Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Rírìn ní Ipa Ọ̀nà Jèhófà Ń Mú Èrè Ńlá Wá

Rírìn ní Ipa Ọ̀nà Jèhófà Ń Mú Èrè Ńlá Wá

Rírìn ní Ipa Ọ̀nà Jèhófà Ń Mú Èrè Ńlá Wá

ǸJẸ́ O ti rìn lọ sórí òkè gíga rí? Tó o bá ti ṣe bẹ́ẹ̀ rí, ó ṣeé ṣe kó dà bíi pé o wà lórí gbogbo ayé nígbà tó o wà lórí òkè ọ̀hún. Gbígbádùn afẹ́fẹ́ tó mọ́ lóló, rírí ibi tó jìnnà réré, àti kéèyàn máa wo ẹwà àdánidá mà máa ń tuni lára o! Ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kéèyàn ó gbàgbé gbogbo ìṣòro rẹ lákòókò yẹn.

Kì í ṣe gbogbo èèyàn ló máa ń rin irú ìrìn bẹ́ẹ̀ lọ sórí òkè, àmọ́ bó o bá jẹ́ Kristẹni tó ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́, o ti lè máa gbé ìgbésí ayé tá a lè fi wé rírìn lọ sórí òkè nípa tẹ̀mí. Ó ṣeé ṣe kó o ti gbàdúrà bíi ti onísáàmù ìgbàanì pé: “Mú mi mọ àwọn ọ̀nà rẹ, Jèhófà; kọ́ mi ní àwọn ipa ọ̀nà rẹ.” (Sáàmù 25:4) Ǹjẹ́ o rántí bó ṣe rí lára rẹ nígbà tó o kọ́kọ́ lọ sí orí òkè ńlá ilé Jèhófà, tó o sì bẹ̀rẹ̀ sí í rìn ní àwọn ibi gíga? (Míkà 4:2; Hábákúkù 3:19) Dájúdájú, kò ní pẹ́ tí wàá fi rí i pé rírìn ní ibi gíga ti ìjọsìn mímọ́ yìí fún ọ ní ààbò àti ayọ̀. Wàá sì bẹ̀rẹ̀ sí í ní irú ìmọ̀lára tí onísáàmù náà ní nígbà tó sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn ènìyàn tí ó mọ igbe ìdùnnú. Jèhófà, inú ìmọ́lẹ̀ ojú rẹ ni wọ́n ti ń rìn.”—Sáàmù 89:15.

Àmọ́ ṣá o, ìgbà mìíràn wà táwọn tó ń rìn lọ sórí àwọn òkè gíga ní láti gba àwọn ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ kọjá. Tí ẹsẹ̀ wọn á bẹ̀rẹ̀ sí gbọ̀n, tá á sì rẹ̀ wọ́n tẹnutẹnu. Àwa náà lè kojú ìṣòro nínú iṣẹ́ ìsìn wa sí Ọlọ́run. Ó ṣeé ṣe kí ẹsẹ̀ wa bẹ̀rẹ̀ sí wúwo nílẹ̀ lẹ́nu àìpẹ́ yìí. Báwo la ṣe lè sọ agbára wa dọ̀tun, ká sì tún padà láyọ̀? Ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ ni pé ká gbà pé ọ̀nà Jèhófà ni èyí tó ga lọ́lá jù lọ.

Àwọn Òfin Gíga Ti Jèhófà

Ọ̀nà Jèhófà ‘ga ju ọ̀nà ènìyàn,’ ìjọsìn rẹ̀ sì ti ‘fìdí múlẹ̀ gbọn-in sí orí àwọn òkè ńlá, a sì ti gbé e lékè àwọn òkè kéékèèké.’ (Aísáyà 55:9; Míkà 4:1) Ọgbọ́n Jèhófà jẹ́ “ọgbọ́n tí ó wá láti òkè.” (Jákọ́bù 3:17) Àwọn òfin rẹ̀ dára ju gbogbo òfin mìíràn lọ. Bí àpẹẹrẹ, nígbà táwọn ará Kénáánì ń hu ìwà òǹrorò, tí wọ́n ń fi ọmọ rúbọ, Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní àwọn òfin tó ga lọ́lá ní ti ìwà híhù, tó sì tún fi ìyọ́nú hàn. Ó sọ fún wọn pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ fi ojúsàájú bá ẹni rírẹlẹ̀ lò, ìwọ kò sì gbọ́dọ̀ ṣe ojúsàájú ẹni ńlá. . . . Kí àtìpó . . . dà bí ọmọ ìbílẹ̀ yín; kí ìwọ sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.”—Léfítíkù 19:15, 34.

Ọ̀rúndún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lẹ́yìn ìyẹn ni Jésù wá fúnni ní ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ ‘òfin ọlọ́lá ọba’ ti Jèhófà. (Aísáyà 42:21) Nínú Ìwàásù Lórí Òkè, ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ máa bá a lọ láti máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá yín àti láti máa gbàdúrà fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí yín; kí ẹ lè fi ara yín hàn ní ọmọ Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run.” (Mátíù 5:44, 45) Ó fi kún un pé: “Gbogbo ohun tí ẹ bá fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín, kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sí wọn. Ní tòótọ́, èyí ni ohun tí Òfin àti àwọn Wòlíì túmọ̀ sí.”—Mátíù 7:12.

Àwọn òfin gíga wọ̀nyí ní ipa lórí ọkàn àwọn tó jẹ́ elétí ọmọ, ó sún wọn láti fara wé Ọlọ́run tí wọ́n ń jọ́sìn. (Éfésù 5:1; 1 Tẹsalóníkà 2:13) Ronú nípa ìyípadà tó wáyé nínú ọ̀ràn Pọ́ọ̀lù. Nígbà tí Bíbélì kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, ohun tó sọ pé ó ṣe ni pé ó “fọwọ́ sí ṣíṣìkàpa” Sítéfánù, ó sì ń hùwà “sí ìjọ lọ́nà bíburú jáì.” Ọdún díẹ̀ péré lẹ́yìn ìyẹn ló ń bá àwọn Kristẹni tó wà ní Tẹsalóníkà lò lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́ bí “ìgbà tí abiyamọ ń ṣìkẹ́ àwọn ọmọ tirẹ̀.” Ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá sọ Pọ́ọ̀lù, tó jẹ́ onínúnibíni tẹlẹ̀ di Kristẹni oníyọ̀ọ́nú. (Ìṣe 8:1, 3; 1 Tẹsalóníkà 2:7) Ó dúpẹ́ gan-an pé ẹ̀kọ́ Kristi yí irú ènìyàn tí òun jẹ́ padà. (1 Tímótì 1:12, 13) Báwo ni irú ẹ̀mí ìmoore bẹ́ẹ̀ ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti máa bá a lọ ní rírìn ní ipa ọ̀nà gíga ti Ọlọ́run?

Rírìn Pẹ̀lú Ẹ̀mí Ìmoore

Inú àwọn tí ń rìn lórí òkè ńlá máa ń dùn sí àwọn ohun àrímáleèlọ tí wọ́n ń rí lórí òkè. Wọ́n tún máa ń gbádùn àwọn nǹkan kéékèèké tí wọ́n máa ń rí lẹ́bàá ọ̀nà tí wọ́n ń rìn, àwọn nǹkan bí òkúta tó ṣàjèjì, òdòdó aláwọ̀ mèremère, tàbí kíkófìrí ẹranko ìgbẹ́. Nípa tẹ̀mí, ó yẹ ká wà lójúfò sí èrè tí ń bẹ nínú bíbá Ọlọ́run rìn, ì báà jẹ́ èrè ńlá tàbí kékeré. Èrè wọ̀nyí lè túbọ̀ fún wa lókun, kó sì sọ ìrìn tí ń tánni lókun di èyí tí ń sọ agbára ẹni dọ̀tun. A ó sì máa sọ irú ọ̀rọ̀ tí Dáfídì sọ, pé: “Mú kí n gbọ́ inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ ní òwúrọ̀, nítorí tí èmi gbẹ́kẹ̀ lé ọ. Mú mi mọ ọ̀nà tí ó yẹ kí n máa rìn.”—Sáàmù 143:8.

Mary, tó ti rìn ní ọ̀nà Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ọdún sọ pé: “Nígbà tí mo bá wo àwọn ìṣẹ̀dá Jèhófà, kì í ṣe bí ìṣẹ̀dá ṣe díjú tó nìkan ni mò ń rí, àmọ́ mo tún ń rí àwọn ànímọ́ Ọlọ́run pẹ̀lú. Ì báà jẹ́ ẹranko tàbí ẹyẹ tàbí kòkòrò, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ló dá wà láyè ara wọn, tí wọ́n sì ní àwọn ànímọ́ tó jọni lójú. Bákan náà ni mo ṣe ń gbádùn òtítọ́ tẹ̀mí tó túbọ̀ ń ṣe kedere sí i bí ọdún ṣe ń gorí ọdún.”

Báwo ni ìmọrírì wa ṣe lè jinlẹ̀ sí i? Lọ́nà kan, nípa ṣíṣàì fojú kéré ohun tí Jèhófà ń ṣe fún wa. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ máa gbàdúrà láìdabọ̀. Ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ohun gbogbo, ẹ máa dúpẹ́.”—1 Tẹsalóníkà 5:17, 18; Sáàmù 119:62.

Ìdákẹ́kọ̀ọ́ ń ràn wá lọ́wọ́ láti ní ẹ̀mí ìmoore. Pọ́ọ̀lù rọ àwọn Kristẹni tó wà ní Kólósè pé: “Ẹ máa bá a lọ ní rírìn ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú [Kristi Jésù], . . . kí ẹ máa kún fún ìgbàgbọ́ ní àkúnwọ́sílẹ̀ nínú ìdúpẹ́.” (Kólósè 2:6, 7) Kíka Bíbélì àti ṣíṣe àṣàrò lórí ohun tá a kà ń fún ìgbàgbọ́ wa lókun, ó sì ń jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ Ẹni tó ni Bíbélì. Àwọn ìṣúra tó lè mú ká ‘kún àkúnwọ́sílẹ̀ nínú ìdúpẹ́’ wà nínú rẹ̀ látìbẹ̀rẹ̀ dópin.

Sísin Jèhófà ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú àwọn arákùnrin wa tún ń jẹ́ kí ọ̀nà náà rọrùn sí i. Onísáàmù náà sọ nípa ara rẹ̀ pé: “Alájọṣe ni mo jẹ́ pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ.” (Sáàmù 119:63) Lára àwọn àkókò tínú wa máa ń dùn jù lọ ni ìgbà tá a bá wà láwọn àpéjọ Kristẹni tàbí láwọn ibòmíràn tá a ti wà láàárín àwọn arákùnrin wa. A mọ̀ dájú pé Jèhófà àtàwọn ọ̀nà rẹ̀ gíga ló jẹ́ ká ní ìdílé Kristẹni tó ṣeyebíye kárí ayé.—Sáàmù 144:15b.

Ní àfikún sí ẹ̀mí ìmoore, mímọ iṣẹ́ ẹni níṣẹ́ yóò fún wa lókun láti máa rìn nìṣó ní ipa ọ̀nà gíga ti Jèhófà.

Rírìn Bó Ṣe Tọ́ àti Bó Ṣe Yẹ

Àwọn tó bá fẹ́ rìn bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ lára àwọn tó ń gun òkè ńlá mọ̀ pé àwọn ní láti rìn tìṣọ́ratìṣọ́ra bí wọn ò bá fẹ́ sọ nù tàbí tí wọn ò bá fẹ́ bá ara wọn níbi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ tó léwu. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá tó mọnú rò, Jèhófà fún wa lómìnira láti dánú ṣe ohun tó wù wá. Àmọ́ irú òmìnira bẹ́ẹ̀ béèrè pé ká máa rìn bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ bá a ṣe ń ṣe ojúṣe wa gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni.

Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà fọkàn tán àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ó mọ̀ pé wọ́n á ṣe ojúṣe wọn bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ. Kò sọ bí agbára àti àkókò tá a gbọ́dọ̀ lò nínú ìgbòkègbodò Kristẹni ṣe ní láti pọ̀ tó, kò sì sọ iye owó tàbí iye àwọn nǹkan mìíràn pàtó tá a gbọ́dọ̀ fi ṣètìlẹ́yìn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn ará Kọ́ríńtì kan àwa náà, pé: “Kí olúkúlùkù ṣe gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti pinnu nínú ọkàn-àyà rẹ̀.”—2 Kọ́ríńtì 9:7; Hébérù 13:15, 16.

Lára ohun tí Kristẹni tó mọṣẹ́ rẹ̀ níṣẹ́ lè fi tọrẹ ni kíkópa nínú sísọ ìhìn rere náà fáwọn ẹlòmíràn. A tún ń fi hàn pé a mọṣẹ́ wa níṣẹ́ nípa fífowó ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ Ìjọba náà kárí ayé. Alàgbà kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Gerhardt, ṣàlàyé pé òun àti ìyàwó òun fi iye tó pọ̀ gan-an kún iye táwọn máa ń fi ṣètìlẹ́yìn tẹ́lẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n lọ sí àpéjọ kan ní Ìlà Oòrùn Yúróòpù. Ó sọ pé: “A rí i pé àwọn arákùnrin wa tó wà níbẹ̀ kò rí towó ṣe rárá; síbẹ̀ wọ́n mọyì àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa gan-an. Nítorí náà, a pinnu pé a ó ṣe gbogbo ìtìlẹ́yìn tá a bá lè ṣe fún àwọn arákùnrin wa tó jẹ́ aláìní láwọn ilẹ̀ mìíràn.”

Fífikún Ìfaradà Wa

Rírin ní àwọn ilẹ̀ olókè ńlá béèrè pé kéèyàn ní okun gan-an. Àwọn tó ń rìn lórí òkè máa ń ṣe eré ìmárale ní gbogbo ìgbà tí wọ́n bá ráyè rẹ̀. Ọ̀pọ̀ sì máa ń rìn lọ sí àwọn ibi tí kò jìnnà láti fi múra sílẹ̀ dìgbà tí wọ́n máa rin ọ̀nà jíjìn. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Pọ́ọ̀lù gbà wá nímọ̀ràn pé kí a jẹ́ kí ọwọ́ wa dí nínú àwọn ìgbòkègbodò Ìjọba Ọlọ́run kí a lè dúró sán-ún nípa tẹ̀mí. Pọ́ọ̀lù sọ pé, àwọn tó fẹ́ “rìn lọ́nà tí ó yẹ Jèhófà,” tí wọ́n sì fẹ́ “di alágbára,” ní láti máa “bá a lọ ní síso èso nínú iṣẹ́ rere gbogbo.”—Kólósè 1:10, 11.

Ìsúnniṣe ló ń jẹ́ kí àwọn tó ń rìn ní òkè ńlá lo ìfaradà. Lọ́nà wo? Níní góńgó kan pàtó lọ́kàn, bíi rírìn dórí òkè kan tó wà ní ọ̀nà jíjìn réré, máa ń jẹ́ kí wọ́n ní ìrọ́jú. Nígbà ti ẹni tó ń rìn ní òkè ńlá náà ba dé àárín ibì pàtàkì kan, ó lè dúró kó díwọ̀n ibi tó tẹ̀ síwájú dé nínú góńgó tó ń lépa. Bó ti ń bojú wẹ̀yìn wo ibi tí òun ti rìn dé, ńṣe ni inú rẹ̀ yóò máa dùn ṣìnkìn.

Bẹ́ẹ̀ náà ni ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun ṣe ń mẹ́sẹ̀ wa dúró, tó sì ń sún wa ṣiṣẹ́. (Róòmù 12:12) Ní báyìí ná, bí a ti ń rìn ní àwọn ọ̀nà Jèhófà, ohun tó sábà máa ń jẹ́ ìwúrí fún wa ni gbígbé àwọn góńgó Kristẹni ka iwájú wa, ká sì máa lé wọn bá. Ẹ sì wo bí inú wa ṣe ń dùn tó, nígbà tá a bá bojú wẹ̀yìn wo ọ̀pọ̀ ọdún tá a ti ń fi ìṣòtítọ́ sìn tàbí tá a bá wo àwọn ìyípadà tá a ti ṣe nínú àkópọ̀ ìwà wa!—Sáàmù 16:11.

Àwọn tó fẹ́ rin ọ̀nà jíjìn, tí wọn ò sì fẹ́ kí ó tètè rẹ̀ wọ́n, kì í rìn ní ìdákúrekú. Bákan náà ni ìtòlẹ́sẹẹsẹ tó gbéṣẹ́, tó ní lílọ sí ìpàdé àti òde ẹ̀rí déédéé nínú, yóò jẹ́ kí a lè máa tẹ̀ síwájú láti lé góńgó wa bá. Ìdí nìyẹn tí Pọ́ọ̀lù fi rọ̀ àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ pé: “Ẹ jẹ́ kí a máa bá a lọ ní rírìn létòletò nínú ọ̀nà ìgbàṣiṣẹ́ kan náà yìí.”—Fílípì 3:16.

Àmọ́ ṣá o, a kì í dá rìn ní ọ̀nà Jèhófà. Òun ló mú kí Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ jẹ́ kí a ronú lórí bí a ó ṣe máa sún ẹnì kìíní kejì wa sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ rere.” (Hébérù 10:24, New International Version) Ìbákẹ́gbẹ́ rere nípa tẹ̀mí yóò jẹ́ kó rọrùn fún wa láti máa tẹ̀ síwájú bí a ṣe ń bá àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ rìn.—Òwe 13:20.

Lékè gbogbo rẹ̀, a ò gbọ́dọ̀ gbàgbé agbára tí Jèhófà ń fúnni. Àwọn tí okun wọn ń bẹ nínú Jèhófà yóò “máa rìn lọ láti ìmí dé ìmí.” (Sáàmù 84:5, 7) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a lè bára wa nínú ipò líle koko lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, síbẹ̀ pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, a lè kẹ́sẹ járí.