Wọ́n Ń bá a Lọ Ní Rírìn Nínú Òtítọ́
Wọ́n Ń bá a Lọ Ní Rírìn Nínú Òtítọ́
“Èmi kò ní ìdí kankan tí ó tóbi ju nǹkan wọ̀nyí lọ fún ṣíṣọpẹ́, pé kí n máa gbọ́ pé àwọn ọmọ mi ń bá a lọ ní rírìn nínú òtítọ́.”—3 Jòhánù 4.
1. Orí kí ni “òtítọ́ ìhìn rere” dá lé?
JÈHÓFÀ ń tẹ́wọ́ gba kìkì àwọn tó ń jọ́sìn rẹ̀ “ní ẹ̀mí àti òtítọ́.” (Jòhánù 4:24) Wọ́n ń ṣègbọràn sí òtítọ́, wọ́n tẹ́wọ́ gba gbogbo ẹ̀kọ́ Kristẹni tá a gbé ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. “Òtítọ́ ìhìn rere” yìí dá lórí Jésù Kristi àti dídá Jèhófà láre gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ nípasẹ̀ Ìjọba náà. (Gálátíà 2:14) Ọlọ́run jẹ́ kí “ìṣiṣẹ́ ìṣìnà” lọ sọ́dọ̀ àwọn tó yàn láti gba èké gbọ́, àmọ́ ìgbàlà sinmi lórí níní ìgbàgbọ́ nínú ìhìn rere àti rírin nínú òtítọ́.—2 Tẹsalóníkà 2:9-12; Éfésù 1:13, 14.
2. Kí ni ohun pàtàkì tí àpọ́sítélì Jòhánù tìtorí rẹ̀ ń dúpẹ́, àjọṣe wo ló sì wà láàárín òun àti Gáyọ́sì?
2 Àwọn olùpòkìkí Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ “alábàáṣiṣẹ́pọ̀ nínú òtítọ́.” Wọ́n di òtítọ́ mú ṣinṣin, wọ́n sì ń rìn nínú rẹ̀ bíi ti àpọ́sítélì Jòhánù àti Gáyọ́sì ọ̀rẹ́ rẹ̀. Gáyọ́sì ni Jòhánù ní lọ́kàn nígbà tó kọ̀wé pé: “Èmi kò ní ìdí kankan tí ó tóbi ju nǹkan wọ̀nyí lọ fún ṣíṣọpẹ́, pé kí n máa gbọ́ pé àwọn ọmọ mi ń bá a lọ ní rírìn nínú òtítọ́.” (3 Jòhánù 3-8) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe bàbá àgbàlagbà náà Jòhánù ló kọ́ Gáyọ́sì lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, síbẹ̀ àgbàlagbà tí àpọ́sítélì yìí jẹ́, bó ṣe jẹ́ Kristẹni tó dàgbà dénú àti ìfẹ́ni bíi ti bàbá tó ní sí i ló fi bójú mu láti ka ọ̀dọ́kùnrin yìí sí ọ̀kan lára àwọn ọmọ Jòhánù nípa tẹ̀mí.
Òtítọ́ àti Ìjọsìn Kristẹni
3. Kí ni ète àti àǹfààní àwọn ìpàdé táwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ṣe?
3 Kí àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ lè kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, wọ́n máa ń pàdé pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìjọ, wọ́n sábà máa ń lo àwọn ilé àdáni. (Róòmù 16:3-5) Wọ́n tipa bẹ́ẹ̀ ń fún ara wọn níṣìírí, wọ́n sì ń ru ara wọn sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà. (Hébérù 10:24, 25) Ohun tí Tertullian (tó gbé ayé ní nǹkan bí ọdún 155 sí 220 Sànmánì Tiwa) kọ nípa àwọn tó pe ara wọn ní Kristẹni lẹ́yìn àwọn àpọ́sítélì ni pé: “A máa ń pàdé pọ̀ láti ka àwọn ìwé Ọlọ́run . . . Àwọn ọ̀rọ̀ mímọ́ wọ̀nyẹn la fi ń fún ìgbàgbọ́ wa lókun, àwọn la fi ń gbé ìrètí wa ró, àwọn la sì fi ń mú kí ìgbọ́kànlé wa dájú.”—Apology, orí 39.
4. Ipa wo ni orin ti kó nínú àwọn ìpàdé Kristẹni?
4 Ó jọ pé orin kíkọ jẹ́ apá kan ìpàdé àwọn Kristẹni ìjímìjí. (Éfésù 5:19; Kólósè 3:16) Ọ̀jọ̀gbọ́n Henry Chadwick kọ̀wé pé Celsus tó jẹ́ aṣelámèyítọ́ ní ọ̀rúndún kejì rí i pé orin táwọn tó pe ara wọn ní Kristẹni ń kọ “dùn gan-an, débi pé ó kórìíra ipa tí orin wọ̀nyẹn ń ní lórí ìmọ̀lára òun.” Chadwick fi kún un pé: “Clement ti Alẹkisáńdíríà ni Kristẹni òǹkọ̀wé àkọ́kọ́ pàá tó jíròrò irú orin tó yẹ káwọn Kristẹni máa kọ. Ó sọ pé kò gbọ́dọ̀ jẹ́ irú orin tó ní í ṣe pẹ̀lú ijó tí ń ru ìfẹ́ ìbálòpọ̀ sókè.” (The Early Church, ojú ìwé 274 sí 275) Gan-an gẹ́gẹ́ bó ṣe hàn gbangba pé àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ máa ń kọrin nígbà tí wọ́n bá pàdé pọ̀, bẹ́ẹ̀ náà làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sábà máa ń kọrin tá a gbé ka Bíbélì, èyí tó ní àwọn ohùn tó ń gbé Ọlọ́run àti Ìjọba náà lárugẹ nínú.
5. (a) Báwo la ṣe ń fúnni ní ìtọ́sọ́nà tẹ̀mí nínú ìjọ Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀? (b) Báwo làwọn Kristẹni tòótọ́ ṣe fi ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nínú Mátíù 23:8, 9 sílò?
5 Nínú àwọn ìjọ Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀, àwọn alábòójútó ló ń fi òtítọ́ kọ́ni, àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ sì máa ń ran àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn lọ́wọ́ lónírúurú ọ̀nà. (Fílípì 1:1) Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso tó gbára lé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ẹ̀mí mímọ́ ló ń fún wọn ní ìtọ́sọ́nà nípa tẹ̀mí. (Ìṣe 15:6, 23-31) Wọn kì í lo orúkọ oyè inú ẹ̀sìn nítorí pé Jésù ti pàṣẹ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Kí a má ṣe pè yín ní Rábì, nítorí ọ̀kan ni olùkọ́ yín, nígbà tí ó jẹ́ pé arákùnrin ni gbogbo yín jẹ́. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ẹ má pe ẹnikẹ́ni ní baba yín lórí ilẹ̀ ayé, nítorí ọ̀kan ni Baba yín, Ẹni ti ọ̀run.” (Mátíù 23:8, 9) Àwọn Kristẹni ìjímìjí àtàwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bára dọ́gba nínú nǹkan wọ̀nyí àti nínú ọ̀pọ̀ nǹkan mìíràn.
A Ṣe Inúnibíni sí Wọn Nítorí Wíwàásù Òtítọ́
6, 7. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìhìn àlàáfíà làwọn Kristẹni ń polongo, kí làwọn èèyàn ṣe sí wọn?
6 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìhìn Ìjọba alálàáfíà làwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ń polongo, síbẹ̀ àwọn èèyàn ṣe inúnibíni sí wọn, àní bí wọ́n ti ṣe sí Jésù. (Jòhánù 15:20; 17:14) Òpìtàn nì, John L. von Mosheim pe àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní ní “àwọn èèyàn tí kì í pani lára, àwọn tí kì í ní èrò búburú lọ́kàn, tí wọn kì í sì í ronú ibi sí orílẹ̀-èdè.” Ọ̀mọ̀wé Mosheim sọ pé ohun tó “mú káwọn ará Róòmù máa bínú sáwọn Kristẹni ni bí ìjọsìn wọn ṣe jẹ́ èyí tó rọrùn, tó sì yàtọ̀ pátápátá sí ààtò ìsìn gbogbo àwọn yòókù.” Ó fi kún un pé: “Wọn kì í rúbọ, wọn ò ní tẹ́ńpìlì, wọn ò ní ère, wọn ò ní aláwo, bẹ́ẹ̀ ni wọn ò ní ẹgbẹ́ àlùfáà; èyí sì tó ohun tí wọ́n fi lè máa bú àwọn Kristẹni pé gbáàtúù aláìmọ̀kan ni wọ́n, torí pé lójú tiwọn, kò sí béèyàn ṣe lè máa sọ pé òun ń ṣẹ̀sìn láìsí nǹkan wọ̀nyí. Nípa bẹ́ẹ̀ àwọn èèyàn kà wọ́n sí ẹni tí kò gbà pé Ọlọ́run wà; ohun tí òfin Róòmù sì sọ ni pé àwọn tí wọ́n bá fi ẹ̀sùn àìgbà-pọ́lọ́run-wà kàn jẹ́ ewu láwùjọ ẹ̀dá.”
7 Àwọn àlùfáà, àwọn agbẹ́gilére, àtàwọn mìíràn tó jẹ́ pé iṣẹ́ tó jẹ mọ́ ìbọ̀rìṣà ni wọ́n ń ṣe jẹun ló máa ń sún àwọn èèyàn láti gbógun ti àwọn Kristẹni, nítorí pé wọn kì í bá wọn lọ́wọ́ sí ìbọ̀rìṣà. (Ìṣe 19:23-40; 1 Kọ́ríńtì 10:14) Tertullian kọ̀wé pé: “Wọ́n ń sọ pé àwọn Kristẹni ló ń fa gbogbo wàhálà tó bá ìlú àti gbogbo àgbákò tó bá àwọn èèyàn. Bí Odò Tiber bá kún bo odi ìlú, bí Odò Náílì kò bá ṣàn kọjá bèbè rẹ̀ kó sì bomi rin oko wọn, bí òjò kò bá rọ̀, tàbí bí ilẹ̀ bá sẹ̀, bí ìyàn bá mú, tàbí bí àjàkálẹ̀ àrùn bá jà, kíá ni wọ́n á figbe ta pé: ‘Ẹ sọ àwọn Kristẹni sẹ́nu kìnnìún!’” Láìfi ohun tó máa tẹ̀yìn rẹ̀ jáde pè, àwọn Kristẹni tòótọ́ ‘yẹra fún àwọn òrìṣà.’—1 Jòhánù 5:21.
Òtítọ́ àti Àwọn Ayẹyẹ Ìsìn
8. Kí nìdí táwọn tó ń rìn nínú òtítọ́ kì í fi í ṣọdún Kérésìmesì?
8 Àwọn tó ń rìn nínú òtítọ́ máa ń yẹra fún àwọn ayẹyẹ tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu nítorí pé ‘ìmọ́lẹ̀ kò ní ìpín kankan pẹ̀lú òkùnkùn.’ (2 Kọ́ríńtì 6:14-18) Bí àpẹẹrẹ, wọn kì í ṣe Kérésìmesì táwọn èèyàn máa ń ṣe ní December 25. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The World Book Encyclopedia sọ pé: “Kò sẹ́ni tó mọ ọjọ́ náà gan-an tá a bí Jésù.” Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Encyclopedia Americana (Ẹ̀dà ti 1956) sọ pé: “Saturnalia, ìyẹn ọdún táwọn ará Róòmù máa ń ṣe ní àárín oṣù December ló jẹ́ àwòkọ́ṣe fún ọ̀pọ̀ àríyá tí wọ́n máa ń ṣe nígbà Kérésìmesì.” Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Cyclopædia ti M’Clintock and Strong, sọ pé: “Ọdún Kérésìmesì kì í ṣe ohun tí Ọlọ́run pa láṣẹ, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ohun tó jọ ọ́ nínú Májẹ̀mú Tuntun.” Ìwé Daily Life in the Time of Jesus pẹ̀lú sọ pé: “Abẹ́lé ni àwọn agbo ẹran . . . máa ń wà nígbà òtútù; kókó yìí nìkan ti tó láti fi mọ̀ pé ọjọ́ tí wọ́n ń ṣe ọdún Kérésìmesì, nígbà òtútù, kò lè tọ̀nà, níwọ̀n bí ìwé Ìhìn Rere ti sọ pé àwọn olùṣọ́ àgùntàn wà ní pápá lákòókò yẹn.”—Lúùkù 2:8-11.
9. Kí nìdí táwọn ìránṣẹ́ Jèhófà nígbà àtijọ́ àti lóde òní kì í fi í ṣe Ọdún Àjíǹde?
9 Ọdún Àjíǹde làwọn èèyàn sọ pé àwọn fi ń ṣayẹyẹ ọjọ́ tá a jí Kristi dìde, àmọ́ àwọn ìsọfúnni tó ṣeé gbára lé fi hàn pé inú ìjọsìn èké ló ti bẹ̀rẹ̀. Ìwé atúmọ̀ èdè náà, The Westminster Dictionary of the Bible sọ pé Ọdún Àjíǹde jẹ́ “ọdún tí wọ́n ń ṣe nígbà ìrúwé láti bọlá fún Teutonic, abo-ọlọ́run ìmọ́lẹ̀ àti ìrúwé tí àwọn ará Jámánì tó tẹ̀ dó sílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ń pè ní Eastre,” tàbí Eostre. Bó ti wù kó rí, ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia Britannica (Ẹ̀dà Kọkànlá) sọ pé: “Kò sí ohunkóhun tó fi hàn pé wọ́n ṣe Ọdún Àjíǹde nínú Májẹ̀mú Tuntun.” Àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ kò ṣe Ọdún Àjíǹde, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í sì í ṣe é lóde òní.
10. Àjọ̀dún wo ni Jésù dá sílẹ̀, àwọn wo ló sì ń ṣe é lọ́nà tó tọ́?
10 Jésù kò sọ pé kí àwọn ọmọlẹ́yìn òun máa ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí òun tàbí ti àjíǹde òun, àmọ́ ó dá Ìṣe Ìrántí ikú ìrúbọ rẹ̀ sílẹ̀. (Róòmù 5:8) Ní tòótọ́, àjọ̀dún kan ṣoṣo tó sọ pé káwọn ọmọ ẹ̀yìn òun máa ṣe nìyẹn. (Lúùkù 22:19, 20) Àjọ̀dún kan náà yìí là ń pè ní Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sì ń ṣe lẹ́ẹ̀kan lọ́dún títí di bí a ti ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí.—1 Kọ́ríńtì 11:20-26.
Òtítọ́ Tá A Kéde Jákèjádò Ayé
11, 12. Báwo làwọn tó ń rìn nínú òtítọ́ ṣe máa ń ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ ìwàásù wọn?
11 Àwọn tó mọ òtítọ́ kà á sí àǹfààní ńlá láti lo àkókò wọn, agbára wọn àti àwọn nǹkan mìíràn tí wọ́n ní fún iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere náà. (Máàkù 13:10) Ọrẹ àtinúwá ni wọ́n fi ń ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ ìwàásù àwọn Kristẹni ìjímìjí. (2 Kọ́ríńtì 8:12; 9:7) Tertullian kọ̀wé pé: “Kódà bí àpótí owó tilẹ̀ wà níbẹ̀, kì í ṣe owó téèyàn ń san kó tó wọlé ló wà nínú rẹ̀, bí ẹni pé ìsìn jẹ́ ọ̀ràn ìṣòwò. Olúkúlùkù ló máa ń mú owó tó mọ níwọ̀nba wá lóṣooṣù—tàbí nígbà tó bá wù ú, àti nígbà tó bá fẹ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀, tí agbára rẹ̀ sì gbé e; nítorí pé kò sẹ́ni tá a fagbára mú; ọrẹ àtinúwá ni.”—Apology, orí 39.
12 Ọrẹ àtinúwá kan náà yìí la fi ń ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ ìwàásù táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe kárí ayé. Yàtọ̀ sáwọn Ẹlẹ́rìí, àwọn tó fẹ́ràn iṣẹ́ náà, tí wọ́n sì lẹ́mìí ìmọrírì kà á sí àǹfààní ńlá láti fi ọrẹ tiwọn ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ yìí. Ìlànà àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ àti tàwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tún bára mu nínú èyí pẹ̀lú.
Òtítọ́ àti Ìwà Èèyàn
13. Nínú ọ̀ràn ìwà híhù, ìmọ̀ràn Pétérù wo làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tẹ̀ lé?
13 Nítorí pé àwọn Kristẹni ìjímìjí rìn nínú òtítọ́, wọ́n ṣègbọràn sí ìmọ̀ràn àpọ́sítélì Pétérù náà pé: “Ẹ tọ́jú ìwà yín kí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, pé, nínú ohun náà tí wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ lòdì sí yín gẹ́gẹ́ bí aṣebi, kí wọ́n lè tipa àwọn iṣẹ́ yín àtàtà tí wọ́n fojú rí, yin Ọlọ́run lógo ní ọjọ́ náà fún àbẹ̀wò rẹ̀.” (1 Pétérù 2:12) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tẹ̀ lé àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn.
14. Ojú wo làwọn Kristẹni fi ń wo eré ìnàjú oníwà pálapàla?
14 Kódà lẹ́yìn tí ìpẹ̀yìndà wọlé, àwọn aláfẹnujẹ́ Kristẹni ṣì ń yẹra fún ìwà pálapàla. W. D. Killen, tó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìtàn ìsìn, kọ̀wé pé: “Ní ọ̀rúndún kejì àti ìkẹta, ńṣe ni èrò máa ń wọ́ ní gbogbo ilé ìṣeré tó wà láwọn ìlú ńláńlá; nítorí pé àwọn òṣèré náà jẹ́ oníwà pálapàla gan-an, ohun tí eré wọ́n wà fún ni títẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn ayé ìgbà yẹn lọ́rùn. . . . Gbogbo Kristẹni tòótọ́ ló kórìíra àwọn ibi irú eré wọ̀nyẹn. . . . Ìwà ìbàjẹ́ tí ń wáyé níbẹ̀ ń kó wọn nírìíra; bíbọ tí wọ́n ń bọ àwọn ọlọ́run àtàwọn abo ọlọ́run abọgibọ̀pẹ̀ níbẹ̀ nígbà gbogbo lòdì pátápátá sí ìgbàgbọ́ wọn.” (The Ancient Church, ojú ìwé 318 sí 319) Àwọn tó jẹ́ ọmọlẹ́yìn tòótọ́ fún Jésù lóde òní náà máa ń yẹra fún eré ìnàjú tí kò dára tó sì kún fún ìwà pálapàla.—Éfésù 5:3-5.
Òtítọ́ àti “Àwọn Aláṣẹ Onípò Gíga”
15, 16. Àwọn wo ni “aláṣẹ onípò gíga,” ojú wo sì làwọn tó ń rìn nínú òtítọ́ fi ń wò wọ́n?
15 Pẹ̀lú gbogbo bí ìwà àwọn Kristẹni ìjímìjí ṣe dára tó, ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn olú ọba Róòmù ló ṣì wọ́n lóye. Òpìtàn E. G. Hardy sọ pé àwọn olú ọba náà kà wọ́n sí “àwọn èèyànkéèyàn tó kàn gba wèrè mẹ́sìn.” Àwọn lẹ́tà tí Gómìnà Pliny Kékeré ti ilẹ̀ Bítíníà àti Olú Ọba Tírájánì ń kọ síra wọn fi hàn pé àwọn aláṣẹ wọ̀nyẹn kò mọ ohun tí ẹ̀sìn Kristẹni dúró fún gan-an. Ojú wo làwọn Kristẹni fi ń wo Ìjọba?
16 Bíi ti àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ìjímìjí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ìtẹríba aláàlà fún àwọn “aláṣẹ onípò gíga.” (Róòmù 13:1-7) Tó bá wá ṣẹlẹ̀ pé ohun táwọn èèyàn fẹ́ kí wọ́n ṣe ta ko ohun tó jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run, ohun tí wọ́n máa sọ ni pé: “Àwa gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.” (Ìṣe 5:29) Ìwé náà, After Jesus—The Triumph of Christianity sọ pé: “Bí àwọn Kristẹni kì í tiẹ̀ jọ́sìn olú ọba, síbẹ̀ wọn kì í ṣe adárútúrútú sílẹ̀. Ìsìn wọn sì rèé, bó tilẹ̀ ṣàjèjì, tó sì máa ń bí àwọn abọ̀rìṣà nínú nígbà mìíràn, kò wu ẹnikẹ́ni léwu ní ilẹ̀ ọba náà.”
17. (a) Ìjọba wo ni àwọn Kristẹni ìjímìjí ṣe alágbàwí rẹ̀? (b) Báwo làwọn ọmọlẹ́yìn tòótọ́ fún Kristi ṣe ń fi ọ̀rọ̀ inú Aísáyà 2:4 sílò nínú ìgbésí ayé wọn?
17 Ìjọba Ọlọ́run làwọn Kristẹni ìjímìjí ń ṣe alágbàwí rẹ̀, àní bí àwọn baba ńlá bí Ábúráhámù, Ísákì, àti Jékọ́bù ṣe lo ìgbàgbọ́ nínú ìlérí ‘ìlú tí Ọlọ́run ṣẹ̀dá rẹ̀.’ (Hébérù 11:8-10) Bíi ti ọ̀gá wọn, àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù “kì í ṣe apá kan ayé.” (Jòhánù 17:14-16) Nígbà tó bá sì kan ọ̀ràn ogun àti gbọ́nmi-si omi-ò-to láàárín àwọn ẹ̀dá ènìyàn, àlàáfíà ni wọ́n ń lépa nípa ‘fífi idà wọn rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀.’ (Aísáyà 2:4) Geoffrey F. Nuttall, tó jẹ́ olùkọ́ nípa ìtàn ṣọ́ọ̀ṣì kíyè sí ìjọra kan tó wúni lórí, ó sì sọ pé: “Ìhà tí àwọn Kristẹni ìjímìjí kọ sí ogun kò yàtọ̀ sí ti àwọn tó pera wọn ní Ẹlẹ́rìí Jèhófà rárá, ìyẹn sì jẹ́ nǹkan ìtìjú fún wa.”
18. Èé ṣe tí kò fí sídìí kankan tó lè mú kí ìjọba èyíkéyìí máa bẹ̀rù àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà?
18 Àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ kì í ṣe ewu fún àwọn olóṣèlú èyíkéyìí, nítorí pé wọn kì í dá sí tọ̀túntòsì, wọ́n sì ń tẹrí ba fún “àwọn aláṣẹ onípò gíga,” bẹ́ẹ̀ náà láwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ọ̀rọ̀ olóòtú nínú ìwé ìròyìn kan ní Àríwá Amẹ́ríkà sọ pé: “Àìgbatẹnirò àti àìfọkàntánni nìkan ló lè jẹ́ ká gbà pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ ewu èyíkéyìí fún ìjọba òṣèlú èyíkéyìí. Wọn kì í ṣe adojú-ìjọba-dé, wọ́n sì jẹ́ olùfẹ́ àlàáfíà gẹ́gẹ́ bí a ti lè retí kí ẹgbẹ́ ìsìn kan jẹ́.” Àwọn aláṣẹ tó jẹ́ olóye mọ̀ pé kò sídìí kankan táwọn fi lè máa bẹ̀rù àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
19. Ní ti ọ̀ràn owó orí, kí la lè sọ nípa àwọn Kristẹni ìjímìjí àtàwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà?
19 Ọ̀nà kan táwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ gbà tẹrí ba fún “àwọn aláṣẹ onípò gíga” ni pé wọ́n ń san owó orí wọn. Nígbà tí Justin Martyr ń kọ̀wé sí Olú Ọba Róòmù nì, Antoninus Pius (ọdún 138 sí 161 Sànmánì Tiwa), ó sọ pé àwọn Kristẹni ń san owó orí wọn “láìfi falẹ̀ rárá ju gbogbo èèyàn lọ.” (First Apology, orí 17) Tertullian sì sọ fún àwọn alákòóso ará Róòmù pé ó yẹ káwọn tó ń bá wọn gbowó orí máa “dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn Kristẹni gan-an ni” nítorí bí wọ́n ṣe ń san owó orí wọn tọkàntọkàn. (Apology, orí 42) Àwọn Kristẹni jàǹfààní láti inú Pax Romana, ìyẹn Àlàáfíà Róòmù, nítorí òfin àti bí ìlú ṣe wà ní àlàáfíà, ọ̀nà tó dára, àti ìrìn àjò ojú omi tí kò fi bẹ́ẹ̀ léwu nínú. Nítorí pé wọ́n mọ ojúṣe wọn láwùjọ, wọ́n kọbi ara sí ọ̀rọ̀ Jésù pé: “Ẹ san àwọn ohun ti Késárì padà fún Késárì, ṣùgbọ́n àwọn ohun ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.” (Máàkù 12:17) Àwọn èèyàn Jèhófà ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yìí lónìí, àwọn èèyàn sì ti gbóríyìn fún wọn nítorí jíjẹ́ tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́, nínú irú nǹkan bíi sísan owó orí.—Hébérù 13:18.
Ìdè Tí Ń Soni Pọ̀ Ni Òtítọ́ Jẹ́
20, 21. Ní ti ẹgbẹ́ àwọn ará tó jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà, kí ló jẹ́ òtítọ́ nípa àwọn Kristẹni ìjímìjí àti àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà òde òní?
20 Nítorí pé àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ rìn nínú òtítọ́, wọ́n wà níṣọ̀kan nínú ẹgbẹ́ àwọn ará tó jẹ́ ẹlẹ́mìí àlááfíà, bẹ́ẹ̀ náà làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lóde òní. (Ìṣe 10:34, 35) Lẹ́tà kan tí wọ́n tẹ̀ sínú ìwé ìròyìn The Moscow Times sọ pé: “[Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà] la mọ̀ bí ẹní mowó pé wọ́n ṣèèyàn, wọ́n jẹ́ onínúure, wọ́n sì jẹ́ ọlọ́kàntútù àti adùn-únbárìn, wọn kì í fa wàhálà fún àwọn ẹlòmíràn, gbogbo ìgbà ni wọ́n sì máa ń wá àlàáfíà nínú àjọṣe wọn pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. . . . Kò sí ẹni tí ń gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, kò sí ọ̀mùtí, tàbí ajoògùnyó láàárín wọn. Ìdí tó sì fi rí bẹ́ẹ̀ kò ju pé: “Wọ́n jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wọn tí a gbé karí Bíbélì darí gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe tàbí ohun tí wọ́n ń sọ. Bí gbogbo ẹni tó wà láyé bá lè gbìyànjú láti gbé níbàámu pẹ̀lú Bíbélì báwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń ṣe, ayé búburú tá a wà yìí yóò yí padà pátápátá.”
21 Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopedia of Early Christianity sọ pé: “Ìjọ ìjímìjí ka ara rẹ̀ sí ìdílé tuntun kan nínú èyí tí àwọn tó ti fìgbà kan jẹ́ ọ̀tá ara wọn, ìyẹn àwọn Júù àtàwọn Kèfèrí, ti lè gbé pà pọ̀ ní àlàáfíà.” Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà náà jẹ́ ẹgbẹ́ àwọn ará kárí ayé tó nífẹ̀ẹ́ àlàáfíà—ọmọ ẹgbẹ́ ayé tuntun ni wọ́n lóòótọ́. (Éfésù 2:11-18; 1 Pétérù 5:9; 2 Pétérù 3:13) Nígbà tí ọ̀gá àwọn olùṣọ́ Ibi Ìpàtẹ Ọjà ti ìlú Pretoria ní Gúúsù Áfíríkà rí i bí àwọn Ẹlẹ́rìí láti inú gbogbo ẹ̀yà ṣe kóra jọ ní àlàáfíà nígbà tí wọ́n wá síbi àpéjọ wọn, ó sọ pé: “Ọmọlúwàbí ni gbogbo wọn, wọ́n sì ń bára wọn sọ̀rọ̀ lọ́nà tó dáa, ìṣarasíhùwà wọn láwọn ọjọ́ díẹ̀ tó kọjá yìí—gbogbo rẹ̀ jẹ́rìí sí irú èèyàn àtàtà táwọn ọmọ ìjọ yín jẹ́, àti pé gbogbo wọn ń gbé pọ̀ bí ìdílé aláyọ̀ kan ṣoṣo.”
A Bù Kún Wọn Nítorí Pé Wọ́n Ń Fi Òtítọ́ Kọ́ni
22. Kí ló ti ń ṣẹlẹ̀ nítorí pé àwọn Kristẹni ń fi òtítọ́ hàn?
22 Pọ́ọ̀lù àtàwọn Kristẹni yòókù ‘fi òtítọ́ hàn’ nípasẹ̀ ìwà wọn àti iṣẹ́ ìwàásù wọn. (2 Kọ́ríńtì 4:2) Ǹjẹ́ o ò gbà pé ohun kan náà ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe àti pé wọ́n ń fi òtítọ́ kọ́ gbogbo orílẹ̀-èdè? Àwọn èèyàn jákèjádò ayé ń tẹ́wọ́ gba ìjọsìn tòótọ́, wọ́n sì ń wọ́ tìrítìrí lọ sí ‘òkè ńlá ilé Jèhófà’ ní iye tó túbọ̀ ń pọ̀ sí i. (Aísáyà 2:2, 3) Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ló ń ṣe batisí lọ́dọọdún láti fi ẹ̀rí hàn pé wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run, èyí sì ń mú kí a dá ọ̀pọ̀ ìjọ tuntun sílẹ̀.
23. Ojú wo lo fi ń wo àwọn tó ń fi òtítọ́ kọ́ gbogbo orílẹ̀-èdè?
23 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ipò àwọn èèyàn Jèhófà yàtọ̀ síra látilẹ̀wá, síbẹ̀ wọ́n wà níṣọ̀kan nínú ìjọsìn tòótọ́. Ìfẹ́ tí wọ́n ń fi hàn la fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn Jésù ni wọ́n. (Jòhánù 13:35) Ǹjẹ́ o ò rí i pé ‘Ọlọ́run wà láàárín wọn ní ti tòótọ́’? (1 Kọ́ríńtì 14:25) Ṣé o ti dara pọ̀ mọ́ àwọn tó ń fi òtítọ́ kọ́ gbogbo orílẹ̀-èdè? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, ǹjẹ́ kí o máa fi ìmọrírì hàn fún òtítọ́, kí o sì láǹfààní láti rìn nínú rẹ̀ títí láé.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Kí làwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ àtàwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi jọra nínú ọ̀nà tí wọ́n gbà ń jọ́sìn?
• Àjọ̀dún kan ṣoṣo wo làwọn tó ń rìn nínú òtítọ́ máa ń ṣe?
• Àwọn wo ni “aláṣẹ onípò gíga,” ojú wo làwọn Kristẹni sì fi ń wò wọ́n?
• Báwo ni òtítọ́ ṣe jẹ́ ìdè tí ń soni pọ̀?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Àwọn ìpàdé Kristẹni máa ń jẹ́ ìbùkún fáwọn tó ń rìn nínú òtítọ́
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Jésù pàṣẹ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa ṣe Ìṣe Ìrántí ikú ìrúbọ òun
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń bọ̀wọ̀ fún “àwọn aláṣẹ onípò gíga” bí àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ti ṣe