Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Ni Ọ̀run Àpáàdì Jẹ́ Gan-an?

Kí Ni Ọ̀run Àpáàdì Jẹ́ Gan-an?

Kí Ni Ọ̀run Àpáàdì Jẹ́ Gan-an?

OHUN yòówù kí ọ̀rọ̀ náà “ọ̀run àpáàdì” gbé wá sí ọ lọ́kàn, ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn ka ọ̀run àpáàdì sí ni ibi ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀. Ohun tí Bíbélì sọ nípa ẹ̀ṣẹ̀ àti ìyọrísí rẹ̀ ni pé: ‘Nípasẹ̀ ènìyàn kan ni ẹ̀ṣẹ̀ fi wọ ayé àti ikú nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, ikú sì tipa báyìí tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn nítorí pé gbogbo wọn ti dẹ́ṣẹ̀.’ (Róòmù 5:12) Ìwé Mímọ́ tún sọ pé: “Owó ọ̀yà tí ẹ̀ṣẹ̀ máa ń san ni ikú.” (Róòmù 6:23) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ikú ni ìyà ẹ̀ṣẹ̀, ìbéèrè pàtàkì tá a fi lè mọ ohun tí ọ̀run àpáàdì jẹ́ gan-an ni: Kí ló máa ń ṣẹlẹ̀ sí wa nígbà tá a bá kú?

Ǹjẹ́ ìwàláàyè ṣì máa ń bá a nìṣó, lọ́nà kan ṣá, lẹ́yìn ikú? Kí ni ọ̀run àpáàdì, irú àwọn èèyàn wo ló sì ń lọ síbẹ̀? Ǹjẹ́ ìrètí kankan wà fáwọn tó wà ní ọ̀run àpáàdì? Bíbélì fún wa ní ìdáhùn tòótọ́, tó sì ń tẹ́ni lọ́rùn sí ìbéèrè wọ̀nyí.

Ǹjẹ́ Èèyàn Ń Wà Láàyè Lẹ́yìn Ikú?

Ǹjẹ́ nǹkan kan nínú wa, bí ọkàn tàbí ẹ̀mí, tó máa ń wà láàyè nìṣó lẹ́yìn tí ara bá kú wà? Ẹ jẹ́ ká wo bí Ádámù, ọkùnrin àkọ́kọ́, ṣe di alààyè. Bíbélì sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹ̀dá ọkùnrin náà láti inú ekuru ilẹ̀, ó sì fẹ́ èémí ìyè sínú ihò imú rẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:7) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èémí ló ń gbé ẹ̀mí rẹ̀ ró, fífẹ́ “èémí ìyè” sínú ihò imú rẹ̀ kì í wulẹ̀ í ṣe fífẹ́ atẹ́gùn sínú ẹ̀dọ̀fóró rẹ̀. Ohun tí Ọlọ́run fi sínú ara bọrọgidi Ádámù ni ohun tó mú kí ìwàláàyè ṣeé ṣe—èyíinì ni “ipá ìwàláàyè,” tó ń ṣiṣẹ́ nínú gbogbo ẹ̀dá orí ilẹ̀ ayé. (Jẹ́nẹ́sísì 6:17; 7:22) Bíbélì pe agbára ìwàláàyè yìí ní “ẹ̀mí.” (Jákọ́bù 2:26) A lè fi ẹ̀mí yìí wé iná mànàmáná tó ń fún ẹ̀rọ tàbí ohun èlò inú ilé lágbára, tó sì ń jẹ́ kó ṣiṣẹ́. Gẹ́gẹ́ bí iná mànàmáná kò ti lè dá ṣe ohun tí ẹ̀rọ tó ń mú ṣiṣẹ́ ń ṣe, bẹ́ẹ̀ náà ni ipá ìwàláàyè kò lè dá ṣe ohunkóhun tí àwọn ẹ̀dá tí ipá yìí ń jẹ́ kó wà láàyè ń ṣe. Kò lè dá dúró láyè ara ẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni kò lè dánú rò.

Kí ló ń ṣẹlẹ̀ sí ẹ̀mí yìí nígbà téèyàn bá kú? Sáàmù 146:4 sọ pé: “Ẹ̀mí rẹ̀ jáde lọ, ó padà sínú ilẹ̀ rẹ̀; ní ọjọ́ yẹn ni àwọn ìrònú rẹ̀ ṣègbé.” Nígbà téèyàn bá kú, ẹ̀mí rẹ̀ tí kò lè dá dúró kò lè lọ máa gbé níbòmíràn gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ẹ̀mí. Ńṣe ni yóò “padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run tòótọ́ tí ó fi í fúnni.” (Oníwàásù 12:7) Èyí túmọ̀ sí pé gbogbo ìrètí pé onítọ̀hún tún lè wà láàyè lọ́jọ́ iwájú dọwọ́ Ọlọ́run.

Socrates àti Plato, ìyẹn àwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí Gíríìkì ìgbàanì, gbà gbọ́ pé kiní kan tí ń jẹ́ ọkàn nínú èèyàn máa ń wà láàyè lẹ́yìn ikú, àti pé kì í kú rárá. Kí ni Bíbélì fi kọ́ni nípa ọkàn? Jẹ́nẹ́sísì 2:7 sọ pé Ádámù “wá di alààyè ọkàn.” Kì í ṣe pé a fún un ní ọkàn; òun fúnra rẹ̀ ni ọkàn, ìyẹn odindi èèyàn. Ìwé Mímọ́ fi hàn pé ọkàn lè ṣiṣẹ́, ó lè fẹ́ jẹun, wọ́n lè jí i gbé, ó lè ṣàìrí oorun sùn, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. (Léfítíkù 23:30; Diutarónómì 12:20; 24:7; Sáàmù 119:28) Àní sẹ́, èèyàn fúnra rẹ̀ ni ọkàn. Nígbà tẹ́nì kan bá kú, ọkàn yẹn kú nìyẹn.—Ìsíkíẹ́lì 18:4.

Kí wá ni ipò tí àwọn òkú wà? Nígbà tí Jèhófà ń dá Ádámù lẹ́jọ́, ohun tó sọ ni pé: “Ekuru ni ọ́, ìwọ yóò sì padà sí ekuru.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:19) Ibo ni Ádámù wà kí Ọlọ́run tó fi ekuru dá a, tó sì fún un ní ìwàláàyè? Kò kúkú sí níbì kankan! Nígbà tí Ádámù kú, ńṣe ló tún padà di ẹni tí kò sí níbì kankan. Ìwé Oníwàásù 9:5, 10 sọ ipò táwọn òkú wà ní kedere, ó ní: “Àwọn òkú, wọn kò mọ nǹkan kan rárá . . . Kò sí iṣẹ́ tàbí ìhùmọ̀ tàbí ìmọ̀ tàbí ọgbọ́n ní Ṣìọ́ọ̀lù, ibi tí ìwọ ń lọ.” Ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ ni pé ikú túmọ̀ sí jíjẹ́ aláìsí. Àwọn òkú kò mọ nǹkan kan, wọn kò ní ìmọ̀lára kankan, wọn kò ní èrò kankan.

Ṣé Ìdálóró Ayérayé Ni àbí Sàréè Gbogbo Aráyé?

Níwọ̀n bí àwọn òkú kò ti mọ nǹkan kan rárá, ọ̀run àpáàdì kò lè jẹ́ ibi tá a ti ń fi iná dáni lóró, táwọn olubi ti ń jìyà lẹ́yìn ikú. Kí wá ni ọ̀run àpáàdì? A óò rí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí tá a bá gbé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jésù lẹ́yìn ikú rẹ̀ yẹ̀ wò. Lúùkù, tó wà lára àwọn tó kọ Bíbélì, ròyìn pé: “A kò ṣá [Jésù] tì sínú Hédíìsì [ìyẹn ọ̀run àpáàdì, King James Version], bẹ́ẹ̀ ni ẹran ara rẹ̀ kò rí ìdíbàjẹ́.” a (Ìṣe 2:31) Ibo ni ọ̀run àpáàdì tí Jésù lọ wà? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Mo fi lé yín lọ́wọ́ . . . pé Kristi kú fún ẹ̀ṣẹ̀ wa gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti wí; àti pé a sin ín, bẹ́ẹ̀ ni, pé a ti gbé e dìde ní ọjọ́ kẹta gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti wí.” (1 Kọ́ríńtì 15:3, 4) Nítorí náà, Jésù lọ sí ọ̀run àpáàdì, ìyẹn sàréè, ṣùgbọ́n Ọlọ́run kò fi í sílẹ̀ síbẹ̀, torí pé ó jí i dìde.

Tún ronú nípa Jóòbù, ọkùnrin olódodo nì, tí ojú pọ́n gidigidi. Nígbà tí ìyà náà fẹ́ pàpọ̀jù, ó gbàdúrà pé: “Ta ló máa gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi, àní kí o fi mí pa mọ́ sínú ọ̀run àpáàdì [Ṣìọ́ọ̀lù], kí o sì fi mí pa mọ́ títí ìrunú rẹ á fi kọjá lọ?” b (Jóòbù 14:13, Douay Version) Ẹ ò rí i pé kò bọ́gbọ́n mu rárá láti ronú pé ńṣe ni Jóòbù ń wá ààbò lọ sínú iná gbígbóná janjan! Lọ́kàn Jóòbù, “ọ̀run àpáàdì” wulẹ̀ jẹ́ sàréè, níbi tí ìjìyà rẹ̀ yóò ti dópin. Fún ìdí yìí, sàréè gbogbo aráyé, tí àwọn èèyàn rere àtàwọn èèyàn búburú ń lọ ni ọ̀run àpáàdì tí Bíbélì sọ̀rọ̀ rẹ̀.

Iná Ọ̀run Àpáàdì —Ṣé Ìparun Yán-ányán-án Ni?

Ó ha lè jẹ́ pé iná tí wọ́n sọ pé ó ń jó ní ọ̀run àpáàdì wulẹ̀ jẹ́ àpẹẹrẹ ìparun yán-ányán-án tàbí ìparun pátápátá bí? Láti fi hàn pé ọ̀tọ̀ ni iná, ọ̀tọ̀ sì ni Hédíìsì, tàbí ọ̀run àpáàdì, Ìwé Mímọ́ sọ pé: “A sì fi ikú àti Hédíìsì sọ̀kò sínú adágún iná.” “Adágún” tá a mẹ́nu kàn níhìn-ín jẹ́ èdè àpèjúwe, níwọ̀n bí ikú àti ọ̀run àpáàdì (Hédíìsì) tá a jù sínú rẹ̀ kì í ti í ṣe ohun tó lè jó. “Èyí [adágún iná náà] túmọ̀ sí ikú kejì”—ikú tó jẹ́ pé téèyàn bá ti kú u kò sí ìrètí àjíǹde mọ́ nìyẹn.—Ìṣípayá 20:14.

Ìtumọ̀ adágún iná náà kò fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ sí ìtumọ̀ “Gẹ̀hẹ́nà oníná [iná ọ̀run àpáàdì, Bibeli Mimọ]” tí Jésù sọ̀rọ̀ rẹ̀. (Mátíù 5:22; Máàkù 9:47, 48) Ìgbà méjìlá ni Gẹ̀hẹ́nà fara hàn nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, ó sì tọ́ka sí àfonífojì Hínómù, tí ń bẹ lẹ́yìn odi Jerúsálẹ́mù. Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, ààtàn ni àfonífojì yìí jẹ́, “níbi tí wọ́n ń ju òkú ọ̀daràn, àti òkú ẹran, àti onírúurú ẹ̀gbin sí.” (Smith’s Dictionary of the Bible) Imí ọjọ́ ni wọ́n máa ń dà sínú iná náà, kó lè jó àwọn ẹ̀gbin náà ráúráú. Jésù fi àfonífojì yẹn ṣàpẹẹrẹ ìparun ayérayé.

Gẹ́gẹ́ bí Gẹ̀hẹ́nà ti ṣàpẹẹrẹ ìparun ayérayé, bẹ́ẹ̀ náà ni adágún iná ṣàpẹẹrẹ ìparun ayérayé. A fi ikú àti Hédíìsì “sọ̀kò” sínú rẹ̀ ní ti pé a óò mú wọn kúrò nígbà tí aráyé bá bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ẹ̀bi ikú. Àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ àmọ̀ọ́mọ̀dá, tó kọ̀ láti ronú pìwà dà, pẹ̀lú yóò ní “ìpín” tiwọn nínú adágún náà. (Ìṣípayá 21:8) Àwọn náà yóò pa run títí láé. Àmọ́ àwọn tó wà nínú ìrántí Ọlọ́run nínú ọ̀run àpáàdì—ìyẹn sàréè gbogbo aráyé—ní ọjọ́ ọ̀la tó gbámúṣé.

Ọ̀run Àpáàdì Yóò Ṣófo!

Ìṣípayá 20:13 sọ pé: “Òkun sì jọ̀wọ́ àwọn òkú tí ń bẹ nínú rẹ̀ lọ́wọ́, ikú àti Hédíìsì sì jọ̀wọ́ àwọn òkú tí ń bẹ nínú wọn lọ́wọ́.” Bẹ́ẹ̀ ni o, ọ̀run àpáàdì tí Bíbélì sọ̀rọ̀ rẹ̀ yóò ṣófo. Gẹ́gẹ́ bí Jésù ti ṣèlérí, “wákàtí náà ń bọ̀, nínú èyí tí gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò gbọ́ ohùn [Jésù], wọn yóò sì jáde wá.” (Jòhánù 5:28, 29) Ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn tó ti kú, tí wọn ò sí láàyè níbì kankan báyìí, àmọ́ tí wọ́n wà nínú ìrántí Jèhófà Ọlọ́run yóò jíǹde, ìyẹn ni pé a óò mú wọn padà bọ̀ sí ìyè, nínú Párádísè ilẹ̀ ayé tá a ti mú bọ̀ sípò.—Lúùkù 23:43; Ìṣe 24:15.

Nínú ayé tuntun ti Ọlọ́run, àwọn èèyàn tá a jí dìde, tí wọ́n sì ń pa òfin òdodo rẹ̀ mọ́, kò ní kú mọ́ láé. (Aísáyà 25:8) Jèhófà “yóò . . . nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́.” Àní sẹ́, “ohun àtijọ́ [á] ti kọjá lọ.” (Ìṣípayá 21:4) Ìbùkún ńláǹlà mà ló ń dúró de àwọn tó wà ní ọ̀run àpáàdì o—ìyẹn “ibojì ìrántí”! Dájúdájú, ìbùkún yìí nìkan tó ohun tó fi yẹ ká túbọ̀ gba ìmọ̀ Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi, Ọmọ rẹ̀ sínú.—Jòhánù 17:3.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Nínú King James Version, ọ̀rọ̀ Gíríìkì “náà Hédíìsì la túmọ̀ sí “ọ̀run àpáàdì” ní ibi mẹ́wẹ̀ẹ̀wá tó ti fara hàn nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì. Ìtàn inú Lúùkù 16:19-31 mẹ́nu kan jíjoró, ṣùgbọ́n àpèjúwe ni gbogbo ìtàn yẹn jẹ́. Wo orí 88 nínú ìwé Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí, tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.

b Ọ̀rọ̀ èdè Hébérù náà Ṣìọ́ọ̀lù fara hàn ní ìgbà márùnlélọ́gọ́ta nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, Bibeli Mimọ sì túmọ̀ rẹ̀ sí “ọ̀run àpáàdì,” “isà òkú,” “ipò òkú,” ibojì, àti “ọ̀gbun.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Jóòbù gbàdúrà pé ká fi òun pa mọ́ sínú ọ̀run àpáàdì

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Gẹ̀hẹ́nà oníná ń ṣàpẹẹrẹ ìparun ayérayé

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

‘Àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò jáde wá’