Yoga—Ṣé Eré Ìmárale Lásán Ni àbí Nǹkan Míì Wà Ńbẹ̀?
Yoga—Ṣé Eré Ìmárale Lásán Ni àbí Nǹkan Míì Wà Ńbẹ̀?
KÉÈYÀN jẹ́ ọ̀pẹ́lẹ́ńgẹ́ kí ara rẹ̀ sì dá ṣáṣá làṣà tó gbòde lónìí. Èyí ti sọ ọ̀pọ̀ èèyàn dẹni tó ń lọ sí gbọ̀ngàn eré ìfarapitú, tí wọ́n sì ń dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ ètò ìlera. Ìdí kan náà yìí ló mú kí ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn tó wà ní Ìwọ̀ Oòrùn ayé dẹni tó ń kópa nínú yoga tí àwọn ará Ìhà Ìlà Oòrùn ayé máa ń ṣe.
Àwọn tó ní ìṣòro másùnmáwo, ìsoríkọ́, àti ìjákulẹ̀ pẹ̀lú ń yíjú sí yoga fún ìtùnú àti ojútùú sí ìṣòro wọn. Àgàgà láti àwọn ọdún 1960 sí 1969, tí í ṣe ẹ̀wádún àwọn abẹ́gbẹ́yodì àtàwọn èyí tó ń ṣonígbọ̀wọ́ ìfẹ́, ẹwà, àti àlàáfíà, làwọn èèyàn ti ń fìfẹ́ hàn sí àwọn ìsìn Ìhà Ìlà Oòrùn ayé tí àṣà ìbẹ́mìílò wọn sì di èyí tó tàn káàkiri Ìhà Ìwọ̀ Oòrùn ayé. Ṣíṣàṣàrò bíi tàwọn ẹlẹ́sìn Híńdù, tó fẹ́ fara jọ yoga, ni àwọn tó ń ṣe fíìmù àtàwọn olórin rọ́ọ̀kì ti sọ di ohun tó gbajúmọ̀. Níwọ̀n bí yoga ti wá di ohun tó túbọ̀ ń gba ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́kàn, a lè béèrè pé: ‘Ṣé yoga wulẹ̀ jẹ́ eré ìmárale tó kàn máa jẹ́ káwọn tó ń ṣe é ní ìlera tó dára, tá á sọ wọ́n di ọ̀pẹ́lẹ́ńgẹ́, tí wọ́n á sì ní ìbàlẹ̀ ọkàn ni? Ǹjẹ́ èèyàn lè ṣe yoga láìní ohunkóhun tó jẹ mọ́ ọ̀ràn ẹ̀sìn nínú? Ǹjẹ́ yoga tiẹ̀ dára fún Kristẹni?’
Bí Yoga Ṣe Bẹ̀rẹ̀
Ojúlówó ọ̀rọ̀ Sanskrit fún yoga lè túmọ̀ sí “àjàgà.” Ó lè túmọ̀ sí láti so nǹkan pọ̀ mọ́ra tàbí láti mú ohun kan wá sábẹ́ àjàgà, láti kó nǹkan níjàánu tàbí láti darí rẹ̀. Lójú ẹlẹ́sìn Híńdù, yoga jẹ́ ọgbọ́n kan tàbí ọ̀nà kan tó lè mú kéèyàn wà níṣọ̀kan pẹ̀lú agbára tó ju ti ẹ̀dá lọ tàbí pẹ̀lú ẹni ẹ̀mí kan. Wọ́n ti ṣàpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi “síso gbogbo agbára ti ara, ti èrò inú àti ti ọkàn pọ̀ mọ́ Ọlọ́run.”
Báwo ni àkókò tí yoga ti wà ṣe pẹ́ tó nínú ìtàn? Àwòrán àwọn èèyàn tí wọ́n jókòó ní onírúurú ipò yoga wà lára àwọn ohun tí wọ́n gbẹ́ sí Àfonífojì Indus, tó wà ní ilẹ̀ Pakistan. Àwọn awalẹ̀pìtàn sọ pé ọ̀làjú Àfonífojì Indus ti bẹ̀rẹ̀ láti àárín ẹgbẹ̀rúndún kẹta sí ẹgbẹ̀rúndún kejì ṣááju Sànmánì Tiwa, ìyẹn sì sún mọ́ àkókò àṣà Jẹ́nẹ́sísì 10:8, 9) Àwọn ẹlẹ́sìn Híńdù gbà pé àwọn àwòrán tó jókòó nípò yoga yẹn jẹ́ ère ọlọ́run Siva, tó jẹ́ olúwa àwọn ẹranko àti olúwa yoga, tí wọ́n sábà ń jọ́sìn nípasẹ̀ ohun kan tó ní ìrísí ẹ̀yà ìbímọ akọ. Ìdí nìyẹn tí ìwé Hindu World fi pe yoga ní “ìlànà àṣà ìṣẹ́ra-ẹni-níṣẹ̀ẹ́, tó bẹ̀rẹ̀ ṣáájú ìgbà ayé àwọn Aryan, tó ní àwọn ohun ìrántí ọ̀pọ̀ ohun tó jẹ́ èrò àti àṣà ayé ìgbàanì nínú.”
ìbílẹ̀ àwọn ará Mesopotámíà gan-an. Àwọn iṣẹ́ ọnà tí wọ́n kó wá láti àgbègbè méjèèjì fi ọkùnrin kan hàn, tó dúró fún ọlọ́run àjúbàfún, tí wọ́n fi ìwo ẹran dé ládé, tí àwọn ẹranko sì sọgbà yí i ká, èyí tó ránni létí Nímírọ́dù, “ọdẹ alágbára ńlá.” (Ọ̀rọ̀ ẹnu lásán ni wọ́n kọ́kọ́ fi ń ta àtaré ọ̀nà tí wọ́n gbà ń ṣe yoga. Ẹ̀yìn ìgbà yẹn ni Patañjali ọmọ ilẹ̀ Íńdíà tó jẹ́ amòye nínú ìmọ̀ yoga wá kọ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa rẹ̀ sílẹ̀, ó pè é ní Yoga Sutra, tó jẹ́ olórí ìwé ìtọ́ni nípa yoga títí di bí a ti ń sọ̀rọ̀ yìí. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Patañjali sọ, yoga jẹ́ “ìsapá ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé láti dé ìjẹ́pípé, nípasẹ̀ ìdarí onírúurú àwọn ohun tó pilẹ̀ àbùdá ènìyàn, èyí tó ṣeé fojú rí àti èyí tí kò ṣeé fojú rí.” Látìgbà tó ti bẹ̀rẹ̀ títí di àkókò tá a wà yìí ni yoga ti jẹ́ apá tó ṣe pàtàkì nínú ìjọsìn ìhà Ìlà Oòrùn ayé, àgàgà nínú Ìsìn Híńdù, Ìsìn Jaini, àti Ìsìn Búdà báyìí. Àwọn kan lára àwọn tó máa ń ṣe yoga gbà gbọ́ pé á mú wọn rí ìdáǹdè gbà, nípasẹ̀ bíbá ẹ̀mí kan lò.
Nítorí náà, a tún béèrè lẹ́ẹ̀kan sí i pé: ‘Ǹjẹ́ èèyàn lè máa ṣe yoga gẹ́gẹ́ bí eré ìmárale lásán láti ní ara tó dá ṣáṣá àti ìfọ̀kànbalẹ̀, láìní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú ìsìn?’ Lójú bó ṣe bẹ̀rẹ̀ yẹn, rárá ni ìdáhùn ìbéèrè náà.
Ibo Ni Yoga Lè Sún Ọ Dé?
Ète táwọn èèyàn fi ń ṣe yoga gẹ́gẹ́ bí àṣà kan ni pé kó lè sún wọn débí tí wọ́n ti máa rí i pé a “so wọ́n pọ̀ mọ́” ẹ̀mí kan tó lágbára ju ẹ̀dá lọ. Àmọ́ ẹ̀mí wo nìyẹn lè jẹ́?
Ohun tí òǹkọ̀wé Benjamin Walker sọ nípa yoga nínú ìwé Hindu World, ni pé: “Ó lè jẹ́ pé ibi tí idán pípa ti bẹ̀rẹ̀ nìyẹn, ìtumọ̀ yoga ṣì fi hàn títí di òní yìí pé ó ní í ṣe pẹ̀lú ẹgbẹ́ òkùnkùn àti iṣẹ́ oṣó.” Àwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí ti ìsìn Híńdù gbà pé ṣíṣe yoga lè fúnni ní àwọn agbára tó ju ti ẹ̀dá lọ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n sábà máa ń sọ pé kì í ṣe ohun tí wọ́n ń torí ẹ̀ ṣe yoga nìyẹn. Bí àpẹẹrẹ, nínú ìwé Indian Philosophy, ààrẹ ilẹ̀ Íńdíà tẹ́lẹ̀, Ọ̀mọ̀wé S. Radhakrishnan, sọ nípa yogi pé ó “máa ń darí ara nípasẹ̀ béèyàn bá ṣe dúró láìka bí ooru àti òtútù ṣe pọ̀ tó sí. . . . Àwọn tó ń ṣe yoga lè rí ohun tó wà lọ́nà jíjìn, wọ́n sì lè gbọ́rọ̀ láti ọ̀nà jíjìn . . . Ó ṣeé ṣe kí ẹni méjì máa fèrò wérò láìsí pé àwọn méjèèjì jíjọ sọ̀rọ̀ pọ̀. . . . Ẹni tó ń ṣe yoga lè ṣe ara rẹ̀ lọ́nà tá á fi wà níbì kan táwọn èèyàn ò sì ní rí i.”
Àwòrán ẹni kan tó ń ṣe yoga tá a rí tó sùn sórí bẹ́ẹ̀dì tí ìṣó wà tàbí ti èyí tó ń rìn lórí ẹyin iná lè dà bí idán lójú àwọn kan, kó sì jẹ́ ohun apanilẹ́rìn-ín fún àwọn ẹlòmíràn. Àmọ́ ìwọ̀nyí kì í ṣe ohun àjèjì rárá nílẹ̀ Íńdíà, gẹ́gẹ́ bí kò ṣe jẹ́ ohun àjèjì níbẹ̀ pé kéèyàn dúró lórí ẹsẹ̀ kan kó sì lajú sóòrùn fún ọ̀pọ̀ wákàtí àti kéèyàn sé èémí débi tí wọ́n á fi gbé onítọ̀hún sin tí wọ́n á sì da erùpẹ̀ bò ó fún àkókò gígùn. Ní June, 1995, ìwé ìròyìn The Times of India ròyìn pé ọmọdébìnrin kan tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ta ààbọ̀ sùn lọ nínú ẹ̀mí nígbà tí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan tó wọn ohun tó lé ní àádọ́ta dín lẹ́gbẹ̀rin [750] kìlógíráàmù rìn kọjá lórí ikùn rẹ̀. Ohun tó ya àwọn èrò tó ń wòran lẹ́nu jù lọ ni pé ọmọ náà kò fara pa rárá nígbà tó jí. Ìròyìn náà fi kún un pé: “Ojúlówó agbára yoga ló fi ṣe é.”
Láìsí àní-àní, kò sí èèyàn lásán tó gbójú gbóyà láti ṣe èyíkéyìí nínú àwọn nǹkan wọ̀nyí. Ìdí nìyẹn tó fi yẹ kí Kristẹni kan bi ara rẹ̀ pé: Kí ni gbogbo itú tí wọ́n ń pa wọ̀nyí fi hàn? Ṣé àtọ̀dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run, “Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ilẹ̀ ayé” ni wọ́n ti wá, tàbí láti àwọn orísun mìíràn? (Sáàmù 83:18) Bíbélì kò fi wá sínú òkùnkùn lórí kókó yìí. Nígbà tó kù díẹ̀ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ Ilẹ̀ Ìlérí, níbi tí àwọn ará Kénáánì ń gbé, Jèhófà tipasẹ̀ Mósè sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ kọ́ láti ṣe gẹ́gẹ́ bí àwọn ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí àwọn orílẹ̀-èdè wọnnì.” Kí ni “àwọn ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí” náà? Mósè kìlọ̀ nípa “ẹnikẹ́ni tí ń woṣẹ́, pidánpidán kan tàbí ẹnikẹ́ni tí ń wá àwọn àmì ìṣẹ̀lẹ̀ tàbí oníṣẹ́ oṣó.” (Diutarónómì 18:9, 10) Àwọn nǹkan wọ̀nyí jẹ́ ohun tí Ọlọ́run ń ṣe họ́ọ̀ sí nítorí pé wọ́n jẹ́ àwọn iṣẹ́ ẹ̀mí èṣù àti ti ẹran ara ẹlẹ́ṣẹ̀.—Gálátíà 5:19-21.
Kì Í Ṣé Ohun Tó Yẹ Kí Kristẹni Yàn
Ohun yòówù kí ẹni tí ń fúnni nítọ̀ọ́ni nípa ìlera ara sọ láti ta ko kókó yìí, yoga kì í ṣe eré ìmárale lásán. Ìwé náà, Hindu Manners, Customs and Ceremonies, sọ ìrírí àwọn méjì tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ṣe yoga, tí wọ́n wà lábẹ́ àbójútó àwòrò kan. Ó ṣàyọlò ọ̀rọ̀ ọ̀kan nínú wọn tó sọ pé: “Mo sapá lọ́nà tó ju ti ẹ̀dá lọ láti sé èémí fún iye àkókò tó ṣeé ṣe fún mi, ìgbà tí mo wá rí i pé mo fẹ́ dákú ni mo tó ṣẹ̀ṣẹ̀ mí. . . . Lọ́jọ́ kan, ní ọ̀sán gangan, ó jọ pé mo rí òṣùpá tó mọ́lẹ̀ yòò, tó dà bíi pé kò dúró lójú kan, tó ń mì síwá sẹ́yìn. Ní àkókò mìíràn, ó dà bí ẹni pé mo wà nínú òkùnkùn biribiri lọ́sàn-án gangan. Inú ọ̀gá mi dùn gan-an nígbà tí mo sọ àwọn ìran tí mo rí wọ̀nyí fún un. . . . Ó mú un dá mi lójú pé kò ní pẹ́ tí máa fí máa rí àwọn nǹkan kàyéfì púpọ̀ sí i nítorí ìjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí mò ń ṣe.” Ọkùnrin kejì sọ pé: “Ó rọ̀ mi kì n máa tẹjú mọ́ òfuurufú lójoojúmọ́ láìsí pé mo ṣẹ́jú tàbí kí n yí ipò tí mo wà padà. . . . Ó máa ń ṣe mi bí ẹni pé mo ń rí àwọn ẹ̀là iná nínú afẹ́fẹ́ láwọn ìgbà mìíràn; ìgbà mìíràn sì tún wà tó máa ń dà bíi pé mò ń rí àwọn iná roboto-roboto àtàwọn ìràwọ̀ kéékèèké mìíràn. Inú olùkọ́ mi dùn púpọ̀ bí ipa tí mò ń sà ṣe ń kẹ́sẹ járí.”
Àwọn ohun kàyéfì téèyàn ń rí wọ̀nyẹn ni ohun tí àwọn tó ń dá àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ gbà pé ó jẹ́ àbájáde tó dára jù lọ tó lè mú kéèyàn mọ ìdí pàtàkì tí òun fi ń ṣe yoga. Dájúdájú, olórí ète yoga ni ìdáǹdè, èyí tí wọ́n ṣàlàyé gẹ́gẹ́ bíi níní àjọṣe pẹ̀lú àwọn ẹ̀mí alágbára tí kò bá ti ẹ̀dá mu. Wọ́n ṣàpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “kéèyàn (mọ̀ọ́mọ̀) dá ìgbòkègbodò tó ń lọ lọ́wọ́ nínú èrò inú rẹ̀ dúró.” Èyí yàtọ̀ pátápátá sí góńgó tá a là sílẹ̀ fáwọn Kristẹni tá a gbà níyànjú pé: “Kí ẹ fi ara yín fún Ọlọ́run ní ẹbọ ààyè, mímọ́, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ pẹ̀lú agbára ìmọnúúrò yín. Ẹ sì jáwọ́ nínú dídáṣà ní àfarawé ètò àwọn nǹkan yìí, ṣùgbọ́n ẹ para dà nípa yíyí èrò inú yín padà, kí ẹ lè ṣàwárí fúnra yín ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó dára, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tí ó sì pé.”—Róòmù 12:1, 2.
Yíyan irú eré ìdárayá to yẹ kéèyàn máa ṣe jẹ́ ọ̀ràn ara ẹni. Àmọ́ àwọn Kristẹni kò ní í jẹ́ kí ohunkóhun—ì báà jẹ́ ara títọ́, jíjẹ, mímu, aṣọ wíwọ̀, eré ìnàjú, tàbí ohunkóhun mìíràn—ba àjọṣe àárín àwọn àti Jèhófà Ọlọ́run jẹ́. (1 Kọ́ríńtì 10:31) Fún àwọn tó ń ṣe eré ìmárale nítorí ìlera ara wọn, ọ̀nà pọ̀ tí wọ́n lè gbà ṣe é láìkó ara wọn sínú ewu ìbẹ́mìílò àti ti ẹgbẹ́ òkùnkùn. Nípa yíyẹra fún àwọn àṣà àti ìgbàgbọ́ tó bẹ̀rẹ̀ látinú ìsìn èké, a lè máa wọ̀nà fún ìbùkún Ọlọ́run ti ètò àwọn nǹkan tuntun òdodo nínú èyí tá a ti máa gbádùn ìlera pípé ní ti ara àti ní ti èrò inú títí ayérayé.—2 Pétérù 3:13; Ìṣípayá 21:3, 4.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
Ọ̀pọ̀ ló ń ṣe àwọn ìgbòkègbodò ìmárale tí kò ní ọ̀rọ̀ pé à ń kóra ẹni sínú ìbẹ́mìílò nínú