Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Mo Fi Àwòṣe Lélẹ̀ Fun Yín”

“Mo Fi Àwòṣe Lélẹ̀ Fun Yín”

“Mo Fi Àwòṣe Lélẹ̀ Fun Yín”

“Ó yẹ kí ẹ jẹ́ olùkọ́ ní ojú ìwòye ibi tí àkókò dé yìí.”—HÉBÉRÙ 5:12.

1. Kí nìdí tí ọ̀rọ̀ inú Hébérù 5:12 fi lè mú kí Kristẹni kan ṣàníyàn?

 BÓ O ṣe ń ka ọ̀rọ̀ onímìísí tó wà nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a fi ṣe ẹṣin ọ̀rọ̀ yìí, ǹjẹ́ ó mú kó o ṣàníyàn nípa ara rẹ? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ìwọ nìkan kọ́ ni ọ̀ràn náà kàn. Gẹ́gẹ́ bí ọmọlẹ́yìn Kristi, a mọ̀ pé a gbọ́dọ̀ jẹ́ olùkọ́. (Mátíù 28:19, 20) A mọ̀ pé àkókò tá a wà ti sọ ọ́ di ọ̀rọ̀ kánjúkánjú fún wa láti kọ́ àwọn èèyàn lọ́nà tó gbéṣẹ́ bí a bá ṣe lè ṣe é tó. A sì mọ̀ pé ohun tá à ń fi kọ́ni lè túmọ̀ sí ìyè tàbí ikú fáwọn tá à ń kọ́! (1 Tímótì 4:16) Nítorí náà, a lè bí ara wa pé: ‘Ṣé irú olùkọ́ tó yẹ kí n jẹ́ ni mo jẹ́? Báwo ni mo ṣe lè sunwọ̀n sí i?’

2, 3. (a) Báwo ni olùkọ́ kan ṣe ṣàlàyé ìpìlẹ̀ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tó gbéṣẹ́? (b) Àwòṣe wo ni Jésù fi lélẹ̀ fún wa nípa kíkọ́nilẹ́kọ̀ọ́?

2 Kò yẹ kí irú àníyàn bẹ́ẹ̀ kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wa. Tá a bá ń ronú pé kíkọ́ni ń béèrè àwọn ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀, a lè máa rò pé kò ní rọrùn fún wa rárá láti sunwọ̀n sí i. Àmọ́ ìpìlẹ̀ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tó gbéṣẹ́ kì í ṣe ọ̀nà téèyàn gbà kọ́ni bí kò ṣe ohun kan tó ṣe pàtàkì gan-an jùyẹn lọ. Kíyè sí ohun tí olùkọ́ kan tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ kọ sínú ìwé kan lórí kókó náà, ó ní: “Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tó gbéṣẹ́ kò sinmi lórí kíkọ́ni lọ́nà kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀, kò sinmi lórí àwọn ìwéwèé kan tàbí àwọn ìgbésẹ̀ kan téèyàn gbé. . . . Ìfẹ́ ni ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú kíkọ́nilẹ́kọ̀ọ́.” Lóòótọ́, ojú ti olùkọ́ ayé ló fi wo ọ̀ràn náà. Àmọ́, kókó tó fà yọ yìí lè gbéṣẹ́ gan-an nínú ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tá à ń ṣe gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni. Lọ́nà wo?

3 Kò sí olùkọ́ mìíràn tó jẹ́ Àwòfiṣàpẹẹrẹ fún wa bí kò ṣe Jésù Kristi. Jésù sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Mo fi àwòṣe lélẹ̀ fún yín.” (Jòhánù 13:15) Àpẹẹrẹ bí Jésù ṣe fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ hàn ló ń tọ́ka sí, àmọ́ àwòṣe tó fi lélẹ̀ fún wa kan olórí iṣẹ́ tó wá ṣe gẹ́gẹ́ bí ènìyàn lórí ilẹ̀ ayé—ìyẹn ni iṣẹ́ kíkọ́ àwọn èèyàn ní ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. (Lúùkù 4:43) Nípa bẹ́ẹ̀, bó o bá fẹ́ fi ọ̀rọ̀ kan ṣoṣo ṣàpèjúwe iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé “ìfẹ́” ni ọ̀rọ̀ tí wàá fẹ́ lò, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? (Kólósè 1:15; 1 Jòhánù 4:8) Ìfẹ́ tí Jésù ní fún Jèhófà, baba rẹ̀ ọ̀run ni èyí tó ga jù lọ. (Jòhánù 14:31) Àmọ́, gẹ́gẹ́ bí olùkọ́, Jésù tún fìfẹ́ hàn láwọn ọ̀nà méjì mìíràn. Ó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ tó fi ń kọ́ni, ó sì nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́. Ẹ jẹ́ ká túbọ̀ fojú ṣùnnùkùn wo apá méjì nínú àwòṣe tó fi lélẹ̀ fún wa.

Ìfẹ́ Tó Ti Wà Tipẹ́ fún Òtítọ́ Ọlọ́run

4. Báwo ni Jésù ṣe mú ìfẹ́ fún ẹ̀kọ́ tí Jèhófà kọ́ ọ dàgbà?

4 Ìhà tí olùkọ́ kan bá kọ sí ẹ̀kọ́ tó fi ń kọ́ àwọn èèyàn máa ń nípa tó lágbára lórí bí ẹ̀kọ́ náà á ṣe múná dóko tó. Tó bá ní ẹ̀mí ìdágunlá, ó lè hàn síta kó sì ran àwọn tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́. Jésù kò ní ẹ̀mí ìdágunlá sí òtítọ́ ṣíṣeyebíye tó fi ń kọ́ni nípa Jèhófà àti Ìjọba Rẹ̀. Ìfẹ́ tí Jésù ní sí ẹ̀kọ́ yìí jinlẹ̀ gan-an ni. Àtìgbà tí òun alára ti jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ló ti mú ìfẹ́ yẹn dàgbà. Àtìbẹ̀rẹ̀ dópin ọ̀pọ̀ ọdún tí Ọmọ bíbí kan ṣoṣo náà fi wà kó tó di ẹ̀dá ènìyàn ló fi jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ tó mọṣẹ́ rẹ̀ níṣẹ́. Ìwé Aísáyà 50:4, 5 ṣàkọsílẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ tó bá a mu wẹ́kú yìí pé: “Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ tìkára rẹ̀ ti fún mi ní ahọ́n àwọn tí a kọ́, kí n lè mọ bí a ti ń fi ọ̀rọ̀ dá ẹni tí ó ti rẹ̀ lóhùn. Ó ń jí mi ní òròòwúrọ̀; ó ń jí etí mi láti gbọ́, bí àwọn tí a kọ́. Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ tìkára rẹ̀ ti ṣí etí mi, èmi, ní tèmi, kò sì ya ọlọ̀tẹ̀. Èmi kò yí padà sí òdì-kejì.”

5, 6. (a) Ìrírí wo ló hàn gbangba pé Jésù ní nígbà tó ṣe batisí, ipa wo ló sì ní lórí rẹ̀? (b) Ìyàtọ̀ wo la rí nínú bí Jésù ṣe lo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti bí Sátánì ṣe lò ó?

5 Nígbà tí Jésù ń dàgbà gẹ́gẹ́ bí èèyàn lórí ilẹ̀ ayé, ó ń bá a nìṣó láti nífẹ̀ẹ́ ọgbọ́n Ọlọ́run. (Lúùkù 2:52) Ó ní ìrírí àrà ọ̀tọ̀ kan nígbà tó ṣe batisí. Lúùkù 3:21 sọ pé: “Ọ̀run ṣí sílẹ̀.” Ó hàn gbangba pé ìgbà yẹn ni Jésù rántí pé òun ti wà tẹ́lẹ̀ kí òun tó di ẹ̀dá ènìyàn. Ẹ̀yìn ìyẹn ló wá fi ogójì ọjọ́ gbààwẹ̀ nínú aginjù. Inú rẹ̀ ti ní láti dùn gan-an nígbà tó ń ṣàṣàrò lórí àwọn àkókò tó fi ń gba ìtọ́ni lọ́dọ̀ Jèhófà lókè ọ̀run. Àmọ́, kò pẹ́ kò jìnnà tí ìfẹ́ tó ní fún òtítọ́ Ọlọ́run fi di èyí tá a dán wò.

6 Nígbà tí àárẹ̀ mú Jésù, tí ebi sì ń pa á ni Sátánì gbìyànjú láti dán an wò. Ẹ ò rí i pé ìyàtọ̀ tó wà láàárín àwọn méjèèjì tó jẹ́ ọmọ Ọlọ́run yìí ò kéré rárá! Àwọn méjèèjì ló ṣàyọlò ọ̀rọ̀ látinú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù—àmọ́ ẹ̀mí tí wọ́n fi ṣe é yàtọ̀ síra pátápátá. Sátánì gbé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbòdì, ó fi àìlọ́wọ̀ lò ó fún àǹfààní ara rẹ̀. Ní ti tòótọ́, ọlọ̀tẹ̀ yẹn kò ní èrò mìíràn lọ́kàn ju pé kó tẹ́ńbẹ́lú òtítọ́ Ọlọ́run. Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, Jésù ṣàyọlò ọ̀rọ̀ inú Ìwé Mímọ́ pẹ̀lú ojúlówó ìfẹ́, ó fara balẹ̀ lo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nínú ìdáhùn rẹ̀ kọ̀ọ̀kan. Jésù ti wà tipẹ́tipẹ́ ṣáájú àkókò tá a kọ àwọn ọ̀rọ̀ onímìísí wọ̀nyẹn, síbẹ̀ kò fọwọ́ yẹpẹrẹ mú wọn rárá. Wọ́n jẹ́ òtítọ́ ṣíṣeyebíye látọ̀dọ̀ Baba rẹ̀ ọ̀run! Ó sọ fún Sátánì pé irú ọ̀rọ̀ tó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì ju oúnjẹ lọ. (Mátíù 4:1-11) Bẹ́ẹ̀ ni o, Jésù nífẹ̀ẹ́ sí gbogbo òtítọ́ tí Jèhófà fi kọ́ ọ. Àmọ́ báwo ló ṣe wá fi ìfẹ́ yẹn hàn gẹ́gẹ́ bí olùkọ́?

Ó Nífẹ̀ẹ́ Òtítọ́ Tó Fi Ń Kọ́ni

7. Kí nìdí tí Jésù ò fi hùmọ̀ ẹ̀kọ́ ti ara rẹ̀?

7 Gbogbo ìgbà ní ìfẹ́ tí Jésù ní sí òtítọ́ tó fi ń kọ́ni máa ń hàn kedere. Ó ṣe tán, ó lè gbé àwọn èrò ara rẹ̀ kalẹ̀ tó bá fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀. Ó ní ìmọ̀ àti ọgbọ́n tó pọ̀ gan-an. (Kólósè 2:3) Síbẹ̀síbẹ̀, gbogbo ìgbà ló ń rán àwọn olùgbọ́ rẹ̀ létí pé gbogbo ohun tí òun fi ń kọ́ni kò ti ọ̀dọ̀ òun wá bí kò ṣe láti ọ̀dọ̀ Baba òun lọ́run. (Jòhánù 7:16; 8:28; 12:49; 14:10) Ó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ tó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá gan-an débi pé kò jẹ́ fi èrò ti ara rẹ̀ rọ́pò wọn.

8. Nígbà tí Jésù bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, báwo ló ṣe fi àwòṣe náà lélẹ̀ pé òun gbára lé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?

8 Nígbà tí Jésù bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ fún gbogbo ènìyàn, kíá ló fi àwòṣe kan lélẹ̀. Kíyè sí ọ̀nà tó kọ́kọ́ gbà kéde fáwọn èèyàn Ọlọ́run pé òun ni Mèsáyà tá a ṣèlérí. Ṣé ó wulẹ̀ fara han ọ̀pọ̀ èrò ni, tó kéde pé òun ni Kristi, tó sì ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu bíi mélòó kan láti fi hàn pé òótọ́ lòun sọ? Rárá o. Ńṣe ló lọ sínú sínágọ́gù kan, níbi táwọn èèyàn Ọlọ́run ti máa ń ka Ìwé Mímọ́. Ibẹ̀ ló ti ka ìwé Aísáyà 61:1, 2 sókè ketekete, tó sì ṣàlàyé pé òun ni àwọn òtítọ́ tó wà nínú àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. (Lúùkù 4:16-22) Ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu tó ṣe ló ràn án lọ́wọ́ láti fi hàn pé Ọlọ́run wà lẹ́yìn òun. Síbẹ̀síbẹ̀, ó máa ń gbára lé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nínú ẹ̀kọ́ tó fi ń kọ́ni.

9. Nínú bí Jésù ṣe bá àwọn Farisí lò, báwo ló ṣe fi ìfẹ́ adúróṣinṣin tó ní sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run hàn?

9 Nígbà táwọn alátakò nípa ọ̀ràn ìsìn gbé ìpèníjà dìde sí Jésù, kò bẹ̀rẹ̀ sí bá wọn ṣàròyé láti fi hàn pé òun mọ̀ jù wọ́n lọ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé á borí wọn dáadáa nínú irú ìjiyàn bẹ́ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ kí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run já wọn ní koro. Bí àpẹẹrẹ, rántí ìgbà táwọn Farisí fẹ̀sùn kan àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù pé wọ́n rú òfin sábáàtì nípa yíya àwọn erín ọkà bíi mélòó kan jẹ ní pápá kan tí wọ́n gbà kọjá. Jésù fèsì pé: “Ṣé ẹ kò tíì ka ohun tí Dáfídì ṣe nígbà tí ebi ń pa òun àti àwọn ọkùnrin tí ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀?” (Mátíù 12:1-5) Dájúdájú, àwọn olódodo àṣelékè wọ̀nyẹn ti lè ka ìtàn onímìísí tó wà nínú 1 Sámúẹ́lì 21:1-6 yẹn dáadáa. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, wọ́n ti kùnà láti fòye mọ ìjẹ́pàtàkì ẹ̀kọ́ tó wà níbẹ̀. Àmọ́, Jésù ní tiẹ̀ kò wulẹ̀ ka ìtàn náà lásán. Ó ti ronú lé e lórí, ó sì ti fi ìsọfúnni tó wà níbẹ̀ sọ́kàn. Ó nífẹ̀ẹ́ sí àwọn ìlànà tí Jèhófà tipasẹ̀ àyọkà yẹn kọ́ni. Nítorí náà, ó lo ìtàn yẹn, àti àpẹẹrẹ kan látinú Òfin Mósè, láti fi bí Òfin náà ṣé mọ́gbọ́n dání tó hàn. Bákan náà ni ìfẹ́ adúróṣinṣin tí Jésù ní sún un láti gbèjà Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójú gbogbo ipá táwọn aṣáájú ìsìn ń sà láti yí i po fún àǹfààní ara wọn, tàbí láti fi àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ ẹ̀dá ènìyàn bò ó mọ́lẹ̀.

10. Báwo ni Jésù ṣe mú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa bí ẹ̀kọ́ tó máa fi kọ́ni ṣe máa jẹ́ ojúlówó tó ṣẹ?

10 Ìfẹ́ tí Jésù ní sí ẹ̀kọ́ tó fi ń kọ́ni kò lè jẹ́ kó kàn máa kọ́ àwọn èèyàn gbuurugbu, lọ́nà tí ẹ̀kọ́ rẹ̀ fi máa sú wọn tàbí lọ́nà tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò fi ní nítumọ̀ létí wọn. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ onímìísí ti fi hàn pé Mèsáyà náà yóò sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ‘ẹwà ní ètè rẹ̀,’ nípa lílo “àwọn ọ̀rọ̀ agbógoyọ.” (Sáàmù 45:2; Jẹ́nẹ́sísì 49:21) Jésù mú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyẹn ṣẹ nípa jíjẹ́ kí àwọn ìhìn òun dùn ún gbọ́ létí, kó sì yéni yékéyéké, nípa lílo “àwọn ọ̀rọ̀ alárinrin” bó ṣe ń fi òtítọ́ tó nífẹ̀ẹ́ sí gan-an kọ́ni. (Lúùkù 4:22) Kò sí àní-àní pé ìṣesí rẹ̀ máa ń fi ìtara ọkàn tó ní hàn, ayọ̀ tí ẹ̀kọ́ tó fi ń kọ́ni ń fún un sì máa ń hàn lójú rẹ̀. Ẹ ò rí i pé ìdùnnú ńlá ló jẹ́ láti fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀, àwòṣe àtàtà ló sì jẹ́ fún wa láti tẹ̀ lé nígbà tá a bá ń bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa ohun tí a ti kọ́!

11. Kí nìdí táwọn ànímọ́ tí Jésù ní gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ kò fi sọ ọ́ di ẹni tó ń gbéra ga?

11 Ǹjẹ́ ọ̀nà kíkàmàmà tí Jésù gbà lóye òtítọ́ àtọ̀runwá àti bí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe ń wọni lọ́kàn ṣinṣin sọ ọ́ di ẹni tó ń gbéra ga? Ohun táwọn èèyàn tó jẹ́ olùkọ́ sábà máa ń ṣe nìyẹn. Àmọ́, rántí pé Jésù gbọ́n lọ́nà tó fi ìbẹ̀rù Ọlọ́run hàn. Irú ọgbọ́n bẹ́ẹ̀ kò sì fàyè gba ìjọra-ẹni-lójú, nítorí pé “ọgbọ́n wà pẹ̀lú àwọn amẹ̀tọ́mọ̀wà.” (Òwe 11:2) Ohun mìíràn tún wà tí kò jẹ́ kí Jésù di agbéraga tàbí kí ó jọ ara rẹ̀ lójú.

Jésù Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn Tó Ń Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́

12. Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé òun ò fẹ́ káwọn ọmọlẹ́yìn òun máa bẹ̀rù òun?

12 Ìfẹ́ jíjinlẹ̀ tí Jésù ní sáwọn èèyàn máa ń hàn nínú bó ṣe ń kọ́ wọn. Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ kì í sọ àwọn èèyàn di ẹni yẹpẹrẹ, kò dà bíi ti àwọn agbéraga èèyàn. (Oníwàásù 8:9) Lẹ́yìn tí Pétérù rí ọ̀kan lára àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe, ẹnu yà á tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tó fi wólẹ̀ lẹ́bàá eékún Jésù. Àmọ́ Jésù ò fẹ́ káwọn ọmọlẹ́yìn òun ní ìbẹ̀rù oníjìnnìjìnnì fún òun. Ó sọ lọ́nà pẹ̀lẹ́tù pé: “Dẹ́kun fífòyà,” ó wá sọ fún Pétérù nípa iṣẹ́ amóríyá ti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn tí Pétérù máa kópa nínú rẹ̀. (Lúùkù 5:8-10) Jésù fẹ́ kó jẹ́ pé ìfẹ́ táwọn ọmọ ẹ̀yìn òun ní fún òtítọ́ ṣíṣeyebíye nípa Ọlọ́run ló máa sún wọn ṣe ohun tí ó tọ́, kó máà jẹ́ ìbẹ̀rù olùkọ́ wọn.

13, 14. Àwọn ọ̀nà wo ni Jésù gbà fi ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò hàn sáwọn èèyàn?

13 Ìfẹ́ tí Jésù ní fáwọn èèyàn tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ tún hàn kedere nínú bó ṣe ní ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò fún wọn. “Nígbà tí ó rí àwọn ogunlọ́gọ̀, àánú wọn ṣe é, nítorí a bó wọn láwọ, a sì fọ́n wọn ká bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́ àgùntàn.” (Mátíù 9:36) Ó káàánú wọn nítorí ipò òṣì tí wọ́n wà, ìyẹn sì sún un láti ràn wọ́n lọ́wọ́.

14 Kíyè sí ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò tí Jésù tún fi hàn nígbà ìṣẹ̀lẹ̀ mìíràn. Nígbà tí obìnrin tó ní ìsun ẹ̀jẹ̀ sún mọ́ ọn láàárín ọ̀pọ̀ èrò tó sì fọwọ́ kan etí aṣọ rẹ̀, a fi iṣẹ́ ìyanu mú obìnrin náà lára dá. Jésù nímọ̀lára pé agbára jáde lára òun, àmọ́ kò rí ẹni náà tá a mú lára dá. Ó sọ pé dandan ní kí òun rí obìnrin náà. Nítorí kí ni? Kì í ṣe tìtorí àtibá a wí pé ó rú Òfin tàbí ìlànà àwọn akọ̀wé àtàwọn Farisí, bí obìnrin ọ̀hún pàápàá ti rò. Dípò bẹ́ẹ̀, ó sọ fún un pé: “Ọmọbìnrin, ìgbàgbọ́ rẹ ti mú ọ lára dá. Máa lọ ní àlàáfíà, kí o sì ní ìlera kúrò lọ́wọ́ àìsàn burúkú tí ń ṣe ọ́.” (Máàkù 5:25-34) Kíyè sí ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò tó wà nínú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn. Kò wulẹ̀ sọ pé: “Kí ara rẹ dá.” Dípò ìyẹn, ó sọ pé: “Kí o . . . ní ìlera kúrò lọ́wọ́ àìsàn burúkú tí ń ṣe ọ́.” Ọ̀rọ̀ tí Máàkù lò níhìn-ín ní ṣáńgílítí jẹ́ èyí tó lè túmọ̀ sí “nínani lọ́rẹ́,” ìyẹn ni fífi ẹgba na èèyàn láti dá a lóró. Nípa bẹ́ẹ̀ Jésù mọ̀ pé àìsàn rẹ̀ tí fìyà jẹ ẹ́ gan-an ni, ó lè jẹ́ kó ní ìrora gógó nínú àgọ́ ara rẹ̀ kó sì tún ní ìmí ẹ̀dùn. Ó káàánú rẹ̀.

15, 16. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wo ló wáyé nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù tó fi hàn pé ànímọ́ rere tó wà lára àwọn èèyàn ni Jésù ń wò?

15 Jésù tún fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn nípa wíwo ànímọ́ rere tí wọ́n ní. Ronú nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tó kọ́kọ́ rí Nàtáníẹ́lì, tó wá di àpọ́sítélì níkẹyìn. “Jésù rí i tí Nàtáníẹ́lì ń bọ̀ lọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì wí nípa rẹ̀ pé: ‘Wò ó, ọmọ Ísírẹ́lì kan dájúdájú, nínú ẹni tí ẹ̀tàn kankan kò sí.’” Lọ́nà ìyanu, Jésù ti wo ọkàn Nàtáníẹ́lì, ó sì ti tipa bẹ́ẹ̀ mọ irú èèyàn tó jẹ́. Ní ti tòótọ́, Nàtáníẹ́lì kì í ṣe ẹni pípé rárá. Ó ní àwọn ìkùdíẹ̀-káàtó tirẹ̀, bíi ti gbogbo wa. Kódà nígbà tó gbọ́ nípa Jésù, ọ̀rọ̀ kòbákùngbé ló sọ, ó ní: “Ohun rere kankan ha lè jáde wá láti Násárétì bí?” (Jòhánù 1:45-51) Àmọ́, nínú gbogbo ohun téèyàn lè sọ nípa Nàtáníẹ́lì, èyí tó dára níbẹ̀ ni Jésù mú, ó pe àfiyèsí sí àìlábòsí ọkùnrin náà.

16 Bákan náà, nígbà tí ọ̀gá ẹgbẹ́ ọmọ ogun kan—tó ṣeé ṣe kó jẹ́ Kèfèrí, ara Róòmù—wá sọ́dọ̀ Jésù, tó ń bẹ̀ ẹ́ pé kó mú ẹrú òun tó ń ṣàìsàn lára dá. Jésù mọ̀ pé sójà náà ní àwọn ìkùdíẹ̀-káàtó tirẹ̀. Ó ṣeé ṣe kí ẹnì kan tó jẹ́ ọ̀gá ẹgbẹ́ ọmọ ogun ayé ìgbà yẹn ti lọ́wọ́ nínú onírúurú ìwà ipá, kó ti tàjẹ̀ sílẹ̀, kó tiẹ̀ ti jọ́sìn ọlọ́run èké pàápàá. Síbẹ̀, ànímọ́ rere tó ní ni Jésù darí àfiyèsí sí—ìyẹn ìgbàgbọ́ àrà ọ̀tọ̀ tí ọkùnrin náà ní. (Mátíù 8:5-13) Lẹ́yìn ìyẹn, nígbà tí Jésù ń bá aṣebi tí wọ́n gbé kọ́gi lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ sọ̀rọ̀, kò bá ọkùnrin náà wí nítorí jíjẹ́ tí ó jẹ́ arúfin tẹ́lẹ̀, àmọ́ ó lo ìrètí ọjọ́ iwájú láti fún un níṣìírí. (Lúùkù 23:43) Jésù mọ̀ pé níní èrò òdì nípa àwọn ẹlòmíràn, ká máa ṣe lámèyítọ́ wọn yóò wulẹ̀ kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wọn ni. Kò sí àní-àní pé bó ṣe ń sapá láti wo ànímọ́ rere tó wà lára àwọn èèyàn yóò ran ọ̀pọ̀ lọ́wọ́ láti túbọ̀ sunwọ̀n sí i.

Ó Múra Tán Láti Sin Àwọn Ẹlòmíràn

17, 18. Nígbà tí Jésù gbà láti wá sórí ilẹ̀ ayé, báwo ló ṣe fi hàn pé òun múra tán láti sin àwọn ẹlòmíràn?

17 Ẹ̀rí lílágbára mìíràn tó fi ìfẹ́ tí Jésù ní fáwọn tó ń kọ́ hàn ni mímúra tó múra tán láti sìn wọ́n. Kí Ọmọ Ọlọ́run tó di ènìyàn pàápàá ló ti nífẹ̀ẹ́ ìran ènìyàn. (Òwe 8:30, 31) Gẹ́gẹ́ bí “Ọ̀rọ̀,” tàbí agbọ̀rọ̀sọ fún Jèhófà, ó ṣeé ṣe kó ti gbádùn ọ̀pọ̀ àjọṣe pẹ̀lú ẹ̀dá ènìyàn. (Jòhánù 1:1) Àmọ́, kí ó bàa lè kọ́ ìran èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ ní tààràtà, “ó sọ ara rẹ̀ di òfìfo, ó sì gbé ìrísí ẹrú wọ̀,” ó fi ipò gíga tó wà ní ọ̀run sílẹ̀. (Fílípì 2:7; 2 Kọ́ríńtì 8:9) Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, kò retí pé káwọn èèyàn máa sin òun. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó sọ pé: “Ọmọ ènìyàn ti wá, kì í ṣe kí a lè ṣe ìránṣẹ́ fún un, bí kò ṣe kí ó lè ṣe ìránṣẹ́, kí ó sì fi ọkàn rẹ̀ fúnni gẹ́gẹ́ bí ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.” (Mátíù 20:28) Ohun tí Jésù wí yìí gan-an ló ṣe.

18 Jésù fi tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ bójú tó àìní àwọn tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́, kì í lọ́ tìkọ̀ láti lo ara rẹ̀ fún wọn. Ó fi ẹsẹ̀ rìn káàkiri Ilẹ̀ Ìlérí, tó ń rin ọgọ́rọ̀ọ̀rún kìlómítà nínú iṣẹ́ ìwàásù bó ṣe ń sapá láti bá gbogbo èèyàn tó bá lè rí sọ̀rọ̀. Kò hùwà bí àwọn Farisí àtàwọn akọ̀wé onígbèéraga wọ̀nyẹn o, ó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ó si ṣeé sún mọ́. Gbogbo onírúurú èèyàn pátá—ìyẹn àwọn onípò-ọlá, àwọn sójà, àwọn amòfin, àwọn obìnrin, àwọn ọmọdé, àti tálákà, àti aláìsàn, kódà àwọn tí wọ́n ti ta nù láwùjọ—ló ń wá sọ́dọ̀ rẹ̀ láìbẹ̀rù. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni pípé ni Jésù, síbẹ̀ èèyàn ni, àárẹ̀ mú un, ebi sì pa á. Àmọ́ nígbà tó rẹ̀ ẹ́ tàbí tó fẹ́ sinmi tàbí tó ń wá ibi dídákẹ́ rọ́rọ́ láti gbàdúrà pàápàá, ó bójú tó àìní àwọn ẹlòmíràn ṣáájú ti ara rẹ̀.—Máàkù 1:35-39.

19. Báwo ni Jésù ṣe fi àwòṣe bíbá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lò tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀, pẹ̀lú sùúrù, àti lọ́nà pẹ̀lẹ́tù lélẹ̀?

19 Jésù tún múra tán láti sin àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pẹ̀lú. Ó ṣe bẹ́ẹ̀ nípa kíkọ́ wọ́n lọ́nà pẹ̀lẹ́tù, ó sì mú sùúrù fún wọn. Nígbà tí wọn ò tètè lóye àwọn kókó pàtàkì kan, kò jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wọn sú òun, kò fàbínú yọ, tàbí kó jágbe mọ́ wọn. Ńṣe ló ń wá àwọn ọ̀nà mìíràn tó máa gbà ràn wọ́n lọ́wọ́ láti lóye kókó náà. Bí àpẹẹrẹ, ronú lórí iye ìgbà táwọn ọmọ ẹ̀yìn jiyàn lórí ẹni tó tóbi jù lọ láàárín wọn. Léraléra, títí di alẹ́ tí Jésù lò kẹ́yìn kí wọ́n tó pa á ló ṣì ń wá ọ̀nà tuntun tó máa gbà kọ́ wọn pé kí wọ́n máa fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ bá ara wọn lò. Lórí ọ̀rọ̀ ìrẹ̀lẹ̀ yìí àti nínú gbogbo àwọn nǹkan mìíràn, Jésù lè fi ẹ̀tọ́ sọ pé: “Mo fi àwòṣe lélẹ̀ fún yín.”— Jòhánù 13:5-15; Mátíù 20:25; Máàkù 9:34-37.

20. Ọ̀nà ìgbàkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ wo ló mú kí Jésù yàtọ̀ sáwọn Farisí, kí sì nìdí tí ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ náà fi gbéṣẹ́?

20 Ṣàkíyèsí pé Jésù kò wulẹ̀ sọ ohun tí àwòṣe náà jẹ́ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀; ńṣe ló “fi àwòṣe náà lélẹ̀.” Ó kọ́ wọn nípa fífi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún wọn. Kò bá wọn sọ̀rọ̀ bí ẹni pé wọn ò já mọ́ nǹkan kan, kó máa ṣe bí ẹni pé òun ga ju ẹni tó lè ṣe ohun tó sọ pé kí wọ́n ṣe. Báwọn Farisí ṣe máa ń ṣe nìyẹn. Jésù sọ nípa wọn pé: “Wọn a máa wí, ṣùgbọ́n wọn kì í ṣe.” (Mátíù 23:3) Jésù fi tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ jẹ́ kí àwọn tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ rí ohun tí àwọn ẹ̀kọ́ tó fi ń kọ́ wọn túmọ̀ sí gan-an nípa bí òun alára ṣe ń fi wọ́n sílò. Nítorí náà, nígbà tó sọ pé káwọn ọmọlẹ́yìn òun gbé ìgbésí ayé oníwọ̀ntúnwọ̀nsì kí wọ́n máà jẹ́ kí ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́nì gbà wọ́n lọ́kàn, kò dìgbà tí wọ́n bá ṣẹ̀ṣẹ̀ ń méfò kí wọ́n tó mọ ohun tó ní lọ́kàn. Wọ́n á ti rí i pé òótọ́ lọ̀rọ̀ tó sọ pé: “Àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ní ihò, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ní ibi wíwọ̀sí, ṣùgbọ́n Ọmọ ènìyàn kò ní ibi kankan láti gbé orí rẹ̀ lé.” (Mátíù 8:20) Jésù sin àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nípa fífi àwòṣe lélẹ̀ fún wọn tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀.

21. Kí la óò gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí?

21 Láìsí àní-àní, Jésù ni Olùkọ́ títóbi lọ́lá jù lọ tó tíì gbé ayé rí! Ìfẹ́ tó ní sí ohun tó fi ń kọ́ni àti bó ṣe nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn tó ń kọ́ hàn kedere sí gbogbo àwọn ọlọ́kàntútù tó rí i tí wọ́n sì gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe kedere sí àwa tá a wà láyé lóde òní, tá à ń kẹ́kọ̀ọ́ àwòṣe tó fi lélẹ̀. Àmọ́ sá o, báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ pípé tí Kristi fi lélẹ̀? Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí yóò dáhùn ìbéèrè yẹn.

Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?

• Kí ni ìpìlẹ̀ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tó gbéṣẹ́, ta ló sì fi àpẹẹrẹ rẹ̀ lélẹ̀?

• Àwọn ọ̀nà wo ni Jésù gbà fìfẹ́ hàn sí òtítọ́ tó fi ń kọ́ni?

• Báwo ni Jésù ṣe fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́?

• Àwọn àpẹẹrẹ wo ló fi bí Jésù ṣe fi tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ múra tán láti sin àwọn tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ hàn?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ àwọn ìlànà tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?