Ǹjẹ́ O Rántí?
Ǹjẹ́ O Rántí?
Ǹjẹ́ o gbádùn kíka àwọn Ilé Ìṣọ́ tó jáde lẹ́nu àìpẹ́ yìí? Tóò, wò ó bí o bá lè dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e wọ̀nyí:
• Kí ni ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò, kí nìdí tó sì fi yẹ káwọn Kristẹni ní in?
Ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò jẹ́ fífi ara ẹni sí ipò táwọn ẹlòmíràn wà, bíi kí ohun tó ń ṣe ẹlòmíràn máa dùn wá nínú ọkàn wa. A gba àwọn Kristẹni níyànjú pé kí wọ́n ‘máa fi ìmọ̀lára fún ọmọnìkejì hàn, kí wọ́n máa ní ìfẹ́ni ará, kí wọ́n sì máa fi ìyọ́nú hàn.’ (1 Pétérù 3:8) Jèhófà fi àpẹẹrẹ ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò lélẹ̀ fún wa láti tẹ̀ lé. (Sáàmù 103:14; Sekaráyà 2:8) A lè túbọ̀ kọbi ara sí ìṣòro àti ìmọ̀lára àwọn ẹlòmíràn nípa fífetísílẹ̀, nípa fífojúsílẹ̀ àti nípa fífojú inú wo nǹkan.—4/15, ojú ìwé 24 sí 26.
• Láti lè ní ayọ̀ tòótọ́, èé ṣe tó fi ṣe pàtàkì pé kéèyàn kọ́kọ́ rí ìwòsàn tẹ̀mí kó tó rí ìwòsàn sí àìlera nípa tara?
Ọ̀pọ̀ èèyàn tí ara wọn le koko ni kò láyọ̀, nítorí àwọn òkè ìṣòro tí wọ́n ń bá yí. Èyí yàtọ̀ pátápátá sí tàwọn Kristẹni kan tí wọ́n jẹ́ aláàbọ̀ ara lónìí, nítorí pé tìdùnnú-tìdùnnú ni wọ́n ń jọ́sìn Jèhófà. Àwọn tí ń jàǹfààní látinú ìwòsàn tẹ̀mí á láǹfààní láti rí ìwòsàn sí àìlera wọn nínú ayé tuntun.—5/1, ojú ìwé 6, 7.
• Kí nìdí tí Hébérù 12:16 fi fi Ísọ̀ sí ìsọ̀wọ́ alágbèrè?
Àkọsílẹ̀ Bíbélì fi hàn pé irú ẹ̀mí tí Ísọ̀ ní jẹ́ ti èrè ojú ẹsẹ̀, ó sì mú kó fojú tín-ínrín àwọn ohun mímọ́. Bí ẹnì kan lónìí bá gba irú ẹ̀mí yìí láyè, ó lè ti irú ẹni bẹ́ẹ̀ dédìí ẹ̀ṣẹ̀ tó wúwo bí àgbèrè.—5/1, ojú ìwé 10, 11.
• Ta ni Tertullian, kí la sì mọ̀ ọ́n mọ́?
Òǹkọ̀wé ni, ó sì tún jẹ́ ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀sìn ní ọ̀rúndún kejì àti ìkẹta Sànmánì Tiwa. Àwọn èèyàn mọ̀ ọ́n mọ́ àwọn ìwé tó kọ láti fi gbèjà ẹ̀sìn Kristẹni aláfẹnujẹ́. Ibi tó ti ń ṣe ìgbèjà yìí ló ti gbé àwọn èròǹgbà àti ìmọ̀ ọgbọ́n orí kan jáde, tí àwọn èèyàn wá gbé àwọn ẹ̀kọ́ èké kà, irú bí ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan.—5/15, ojú ìwé 29 sí 31.
• Kí ló dé tí ò fi yẹ ká di ẹ̀bi àìsàn, àìmọ̀wàáhù àti ikú ru àwọn èròjà tó pilẹ̀ àbùdá èèyàn?
Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti sọ pé ẹ̀rí rẹ̀ wà pé èròjà tó ń pilẹ̀ àbùdá èèyàn wà lára ohun tó ń fa àìsàn. Àwọn kan sì gbà gbọ́ pé àwọn ohun tó pilẹ̀ àbùdá wa ló ń fa bá a ṣe ń hùwà. Àmọ́, Bíbélì ṣàlàyé ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìran èèyàn, àti bí ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé ṣe ran èèyàn. Òótọ́ ni pé apilẹ̀ àbùdá lè nípa tí ó ń kó nínú bá a ṣe ń hùwà, àmọ́ àìpé wa àti àyíká wa ni olórí ohun tó ń fà á.—6/1, ojú ìwé 9 sí 11.
• Báwo ni àjákù ìwé tá a fi òrépèté ṣe, tí wọ́n rí nílùú Oxyrhynchus, ilẹ̀ Íjíbítì, ṣe túbọ̀ tànmọ́lẹ̀ sórí bí wọ́n ṣe ń lo orúkọ Ọlọ́run?
Ọ̀rọ̀ inú ìwé Jóòbù 42:11, 12, ti ìtumọ̀ Septuagint níbi tí lẹ́tà mẹ́rin lédè Hébérù ti dúró fún orúkọ Ọlọ́run, wà nínú àjákù ìwé tí wọ́n rí yìí. Èyí jẹ́ àfikún ẹ̀rí pé orúkọ Ọlọ́run lédè Hébérù wà nínú ìtumọ̀ Septuagint, táwọn òǹkọ̀wé Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì sábàá máa ń tọ́ka sí.—6/1, ojú ìwé 30.
• Àwọn eré ìdárayá wo làwọn èèyàn ń wò lónìí tí kò fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ sí àwọn eré ìdárayá oníwà ipá, tó ń gbẹ̀mí àwọn èèyàn, èyí táwọn oníjà àjàkú akátá máa ń ṣe ní Ilẹ̀ Ọba Róòmù?
Ìpàtẹ kan tí wọ́n ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yìí ní Gbọ̀ngàn Ìwòran tó wà nílùú Róòmù, ilẹ̀ Ítálì ránni létí àwọn ohun tó jọ eré ìdárayá oníjà àjàkú akátá yìí. Ó fi àwọn fíìmù kan hàn nípa bíbá akọ màlúù jà, ẹ̀ṣẹ́ kíkàn, àwọn eré tí wọ́n ń fi ọkọ̀ àti alùpùpù sá àti ìjà ìgboro láàárín àwọn tó wá wòran eré ìdárayá. Àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ fi sọ́kàn pé Jèhófà kórìíra ìwà ipá àtàwọn tó ń hu irú ìwà bẹ́ẹ̀. Àwọn Kristẹni òde òní náà kò gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ sí ìwà ipá. (Sáàmù 11:5)—6/15, ojú ìwé 29.
• Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ Ẹ́sírà, bá a ṣe ń sapá láti di olùkọ́ tó gbéṣẹ́?
Ẹ́sírà 7:10 sọ àwọn ohun mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí Ẹ́sírà ṣe. Àwa náà lè sapá láti ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí. Ó sọ pé: “Ẹ́sírà fúnra rẹ̀ ti [1] múra ọkàn-àyà rẹ̀ sílẹ̀ [2] láti ṣe ìwádìí nínú òfin Jèhófà àti [3] láti pa á mọ́ àti [4] láti máa kọ́ni ní ìlànà àti ìdájọ́ òdodo ní Ísírẹ́lì.”—7/1, ojú ìwé 20.
• Nínú àwọn ìgbòkègbodò méjì wo ló ti yẹ kí obìnrin tó jẹ́ Kristẹni máa bo orí?
Ọ̀kan jẹ́ nínú àwọn ipò kan tó máa ń dìde nínú ìdílé. Bíbò tí obìnrin náà bo orí rẹ̀ fi hàn pé ó gbà pé ojúṣe ọkọ òun ni láti ṣáájú ìdílé nínú àdúrà àti láti kọ́ àwọn ní ẹ̀kọ́ Bíbélì. Òmíràn sì jẹ́ nínú àwọn ìgbòkègbodò inú ìjọ, èyí tó fi hàn pé obìnrin náà gbà pé àwọn ọkùnrin tó ti ṣèrìbọmi ni Ìwé Mímọ́ fún láṣẹ láti kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ àti láti tọ́ni sọ́nà. (1 Kọ́ríńtì 11:3-10)—7/15, ojú ìwé 26, 27.
• Báwo làwọn Kristẹni ṣe mọ̀ pé ohun tó ń bẹ nídìí yoga ju eré ìdárayá lásán lọ, pé ó sì léwu?
Olórí ète yoga jẹ́ láti mú kéèyàn wà níṣọ̀kan pẹ̀lú agbára tó ju ti ẹ̀dá lọ tàbí pẹ̀lú ẹni ẹ̀mí kan. Èyí ta ko ìlànà Ọlọ́run, nítorí pé yoga ní nínú kéèyàn mọ̀ọ́mọ̀ dá ìgbòkègbodò tó ń lọ lọ́wọ́ nínú èrò inú rẹ̀ dúró. (Róòmù 12:1, 2) Yoga lè kó èèyàn sínú ewu ìbẹ́mìílò àti ti ẹgbẹ́ òkùnkùn. (Diutarónómì 18:10, 11)—8/1, ojú ìwé 20 sí 22.