Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Wàá Pa Ìwà Títọ́ Ẹ Mọ́?

Ṣé Wàá Pa Ìwà Títọ́ Ẹ Mọ́?

Ṣé Wàá Pa Ìwà Títọ́ Ẹ Mọ́?

ẸYẸ ológoṣẹ́ mélòó ló kú lánàá? Kò sẹ́ni tó mọye wọn. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló tiẹ̀ máa sọ pé ìyẹn ò kan àwọn o, torí pé àìmọye ẹyẹ ní ń bẹ nígbó. Àmọ́ ṣá, Jèhófà ò fọ̀ràn wọn ṣeré o. Nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹyẹ táwọn èèyàn ò kà sí yìí, ó sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Kò sí ọ̀kan nínú wọn tí yóò jábọ́ lulẹ̀ láìjẹ́ pé Baba yín mọ̀.” Ó tún fi kún un pé: “Ẹ má bẹ̀rù: ẹ níye lórí púpọ̀ ju ọ̀pọ̀ ológoṣẹ́ lọ.”—Mátíù 10:29, 31.

Ẹ̀yìn-ọ̀-rẹyìn ló wá yé àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà kedere pé àwọn ṣe pàtàkì púpọ̀ lójú Jèhófà. Ọ̀kan lára wọn, ìyẹn àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé: “Nípa èyí ni a fi ìfẹ́ Ọlọ́run hàn kedere nínú ọ̀ràn tiwa, nítorí Ọlọ́run rán Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo jáde sínú ayé kí a lè jèrè ìyè nípasẹ̀ rẹ̀.” (1 Jòhánù 4:9) Kì í ṣe kìkì pé Jèhófà pèsè ìràpadà nìkan ni, àmọ́ ó tún fi dá gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lójú pé: “Dájúdájú, èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà tàbí kọ̀ ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà.”—Hébérù 13:5.

Ó ṣe kedere pé mìmì kan ò lè mi ìfẹ́ tí Jèhófà ní sáwọn èèyàn rẹ̀. Àmọ́ o, ìbéèrè kan tó jẹ yọ rèé, ‘Ṣé a ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà tá ò fi ní fi í sílẹ̀ láéláé?’

Sátánì Ń Wá Ọ̀nà Láti Ba Ìwà Títọ́ Wa Jẹ́

Jèhófà pe àfiyèsí Sátánì sí bí Jóòbù ṣe pa ìwà títọ́ rẹ̀ mọ́, àmọ́ nígbà tí Sátánì máa dáhùn, ohun tó sọ ni pé: “Ṣé o rò pé Jóòbù á máa sìn ẹ́ ni, ká ní kò rí àǹfààní kan gbà níbẹ̀?” (Jóòbù 1:9, Today’s English Version) Ohun tó ń sọ ni pé nítorí ‘àwọn àǹfààní tí ẹ̀dá èèyàn ń rí gbà’ lọ́dọ̀ Ọlọ́run ni wọ́n ṣe ń pa ìwà títọ́ mọ́. Tó bá jẹ́ òótọ́ lohun tó sọ yìí, a jẹ́ pé tí àǹfààní tó tó àǹfààní bá yọ sáwọn Kristẹni, wọ́n lè fi Ọlọ́run sílẹ̀ nìyẹn.

Nínú ọ̀ràn Jóòbù, ohun tí Sátánì kọ́kọ́ sọ ni pé Jóòbù á fi ìwà títọ́ rẹ̀ sílẹ̀ tó bá lè pàdánù àwọn ohun ìní rẹ̀ tó kà sí ààyò. (Jóòbù 1:10, 11) Nígbà tí ọ̀rọ̀ rírùn tí Sátánì sọ yìí já sírọ́, ló bá tún sọ pé: “Ani ohun gbogbo ti enia ni, on ni yio fi rà ẹmi rẹ̀.” (Jóòbù 2:4, Bibeli Mimọ) Ohun tí Sátánì sọ lè jóòótọ́ nínú ọ̀ràn àwọn kan, àmọ́ Jóòbù ní tiẹ̀ pa ìwà títọ́ rẹ̀ mọ́. Ìtàn tó wà lákọọ́lẹ̀ fi hàn pé bẹ́ẹ̀ lọ̀ràn rí. (Jóòbù 27:5; 42:10-17) Ṣé ìwọ náà ní irú ìwà títọ́ yẹn? Àbí wàá gba Sátánì láyè láti ba ìdúróṣinṣin rẹ jẹ́? Máa ronú nípa bó o ṣe ń ṣe sí, bí a ó ṣe máa jíròrò àwọn òtítọ́ kan tó kan gbogbo Kristẹni.

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbà gbọ́ pé ìdúróṣinṣin Kristẹni tòótọ́ máa ń lágbára gan-an. Ó kọ̀wé pé: “Mo gbà gbọ́ dájú pé kì í ṣe ikú tàbí ìyè . . . tàbí àwọn ohun tí ó wà níhìn-ín nísinsìnyí tàbí àwọn ohun tí ń bọ̀ . . . tàbí ìṣẹ̀dá èyíkéyìí mìíràn ni yóò lè yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó wà nínú Kristi Jésù Olúwa wa.” (Róòmù 8:38, 39) Àwa náà lè ní irú ìgbàgbọ́ tó lágbára bẹ́ẹ̀ tá a bá ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún Jèhófà. Irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ jẹ́ ìdè alọ́májàá, kódà ikú pàápàá kò lè já a.

Tá a bá ní irú àjọṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run, a ò ní béèrè láé pé, ‘Ǹjẹ́ màá ṣì lè máa jọ́sìn Ọlọ́run lọ láìpẹ́ sígbà tá a wà yìí báyìí?’ Irú iyèméjì báyìí lè jẹ́ kó dà bíi pé ohun tó bá ṣẹlẹ̀ sí wa nínú ìgbésí ayé wa ló máa pinnu bóyá a máa dúró ṣinṣin ti Ọlọ́run tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Àwọn ohun tó lè ṣẹlẹ̀ séèyàn kò ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú ojúlówó ìwà títọ́. Irú èèyàn tá a jẹ́ nínú lọ́hùn-ún ló máa ń pinnu rẹ̀. (2 Kọ́ríńtì 4:16-18) Tó bá jẹ́ pé gbogbo ọkàn wa pátá la fi nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, a ò ní já a kulẹ̀ láé.—Mátíù 22:37; 1 Kọ́ríńtì 13:8.

Àmọ́ o, a gbọ́dọ̀ rántí pé Sátánì ò fìgbà kan túra sílẹ̀ nínú bó ṣe ń sapá láti ba ìdúróṣinṣin wa jẹ́. Ó lè dán wa wò láti fàyè gba ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara àti ẹ̀mí ṣe ohun tẹ́gbẹ́ ń ṣe tàbí ká jẹ́ káwọn ìṣòro tó dé bá wa mú wa fi òtítọ́ sílẹ̀. Ayé tó ti kẹ̀yìn sí Ọlọ́run ni olórí ìsọ̀ǹgbè Sátánì tí wọ́n jọ ń gbógun tì wá, àmọ́ àìpé àwa náà lè jẹ́ kí ọwọ́ rẹ̀ tètè tẹ̀ wá. (Róòmù 7:19, 20; 1 Jòhánù 2:16) Ṣùgbọ́n ṣá, a ní ọ̀pọ̀ àǹfààní láti borí nínú ogun yìí. Ọ̀kan lára àǹfààní pàtàkì tá a ní ni pé a mọ àwọn ètekéte Sátánì.—2 Kọ́ríńtì 2:11.

Kí ni àwọn ètekéte Sátánì? Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé wọn nínú lẹ́tà tó kọ sáwọn ará Éfésù, ó sì pè wọ́n ní “àwọn ètekéte,” tàbí ‘àrékérekè.’ (Éfésù 6:11) Sátánì ń kẹ́ àwọn ètekéte rẹ̀ yìí sójú ọ̀nà fún wa ká bàa lè kó sí i, kó sì ba ìwà títọ́ wa jẹ́. A dúpẹ́ pé a lè dá àwọn ìwà àrékérekè yìí mọ̀ nítorí pé a ti kọ àwọn ọgbọ́n tí Èṣù ń lò sílẹ̀ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Oríṣiríṣi ọ̀nà tí Sátánì gbà láti fi ba ìwà títọ́ Jésù àti Jóòbù jẹ́, jẹ́ ká mọ díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà tó ń gbà láti ba ìwà títọ́ àwọn Kristẹni jẹ́.

Ìwà Títọ́ Jésù Ò Ṣe É Bà Jẹ́

Nígbà tí Jésù bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, àyà ko Sátánì débí pé ó dán Ọmọ Ọlọ́run wò pé kí ó sọ òkúta di búrẹ́dì. Ẹ ò rí i pé alárèékérekè gbáà ni! Jésù ò tíì fi oúnjẹ kan ẹnu fún odindi ogójì ọjọ́, ó sì dájú pé ebi á ti máa pa á gan-an. (Lúùkù 4:2, 3) Ohun tí Sátánì ń sọ fún Jésù ni pé kó tẹ́ ìfẹ́ ọkàn ẹ̀ lọ́rùn ní kíákíá, ìyẹn lọ́nà tí kò bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu. Bákan náà ló rí lónìí, ohun tí àwọn ọ̀rọ̀ èké tí aráyé ń polongo ń sọ ni pé kéèyàn ṣe ohunkóhun tọ́kàn rẹ̀ bá ti fẹ́ lójú ẹsẹ̀, láìka ohun tó lè tẹ̀yìn rẹ̀ yọ sí. Ohun tí wọ́n ń sọ ni pé, ‘Àsìkò tó yẹ kó o ṣe é rèé,’ tàbí ‘Ṣáà ṣe ohun tó bá wù ẹ́ o jàre!’

Ká ní ọ̀ràn àtifi nǹkan síkùn nìkan ló ká Jésù lára, láìka ohun tó máa jẹ́ àbájáde rẹ̀ sí, Sátánì ì bá ti mú kí Jésù ba ìwà títọ́ rẹ̀ jẹ́. Ojú ohun tẹ̀mí ni Jésù fi wo ọ̀ràn náà, ó sì fi ìdúróṣinṣin dáhùn pé: “A kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Ènìyàn kò gbọ́dọ̀ tipa oúnjẹ nìkan ṣoṣo wà láàyè.’”—Lúùkù 4:4; Mátíù 4:4.

Sátánì tún dá ọgbọ́n mìíràn. Èṣù dorí Ìwé Mímọ́ tí Jésù pẹ̀lú ti ń fa ọ̀rọ̀ yọ kodò, ó sì sọ fún Jésù pé kó fò bọ́ sílẹ̀ látorí tẹ́ńpìlì. Sátánì tiẹ̀ sọ pé: ‘Áńgẹ́lì kan á dáàbò bọ̀ ọ́.’ Jésù kò ní in lọ́kàn pé kí Bàbá òun dáàbò bo òun lọ́nà iṣẹ́ ìyanu káwọn èèyàn lè máa ṣe sàdáńkátà òun. Jésù sọ pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ dán Jèhófà Ọlọ́run rẹ wò.”—Mátíù 4:5-7; Lúùkù 4:9-12.

Ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ tí Sátánì lò gbẹ̀yìn ṣe tààràtà ju àwọn ti tẹ́lẹ̀ lọ. Ó wá fẹ́ bá Jésù ṣe àdéhùn ọ̀sán gangan, ó fi gbogbo ayé àti ògo rẹ̀ lọ Jésù, ó sì sọ fún un pé tó bá ṣáà ti lè jọ́sìn òun lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, gbogbo nǹkan wọ̀nyí á di tiẹ̀. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ohun tí Sátánì ní ló gbé kalẹ̀ yẹn. Àmọ́ báwo ni Jésù á ṣe lọ jọ́sìn ẹni tó jẹ́ olórí ọ̀tá Bàbá rẹ̀? Ká má rí i! Ohun tí Jésù fi dá a lóhùn ni pé: “Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni ìwọ gbọ́dọ̀ jọ́sìn, òun nìkan ṣoṣo sì ni ìwọ gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún.”—Mátíù 4:8-11; Lúùkù 4:5-8.

Nígbà tí gbogbo ọgbọ́n tí Sátánì dá ò ṣiṣẹ́, ó ‘fà sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ Jésù títí di àkókò mìíràn tí ó wọ̀.’ (Lúùkù 4:13) Èyí fi hàn pé lójú méjèèjì ni Sátánì ń wá ọ̀nà pé kóun ṣáà ráyè dán ìwà títọ́ Jésù wò. Ọdún méjì àbọ̀ lẹ́yìn ìgbà yìí ni àkókò tó wọ̀ dé, ìyẹn ìgbà tí Jésù ń mú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ gbára dì nítorí ikú rẹ̀ tó ti sún mọ́lé. Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé: “Ṣàánú ara rẹ, Olúwa; ìwọ kì yóò ní ìpín yìí rárá.”—Mátíù 16:21, 22.

Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe kí irú ìmọ̀ràn tó lè kóni sí yọ́ọ́yọ́ọ́ yìí fi òjé jẹ Jésù, ó ṣe tán, ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ló sọ ọ́ tí kò sì ní ète búburú lọ́kàn? Ojú ẹsẹ̀ ni Jésù ti mọ̀ pé èrò Sátánì làwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn, pé kì í ṣe ti Jèhófà. Kristi sì fi gbogbo ara dáhùn pé: “Dẹ̀yìn lẹ́yìn mi, Sátánì! Ohun ìkọ̀sẹ̀ ni ìwọ jẹ́ fún mi, nítorí kì í ṣe àwọn ìrònú Ọlọ́run ni ìwọ ń rò, bí kò ṣe ti ènìyàn.”—Mátíù 16:23.

Ìfẹ́ alọ́májàá tí Jésù ní fún Jèhófà ni ò jẹ́ kí Sátánì ráyè ba ìwà títọ́ rẹ̀ jẹ́. Kò sóhun tí Èṣù lè gbé kalẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sírú àdánwò náà, bó ti wù kí ó le tó, tó lè ba ìdúróṣinṣin Jésù sí Bàbá rẹ̀ ọ̀run jẹ́. Ṣé àwa náà á lè pinnu lọ́nà kan náà nígbà tí ipò àwọn nǹkan bá mú kó ṣòro fún wa láti pa ìwà títọ́ wa mọ́? Àpẹẹrẹ Jóòbù á túbọ̀ jẹ́ ká lóye àwọn ìṣòro ńláǹlà tá a lè bá pàdé.

Pípa Ìwà Títọ́ Mọ́ Nígbà Ìpọ́njú

Gẹ́gẹ́ bí Jóòbù ṣe mọ̀, ìpọ́njú lè dé bá wa nígbàkigbà. Jóòbù láya sílé àtọmọ mẹ́wàá. Tẹ̀rín-tẹ̀yẹ ni gbogbo wọ́n fi ń bára wọn lò nílé, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kì í fọwọ́ yẹpẹrẹ mú àwọn ohun tẹ̀mí. (Jóòbù 1:5) Àmọ́ Jóòbù ò mọ̀ pé ọ̀ràn ìwà títọ́ òun ti fa awuyewuye lájùlé ọ̀run, tí Sátánì sì ti sọ pé ohun tó bá gbà lòun máa fún un pé òun gbọ́dọ̀ ba ìwà títọ́ rẹ̀ jẹ́.

Ká wí ká fọ̀, gbogbo ohun àmúṣọrọ̀ Jóòbù wọmi. (Jóòbù 1:14-17) Àmọ́ ṣá, mìmì kan ò mi ìwà títọ́ Jóòbù nítorí pé kì í ṣe owó ló gbọ́kàn lé. Nígbà tí Jóòbù ń sọ nípa ìgbà tó ṣì lówó bíi ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó sọ pé: “Bí mo bá fi wúrà ṣe ìgbọ́kànlé mi, . . . bí mo bá ń yọ̀ nítorí pé dúkìá mi pọ̀, . . . ìyẹn pẹ̀lú yóò jẹ́ ìṣìnà . . . , nítorí èmi ì bá ti sẹ́ Ọlọ́run tòótọ́ tí ó wà lókè.”—Jóòbù 31:24, 25, 28.

Lọ́jọ́ tòní, àwa náà lè pàdánù gbogbo ohun ìní wa lọ́sàn-án kan òru kan. Àwọn gbájúẹ̀ lu oníṣòwò kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní jìbìtì, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ di ẹdun arinlẹ̀. Ó là á mọ́lẹ̀ pé: “Díẹ̀ ló kù kí àrùn ọkàn kọlù mí. Àrùn yìí ì bá kúkú kọlù mí ká ní kì í ṣe ti àjọṣe tó wà láàárín èmi àti Ọlọ́run ni. Àmọ́, ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí jẹ́ kí n mọ̀ pé mi ò fi àwọn ohun tẹ̀mí sípò àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé mi. Ó jọ pé eré àtilà ni mò ń fojoojúmọ́ ayé sá kiri.” Àtìgbà náà ni Ẹlẹ́rìí yìí ti kọwọ́ ọmọ rẹ̀ bọ aṣọ, tó rọra ń ṣe òwò rẹ̀ lónírẹ́jẹ́, ó sì ń ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lóòrèkóòrè. Ó ń lo àádọ́ta wákàtí tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lóṣù nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni. Àmọ́ àwọn ìṣòro mìíràn wà tó lè kó ṣìbáṣìbo báni ju pípàdánù àwọn ohun ìní ẹni lọ.

Ojora tí ìròyìn àkọ́kọ́ kó bá Jóòbù kò tíì kúrò lára rẹ̀ nígbà tó tún gbọ́ pé àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́wẹ̀ẹ̀wá ti kú. Síbẹ̀, ohun tó tẹnu rẹ̀ jáde ni pé: “Kí orúkọ Jèhófà máa bá a lọ láti jẹ́ èyí tí a bù kún fún.” (Jóòbù 1:18-21) Ǹjẹ́ a ó ṣì pa ìwà títọ́ wa mọ́ tó bá ṣẹlẹ̀ pé àwọn èèyàn wa bíi mélòó kan kú láìròtẹ́lẹ̀? Kristẹni alábòójútó ni Francisco ní Sípéènì, ọmọ ẹ̀ méjì ló kú lẹ́ẹ̀kan náà nínú jàǹbá ọkọ̀ kan. Títúbọ̀ sún mọ́ Jèhófà àti ṣíṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni ló tù ú nínú.

Pẹ̀lú pé àwọn ọmọ Jóòbù mẹ́wẹ̀ẹ̀wá ti ṣòfò ẹ̀mí, àjálù rẹ̀ ṣì kù. Sátánì fi àrùn tó ń ríni lára, tó sì ń roni lára gógó kọ lù ú. Àkókò yìí gan-an ni ìyàwó Jóòbù wá fún un ní ìmọ̀ràn tí ò bọ́ sí i. Ó sọ fún Jóòbù pé: “Bú Ọlọ́run, kí o sì kú!” Jóòbù kọ ìmọ̀ràn rẹ̀ yìí, kò sì “fi ètè rẹ̀ dẹ́ṣẹ̀.” (Jóòbù 2:9, 10) Orí àjọṣe tó ní pẹ̀lú Jèhófà ló gbé ìwà títọ́ rẹ̀ kà, kì í ṣe orí ìtìlẹ́yìn ìdílé rẹ̀.

Flora, tí ọkọ rẹ̀ àti ọmọkùnrin rẹ̀ àkọ́bí pa ọ̀nà Kristẹni tì lóhun tó lé lọ́dún mẹ́wàá sẹ́yìn mọ bí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jóòbù ṣe máa rí lára rẹ̀. Ó sọ pé: “Tó bá ṣẹlẹ̀ lójijì pé èèyàn ò rí ìtìlẹ́yìn nípa tẹ̀mí àti tara gbà látọ̀dọ̀ ìdílé rẹ̀ mọ́, orí olúwarẹ̀ á fẹ́rẹ̀ẹ́ dà rú. Ṣùgbọ́n mo mọ̀ pé inú ètò Jèhófà nìkan ni mo ti lè rí ìdùnnú. Èyí ló jẹ́ kí n dúró gbọn-in, kí n sì fi Jèhófà sí ipò àkọ́kọ́ pẹ̀lú gbogbo bí mo ṣe ń sapá láti jẹ́ aya rere àti ìyá rere. Gbogbo ìgbà ni mò ń gbàdúrà, Jèhófà sì ń fún mi lókun. Mo láyọ̀ nítorí pé mo da ara dé Jèhófà pátápátá, pẹ̀lú gbogbo bí ọkọ mi ṣe ń ṣàtakò.”

Àwọn alábàákẹ́gbẹ́ Jóòbù mẹ́ta ló tún kàn tí Sátánì lò láti ba ìwà títọ́ rẹ̀ jẹ́. (Jóòbù 2:11-13) Ẹ wo bí ọkàn rẹ̀ á ti gbọgbẹ́ tó nígbà tí wọ́n kẹ́nu bò ó. Ká lóun náà ti gba ohun tí wọ́n sọ ni, ì bá pàdánù ìgbọ́kànlé rẹ̀ nínú Jèhófà Ọlọ́run. Ìmọ̀ràn tó ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì báni tí wọ́n ń fún un ì bá ti bà á lọ́kàn jẹ́, ì bá sì tún ba ìwà títọ́ rẹ̀ jẹ́, ọwọ́ Sátánì ì bá sì tipa bẹ́ẹ̀ bà á.

Àmọ́ ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀, ohun tó tún tẹnu Jóòbù jáde ni pé: “Títí èmi yóò fi gbẹ́mìí mì, èmi kì yóò mú ìwà títọ́ mi kúrò lọ́dọ̀ mi!” (Jóòbù 27:5) Kò sọ pé, ‘Mi ò ní jẹ́ kí ẹ̀yin ọkùnrin wọ̀nyí ba ìwà títọ́ mi jẹ́!’ Jóòbù mọ̀ pé òun alára àti ìfẹ́ tí òun bá ní fún Jèhófà ni kò ní jẹ́ kí ìwà títọ́ òun yẹ̀.

Ọgbọ́n Ẹ̀wẹ́ Àtayébáyé Ló Ṣì Fi Ń Mú Àwọn Èèyàn Lóde Òní

Sátánì ṣì ń lo àwọn ìmọ̀ràn tó lè kóni sí yọ́ọ́yọ́ọ́ tàbí àwọn ọ̀rọ̀ aláìnírònú látẹnu àwọn ọ̀rẹ́ àtàwọn onígbàgbọ́ ẹlẹ́gbẹ́ wa. Ìrẹ̀wẹ̀sì látọ̀dọ̀ àwọn tá a jọ wà nínú ìjọ lè ba ìgbọ́kànlé wa jẹ́ wẹ́rẹ́ ju àtakò látọ̀dọ̀ àwọn ará ìta lọ. Kristẹni alàgbà kan tó ti lọ sógun rí nígbà tó ṣì ń ṣe sójà sọ pé ńṣe làwọn ọ̀rọ̀ àti ìwà aláìnírònú látọ̀dọ̀ àwọn Kristẹni ẹlẹ́gbẹ́ òun kan dà bí ohun tó ṣẹlẹ̀ sóun lójú ogun. Ó tiẹ̀ sọ pé àwọn ọ̀rọ̀ àtàwọn ìwà aláìnírònú wọ̀nyí “ni ohun tó nira jù lọ láti fara dà.”

Tá a bá tún gba ibòmíràn wò ó, inú lè máa bí wa nítorí àìpé àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa débi tá a fi máa bẹ̀rẹ̀ sí bá àwọn kan yodì tàbí ká tiẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí pa àwọn ìpàdé Kristẹni jẹ. Ó lè jẹ́ pé bá a ṣe máa mú àròdùn wa yìí kúrò lohun tó ń ká wa lára jù lọ. Àmọ́ á mà burú o, tá a bá fàyè gba irú èrò kúkúrú bẹ́ẹ̀, ká sì wá jẹ́ kí ohun táwọn kan ṣe tàbí tí wọ́n sọ ṣàkóbá fún ohun ìní wa tó ṣe pàtàkì jù lọ, ìyẹn àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà. Tá a bá jẹ́ kí èyí ṣẹlẹ̀ sí wa, a jẹ́ pé a ti kó sí ọ̀kan lára pańpẹ́ tí Sátánì ti ń lò látayébáyé nìyẹn o.

Òótọ́ ni pé ìlànà gíga là ń retí pé kí ó wà nínú ìjọ Kristẹni. Àmọ́ tá a bá ń retí ohun tó ga jù látọ̀dọ̀ àwọn olùjọ́sìn ẹlẹ́gbẹ́ wa, tí wọ́n ṣì jẹ́ aláìpé, kò sọ́gbọ́n ká máà já wa kulẹ̀. Jèhófà ní tiẹ̀ kì í ṣe bẹ́ẹ̀, ohun tó mọ̀ pé àwọn ìránṣẹ́ òun á lè ṣe ló máa ń retí pé kí wọ́n ṣe. Tá a bá tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀, a óò múra tán láti gbójú fo àìpé àwọn ará wa. (Éfésù 4:2, 32) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbà wá nímọ̀ràn pé: “Bí inú bá ń bi ọ, má ṣe jẹ́ kí ìbínú mú ọ dẹ́ṣẹ̀; má ṣe jẹ́ kí oòrùn wọ̀ bá ìbínú rẹ; má gba èṣù láyè.”—Éfésù 4:26, 27, The New English Bible.

Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe fi hàn, onírúurú ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ ni Sátánì ń lò láti rọ́nà ba ìwà títọ́ àwọn Kristẹni jẹ́, tó bá ṣeé ṣe fún un. Lára àwọn ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ rẹ̀ yìí jẹ́ èyí tó máa ń wu ẹran ara aláìpé, àwọn mìíràn sì máa ń fa ìrora. Látinú ohun tá a ti jíròrò yìí, o lè ti rí ìdí tí ò fi yẹ kó o túra sílẹ̀ nígbà kankan. Jẹ́ kí ìfẹ́ tó o ní fún Ọlọ́run wà lọ́kàn rẹ digbí, kó o sì pinnu pé wàá mú Èṣù ní òpùrọ́, kí o sì mú inú Jèhófà dùn. (Òwe 27:11; Jòhánù 8:44) Rántí pé bí iná ń jó tí ìjì àdánwò ń jà, a ò gbọ́dọ̀ fi ìwà títọ́ Kristẹni báni dọ́rẹ̀ẹ́.