Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Àwọn ìgbà wo ló yẹ kí Kristẹni obìnrin borí rẹ̀ fún àwọn ìdí tó jẹ mọ́ ọ̀ràn tẹ̀mí?

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Olúkúlùkù obìnrin tí ń gbàdúrà tàbí tí ń sọ tẹ́lẹ̀ láìbo orí rẹ̀ dójú ti orí rẹ̀.” Kí nìdí? Nítorí ìlànà ipò orí tí Bíbélì là kalẹ̀ ni, èyí tó sọ pé: “Orí obìnrin ni ọkùnrin.” Gbígbàdúrà tàbí kíkọ́ni nínú ìjọ Kristẹni jẹ́ ojúṣe ọkùnrin. Ìyẹn ló fi yẹ kí Kristẹni obìnrin fi nǹkan borí nígbà tó bá ń bójú tó àwọn ọ̀ràn tó jẹ mọ́ ìjọsìn, èyí tó sábà máa ń jẹ́ ojúṣe ọkọ rẹ̀ tàbí ti ọkùnrin tó ti ṣe batisí.—1 Kọ́ríńtì 11:3-10.

Àwọn ipò kan lè dìde tó lè jẹ́ kó di dandan pé kí Kristẹni obìnrin tó wà nílé ọkọ fi nǹkan borí. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ìdílé bá pàdé pọ̀ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tàbí fún oúnjẹ, ọkọ ló sábà máa ń mú ipò iwájú nínú kíkọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ àti ṣíṣáájú wọn nínú àdúrà sí Ọlọ́run. Àmọ́, bí ọkùnrin náà bá jẹ́ aláìgbàgbọ́, ojúṣe yìí lè di ti ìyàwó rẹ̀. Fún ìdí yìí, Kristẹni arábìnrin ní láti fi nǹkan borí nígbà tó bá ń gbàdúrà sókè fún ara rẹ̀ àtàwọn ẹlòmíràn tàbí nígbà tó bá ń bá àwọn ọmọ rẹ̀ ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì níbi tí ọkọ rẹ̀ wà. Bí ọkọ rẹ̀ kò bá sí níbẹ̀, kò pọn dandan kí ìyàwó fi nǹkan borí, torí pé Ọlọ́run fún òun náà láṣẹ láti kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́.—Òwe 1:8; 6:20.

Àmọ́, bí ọ̀dọ́mọkùnrin kan nínú ìdílé náà bá jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà Ọlọ́run tó ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́, tó sì ti ṣe batisí ńkọ́? Níwọ̀n bí ọmọkùnrin yìí ti jẹ́ ara ìjọ Kristẹni, àwọn ọkùnrin inú ìjọ Kristẹni ló yẹ kí ó máa fún un ní ìtọ́ni. (1 Tímótì 2:12) Bí bàbá ọmọ náà bá jẹ́ onígbàgbọ́, òun ló yẹ kó máa kọ́ ọmọkùnrin rẹ̀. Àmọ́ o, bí bàbá náà kò bá sí nílé, á jẹ́ pé ìyá náà á fi nǹkan borí nígbà tó bá ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú ọmọkùnrin rẹ̀ ọ̀dọ́ tó ti ṣe batisí àtàwọn ọmọ yòókù. Òun ló máa pinnu bóyá òun á ní kí ọmọ òun tó ti ṣe batisí gbàdúrà nígbà tí wọ́n bá ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ tàbí nígbà oúnjẹ. Ó lè gbà pé ọmọ náà kò tíì tóótun tó, kí ó sì tipa báyìí pinnu pé òun fúnra òun á gbàdúrà. Bó bá yàn láti gbàdúrà nírú àkókò bẹ́ẹ̀, ó ní láti fi nǹkan borí.

Nígbà táwọn Kristẹni obìnrin bá ń kópa nínú àwọn ìgbòkègbodò kan tó jẹ́ ti ìjọ, ó lè pọn dandan kí wọ́n fi nǹkan borí. Bí àpẹẹrẹ, ó lè jẹ́ àwọn Kristẹni arábìnrin nìkan ló pésẹ̀ síbi ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá láàárín ọ̀sẹ̀, láìsí ọkùnrin kankan tó ti ṣe batisí. Àwọn ìgbà míì lè wà tí kò ní sí àwọn ọkùnrin tó ti ṣe batisí nípàdé ìjọ. Bó bá di dandan kí arábìnrin kan ṣe iṣẹ́ tí arákùnrin sábà máa ń ṣe nínú ìpàdé ìjọ tàbí nígbà ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá, ó ní láti fi nǹkan borí.

Ṣé dandan ni kí àwọn Kristẹni obìnrin fi nǹkan borí bí wọ́n bá ń ṣe ìtumọ̀ lọ́rọ̀ ẹnu tàbí bí wọ́n bá ń túmọ̀ àsọyé Bíbélì sí èdè àwọn adití tàbí bí wọ́n bá ń ka àwọn ìpínrọ̀ fún àwùjọ látinú ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí à ń lò nínú ìpàdé ìjọ? Rárá o. Kì í ṣe iṣẹ́ olùdarí tàbí iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ làwọn arábìnrin tí ń ṣe iṣẹ́ wọ̀nyẹn ń ṣe. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, kò pọn dandan kí àwọn arábìnrin tí ń kópa nínú àṣefihàn, tí wọ́n ń sọ ìrírí, tàbí tí wọ́n ní ọ̀rọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run fi nǹkan borí.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọkùnrin tó ti ṣe batisí ló ń kọ́ni nínú ìjọ, tọkùnrin tobìnrin ló ni ẹrù iṣẹ́ wíwàásù àti kíkọ́ni lóde ìjọ. (Mátíù 24:14; 28:19, 20) Ìyẹn ló fi jẹ́ pé nígbà tí Kristẹni obìnrin bá ń bá ará ìta sọ̀rọ̀ nípa Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run níbi tí ọkùnrin Ẹlẹ́rìí Jèhófà wà, kò pọn dandan kí obìnrin náà fi nǹkan borí.

Àmọ́, ìyẹn tún yàtọ̀ sígbà téèyàn bá ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí à ń ṣe déédéé nínú ilé, níbi tí ọkùnrin tó ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́, tó sì ti ṣèrìbọmi wà. Èyí jẹ́ ètò ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tá a ti ṣètò rẹ̀ tẹ́lẹ̀, èyí tí ẹni tí ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà ti jẹ́ olùdarí ní ti gidi. Nínú irú ipò bẹ́ẹ̀, ìkẹ́kọ̀ọ́ náà kò yàtọ̀ sí kíkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ nínú ìjọ. Bó bá jẹ́ pé obìnrin Ẹlẹ́rìí tó ti ṣèrìbọmi ló fẹ́ darí ìkẹ́kọ̀ọ́ níbi tí ọkùnrin Ẹlẹ́rìí tó ti ṣèrìbọmi wà, ó di dandan kí obìnrin náà fi nǹkan borí. Ṣùgbọ́n arákùnrin yẹn tó ti ṣe ìyàsímímọ́ ló máa gbàdúrà. Arábìnrin kan kò ní gbàdúrà níbi tí arákùnrin tó ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ wà, àfi bí ìdí gúnmọ́ bá wà, bíi bóyá arákùnrin náà ní ìṣòro tí kò jẹ́ kí ó lè sọ̀rọ̀.

Ìgbà mìíràn wà tí ọkùnrin tí kò tíì ṣèrìbọmi àmọ́ tó jẹ́ akéde Ìjọba náà máa ń bá Kristẹni arábìnrin lọ síbi tó ti máa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bí arábìnrin náà bá fẹ́ bẹ́ẹ̀, ó lè sọ pé kí ọkùnrin náà darí ìkẹ́kọ̀ọ́ yẹn. Ṣùgbọ́n níwọ̀n bí kò ti tọ́ kí ọkùnrin yìí ṣáájú arábìnrin tó ti ṣèrìbọmi nínú àdúrà sí Jèhófà, obìnrin náà ló tọ́ kó gbàdúrà níbi ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Bó bá jẹ́ pé arábìnrin náà ló darí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, tó sì gbàdúrà, yóò pọn dandan kí arábìnrin náà borí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọkùnrin náà tó jẹ́ akéde kò tíì ṣèrìbọmi, ojú ọmọ ìjọ làwọn ará ìta fi ń wò ó nítorí iṣẹ́ ìwàásù tó ń ṣe.

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé ó “yẹ kí obìnrin ní àmì ọlá àṣẹ ní orí rẹ̀ nítorí àwọn áńgẹ́lì.” Bẹ́ẹ̀ ni o, àwọn Kristẹni arábìnrin ní àǹfààní jíjẹ́ àpẹẹrẹ rere lójú ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn áńgẹ́lì tó ń fi ìdúróṣinṣin tẹrí ba fún Jèhófà. Ẹ ò rí i pé ó yẹ kí àwọn obìnrin olùbẹ̀rù Ọlọ́run rí i dájú pé àwọn ń fi nǹkan borí nígbà tó bá yẹ kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀!

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Fífi nǹkan borí jẹ́ àmì bíbọ̀wọ̀ fún ipò orí