Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Má Ṣe Jẹ́ Kí A Tàn Ọ́ Jẹ

Má Ṣe Jẹ́ Kí A Tàn Ọ́ Jẹ

Má Ṣe Jẹ́ Kí A Tàn Ọ́ Jẹ

ÓFẸ́RẸ̀Ẹ́ jẹ́ àtọjọ́ táláyé ti dáyé ni ẹ̀tàn ti wà. Ọ̀kan lára àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó kọ́kọ́ wáyé pàá nínú ìtàn tó wà lákọọ́lẹ̀ jẹ́ ọ̀ràn ẹ̀tàn. Ìyẹn ni ìgbà tí Sátánì tan Éfà jẹ nínú ọgbà Édẹ́nì.—Jẹ́nẹ́sísì 3:13; 1 Tímótì 2:14.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò tíì sí àkókò kan tí ẹ̀tàn ò gbòde kan lórí ilẹ̀ ayé látìgbà yẹn wá, síbẹ̀ ti àkókò wa yìí peléke. Nígbà tí Bíbélì ń sọ nípa bí ayé ṣe máa rí lóde òní, ó kìlọ̀ pé: “Àwọn ènìyàn burúkú àti àwọn afàwọ̀rajà yóò máa tẹ̀ síwájú láti inú búburú sínú búburú jù, wọn yóò máa ṣini lọ́nà, a ó sì máa ṣi àwọn pẹ̀lú lọ́nà.”—2 Tímótì 3:13.

Ìdí tí wọ́n fi ń tan àwọn èèyàn jẹ pọ̀ lóríṣiríṣi. Àwọn ẹlẹ́tàn àtàwọn gbájú-ẹ̀ máa ń tan àwọn tó bá kó sí wọn lọ́wọ́ jẹ nítorí àtirí owó gbà lọ́wọ́ wọn. Àwọn òṣèlú kan máa ń tan àwọn tó dìbò fún wọn jẹ, nítorí àtijókòó pa sórí àlééfà. Àwọn èèyàn tiẹ̀ máa ń tan ara wọn jẹ pàápàá. Dípò kí wọ́n ṣe ohun tí ó tọ́, wọ́n á máa tan ara wọn jẹ pé kò sóhun tó burú nínú lílọ́wọ́ sí àwọn àṣà tó léwu, bíi sìgá mímu, ìjoògùnyó, àti ìwà pálapàla láàárín takọtabo.

Ìtànjẹ tún wà nínú ọ̀ràn ẹ̀sìn pẹ̀lú. Àwọn aṣáájú ìsìn ọjọ́ Jésù tan àwọn èèyàn jẹ. Àwọn ẹlẹ́tàn yẹn ni Jésù ń bá wí nígbà tó sọ pé: “Afọ́jú afinimọ̀nà ni wọ́n. Bí afọ́jú bá wá ń fi afọ́jú mọ̀nà, àwọn méjèèjì yóò já sínú kòtò.” (Mátíù 15:14) Kò tán síbẹ̀ o, àní èèyàn tún ń tan ara rẹ̀ jẹ nínú ọ̀ràn ìsìn. Òwe 14:12 sọ pé: “Ọ̀nà kan wà tí ó dúró ṣánṣán lójú ènìyàn, ṣùgbọ́n àwọn ọ̀nà ikú ni òpin rẹ̀ ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀.”

Gẹ́gẹ́ bó ṣe rí nígbà ayé Jésù, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń tanra wọn jẹ nínú ọ̀ràn ẹ̀sìn lóde òní, àmọ́ ìyẹn ò mà yani lẹ́nu o! Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé Sátánì “ti fọ́ èrò inú àwọn aláìgbàgbọ́ lójú, kí ìmọ́lẹ̀ ìhìn rere ológo nípa Kristi, ẹni tí ó jẹ́ àwòrán Ọlọ́run, má bàa mọ́lẹ̀ wọlé.”—2 Kọ́ríńtì 4:4.

Bí oníjìbìtì bá tàn wá jẹ, a lè pàdánù owó wa. Bí òṣèlú bá tàn wá jẹ, ìyẹn lè dín òmìnira àtiṣe gbogbo ohun tó wù wá láti ṣe kù. Àmọ́, bí Sátánì bá tàn wá jẹ débi tá a fi wá kọ òtítọ́ nípa Jésù Kristi sílẹ̀, a jẹ́ pé a ò ní í ní ìyè àìnípẹ̀kun nìyẹn o! Nítorí náà, má ṣe jẹ́ kí a tàn ọ́ jẹ. Ṣí èrò inú àti ọkàn rẹ̀ payá sí Bíbélì, tí í ṣe orísun òtítọ́ tí kò ṣeé já ní koro nípa ẹ̀sìn. Àǹfààní tá a máa pàdánù pọ̀ gan-an tá ò bá ṣe bẹ́ẹ̀.—Jòhánù 17:3.