Kí Ló Ti Ṣẹlẹ̀ sí Iná Ọ̀run Àpáàdì?
Kí Ló Ti Ṣẹlẹ̀ sí Iná Ọ̀run Àpáàdì?
KÍ NI gbólóhùn náà “ọ̀run àpáàdì” gbé wá sí ọ lọ́kàn? Ṣé ibi tí iná gidi ti ń fi imí ọjọ́ jó, téèyàn ti ń joró, tó sì ń payín keke títí ayé lo ka ọ̀run àpáàdì sí? Tàbí kẹ́, ṣé ipò kan ni ọ̀run àpáàdì wúlẹ̀ ń ṣàpẹẹrẹ?
Tipẹ́tipẹ́ làwọn aṣáájú ẹ̀sìn nínú àwọn ṣọ́ọ̀ṣì ti ń fi yéni pé ọ̀run àpáàdì tó ń jó lala, tá a ti ń dáni lóró burúkú-burúkú ni ìpín àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn ẹ̀sìn mìíràn ló ṣì gba ẹ̀kọ́ yẹn gbọ́ dòní. Ìwé ìròyìn U.S.News & World Report, sọ pé: “Òótọ́ ni pé ẹ̀sìn Kristẹni ló tan ọ̀rọ̀ nípa ọ̀run àpáàdì kálẹ̀. Ṣùgbọ́n ẹ̀sìn Kristẹni nìkan kọ́ ló ń fi ẹ̀kọ́ ọ̀run àpáàdì kọ́ni. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo ẹ̀sìn ńláńlá àtàwọn ẹ̀sìn kéékèèké kárí ayé ló ń kọ́ni pé àwọn èèyàn á jìyà iṣẹ́ ọwọ́ wọn lẹ́yìn ikú.” Àwọn ẹlẹ́sìn Híńdù, Búdà, àwọn Mùsùlùmí, àwọn ẹlẹ́sìn Jain àti Tao gbà pé ọ̀run àpáàdì kan wà níbì kan.
Àmọ́, òye tuntun ti dóde báyìí nípa ọ̀run àpáàdì. Ìwé ìròyìn tá a tọ́ka sí lókè yìí sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan ṣì wonkoko mọ́ èrò náà pé iná ń jó nínú ọ̀run àpáàdì, èyí tá a tún ń gbọ́ táwọn kan ń sọ báyìí ni pé dídáwà ní ipò tí kò bára dé ni gbogbo ìyà àìnípẹ̀kun náà jẹ́, tó túmọ̀ sí pé iná tilẹ̀ lè máà sí ní ọ̀run àpáàdì rárá.”
Ìwé ìròyìn àwọn ẹlẹ́sìn Jesuit náà, La Civiltà Cattolica, sọ pé: “Ẹ̀kọ́ ìṣìnà ni . . . láti ronú pé Ọlọ́run ń tipasẹ̀ àwọn ẹ̀mí èṣù fi iná dá àwọn ẹni ibi lóró.” Ó fi kún un pé: “Ọ̀run àpáàdì wà. Àmọ́ kì í ṣe ibì kan, bí kò ṣe ipò kan. Ìyẹn ipò ìbànújẹ́ tí ẹni náà wà nítorí àìní àjọṣe kankan pẹ̀lú Ọlọ́run.” Póòpù John Paul Kejì sọ lọ́dún 1999, pé: “Ọ̀run àpáàdì kì í ṣe ibì kan, bí kò ṣe ipò àwọn tó mọ̀ọ́mọ̀ ya ara wọn nípa sí Ọlọ́run pátápátá, ẹni tí í ṣe orísun gbogbo ìyè àti ayọ̀.” Ní ti àwọn àwòrán tó ń fi hàn pé ọ̀run àpáàdì jẹ́ ibi oníná, ó sọ pé: “Ohun tí àwòrán wọ̀nyẹn ń fi hàn ni ìgbésí ayé àìnírètí, ìgbésí ayé ìmúlẹ̀mófo, tí àwọn tí kò ní Ọlọ́run ń gbé.” Martin Marty, tí í ṣe òpìtàn ṣọ́ọ̀ṣì sọ pé, ká ní póòpù sọ pé ọ̀run àpáàdì jẹ́ ibi “tíná ti ń jó lala, tí èṣù aláṣọ pupa ti mú àmúga ńlá lọ́wọ́ ni, ẹ̀rín làwọn èèyàn ì bá fi í rín.”
Àwọn ìjọ mìíràn pẹ̀lú ti ń yí èrò wọn padà. Ìròyìn kan tí àjọ tó ń mójú tó ọ̀ràn ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn nínú Ìjọ Áńgílíkà gbé jáde sọ pé: “Ọ̀run àpáàdì kì í ṣe ibi ìdálóró ayérayé, bí kò ṣe yíyàn láti wonkoko mọ́ ohun tí Ọlọ́run sọ pé kò dáa, kéèyàn sì ri ara rẹ̀ bọnú nǹkan ọ̀hún débi pé àtúbọ̀tán rẹ̀ ni pé kéèyàn ṣaláìsí pátápátá.”
Ìwé katikísìmù Ìjọ Oníbíṣọ́ọ̀bù ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà sọ pé ọ̀run àpáàdì túmọ̀ sí “ikú àkúrun nítorí kíkọ Ọlọ́run sílẹ̀.” Ìwé ìròyìn U.S.News & World Report sọ pé àwọn èèyàn púpọ̀ sí i ló ń tan èrò náà kálẹ̀ pé “ìparun ni ìpín àwọn ẹni ibi,
kì í ṣe ìyà àìnípẹ̀kun. . . . [Àwọn èèyàn wọ̀nyí] ń fi yéni pé àwọn tó bá kọ Ọlọ́run sílẹ̀ á kàn ṣègbé ni, nínú ‘iná ajónirun’ ní ọ̀run àpáàdì.”Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èròǹgbà tó lòde báyìí ni ìgbàgbọ́ pé iná àti imí ọjọ́ kò sí ní ọ̀run àpáàdì, ọ̀pọ̀ ló ṣì gbà pé ọ̀run àpáàdì jẹ́ ibi ìdánilóró ní ti gidi. Ọ̀gbẹ́ni Albert Mohler, láti ilé ẹ̀kọ́ Southern Baptist Theological Seminary nílùú Louisville, ní Ìpínlẹ̀ Kentucky, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Ìwé Mímọ́ fi hàn kedere pé ọ̀run àpáàdì jẹ́ ibi tá a ti ń fi iná gidi dáni lóró.” Ìròyìn náà, Irú Ibi Tí Ọ̀run Àpáàdì Jẹ́, tí Àjọ Ẹgbẹ́ Àwọn Ajíhìnrere gbé jáde, sọ pé: “Ọ̀run àpáàdì jẹ́ ipò jíjẹ́ ẹni ìtanù, tí onítọ̀hún á sì máa mọ̀ ọ́n lára pé à ń dá òun lóró.” Ó fi kún un pé: “Bí ẹ̀ṣẹ̀ téèyàn dá láyé bá ṣe wúwo tó, bẹ́ẹ̀ náà ni ìyà onítọ̀hún á ṣe pọ̀ tó ní ọ̀run àpáàdì.”
Ká tún béèrè lẹ́ẹ̀kan sí i, ṣé inú iná tá a ti ń dáni lóró títí ayé ni ọ̀run àpáàdì jẹ́ ni, àbí ìparun yán-ányán-án? Tàbí kẹ̀, ṣé ipò àìní àjọṣe kankan pẹ̀lú Ọlọ́run lásán ni? Kí ni ọ̀run àpáàdì jẹ́ gan-an?
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]
Ìtàn Ṣókí Nípa Iná Ọ̀run Àpáàdì
ÌGBÀ wo làwọn tó pera wọn ní Kristẹni tẹ́wọ́ gba ìgbàgbọ́ nínú iná ọ̀run àpáàdì? Ọjọ́ pẹ́ lẹ́yìn àkókò Jésù Kristi àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ kí wọ́n tó tẹ́wọ́ gba ẹ̀kọ́ náà. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ èdè Faransé náà, Encyclopædia Universalis, sọ pé: “Àpókálíìsì Pétérù (ọ̀rúndún kejì sànmánì tiwa) ni ìwé [àpókírífà] àkọ́kọ́ táwọn Kristẹni kọ, tó sọ̀rọ̀ nípa fífìyàjẹ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ àti dídá wọn lóró ní ọ̀run àpáàdì.”
Àmọ́ o, àríyànjiyàn nípa ọ̀run àpáàdì wà láàárín àwọn Bàbá Ìjọ ìjímìjí. Justin Martyr, Clement ará Alẹkisáńdíríà, Tertullian àti Cyprian gbà gbọ́ pé ibi oníná ni ọ̀run àpáàdì. Origen àti ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn nì, Gregory ti ìlú Nyssa, ka ọ̀run àpáàdì síbi téèyàn ò ti ní àjọṣe kankan pẹ̀lú Ọlọ́run—ibi ìjìyà nípa tẹ̀mí. Ṣùgbọ́n Augustine ti ìlú Hippo ní tirẹ̀ gbà gbọ́ pé ìjìyà inú ọ̀run àpáàdì jẹ́ nípa tẹ̀mí àti nípa tara—èrò yìí sì wá tàn kálẹ̀. Ọ̀jọ̀gbọ́n J.N.D. Kelly kọ̀wé pé: “Nígbà tó fi máa di ọ̀rúndún karùn-ún, ẹ̀kọ́ tó gbòde kan ni ẹ̀kọ́ mímúná náà pé lẹ́yìn táwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ bá ti kú, ìdájọ́ ló ń dúró dè wọ́n àti pé iná àjóòkú ló máa jó wọn run.”
Ní ọ̀rúndún kẹrìndínlógún, àwọn alátùn-únṣe inú ẹ̀sìn Pùròtẹ́sítáǹtì, bíi Martin Luther àti John Calvin gbà pé èdè ìṣàpẹẹrẹ ni iná tá a fi ń dáni lóró nínú ọ̀run àpáàdì jẹ́. Wọ́n ní ohun tó túmọ̀ sí ni wíwà títí ayérayé láìní àjọṣe kankan pẹ̀lú Ọlọ́run. Àmọ́ ṣá o, èrò náà pé ọ̀run àpáàdì jẹ́ ibi ìdánilóró tún padà wá ní ọ̀rúndún méjì tó tẹ̀ lé e. Oníwàásù ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítáǹtì nì, Jonathan Edwards, máa ń fi àwòrán ọ̀run àpáàdì tí ń da jìnnìjìnnì boni dáyà já àwọn ará Amẹ́ríkà Agbókèèrè-ṣàkóso ní ọ̀rúndún kejìdínlógún.
Ṣùgbọ́n láìpẹ́ sígbà yẹn ni iná ọ̀run àpáàdì tún bẹ̀rẹ̀ sí í kú lọ díẹ̀díẹ̀. Ìwé ìròyìn U.S.News & World Report sọ pé: “Ọ̀run àpáàdì fẹ́rẹ̀ẹ́ di ohun ìgbàgbé ní ọ̀rúndún ogún.”
[Àwọn àwòrán]
Justin Martyr gbà gbọ́ pé ọ̀run àpáàdì jẹ́ ibi oníná
Augustine ti ìlú Hippo kọ́ni pé ìjìyà inú ọ̀run àpáàdì jẹ́ nípa tẹ̀mí àti nípa tara