Pẹpẹ Kan fún Ọlọ́run Tí Kò Lórúkọ
Pẹpẹ Kan fún Ọlọ́run Tí Kò Lórúkọ
ÀPỌ́SÍTÉLÌ Pọ́ọ̀lù ṣèbẹ̀wò sílùú Áténì, nílẹ̀ Gíríìsì ní nǹkan bí ọdún 50 Sànmánì Tiwa. Ó rí pẹpẹ kan níbẹ̀ tí wọ́n yà sọ́tọ̀ fún ọlọ́run àìmọ̀. Ó sì wá mẹ́nu ba ohun tó rí yìí lẹ́yìn náà nígbà tó ń jẹ́rìí kíkúnná nípa Jèhófà.
Nígbà tí Pọ́ọ̀lù bẹ̀rẹ̀ àsọyé rẹ̀ lórí Òkè Máàsì, ìyẹn Áréópágù, ó sọ pé: “Ẹ̀yin ènìyàn Áténì, mo ṣàkíyèsí pé nínú ohun gbogbo, ó jọ pé ẹ kún fún ìbẹ̀rù àwọn ọlọ́run àjúbàfún ju àwọn mìíràn lọ. Fún àpẹẹrẹ, bí mo ti ń kọjá lọ, tí mo sì ń fẹ̀sọ̀ kíyè sí àwọn ohun tí ẹ ń júbà fún, mo tún rí pẹpẹ kan, lórí èyí tí a kọ àkọlé náà ‘Sí Ọlọ́run Àìmọ̀.’ Nítorí náà, ohun tí ẹ ń fún ní ìfọkànsin Ọlọ́run láìmọ̀, èyí ni mo ń kéde fún yín.”—Ìṣe 17:22-31.
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ò tíì mọbi tí pẹpẹ yìí wà nílùú Áténì, irú àwọn pẹpẹ bẹ́ẹ̀ wà káàkiri ilẹ̀ Gíríìsì. Fún àpẹẹrẹ, Pausanias ọmọ Gíríìkì tó gbé ayé ní ọ̀rúndún kejì, tí í ṣe onímọ̀ nípa ilẹ̀ ayé àtàwọn ẹ̀dá inú rẹ̀, sọ̀rọ̀ nípa pẹpẹ “àwọn ọlọ́run Olórúkọ Àìmọ̀” nílùú Phaleron tó wà nítòsí Áténì. (Description of Greece, Attica I, 4) Ìwé kan náà sọ pé nílùú Olympia, “pẹpẹ kan wà fún àwọn ọlọ́run Àìmọ̀.”—Eleia I, XIV, 8.
Nínú ìwé kan tí Philostratus òǹkọ̀wé Gíríìkì nì (tó gbé ayé láti nǹkan bí ọdún 170 sí 245 Sànmánì Tiwa) kọ, tó pe àkọlé rẹ̀ ní The Life of Apollonius of Tyana (VI, III), ó sọ pé nílùú Áténì “wọ́n mọ àwọn pẹpẹ kan láti fi bọlá fáwọn ọlọ́run àìmọ̀ pàápàá.” Àti pé nínú ìwé náà, Lives of Philosophers (1.110), ọ̀gbẹ́ni Diogenes Laertius (tó gbé ayé láti nǹkan bí ọdún 200 sí 250 Sànmánì Tiwa) kọ̀wé pé èèyàn lè rí “àwọn pẹpẹ tí kò lórúkọ” ní ibi púpọ̀ nígboro Áténì.
Àwọn ará Róòmù tún mọ pẹpẹ fáwọn ọlọ́run tí kò lórúkọ. Àwòrán pẹpẹ kan lẹ̀ ń wò níhìn-ín yìí tí wọ́n ti mọ láti nǹkan bí ọ̀rúndún kìíní tàbí ọ̀rúndún kejì ṣáájú Sànmánì Tiwa, tí wọ́n sì ti tọ́jú rẹ̀ sí ibi ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí tí à ń pè ní Palatine Antiquarium nílùú Róòmù, lórílẹ̀-èdè Ítálì. Àkọlé tí wọ́n fi èdè Látìn kọ sára rẹ̀ fi hàn pé wọ́n ya pẹpẹ yìí sí mímọ́ yálà fún “ọlọ́run kan tàbí abo ọlọ́run kan”—èyí jẹ́ gbólóhùn “tó sábà máa ń wà nínú àdúrà tàbí ọ̀rọ̀ ìyàsímímọ́ tí wọ́n máa ń kọ sára àkọlé àti sínú àwọn ìwé ìtàn.”
Di bá a ti ń wí yìí, ọ̀pọ̀ ni kò tíì mọ “Ọlọ́run tí ó dá ayé àti gbogbo ohun tí ó wà nínú rẹ̀.” Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù ṣe sọ fáwọn ará Áténì, Ọlọ́run yìí—Jèhófà—“kò jìnnà sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa.”—Ìṣe 17:24, 27.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 32]
Pẹpẹ: Soprintendenza Archeologica di Roma