Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Ǹjẹ́ Ẹ Mọ Ìdí Tí Mo Fi Dá Owó Yín Padà?”

“Ǹjẹ́ Ẹ Mọ Ìdí Tí Mo Fi Dá Owó Yín Padà?”

“Ǹjẹ́ Ẹ Mọ Ìdí Tí Mo Fi Dá Owó Yín Padà?”

NANA ìyá anìkàntọ́mọ tóun àtàwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́ta ń gbé lágbègbè Kaspi, ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti Georgia kọ̀wé pé: “Káì, ọ̀dá owó ló dá mi tó báyìí.” Àmọ́ láàárọ̀ ọjọ́ kan, òjò owó rọ̀. Ó rí ọ̀ọ́dúnrún owó lari [tí o ju ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlógún owó náírà lọ] nílẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ àgọ́ ọlọ́pàá. Kò sẹ́nì kankan nítòsí. Owó ńlá ni owó tó rí yìí o. Kódà, Nana ò tíì rí ọgọ́rùn-ún owó lari sójú rí láti odindi ọdún márùn-ún tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí í ná owó lari lórílẹ̀-èdè náà. Báwọn oníṣòwò ibẹ̀ bá fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ṣiṣẹ́, wọn ò tíì lè rí owó tó pọ̀ tó yẹn.

Nana wá ronú pé: ‘Àǹfààní wo ni owó yìí á ṣe fún mi bí mo bá tìtorí rẹ̀ sọ ìgbàgbọ́ mi nù, tí mo sọ ìbẹ̀rù Ọlọ́run nù, tí mo sì pàdánù ipò tẹ̀mí mi?’ Ó ti mú àwọn ànímọ́ Kristẹni wọ̀nyí dàgbà, kódà ó ti fara da inúnibíni rírorò, ó sì ti jìyà nítorí ìgbàgbọ́ rẹ̀.

Nígbà tí Nana dé àgọ́ ọlọ́pàá, ó ráwọn ọlọ́pàá márùn-ún tí wọ́n ń wá gbogbo àyíká. Èyí ló jẹ́ kó mọ̀ pé owó yẹn ni wọ́n ń wá. Ó sún mọ́ wọn, ó sì sọ pé: “Kí lẹ̀ ń wá?”

Wọ́n dá a lóhùn pé “Owó ni.”

“Èló?”

“Ọ̀ọ́dúnrún lari!”

Nana sọ fún wọn pé, “Mo ti báa yín rí owó náà.” Ó wá béèrè pé: “Ǹjẹ́ ẹ mọ ìdí tí mo fi dá owó yín padà?” Wọn ò mọ̀ ọ́n.

Nana sọ pé: “Ìdí ni pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mí. Ká ní kì í ṣe bẹ́ẹ̀ ni, mi ò bá tí dá owó yín padà.”

Ọ̀gá ọlọ́pàá tó ni owó tó sọ nù náà fún Nana ní ogún lari láti fi dúpẹ́ fún ìwà ìṣòtítọ́ tó hù.

Kò pẹ́ tí ìròyìn ohun tó ṣẹlẹ̀ fi kárí gbogbo àgbègbè Kaspi. Lọ́jọ́ tó tẹ̀ lé e, ọmọbìnrin kan tó ń bójú tó ìmọ́tótó àgọ́ ọlọ́pàá náà sọ fún Nana pé: “Gbogbo ìgbà ni [ọ̀gá ọlọ́pàá] máa ń fi àwọn ìwé ìròyìn yín sínú ọ́fíìsì rẹ̀. Ó ṣeé ṣe kó wá túbọ̀ mọyì àwọn ìwé ìròyìn náà ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.” Kódà, ọlọ́pàá kan sọ pé: “Tí gbogbo èèyàn bá di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ta ló máa hùwà ọ̀daràn?”