“Àwọn Ohun Ọlá Ńlá Ọlọ́run” Ń ru Wá Sókè
“Àwọn Ohun Ọlá Ńlá Ọlọ́run” Ń ru Wá Sókè
“Àwa gbọ́ wọn tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ ní ahọ́n wa nípa àwọn ohun ọlá ńlá Ọlọ́run.” —Ìṣe 2:11.
1, 2. Kí ni ohun àrà tó wáyé ní Jerúsálẹ́mù ní ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa?
LÁÀÁRỌ̀ ọjọ́ kan, tí ìgbà ìrúwé ń parí lọ lọ́dún 33 Sànmánì Tiwa, àwùjọ àwọn ọkùnrin àtàwọn obìnrin kan, ìyẹn àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi tí wọ́n kóra jọ sí ilé àdáni kan ní Jerúsálẹ́mù, rí ohun àrà kan. “Lójijì, ariwo kan dún láti ọ̀run gan-an gẹ́gẹ́ bí ti atẹ́gùn líle tí ń rọ́ yìì, ó sì kún inú gbogbo ilé tí wọ́n jókòó sí. Àwọn ahọ́n bí ti iná sì di rírí fún wọn, . . . , gbogbo wọ́n sì wá kún fún ẹ̀mí mímọ́, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fi onírúurú ahọ́n àjèjì sọ̀rọ̀.”—Ìṣe 2:2-4, 15.
2 Ọ̀pọ̀ èrò pé jọ síwájú ilé náà. Lára àwọn tó pé jọ ni àwọn Júù tá a bí sí ìdálẹ̀, tí wọ́n jẹ́ “àwọn ènìyàn tí ó ní ìfọkànsìn,” tí wọ́n wá ṣe àjọyọ̀ Pẹ́ńtíkọ́sì ní Jerúsálẹ́mù. Háà ṣe wọ́n, torí pé kálukú wọn ń gbọ́ tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn ń fi èdè ìbílẹ̀ olúkúlùkù wọn sọ̀rọ̀ “nípa àwọn ohun ọlá ńlá Ọlọ́run.” Báwo lèyí ṣe ṣeé ṣe, nígbà tó jẹ́ pé ará Gálílì ni gbogbo àwọn tí ń sọ̀rọ̀?—Ìṣe 2:5-8, 11.
3. Kí ni ọ̀rọ̀ tí àpọ́sítélì Pétérù sọ fún ogunlọ́gọ̀ tó pé jọ nígbà Pẹ́ńtíkọ́sì?
3 Àpọ́sítélì Pétérù jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ará Gálílì yẹn. Ó ṣàlàyé pé níwọ̀nba ọ̀sẹ̀ díẹ̀ sígbà yẹn làwọn olubi èèyàn pa Jésù Kristi. Àmọ́ Ọlọ́run jí Ọmọ rẹ̀ dìde kúrò nínú òkú. Lẹ́yìn ìgbà yẹn, Jésù fara han ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, títí kan Pétérù àtàwọn mìíràn tó wà níbẹ̀ yẹn. Kìkì ọjọ́ mẹ́wàá ṣáájú ìgbà yẹn ni Jésù gòkè re ọ̀run. Òun ló tú ẹ̀mí mímọ́ sórí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ yìí kan àwọn tó wá ṣe àjọyọ̀ Pẹ́ńtíkọ́sì? Bẹ́ẹ̀ ni, ó kàn wọ́n. Ikú Jésù ló ṣí ọ̀nà sílẹ̀ láti rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ wọn gbà àti láti rí “ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ ẹ̀mí mímọ́” gbà, bí wọ́n bá gba Jésù gbọ́. (Ìṣe 2:22-24, 32, 33, 38) Kí wá ni àwọn èrò ìwòran ṣe nígbà tí wọ́n gbọ́ “àwọn ohun ọlá ńlá Ọlọ́run”? Báwo sì ni ìtàn yìí ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti fojú ṣùnnùkùn wo iṣẹ́ ìsìn tiwa sí Jèhófà?
Ọ̀rọ̀ Náà Gbún Wọn Ní Kẹ́sẹ́!
4. Àsọtẹ́lẹ̀ wo tí Jóẹ́lì sọ ló nímùúṣẹ ní ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa?
4 Gbàrà táwọn ọmọlẹ́yìn ní Jerúsálẹ́mù rí ẹ̀mí mímọ́ gbà ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí wàásù ìhìn rere ìgbàlà fáwọn ẹlòmíì. Wọ́n ti ọ̀dọ̀ ogunlọ́gọ̀ tó kóra jọ ní àárọ̀ ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì yẹn bẹ̀rẹ̀. Ìwàásù wọn jẹ́ ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ pàtàkì kan tí Jóẹ́lì ọmọ Pétúélì kọ sílẹ̀ ní ọ̀rúndún mẹ́jọ ṣáájú ìgbà yẹn, pé: “Èmi yóò tú ẹ̀mí mi jáde sára gbogbo onírúurú ẹran ara, àwọn ọmọkùnrin yín àti àwọn ọmọbìnrin yín yóò sì máa sọ tẹ́lẹ̀ dájúdájú. Ní ti àwọn àgbà ọkùnrin yín, wọn yóò máa lá àlá. Ní ti àwọn ọ̀dọ́kùnrin yín, wọn yóò máa rí ìran. Èmi yóò sì tú ẹ̀mí mi jáde àní sára àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti sára àwọn ìránṣẹ́bìnrin pàápàá ní ọjọ́ wọnnì . . . kí ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù ti Jèhófà tó dé.”—Jóẹ́lì 1:1; 2:28, 29, 31; Ìṣe 2:17, 18, 20.
5. Lọ́nà wo làwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní gbà sọ tẹ́lẹ̀? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
5 Ṣé ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé Ọlọ́run máa sọ gbogbo àwọn ènìyàn kan, lọ́kùnrin àti lóbìnrin di wòlíì, gẹ́gẹ́ bó ṣe yan Dáfídì, Jóẹ́lì àti Dèbórà, kí ó sì gbẹnu wọn sọ àwọn ohun tí ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀? Rárá o. Àwọn Kristẹni ‘ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin, ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin’ yóò máa sọ tẹ́lẹ̀ ní ti pé, ẹ̀mí Jèhófà yóò sún wọn láti máa polongo “àwọn ohun ọlá ńlá” tí Jèhófà ti ṣe àti èyí tí yóò ṣe lọ́jọ́ iwájú. Ìyẹn ni pé wọ́n á jẹ́ agbẹnusọ fún Ọ̀gá Ògo. a Àmọ́ o, báwo lọ̀rọ̀ yìí ṣe rí lára ogunlọ́gọ̀ náà?—Hébérù 1:1, 2.
6. Nígbà tí ogunlọ́gọ̀ náà gbọ́ ọ̀rọ̀ Pétérù, ìgbésẹ̀ wo ni ọ̀pọ̀ nínú wọ́n gbé?
6 Lẹ́yìn tí ogunlọ́gọ̀ náà gbọ́ àlàyé Pétérù, ọ̀pọ̀ nínú wọn ló gbé ìgbésẹ̀. Wọ́n “fi tọkàntọkàn gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ . . . a sì batisí” wọn, “ní ọjọ́ yẹn nǹkan bí ẹgbẹ̀ẹ́dógún ọkàn ni a sì fi kún wọn.” (Ìṣe 2:41) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Júù àbínibí àti Júù aláwọ̀ṣe ni wọ́n, wọ́n ti ní ìmọ̀ tó ṣe kókó nípa Ìwé Mímọ́. Ìmọ̀ yẹn, pa pọ̀ pẹ̀lú ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nínú ohun tí wọ́n gbọ́ lẹ́nu Pétérù, ló jẹ́ kó ṣeé ṣe láti batisí wọn “ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́.” (Mátíù 28:19) Lẹ́yìn ìbatisí wọn, “wọ́n . . . ń bá a lọ ní fífi ara wọn fún ẹ̀kọ́ àwọn àpọ́sítélì.” Pẹ̀lúpẹ̀lù, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà. Kódà, “láti ọjọ́ dé ọjọ́ ni wọ́n sì ń pésẹ̀ nígbà gbogbo sí tẹ́ńpìlì pẹ̀lú ìfìmọ̀ṣọ̀kan, . . . wọ́n ń yin Ọlọ́run, wọ́n sì ń rí ojú rere lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn.” Ìyọrísí iṣẹ́ ìjẹ́rìí yìí ni pé “Jèhófà ń bá a lọ láti mú àwọn tí à ń gbà là dara pọ̀ mọ́ wọn lójoojúmọ́.” (Ìṣe 2:42, 46, 47) A bẹ̀rẹ̀ sí dá àwọn ìjọ Kristẹni sílẹ̀ lọ́nà yíyára kánkán ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀ tí àwọn onígbàgbọ́ tuntun wọ̀nyí ń gbé. Láìsí àní-àní, ó kéré tán ọ̀kan lára ohun tó mú ìbísí wá ni ìtara tí wọ́n fi wàásù “ìhìn rere” náà nígbà tí wọ́n padà délé.—Kólósè 1:23.
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ń Sa Agbára
7. (a) Kí ló ń fa àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè wá sínú ètò Jèhófà lónìí? (b) Kí làwọn ohun tó o rí tó fi hàn pé ìbísí púpọ̀ ṣì ń bẹ níwájú ní pápá kárí ayé àti lágbègbè rẹ? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
7 Àwọn tó fẹ́ di ìránṣẹ́ Ọlọ́run lóde òní ńkọ́? Ó pọn dandan kí àwọn náà fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Bí wọ́n ti ń ṣe èyí, wọ́n á wá mọ̀ pé Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run “aláàánú àti olóore ọ̀fẹ́, [tí] ó ń lọ́ra láti bínú, [tí] ó sì pọ̀ yanturu ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti òtítọ́.” (Ẹ́kísódù 34:6; Ìṣe 13:48) Wọ́n á wá mọ̀ nípa ìpèsè aláàánú tí Jèhófà ṣe láti rà wá padà nípasẹ̀ Jésù Kristi, tó jẹ́ pé ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ tá a ta sílẹ̀ lè wẹ̀ wọ́n mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀. (1 Jòhánù 1:7) Inú wọ́n tún dùn láti mọ̀ nípa ète Ọlọ́run nípa “àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo.” (Ìṣe 24:15) Ìfẹ́ fún ẹni tó jẹ́ Orísun “àwọn ohun ọlá ńlá” wọ̀nyí kún inú ọkàn wọn, èyí sì ń sún wọn láti wàásù òtítọ́ ṣíṣeyebíye wọ̀nyí. Wọ́n á wá ya ara wọn sí mímọ́, wọ́n á ṣe ìrìbọmi gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Ọlọ́run, wọ́n á sì máa “pọ̀ sí i nínú ìmọ̀ pípéye nípa Ọlọ́run.” b—Kólósè 1:10b; 2 Kọ́ríńtì 5:14.
8-10. (a) Báwo ni ìrírí Kristẹni obìnrin kan ṣe fi hàn pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run “ń sa agbára”? (b) Kí ni ìrírí yìí kọ́ ẹ nípa Jèhófà àti bó ṣe ń bá àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lò? (Ẹ́kísódù 4:12)
8 Ìmọ̀ táwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ń gbà nípasẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wọn kì í ṣe oréfèé. Irú ìmọ̀ bẹ́ẹ̀ ń ru wọ́n lọ́kàn sókè, ó ń yí wọn lérò padà, ó sì ti di apá kan ara wọn. (Hébérù 4:12) Bí àpẹẹrẹ, iṣẹ́ títọ́jú àwọn arúgbó ni obìnrin kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Camille ń ṣe. Ọ̀kan lára àwọn tó ń tọ́jú ni Martha, tí í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Níwọ̀n bí àrùn ọpọlọ ti ń da Martha láàmú, ó ń fẹ́ àbójútó nígbà gbogbo. Wọ́n ní láti máa rán an létí láti jẹun—kódà wọ́n tún ń rán an létí láti gbé oúnjẹ tó fi sẹ́nu mì. Àmọ́, ohun kan wà tí kò lè pa rẹ́ lọ́kàn Martha, gẹ́gẹ́ bí a ó ti rí i.
9 Lọ́jọ́ kan, Martha rí Camille tó ń sunkún nítorí ìṣòro kan tó bà á nínú jẹ́. Martha gbá Camille mọ́ra, ó ní kí ó jẹ́ kí òun kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àmọ́ ṣé ẹni tó wà nírú ipò tí Martha wà yìí lè darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? Bẹ́ẹ̀ ni o! Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Martha kò rántí ọ̀pọ̀ nǹkan mọ́, síbẹ̀ kò gbàgbé Ọlọ́run rẹ̀ atóbilọ́lá; bẹ́ẹ̀ ni kò gbàgbé àwọn òtítọ́ ṣíṣeyebíye tó kọ́ nínú Bíbélì. Nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, Martha á ní kí Camille ka ìpínrọ̀ kọ̀ọ̀kan, kí ó ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a tọ́ka sí, kí ó ka ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ ìwé, kí ó sì wá dáhùn rẹ̀. Èyí ń bá a lọ bẹ́ẹ̀ fún sáà kan, Camille sì tẹ̀ síwájú nínú ìmọ̀ Bíbélì, láìfi ìṣòro Martha pè. Martha rí i pé ó pọn dandan kí Camille máa bá àwọn èèyàn tó ní ìfẹ́ sí sísin Ọlọ́run kẹ́gbẹ́. Fún ìdí yìí, ó fún akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ní aṣọ àti bàtà, kí Camille lè rí aṣọ tó bójú mu wọ̀ nígbà tó bá máa kọ́kọ́ lọ ṣèpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba.
10 Ìfẹ́, àpẹẹrẹ rere àti ìgbàgbọ́ tí Martha ní wọ Camille lọ́kàn ṣinṣin. Ó pinnu pé ohun tí Martha ń gbìyànjú láti fi kọ́ òun látinú Bíbélì ṣe pàtàkì gan-an, nítorí pé Martha ti fẹ́rẹ̀ẹ́ gbàgbé gbogbo nǹkan tán, àfi ohun tó kọ́ nínú Ìwé Mímọ́. Nígbà tó yá, tí iṣẹ́ gbé Camille lọ sí ilé ìtọ́jú mìíràn, ó rí i pé àkókò tó láti gbé ìgbésẹ̀. Gbàrà tó débẹ̀ ló lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba, ó wọ aṣọ àti bàtà tí Martha fún un, ó sì sọ pé kí wọ́n wá máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Camille tẹ̀ síwájú láìsọsẹ̀, ó sì ṣèrìbọmi.
A Ru Wá Sókè Láti Rọ̀ Mọ́ Ìlànà Jèhófà
11. Láfikún sí jíjẹ́ onítara nínú iṣẹ́ ìwàásù náà, báwo la ṣe lè fi hàn pé ìhìn Ìjọba náà ń ru wá sókè?
11 Lónìí, ó lé ní mílíọ̀nù mẹ́fà Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ń wàásù “ìhìn rere ìjọba” náà kárí ayé, gẹ́gẹ́ bí Martha àti Camille ti ń ṣe báyìí. (Mátíù 24:14; 28:19, 20) Bíi ti àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní, “àwọn ohun ọlá ńlá Ọlọ́run” ń wú wọn lórí gan-an. Wọ́n mọrírì àǹfààní tí wọ́n ní láti máa jẹ́ orúkọ mọ́ Jèhófà àti pé ó ti tú ẹ̀mí rẹ̀ sórí wọn. Abájọ tí wọ́n fi ń sa gbogbo ipá wọn láti “máa rìn lọ́nà tí ó yẹ Jèhófà fún ète wíwù ú ní kíkún,” tí wọ́n ń tẹ̀ lé ìlànà rẹ̀ nínú gbogbo apá ìgbésí ayé wọn. Ọ̀kan lára apá tí wọ́n ti ń tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run wé mọ́ ọ̀ràn ìwọṣọ àti ìmúra.—Kólósè 1:10a; Títù 2:10.
12. Ìmọ̀ràn pàtó wo lórí ọ̀ràn ìwọṣọ àti ìmúra la rí nínú 1 Tímótì 2:9, 10?
12 Bẹ́ẹ̀ ni o, Jèhófà ní ìlànà tó fẹ́ ká máa tẹ̀ lé nínú ọ̀ràn ìrísí. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tọ́ka sí díẹ̀ lára àwọn ìlànà Ọlọ́run nínú ọ̀ràn yìí. Ó sọ pé: “Mo ní ìfẹ́-ọkàn pé kí àwọn obìnrin máa fi aṣọ tí ó wà létòletò ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́, pẹ̀lú ìmẹ̀tọ́mọ̀wà àti ìyèkooro èrò inú, kì í ṣe pẹ̀lú àwọn àrà irun dídì àti wúrà tàbí péálì tàbí aṣọ àrà olówó ńlá gan-an, ṣùgbọ́n lọ́nà tí ó yẹ àwọn obìnrin tí ó jẹ́wọ́ gbangba pé wọn ń fi ọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run, èyíinì ni, nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ rere.” c Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ nínú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí?—1 Tímótì 2:9, 10.
13. (a) Kí ni “aṣọ tí ó wà létòletò” túmọ̀ sí? (b) Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ìlànà Jèhófà kò nira jù láti tẹ̀ lé?
13 Ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù fi hàn pé àwọn Kristẹni ní láti “máa fi aṣọ tí ó wà létòletò ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́.” Wọn ò gbọ́dọ̀ rí jáujàu, wúruwùru, tàbí jákujàku. Gbogbo èèyàn, kódà àwọn tí kò rí jájẹ pàápàá, ló lè pa ìlànà tí kò nira yìí mọ́ nípa rírí i dájú pé aṣọ wọ́n mọ́ tónítóní, ó sì ṣeé rí mọ́ni. Bí àpẹẹrẹ, ọdọọdún làwọn Ẹlẹ́rìí lórílẹ̀-èdè kan ní Gúúsù Amẹ́ríkà ń rin ọ̀pọ̀ kìlómítà gba inú ẹgàn kọjá, tí wọ́n á tún fi ọkọ̀ ọ̀pẹẹrẹ rìnrìn àjò fún ọ̀pọ̀ wákàtí kí wọ́n bàa lè wá sí àpéjọ àgbègbè. Bí wọ́n ṣe wà lẹ́nu ìrìn àjò náà, nígbà míì àwọn kan lè já sínú odò tàbí kí nǹkan kan látinú igbó kọ́ wọn láṣọ kí ó sì fà á ya. Nígbà tí wọ́n bá fi máa dé ibi tí wọ́n ti fẹ́ lọ ṣe àpéjọ, wọ́n á wá rí wúruwùru. Ìdí nìyẹn tí wọ́n á fi wá àyè tún àwọn bọ́tìnì tó ti já so, tí wọ́n á tún síìpù aṣọ wọn ṣe, tí wọ́n á fọ aṣọ tí wọ́n fẹ́ lò ní àpéjọ náà, wọ́n á sì lọ̀ ọ́. Wọ́n mọrírì pípè tí Jèhófà pè wọ́n wá jẹun lórí tábìlì rẹ̀, ìdí nìyẹn tí wọn fi fẹ́ múra lọ́nà tó bójú mu.
14. (a) Kí ló túmọ̀ sí láti múra pẹ̀lú “ìmẹ̀tọ́mọ̀wà àti ìyèkooro èrò inú”? (b) Kí ni mímúra lọ́nà tí ń fi hàn pé à “ń fi ọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run” wé mọ́?
14 Pọ́ọ̀lù tún sọ pé ó yẹ ká múra “pẹ̀lú ìmẹ̀tọ́mọ̀wà àti ìyèkooro èrò inú.” Èyí túmọ̀ sí pé kò yẹ ká múra lọ́nà ṣekárími, tàbí bí ewèlè, tàbí ká múra lọ́nà tí ń ru ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sókè, tàbí ká wọ aṣọ tí ń fi ibi kọ́lọ́fín ara hàn, tàbí ká múra bíi sóòyòyò. Láfikún sí i, ó yẹ ká máa múra lọ́nà tí “ń fi ọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run” hàn. Ǹjẹ́ ìyẹn ò gbèrò? Kì í ṣọ̀ràn mímúra lọ́nà tó bójú mu nígbà tá a bá ń bọ̀ nípàdé ìjọ nìkan ni, ká sì wá di aláìbìkítà nípa ìmúra wa láwọn ìgbà míì. Ó yẹ kí ìrísí wa máa fi hàn pé olùfọkànsìn àti ẹni iyì ni wá nígbà gbogbo. Kristẹni àti òjíṣẹ́ sáà ni wá ní gbogbo wákàtí ọjọ́. A mọ̀ pé ó yẹ kí aṣọ iṣẹ́ àti aṣọ iléèwé wa bá ohun tí à ń lò wọ́n fún mu. Síbẹ̀síbẹ̀, ó yẹ kí ìmúra wa bójú mu, kí ó sì buyì kúnni. Bó bá jẹ́ ìgbà gbogbo ni ìmúra wa ń fi hàn pé a gba Ọlọ́run gbọ́, a ò ní lọ́ tìkọ̀ nígbàkigbà láti jẹ́rìí lọ́nà àìjẹ́ bí àṣà, torí pé ìrísí wa kò ní tì wá lójú.—1 Pétérù 3:15.
‘Ẹ Má Ṣe Nífẹ̀ẹ́ Ayé’
15, 16. (a) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká yẹra fún fífarawé ayé nínú ọ̀nà ìwọṣọ àti ìmúra wa? (1 Jòhánù 5:19) (b) Kí nìdí tó fi bọ́gbọ́n mu pé ká yẹra fún ṣíṣe oge àṣejù nínú ọ̀nà ìwọṣọ àti ìmúra wa?
15 Ìmọ̀ràn tó wà nínú 1 Jòhánù 2:15, 16 tún tọ́ wa sọ́nà nínú ọ̀ràn ìwọṣọ àti ìmúra wa. Ó kà pé: “Ẹ má ṣe máa nífẹ̀ẹ́ yálà ayé tàbí àwọn ohun tí ń bẹ nínú ayé. Bí ẹnikẹ́ni bá nífẹ̀ẹ́ ayé, ìfẹ́ fún Baba kò sí nínú rẹ̀; nítorí ohun gbogbo tí ń bẹ nínú ayé—ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú àti fífi àlùmọ́ọ́nì ìgbésí ayé ẹni hàn sóde lọ́nà ṣekárími—kò pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Baba, ṣùgbọ́n ó pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ ayé.”
16 Ìmọ̀ràn yìí mà kúkú bákòókò mu o! Lóde òní tó jẹ́ pé ẹ̀mí ṣe ohun tẹ́gbẹ́ ń ṣe ló layé, a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ayé yìí pàṣẹ bí a ó ṣe múra fún wa. Oríṣiríṣi àṣà ìwọṣọ àti ìmúra tí kò bójú mu ló ti dóde lẹ́nu àwọn ọdún àìpẹ́ yìí. Kódà àwọn Kristẹni kò lè gbára lé ìlànà táwọn èèyàn ayé gbé kalẹ̀ nípa irú aṣọ tó yẹ káwọn alákọ̀wé máa wọ̀ lọ síbi iṣẹ́ mọ́. Èyí tún jẹ́ ìdí mìíràn tó fi yẹ ká wà lójúfò, ká “jáwọ́ nínú dídáṣà ní àfarawé ètò àwọn nǹkan yìí,” láti lè máa gbé níbàámu pẹ̀lú àwọn ìlànà Ọlọ́run, ká sì tipa báyìí máa “ṣe ẹ̀kọ́ Olùgbàlà wa, Ọlọ́run, lọ́ṣọ̀ọ́ nínú ohun gbogbo.”—Róòmù 12:2; Títù 2:10.
17. (a) Àwọn ìbéèrè wo la lè gbé yẹ̀ wò nígbà tá a bá fẹ́ lọ ra aṣọ tàbí tá a fẹ́ yan bá a ṣe fẹ́ kí rírán aṣọ kan rí? (b) Kí nìdí tó fi yẹ kí àwọn olórí ìdílé kíyè sí ìmúra àwọn tó wà nínú ìdílé wọn?
17 Kó o tó pinnu pé o fẹ́ ra aṣọ kan, á dáa kó o bí ara rẹ pé: ‘Kí ló dé táṣọ yìí fi wù mí? Ṣé gbajúmọ̀ eléré tí mo gba tiẹ̀ ló ń wọ̀ ọ́? Ṣé aṣọ yìí kì í ṣe aṣọ àwọn ẹgbẹ́ ọmọọ̀ta kan tàbí ti ẹgbẹ́ kan tí ń dá ẹ̀mí jẹ́-n-ṣe-tèmi àti ẹ̀mí ọ̀tẹ̀ sílẹ̀?’ Ó yẹ ká wo aṣọ náà, ká tún un wò dáadáa. Bó bá jẹ́ ẹ̀wù tàbí síkẹ́ẹ̀tì ni, ṣé ó balẹ̀ dáadáa? Rírán rẹ̀ ńkọ́? Ṣé aṣọ náà wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì, ṣé ó bójú mu, ṣé ó sì buyì kúnni, tàbí ṣé ó fúnni pinpin, ṣé ó ń ru ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sókè, tàbí ṣé ó rí wúruwùru? Bi ara rẹ pé, ‘Ṣé mi ò ní mú àwọn èèyàn kọsẹ̀ bí mo bá wọ aṣọ yìí?’ (2 Kọ́ríńtì 6:3, 4) Kí nìdí tó fi yẹ ká ronú lórí ìyẹn? Torí Bíbélì sọ pé: “Kristi pàápàá kò ṣe bí ó ti wu ara rẹ̀.” (Róòmù 15:3) Àwọn Kristẹni olórí ìdílé gbọ́dọ̀ kíyè sí ìmúra àwọn tó wà nínú ìdílé wọn. Ó yẹ kí àwọn olórí ìdílé ṣe tán láti pèsè ìmọ̀ràn onífẹ̀ẹ́ tó sojú abẹ níkòó nígbà tó bá yẹ bẹ́ẹ̀, láti fi hàn pé àwọn bọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run ológo tí wọ́n ń sìn.—Jákọ́bù 3:13.
18. Kí ni yóò jẹ́ kí o pe àfiyèsí pàtàkì sí ìwọṣọ àti ìmúra rẹ?
18 Jèhófà, ọ̀gá ògo, ẹni mímọ́ jù lọ, ló fi iṣẹ́ tí à ń jẹ́ rán wa. (Aísáyà 6:3) Bíbélì rọ̀ wá pé ká máa fara wé e “gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ tí í ṣe olùfẹ́ ọ̀wọ́n.” (Éfésù 5:1) Ìwọṣọ àti ìmúra wa lè fògo fún Baba wa ọ̀run tàbí kí ó tàbùkù rẹ̀. Ó dájú pé ńṣe la fẹ́ mú un lọ́kàn yọ̀!—Òwe 27:11.
19. Àwọn àǹfààní wo ló ń wá látinú sísọ “àwọn ohun ọlá ńlá Ọlọ́run” di mímọ̀ fáwọn ẹlòmíràn?
19 Ojú wo lo fi ń wo “àwọn ohun ọlá ńlá Ọlọ́run” tó o ti kọ́? Ká sòótọ́, àǹfààní ńlá mà ni ẹ̀kọ́ òtítọ́ tá a ti kọ́ yìí o! A dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá nítorí pé à ń lo ìgbàgbọ́ nínú ẹ̀jẹ̀ tí Jésù Kristi ta sílẹ̀. (Ìṣe 2:38) Fún ìdí yìí, a ní òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ níwájú Ọlọ́run. A kì í bẹ̀rù ikú bí àwọn tí kò ní ìrètí kankan ti ń bẹ̀rù ikú. Dípò ìyẹn ọ̀rọ̀ Jésù fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé níjọ́ ọjọ́ kan “gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò gbọ́ ohùn rẹ̀, wọn yóò sì jáde wá.” (Jòhánù 5:28, 29) Jèhófà ti ṣí gbogbo nǹkan wọ̀nyí payá fún wa nínú ojú àánú rẹ̀. Kò fi mọ síbẹ̀ o, ó tún ti tú ẹ̀mí rẹ̀ sórí wa. Nítorí náà, ó yẹ kí ìmọrírì fún gbogbo ẹ̀bùn rere wọ̀nyí sún wa láti máa gbé àwọn ìlànà gíga rẹ̀ lárugẹ, ká máa fìtara yìn ín, ká sì máa polongo “àwọn ohun ọlá ńlá” wọ̀nyí fáwọn ẹlòmíì.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Nígbà tí Jèhófà yan Mósè àti Áárónì pé kí wọ́n ṣojú fáwọn èèyàn òun níwájú Fáráò, Ó sọ fún Mósè pé: “Mo fi ọ́ ṣe Ọlọ́run fún Fáráò, Áárónì arákùnrin rẹ gan-an yóò sì di wòlíì rẹ.” (Ẹ́kísódù 7:1) Áárónì jẹ́ wòlíì, kì í ṣe nípa sísọ ohun tí ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀, bí kò ṣe nípa dídi agbọ̀rọ̀sọ tàbí agbẹnusọ fún Mósè.
b Ọ̀kẹ́ àìmọye lára ọ̀pọ̀ èrò tó wá síbi Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa tá a ṣe ní March 28, 2002, ni kò tíì bẹ̀rẹ̀ sí fi taratara sin Jèhófà. Àdúrà wa ni pé kí ọkàn ọ̀pọ̀ lára àwọn olùfìfẹ́hàn wọ̀nyí sún wọn láti tẹ́wọ́ gba àǹfààní dídi akéde ìhìn rere náà.
c Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Kristẹni obìnrin ni Pọ́ọ̀lù ń bá wí, ìlànà kan náà kan àwọn Kristẹni ọkùnrin àtàwọn ọ̀dọ́.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Kí ni “àwọn ohun ọlá ńlá” táwọn èèyàn gbọ́ lọ́jọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa, kí ni wọ́n sì ṣe nípa rẹ̀?
• Báwo lèèyàn ṣe ń di ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi, kí sì lohun tó wé mọ́ jíjẹ́ ọmọ ẹ̀yìn?
• Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì láti kíyè sí ìwọṣọ àti ìmúra wa?
• Àwọn kókó wo ló yẹ ká fi sọ́kàn nígbà tá a bá ń ronú lórí bóyá aṣọ kan tàbí ohun tá a fẹ́ faṣọ náà rán bójú mu?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Pétérù kéde pé a ti jí Jésù dìde kúrò nínú òkú
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Ṣé ìrísí rẹ ń fògo fún Ọlọ́run tí ò ń sìn?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Àwọn Kristẹni òbí gbọ́dọ̀ kíyè sí ìrísí àwọn tó wà nínú ìdílé wọn