Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ìlànà wo ni Ìwé Mímọ́ fúnni nípa ọmọ títọ́ nígbà tí òbí kan bá jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí èkejì kì í sì í ṣe Ẹlẹ́rìí?
Ìlànà méjì tó ṣe kókó látinú Ìwé Mímọ́ ló pèsè ìtọ́ni nípa ọmọ títọ́ fún òbí kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí àmọ́ tí ọkọ tàbí aya rẹ̀ kì í ṣe Ẹlẹ́rìí. Èkíní ni: “Àwa gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.” (Ìṣe 5:29) Èkejì ni: “Ọkọ ni orí aya rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti jẹ́ orí ìjọ.” (Éfésù 5:23) Kì í ṣe kìkì àwọn aya tí ọkọ wọn jẹ́ Ẹlẹ́rìí ni ìlànà kejì yìí bá wí, àmọ́ ó tún bá àwọn tí ọkọ wọn kì í ṣe Ẹlẹ́rìí wí pẹ̀lú. (1 Pétérù 3:1) Báwo ni òbí kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí ṣe lè wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì nínú títẹ̀lé àwọn ìlànà wọ̀nyí nígbà tó bá ń tọ́ àwọn ọmọ rẹ̀?
Tó bá jẹ́ pé ọkọ ni Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ẹrù iṣẹ́ rẹ̀ ni pé kó pèsè fún ìdílé rẹ̀ nípa tẹ̀mí àti nípa tara. (1 Tímótì 5:8) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àkókò tí ìyá tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ fi ń wà pẹ̀lú àwọn ọmọ lè pọ̀ ju ti baba lọ, síbẹ̀ baba tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí gbọ́dọ̀ kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́. Ó lè ṣe èyí nípa fífi nǹkan tẹ̀mí kọ́ wọn nínú ilé àti nípa kíkó wọn lọ sáwọn ìpàdé Kristẹni, níbi tí wọ́n ti máa jàǹfààní látinú ìtọ́ni tí wọ́n ń gbà lórí ọ̀nà ìwà híhù àti ìbákẹ́gbẹ́ tó gbámúṣé.
Bí aya tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ bá wá kọ̀ jálẹ̀ pé òun gbọ́dọ̀ máa kó àwọn ọmọ lọ sílé ìjọsìn tòun tàbí pé òun á máa fi àwọn ohun tí òun gbà gbọ́ kọ́ wọn ńkọ́? Òfin orílẹ̀-èdè náà lè fún un lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Yálà àwọn ọmọ gbà kó sún àwọn láti jọ́sìn nírú ibi bẹ́ẹ̀ tàbí wọn ò gbà lè sinmi lórí bí nǹkan tẹ̀mí tí baba wọn ti fi kọ́ wọn ṣe múná dóko tó. Bí àwọn ọmọ náà ṣe ń dàgbà, ẹ̀kọ́ Ìwé Mímọ́ tí baba wọn fi kọ́ wọn gbọ́dọ̀ ràn wọ́n lọ́wọ́ láti tẹ̀ lé òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Inú baba tó jẹ́ onígbàgbọ́ náà á mà dùn o, bí àwọn ọmọ rẹ̀ bá pinnu láti dúró nínú òtítọ́!
Tó bá jẹ́ ìyá ni Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó gbọ́dọ̀ bọ̀wọ̀ fún ìlànà ipò orí kó sì tún máa ṣàníyàn nípa ire ayérayé àwọn ọmọ rẹ̀. (1 Kọ́ríńtì 11:3) Ọ̀pọ̀ ìgbà ni ọkọ tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ kò ní bínú bí aya rẹ̀ tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí bá ń fi ìlànà ìwà rere àti nǹkan tẹ̀mí kọ́ àwọn ọmọ wọn, ohun tó sì lè ràn án lọ́wọ́ láti ṣèyẹn wà lárọ̀ọ́wọ́tó láwọn ìpàdé àwọn èèyàn Jèhófà. Ìyá náà lè ran ọkọ rẹ̀ tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ lọ́wọ́ láti rí àǹfààní ẹ̀kọ́ tí ń gbéni ró táwọn ọmọ wọn ń kọ́ nínú ètò-àjọ Jèhófà. Ó lè fọgbọ́n tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì títẹ àwọn ìlànà ìwà rere tí Bíbélì fi kọ́ni mọ́ àwọn ọmọ wọn lọ́kàn, bó ṣe jẹ́ pé inú ayé tí ìwà àwọn èèyàn ibẹ̀ túbọ̀ ń burú sí i ni wọ́n ń gbé.
Àmọ́ ṣá o, ọkọ tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ lè kọ̀ délẹ̀ pé ìsìn òun làwọn ọmọ òun máa ṣe, kó máa kó wọn lọ sílé ìjọsìn rẹ̀ kó sì máa fi àwọn ẹ̀kọ́ ìsìn rẹ̀ kọ́ wọn. Tàbí kẹ̀ ọkọ kan lè lòdì sí gbogbo ìsìn, kó sì sọ pé wọn ò gbọ́dọ̀ fi ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn kankan kọ́ àwọn ọmọ òun. Gẹ́gẹ́ bí olórí ìdílé, òun gan-an ni ẹrù iṣẹ́ ṣíṣe ìpinnu já lé léjìká. a
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé yóò máa bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ̀, síbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Kristẹni tó ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́, aya tó jẹ́ onígbàgbọ́ gbọ́dọ̀ máa rántí ìṣarasíhùwà àpọ́sítélì Pétérù àti ti Jòhánù, tí wọ́n sọ pé: “Ní tiwa, Ìṣe 4:19, 20) Nítorí pé ìyá tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí bìkítà nípa ire tẹ̀mí àwọn ọmọ rẹ̀, yóò wá ọ̀nà tá á fi máa fún wọn nítọ̀ọ́ni lórí bí wọn ó ṣe máa hùwà. Ojúṣe rẹ̀ níwájú Jèhófà ni pé kí ó kọ́ àwọn ẹlòmíràn nípa ohun tó mọ̀ pé ó jẹ́ òtítọ́, ẹ̀kọ́ yẹn ò sì yọ àwọn ọmọ rẹ̀ sílẹ̀. (Òwe 1:8; Mátíù 28:19, 20) Báwo ni ìyá tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí yóò ṣe kojú ìṣòro líle koko náà?
àwa kò lè dẹ́kun sísọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tí a ti rí tí a sì ti gbọ́.” (Bí àpẹẹrẹ, gbé ọ̀ràn ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run yẹ̀ wò. Ó lè má ṣeé ṣe fún aya tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí láti jókòó síbì kan kó máa bá àwọn ọmọ rẹ̀ ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nítorí pé ọkọ rẹ̀ ò fẹ́ bẹ́ẹ̀. Ǹjẹ́ ìyẹn wá túmọ̀ sí pé kò gbọ́dọ̀ bá àwọn ọmọ rẹ̀ sọ ohunkóhun nípa Jèhófà bí? Rárá o. Ọ̀rọ̀ àti ìṣe rẹ̀ gbọ́dọ̀ fi ìgbàgbọ́ tó ní nínú Ẹlẹ́dàá hàn. Ó dájú pé àwọn ọmọ rẹ̀ yóò máa béèrè ìbéèrè lórí kókó yìí pẹ̀lú. Kò yẹ kó lọ́ tìkọ̀ láti lo òmìnira ẹ̀sìn rẹ̀ nípa sísọ ìgbàgbọ́ tó ní nínú Ẹlẹ́dàá fáwọn èèyàn títí kan àwọn ọmọ rẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè máà láǹfààní láti bá àwọn ọmọ náà ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tàbí láti kó wọn lọ sípàdé déédéé, síbẹ̀ ó lè gbin ìmọ̀ nípa Jèhófà Ọlọ́run sí wọn lọ́kàn.—Diutarónómì 6:7.
Ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ nípa àjọṣe tó wà láàárín Ẹlẹ́rìí kan àti ọkọ tàbí aya rẹ̀ tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ ni pé: “Ọkọ tí kò gbà gbọ́ ni a sọ di mímọ́ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú aya rẹ̀, aya tí kò sì gbà gbọ́ ni a sọ di mímọ́ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú arákùnrin náà; bí bẹ́ẹ̀ kọ́, àwọn ọmọ yín ì bá jẹ́ aláìmọ́ ní ti gidi, ṣùgbọ́n nísinsìnyí wọ́n jẹ́ mímọ́.” (1 Kọ́ríńtì 7:14) Jèhófà gbà pé ìgbéyàwó náà jẹ́ mímọ́ nítorí ọkọ tàbí aya tó jẹ́ onígbàgbọ́, àwọn ọmọ náà sì jẹ́ mímọ́ lójú Jèhófà. Aya tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí gbọ́dọ̀ sa gbogbo ipá rẹ̀ láti ran àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n lè lóye òtítọ́, kí ó sì fi àbájáde rẹ̀ lé Jèhófà lọ́wọ́.
Bí àwọn ọmọ náà ti ń dàgbà, wọ́n ní láti pinnu ohun tó yẹ káwọn ṣe látàrí ọ̀rọ̀ tí wọ́n ti gbọ́ látẹnu àwọn òbí wọn. Wọ́n lè pinnu láti tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ Jésù pé: “Ẹni tí ó bá ní ìfẹ́ni tí ó pọ̀ fún baba tàbí ìyá ju èyí tí ó ní fún mi, kò yẹ fún mi.” (Mátíù 10:37) A tún pàṣẹ fún wọn pé: “Ẹ̀yin ọmọ, ẹ jẹ́ onígbọràn sí àwọn òbí yín ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Olúwa.” (Éfésù 6:1) Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ló ti yàn láti ‘ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso’ dípò òbí tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí, láìfi ìyà tí òbí ọ̀hún máa fi jẹ wọ́n pè. Ẹ ò rí i pé èrè ńlá ló máa jẹ́ fún òbí tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí láti rí i tí àwọn ọmọ òun pinnu láti sin Jèhófà láìfi àtakò pè!
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ẹ̀tọ́ tí aya náà ní lábẹ́ òfin pé ó lè ṣe ẹ̀sìn tó wù ú kan ẹ̀tọ́ rẹ̀ láti lọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni. Nínú àwọn ọ̀ràn kan, a ti rí ọkọ tó kọ̀ láti bójú tó àwọn ọmọ aláìtójúúbọ́ láwọn àkókò wọ̀nyẹn, nítorí náà ó di dandan kí ìyá tó nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ rẹ̀ máa kó wọn lọ sípàdé.