Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ǹjẹ́ Ébẹ́lì mọ̀ pé ó pọn dandan láti fi ẹran rúbọ kéèyàn tó lè rí ojú rere Ọlọ́run?
Ìtàn Bíbélì nípa ẹbọ tí Kéènì àti Ébẹ́lì rú kò gùn rárá. Ohun tá a kà nínú Jẹ́nẹ́sísì 4:3-5 ni pé: “Ó ṣẹlẹ̀ pé, ní òpin àwọn àkókò kan, Kéènì tẹ̀ síwájú láti mú àwọn èso kan tí ilẹ̀ mú jáde, wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ fún Jèhófà. Ṣùgbọ́n ní ti Ébẹ́lì, òun pẹ̀lú mú àwọn àkọ́bí nínú agbo ẹran rẹ̀ wá, àní àwọn apá tí ó lọ́ràá nínú wọn. Wàyí o, nígbà tí Jèhófà fi ojú rere wo Ébẹ́lì àti ọrẹ ẹbọ rẹ̀, òun kò fi ojú rere kankan wo Kéènì àti ọrẹ ẹbọ rẹ̀.”
Kò síbi tí Bíbélì ti mẹ́nu kàn án pé Jèhófà ti sọ ohunkóhun ṣáájú àkókò yẹn nípa ẹbọ tàbí nípa irú ẹbọ tí òun máa tẹ́wọ́ gbà. Nítorí náà, ó dájú pé Kéènì àti Ébẹ́lì ló fúnra wọn yàn láti rú ẹbọ tí wọ́n rú. Wọn ò láǹfààní àtidé inú Párádísè tó jẹ́ ilé àwọn òbí wọn níbẹ̀rẹ̀; wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí nímọ̀lára pé ẹlẹ́ṣẹ̀ làwọn; àti pé àwọn ti di àjèjì sí Ọlọ́run. Inú ipò ẹ̀ṣẹ̀ àti ti ìkáàánú tí wọ́n wà ni wọ́n ti rí i pé ó pọn dandan fáwọn láti yíjú sí Ọlọ́run fún ìrànlọ́wọ́. Ó ṣeé ṣe kí fífún tí wọ́n fún Ọlọ́run ní ẹ̀bùn jẹ́ ohun táwọn fúnra wọn fínnúfíndọ̀ ṣe kí wọ́n lè rí ojú rere Ọlọ́run.
Àbájáde rẹ̀ ni pé Ọlọ́run tẹ́wọ́ gba ẹbọ Ébẹ́lì àmọ́ kò tẹ́wọ́ gba ti Kéènì. Kí nìdí? Àbí ó lè jẹ́ nítorí pé Ébẹ́lì fi ohun tí ó tọ́ rúbọ, tí Kéènì kò sì ṣe bẹ́ẹ̀ ni? A ò lè sọ ní pàtó pé irú ẹbọ tí wọ́n rú ní ohunkóhun ṣe nínú ọ̀ràn náà, nítorí pé kò sẹ́ni tá a sọ irú ẹbọ tó ṣètẹ́wọ́gbà àti èyí tí kò ṣètẹ́wọ́gbà fún nínú àwọn méjèèjì ṣáájú àkókò yẹn. Bó ti wù kó rí, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé kò sí èyí tí kò ṣètẹ́wọ́gbà níbẹ̀. Nínú Òfin tí Jèhófà wá fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì níkẹyìn, kì í ṣe ẹbọ tí wọ́n fi ẹran tàbí àwọn ẹ̀yà ara ẹran rú nìkan ló ṣètẹ́wọ́gbà, àmọ́ èyí tí wọ́n fi ọkà sísun, àwọn ìtí báálì, ìyẹ̀fun kíkúnná, àwọn ohun yíyan, àti wáìnì rú tún ṣètẹ́wọ́gbà pẹ̀lú. (Léfítíkù 6:19-23; 7:11-13; 23:10-13) Ó hàn gbangba pè kì í ṣe kìkì ohun tí Kéènì àti Ébẹ́lì fi rúbọ ló mú kí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gba ọ̀kan tó sì kọ èkejì sílẹ̀.—Fi wé Aísáyà 1:11; Ámósì 5:22.
Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún lẹ́yìn náà ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Nípa ìgbàgbọ́ ni Ébẹ́lì rú ẹbọ tí ó níye lórí ju ti Kéènì sí Ọlọ́run, nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ náà tí ó fi ní ẹ̀rí tí a jẹ́ sí i pé ó jẹ́ olódodo, tí Ọlọ́run ń jẹ́rìí nípa àwọn ẹ̀bùn rẹ̀.” (Hébérù 11:4) Látàrí èyí, ìgbàgbọ́ ló mú kí Ọlọ́run ka Ébẹ́lì sí olódodo. Àmọ́ ìgbàgbọ́ nínú kí ni? Ìgbàgbọ́ nínú ìlérí Jèhófà pé yóò pèsè Irú Ọmọ tí yóò ‘pa ejò náà ní orí,’ tí yóò sì mú àlàáfíà àti ìjẹ́pípé téèyàn ti gbádùn nígbà kan rí padà wá ni. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ gbólóhùn tó sọ pé a ó ‘pa Irú Ọmọ náà ní gìgísẹ̀’ ló mú kí Ébẹ́lì ronú pé ìrúbọ tó ní títa ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ nínú la nílò. (Jẹ́nẹ́sísì 3:15) Ohun yòówù kó jẹ́, òkodoro òtítọ́ ibẹ̀ ni pé ìgbàgbọ́ tí Ébẹ́lì ní ló mú kí ẹbọ tirẹ̀ jẹ́ ‘èyí tí ó níye lórí ju ti Kéènì lọ.’
Bákan náà, kíkọ̀ tí Ọlọ́run kọ Kéènì kì í ṣe nítorí pé ó rú ẹbọ tí kò dára, àmọ́ nítorí pé kò ní ìgbàgbọ́, gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀ ti fi hàn. Jèhófà sọ ọ́ ní kedere fún Kéènì pé: “Bí ìwọ bá yíjú sí ṣíṣe rere, ara rẹ kò ha ní yá gágá bí?” (Jẹ́nẹ́sísì 4:7) Ọlọ́run kò kọ Kéènì sílẹ̀ nítorí àìní inú dídùn sí irú ẹbọ tó rú. Dípò ìyẹn, Ọlọ́run kọ Kéènì sílẹ̀ “nítorí pé àwọn iṣẹ́ tirẹ̀ burú”—èyí tí owú, ìkórìíra àti ìṣìkàpànìyàn nígbẹ̀yìngbẹ́yín wá fi hàn.—1 Jòhánù 3:12.