Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìgbà Wo Ni Jèhófà Máa Ń Bù Kún—Ìsapá Tí A Fi Taratara Ṣe?

Ìgbà Wo Ni Jèhófà Máa Ń Bù Kún—Ìsapá Tí A Fi Taratara Ṣe?

Ìgbà Wo Ni Jèhófà Máa Ń Bù Kún—Ìsapá Tí A Fi Taratara Ṣe?

“JẸ́ KÍ n lọ, nítorí ọ̀yẹ̀ ti là.”

“Èmi kò ní jẹ́ kí o lọ, àyàfi tí o bá kọ́kọ́ súre fún mi.”

“Kí ni orúkọ rẹ?”

“Jékọ́bù.”

“A kì yóò pe orúkọ rẹ ní Jékọ́bù mọ́ bí kò ṣe Ísírẹ́lì, nítorí ìwọ ti bá Ọlọ́run àti ènìyàn wọ̀jà, o sì borí lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn.”—Jẹ́nẹ́sísì 32:26-28.

Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ gbígbámúṣé yẹn wáyé látàrí fífakọyọ tí Jékọ́bù, ẹni ọdún mẹ́tàdínlọ́gọ́rùn-ún fakọ yọ nínú ìfigẹ̀wọngẹ̀ kan. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì kò sọ pé eléré ìdárayá ni Jékọ́bù, síbẹ̀ ó bá áńgẹ́lì kan wọ̀yá ìjà ní gbogbo òru. Nítorí kí ni? Ohun tó ká Jékọ́bù lára jù lọ ni ìlérí tí Jèhófà ṣe fún àwọn baba ńlá rẹ̀—ìyẹn ogún tẹ̀mí tí ó ní.

Ọ̀pọ̀ ọdún ṣáájú àkókò yẹn ni Ísọ̀, ẹ̀gbọ́n Jékọ́bù ti fi ẹ̀tọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àkọ́bí fún Jékọ́bù ó sì fi gba àwo ọbẹ̀ kan. Jékọ́bù wá gbọ́ pé Ísọ̀ ń kó irínwó ọkùnrin bọ̀ báyìí. Ó dájú pé ìyẹn kó jìnnìjìnnì bá Jékọ́bù, tó fi ń wá ẹ̀rí ìdánilójú ìlérí Jèhófà pé ìdílé òun yóò láásìkí ní ilẹ̀ tó wà ní òdìkejì Odò Jọ́dánì. Jékọ́bù gbé ìgbésẹ̀ tó ṣe gúnmọ́ ní ìbámu pẹ̀lú àdúrà rẹ̀. Ó kó àwọn ẹ̀bùn ránṣẹ́ sí Ísọ̀ tó ń bọ̀ wá pàdé rẹ̀. Ó tún gbé ìgbésẹ̀ tó máa jẹ́ ààbò fún wọn. Ó pín agbo rẹ̀ sí méjì, ó sì kó àwọn aya rẹ̀ àtàwọn ọmọ rẹ̀ sọdá ibi pẹ́ṣẹ́pẹ́ṣẹ́ odò Jábókù. Pẹ̀lú ìsapá tó fi taratara ṣe àti ọ̀pọ̀ omijé, ó tún sakun gidigidi láti bá áńgẹ́lì kan wọ̀yá ìjà “kí ó lè fi taratara bẹ̀bẹ̀ fún ojú rere fún ara rẹ̀.”—Hóséà 12:4; Jẹ́nẹ́sísì 32:1-32.

Gbé àpẹẹrẹ tó ṣáájú ìyẹn yẹ̀ wò, ìyẹn ni ti Rákélì, tó jẹ́ ìyàwó kejì fún Jékọ́bù, tó sì jẹ́ pé òun ni ọkọ wọn fẹ́ràn jù lọ. Rákélì mọ̀ nípa ìlérí tí Jèhófà ṣe láti bù kún Jékọ́bù. Léà ẹ̀gbọ́n rẹ̀ tó jẹ́ ìyàwó àkọ́kọ́ fún Jékọ́bù ti bí ọmọkùnrin mẹ́rin nígbà tí Rákélì ṣì jẹ́ àgàn. (Jẹ́nẹ́sísì 29:31-35) Dípò tó fi máa kárí sọ, ńṣe ló ń bẹ Jèhófà nínú àdúrà, tó sì gbé ìgbésẹ̀ gúnmọ́ ní ìbámu pẹ̀lú àdúrà rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí Sárà, ìyá ńlá rẹ̀ ti ṣe fún Hágárì, Rákélì mú Bílíhà, ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ fún Jékọ́bù gẹ́gẹ́ bí aya onípò kejì kí nǹkan lè rí bí Rákélì ṣe sọ ọ́ pé, “kí èmi, àní èmi, lè ní àwọn ọmọ láti ọ̀dọ̀ rẹ̀.” a Bílíhà bí ọmọkùnrin méjì fún Jékọ́bù—ìyẹn Dánì àti Náfútálì. Ìgbà tí wọ́n bí Náfútálì ni Rákélì sọ bí ọ̀rọ̀ náà ṣe ká òun lára tó jáde, ó ní: “Gídígbò tí a jà ní àjàkú-akátá ni mo bá arábìnrin mi jà. Mo sì ti mókè!” Ẹ̀yìn ìyẹn la wá fi ọmọkùnrin méjì, ìyẹn Jósẹ́fù àti Bẹ́ńjámínì jíǹkí Rákélì.—Jẹ́nẹ́sísì 30:1-8; 35:24.

Kí nìdí tí Jèhófà fi bù kún ìsapá tí Jékọ́bù àti Rákélì ṣe nípa tara àti ní ti ìmọ̀lára? Wọ́n fi ṣíṣe ìfẹ́ Jèhófà sí ipò kìíní, wọ́n sì mọyì ogún wọn. Wọ́n fi tọkàntọkàn gbàdúrà fún ìbùkún rẹ̀ nínú ìgbésí ayé wọn, wọ́n sì gbé ìgbésẹ̀ aláápọn ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run àti ẹ̀bẹ̀ àwọn fúnra wọn.

Bíi ti Jékọ́bù àti Rákélì, ọ̀pọ̀ lóde òní ló lè jẹ́rìí sí i pé a nílò ìsapá tí a fi taratara ṣe ká tó lè rí ìbùkún Jèhófà gbà. Omijé, ìrẹ̀wẹ̀sì àti kí nǹkan tojú súni ló sì sábà máa ń bá irú ìsapá bẹ́ẹ̀ rìn. Kristẹni kan tó jẹ́ ìyá, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Elizabeth, rántí bó ṣe ṣòro tó fún òun láti tún bẹ̀rẹ̀ sí lọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni déédéé lẹ́yìn tó ti pa ìpàdé jẹ́ fún àkókò gígùn. Ìpèníjà ńlá ló jẹ́ fún un láti tọ́jú àwọn ọmọkùnrin kéékèèké márùn-ún, láti máa bá ọkọ kan tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ gbé, àti láti máa rin ìrìn àjò ọgbọ̀n kìlómítà dé Gbọ̀ngàn Ìjọba tó sún mọ́ ọn jù lọ. Ó sọ pé: “Gbígbìyànjú láti lọ sí ìpàdé déédéé gba ọ̀pọ̀ ìsẹ́ra ẹni, tí mo mọ̀ pé ó ṣàǹfààní fún èmi àtàwọn ọmọkùnrin mi. Ó ràn wọ́n lọ́wọ́ láti rí i pé ipa ọ̀nà tó yẹ láti tọ̀ nìyí.” Jèhófà bù kún ìsapá rẹ̀. Méjì ló wà nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún lára àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ mẹ́ta tó ń ṣe déédéé nínú ìjọ Kristẹni. Nígbà tó ń sọ bí ìtẹ̀síwájú wọn nípa tẹ̀mí ṣe múnú rẹ̀ dùn tó, ó ní: “Wọ́n ti dàgbà jù mí lọ nípa tẹ̀mí.” Ẹ ò rí i pé ìbùkún ńlá nìyẹn jẹ́ fún ìsapá tó fi taratara ṣe!

Ìsapá Tí A Fi Ìtara Ṣe Tí Jèhófà Máa Ń Bù Kún

Ó dájú pé fífi taratara sapá àti ṣíṣe iṣẹ́ àṣekára ní èrè tiwọn. Bí a bá ṣe sapá lórí iṣẹ́ kan tó ni ayọ̀ tí a óò rí níbẹ̀ yóò ṣe pọ̀ tó. Bí Jèhófà ṣe dá wa nìyẹn. Sólómọ́nì Ọba kọ̀wé pé: “Kí olúkúlùkù ènìyàn máa jẹ, kí ó sì máa mu ní tòótọ́, kí ó sì rí ohun rere nítorí gbogbo iṣẹ́ àṣekára rẹ̀. Ẹ̀bùn Ọlọ́run ni.” (Oníwàásù 3:13; 5:18, 19) Àmọ́ ṣá o, ká tó lè rí ìbùkún Ọlọ́run gbà, a gbọ́dọ̀ rí i dájú pé ìsapá wa jẹ́ èyí tí ó tọ́. Bí àpẹẹrẹ, ǹjẹ́ a lè máa retí ìbùkún Jèhófà lórí ọ̀nà ìgbésí ayé kan tó fi ohun tẹ̀mí sí ipò kejì? Ǹjẹ́ Kristẹni kan tó ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ lè retí àtirí ojú rere Jèhófà tó bá lọ gba iṣẹ́ kan tàbí ìgbéga tí yóò máa mú un pàdánù ìbákẹ́gbẹ́ àti ìtọ́ni tó ń gbé ìgbàgbọ́ ró láwọn ìpàdé Kristẹni?—Hébérù 10:23-25.

Gbogbo ìgbésí ayé téèyàn fi ṣe iṣẹ́ àṣekára níbi tó ti ń lépa àtijẹ àtimu tàbí ọrọ̀ àlùmọ́nì kiri kò ní fi dandan túmọ̀ sí pé irú ẹni bẹ́ẹ̀ yóò “rí ohun rere” tó bá ṣe bẹ́ẹ̀ láìfi nǹkan tẹ̀mí kún un. Jésù ṣàpèjúwe àbájáde ìsapá téèyàn ṣe lọ́nà àìtọ́ nínú òwe afúnrúgbìn. Jésù ṣàlàyé irúgbìn tá a “fún sáàárín àwọn ẹ̀gún,” pé “èyí ni ẹni tí ń gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, ṣùgbọ́n tí àníyàn ètò àwọn nǹkan yìí àti agbára ìtannijẹ ọrọ̀ fún ọ̀rọ̀ náà pa, ó sì di aláìléso.” (Mátíù 13:22) Pọ́ọ̀lù tún kìlọ̀ nípa pańpẹ́ kan náà, ó sì fi kún un pé àwọn tó ń lépa ọrọ̀ “máa ń ṣubú sínú ìdẹwò àti ìdẹkùn àti ọ̀pọ̀ ìfẹ́-ọkàn tí í ṣe ti òpònú, tí ó sì ń ṣeni lọ́ṣẹ́, èyí tí ń ri ènìyàn sínú ìparun àti ègbé.” Kí ni oògùn irú ọ̀nà ìgbésí ayé tí ń yọrí sí ègbé nípa tẹ̀mí bẹ́ẹ̀? Pọ́ọ̀lù tún sọ pé: ‘Sá fún nǹkan wọ̀nyí, kí o má ṣe gbé ìrètí rẹ lé ọrọ̀ àìdánilójú, bí kò ṣe lé Ọlọ́run, ẹni tí ń pèsè ohun gbogbo fún wa lọ́pọ̀ jaburata fún ìgbádùn wa.’—1 Tímótì 6:9, 11, 17.

Láìka iye ọjọ́ orí wa tàbí iye ọdún tá a ti fi sin Jèhófà sí, gbogbo wa lè jàǹfààní látinú fífarawé ìsapá tí Jékọ́bù àti Rákélì fi taratara ṣe. Bí wọ́n ṣe ń wá àtirí ojú rere Ọlọ́run, wọn ò gbàgbé ogún wọn, bó ti wù kí ipò tí wọ́n wà jẹ́ èyí tí ń jáni láyà tàbí èyí tí ń tánni ní sùúrù tó. Lóde òní, pákáǹleke àtàwọn ìṣòro tó ń dojú kọ wá lè jẹ́ èyí tó ń dáyà foni, tó ń tánni ní sùúrù, tàbí tó tiẹ̀ ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì báni pàápàá. Ìdẹwò náà ni láti mú wa jáwọ́ nínú lílàkàkà, ká sì di ẹni tó ṣubú sínú ìkọlù Sátánì. Gbogbo ohun tó wà níkàáwọ́ rẹ̀ ló lè lò láti mú àwọn ète rẹ̀ ṣẹ, ì báà jẹ́ eré ìnàjú tàbí eré ìtura, eré ìdárayá tàbí ìgbòkègbodò àfipawọ́, iṣẹ́ ẹni tàbí ọrọ̀ àlùmọ́nì. Ó sábà máa ń ṣèlérí àbájáde tó fani lọ́kàn mọ́ra àmọ́ kì í rí bẹ́ẹ̀ rárá. Àwọn tó tàn jẹ tàbí tó ré lọ láti kó sínú irú ìlépa bẹ́ẹ̀ sábà máa ń rí i pé ìjákulẹ̀ ni gbogbo rẹ̀ ń yọrí sí. Bíi ti Jékọ́bù àti Rákélì ìgbàanì, ẹ jẹ́ kí a ní ẹ̀mí ìfitaratara-jìjàkadì ká sì borí àwọn ètekéte Sátánì.

Kò sóhun tó ń wu Sátánì láti rí ju pé ká juwọ́ sílẹ̀, ká máa ronú pé ‘kò sí ìrètí kankan fún wa mọ́. Kò lè sí ọ̀nà àbájáde mọ́. A ò tiẹ̀ ní sapá kankan mọ́.’ Nígbà náà, ó ṣe pàtàkì gan-an pé kí gbogbo wa yẹra fún ẹ̀mí ìjuwọ́sílẹ̀, ká má máa ronú pé ‘kó sẹ́ni tó nífẹ̀ẹ́ mi’ àti pé ‘Jèhófà ti gbàgbé mi.’ Ríronú lọ́nà yẹn túmọ̀ sí ṣíṣe ara ẹni ní jàǹbá. Bóyá ó sì tún lè túmọ̀ sí pé a ti juwọ́ sílẹ̀, a ò sì fẹ́ máa bá ìjàkadì náà nìṣó títí a óò fi gbà ìbùkún. Rántí pé Jèhófà ń bù kún ìsapá tá a fi taratara ṣe.

Máa Jìjàkadì Nìṣó Kí O Lè Rí Ìbùkún Jèhófà Gbà

Ohun tí ìlera wa nípa tẹ̀mí sinmi lé lórí jù lọ ni lílóye kókó méjì pàtàkì nípa ìgbésí ayé wa gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Jèhófà. (1) Kò sẹ́ni tó jẹ́ pé òun nìkan ṣoṣo ló dojú kọ ìṣòro tàbí àìsàn tàbí àwọn ipò líle koko nínú ayé yìí, àti pé (2) Jèhófà ń fetí sí igbe àwọn tó ń fi taratara bẹ̀bẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́ àti ìbùkún rẹ̀.—Ẹ́kísódù 3:7-10; Jákọ́bù 4:8, 10; 1 Pétérù 5:8, 9.

Bó ti wù kí ipò tó o wà nira tó tàbí bó ti wù kó o rò pé o ò já mọ́ nǹkan kan tó, má ṣe kó sínú “ẹ̀ṣẹ̀ tí ó máa ń wé mọ́ wa pẹ̀lú ìrọ̀rùn”—ìyẹn ni àìní ìgbàgbọ́. (Hébérù 12:1) Máa jìjàkadì nìṣó títí tó o fi máa rí ìbùkún gbà. Mú sùúrù, kó o máa rántí Jékọ́bù arúgbó tó fi gbogbo òru ja ìjàkadì kó lè rí ìbùkún gbà. Bíi ti àgbẹ̀ tó fúnrúgbìn nígbà ìrúwé tó wá ń dúró de àsìkò ìkórè ni kí ìwọ náà máa fi sùúrù retí ìbùkún Jèhófà lórí ìgbòkègbodò tẹ̀mí rẹ, bó ti wù kí o rò pé ó kéré tó. (Jákọ́bù 5:7, 8) Sì máa fi ọ̀rọ̀ onísáàmù sọ́kàn nígbà gbogbo pé: “Àwọn tí ń fi omijé fúnrúgbìn yóò fi igbe ìdùnnú ká a.” (Sáàmù 126:5; Gálátíà 6:9) Dúró láìyẹsẹ̀, má sì kúrò lágbo àwọn tó ń jìjàkadì.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Yíyan wáhàrì wà ṣáájú májẹ̀mú Òfin, Òfin fàyè gbà á, ó sì ń dárí rẹ̀. Kò tíì tó àkókò lójú Ọlọ́run nígbà yẹn láti tún fìdí ìlànà ìgbéyàwó ọkọ-kan-aya-kan tó bẹ̀rẹ̀ nínú ọgbà Édẹ́nì múlẹ̀ lẹ́ẹ̀ẹ̀kan sí i títí dìgbà tí Jésù Kristi máa fara hàn, àmọ́ ó fi òfin dáàbò bo àwọn tó jẹ́ wáhàrì. Yíyan wáhàrì ṣèrànwọ́ láti mú kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tètè pọ̀ níye.