀ rẹ̀, ìyẹn ètò Jèhófà ní ọ̀run, tó kún fún àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí. Àṣẹ́kù “Ísírẹ́lì Ọlọ́run,” ìyẹn ìjọ àwọn Kristẹni tá a fẹ̀mí yàn jákèjádò ayé, tó ń retí láti bá Kristi jọba lọ́run, ló ń ṣojú fún Síónì lórí ilẹ̀ ayé lónìí. (Gálátíà 6:16) Àwọn tó wà nínú orílẹ̀-èdè tẹ̀mí yìí jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì, àwọn tó ṣì wà lórí ilẹ̀ ayé lára wọn ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” yìí ni àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà orí ọgọ́ta ń ṣẹ sí lára lóde òní. (2 Tímótì 3:1; Ìṣípayá 14:1) Àsọtẹ́lẹ̀ yìí tún sọ ohun púpọ̀ nípa “ogunlọ́gọ̀ ńlá” ti “àwọn àgùntàn mìíràn” tó jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró wọ̀nyí.—Ìṣípayá 7:9; Jòhánù 10:16.

7. Ipò wo ni Síónì wà lọ́dún 1918, báwo la sì ṣe sọ èyí tẹ́lẹ̀?

7 Ǹjẹ́ ìgbà kankan wà tí “Ísírẹ́lì Ọlọ́run” wà nínú òkùnkùn, gẹ́gẹ́ bó ti kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀ sí obìnrin inú àsọtẹ́lẹ̀ yìí? Bẹ́ẹ̀ ni. Èyí ṣẹlẹ̀ ní ohun tó lé ní ọgọ́rin ọdún sẹ́yìn. Nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró sapá gidigidi láti rí i pé iṣẹ́ ìwàásù náà kò dáwọ́ dúró. Àmọ́, díẹ̀ ló kù kí iṣẹ́ ìwàásù tí a fètò sí náà dáwọ́ dúró ní 1918, ìyẹn ọdún tó gbẹ̀yìn ogun náà. Ìjọba fi Joseph F. Rutherford, tó ń bójú tó iṣẹ́ ìwàásù kárí ayé nígbà náà, àtàwọn Kristẹni mìíràn tí wọ́n jẹ́ igi lẹ́yìn ọgbà, sí ẹ̀wọ̀n ọdún gbọọrọ lórí ẹ̀sùn èké. Lọ́nà àsọtẹ́lẹ̀, ìwé Ìṣípayá ṣàpèjúwe àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó wà lórí ilẹ̀ ayé lákòókò yẹn gẹ́gẹ́ bí àwọn òkú tó wà ní “ọ̀nà fífẹ̀ ìlú ńlá títóbi náà, èyí tí a ń pè lọ́nà ìtumọ̀ ti ẹ̀mí ní Sódómù àti Íjíbítì.” (Ìṣípayá 11:8) Àkókò tó ṣókùnkùn biribiri nìyẹn jẹ́ fún Síónì lóòótọ́, gẹ́gẹ́ bó ṣe hàn nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn ọmọ rẹ̀ ẹni àmì òróró lórí ilẹ̀ ayé!

8. Ìyípadà gígadabú wo ló wáyé lọ́dún 1919, kí sì ni ìyọrísí rẹ̀?

8 Àfi bó ṣe di ọdún 1919 tí ìyípadà gígadabú dé. Jèhófà tànmọ́lẹ̀ sórí Síónì! Àwọn tó ṣẹ́ kù lára Ísírẹ́lì Ọlọ́run gbéra nílẹ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí gbé ìmọ́lẹ̀ Ọlọ́run yọ, wọ́n sì tún bẹ̀rẹ̀ sí wàásù ìhìn rere náà láìbẹ̀rù. (Mátíù 5:14-16) Àkọ̀tun ìtara tí àwọn Kristẹni yìí ní mú kí àwọn mìíràn wá sínú ìmọ́lẹ̀ Jèhófà. A fẹ̀mí yan àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sínú ìmọ́lẹ̀ yìí láti di ara Ísírẹ́lì Ọlọ́run. Aísáyà 60:3 pè wọ́n ní ọba, nítorí pé wọ́n máa jẹ́ ajùmọ̀jogún pẹ̀lú Kristi nínú Ìjọba Ọlọ́run ní ọ̀run. (Ìṣípayá 20:6) Lẹ́yìn náà, a wá bẹ̀rẹ̀ sí mú ogunlọ́gọ̀ ńlá ti àwọn àgùntàn mìíràn wá sínú ìmọ́lẹ̀ Jèhófà. Àwọn wọ̀nyí ló di “àwọn orílẹ̀-èdè” tá a mẹ́nu kàn nínú àsọtẹ́lẹ̀ náà.

Àwọn Ọmọ Obìnrin Náà Darí Wálé!

9, 10. (a) Ohun ìdùnnú ńláǹlà wo ni obìnrin náà rí, kí sì ni èyí dúró fún? (b) Kí nìdí tí Síónì fi ń yọ̀?

9 Wàyí o, Jèhófà wá bẹ̀rẹ̀ sí sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa ìsọfúnni inú Aísáyà 60:1-3. Ó pàṣẹ mìíràn fún obìnrin náà. Ẹ gbọ́ ohun tó sọ, ó ní: “Gbé ojú rẹ sókè yí ká, kí o sì wò!” Bí obìnrin yìí ṣe gbójú sókè lóòótọ́, ohun ìdùnnú ńláǹlà ló rí ní ọ̀ọ́kán! Àwọn ọmọ rẹ̀ ń darí bọ̀ wálé. Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yẹn fi kún un pé: “A ti kó gbogbo wọn jọpọ̀; wọ́n ti wá sọ́dọ̀ rẹ. Ibi jíjìnnàréré ni àwọn ọmọkùnrin rẹ ti ń bọ̀, àti àwọn ọmọbìnrin rẹ tí a óò tọ́jú ní ìhà rẹ.” (Aísáyà 60:4) Ìpolongo Ìjọba Ọlọ́run kárí ayé tó bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1919 mú kí ẹgbẹẹgbẹ̀rún ẹni tuntun wá sínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú di “ọmọkùnrin” àti “ọmọbìnrin” Síónì, ìyẹn àwọn ẹni àmì òróró tí í ṣe ara Ísírẹ́lì Ọlọ́run. Jèhófà tipa báyìí bu ẹwà kún Síónì bó ṣe mú àwọn tó ṣẹ́ kù lára ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì wá sínú ìmọ́lẹ̀.

10 Ǹjẹ́ ìdùnnú kò ní ṣubú lu ayọ̀ fún Síónì nígbà tí àwọn ọmọ rẹ̀ dé sọ́dọ̀ rẹ̀? Síbẹ̀, Jèhófà fún Síónì ní ìdí púpọ̀ sí i láti máa yọ̀. Ọ̀rọ̀ yẹn lọ báyìí: “Ní àkókò yẹn, ìwọ yóò wò, ìwọ yóò sì wá tàn yinrin dájúdájú, ọkàn-àyà rẹ yóò sì gbọ̀n pẹ̀pẹ̀ ní tòótọ́, yóò sì gbòòrò, nítorí pé ọ̀dọ̀ rẹ ni ọlà òkun yóò darí sí; àní ohun àmúṣọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè yóò wá sọ́dọ̀ rẹ.” (Aísáyà 60:5) Níbàámu pẹ̀lú àsọtẹ́lẹ̀ yẹn, láti àwọn ọdún 1930 ni ẹgbàágbèje àwọn Kristẹni tó ń retí láti wà lórí ilẹ̀ ayé ti ń rọ́ wá sí Síónì. Inú “òkun” aráyé tó kẹ̀yìn sí Ọlọ́run ni wọ́n ti jáde wá, àwọn sì ni ohun àmúṣọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè. Àwọn ni “ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra tí ń bẹ nínú gbogbo orílẹ̀-èdè.” (Hágáì 2:7; Aísáyà 57:20) Tún ṣàkíyèsí pé kì í ṣe pé olúkúlùkù àwọn “ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra” wọ̀nyí kàn lọ ń sin Jèhófà bó ṣe wù wọ́n. Rárá o, kàkà bẹ́ẹ̀ wọ́n bù kún ẹwà Síónì nípa wíwá láti jọ́sìn pẹ̀lú àwọn arákùnrin wọn ẹni àmì òróró, wọ́n sì jùmọ̀ di “agbo kan” lábẹ́ “olùṣọ́ àgùntàn kan.”—Jòhánù 10:16.

Àwọn Oníṣòwò, Àwọn Olùṣọ́ Àgùntàn Àtàwọn Ọlọ́jà Ń Wọ́ Bọ̀ Lọ́dọ̀ Síónì

11, 12. Ṣàpèjúwe àwọn èrò tá a rí tí ń wọ́ bọ̀ lọ́dọ̀ Síónì.

11 Àwọn tá a sọ tẹ́lẹ̀ pé wọ́n ń rọ́ wá yìí yóò mú kí iye àwọn tó ń yin Jèhófà pọ̀ sí i gan-an ni. Àsọtẹ́lẹ̀ èyí wà nínú ọ̀rọ̀ tó tẹ̀ lé e. Jẹ́ ká sọ pé o wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ obìnrin inú àsọtẹ́lẹ̀ yẹn lórí Òkè Síónì. Wo ìlà oòrùn, kí lo rí ná? “Ìrọ́-sókè-sódò àgbájọ ràkúnmí pàápàá yóò bò ọ́, àwọn ẹgbọrọ akọ ràkúnmí Mídíánì àti ti Eéfà. Gbogbo àwọn tí ó wá láti Ṣébà—wọn yóò wá. Wúrà àti oje igi tùràrí ni wọn yóò rù. Ìyìn Jèhófà sì ni wọn yóò máa kéde.” (Aísáyà 60:6) Agbo àwọn oníṣòwò àti ọ̀wọ́ àwọn ràkúnmí wọn ń gba àwọn ọ̀nà tó wá sí Jerúsálẹ́mù bọ̀. Àwọn ràkúnmí wọn pọ̀ lọ súà, bí ilẹ̀ bí ẹní! Àwọn oníṣòwò yìí kó àwọn ẹ̀bùn iyebíye wá, bíi “wúrà àti oje igi tùràrí.” Àwọn oníṣòwò yìí sì wá sínú ìmọ́lẹ̀ Ọlọ́run láti wá yìn ín ní gbangba, ‘láti kéde ìyìn Jèhófà.’

12 Àwọn oníṣòwò nìkan kọ́ ló ń bọ̀ o. Kódà àwọn olùṣọ́ àgùntàn ń wọ́ bọ̀ ní Síónì. Àsọtẹ́lẹ̀ náà fi kún un pé: “Gbogbo agbo ẹran Kídárì—a óò kó wọn jọpọ̀ sọ́dọ̀ rẹ. Àwọn àgbò Nébáótì—wọn yóò máa ṣe ìránṣẹ́ fún ọ.” (Aísáyà 60:7a) Àwọn ẹ̀yà tó jẹ́ darandaran pẹ̀lú ń bọ̀ ní ìlú mímọ́ náà láti fi èyí tó dáa jù lọ nínú agbo ẹran wọn rúbọ sí Jèhófà. Àní wọ́n tiẹ̀ yọ̀ǹda ara wọn láti ṣe ìránṣẹ́ fún Síónì! Irú ojú wo ni Jèhófà yóò fi wo àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè yìí? Ọlọ́run fúnra rẹ̀ dáhùn pé: “Pẹ̀lú ìtẹ́wọ́gbà ni wọn yóò fi gòkè wá sórí pẹpẹ mi, èmi yóò sì bu ẹwà kún ilé ẹwà mi.” (Aísáyà 60:7b) Jèhófà fi tayọ̀tayọ̀ tẹ́wọ́ gba ọrẹ ẹbọ àti iṣẹ́ ìsìn àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè yìí. Wíwá wọn bu ẹwà kún tẹ́ńpìlì rẹ̀.

13, 14. Kí la rí tó ń ti ìwọ̀ oòrùn bọ̀?

13 Wá yíjú wo òkèèrè níhà ìwọ̀ oòrùn báyìí. Kí lo rí ná? Lókèèrè réré, nǹkan kan wà tó dà bí ìkuukùu funfun tó bo òkun. Jèhófà wá béèrè ìbéèrè tó wà lọ́kàn rẹ yẹn, ó ní: “Ta ni ìwọ̀nyí tí ń fò bọ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọsánmà, àti bí àdàbà sí ihò ilé ẹyẹ wọn?” (Aísáyà 60:8) Jèhófà dáhùn ìbéèrè tí òun alára béèrè, ó ní: “Èmi ni àwọn erékùṣù pàápàá yóò máa retí, àti àwọn ọkọ̀ òkun Táṣíṣì pẹ̀lú gẹ́gẹ́ bíi ti ìgbà àkọ́kọ́, láti lè kó àwọn ọmọ rẹ láti ibi jíjìnnàréré wá, bí fàdákà wọn àti wúrà wọn ti ń bẹ pẹ̀lú wọn, fún orúkọ Jèhófà Ọlọ́run rẹ àti fún Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì, nítorí pé yóò ti ṣe ọ́ lẹ́wà.”—Aísáyà 60:9.

14 Ǹjẹ́ o lè fojú inú wo ìran náà? Ìkuukùu funfun náà ti túbọ̀ sún mọ́ ọ. Ó sì wá dà bí àwọn nǹkan funfun tó-tò-tó níhà ìwọ̀ oòrùn lọ́hùn-ún lọ́hùn-ún. Wọ́n dà bí agbo àwọn ẹyẹ tí ń dà gììrì bọ̀ bí ìgbì omi òkun. Àmọ́ bí wọ́n ṣe ń sún mọ́ itòsí, o wá rí i pé àwọn ọkọ̀ òkun tó ta ìgbòkun kí wọ́n lè rìn dáadáa lójú omi ni. Àwọn ọkọ̀ òkun tó ń bọ̀ ní Jerúsálẹ́mù yìí sì pọ̀ débi pé wọ́n dà bí agbo àdàbà. Eré tete ni ọ̀wọ́ àwọn ọkọ̀ òkun wọ̀nyí ń bá bọ̀ láti èbúté jíjìnnà réré, bí wọ́n ti ń kó àwọn onígbàgbọ́ bọ̀ ní Jerúsálẹ́mù láti wá sin Jèhófà.

Ètò Jèhófà Ń Gbilẹ̀ sí I

15. (a) Ìbísí wo ni Aísáyà 60:4-9 sọ tẹ́lẹ̀? (b) Irú ẹ̀mí wo làwọn ojúlówó Kristẹni ní?

15 Ẹsẹ kẹrin sí ìkẹsàn-án mà kúkú ṣe àpèjúwe tó ṣe kedere gan-an nípa bí ẹ̀sìn tòótọ́ ṣe gbilẹ̀ kárí ayé láti ọdún 1919 wá o! Kí nìdí tí Jèhófà fi fi irú ìbísí bẹ́ẹ̀ jíǹkí Síónì? Torí pé láti ọdún 1919 ni Ísírẹ́lì Ọlọ́run ti ń tan ìmọ́lẹ̀ Jèhófà, ní ìgbọràn sí àṣẹ Rẹ̀. Àmọ́, ǹjẹ́ o ṣàkíyèsí pé àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé yìí “gòkè wá sórí pẹpẹ” Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí ẹsẹ keje ti wí? Ibi ìrúbọ ni pẹpẹ jẹ́. Apá yìí nínú àsọtẹ́lẹ̀ náà sì rán wa létí pé iṣẹ́ ìsìn Jèhófà wé mọ́ ẹbọ rírú. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Mo . . . pàrọwà fún yín . . . pé kí ẹ fi ara yín fún Ọlọ́run ní ẹbọ ààyè, mímọ́, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ pẹ̀lú agbára ìmọnúúrò yín.” (Róòmù 12:1) Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ yìí, àwọn ojúlówó Kristẹni kò fi ọ̀ràn ìjọsìn mọ sórí wíwulẹ̀ máa pàdé pọ̀ lẹ́ẹ̀kan lọ́sẹ̀. Wọ́n ń lo àkókò, agbára, àti dúkìá wọn láti fi gbé ìjọsìn mímọ́ lárugẹ. Ǹjẹ́ wíwà tí irú àwọn olùfọkànsìn bẹ́ẹ̀ wà nínú ilé Jèhófà kò bu ẹwà kún ilé ọ̀hún? Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà sọ pé ó bu ẹwà kún un. Ó sì dá wa lójú pé irú àwọn èèyàn tó ń fìtara jọ́sìn bẹ́ẹ̀ yóò lẹ́wà lójú Jèhófà.

16. Àwọn wo ló kọ́wọ́ ti iṣẹ́ àtúnkọ́ tó wáyé ní ìgbàanì, àwọn wo ló sì ń ṣe bẹ́ẹ̀ lóde òní?

16 Àwọn ṣẹ̀ṣẹ̀dé yìí fẹ́ ṣiṣẹ́. Àsọtẹ́lẹ̀ náà fi kún un pé: “Àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè yóò sì mọ àwọn ògiri rẹ ní ti tòótọ́, àwọn ọba wọn yóò sì máa ṣe ìránṣẹ́ fún ọ.” (Aísáyà 60:10) Nígbà tí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí kọ́kọ́ nímùúṣẹ nígbà yẹn lọ́hùn-ún nígbà tí wọ́n ń ti ìgbèkùn Bábílónì bọ̀, àwọn ọba àtàwọn mìíràn láti inú àwọn orílẹ̀-èdè dìídì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti tún tẹ́ńpìlì àti ìlú Jerúsálẹ́mù kọ́. (Ẹ́sírà 3:7; Nehemáyà 3:26) Nínú ìmúṣẹ ti òde òní, ogunlọ́gọ̀ ńlá ń ṣètìlẹyìn fún àwọn ẹni àmì òróró nínú gbígbé ìjọsìn tòótọ́ ga. Wọ́n ń ṣèrànwọ́ nínú gbígbé àwọn ìjọ Kristẹni ró, wọ́n sì ń tipa bẹ́ẹ̀ mú kí “ògiri” ètò Jèhófà tó dà bí ìlú ńlá túbọ̀ lágbára sí i. Wọ́n tún ń kópa nínú kíkọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba, Gbọ̀ngàn Àpéjọ, àtàwọn ilé Bẹ́tẹ́lì. Ní gbogbo ọ̀nà wọ̀nyí, wọ́n ń ṣètìlẹyìn fún àwọn arákùnrin wọn ẹni àmì òróró láti bójú tó àwọn ohun tí ètò Jèhófà tó ń gbilẹ̀ sí i nílò!

17. Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà bu ẹwà kún àwọn èèyàn rẹ̀?

17 Àwọn ọ̀rọ̀ tó gbẹ̀yìn nínú Aísáyà 60:10 mà wúni lórí o! Jèhófà sọ pé: “Nínú ìkannú mi ni èmi yóò ti kọlù ọ́, ṣùgbọ́n nínú ìfẹ́ rere mi ni èmi yóò ti ṣàánú fún ọ dájúdájú.” Bẹ́ẹ̀ ni o, lẹ́yìn lọ́hùn-ún ní 1918 sí 1919, Jèhófà bá àwọn èèyàn rẹ̀ wí. Àmọ́ ìyẹn ti kọjá báyìí. Àkókò tó wàyí tí Jèhófà yóò ṣojú àánú sáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ẹni àmì òróró àtàwọn àgùntàn mìíràn tí í ṣe alábàákẹ́gbẹ́ wọn. Àmì ojú àánú yìí ni ìbísí yàbùgà-yabuga tó fi jíǹkí wọn, tó fi “bu ẹwà kún” wọn.

18, 19. (a) Ìlérí wo ni Jèhófà ṣe fún àwọn ẹni tuntun tó ń wọnú ètò rẹ̀? (b) Kí ni ìyókù àwọn ẹsẹ inú Aísáyà orí ọgọ́ta sọ fún wa?

18 Ẹgbàágbèje “àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè” tuntun ló ń dara pọ̀ mọ́ ètò Jèhófà lọ́dọọdún, ọ̀nà náà ṣì wà ní ṣíṣí sílẹ̀ gbayawu kí àwọn púpọ̀ sí i lè wọlé. Jèhófà sọ fún Síónì pé: “A óò ṣí àwọn ẹnubodè rẹ sílẹ̀ nígbà gbogbo; a kì yóò tì wọ́n àní ní ọ̀sán tàbí ní òru, láti lè mú ohun àmúṣọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè wá sọ́dọ̀ rẹ, àwọn ọba wọn yóò sì mú ipò iwájú.” (Aísáyà 60:11) Àwọn alátakò kan ń gbìyànjú láti ti “àwọn ẹnubodè” wọ̀nyẹn, ṣùgbọ́n a kúkú mọ̀ pé wọn kò lè tì í. Jèhófà fúnra rẹ̀ ló sọ pé bó ti wù kó rí, ṣíṣí ni ẹnubodè wọ̀nyẹn yóò wà. Ìbísí kò ní dáwọ́ dúró.

19 Àwọn ọ̀nà míì ṣì wà tí Jèhófà gbà bù kún àwọn èèyàn rẹ̀, tí ó sì bu ẹwà kún wọn, ní ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí. Ìyókù àwọn ẹsẹ inú Aísáyà orí ọgọ́ta ṣàlàyé àwọn ọ̀nà wọ̀nyẹn lọ́nà àsọtẹ́lẹ̀.

Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?

• Ta ni “obìnrin” Ọlọ́run, ta ló sì ṣojú fún un lórí ilẹ̀ ayé?

• Ìgbà wo làwọn ọmọ Síónì dùbúlẹ̀ gbalaja, nígbà wo ni wọ́n “dìde,” báwo sì ni wọ́n ṣe “dìde”?

• Báwo ni Jèhófà ṣe fi àmì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ sọ àsọtẹ́lẹ̀ ìbísí tó ń wáyé lóde òní nínú iye àwọn oníwàásù Ìjọba náà?

• Ní àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ òun tàn sára àwọn èèyàn òun?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

A pàṣẹ pé kí “obìnrin” Jèhófà dìde

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Ọ̀wọ́ àwọn ọkọ̀ òkun dà bí àwọn àdàbà lókèèrè réré