“Máa Tọ̀ Mí Lẹ́yìn Nígbà Gbogbo”
“Máa Tọ̀ Mí Lẹ́yìn Nígbà Gbogbo”
“Ipa ọ̀nà yìí ni a pè yín sí, nítorí Kristi pàápàá jìyà fún yín, ó fi àwòkọ́ṣe sílẹ̀ fún yín kí ẹ lè tẹ̀ lé àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí.”—1 PÉTÉRÙ 2:21.
1, 2. Kí nìdí tí àpẹẹrẹ pípé tí Kristi fi lélẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ ò fi ga jù fún wa láti fara wé?
JÉSÙ KRISTI ni olùkọ́ títóbi lọ́lá jù lọ tó tíì gbé ayé rí. Láfikún sí i, ó tún jẹ́ ẹni pípé, kò dẹ́ṣẹ̀ rí ní gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ènìyàn. (1 Pétérù 2:22) Àmọ́, ṣé ó wá túmọ̀ sí pé àpẹẹrẹ tí Jésù fi lélẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ ti ga kọjá ohun táwa ẹ̀dá aláìpé lè fara wé ni? Ó tì o.
2 Gẹ́gẹ́ bá a ṣe rí i nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, ìfẹ́ ni ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ Jésù. Ìfẹ́ sì jẹ́ ohun kan tí gbogbo wa lè mú dàgbà. Gbogbo ìgbà ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa ń rọ̀ wá pé ká máa dàgbà, ká sì máa pọ̀ sí i nínú ìfẹ́ tá a ní fáwọn ẹlòmíràn. (Fílípì 1:9; Kólósè 3:14) Jèhófà ò retí pé káwọn ìṣẹ̀dá òun ṣe ju agbára wọn lọ rí. Àní nítorí pé “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́” tó sì ti dá wa ní àwòrán ara rẹ̀, a lè sọ pé ó dá wa láti máa fìfẹ́ hàn. (1 Jòhánù 4:8; Jẹ́nẹ́sísì 1:27) Nítorí náà, nígbà tá a bá ka ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pétérù tá a fi ṣe ẹṣin ọ̀rọ̀ yìí, a lè ní ìdánilójú pé a óò kẹ́sẹ járí. A lè tẹ̀ lé ìṣísẹ̀ Kristi pẹ́kípẹ́kí. Kódà, a lè ṣègbọràn sí àṣẹ Jésù pé: “Máa tọ̀ mí lẹ́yìn nígbà gbogbo.” (Lúùkù 9:23) Ẹ jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò bá a ṣe lè fara wé ìfẹ́ tí Kristi fi hàn, lákọ̀ọ́kọ́ sí òtítọ́ tó fi kọ́ni, lẹ́yìn náà sí àwọn èèyàn tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́.
Mímú Ìfẹ́ fún Òtítọ́ Tá A Kọ́ Dàgbà
3. Èé ṣe tó fi ṣòro fáwọn kan láti kẹ́kọ̀ọ́, àmọ́ ọ̀rọ̀ ìyànjú wo la rí nínú Òwe 2:1-5?
3 Ká tó lè nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ tá a fi ń kọ́ àwọn ẹlòmíràn, àwa fúnra wa gbọ́dọ̀ fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ irú òtítọ́ bẹ́ẹ̀. Láyé òde òní, irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ kì í sábà rọrùn láti ní. Àwọn kókó bí i kéèyàn má kàwé dójú ìlà àti àwọn àṣà búburú táwọn ọ̀dọ́ máa ń mú dàgbà ti sọ ọ̀pọ̀ di ẹni tó kórìíra ẹ̀kọ́ kíkọ́. Àmọ́, ó pọn dandan pé ká kẹ́kọ̀ọ́ látọ̀dọ̀ Jèhófà. Òwe 2:1-5 sọ pé: “Ọmọ mi, bí ìwọ yóò bá gba àwọn àsọjáde mi, tí ìwọ yóò sì fi àwọn àṣẹ tèmi ṣúra sọ́dọ̀ rẹ, láti lè dẹ etí rẹ sí ọgbọ́n, kí o lè fi ọkàn-àyà rẹ sí ìfòyemọ̀; jù bẹ́ẹ̀ lọ, bí o bá ké pe òye, tí o sì fọ ohùn rẹ jáde sí ìfòyemọ̀, bí o bá ń bá a nìṣó ní wíwá a bí fàdákà, tí o sì ń bá a nìṣó ní wíwá a kiri bí àwọn ìṣúra fífarasin, bí ọ̀ràn bá rí bẹ́ẹ̀, ìwọ yóò lóye ìbẹ̀rù Jèhófà, ìwọ yóò sì rí ìmọ̀ Ọlọ́run gan-an.”
4. Kí ló túmọ̀ sí láti “fi” ọkàn-àyà “sí” nǹkan, ojú ìwòye wo ló sì lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀?
4 Ṣàkíyèsí pé ní ẹsẹ ìkíní sí ìkẹrin, a rọ̀ wá léraléra pé ká máa sapá kì í ṣe kìkì láti ‘gbà’ àti láti ‘fi ṣúra sọ́dọ̀’ ara wa nìkan àmọ́ ká tún máa “bá a nìṣó ní wíwá a” àti “ní wíwá a kiri.” Àmọ́, kí ló máa sún wa ṣe gbogbo iṣẹ́ yìí? Tóò, kíyè sí gbólóhùn náà, “fi ọkàn-àyà rẹ sí ìfòyemọ̀.” Ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ sọ pé ọ̀rọ̀ ìyànjú yìí “kì í ṣe èyí tá a kàn ń bẹ̀bẹ̀ pé ká fún láfiyèsí nìkan; ó jẹ́ bíbéèrè fún àwọn ànímọ́ kan: ìyẹn ni pé kéèyàn máa hára gàgà láti gba ẹ̀kọ́.” Kí ló lè mú ká jẹ́ elétí ọmọ ká sì máa hára gàgà láti kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí Jèhófà fi ń kọ́ wa? Irú ojú tá a bá fi ń wo nǹkan ni. A ní láti wo “ìmọ̀ Ọlọ́run gan-an” gẹ́gẹ́ bíi “fàdákà” àti “ìṣúra fífarasin.”
5, 6. (a) Kí ló lè ṣẹlẹ̀ bí àkókò ti ń lọ, báwo la ò ṣe ní jẹ́ kíyẹn ṣẹlẹ̀? (b) Kí nìdí tá a fi ní láti máa fi kún àwọn ìṣúra ìmọ̀ tá a ti rí nínú Bíbélì?
5 Kò ṣòro láti ní irú ojú ìwòye bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ó ṣeé ṣe kí òtítọ́ nípa bí Jèhófà ṣe pinnu pé àwọn olóòótọ́ èèyàn yóò gbé títí láé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé wà lára “ìmọ̀ Ọlọ́run” tó o ti kọ́. (Sáàmù 37:28, 29) Nígbà tó o kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ yẹn, ó dájú pé ojúlówó ìṣúra lo kà á sí, ìyẹn ìmọ̀ kan tó jẹ́ kí èrò inú àti ọkàn-àyà rẹ kún fún ìrètí àti ayọ̀. Ìsinsìnyí wá ńkọ́? Àmọ́ bí àkókò ti ń lọ, ṣé ìmọrírì tó o ní fún ìṣúra rẹ ti ṣá? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, gbìyànjú láti ṣe nǹkan méjì. Ìkíní, sọ ìmọrírì rẹ dọ̀tun, ìyẹn ni pé kó o rán ara rẹ létí ìdí tó o fi mọyì òtítọ́ kọ̀ọ̀kan tí Jèhófà ti kọ́ ọ, títí kan àwọn tó o ti kọ́ ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn.
6 Èkejì, máa fi kún ìṣúra rẹ. Ó ṣe tán, tó o bá ṣèèṣì wú ohun iyebíye kan jáde nínú ilẹ̀, ṣe wàá kan jù ú sápò tí wàá sì máa bá ọ̀nà rẹ̀ lọ pé ìyẹn ti tó ọ ni? Tàbí wàá túbọ̀ gbẹ́ ilẹ̀ ibẹ̀ dáadáa láti wò ó bóyá ó ṣì kù síbẹ̀? Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kún fún òtítọ́ ṣíṣeyebíye tó dà bíi fàdákà àti ìṣúra fífarasin. Bó ti wù káwọn tó o ti rí pọ̀ tó, o ṣì lè rí púpọ̀ sí i. (Róòmù 11:33) Nígbà tó o bá kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ kan tó jẹ́ tuntun sí ọ, bi ara rẹ pé: ‘Kí ló mú kí òtítọ́ yìí jẹ́ ìṣúra? Ṣé ó túbọ̀ jẹ́ kí òye mi nípa Jèhófà àtàwọn ète rẹ̀ jinlẹ̀ sí i? Ṣé ó fún mi ní àwọn ìtọ́sọ́nà gbígbéṣẹ́ tó lè ràn mí lọ́wọ́ láti tẹ̀ lé ìṣísẹ̀ Jésù?’ Ṣíṣàṣàrò lórí irú àwọn ìbéèrè bẹ́ẹ̀ yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ tí Jèhófà ti kọ́ ọ.
Fífi Ìfẹ́ Hàn Sáwọn Òtítọ́ Tá A Fi Ń Kọ́ Àwọn Èèyàn
7, 8. Àwọn ọ̀nà díẹ̀ wo la lè gbà fi han àwọn ẹlòmíràn pé a nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ tá a kọ́ látinú Bíbélì? Sọ àpẹẹrẹ kan.
7 Bá a ṣe ń kọ́ àwọn ẹlòmíràn, báwo la ṣe lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ tá a ti kọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run? Nípa títẹ̀lé àpẹẹrẹ Jésù, a gbára lé Bíbélì gan-an nínú iṣẹ́ ìwàásù àti iṣẹ́ ìkọ́ni tá à ń ṣe. Ẹnu àìpẹ́ yìí la gba àwọn èèyàn Ọlọ́run káàkiri àgbáyé níyànjú pé kí wọ́n máa lo Bíbélì dáadáa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn fún gbogbo ènìyàn. Bó o ṣe ń tẹ̀ lé àbá yẹn, wá bó o ṣe máa jẹ́ kí onílé mọ̀ pé ìwọ alára mọyì ohun tó ò ń kà fún un látinú Bíbélì.—Mátíù 13:52.
8 Bí àpẹẹrẹ, kété lẹ́yìn ìkọlù àwọn apániláyà ní New York City, Kristẹni arábìnrin kan ń ka ìwé Sáàmù 46:1, 11 fáwọn tó bá pàdé lóde ẹ̀rí. Ó kọ́kọ́ bi àwọn èèyàn bí nǹkan ṣe rí lẹ́yìn ọ̀ràn ìbànújẹ́ náà. Ó fetí sílẹ̀ dáadáa sí ìdáhùn wọn, ó sì gbà pé òótọ́ lohun tí wọ́n sọ, lẹ́yìn náà ló wá sọ pé: “Ǹjẹ́ mo lè ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan fún yín, èyí tó ti tù mí nínú gan-an lákòókò líle koko yìí?” Àwọn tó pọ̀ jù lọ nínú wọn ló gbà pé kó ṣe bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ ìjíròrò alárinrin sì tẹ̀ lé e. Bí arábìnrin kan náà yìí bá ń bá àwọn ọ̀dọ́ sọ̀rọ̀, á sọ pé: “Mo ti ń fi Bíbélì kọ́ni láti àádọ́ta ọdún báyìí, ǹjẹ́ o mọ ohun tó yà mí lẹ́nu níbẹ̀? Mi ò tíì bá ìṣòro kan pàdé rí tí ìwé yìí ò lè yanjú.” Nípa fífi òótọ́ inú àti ìtara sọ̀rọ̀, à ń fi han àwọn èèyàn pé a mọyì ohun tá a ti kọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, a sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú.—Sáàmù 119:97, 105.
9, 10. Kí nìdí tó fi yẹ ká lo Bíbélì nígbà tá a bá ń dáhùn àwọn ìbéèrè tó jẹ mọ́ ìgbàgbọ́ wa?
9 Nígbà táwọn èèyàn bá bi wá láwọn ìbéèrè nípa ìgbàgbọ́ wa, àǹfààní tó dáa nìyẹn jẹ́ fún wa láti fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Nípa títẹ̀lé àpẹẹrẹ Jésù, a kì í gbé àwọn ìdáhùn wa karí èrò ti ara wa. (Òwe 3:5, 6) Dípò ìyẹn, Bíbélì la máa ń lò nígbà tá a bá ń dáhùn. Ṣé ò ń bẹ̀rù pé ẹnì kan lè bi ọ́ ní ìbéèrè tó ò ní lè dáhùn ni? Ṣàgbéyẹ̀wò ìgbésẹ̀ méjì tó dára tó o lè gbé.
10 Ṣe gbogbo ohun tó o bá lè ṣe láti múra sílẹ̀. Àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé pé: “Ẹ sọ Kristi di mímọ́ gẹ́gẹ́ bí Olúwa nínú ọkàn-àyà yín, kí ẹ wà ní ìmúratán nígbà gbogbo láti ṣe ìgbèjà níwájú olúkúlùkù ẹni tí ó bá fi dandan béèrè lọ́wọ́ yín ìdí fún ìrètí tí ń bẹ nínú yín, ṣùgbọ́n kí ẹ máa ṣe bẹ́ẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú inú tútù àti ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀.” (1 Pétérù 3:15) Ṣé o múra tán láti gbèjà ìgbàgbọ́ rẹ? Bí àpẹẹrẹ, bí ẹnì kan bá fẹ́ mọ ìdí tí o kì í fi í kópa nínú àwọn àṣà kan tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu, má wulẹ̀ sọ pé, “Ẹ̀sìn mi kì í ṣe nǹkan bẹ́ẹ̀.” Irú ìdáhùn bẹ́ẹ̀ lè fi hàn pé ò ń jẹ́ káwọn ẹlòmíràn pinnu fún ọ, ó sì ní láti jẹ́ pé inú ẹgbẹ́ òkùnkùn lo wà. Ohun tí ì bá dára jù láti sọ ni pé: “Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kà á léèwọ̀,” tàbí, “Kò ní múnú Ọlọ́run mi dùn.” Kó o sì wá ṣe àlàyé tó mọ́gbọ́n dání nípa ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀.—Róòmù 12:1.
11. Ìwé ìwádìí wo ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti gbára dì láti dáhùn àwọn ìbéèrè tó bá dìde nípa òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?
11 Tó o bá rí i pé o ò múra sílẹ̀, o ò ṣe lo àkókò díẹ̀ láti fi wo Àwọn Àkòrí Ọ̀rọ̀ Bíbélì fún Ìjíròrò, tó bá wà ní èdè rẹ? a Yẹ àwọn kókó ẹ̀kọ́ bíi mélòó kan táwọn èèyàn lè máa béèrè ìbéèrè nípa wọn wò, kó o sì há àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ bíi mélòó kan sórí. Jẹ́ kí Àwọn Àkòrí Ọ̀rọ̀ Bíbélì fún Ìjíròrò àti Bíbélì rẹ máa wà ní sẹpẹ́ ní gbogbo ìgbà. Má ṣe lọ́ tìkọ̀ láti lò wọ́n, sọ fún ẹni tó ń bi ọ́ ní ìbéèrè pé o ní ìwé ìwádìí kan tó o máa ń fẹ́ràn láti lò kí o lè rí ìdáhùn tó bá Bíbélì mu sí àwọn ìbéèrè.
12. Báwo la ṣe lè fèsì bí a kò bá mọ ìdáhùn sí ìbéèrè kan tó jẹ mọ́ Bíbélì?
12 Gbìyànjú láti má ṣe dààmú ju bó ṣe yẹ lọ. Kò sí ẹ̀dá aláìpé tó mọ gbogbo nǹkan tán. Nítorí náà, nígbà tí wọ́n bá bi ọ́ ní ìbéèrè kan tó jẹ mọ́ Bíbélì tí o ò sì mọ ìdáhùn rẹ̀, o lè fèsì báyìí pé: “O ṣeun tó o béèrè irú ìbéèrè tó mọ́gbọ́n dání yìí. Ká sòótọ́, mi ò mọ ìdáhùn rẹ̀, àmọ́ ó dá mi lójú pé Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Mo máa ń fẹ́ràn láti ṣèwádìí nínú Bíbélì, nítorí náà jẹ́ kí n lọ ṣèwádìí lórí ìbéèrè ẹ yẹn, kí n sì wá fún ọ lésì.” Irú ọ̀rọ̀ báyẹn téèyàn fi òótọ́ inú àti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ sọ lè ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún ìjíròrò síwájú sí i.—Òwe 11:2.
Ìfẹ́ fún Àwọn Tá À Ń Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́
13. Báwo la ṣe lè ní èrò tó tọ̀nà nípa àwọn tá à ń wàásù fún?
13 Jésù fìfẹ́ hàn sáwọn tó kọ́ lẹ́kọ̀ọ́. Báwo la ṣe lè fara wé e nínú èyí? Ẹ má ṣe jẹ́ ká lẹ́mìí àìgbatẹnirò sáwọn tó wà láyìíká wa láé. Lóòótọ́, “ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè” ti sún mọ́lé ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, púpọ̀ lára ẹgbàágbèje èèyàn tó wà láyé ló sì máa pa run. (Ìṣípayá 16:14; Jeremáyà ) Síbẹ̀, a ò mọ àwọn tó máa wà láàyè, a ò sì mọ àwọn tó máa kú. Ọjọ́ iwájú ni ìdájọ́ yẹn yóò wáyé, Jésù Kristi, ẹni tí Jèhófà yàn ni yóò sì ṣe é. Títí dìgbà tó bá ṣèdájọ́ yẹn, ojú ẹni tó lè di ìránṣẹ́ Jèhófà lọ́la la ó máa fi wo gbogbo èèyàn.— 25:33Mátíù 19:24-26; 25:31-33; Ìṣe 17:31.
14. (a) Báwo la ṣe lè yẹ ara wa wò láti mọ̀ bóyá a ní ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wo fáwọn èèyàn? (b) Àwọn ọ̀nà gbígbéṣẹ́ wo la lè gbà fi ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wo àti ìfẹ́ hàn sáwọn ẹlòmíràn?
14 Nítorí náà, bíi ti Jésù, à ń sapá láti lẹ́mìí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò fáwọn èèyàn. A lè bi ara wa pé: ‘Ǹjẹ́ mo máa ń gba tàwọn èèyàn tí wọ́n ti fi irọ́ àti màkàrúrù inú ẹ̀sìn, inú ètò ìṣèlú, àti ti ètò ìṣòwò ayé yìí tàn jẹ rò? Bó bá dà bíi pé wọn ò ka ìhìn tá à ń mú tọ̀ wọ́n wá sí, ǹjẹ́ mò ń gbìyànjú láti mọ ìdí tí wọ́n fi ń ronú lọ́nà bẹ́ẹ̀? Ǹjẹ́ mo gbà pé èmi alára àtàwọn kan tá a jọ ń sin Jèhófà báyìí ti ronú lọ́nà bẹ́ẹ̀ rí? Ǹjẹ́ mo máa ń mú ọ̀nà tí mo gbà ń wàásù bá ipò àwọn èèyàn mu? Àbí ńṣe ni mò ń pa àwọn èèyàn wọ̀nyí tì bí ẹni pé wọn ò lè yí padà mọ́?’ (Ìṣípayá 12:9) Nígbà táwọn èèyàn bá rí i pé lóòótọ́ la ní ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò fáwọn, ó ṣeé ṣe kí wọ́n tẹ́wọ́ gba ìhìn tá à ń jẹ́ fún wọn. (1 Pétérù 3:8) Ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò tún lè mú ká túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ àwọn tá à ń bá pàdé lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. A lè kọ ìbéèrè wọn àti ohun tó ń jẹ wọ́n lọ́kàn sílẹ̀. Nígbà tá a bá padà wá, a lè fi hàn wọ́n pé a ti ń ronú lórí ohun tí wọ́n sọ nígbà tá a wá sọ́dọ̀ wọn tẹ́lẹ̀. Tí wọ́n bá sì ní ọ̀ràn kánjúkánjú tó ń jẹ wọ́n lọ́kàn, a lè fún wọn ní ìrànlọ́wọ́ tó ṣe gúnmọ́.
15. Èé ṣe tó fi yẹ ká wo ànímọ́ rere táwọn èèyàn ní, báwo la sì ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀?
15 Bíi ti Jésù, a ó máa wo ànímọ́ tó dára lára àwọn èèyàn. Bóyá òbí kan tó jẹ́ anìkàntọ́mọ ń sapá lọ́nà tó dára gan-an láti tọ́ àwọn ọmọ rẹ̀. Ọkùnrin kan ń forí ṣe fọrùn ṣe láti pèsè fún ìdílé rẹ̀. Àgbàlagbà kan ń fìfẹ́ hàn sí àwọn ọ̀ràn tẹ̀mí. Ǹjẹ́ a máa ń kíyè sí irú àwọn ànímọ́ bẹ́ẹ̀ lára àwọn tá à ń bá pàdé, ká sì gbóríyìn fún wọn bó ṣe yẹ? Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, à ń tẹnu mọ́ ibi tí èdè wa ti yéra, ìyẹn sì lè ṣí ọ̀nà sílẹ̀ láti jẹ́rìí nípa Ìjọba náà.—Ìṣe 26:2, 3.
Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀ Ṣe Pàtàkì Nínú Fífi Ìfẹ́ Hàn
16. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́, ká sì máa tẹrí ba fáwọn tá à ń wàásù fún?
16 Ìfẹ́ tá a ní sáwọn èèyàn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ yóò ràn wá lọ́wọ́ láti kọbi ara sí ìkìlọ̀ ọlọgbọ́n tó wà nínú Bíbélì, to sọ pé: “Ìmọ̀ a máa wú fùkẹ̀, ṣùgbọ́n ìfẹ́ a máa gbéni ró.” (1 Kọ́ríńtì 8:1) Jésù ní ìmọ̀ tó ga, síbẹ̀, kò gbéra ga rí. Nítorí náà, bó o ṣe ń sọ ìgbàgbọ́ rẹ fáwọn èèyàn, yẹra fún iyàn jíjà tàbí ṣíṣe bíi pé o gbọ́n jù wọ́n lọ. Góńgó wa ni pé ká dé inú ọkàn àwọn èèyàn ká sì tún jẹ́ kí òtítọ́ tá a fẹ́ràn gan-an fa àwọn èèyàn mọ́ra. (Kólósè 4:6) Rántí pé nígbà tí Pétérù gba àwọn Kristẹni níyànjú láti wà ní ìmúratán nígbà gbogbo láti ṣe ìgbèjà, ó fi ìránnilétí náà kún un pé a gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ “pa pọ̀ pẹ̀lú inú tútù àti ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀.” (1 Pétérù 3:15) Bí a bá jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́ tí a sì ní ìtẹríba, ó ṣeé ṣe ká fa àwọn èèyàn sọ́dọ̀ Ọlọ́run tá à ń sìn.
17, 18. (a) Báwo ló ṣe yẹ ká ṣe sáwọn tó ń ṣe lámèyítọ́ pé a ò tóótun láti jẹ́ òjíṣẹ́? (b) Èé ṣe tí mímọ àwọn èdè tá a fi kọ Bíbélì láyé ìgbàanì kò fi pọn dandan fún akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
17 Kò sídìí tó fi yẹ ká máa fi ìmọ̀ tá a ní àti bí a ṣe kàwé tó yangàn fáwọn èèyàn. Bí àwọn kan ní ìpínlẹ̀ rẹ kò bá fẹ́ fetí sí ẹni tí kò bá gba ìwé ẹ̀rí tàbí oyè jáde ní yunifásítì, má ṣe jẹ́ kí ohun tí wọ́n ń ṣe yìí kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọ. Jésù kò fetí sí àtakò táwọn èèyàn ń ṣe pé kò lọ sílé ìwé àwọn rábì tí wọ́n kà sí pàtàkì nígbà ayé rẹ̀; bẹ́ẹ̀ náà ni kò jẹ́ kí ẹ̀tanú tó gbòde kan nígbà yẹn sọ òun di nǹkan míì, kó wá máa gbìyànjú láti fi ìmọ̀ ńláǹlà tó ní yangàn fáwọn èèyàn.—Jòhánù 7:15.
18 Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti ìfẹ́ ṣe pàtàkì gan-an fáwọn Kristẹni òjíṣẹ́ ju ìmọ̀ ẹ̀kọ́ ayé èyíkéyìí tí wọ́n lè ní lọ. Àgbà olùkọ́ náà, Jèhófà, ló mú wa tóótun fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà. (2 Kọ́ríńtì 3:5, 6) Àti pé láìfi ohun táwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì ń sọ pè, kò pọn dandan pé ká kọ́ àwọn èdè tá a fi kọ Bíbélì láyé ìgbàanì ká tó di olùkọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Jèhófà mí sáwọn èèyàn láti kọ Bíbélì lọ́nà tó ṣe kedere, tó sì múná dóko débi pé ṣàṣà lẹni tí ò lè lóye òtítọ́ ṣíṣeyebíye tó wà nínú rẹ̀. Àwọn òtítọ́ wọ̀nyẹn kò yí padà, kódà lẹ́yìn tí wọ́n ti túmọ̀ rẹ̀ sí àwọn ọgọ́rọ̀ọ̀rún èdè. Nítorí náà, òótọ́ ni pé níní ìmọ̀ àwọn èdè àtijọ́ lè wúlò nígbà mìíràn, síbẹ̀ kò pọn dandan. Àti pé, fífi ẹ̀bùn sísọ onírúurú èdè yangàn lè mú kéèyàn pàdánù ànímọ́ tó pọn dandan fún Kristẹni tòótọ́ láti ní—ìyẹn jíjẹ́ ẹni tó ṣeé kọ́ lẹ́kọ̀ọ́.—1 Tímótì 6:4.
19. Ọ̀nà wo ni iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni wa gbà jẹ́ iṣẹ́ ìsìn kan?
19 Kò sí àní-àní pé iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni wa jẹ́ iṣẹ́ kan tó gba kéèyàn lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. Gbogbo ìgbà la máa ń kojú àtakò, ìdágunlá, kódà inúnibíni pàápàá. (Jòhánù 15:20) Àmọ́, bí a ti ń fi òótọ́ inú ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, iṣẹ́ ìsìn pàtàkì là ń ṣe. Bí a bá ń fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ sin àwọn ẹlòmíràn nínú iṣẹ́ yìí, ìfẹ́ tí Jésù Kristi fi hàn sáwọn èèyàn là ń fara wé. Rò ó wò ná: Tá a bá ní láti wàásù fún ẹgbẹ̀rún àwọn tó ń dágunlá tàbí àwọn alátakò ká tó lè dé ọ̀dọ̀ ẹni bí àgùntàn kan ṣoṣo, ǹjẹ́ ìsapá yẹn ò tó èyí tó yẹ ká ṣe? Ó tó bẹ́ẹ̀ mọ̀nà! Nítorí náà, nípa títẹramọ́ iṣẹ́ náà, láìjuwọ́sílẹ̀, ńṣe là ń fi tinútinú sin àwọn ẹni bí àgùntàn tí a ò tíì bá pàdé. Dájúdájú, Jèhófà àti Jésù yóò rí i dájú pé ọ̀pọ̀ irú àwọn ẹni ṣíṣeyebíye bẹ́ẹ̀ la óò rí tí a ó sì ràn lọ́wọ́ kí òpin náà tó dé.—Hágáì 2:7.
20. Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà fi àpẹẹrẹ ìwà tiwa kọ́ àwọn ẹlòmíràn lẹ́kọ̀ọ́?
20 Fífi àpẹẹrẹ ìwà tiwa kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ tún jẹ́ ọ̀nà mìíràn láti fi hàn pé a múra tán láti sin àwọn ẹlòmíràn. Bí àpẹẹrẹ, a fẹ́ kọ́ àwọn èèyàn pé sísin Jèhófà, “Ọlọ́run aláyọ̀,” ni ohun tó dára jù lọ, ohun sì ni ọ̀nà ìgbésí ayé tó nítumọ̀ jù lọ téèyàn lè gbé. (1 Tímótì 1:11) Bí wọ́n ṣe ń kíyè sí ìwà wa àti bí a ṣe ń bá àwọn aládùúgbò wa, àwọn ọmọ tá a jọ ń lọ sílé ìwé, àtàwọn òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ wa lò, ǹjẹ́ wọ́n lè rí i pé a jẹ́ aláyọ̀, a sì nítẹ̀ẹ́lọ́rùn? Bákan náà la tún ń kọ́ àwọn tá à ń bá ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pé ìjọ Kristẹni jẹ́ ibi tí ìfẹ́ ti gbilẹ̀ nínú ayé oníkanra táwọn èèyàn kò ti ń yá mọ́ni yìí. Ǹjẹ́ àwọn tá à ń bá ṣèkẹ́kọ̀ọ́ lé rí i kedere pé a nífẹ̀ẹ́ gbogbo àwọn tó wà nínú ìjọ, a sì ń sa gbogbo ipá wa láti jẹ́ kí àlàáfíà wà láàárín ara wa?—1 Pétérù 4:8.
21, 22. (a) Yíyẹ ara ẹni wò nítorí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa lè sún wa dórí yíyọ̀ǹda ara wa fún àwọn àǹfààní wo? (b) Kí la óò jíròrò nínú àwọn àpilẹ̀kọ tó wà nínú ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ tó tẹ̀ lé èyí?
21 Ẹ̀mí ìmúratán tá a ní sí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa lè mú ká máa yẹ ara wa wò lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀ láìṣàbòsí, ọ̀pọ̀ ti rí i pé àwọn lè mú iṣẹ́ ìsìn àwọn gbòòrò sí i nípa títẹ́wọ́ gba iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún tàbí kí wọ́n lọ sìn láwọn ibi tí àìní gbé pọ̀. Àwọn kan ti pinnu láti kọ́ èdè àjèjì kí wọ́n lè sin àwọn àjèjì tó ń ṣí wá sí ìlú wọn. Bí irú àǹfààní wọ̀nyẹn bá ṣí sílẹ̀ fún ọ, fara balẹ̀ gbé wọn yẹ̀ wò tàdúràtàdúrà. Ìgbésí ayé iṣẹ́ ìsìn ń mú ayọ̀ ńlá, ìtẹ́lọ́rùn, àti ìbàlẹ̀ ọkàn wá.—Oníwàásù 5:12.
22 Ní gbogbo ọ̀nà, ẹ jẹ́ ká máa bá a nìṣó láti fara wé Jésù Kristi nípa mímú kí ìfẹ́ tá a ní fún òtítọ́ tá a fi ń kọ́ni àti èyí tá a ní fáwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ gbòòrò sí i. Mímú ìfẹ́ dàgbà àti fífi ìfẹ́ hàn láwọn ọ̀nà méjèèjì wọ̀nyí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti fi ìpìlẹ̀ rere lélẹ̀ fún jíjẹ́ olùkọ́ bíi ti Kristi. Àmọ́, báwo la ṣe lè mọlé lórí ìpìlẹ̀ yẹn? Nínú ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ tó tẹ̀ lé èyí, ọ̀wọ́ àwọn àpilẹ̀kọ kan níbẹ̀ yóò jíròrò bíi mélòó kan lára àwọn ọ̀nà pàtó tí Jésù gbà kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Báwo ló ṣe dá wa lójú pé àpẹẹrẹ Jésù gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ kò ga kọjá èyí tá a lè fara wé?
• Báwo la ṣe lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn òtítọ́ tá a ti kọ́ látinú Bíbélì?
• Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ bí ìmọ̀ wa ṣe ń pọ̀ sí i?
• Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà fìfẹ́ hàn sáwọn tá à ń gbìyànjú láti kọ́ lẹ́kọ̀ọ́?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Ṣe gbogbo ohun tó o bá lè ṣe láti múra sílẹ̀
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]
Tó o bá ka “ìmọ̀ Ọlọ́run” sí ìṣúra, o lè lo Bíbélì lọ́nà tó gbéṣẹ́
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
À ń fi ìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn nípa sísọ ìhìn rere fún wọn