Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀kọ Àríkọ́gbọ́n Lára Ẹyẹ Àkọ̀

Ẹ̀kọ Àríkọ́gbọ́n Lára Ẹyẹ Àkọ̀

Ẹ̀kọ Àríkọ́gbọ́n Lára Ẹyẹ Àkọ̀

“ÀNÍ ẹyẹ àkọ̀ ní ojú ọ̀run-ó mọ àkókò rẹ̀ tí a yàn kalẹ̀ dáadáa . . . Ṣùgbọ́n ní ti àwọn ènìyàn mi, wọn kò mọ ìdájọ́ Jèhófà.” (Jeremáyà 8:7) Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn ni Jeremáyà lò láti kéde ìdájọ́ Jèhófà sórí àwọn èèyàn Júdà tó jẹ́ apẹ̀yìndà, àwọn tí wọ́n ti fi Jèhófà Ọlọ́run wọn sílẹ̀, tí wọ́n sì ń jọ́sìn àwọn ọlọ́run ilẹ̀ òkèèrè. (Jeremáyà 7:18, 31) Kí nìdí tó fi jẹ́ pé ara ẹyẹ àkọ̀ ni Jeremáyà tí sọ pé káwọn Júù aláìṣòótọ́ wọ̀nyí ti kọ́gbọ́n?

Ẹyẹ àkọ̀, àgàgà ẹyẹ àkọ̀ funfun jẹ́ ẹyẹ táwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ̀ bí ẹní mowó nítorí bó ṣe máa ń fò láti ibì kan lọ síbòmíràn láwọn ilẹ̀ tí wọ́n ti kọ Bíbélì. Abo ẹ̀dà ọ̀rọ̀ kan tó túmọ̀ sí “ẹni ìdúróṣinṣin; onínú rere onífẹ̀ẹ́” ni orúkọ tí ẹyẹ wọ́dòwọ́dò ńlá ẹlẹ́sẹ̀ gígùn yìí ń jẹ́ lédè Hébérù. Orúkọ yìí sì bá a mu wẹ́kú, nítorí pé, yàtọ̀ sí ohun tí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ẹyẹ mìíràn máa ń ṣe, ńṣe ni akọ àti abo ẹyẹ àkọ̀ máa ń ṣe tọkọtaya kalẹ́. Lẹ́yìn tí wọ́n bá ti lọ lo ìgbà òtútù ní àwọn àgbègbè tó móoru, ọ̀pọ̀ jù lọ ẹyẹ àkọ̀ ló máa ń padà wá lọ́dọọdún, tó sì jẹ́ pé inú ìtẹ́ tí wọ́n ti lò tẹ́lẹ̀ ni wọ́n máa ń padà sí.

Ìṣesí tá a dá mọ́ ẹyẹ àkọ̀ yìí ṣàpèjúwe ojúlówó ìdúróṣinṣin láwọn ọ̀nà mìíràn tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Takọtabo ẹyẹ náà ló máa ń sàba lórí ẹyin, àwọn méjèèjì ló sì máa ń fún àwọn òròmọ wọn lóúnjẹ. Ìwé Our Magnificent Wildlife ṣàlàyé pé: “Àwọn ẹyẹ àkọ̀ tó jẹ́ òbí máa ń jẹ́ olóòótọ́ síra wọn lọ́nà tó bùáyà. Akọ ẹyẹ àkọ̀ kan fò, ó sì lọ forí sọ wáyà iná nílẹ̀ Jámánì, ó sì gan mọ́bẹ̀. Aya rẹ̀ sì dá nìkan sàba lórí ẹyin fún odindi ọjọ́ mẹ́ta, kìkì ìgbà kan ṣoṣo tó wá oúnjẹ lọ fúngbà díẹ̀ ló fibẹ̀ sílẹ̀ ní gbogbo àkókò náà. . . . Yàtọ̀ síyẹn, nígbà tí wọ́n yìnbọn pa abo ẹyẹ àkọ̀ kan, èyí akọ ló tọ́ àwọn ọmọ wọn dàgbà.”

Láìṣe àní-àní, bí ẹyẹ àkọ̀ ṣe ń fi tọkàntọkàn dúró ti ẹnì kejì rẹ̀ títí dọjọ́ alẹ́, tí wọ́n sì ń tọ́jú àwọn ọmọ wọn lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́ fi hàn pé ẹyẹ náà gbé níbàámu pẹ̀lú ìtumọ̀ orúkọ rẹ̀.—“ẹni ìdúróṣinṣin.” Ìdí nìyẹn tí ẹyẹ àkọ̀ fi jẹ́ ohun tó dáa gan-an láti sọ pé káwọn ọmọ Ísírẹ́lì aláìṣòótọ́ tí wọ́n jẹ́ oníwàkiwà kẹ́kọ̀ọ́ lára rẹ̀.

Lójú ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn lónìí, ìdúróṣinṣin jẹ́ àṣà àtijọ́—téèyàn lè máa kan sáárá sí àmọ́ tí kò ṣeé ṣe. Bí ìkọ̀sílẹ̀ ṣe ń pọ̀ sí i, táwọn ọmọ tí wọ́n já sílẹ̀ ò lóǹkà, táwọn èèyàn sì ń kówó jẹ lójú méjèèjì pa pọ̀ mọ́ àwọn onírúurú ìwà ẹ̀tàn mìíràn tó wà káàkiri fi hàn pé àwọn èèyàn ò ka ìdúróṣinṣin sí bàbàrà mọ́. Ní ìyàtọ̀ síyẹn, Bíbélì fojú tó ga gan-an wo ìdúróṣinṣin tí ìfẹ́ àti inú rere súnni ṣe. Ó rọ àwọn Kristẹni láti “gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀, èyí tí a dá ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run nínú òdodo tòótọ́ àti ìdúróṣinṣin.” (Éfésù 4:24) Dájúdájú, àkópọ̀ ìwà tuntun ń ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ adúróṣinṣin, àmọ́ a tún lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìdúróṣinṣin lára ẹyẹ àkọ̀.