Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jọ́sìn Ọlọ́run “Ní Ẹ̀mí”

Jọ́sìn Ọlọ́run “Ní Ẹ̀mí”

Jọ́sìn Ọlọ́run “Ní Ẹ̀mí”

“Ta ni ẹ lè fi Ọlọ́run wé? Ère wo ni ẹ lè gbẹ́ tó máa bá bó ṣe rí mu?”—AÍSÁYÀ 40:18, “THE JERUSALEM BIBLE”

Ó ṢEÉ ṣe kó o fi tọkàntọkàn gbà pé lílo àwọn ère ṣètẹ́wọ́gbà nínú jíjọ́sìn Ọlọ́run. O lè ronú pé èyí á jẹ́ kó o túbọ̀ sún mọ́ Olùgbọ́ àdúrà, ẹni tí a kò lè fojú rí, tó sì lè dà bíi pé kì í ṣe ẹnì gidi tá a lè lóye rẹ̀.

Àmọ́ ṣé a lómìnira fàlàlà láti yan ọ̀nà tó wù wá láti tọ Ọlọ́run lọ? Ǹjẹ́ kì í ṣe Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ló láṣẹ àtisọ ohun tó ṣètẹ́wọ́gbà àti èyí tí kò ṣètẹ́wọ́gbà? Jésù ṣàlàyé ojú tí Ọlọ́run fi wo ọ̀ràn náà nígbà tó sọ pé: “Èmi ni Ọ̀nà, Òtítọ́ àti Ìyè. Kò sí ẹni tí ó lè wá sọ́dọ̀ Baba bí kò ṣe nípasẹ̀ mi.” (Jòhánù 14:6) a Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn nìkan ti fagi lé lílo àwọn ère ìjọsìn tàbí ohunkóhun mìíràn tá a kà sí mímọ́.

Dájúdájú, irú ìjọsìn pàtó kan wà tí Jèhófà Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà. Èwo nìyẹn? Ní àkókò mìíràn, Jésù ṣàlàyé pé: “Wákàtí náà yóò dé—ó tiẹ̀ ti dé ná—nígbà tí àwọn olùjọsìn tòótọ́ yóò máa jọ́sìn Baba ní ẹ̀mí àti òtítọ́: irú olùjọ́sìn tí Baba ń fẹ́ nìyẹn. Ọlọ́run jẹ́ ẹ̀mí, àwọn tó ń jọ́sìn sì gbọ́dọ̀ jọ́sìn ní ẹ̀mí àti òtítọ́.”—Jòhánù 4:23, 24.

Ǹjẹ́ ère lè ṣojú fún Ọlọ́run tó “jẹ́ ẹ̀mí”? Rárá o. Bó ti wù kí ère kan lẹ́wà tó, kò lè bá ògo Ọlọ́run dọ́gba láé. Nítorí náà, kò sí ère kan tó lè jẹ́ àwòrán Ọlọ́run. (Róòmù 1:22, 23) Ǹjẹ́ ẹnì kan lè ‘máa jọ́sìn ní òtítọ́’ bí ó bá ń tọ Ọlọ́run lọ nípasẹ̀ àwọn ère kan tí ènìyàn fọwọ́ ṣe?

Ẹ̀kọ́ Ṣíṣe Kedere Tí Bíbélì Fi Kọ́ni

Òfin Ọlọ́run ka yíyá ère gẹ́gẹ́ bí ohun tá a fi ń jọ́sìn léèwọ̀. Èyí tó ṣìkejì nínú Òfin Mẹ́wàá náà sọ pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe ère gbígbẹ́ kan fún ara rẹ tàbí àwòrán ohunkóhun ní ọ̀run lókè tàbí lórí ilẹ̀ ayé ní ìsàlẹ̀ tàbí nínú omi lábẹ́ ilẹ̀ ayé; ìwọ kò gbọ́dọ̀ tẹrí ba fún wọn, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọ́dọ̀ sìn wọ́n.” (Ẹ́kísódù 20:4, 5) Ìwé Mímọ́ Kristẹni tí ó ní ìmísí tún pa á láṣẹ pé: “Kí o sá fún ìbọ̀rìṣà pátápátá.”—1 Kọ́ríńtì 10:14.

Lóòótọ́, ọ̀pọ̀ ló sọ pé lílò táwọn ń lo ère nínú ìjọsìn kì í ṣe ìbọ̀rìṣà. Bí àpẹẹrẹ, àwọn Kristẹni Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì máa ń sẹ́ pé kì í kúkú ṣe pé àwọn ń jọ́sìn àwọn ère ìsìn tí wọ́n ń forí balẹ̀ fún, tí wọ́n ń kúnlẹ̀ síwájú rẹ̀, tí wọ́n sì ń gbàdúrà sí. Àlùfáà Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì kan kọ̀wé pé: “À ń bọ̀wọ̀ fún wọn nítorí pé ohun mímọ́ ni wọ́n, àti nítorí pé a ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún ohun táwọn Ère náà ń ṣàpẹẹrẹ.”

Àmọ́, ìbéèrè náà ṣì wà níbẹ̀ pé: Ǹjẹ́ Ọlọ́run tẹ́wọ́ gba lílo àwọn ère ìjọsìn kódà fún ète tí wọ́n pè ní wíwulẹ̀ júbà wọn? Kò síbi tí Bíbélì ti fàyè gba irú àṣà bẹ́ẹ̀. Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbé ère ọmọ màlúù kan kalẹ̀, tí wọ́n sọ pé Jèhófà làwọn ń jọ́sìn, ó fi hàn pé òun ò tẹ́wọ́ gba ohun tí wọ́n ṣe yẹn rárá nípa sísọ pé wọ́n ti pẹ̀yìn dà.—Ẹ́kísódù 32:4-7.

Ewu Tó Fara Sin

Lílo èrè nínú ìjọsìn jẹ́ àṣà tó léwu. Ó lè jẹ́ káwọn èèyàn máa jọ́sìn nǹkan yẹn dípò Ọlọ́run tí wọ́n sọ pé nǹkan náà dúró fún. Ní ọ̀rọ̀ mìíràn, ère náà á wá di ohun tí wọ́n sọ dòrìṣà.

Àwọn nǹkan mélòó kan dà bẹ́ẹ̀ nígbà ayé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Bí àpẹẹrẹ, Mósè ṣe ejò bàbà kan nígbà ìrìn àjò wọn nínú aginjù. Ìwòsàn ni ejò tó gbé kọ́ sórí òpó náà dúró fún níbẹ̀rẹ̀. Àwọn tí ejò bá bù jẹ lè wo ejò bàbà náà kí wọ́n sì rí ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run gbà. Àmọ́ nígbà táwọn èèyàn náà tẹ̀ dó sí Ilẹ̀ Ìlérí tán, ó dà bíi pé wọ́n sọ òpó tá à ń wí yìí dòrìṣà, bí ẹni pé ejò bàbà náà fúnra rẹ̀ ló ní agbára láti wò wọ́n sàn. Wọ́n wá ń fín tùràrí sí i, kódà wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Néhúṣítánì.—Númérì 21:8, 9; 2 Àwọn Ọba 18:4.

Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tún gbìyànjú láti lo àpótí májẹ̀mú gẹ́gẹ́ bí oògùn láti fi bá àwọn ọ̀tá wọn jà, àbájáde rẹ̀ kò sì dára rárá. (1 Sámúẹ́lì 4:3, 4; 5:11) Nígbà ayé Jeremáyà, àwọn èèyàn Jerúsálẹ́mù ka tẹ́ńpìlì náà sí bàbàrà ju Ọlọ́run tí wọ́n ń sìn níbẹ̀ lọ.—Jeremáyà 7:12-15.

Ìgbìyànjú láti jọ́sìn àwọn nǹkan dípò jíjọ́sìn Ọlọ́run kò tíì kásẹ̀ nílẹ̀. Olùwádìí nì, Vitalij Ivanovich Petrenko, sọ pé: “Ère . . . ti di ohun tí wọ́n ń jọ́sìn, ó sì fi wọ́n sínú ewu ìbọ̀rìṣà . . . A ní láti gbà pé àṣà àjọgbà tó pilẹ̀ látọ̀dọ̀ àwọn kèfèrí ni jíjọ́sìn ère.” Bákan náà ni Demetrios Constantelos tó jẹ́ àlùfáà Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ti Gíríìkì sọ nínú ìwé rẹ̀, Understanding the Greek Orthodox Church, pé: “Ó ṣeé ṣe fún Kristẹni kan láti sọ ère kan di ohun tó ń jọ́sìn.”

Sísọ pé àwọn ère ìjọsìn wulẹ̀ jẹ́ àmọ́ tí kì í ṣara ẹran nínú ọ̀ràn ìjọsìn jẹ́ ohun tó ń kọni lóminú gan-an. Kí nìdí? Tóò, ǹjẹ́ kì í ṣe òótọ́ ni pé àwọn èèyàn lè ka àwọn ère kan tó jẹ́ ti Màríà àti tàwọn “ẹni mímọ́” kan sí èyí tó yẹ fún ìfọkànsìn gíga, tó sì gbéṣẹ́ ju àwọn ère mìíràn tó jẹ́ pé àwọn ẹni tó ti kú tipẹ́ yìí kan náà ni wọ́n dúró fún? Bí àpẹẹrẹ, àwọn Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì olùfọkànsìn tó wà nílùú Tínos, ní ilẹ̀ Gíríìsì ní ère Màríà tiwọn, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn olùfọkànsìn tó wà nílùú Soumela, ní àríwá Gíríìsì tún ní ère Màríà tiwọn lọ́tọ̀. Ìlú méjèèjì yìí ló gbà pé ère tàwọn ló dára jù, tó lè ṣe iṣẹ́ ìyanu tó ga ju ti ìlú kejì lọ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni tó ti kú tipẹ́ kan náà ni ère méjèèjì dúró fún. Nítorí náà, àwọn èèyàn gbà ní ti gidi pé agbára ń bẹ lọ́wọ́ àwọn ère kan, ìdí nìyẹn tí wọ́n fi ń jọ́sìn wọn.

Ǹjẹ́ Ó Yẹ Ká Gbàdúrà sí “Àwọn Ẹni Mímọ́” Tàbí Màríà?

Ọ̀rọ̀ nípa jíjúbà àwọn kan bíi Màríà àtàwọn “ẹni mímọ́” ńkọ́? Nígbà tí Jésù ń fèsì àdánwò kan tí Sátánì gbé dìde, ó tọ́ka sí Diutarónómì 6:13, ó sì sọ pé: “Olúwa Ọlọ́run rẹ ni kí o máa jọ́sìn, òun nìkan ṣoṣo ni kí o sì máa sìn.” (Mátíù 4:10) Ẹ̀yìn ìgbà yẹn ló wá sọ pé àwọn olùjọsìn tòótọ́ yóò jọ́sìn “Baba” nìkan ṣoṣo. (Jòhánù 4:23) Ìdí nìyẹn tí áńgẹ́lì kan fi bá àpọ́sítélì Jòhánù wí nígbà tó gbìyànjú láti jọ́sìn rẹ̀, ó sọ pé: “Má ṣe bẹ́ẹ̀ . . . Ọlọ́run ni kí o jọ́sìn.”—Ìṣípayá 22:9.

Ǹjẹ́ ó yẹ kéèyàn máa gbàdúrà sí Màríà, ìyá Jésù, tàbí sí “àwọn ẹni mímọ́” kan, pé kí wọ́n mú ẹ̀bẹ̀ òun lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run? Ìdáhùn tààrà tí Bíbélì fúnni ni pé: “Alárinà kan ṣoṣo ni ó wà láàárín Ọlọ́run àti ènìyàn, òun fúnra rẹ̀ ọkùnrin kan, ìyẹn Kristi Jésù.”—1 Tímótì 2:5.

Pa Àjọṣe Àárín Ìwọ àti Ọlọ́run Mọ́

Níwọ̀n bí lílo àwọn ère nínú ìjọsìn ti lòdì sí ẹ̀kọ́ yíyè kooro látinú Bíbélì, kò lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti rí ojú rere Ọlọ́run, kò sì lè fún wọn ní ìgbàlà. Ní ìyàtọ̀ pátápátá síyẹn, Jésù sọ pé ìyè àìnípẹ̀kun sinmi lórí gbígba ìmọ̀ Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, mímọ àwọn ànímọ́ rẹ̀ tí kò láfiwé àti mímọ àwọn ète rẹ̀ àti bó ṣe ń bá àwọn èèyàn lò. (Jòhánù 17:3) Àwọn ère tí kò lè ríran, tí kò lè ronú, tí ò sì lè sọ̀rọ̀, kò lè ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti mọ Ọlọ́run àti láti jọ́sìn rẹ̀ lọ́nà tó ṣètẹ́wọ́gbà. (Sáàmù 115:4-8) Nípasẹ̀ kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, nìkan ṣoṣo la fi lè mọ ẹ̀kọ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ.

Yàtọ̀ sí pé jíjọ́sìn ère ò ṣeni láǹfààní kankan, ó tún léwu nípa tẹ̀mí. Lọ́nà wo? Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ó lè ba àjọṣe àárín àwa àti Jèhófà jẹ́. Ohun tí Ọlọ́run sọ tẹ́lẹ̀ nípa Ísírẹ́lì, tó “fi àwọn òrìṣà mú un bínú,” ni pé: “Èmi yóò gbé ojú mi pa mọ́ kúrò lọ́dọ̀ wọn.” (Diutarónómì 32:16, 20, The New American Bible) Títún àjọṣe wọn pẹ̀lú Ọlọ́run ṣe túmọ̀ sí pé kí wọ́n ‘kọ àwọn òrìṣà sílẹ̀.’—Aísáyà 31:6, 7, NAB.

Ẹ ò rí i bí ìmọ̀ràn tí Ìwé Mímọ́ fúnni ṣe dára tó pé: “Ẹ̀yin ọmọ mi kéékèèké, ẹ máa sá fún àwọn òrìṣà”!—1 Jòhánù 5:21, NAB.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Bí a ò bá fi hàn pé ó yàtọ̀, gbogbo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a ṣàyọlò rẹ̀ jẹ́ látinú Jerusalem Bible ti àwọn Kátólíìkì.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]

A Ràn Wọ́n Lọ́wọ́ Láti Jọ́sìn “Ní Ẹ̀mí”

Olivera jẹ́ ọmọ ìjọ tí kò fọ̀rọ̀ ẹ̀sìn ṣeré rárá nínú Ìjọ Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ní Albania. Nígbà tí orílẹ̀-èdè náà gbẹ́sẹ̀ lé ọ̀ràn ìsìn lọ́dún 1967, ńṣe ni Olivera ń bá ìjọsìn nìṣó ní bòńkẹ́lẹ́. Èyí tó pọ̀ jù lọ nínú owó ìfẹ̀yìntì rẹ̀ tí kò ju táṣẹ́rẹ́ lọ ló fi ń ra àwọn ère tí wọ́n fi wúrà àti fàdákà ṣe, ó tún ń ra tùràrí, àti àbẹ́là. Ó kó nǹkan wọ̀nyí pa mọ́ sínú ibùsùn rẹ̀, ọ̀pọ̀ ìgbà ló sì máa ń sùn sórí àga kan nítòsí, nítorí ìbẹ̀rù pé àwọn èèyàn lè rí wọn tàbí kí wọ́n jí wọn kó. Nígbà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ Olivera ní nǹkan bí ọdún 1990 sí 1993, ó rí i pé òtítọ́ Bíbélì ni wọ́n ń wàásù. Ó rí ohun tí Bíbélì sọ nípa bí ìjọsìn tòótọ́ ṣe gbọ́dọ̀ jẹ́ èyí tí à ń ṣe “ní ẹ̀mí,” ó sì wá mọ ojú tí Ọlọ́run fi wo lílo àwọn ère ìsìn. (Jòhánù 4:24) Ẹlẹ́rìí tó ń bá a ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kíyè sí i pé gbogbo ìgbà tí òun ń dé ilé Olivera ni àwọn ère wọ̀nyẹn ń dín kù. Níkẹyìn, kò ku ẹyọ kan mọ́. Lẹ́yìn tí Olivera ṣe ìrìbọmi tán, ó sọ pé: “Lónìí, dípò àwọn ère tí kò ní láárí, mo ní ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà. Mo sì dúpẹ́ pé kò dìgbà tí mo bá lo àwọn ère wọ̀nyẹn kí ẹ̀mí Ọlọ́run tó dé ọ̀dọ̀ mi.”

Athena, tó ń gbé ní erékùṣù Lesbos ní ilẹ̀ Gíríìsì jẹ́ ògbóǹtagí ọmọ Ìjọ Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì. Ó wà nínú ẹgbẹ́ akọrin, ó sì ń tẹ̀ lé gbogbo àṣà ẹ̀sìn rẹ̀ láìkù síbì kan, títí kan lílo àwọn ère ìjọsìn. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ran Athena lọ́wọ́ láti rí i pé kì í ṣe gbogbo ohun tí ẹ̀sìn rẹ̀ fi kọ́ ọ ló wà níbàámu pẹ̀lú Bíbélì. Èyí kan lílo àwọn ère ìjọsìn àti àgbélébùú nínú ìjọsìn. Athena sọ pé òun gbọ́dọ̀ fúnra òun ṣèwádìí lórí bí àwọn ohun tí wọ́n ń lò fún ìjọsìn wọ̀nyí ṣe bẹ̀rẹ̀. Lẹ́yìn tó ṣèwádìí nínú onírúurú ìwé, ó wá rí i dájú pé kì í ṣe inú ẹ̀sìn Kristẹni ni àwọn nǹkan wọ̀nyẹn ti bẹ̀rẹ̀. Fífẹ́ tó fẹ́ jọ́sìn Ọlọ́run “ní ẹ̀mí” sún un láti kó gbogbo àwọn ère rẹ̀ dà nù, láìfi owó gọbọi tó ná lé wọn lórí pè. Àmọ́ inú Athena dùn láti yááfì gbogbo nǹkan wọ̀nyí, kó lè jọ́sìn Ọlọ́run lọ́nà tó mọ́ nípa tẹ̀mí, tó sì ṣètẹ́wọ́gbà.—Ìṣe 19:19.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Ṣé Iṣẹ́ Ọnà Lásán Làwọn Ère Ìjọsìn?

Lẹ́nu àwọn ọdún àìpẹ́ yìí ni àwọn èèyàn ń kó àwọn ère ìjọsìn jọ káàkiri ayé. Àwọn tó ń kó wọn jọ kì í sábà ka ère náà sí ohun mímọ́ tí wọ́n ń lò fún ìjọsìn, bí kò ṣe iṣẹ́ ọ̀nà tó ń fi àṣà ìbílẹ̀ Byzantium hàn. Kì í ṣe ohun àjèjì láti rí ọ̀pọ̀ irú àwọn ère ìjọsìn bẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi ṣe ọ̀ṣọ́ sí ilé tàbí ọ́fíìsì ẹnì kan tó sọ pé òun ò gbà pé Ọlọ́run wà.

Àmọ́, àwọn Kristẹni tòótọ́ kò gbàgbé ohun tí ère náà wà fún gan-an. Ohun tí wọ́n ń lò fún ìjọsìn ni. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Kristẹni kì í ṣe lámèyítọ́ àwọn ẹlòmíràn tó ní àwọn ère wọ̀nyí, síbẹ̀ àwọn fúnra wọn ò ní ère ìjọsìn kankan, kódà wọn kì í kó wọ́n sílé pàápàá. Èyí ṣe wẹ́kú pẹ̀lú ìlànà tó wà nínú Diutarónómì 7:26, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe túmọ̀ rẹ̀ nínú The Jerusalem Bible. Ó kà níbẹ̀ pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ mú ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí èyíkéyìí [ìyẹn àwọn ère tí wọ́n ń lò nínú ìjọsìn] wá sínú ilé rẹ, kí ìwọ alára má bàa di ẹni ìparun bíi tirẹ̀. O gbọ́dọ̀ kà wọ́n sí ohun àìmọ́ àti ohun ìríra.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Ọlọ́run kò fàyè gba lílo àwọn ère nínú ìjọsìn

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Ìmọ̀ látinú Bíbélì ń ràn wá lọ́wọ́ láti jọ́sìn Ọlọ́run ní ẹ̀mí