Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Aráyé Ti Dorí Ìtumọ̀ Ìdúróṣinṣin Kodò

Aráyé Ti Dorí Ìtumọ̀ Ìdúróṣinṣin Kodò

Aráyé Ti Dorí Ìtumọ̀ Ìdúróṣinṣin Kodò

ÌRỌ̀LẸ́ ọjọ́ Friday kan mà ni o, tí ooru mú nílùú Tel Aviv, nílẹ̀ Ísírẹ́lì. Ọ̀dọ́mọkùnrin kan wọ àárín àwùjọ àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n kóra jọ síwájú ilé kan táwọn èèyàn ti ń gbafẹ́ lálaalẹ́. Kò pẹ́ púpọ̀ tí àdó olóró fi bú gbàù láàárín àwọn èrò yìí.

Àwọn tó máa ń to bọ́ǹbù sára, tí wọ́n á para wọn àtàwọn ẹlòmíràn ló ṣọṣẹ́ yìí o. Ó ti gbẹ̀mí ara rẹ̀ àti tàwọn èwe mọ́kàndínlógún mìíràn. Nọ́ọ̀sì kan sọ fáwọn akọ̀ròyìn lẹ́yìn náà pé: “Ńṣe ni ara èèyàn kàn já sílẹ̀ lọ jálajàla. Ọ̀dọ́mọdé ni gbogbo wọn. Mi ò tíì rí irú ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń múni gbọ̀n rìrì tó bẹ́ẹ̀ rí láyé mi.”

Thurstan Brewin kọ ọ́ nínú ìwé ìròyìn The Lancet pé: “Ànímọ́ tó wu gbogbo èèyàn ni, ńṣe ló dà bí ànímọ́ ìdúróṣinṣin . . . tó jẹ́ pé ó lè tètè tanná ran ogun, tó sì tún lè mú kó máà tán nílẹ̀ bọ̀rọ̀.” Òdodo ọ̀rọ̀, ìwà pípani nípakúpa táwọn èèyàn ń hù lórúkọ ìwà ìdúróṣinṣin ti tapo sí aṣọ àlà ìtàn ẹ̀dá èèyàn látorí àwọn Ogun Ìsìn táwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ń jà títí dórí ìpẹ̀yàrun tó wáyé nígbà ìjọba Násì ní Jámánì.

Ìwà Àìdúróṣinṣin Ń Fi Ẹ̀mí Púpọ̀ Sí I Ṣòfò

Kò sírọ́ níbẹ̀ pé ìdúróṣinṣin tó bá lọ́wọ́ àṣejù nínú máa ń ba nǹkan jẹ́, tí kò bá sì tún sí ìdúróṣinṣin ńṣe làwùjọ á pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ. Jíjẹ́ adúróṣinṣin túmọ̀ sí pé kéèyàn máa fi inú kan bá ẹnì kan lò tàbí kéèyàn máa fi ọkàn kan lépa góńgó kan, ó sì tún túmọ̀ sí kéèyàn dúró ti ẹnì kan tàbí ohun kan gbágbáágbá, iná ì báà máa jó tàbí kí ìjì máa jà. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló kúkú sọ pé àwọn fẹ́ràn irú ìdúróṣinṣin yìí. Àmọ́ a ò rí ànímọ́ yìí páàpáà níbi tó ti yẹ ká rí i, ìyẹn láàárín agbo ìdílé. Ìmọtara-ẹni-nìkan, kòókòó jàn-ánjàn-án ìgbésí ayé ojoojúmọ́ àti àwọn tọkọtaya tó tún ń lójú lóde, tó gbòde kan ti mú kí iye ìkọ̀sílẹ̀ ga sókè sí i. Bó ṣe jẹ́ pé àwọn èwe ló kú nínú bọ́ǹbù tó dún ní Tel Aviv náà ló ṣe jẹ́ pé àwọn èwe aláìmọwọ́mẹsẹ̀ ló ń forí fá ohun tá à ń sọ yìí.

Ìròyìn kan sọ pé: “Lọ́pọ̀ ìgbà ni àìrójúráyè ìdílé tí títúká, jíjáwèé ìkọ̀sílẹ̀ àti dídá tọ́mọ ń fà máa ń ṣàkóbá fún ẹ̀kọ́ ọmọ kan.” Àwọn ọmọkùnrin tó jẹ́ pé ìyá nìkan ló ń tọ́ wọn ló dà bí ẹni pé ẹ̀kọ́ wọn kì í já geere, àwọn ló sì ṣeé ṣe kí wọ́n fọwọ́ ara wọn gbẹ̀mí ara wọn tàbí kí wọ́n ti kékeré máa hùwà ọ̀daràn ju àwọn ọmọ yòókù lọ. Mílíọ̀nù kan àwọn ọmọ ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà làwọn òbí wọ́n ń kọra wọn sílẹ̀ lọ́dọọdún. Láàárín ọdún kan lórílẹ̀-èdè tá à ń wí yìí, ìdajì àwọn ọmọ táwọn òbí wọn fẹ́ra níṣu lọ́kà ló ṣeé ṣe káwọn òbí náà kọra wọn sílẹ̀ nígbà táwọn ọmọ wọn bá fi máa pé ẹni ọdún méjìdínlógún. Ìròyìn sì fi hàn pé bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ làwọn èwe kárí ayé ń kàgbákò lóríṣiríṣi.

Ṣé Ìdúróṣinṣin Wá Jẹ́ Ìlànà Tó Ga Ju Ohun Tọ́wọ́ Èèyàn Lè Tẹ̀ Ni?

Ìwà ìdúróṣinṣin táwọn èèyàn ń ní tẹ́lẹ̀ tó ṣàdédé pòórá lọ́sàn-án gangan yìí ti jẹ́ kí ọ̀rọ̀ tí Dáfídì Ọba sọ bágbà wa yìí mu wẹ́kú, pé: “Gbà mí là, Jèhófà, nítorí pé ẹni ìdúróṣinṣin ti wá sí òpin; nítorí pé àwọn olùṣòtítọ́ ti pòórá kúrò nínú àwọn ọmọ ènìyàn.” (Sáàmù 12:1) Kí ló dé tí ìdúróṣinṣin fi dàwátì níbi gbogbo? Nígbà tí Roger Rosenblatt ń kọ̀wé nínú ìwé ìròyìn Time, ó sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ànímọ́ tó dára ni ìdúróṣinṣin jẹ́, ìbẹ̀rù tí ń kóni láyà sókè, àìsí iyì ara ẹni, ìwà ìnìkànjọpọ́n àti ìlépa ipò ọlá tó wà nínú ẹ̀jẹ̀ wa kì í fẹ́ gbà fún wa láti ní ànímọ́ yìí.” Bíbélì ò pẹ́ ọ̀rọ̀ sọ nípa àkókò tá a wà yìí o, ó sọ pé: “Nítorí àwọn ènìyàn yóò jẹ́ olùfẹ́ ara wọn, . . . aláìdúróṣinṣin, aláìní ìfẹ́ni àdánidá.”—2 Tímótì 3:1-5.

Tá a bá ronú nípa ipa ńláǹlà tí níní ìdúróṣinṣin tàbí àìní in lè ní lórí bí ẹnì kan ṣe ń ronú àti bó ṣe ń hùwà, a lè wá béèrè pé, ‘Ta lẹni náà tí ìdúróṣinṣin wa tọ́ sí?’ Wo àlàyé tí àpilẹ̀kọ tó kàn máa ṣe lórí ìbéèrè yìí.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]

Fọ́tò tó wà lókè: © AFP/CORBIS