Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Mo Gbó Mo Sì Tọ́

Mo Gbó Mo Sì Tọ́

Ìtàn Ìgbésí Ayé

Mo Gbó Mo Sì Tọ́

GẸ́GẸ́ BÍ MURIEL SMITH ṢE SỌ Ọ́

Ilẹ̀kùn àbáwọlé mi fẹ́rẹ̀ẹ́ gbọ̀n yọ nígbà tẹ́nì kan bẹ̀rẹ̀ sí kàn án gbàgbàgbà. Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ darí wálé látòde ẹ̀rí ni pé kí n wá jẹun ọ̀sán. Omi tí màá fi po tíì ni mo gbé kaná bí ìṣe mi, mo sì ń múra láti sinmi fún ọgbọ̀n ìṣẹ́jú. Ẹni tó ń kanlẹ̀kùn náà ò mà yéé kanlẹ̀kùn o. Mo lọ sídìí ilẹ̀kùn pẹ̀lú kàyéfì nípa irú ẹni tó lè máa kanlẹ̀kùn lásìkò yìí. Kò sì pẹ́ tí mo fi rí onítọ̀hún. Àwọn ọkùnrin méjì tó wà lẹ́nu ọ̀nà mi sọ fún mi pé ọlọ́pàá làwọn. Wọ́n ní ńṣe làwọn wá tú ilé mi wò bóyá àwọn á rí àwọn ìwé táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tẹ̀—ìyẹn ètò àjọ tí wọ́n fòfin dè lásìkò náà.

Kí ló mú kí wọ́n fòfin de àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Ọsirélíà, báwo ni mo sì ṣe di ọ̀kan lára wọn? Ọdún 1910 lọ̀rọ̀ náà bẹ̀rẹ̀ bí eré nígbà tí màmá mi fún mi lẹ́bùn kan. Ọmọ ọdún mẹ́wàá ni mí nígbà náà.

ILÉ onígi ni ìdílé mi ń gbé ní ìgbèríko Crows Nest tó wà ní Ìlà Oòrùn ìlú Sydney. Mo ti ilé ìwé dé lọ́jọ́ kan ni mo bá màmá mi àti ọkùnrin kan tí wọ́n jọ ń sọ̀rọ̀ lẹ́nu ọ̀nà ìta. Mo fẹ́ mọ ẹni tí ọkùnrin àjèjì yìí tó múra dáadáa tòun ti àpò tí ìwé kúnnú rẹ̀ jẹ́. Mo fọgbọọgbọ́n tọrọ gáfárà mo sì wọnú ilé lọ. Àmọ́ kò ju ìṣẹ́jú bíi mélòó kan lẹ́yìn náà tí Màmá fi pè mí. Ó sọ pé: “Àwọn ìwé tó fani mọ́ra wà lọ́wọ́ ọ̀gbẹ́ni yìí o, gbogbo wọn ló sì sọ̀rọ̀ nípa Ìwé Mímọ́. Àmọ́ ní báyìí tí ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ẹ ti sún mọ́lé, ó o lè jẹ méjì lábà àlàdé o. Ńṣe lo máa yàn bóyá láti ra àwọn ìwé yìí tàbí aṣọ tuntun. Ó yá, èwo lo yàn?”

Mo dáhùn pé “Màmá mi, àwọn ìwé yẹn gan-an ni mo fẹ́, ẹ ṣeun.”

Bí mo ṣe dẹni tó ní ìdìpọ̀ mẹ́ta àkọ́kọ́ ìwé Studies in the Scriptures, tí Charles Taze Russell kọ nìyẹn o. Ọ̀gbẹ́ni náà sọ fún màmá mi pé àwọn ìwé náà lè ṣòro fún mi láti lóye, pé kí màmá gbìyànjú láti máa là á yé mi. Màmá sọ fún un pé kò síṣòro nínú ìyẹn. Àmọ́ kò pẹ́ sígbà yìí tí Màmá fi fi ilẹ̀ ṣaṣọ bora. Bàbá gbìyànjú gan-an láti tọ́jú èmi àti àbúrò mi ọkùnrin àtèyí obìnrin. Àmọ́ èmi náà ti wá ní ẹrù iṣẹ́ láti gbé báyìí, ó sì dà bí ẹni pé wọ́n fẹ́ pọ̀ ju agbára mi lọ. Àṣé kékeré ni ti ikú màmá, àjálù mìíràn ṣì ń bọ̀ níwájú.

Ogun Àgbáyé Kìíní bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1914. Ọdún kan péré lẹ́yìn náà ni wọ́n pa bàbá wa ọ̀wọ́n. Ní báyìí, a ti di ọmọ òrukàn. Àbúrò mi ọkùnrin àti àbúrò mi obìnrin lọ ń gbé lọ́dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí wa, wọ́n rán èmi lọ sí ilé ẹ̀kọ́ táwọn Kátólíìkì dá sílẹ̀ ibẹ̀ ni mo sì ń gbé. Àwọn ìgbà míì wà tí ìnìkanwà á mú kí gbogbo nǹkan tojú sú mi. Síbẹ̀, mo ṣì ń dúpẹ́ pé wọ́n fún mi láǹfààní láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa orin, pàápàá nípa dùrù títẹ̀ nítorí pé mo fẹ́ràn rẹ̀ púpọ̀. Ọdún ń gorí ọdún, mo sì gboyè jáde nílé ẹ̀kọ́. Nígbà tó di 1919, mo fẹ́ Roy Smith tó ń ta àwọn ohun èèlò orin. Ní 1920, a bí ọmọ kan, àwọn àníyàn ìgbésí ayé sì tún bò mí mọ́lẹ̀. Àmọ́ àwọn ìwé ọjọ́ kìíní àná ń kọ́?

Aládùúgbò Mi Kan Nípìn-ín Nínú Òtítọ́ Tẹ̀mí

Ní gbogbo ọdún wọ̀nyẹn, bí ìgbín fà ìkarawun a tẹ̀ lé e lọ̀rọ̀ èmi àtàwọn “Ìwé Bíbélì” wọ̀nyẹn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé mi ò tíì fi bẹ́ẹ̀ kà wọ́n, mo mọ̀ lọ́kàn mi pé àwọn ìsọfúnni tó ṣe pàtàkì ló wà nínú wọn. Lọ́jọ́ kan ní apá ìparí àwọn ọdún 1920 sí 1929, Lil Bimson tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn aládùúgbò wa wá kí wa. A lọ sí pálọ̀, a jókòó síbẹ̀ a sì ń mu tíì.

Àfi ẹ̀ẹ̀kan náà tó sọ pé: “Ẹ̀n ẹ́n, o tiẹ̀ láwọn ìwé yìí!

Pẹ̀lú ìyàlẹ́nu ni mo fi béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Àwọn ìwé wo?”

Ó wá nawọ́ sáwọn ìwé Studies in the Scriptures tó wà nínú àpótí ìwé. Lil yá àwọn ìwé náà lọ sílé rẹ̀ lọ́jọ́ náà ó sì kà wọ́n tìtaratìtara. Kò pẹ́ tí ìfẹ́ tó ní sí àwọn nǹkan tó kà fi fara hàn. Ó gba àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ sí i lọ́dọ̀ àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, gẹ́gẹ́ bá a ṣe mọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sí nígbà náà. Kò tán síbẹ̀ o, gbogbo nǹkan tó ń kẹ́kọ̀ọ́ pátá ló máa ń sọ fún wa. Ọ̀kan lára àwọn ìwé tó gbà ni ìwé Duru Ọlọrun, kò sì pẹ́ tí ìwé náà fi dé ilé wa. Ìgbésí ayé mi nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà bẹ̀rẹ̀ nígbà tí mo ya àkókò sọ́tọ̀ láti ka àwọn ìwé wọ̀nyí tá a gbé ka Bíbélì. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, mo wá rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè tó ṣe kókó tí ṣọ́ọ̀ṣì tí mò ń lọ ò lè dáhùn.

Ọlọ́run tún bá mi ṣe é, Roy náà nífẹ̀ẹ́ sáwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì púpọ̀, àwa méjèèjì sì di ẹni tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì gan-an. Tẹ́lẹ̀ Roy wà nínú Ẹgbẹ́ Ògbóni. Àmọ́ ní báyìí, ìdílé wa ti ń fi ìrẹ́pọ̀ ṣe ìsìn tòótọ́. Ẹ̀ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ láàárín ọ̀sẹ̀ ni arákùnrin kan máa ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú gbogbo ìdílé wa. A tún rí ìṣírí gbà síwájú sí i nígbà tá a bẹ̀rẹ̀ sí lọ sí ìpàdé àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Gbọ̀ngàn kékeré kan tí wọ́n háyà ní apá ìgbèríko ìlú Newtown la ti ń ṣèpàdé ní Sydney. Gbogbo àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà lórílẹ̀-èdè náà lákòókò tá à ń wí yìí kò tó irínwó. Nítorí náà, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ará gbọ́dọ̀ rin ọ̀nà jíjìn gan-an kí wọ́n tó lè wá sípàdé.

Kí ìdílé wa tó lè dé ìpàdé, a máa ń gba orí omi tó wà níbi Èbúté Ọkọ̀ Ojú Omi tó wà nílùú Sydney kọjá. Kí wọ́n tó ṣe Afárá síbẹ̀ lọ́dún 1932, ọkọ̀ ojú omi ló máa ń gbé wa kọjá nígbàkigbà tá a bá fẹ́ gbabẹ̀. Pẹ̀lú bí ìrìn náà ṣe ń ná wa lákòókò tó sì tún ń ná wa lówó tó, a sapá láti rí i pé a ò pàdánù oúnjẹ tẹ̀mí èyíkéyìí tí Jèhófà ń pèsè. Ìsapá tá a sì ṣe láti jẹ́ kí òtítọ́ fìdí múlẹ̀ gbọn-in nínú wa bọ́ sákòókò gan-an ni nítorí pé Ogun Àgbáyé Kejì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ bẹ́ sílẹ̀ nígbà náà, bẹ́ẹ̀ sì ni ọ̀rọ̀ àìdásí-tọ̀túntòsì máa han ìdílé wa léèmọ̀.

Àkókò Àdánwò àti Ìbùkún

Àkókò tó ń mú ọkàn yọ̀ ni ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1930 sí 1939 jẹ́ fún èmi àti ìdílé mi. Ọdún 1930 ni mo ṣèrìbọmi. Lọ́dún 1931, mo wà ní àpéjọ mánigbàgbé náà níbi tí gbogbo wa ti dìde dúró tá a sì fohùn ṣọ̀kan láti máa jẹ́ orúkọ dáradára náà Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Èmi àti Roy sapá gidigidi láti máa gbé níbàámu pẹ̀lú orúkọ yẹn nípa kíkópa nínú gbogbo ọ̀nà tá a fi ń ṣiṣẹ́ ìwàásù àtàwọn ìgbòkègbodò mìíràn tí ètò àjọ náà bá ní ká ṣe. Bí àpẹẹrẹ, ní 1932, a ṣe ìpínkiri ìwé pẹlẹbẹ kan lọ́nà àkànṣe. A pín ìwé pẹlẹbẹ yìí fún ẹgbàágbèje èèyàn tó wá síbi ayẹyẹ ṣíṣí Afárá tí wọ́n ṣe síbi Èbúté Ọkọ̀ Ojú Omi tó wà nílùú Sydney. Ohun kan tó jẹ́ àkànṣe nínú ìgbòkègbodò yìí ni pé a lo àwọn ọkọ̀ tó ní ohun èlò gbohùngbohùn. Èyí sì jẹ́ àǹfààní ńlá fún wa nítorí pé wọ́n fi ẹ̀rọ̀ gbohùngbohùn sínú ọkọ̀ ìdílé wa. Ìmọ̀ ẹ̀rọ yìí la lò tí gbogbo òpópó ìlú Sydney fi ń dún lọ́tùn-ún-lósì fún àsọyé Bíbélì tí Arákùnrin Rutherford sọ.

Àmọ́, ìgbà ò lọ bí òréré, ipò nǹkan bẹ̀rẹ̀ sí yí padà ó sì túbọ̀ ń le koko sí i. Nígbà tó fi máa di 1932, Ìlọsílẹ̀ Gígadabú Nínú Ọrọ̀ Ajé ṣe orílẹ̀-èdè Ọsirélíà báṣubàṣu, èyí sì mú kí èmi àti Roy pinnu láti mú àwọn nǹkan rọrùn sí i nínú ìgbésí ayé wa. Ọ̀kan lára ọ̀nà tá a gbà ṣe èyí ni pé a ṣí lọ sítòsí ibi tí ìjọ wa ti ń ṣèpàdé, èyí sì mú kí owó tá a fi ń wọkọ̀ dín kù. Àmọ́ ṣá, ètò ọrọ̀ ajé tí ò dára yìí kò wá tó nǹkan kan tá a bá fi wéra pẹ̀lú ìpayà tí Ogun Àgbáyé Kejì kó bá gbogbo ayé.

Àwọn èèyàn dojú inúnibíni kọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé nítorí wọ́n ń tẹ̀ lé àṣẹ Jésù pé wọn kì í ṣe apá kan ayé. Èyí sì kan àwọn tó wà ní orílẹ̀-èdè Ọsirélíà náà. Ìrunú àkókò ogun yìí mú káwọn kan bẹ̀rẹ̀ sí i pè wá ní ẹlẹ́sìn Kọ́múníìsì. Àwọn alátakò yìí parọ́ pé ńṣe làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lo ilé iṣẹ́ rédíò mẹ́rin tí wọ́n ní ní Ọsirélíà láti fi ìsọfúnni ránṣẹ́ sí ọmọ ogun ilẹ̀ Japan.

Wọ́n fúngun mọ́ àwọn arákùnrin ọ̀dọ́ tí wọ́n ní kí wọ́n wá wọṣẹ́ ológun. Inú mi dùn láti sọ pé àwọn ọmọkùnrin wa mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ló fọwọ́ dan-indan-in mú ohun tí wọ́n gbà gbọ́, wọn ò dá sí tọ̀túntòsì. Wọ́n ní kí ọmọkùnrin wa tó dàgbà jù, ìyẹn Richard lọ fi ẹ̀wọ̀n ọdún kan àtààbọ̀ jura. Ọmọkùnrin wa kejì, ìyẹn Kevin forúkọ sílẹ̀ pé ẹ̀rí ọkàn òun ò ṣe iṣẹ́ ológun. Àmọ́ ṣá, àbígbẹ̀yìn wa, Stuart, ní tiẹ̀ kú nínú jàǹbá tó ṣẹlẹ̀ sí i lórí alùpùpù nígbà tó ń lọ sí kóòtù láti lọ parí ẹjọ́ tí wọ́n pè é nítorí pé kò dá sí tọ̀túntòsì. Àjálù náà mu wa lómi gan-an. Síbẹ̀, fífi tá a fi Ìjọba náà sọ́kàn àti ìlérí àjíǹde tí Jèhófà ṣe jẹ́ ká lè mú un mọ́ra.

Ohun Tí Wọ́n Wá Wá Gangan Kọ́ Ni Wọ́n Rí

Wọ́n fòfin de àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tá a wà ní Ọsirélíà ní January 1941. Àmọ́ ńṣe lèmi àti Roy ṣe bíi tàwọn àpọ́sítélì Jésù, Ọlọ́run la ṣègbọràn sí gẹ́gẹ́ bí aláṣẹ kì í ṣe èèyàn. À ń bá iṣẹ́ wa lọ lábẹ́lẹ̀ fún odidi ọdún méjì àtààbọ̀. Àárín àkókò yìí làwọn ọlọ́pàá méjì tí ò wọṣọ tí mo mẹ́nu bà níbẹ̀rẹ̀ kan ilẹ̀kùn mi. Kí ló wá ṣẹlẹ̀?

Tóò, mo ní kí wọ́n wọlé. Bí wọ́n sì ṣe wọlé ni mo béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ǹjẹ́ ẹ lè jẹ́ kí n mu tíì ọwọ́ mi yìí tán kẹ́ ẹ tó bẹ̀rẹ̀ sí tú inú ilé?” Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún mi pé wọ́n gbà. Mo yáa wọ ilé ìgbọ́únjẹ lọ láti gbàdúrà sí Jèhófà kí n sì tún ronú àwọn nǹkan tí màá sọ. Nígbà tí mo padà dé, ọ̀kan lára àwọn ọlọ́pàá náà wọ ibi tá a ti ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ó sì kó gbogbo nǹkan tó bá ṣáà ti ní òǹtẹ̀ Ilé Ìṣọ́ lára, títí kan àwọn ìwé tó wà nínú àpò òde ẹ̀rí mi àti Bíbélì mi.

Ó wá bi mi pé “Ṣó dá ẹ lójú pé kò ku àwọn ìwé mìíràn tó o tọ́jú pa mọ́ sínú páálí? Ohun tá a gbọ́ ni pé ẹ máa ń lọ sí ìpàdé kan lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ ní gbọ̀ngàn kan tó wà lópin òpópónà yìí àti pé ẹ máa ń kó ọ̀pọ̀ ìwé lọ síbẹ̀.”

Mo dá a lóhùn pé, “Òótọ́ lo sọ, àmọ́ àwọn ìwé náà ò sí níbẹ̀ báyìí.”

Ọlọ́pàá náà tún ní “Bẹ́ẹ̀ ni, a mọ ìyẹn, ìyáàfin Smith. A sì tún mọ̀ pé inú ilé àwọn èèyàn lágbègbè yìí lẹ kó àwọn ìwé náà sí.”

Wọ́n rí páálí ìwé márùn-ún nínú yàrá ọmọ wa, ìwé pẹlẹbẹ Freedom or Romanism, ló sì wà nínú wọn.

Ó tún béèrè pé “Ṣó dá ẹ lójú pé kò sí ìwé kankan níbi tẹ́ ẹ̀ ń gbé ọkọ̀ sí?”

Mo ní “Rárá o, kò sí ohunkóhun níbẹ̀.”

Ni ọlọ́pàá yìí bá ṣí àpótí kan tó wà nínú ilé ìjẹun. Ó rí àwọn fọ́ọ̀mù tá à ń kọ ìròyìn ìjọ sí, àmọ́ a ò tíì kọ nǹkan kan sínú wọn. Ó palẹ̀ gbogbo wọn mọ́ ó sì sọ pé dandan òun gbọ́dọ̀ wo ibi tá à ń gbé ọkọ̀ sí.

Ni mo bá sọ fún un pé, “Ó yá, ẹ ká lọ.”

Wọ́n tẹ̀ lé mi lọ síbi tá à ń gbé ọkọ̀ sí, lẹ́yìn tí wọ́n yẹ ibẹ̀ wò tán, wọ́n lọ.

Àwọn ọlọ́pàá yìí rò pé ohun tó ṣeyebíye ló wà nínú páálí márààrún táwọn kó! Àmọ́, ohun tí wọ́n torí ẹ̀ wá gan-an ṣì wà nínú ilé. Bó ṣe jẹ́ ni pé, èmi ni akọ̀wé ìjọ nígbà yẹn, ìwé tí orúkọ gbogbo àwọn akéde wà nínú rẹ̀ wà lọ́wọ́ mi, àwọn ìsọfúnni mìíràn sì tún wà lọ́wọ́ mi pẹ̀lú. Àmọ́ mo dúpẹ́ pé àwọn ará ti kì wá nílọ̀ tẹ́lẹ̀ pé àwọn ọlọ́pàá lè wá yẹ ilé wò o. Èmi náà sì ti tọ́jú àwọn ìwé wọ̀nyẹn dáadáa. Mo kó wọn sínú àwọn àpòòwé mo sì fi wọ́n sábẹ́ agolo tíì, agolo ṣúgà àti agolo ìyẹ̀fun. Mo tún kó àwọn kan pa mọ́ sínú ilé ẹyẹ, èyí tó wà nítòsí ibi tá à ń gbé ọkọ̀ sí. Àwọn ọlọ́pàá wọ̀nyí sì ti kọjá lára ìsọfúnni tí wọ́n torí ẹ̀ wá gan-an.

Wíwọnú Iṣẹ́ Ìsìn Alákòókò Kíkún

Nígbà tó fi máa di 1947, àwọn tó dàgbà ju nínú àwọn ọmọ wa ti ní ìdílé tiwọn. Nígbà tí èmi àti Roy rí i bẹ́ẹ̀, a wá sọ pé ó máa ṣeé ṣe fún wa láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Àìní pọ̀ ní apá Gúúsù Ọsirélíà nígbà náà, èyí ló mú ká ta ilé wa tá a sì ra ilé alágbèérìn kan tá a pe orúkọ rẹ̀ ní Mísípà, tó túmọ̀ sí “Ilé Ìṣọ́.” Irú ìgbésí ayé tá à ń gbé yìí mú kó ṣeé ṣe fún wa láti lọ wàásù láwọn ìgbèríko. Lọ́pọ̀ ìgbà la máa ń wàásù láwọn àgbègbè tí a ò yàn fúnni. Inú mi máa ń dùn tí mo bá ti ń rántí àwọn àkókò yẹn. Lára àwọn tí mo bá ṣèkẹ́kọ̀ọ́ ni ọ̀dọ́mọbìnrin kan tó ń jẹ́ Beverly. Ó kúrò lágbègbè yìí kó tó tó àsìkò tó máa ṣèrìbọmi. Mi ò lè sọ bí inú mi ṣe dùn tó ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà tí arábìnrin kan wá bá mi ní àpéjọ àgbègbè kan tó sì sọ fún mi pé òun ni Beverly! Mo láyọ̀ gan-an pé lẹ́yìn gbogbo ọdún wọ̀nyẹn, òun àti ọkọ rẹ̀ àtàwọn ọmọ rẹ̀ ń sin Jèhófà.

Mo láǹfààní láti lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Aṣáájú Ọ̀nà ní 1979. Ọ̀kan lára àwọn ohun tí wọ́n tẹnu mọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ náà ni pé téèyàn bá fẹ́ gbó kó sì tọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà, onítọ̀hún gbọ́dọ̀ máa dá kẹ́kọ̀ọ́ déédéé. Mo sì rí i pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí. Kò sóhun mìíràn tí mò ń fi ìgbésí ayé mi ṣe ju kí n kẹ́kọ̀ọ́, kí n lọ sípàdé àti òde ẹ̀rí. Àǹfààní ńlá ni mò kà á sí pé mo ti ń sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà déédéé fún ohun tó lé ní àádọ́ta ọdún.

Fífarada Ìṣòro Àìlera

Bó ti wù ó rí, mo kojú àwọn ìpèníjà líle koko kan láti àwọn ẹ̀wádún bíi mélòó kan sẹ́yìn. Lọ́dún 1962, àyẹ̀wò fi hàn pé mo lárùn glaucoma. Lákòókò yìí, kò fi bẹ́ẹ̀ sí ìtọ́jú kan tó ṣe sàn-án, kò sì pẹ́ rárá tí ojú mi fi bẹ̀rẹ̀ sí ṣe bàìbàì. Roy náà di olókùnrùn kalẹ̀. Ní 1983, àrùn ẹ̀gbà kọ lù ú. Ńṣe ló di jọwọlọ kalẹ̀ tí ò lè sọ̀rọ̀ mọ́. Ó kú ní 1986. Ìtìlẹyìn tó ṣe fún mi nígbà tí mo wà nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún kọjá kèrémí. Àárò rẹ̀ ń sọ mi gan-an ni.

Pẹ̀lú gbogbo ìṣòro wọ̀nyí, mi ò fọwọ́ yẹpẹrẹ mú nǹkan tẹ̀mí rárá. Mo ra ọkọ̀ kan tára rẹ̀ gbàyà dáadáa, tó dára fún iṣẹ́ ìjẹ́rìí láwọn ìgbèríko. Ọmọbìnrin mi Joyce sì ràn mí lọ́wọ́ láti máa bá iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà mi lọ. Ìṣòro ojú mi burú sí i débi pé ojú mi kan fọ́ pátápátá. Àwọn dókítà sì fi ojú oníke rọ́pò rẹ̀. Síbẹ̀, lọ́lá gíláàsì amúǹkan-tóbi tí mò ń lò àtàwọn ìwé tá a fi lẹ́tà gàdàgbà kọ, mo ṣì ń fi ojú kan tó kù kẹ́kọ̀ọ́ fún wákàtí mẹ́ta sí márùn-ún.

Àkókò tó ṣeyebíye ni àkókò ìkẹ́kọ̀ọ́ jẹ́ fún mi. Èyí lè jẹ́ kẹ́ ẹ finú wo bí ọkàn mi ṣe dàrú tó nígbà tí mò ń kàwé lọ́sàn-án ọjọ́ kan tó wá di pé lójijì, mi ò rí nǹkan kan mọ́. Ńṣe ló dà bí ẹni pé ẹnì kan ló paná. Bí ojú mi méjèèjì ò ṣe ríran mọ́ nìyẹn o. Báwo wá ni mo ṣe ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ mi? Bó tiẹ̀ jẹ́ pé mo ti di odi báyìí, àwọn kásẹ́ẹ̀tì àtẹ́tígbọ́ àti ìtìlẹ́yìn onífẹ̀ẹ́ ìdílé mi ti jẹ́ kára mi le nípa tẹ̀mí.

Fífara Dà Á Títí Dé Òpin

Ní báyìí tí mo ti lé lọ́gọ́rùn-ún ọdún, àwọn nǹkan mìíràn wà tó tún ti ṣèpalára fún ìlera mi. Ó sì ti gba pé kí n máa tẹ̀ ẹ́ jẹ́jẹ́. Nígbà mìíràn, ńṣe ni gbogbo nǹkan á pòrúurùu mọ́ mi lọ́kàn. Àní, ní báyìí tí kò sí ojú mọ́, ńṣe ni mo kàn máa ń táràrà kiri nígbà míì! Ó wù mí kí n ní ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sí i, àmọ́ mi ò lè jáde lọ wá àwọn èèyàn nítorí ipò àìlera mi. Tẹ́lẹ̀, ọ̀rọ̀ ọ̀hún máa ń mú mi sorí kọ́. Àmọ́ ó ti di pé kí n mọ ibi tágbára mi mọ kí n sì gbà kámú pẹ̀lú ìwọ̀nba tí mo bá lè ṣe. Èyí ò rọrùn ṣáá o. Síbẹ̀, ṣìnkìn ni inú mi máa ń dùn pé mo ṣì ń ròyìn iye àkókò díẹ̀ tí mo fi ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà Ọlọ́run wa lóṣooṣù. Ìgbàkigbà tí àǹfààní bá yọ láti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì, bóyá àwọn nọ́ọ̀sì, àwọn oníṣòwò àtàwọn tó bá wá sílé mi, mo máa ń fi ọgbọọgbọ́n lo àǹfààní náà láti bá wọn sọ̀rọ̀.

Ọ̀kan lára àwọn ìbùkún tó ń múnú mi dùn jù lọ ni bí mo ṣe rí àtìrandíran mi títí dé ìran kẹrin tí wọ́n ń fi tọkàntọkàn sin Jèhófà. Lára wọn ń sìn bí òjíṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà láwọn ibi tí àìní gbé pọ̀, àwọn míì ń sìn bí alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, àti ní Bẹ́tẹ́lì. Lóòótọ́, èmi náà ti retí pé òpin ètò àwọn nǹkan yìí á ti dé ṣáájú àkókò yìí gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ àwọn ẹgbẹ́ mi ṣe rò. Àmọ́ ìbísí tí mo ti rí láàárín àádọ́rin ọdún ti mo fi ṣe iṣẹ́ ìsìn kọyọyọ! Lílọ́wọ́ tí mo lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ kíkọyọyọ yìí ń fún mi ní ìtẹ́lọ́rùn ńláǹlà.

Àwọn nọ́ọ̀sì tó máa ń wá sọ́dọ̀ mi sọ pé ó ní láti jẹ́ pé ìgbàgbọ́ mi ló jẹ́ kí n ṣì wà láàyè. Òótọ́ sì ni wọ́n sọ. Ṣíṣe déédéé nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ló ń fún èèyàn ní ìgbésí ayé tó dára jù lọ. Èmi náà lè sọ pé mo gbó mo sì tọ́ dáadáa bíi ti Dáfídì Ọba.—1 Kíróníkà 29:28.

(Arábìnrin Muriel Smith kú ní April 1, 2002, nígbà tó kù díẹ̀ ká parí iṣẹ́ lórí àpilẹ̀kọ yìí. Oṣù kan péré ló kù kó pé ẹni ọdún méjìlélọ́gọ́rùn-ún. Ká sòótọ́, àwòfiṣàpẹẹrẹ ló jẹ́ nínú ìṣòtítọ́ àti ẹ̀mí ìfaradà.)

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Fọ́tò ìgbà tí mo wà ní nǹkan bí ọmọ ọdún márùn-ún àti ti ìgbà tí mo mọ Roy ọkọ mi lọ́mọ ọdún mọ́kàndínlógún

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Ọkọ̀ wa àti ilé alágbèérìn tá a pe orúkọ rẹ̀ ní Mísípà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

Èmi àti Roy, ọkọ mi lọ́dún 1971