Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ Bó O Ṣe Ń Kọ́ni Múná Dóko?

Ǹjẹ́ Bó O Ṣe Ń Kọ́ni Múná Dóko?

Ǹjẹ́ Bó O Ṣe Ń Kọ́ni Múná Dóko?

GBOGBO wa ló yẹ ká jẹ́ olùkọ́. A à báà jẹ́ òbí, tàbí alàgbà, tàbí olùpòkìkí ìhìn rere. Àwọn òbí ń kọ́ àwọn ọmọ wọn, àwọn alàgbà ń kọ́ àwọn mẹ́ńbà ìjọ Kristẹni, àwọn oníwàásù ìhìn rere sì ń kọ́ àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń fìfẹ́ hàn. (Diutarónómì 6:6, 7; Mátíù 28:19, 20; 1 Tímótì 4:13, 16) Kí lo lè ṣe láti jẹ́ kí ọ̀nà tó ò ń gbà kọ́ni túbọ̀ múná dóko? Ọ̀nà kan ni pé kó o fara wé àpẹẹrẹ àwọn olùkọ́ tó dáńgájíà tá a mẹ́nu kàn nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kó o sì tẹ̀ lé ọ̀nà tí wọ́n gbà kọ́ni. Irú olùkọ́ bẹ́ẹ̀ ni Ẹ́sírà.

Kíkẹ́kọ̀ọ́ Látinú Àpẹẹrẹ Ẹ́sírà

Ẹ́sírà jẹ́ àlùfáà láti ìdílé Áárónì. Ó gbé ayé ní nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀tàlá [2,500] ọdún sẹ́yìn ní Bábílónì. Ní ọdún 468 ṣááju Sànmánì Tiwa, ó lọ sí Jerúsálẹ́mù kí ó lè gbé ìjọsìn mímọ́ lárugẹ láàárín àwọn Júù tó ń gbé níbẹ̀. (Ẹ́sírà 7:1, 6, 12, 13) Iṣẹ́ yìí béèrè pé kó kọ́ àwọn èèyàn ní Òfin Ọlọ́run. Kí ni Ẹ́sírà ṣe láti rí i pé ọ̀nà tí òun ń gbà kọ́ni múná dóko? Ó gbé àwọn ìgbésẹ̀ bíi mélòó kan tó pọn dandan. Kíyè sí àwọn ìgbésẹ̀ tó wà ní Ẹ́sírà 7:10 yìí ná:

“Ẹ́sírà fúnra rẹ̀ ti [1] múra ọkàn-àyà rẹ̀ sílẹ̀ [2] láti ṣe ìwádìí nínú òfin Jèhófà àti [3] láti pa á mọ́ àti [4] láti máa kọ́ni ní ìlànà àti ìdájọ́ òdodo ní Ísírẹ́lì.” Ẹ jẹ́ ká sáré yẹ ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìgbésẹ̀ wọ̀nyí wò, ká sì wo ẹ̀kọ́ tá a lè rí kọ́ nínú wọn.

“Ẹ́sírà Fúnra Rẹ̀ Ti Múra Ọkàn-Àyà Rẹ̀ Sílẹ̀”

Gẹ́gẹ́ bí àgbẹ̀ ṣe kọ́kọ́ ń múra ilẹ̀ sílẹ̀ nípa lílo ohun èlò ìtúlẹ̀ kí ó tó bẹ̀rẹ̀ sí fúnrúgbìn ni Ẹ́sírà ṣe fi tàdúràtàdúrà múra ọkàn-àyà rẹ̀ sílẹ̀ láti gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Ẹ́sírà 10:1) Ní ọ̀rọ̀ mìíràn, ó ‘fi ọkàn-àyà rẹ̀’ sí ẹ̀kọ́ Jèhófà.—Òwe 2:2.

Bákan náà ni Bíbélì sọ pé Jèhóṣáfátì Ọba “múra ọkàn-àyà [rẹ̀] sílẹ̀ láti wá Ọlọ́run tòótọ́.” (2 Kíróníkà 19:3) Ní ìyàtọ̀ síyẹn, ìran Ísírẹ́lì “tí kò múra ọkàn-àyà wọn sílẹ̀” la ṣàpèjúwe gẹ́gẹ́ bí “alágídí àti ọlọ̀tẹ̀.” (Sáàmù 78:8) Jèhófà ń rí “ẹni ìkọ̀kọ̀ ti ọkàn-àyà.” (1 Pétérù 3:4) Dájúdájú, “yóò . . . kọ́ ọlọ́kàn tútù ní ọ̀nà rẹ̀.” (Sáàmù 25:9) Ẹ ò rí i bó ti ṣe pàtàkì tó pé kí àwọn olùkọ́ òde òní tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Ẹ́sírà nípa kíkọ́kọ́ gbàdúrà, láti lè mú kí ọkàn-àyà wọn wà nípò tó dára!

“Láti Ṣe Ìwádìí Nínú Òfin Jèhófà”

Kí Ẹ́sírà lè jẹ́ olùkọ́ tó dáńgájíá, ó ṣe ìwádìí nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Bí o bá lọ rí dókítà kan, ǹjẹ́ o ò ní tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa, tí wàá sì rí i dájú pé o lóye gbogbo ọ̀rọ̀ tó ń sọ tàbí oògùn tó sọ pé kó o lò? Ó dájú pé wàá ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí pé ó kan ìlera rẹ. Nítorí náà, ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká fetí sí àwọn ohun tí Jèhófà ń sọ fún wa nípasẹ̀ Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀, àti nípasẹ̀ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye.” Ó ṣe tán, ìmọ̀ràn rẹ̀ kan ìwàláàyè wa gan-an! (Mátíù 4:4; 24:45-47) Lóòótọ́, dókítà lè ṣàṣìṣe, àmọ́ “òfin Jèhófà pé.” (Sáàmù 19:7) Ọ̀rọ̀ rẹ̀ kì í ṣe ohun tá à ń ṣe iyèméjì sí.

Ìwé Kíróníkà méjèèjì nínú Bíbélì (tí Ẹ́sírà kọ́kọ́ kọ gẹ́gẹ́ bí ìdìpọ̀ kan) fi hàn pé lóòótọ́ ni Ẹ́sírà jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ tó dáńgájíá. Nígbà tó ń kọ àwọn ìwé wọ̀nyẹn, ó ṣèwádìí látinú onírúurú ìwé. a Àwọn Júù tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ti Bábílónì dé fẹ́ mọ ìtàn orílẹ̀-èdè wọn. Wọn ò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ nípa ààtò ìsìn wọn, wọn ò mọ ohun tó ń lọ nínú tẹ́ńpìlì, wọn ò sì mọ̀ nípa iṣẹ́ àwọn ọmọ Léfì. Wọ́n nílò ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìtàn ìrandíran wọn gan-an ni. Ẹ́sírà pe àfiyèsí pàtàkì sí àwọn nǹkan wọ̀nyẹn. Títí di ìgbà dídé Mèsáyà, àwọn Júù gbọ́dọ̀ wà gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè kan tó ní ilẹ̀ tirẹ̀, tó ní tẹ́ńpìlì tirẹ̀, tó sì ní àwọn àlùfáà àti gómìnà tirẹ̀. Ọpẹ́lọpẹ́ ìsọfúnni tí Ẹ́sírà kó jọ ni wọ́n fi wà níṣọ̀kan, tí ìjọsìn tòótọ́ sì fẹsẹ̀ múlẹ̀.

Báwo ni ọ̀nà tó ò ń gbà kẹ́kọ̀ọ́ ṣe rí ní ìfiwéra pẹ̀lú ti Ẹ́sírà? Fífi taápọntaápọn kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti fi Bíbélì kọ́ni lọ́nà tó gbéṣẹ́.

“Ṣe Ìwádìí Nínú Òfin Jèhófà” Gẹ́gẹ́ Bí Ìdílé

Ṣíṣe ìwádìí nínú òfin Jèhófà kò mọ sórí ìgbà tá a bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́ nìkan. Àǹfààní ńlá láti ṣe ìwádìí ni ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé jẹ́.

Àtọjọ́ tí Jan àti Julia, tọkọtaya kan ní Netherlands, ti bí àwọn ọmọkùnrin wọn méjèèjì ni wọ́n ti ń ka ìwé sókè ketekete sí wọn létí. Lónìí, Ivo ti di ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, Edo náà sì ti di ọmọ ọdún mẹ́rìnlá. Wọ́n ṣì ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé wọn lẹ́ẹ̀kan lọ́sẹ̀. Jan ṣàlàyé pé: “Kì í ṣe àtika ibi tó pọ̀ rẹpẹtẹ lákòókò ìkẹ́kọ̀ọ́ ló ká wa lára, bí kò ṣe pé káwọn ọmọkùnrin náà lóye ohun tá à ń jíròrò rẹ̀.” Ó fi kún un pé: “Àwọn ọmọkùnrin náà máa ń ṣe ìwádìí gan-an. Wọ́n máa ń wá ìtumọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣàjèjì, wọ́n sì máa ń ṣèwádìí nípa àwọn èèyàn tí Bíbélì mẹ́nu kàn—wọ́n á mọ àkókò táwọn èèyàn náà gbé ayé, irú ẹni tí wọ́n jẹ́, irú iṣẹ́ tí wọ́n ṣe, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Láti ìgbà tí wọ́n ti mọ̀wé kà, ni wọ́n ti ń ṣèwádìí látinú àwọn ìwé bíi Insight on the Scriptures, ìwé atúmọ̀ èdè, àtàwọn ìwé gbédègbẹ́yọ̀. Èyí ń mú kí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé túbọ̀ gbádùn mọ́ni gan-an ni. Ńṣe làwọn ọmọkùnrin wa máa ń fi ìháragàgà dúró de ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé.” Àǹfààní mìíràn tún ni pé àwọn ọmọkùnrin méjèèjì ló ń gbégbá orókè nínú ìlò èdè ní kíláàsì wọn.

John àti Tini, tó jẹ́ tọkọtaya mìíràn ní orílẹ̀-èdè Netherlands, bá Esli, ọmọkùnrin wọn, (tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìnlélógún tó sì ń ṣe aṣáájú ọ̀nà ní ìjọ mìíràn báyìí), àti Linda, ọmọbìnrin wọn, (tó jẹ́ ọmọ ogún ọdún tó sì ti fẹ́ arákùnrin kan tó dúró dáradára báyìí) ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́. Àmọ́, dípò kí wọ́n máa kẹ́kọ̀ọ́ ìtẹ̀jáde kan nípasẹ̀ ìbéèrè àti ìdáhùn, ohun tí wọ́n ṣe ni pé wọ́n jẹ́ kí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé náà bá ọjọ́ orí àti ohun táwọn ọmọ náà nílò mu. Ọgbọ́n wo ni wọ́n dá sí i?

John ṣàlàyé pé àwọn ọmọ òun máa ń yan àkòrí tó bá wọ̀ wọ́n lọ́kàn nínú “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” (nínú Ilé Ìṣọ́) àti “Ojú Ìwòye Bíbélì” (nínú Jí!). Ẹ̀yìn ìyẹn ni wọ́n máa ń sọ ohun tí wọ́n ti kà fún wa, èyí sì máa ń yọrí sí ìjíròrò tó lárinrin nínú ìdílé. Ọgbọ́n yìí ló jẹ́ káwọn ọmọ náà mọ bí a ṣe ń ṣe ìwádìí àti bí a ṣe ń jíròrò ohun tí wọ́n ń kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀. Ǹjẹ́ o máa ń “ṣe ìwádìí nínú òfin Jèhófà” pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ? Kì í ṣe kìkì pé èyí máa mú ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ rẹ sunwọ̀n sí i nìkan ni, àmọ́ á tún ran àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ láti di olùkọ́ tó dáńgájíá.

“Láti Pa Á Mọ́”

Ẹ́sírà fi ohun tó kọ́ sílò. Bí àpẹẹrẹ, ó ṣeé ṣe kí ara tù ú ní Bábílónì. Síbẹ̀, nígbà tó rí i pé òun lè ṣèrànwọ́ fáwọn èèyàn òun tó wà nílé lọ́hùn-ún, ó pa gbogbo ohun tó ń gbádùn ní Bábílónì tì, ó forí lé Jerúsálẹ́mù, láìfi gbogbo ìnira, ìṣòro, àti ewu ibẹ̀ pè. Ó hàn gbangba pé, kì í ṣe kìkì pé Ẹ́sírà ń kó ìmọ̀ Bíbélì jọ nìkan ni, àmọ́ ó múra tán láti fi ohun tó ń kọ́ sílò.—1 Tímótì 3:13.

Lẹ́yìn ìyẹn, nígbà tí Ẹ́sírà ń gbé ní Jerúsálẹ́mù, ó tún fi hàn pé òun ń fi àwọn ohun tí òun ń kọ́ àti èyí tí òun ń fi kọ́ni sílò. Èyí wá hàn gbangba nígbà tó gbọ́ nípa bí àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì ṣe ń fi àwọn obìnrin tó jẹ́ abọgibọ̀pẹ̀ ṣaya. Àkọsílẹ̀ Bíbélì sọ fún wa pé ‘ó gbọn ẹ̀wù rẹ̀ àti aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀ tí kò lápá ya, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fà lára irun orí rẹ̀ àti irùngbọ̀n rẹ̀ tu, ó sì jókòó tìyàlẹ́nu-tìyàlẹ́nu títí di àṣálẹ́.’ Kódà ‘ojú ń tì í, ara sì ń tì í láti gbé ojú rẹ̀ sókè’ sí Jèhófà.—Ẹ́sírà 9:1-6.

Ẹ̀kọ́ Òfin Ọlọ́run tó kọ́ mà nípa lórí rẹ̀ gan-an o! Ẹ́sírà mọ̀ dájú pé àbájáde búburú ló máa tẹ̀yìn àìgbọràn àwọn ènìyàn náà yọ. Àwọn Júù tó ti ìgbèkùn dé kéré níye gan-an. Bí wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí gbé àwọn abọ̀rìṣà níyàwó, èyí lè mú kí wọ́n dà pọ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀-èdè abọ̀rìṣà tó yí wọ́n ká níkẹyìn, ìjọsìn mímọ́ sì lè wá di èyí tó pòórá kúrò lórí ilẹ̀ ayé!

Ó dùn mọ́ni nínú pé àpẹẹrẹ ìbẹ̀rù àtọkànwá àti ìtara tí Ẹ́sírà ní mú káwọn ọmọ Ísírẹ́lì tún ọ̀nà wọn ṣe. Wọ́n lé àwọn àjèjì aya wọn lọ. Wọ́n mú gbogbo nǹkan tọ́ láàárín oṣù mẹ́ta. Dídúró tí Ẹ́sírà dúró ṣinṣin ti Òfin Ọlọ́run ni olórí ohun tó mú kí ọ̀nà tó gbà kọ́ni múná dóko.

Bákan náà ló rí lóde òní. Baba kan tó jẹ́ Kristẹni sọ pé: “Àwọn ọmọ kì í ṣe ohun tó o bá sọ; ohun tó o bá ṣe ni wọ́n máa ń ṣe!” Bọ́rọ̀ ṣe rí nínú ìjọ Kristẹni náà nìyẹn. Àwọn alàgbà tó ń fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ lè retí pé ìjọ yóò fi ẹ̀kọ́ àwọn sílò.

“Láti Máa Kọ́ni ní Ìlànà àti Ìdájọ́ Òdodo ní Ísírẹ́lì”

Ìdí mìíràn tún wà tí ọ̀nà tí Ẹ́sírà gbà kọ́ni fi múná dóko. Kò fi èrò ti ara rẹ̀ kọ́ni, bí kò ṣe “ìlànà àti ìdájọ́ òdodo.” Ìyẹn ni àwọn ìlànà, tàbí àwọn òfin, ti Jèhófà. Ohun tó jẹ́ ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àlùfáà nìyẹn. (Málákì 2:7) Ó tún kọ́ni ní ìdájọ́ òdodo, ó sì fi àpẹẹrẹ ohun tó ń kọ́ni lélẹ̀ nípa rírọ̀ mọ́ ohun tí ó jẹ́ ẹ̀tọ́ ní ọ̀nà òdodo àti àìṣègbè, ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà. Nígbà táwọn tó ní ọlá àṣẹ bá ń ṣe ìdájọ́ òdodo, ìlú á tòrò, gbogbo nǹkan á sì máa lọ ní mẹ̀lọmẹ̀lọ. (Òwe 29:4) Bákan náà ni àwọn Kristẹni alàgbà, àwọn òbí, àtàwọn olùpòkìkí Ìjọba tó mọ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dáadáa yóò mú káwọn nǹkan máa lọ ní mẹ̀lọmẹ̀lọ nípa tẹ̀mí, bí wọ́n bá ń fi ìlànà àti òdodo Jèhófà kọ́ni nínú ìjọ, nínú ìdílé wọn, àti nígbà tí wọ́n bá ń kọ́ àwọn olùfìfẹ́hàn.

Ǹjẹ́ o ò gbà pé ọ̀nà tí ò ń gbà kọ́ni lè túbọ̀ múná dóko tó o bá tẹ̀ lé gbogbo àpẹẹrẹ tí Ẹ́sírà olóòótọ́ fi lélẹ̀? Nítorí náà, ‘múra ọkàn-àyà rẹ sílẹ̀, ṣe ìwádìí nínú òfin Jèhófà, pa á mọ́, kí o sì máa kọni ní ìlànà àti òdodo Jèhófà.’ Ẹ́sírà 7:10.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A lè rí ìtòlẹ́sẹẹsẹ ogún ìwé lára èyí tó lò nínú ìwé Insight on the Scriptures, Apá Kìíní, ojú ìwé 444 sí 445, tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]

KÍ LÓ JẸ́ KÍ Ọ̀NÀ TÍ Ẹ́SÍRÀ GBÀ KỌ́NI MÚNÁ DÓKO?

1. Ó jẹ́ kí ọkàn-àyà òun wà nípò tó dára

2. Ó ṣe ìwádìí nínú Òfin Jèhófà

3. Ó fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ nínú fífi ohun tí ó kọ́ sílò

4. Ó fi ara rẹ̀ fún ẹ̀kọ́ kíkọ́ kí ó lè kọ́ni ní ohun tí Ìwé Mímọ́ wí