Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Ìgbàgbọ́ Nínú Ohun Asán Ló Ń Darí Ìgbésí Ayé Rẹ?

Ṣé Ìgbàgbọ́ Nínú Ohun Asán Ló Ń Darí Ìgbésí Ayé Rẹ?

Ṣé Ìgbàgbọ́ Nínú Ohun Asán Ló Ń Darí Ìgbésí Ayé Rẹ?

JÁKÈJÁDÒ ayé làwọn èèyàn ti ní ìgbàgbọ́ nínú ohun asán. Wọ́n máa ń kà á mọ́ ara àṣà táwọn jogún. Tàbí kẹ̀ kí wọ́n kà á sí ohun tí kò fi bẹ́ẹ̀ jẹ́ bàbàrà—tó kàn ń fi adùn kún ìgbésí ayé ẹni. Àwọn ará Ìwọ̀ Oòrùn ayé kò fi bẹ́ẹ̀ ka ìgbàgbọ́ nínú ohun asán sí nǹkan dan-indan-in. Àmọ́ ìgbàgbọ́ nínú ohun asán lè nípa tó lágbára lórí àwọn èèyàn láwọn ibòmíràn, bí ilẹ̀ Áfíríkà.

Èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àṣà ìbílẹ̀ Áfíríkà ló dá lórí ìgbàgbọ́ nínú ohun asán. Àwọn ohun tí wọ́n ń gbé jáde nínú sinimá, àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ orí rédíò, àtàwọn ìwé tí wọ́n ń kọ nílẹ̀ Áfíríkà sábà máa ń fi ìgbàgbọ́ nínú ohun asán àti ọ̀ràn ìbẹ́mìílò hàn, irú bí iṣẹ́ òkùnkùn, jíjọ́sìn àwọn baba ńlá, àti lílo ońdè fún ààbò. Kí nìdí tí ìgbàgbọ́ nínú ohun asán fi nípa lórí àwọn èèyàn tó bẹ́ẹ̀, ibo sì ni ìgbàgbọ́ nínú ohun asán ti wá?

Ibo Ni Ìgbàgbọ́ Nínú Ohun Asán Ti Wá?

Ọ̀pọ̀ ìgbàgbọ́ nínú ohun asán ló wá látinú ìbẹ̀rù ẹ̀mí àwọn òkú tàbí ìbẹ̀rù àwọn ẹ̀mí èyíkéyìí mìíràn. Táwọn nǹkan bá ṣẹlẹ̀, àwọn èèyàn máa ń túmọ̀ wọn sí pé ńṣe làwọn ẹ̀mí wọ̀nyí ń gbìyànjú láti halẹ̀ mọ́ àwọn alààyè, láti kìlọ̀ fún wọn tàbí kí wọ́n bù kún àwọn alààyè lọ́nà kan ṣáá.

Ìgbàgbọ́ nínú ohun asán tún so pọ̀ mọ́ ìwòsàn àti ìṣègùn pẹ́kípẹ́kí. Ìṣègùn òyìnbó gbówó lórí gan-an, kì í sì í sábà sí lárọ̀ọ́wọ́tó ọ̀pọ̀ èèyàn tó wà láwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà. Ìdí nìyẹn tí ọ̀pọ̀ fi ń wá ìwòsàn tàbí tí wọ́n ń gbìyànjú láti dá àìsàn dúró nípa yíyíjú sí àṣà àwọn baba ńlá ìgbàanì, ìbẹ́mìílò, àti ìgbàgbọ́ nínú ohun asán. Ó tún máa ń rọrùn fún wọn láti lọ sọ́dọ̀ adáhunṣe tó mọ àṣà wọn tó sì ń sọ èdè ìbílẹ̀ wọn ju kí wọ́n lọ sọ́dọ̀ oníṣègùn òyìnbó. Ìdí nìyẹn tí ìgbàgbọ́ nínú ohun asán kò fi lè kásẹ̀ nílẹ̀.

Àwọn tí ìgbàgbọ́ nínú ohun asán jẹ lógún gbà gbọ́ pé àìsàn àti jàǹbá kì í ṣàdédé ṣẹlẹ̀, pé àwọn agbára láti ilẹ̀ ẹ̀mí ló ń fà á. Babaláwo kan lè sọ pé baba ńlá kan tó ti kú ló ń bínú nítorí nǹkan kan. Abẹ́mìílò kan sì lè sọ pé ẹnì kan ló ní kí babaláwo mìíràn bá òun sà sí onítọ̀hún, ìyẹn ló sì fa àìsàn tàbí jàǹbá tó ṣẹlẹ̀.

Ìgbàgbọ́ nínú ohun asán yàtọ̀ síra gan-an jákèjádò ayé, bí wọ́n sì ṣe ń tàn wọ́n kálẹ̀ sinmi lórí ìtàn ìṣẹ̀ǹbáyé, ìtàn àtẹnudẹ́nu, àti ipò àwọn ará àdúgbò náà. Àmọ́ ohun tí gbogbo rẹ̀ fi bára mu ni ìgbàgbọ́ pé ẹnì kan, tàbí ohun kan, láti ilẹ̀ ẹ̀mí àìrí ń fẹ́ kí wọ́n tu òun lójú.

Ṣé Ó Léwu Tàbí Kò Léwu?

Lójú ọ̀pọ̀ jù lọ ìdílé, nǹkan àrà tó ń múnú ẹni dùn ni kéèyàn bí ìbejì. Àmọ́ àwọn tó nígbàgbọ́ nínú ohun asán lè sọ pé àmì kan ni. Láwọn apá ibì kan ní Ìwọ Oòrùn Áfíríkà, ọ̀pọ̀ gbà pé òrìṣà àkúnlẹ̀bọ làwọn ìbejì, wọ́n sì máa ń bọ wọn. Bí ọ̀kan nínú wọn tàbí àwọn méjèèjì bá kú, wọ́n a ṣe àwọn ère kéékèèké fáwọn ìbejì náà, ìdílé náà á sì máa fún àwọn ère wọ̀nyí lóúnjẹ. Láwọn ibòmíràn, wọ́n gbà pé èpè ló mọ́ ẹni tó bá bí ìbejì, tó fi jẹ́ pé àwọn òbí kan máa ń pa àwọn méjèèjì tàbí kí wọ́n pa ọkàn lára wọn. Nítorí kí ni? Wọ́n gbà gbọ́ pé táwọn méjèèjì bá wà, ọjọ́ kan ni wọ́n máa lu àwọn òbí wọn pa.

Àwọn àpẹẹrẹ wọ̀nyí fi hàn pé bí ìgbàgbọ́ nínú ohun asán kan tiẹ̀ jẹ́ èyí tó dùn mọ́ni tí kò sì lè pani lára, àwọn mìíràn léwu gan-an—wọ́n sì lè yọrí sí ikú. Pẹ̀lú èrò ibi lọ́kàn, ohun kan tí kò lè pani lára lè di èyí tá a sọ di ohun tó léwu gan-an.

Bẹ́ẹ̀ ni o, ìgbàgbọ́ nínú ohun asán jẹ́ ìgbàgbọ́ kan, ìyẹn irú ẹ̀sìn kan. Téèyàn bá ronú lórí ewu tó wà nínú ìgbàgbọ́ nínú ohun asán, ó bọ́gbọ́n mu láti béèrè pé: Ta ni ìgbàgbọ́ nínú ohun asán àti ohun tó ní nínú ń fìyìn fún gan-an?

Ibi Tí Ìgbàgbọ́ Nínú Ohun Asán Ti Wá

Pẹ̀lú gbogbo ẹ̀rí tó fi hàn pé Sátánì wà, àwọn kan ṣì ń sẹ́ pé kò sóhun tó ń jẹ́ Sátánì tàbí àwọn ẹ̀mí búburú. Àmọ́ o, èèyàn lè kóra rẹ̀ sínú jàǹbá ńlá nígbà tí ogun bá ń jà lọ́wọ́, tónítọ̀hún ò sì fẹ́ gbà pé ọ̀tá tó jẹ́ eléwu wà nítòsí. Bákan náà lọ̀rọ̀ rí nígbà téèyàn bá ń bá àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí alágbára wọ̀yá ìjà, nítorí pé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Àwa ní gídígbò kan . . . lòdì sí àwọn agbo ọmọ ogun ẹ̀mí burúkú.”—Éfésù 6:12.

Àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí burúkú wà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò lè rí wọn. Bíbélì ṣàlàyé pé ẹ̀dá ẹ̀mí kan tí a kò lè fojú rí lo ejò, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọlọ́sanyìn ṣe máa ń lo ère, láti fi bá Éfà, obìnrin àkọ́kọ́, sọ̀rọ̀ kí ó sì mú kí ó ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-5) Bíbélì pe ẹni ẹ̀mí yìí ní “ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà, ẹni tí a ń pè ní Èṣù àti Sátánì, ẹni tí ń ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà.” (Ìṣípayá 12:9) Ẹni yẹn, ìyẹn Sátánì, fi ẹ̀tàn mú kí àwọn áńgẹ́lì mìíràn ṣọ̀tẹ̀. (Júúdà 6) Àwọn áńgẹ́lì burúkú wọ̀nyí ló wá di àwọn ẹ̀mí èṣù, ìyẹn àwọn ọ̀tá Ọlọ́run.

Jésù lé ẹ̀mí èṣù jáde lára àwọn èèyàn, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ṣì ṣe bákan náà pẹ̀lú. (Máàkù 1:34; Ìṣe 16:18) Àwọn ẹ̀mí wọ̀nyí kì í ṣe àwọn baba ńlá tó ti kú, nítorí pé àwọn òkú “kò mọ nǹkan kan rárá.” (Oníwàásù 9:5) Dípò ìyẹn àwọn áńgẹ́lì tó ṣọ̀tẹ̀ ni wọ́n, ìyẹn àwọn tí Sátánì tàn jẹ. Kíkàn sí wọn tàbí jíjẹ́ kí wọ́n nípa lórí ẹni kì í ṣe ohun tó yẹ ká fọwọ́ yẹpẹrẹ mú, nítorí pé àwọn náà á fẹ́ pa wá jẹ bíi ti Sátánì Èṣù ọ̀gá wọn ni. (1 Pétérù 5:8) Góńgó wọn ni láti mú ká pàdánù ìrètí kan ṣoṣo tí aráyé ní—ìyẹn Ìjọba Ọlọ́run.

Bíbélì ṣí ọgbọ́n kan tí Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ ń dá payá, ó ní: “Sátánì fúnra rẹ̀ a máa pa ara rẹ̀ dà di áńgẹ́lì ìmọ́lẹ̀.” (2 Kọ́ríńtì 11:14) Sátánì á fẹ́ tàn wá ká lè gbà pé òun lè fún wa ní ọ̀nà ìgbésí ayé kan tó sàn ju èyí tí à ń gbé lọ. Nítorí ìdí èyí, ó lè dà bíi pé àwọn àǹfààní onígbà díẹ̀ kan ń wá látọ̀dọ̀ àwọn ẹ̀mí búburú. Àmọ́ wọn ò lè fúnni ní ojútùú pípẹ́ títí. (2 Pétérù 2:4) Wọn ò lè fún ẹnikẹ́ni ní ìyè àìnípẹ̀kun, kódà àwọn fúnra wọn máa pa run láìpẹ́. (Róòmù 16:20) Ẹlẹ́dàá wa nìkan ṣoṣo ni orísun ìyè ayérayé àti ti ayọ̀ tòótọ́ àti ti ààbò tó dára jù lọ kúrò lọ́wọ́ àwọn ẹ̀mí búburú.—Jákọ́bù 4:7.

Ọlọ́run ka kéèyàn máa wá ìrànlọ́wọ́ látọ̀dọ̀ abẹ́mìílò léèwọ̀. (Diutarónómì 18:10-12; 2 Àwọn Ọba 21:6) Ìyẹn yóò túmọ̀ sí pé èèyàn ń kàn sí ọ̀tá náà, pé ó ń bá ẹni tó purọ́ mọ́ Ọlọ́run gbìmọ̀ pọ̀! Wíwo ìràwọ̀ ọjọ́ ìbí, wíwádìí nǹkan lọ́dọ̀ oníṣègùn ìbílẹ̀, tàbí lílọ́wọ́ nínú ohunkóhun tó ní í ṣe pẹ̀lú ìgbàgbọ́ nínú ohun asán yóò túmọ̀ sí fífàyè gba àwọn ẹ̀mí búburú láti máa darí àwọn ìpinnu tó ò ń ṣe nínú ìgbésí ayé rẹ. Ìyẹn ò sì yàtọ̀ sígbà téèyàn bá dara pọ̀ mọ́ wọn nínú ọ̀tẹ̀ tí wọ́n ń ṣe sí Ọlọ́run.

Ǹjẹ́ Ó Ṣeé Ṣe Láti Rí Ààbò Kúrò Lọ́wọ́ Ibi?

Ade, a tó ń gbé ní orílẹ̀-èdè Niger, ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tó jẹ́ oníwàásù alákòókò kíkún. Ade ṣàlàyé ìdí tóun fi so tírà mọ́ ṣọ́ọ̀bù òun, ó ní: “Ọ̀pọ̀ ọ̀tá ló wà.” Ẹni tó ń kọ́ Ade lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sọ fún un pé Jèhófà nìkan la lè gbára lé fún ààbò tòótọ́. Ó ka ìwé Sáàmù 34:7 fún Ade, èyí tó sọ pé: “Áńgẹ́lì Jèhófà dó yí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ ká, ó sì ń gbà wọ́n sílẹ̀.” Ade wá sọ pé: “Bí Jèhófà bá lè dáàbò bò mí ní tòótọ́, màá yọ tírà náà kúrò.” Ó ti wá ń sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà àti òjíṣẹ́ alákòókò kíkún báyìí, ìyẹn ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn àkókò yẹn. Kò sì sí ìkankan nínú àwọn ọ̀tá rẹ̀ tó ti rí i gbé ṣe.

Bíbélì sọ pé ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀ ló ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wa, yálà a gba ohun asán gbọ́ tàbí a kò gbà á gbọ́. (Oníwàásù 9:11) Àmọ́ Jèhófà kò lè fi ohun búburú dán wa wò láé. (Jákọ́bù 1:13) Ẹ̀ṣẹ̀ tá a jogún látọ̀dọ̀ Ádámù ló fa ikú àti àìpé. (Róòmù 5:12) Látàrí èyí, olúkúlùkù wa ló ń ṣàìsàn lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan tá a sì ń ṣe àwọn àṣìṣe tí àbájáde rẹ̀ lè burú jáì. Nítorí náà, àṣìṣe gbáà ló jẹ́ láti máa sọ pé gbogbo àìsàn tá a bá ní ló ń wá látọ̀dọ̀ àwọn ẹ̀mí búburú. Irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ yóò wulẹ̀ mú ká máa gbìyànjú láti tu àwọn ẹ̀mí lójú láwọn ọ̀nà kan ni. b Nígbà tá a bá ń ṣàìsàn, ó yẹ ká lọ gba ìtọ́jú lọ́dọ̀ dókítà, kì í ṣe ká máa gba ìmọ̀ràn lọ́dọ̀ ẹni tó jẹ́ ‘òpùrọ́ àti baba irọ́,’ ìyẹn Sátánì Èṣù. (Jòhánù 8:44) Àkọsílẹ̀ oníṣirò fi hàn pé àwọn èèyàn tó ń gbé láwọn orílẹ̀-èdè tí ìgbàgbọ́ nínú ohun asán nípa àwọn baba ńlá ti wọ́pọ̀ kì í pẹ́ láyé ju àwọn tó wà lórílẹ̀-èdè mìíràn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kì í gbé ìgbésí ayé tó dára ju tàwọn ẹlòmíì lọ. Ó wá hàn gbangba pé ìgbàgbọ́ nínú ohun asán kò ṣàǹfààní kankan fún ìlera ara ẹni.

Ọlọ́run lágbára ju ẹ̀mí búburú èyíkéyìí lọ, Ó sì nífẹ̀ẹ́ sí ire wa. “Ojú Jèhófà ń bẹ lára àwọn olódodo, etí rẹ̀ sì ṣí sí ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ wọn.” (1 Pétérù 3:12) Gbàdúrà sí i pé kó fún ọ ní ààbò àti ọgbọ́n. (Òwe 15:29; 18:10) Sapá láti lóye Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Mímọ́ rẹ̀. Ìmọ̀ pípéye látinú Bíbélì ni ààbò dídára jù lọ tá a lè ní. Yóò ràn wá lọ́wọ́ láti mọ ìdí tí ohun búburú fi ń ṣẹlẹ̀ àti bí a ṣe lè rí ojú rere Ọlọ́run Olódùmarè.

Àwọn Àǹfààní Tó Wà Nínú Ìmọ̀ Ọlọ́run

Ìmọ̀ pípéye nípa Jèhófà àtàwọn ète rẹ̀—tó jẹ́ òdìkejì àìmọ̀kan àti ìgbàgbọ́ nínú ohun asán—ni olórí ohun tí ń fúnni ní ààbò tòótọ́. Èyí hàn kedere nínú ọ̀ràn Jean, ìyẹn ọkùnrin kan láti orílẹ̀-èdè Benin. Wọn kì í fi ìgbàgbọ́ nínú ohun asán ṣeré rárá nínú ìdílé Jean. Àṣà ìbílẹ̀ wọn ni pé obìnrin tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bí ọmọkùnrin gbọ́dọ̀ jókòó sínú abà àrà ọ̀tọ̀ kan fún ọjọ́ mẹ́sàn-án gbáko. Tó bá jẹ́ pé ọmọbìnrin ló bí, yóò wà nínú abà náà fún ọjọ́ méje.

Ní ọdún 1975, ìyàwó Jean bí ọmọkùnrin rírẹwà kan tí wọ́n sọ ní Marc. Nítorí ìmọ̀ Bíbélì tí wọ́n ní, Jean àti aya rẹ̀ kò fẹ́ ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú àwọn ẹ̀mí búburú. Àmọ́ ṣé wọ́n máa tìtorí ìbẹ̀rù àti ìyọlẹ́nu àwọn èèyàn tẹ̀ lé ìgbàgbọ́ nínú ohun asán, kí ìyá ọmọ náà sì wá lọ jókòó sínú abà ọ̀hún? Rárá o—wọn ò fara mọ́ àṣà ìgbàgbọ́ nínú ohun asán yìí rárá.—Róòmù 6:16; 2 Kọ́ríńtì 6:14, 15.

Ǹjẹ́ láburú kankan ṣẹlẹ̀ sí ìdílé Jean? Ọ̀pọ̀ ọdún ti kọjá lẹ́yìn ìgbà yẹn, Marc sì ti ń sìn gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ nínú ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò wọn. Inú ìdílé náà dùn gan-an pé àwọn ò jẹ́ kí ìgbàgbọ́ nínú ohun asán nípa lórí ìgbésí ayé àwọn, àwọn ò sì jẹ́ kí ó kó bá ire tẹ̀mí àwọn.—1 Kọ́ríńtì 10:21, 22.

Àwọn Kristẹni tòótọ́ gbọ́dọ̀ mú ohun tó jọ mọ́ àwọn àṣà búburú ti ìgbàgbọ́ nínú ohun asán kúrò nínú ìgbésí ayé wọn, kí wọ́n sì tẹ́wọ́ gba ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí tí Ẹlẹ́dàá náà, Jèhófà, àti Ọmọ rẹ̀, Jésù Kristi ń fúnni. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n lè wá gbádùn ìfọ̀kànbalẹ̀ téèyàn ń ní nígbà tó bá mọ̀ pé òun ń ṣe ohun tí ó tọ́ lójú Ọlọ́run—Jòhánù 8:32.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ padà.

b Wo àpilẹ̀kọ “Ṣé Èṣù Ló Ń Jẹ́ Ká Ṣàìsàn Ni?” nínú Ilé Ìṣọ́ September 1, 1999.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Àwọn Ìgbàgbọ́ Nínú Ohun Asán Tó Wọ́pọ̀ Kárí Ayé

• Kéèyàn jẹ́ kí igi ìjẹun wà lóòró nínú àwo ìrẹsì jẹ́ àmì pé èèyàn á kú

• Rírí òwìwí lọ́sàn-án gangan máa ń jẹ́ kéèyàn ṣorí burúkú

• Iná àbẹ́là tó ń kú lọ nígbà tí ayẹyẹ ń lọ lọ́wọ́ fi hàn pé àwọn ẹ̀mí búburú wà nítòsí

• Jíju agboòrùn sílẹ̀ẹ́lẹ̀ fi hàn pé wọ́n máa pa ẹnì kan nínú ilé yẹn

• Fífi fìlà sórí ibùsùn ń mú kéèyàn ṣorí burúkú

• Ìró aago máa ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù lọ

• Fífẹ́ gbogbo iná àbẹ́là tí wọ́n tàn sórí kéèkì ọjọ́ ìbí pa lẹ́ẹ̀kan náà ń mú kí gbogbo ohun tónítọ̀hún ń fẹ́ tẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́

• Tí ìgbálẹ̀ bá fara ti ibùsùn, àwọn ẹ̀mí búburú tó wà lára ìgbálẹ̀ náà á sà sínú ibùsùn ọ̀hún

• Tí ológbò dúdú bá dá ipasẹ̀ rẹ kọjá, àpẹẹrẹ orí burúkú ni

• Tí àmúga tá a fi ń jẹun bá dédé já bọ́ á jẹ́ pé ọkùnrin kan fẹ́ báni lálejò nìyẹn

• Akóredé ni àwòrán erin tó bá dojú kọ ilẹ̀kùn

• Pátákò ẹsẹ̀ ẹṣin tá a fi síbi àtẹ́rígbà máa kóre wọlé ẹni

• Ewéko Ivy tó hù sórí ilé máa ń bi ibi dà nù ni

• Orí burúkú ni kéèyàn máa rìn lábẹ́ àtẹ̀gùn

• Tí dígí bá bọ́ fọ́ lọ́wọ́ èèyàn, ó túmọ̀ sí pé ọdún méje gbáko lonítọ̀hún fi máa ṣorí burúkú

• Tí ata bá ṣèèṣì dà nù, ó túmọ̀ sí pé èdè àìyedè máa wáyé láàárín ìwọ àti ọ̀rẹ́ rẹ tímọ́tímọ́ nìyẹn

• Tí iyọ̀ bá dà nù lọ́wọ́ èèyàn, ó máa ń ṣokùnfà orí burúkú àyàfi tónítọ̀hún bá rọra bu iyọ̀ tínńtín sórí èjìká rẹ̀ òsì

• Jíjẹ́ kí àga kan máa mì láìsí ẹni tó jókòó lé e ń pe àwọn ẹ̀mí èṣù láti wá jókòó sórí rẹ̀

• Dída ojú bàtà dé máa ń fa orí burúkú

• Nígbà tí ẹnì kan bá kú, àwọn fèrèsé gbọ́dọ̀ wà ní ṣíṣí sílẹ̀ kí ọkàn onítọ̀hún lè kúrò nínú ilé náà

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]

Bíbọ́ Lọ́wọ́ Ipa Tí Ìgbàgbọ́ Nínú Ohun Asán Ń Ní Lórí Ẹni

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń wàásù lágbègbè kan ní Gúúsù Áfíríkà. Bí wọ́n ṣe kan ilẹ̀kùn ilé kan báyìí ni obìnrin kan tó wọ aṣọ Sangoma (adáhunṣe) jáde sí wọn. Wọ́n fẹ́ kúrò níbẹ̀, àmọ́ obìnrin náà sọ pé àfi dandan kí wọ́n jẹ́rìí fún òun. Ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí náà ka Diutarónómì 18:10-12 fún un kí ó lè rí ohun tí Bíbélì sọ nípa àwọn àṣà ìbẹ́mìílò. Adáhunṣe náà tẹ́wọ́ gba ìhìn náà, ó sì gbà pé kí wọ́n wá máa bá òun ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó sọ pé tí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà bá lè mú un dá òun lójú pé Jèhófà kò nífẹ̀ẹ́ sí iṣẹ́ Sangoma tí òun ń ṣe, òun á jáwọ́ níbẹ̀.

Lẹ́yìn tó kẹ́kọ̀ọ́ orí kẹwàá ìwé Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye pẹ̀lú Bíbélì tán, ó jó gbogbo ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú iṣẹ́ àjẹ́, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wá sáwọn ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ìyẹn nìkan kọ́ o, àní ó tún lọ fẹsẹ̀ ìgbéyàwó rẹ̀ múlẹ̀ lábẹ́ òfin, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọdún kẹtàdínlógún tó ti kúrò lọ́dọ̀ ọkọ rẹ̀ nìyẹn. Àwọn méjèèjì ti ya ara wọn sí mímọ́, wọ́n sì ti ṣe ìrìbọmi gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà báyìí.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

“Sangoma” kan ń da eegun sílẹ̀ láti mọ ohun tó fa àwọn ìṣòro aláìsàn kan

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Ìmọ̀ pípéye nípa Ọlọ́run ń mú ààbò àti ayọ̀ tòótọ́ wá