Inú Wọ́n Dùn Pé Wọ́n Ti Mọ̀wé Kà!
Inú Wọ́n Dùn Pé Wọ́n Ti Mọ̀wé Kà!
LÁWỌN apá ibì kan ní Solomon Islands, nǹkan bí ìpín ọgọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tó ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà báyìí ni ò mọ̀wé kà tẹ́lẹ̀. Èyí kò jẹ́ kí wọ́n lè kópa nínú àwọn ìpàdé ìjọ dáadáa, ó sì tún mú kó ṣòro fún wọn láti fi òtítọ́ Ìjọba náà kọ́ àwọn èèyàn. Ǹjẹ́ àwọn àgbàlagbà tí wọn ò lè fìdí ìgò kọ “ó,” á lè mọ̀wé kà báyìí?
Ìwé pẹlẹbẹ náà Apply Yourself to Reading and Writing, táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde ni wọ́n ń lò láwọn kíláàsì mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà ní ọ̀pọ̀ jù lọ ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí Solomon Islands. Àwọn ìrírí tó wà nísàlẹ̀ yìí jẹ́ àpẹẹrẹ díẹ̀ lára ọ̀pọ̀ èèyàn tá a ti fi ètò yìí ràn lọ́wọ́ láti mọ nǹkan púpọ̀ sí i. Èyí tó tiẹ̀ ṣe pàtàkì jù níbẹ̀ ni pé, mímọ ìwé kà ti jẹ́ kí wọ́n lè túbọ̀ jẹ́rìí lọ́nà tó múná dóko nípa ohun tí wọ́n gbà gbọ́.—1 Pétérù 3:15.
Míṣọ́nnárì kan tá a rán lọ sí ìjọ kan táwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run tó wà níbẹ̀ lé ní ọgọ́rùn-ún kíyè sí i pé nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ tí wọ́n ń lo Ilé Ìṣọ́, ìwọ̀nba díẹ̀ làwọn tó máa ń ní ìwé ìròyìn tiwọn lọ́wọ́, àwọn díẹ̀ ló sì máa ń lóhùn sí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Kí ló fà á? Àìmọ̀wé kà kúkú ni. Nígbà tí wọ́n ṣèfilọ̀ nínú ìjọ náà pé wọ́n fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ilé ẹ̀kọ́ mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà, míṣọ́nnárì náà fi tayọ̀tayọ̀ yọ̀ǹda ara rẹ̀ láti máa kọ́ àwọn èèyàn. Nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀, ìwọ̀nba èèyàn díẹ̀ ló wá. Àmọ́ nígbà tó ṣe díẹ̀, tọmọdé tàgbà tó lé ní ogójì bẹ̀rẹ̀ sí wá.
Kí ló wá tibẹ̀ jáde? Míṣọ́nnárì náà sọ pé: “Kò pẹ́ sígbà tí ilé ẹ̀kọ́ náà bẹ̀rẹ̀, mo lọ sọ́jà láago mẹ́fà àárọ̀ ọjọ́ kan láti lọ ra oúnjẹ táwa míṣọ́nnárì á jẹ. Ibẹ̀ ni mo ti rí lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà, títí kan àwọn tó kéré gan-an lọ́jọ́ orí, tí wọ́n ń ta àgbọn àti ẹ̀fọ́. Kí ló mú wọn ṣe èyí? Nítorí
àtirówó tí wọ́n á fi ra ohun ìkọ̀wé àti ìwé tí wọ́n á lò ní kíláàsì mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà kúkú ni! Bákan náà, ilé ẹ̀kọ́ yìí tún ń jẹ́ kó yá wọn lára láti gba ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ tí wọ́n á máa lò.” Ó fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Ní báyìí, tá a bá ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́, àtàgbà àtọmọdé ló máa ń dáhùn, ìjíròrò wa sì máa ń gbádùn mọ́ni.” Ìdùnnú wá ṣubú layọ̀ fún míṣọ́nnárì yìí nígbà tí mẹ́rin lára àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ náà sọ pé àwọn náà fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí wàásù ní gbangba. Wọ́n sọ pé èrèdí èyí ni pé àwọn “ò bẹ̀rù mọ́.”Àǹfààní táwọn akẹ́kọ̀ọ́ yìí ti jẹ látinú kíláàsì mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà kọjá pé wọ́n ti lè kọ̀wé tí wọ́n sì lè kà á nìkan. Bí àpẹẹrẹ, ìyàwó Ẹlẹ́rìí kan jẹ́ aláìgbàgbọ́. Ó máa ń fojú àwọn ará inú ìjọ rí màbo tẹ́lẹ̀. Kí ọ̀rọ̀ tó ṣe bí ọ̀rọ̀ báyìí, obìnrin yìí á ti bẹ̀rẹ̀ sí ju òkò lu àwọn èèyàn. Ó tiẹ̀ máa ń fi àpólà igi na àwọn obìnrin mìíràn pàápàá. Ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan tó bá sì tẹ̀ lé ọkọ rẹ̀ wá sípàdé, owú jíjẹ rẹ̀ le débi pé ńṣe lọkọ rẹ̀ máa ń dé ìgò dúdú sójú kí ìyàwó rẹ̀ má bàa fẹ̀sùn kàn án pé ó ń wo àwọn obìnrin mìíràn.
Àmọ́, kò pẹ́ tí ilé ẹ̀kọ́ náà bẹ̀rẹ̀ tí obìnrin yìí fi béèrè pé: “Ṣé èmi náà lè máa wá sí ilé ẹ̀kọ́ yìí?” Wọ́n ní ó lè máa wá. Látìgbà yìí ni kì í ti í pa ilé ẹ̀kọ́ jẹ, kì í sì í pa ìpàdé ìjọ jẹ. Kò fi ẹ̀kọ́ ìwé kíkà tó ń kọ́ ṣeré rárá, ó sì tẹ̀ síwájú gan-an, èyí múnú rẹ̀ dùn púpọ̀. Ohun tó béèrè lẹ́yìn náà ni pé: “Ṣé ẹ lè kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?” Tayọ̀tayọ̀ lọkọ rẹ̀ fi bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́. Ó ń tẹ̀ síwájú nínú ẹ̀kọ́ mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà rẹ̀, ó sì tún ń tẹ̀ síwájú nínú ìmọ̀ Bíbélì.
Baba ńlá ìṣòro ló máa jẹ́ fẹ́ni àádọ́ta ọdún tí ò fọwọ́ kan pẹ́ńsùlù rí láti kọ a, b, d. Báwọn mìíràn tiẹ̀ ṣe di pẹ́ńsùlù mú pinpin, tí wọ́n sì ń tẹ̀ ẹ́ mọ́ bébà nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ mú káwọn ọmọ ìka wọn lé ròrò. Àmọ́ lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ bíi mélòó kan tí wọ́n ti ń ṣakitiyan, lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà fi ẹ̀rín músẹ́ sọ pé: “Mo lè kọ̀wé lórí bébà báyìí láìtẹ ọwọ́ mọ́ ọn pinpin!” Ìtẹ̀síwájú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yìí tún wú àwọn tíṣà wọn náà lórí púpọ̀. Ọ̀kan lára wọn sọ pé: “Ó máa ń fún mi láyọ̀ púpọ̀ láti kọ́ àwọn èèyàn yìí. Àtẹ́wọ́ wàá-wòó táwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà máa ń pa tí ẹ̀kọ́ bá ti parí fi hàn pé wọ́n mọrírì ètò yìí tó wá látọ̀dọ̀ Jèhófà.”
Bí inú àwọn míṣọ́nnárì yìí ṣe ń dùn ni inú àwọn Ẹlẹ́rìí tó ti mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà yìí náà ń dùn ṣìnkìn. Èé ṣe? Ìdí ni pé wọ́n lè fi mímọ̀ tí wọ́n mọ̀ ọ́n kọ tí wọ́n sì mọ̀ ọ́n kà bọlá fún Jèhófà.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]
Àtàgbà àtọmọdé ló mọrírì ilé ẹ̀kọ́ mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà náà