Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ta Ló Yẹ Kó O Jẹ́ Adúróṣinṣin Sí?

Ta Ló Yẹ Kó O Jẹ́ Adúróṣinṣin Sí?

Ta Ló Yẹ Kó O Jẹ́ Adúróṣinṣin Sí?

“Orílẹ̀-èdè wa: . . . Ohun tó tọ́ láá máa ṣe nígbà gbogbo; àmọ́ ì báà jẹ́ ohun tó tọ́ tàbí ohun tí kò tọ́ ló ṣe, ẹ̀yìn rẹ̀ la máa wà gbágbáágbá.”—Stephen Decatur, ọmọ ogun ojú omi Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, 1779-1820.

Ọ̀PỌ̀ èèyàn ló ka ìdúróṣinṣin ti orílẹ̀-èdè wọn sí ohun àkọ́múṣe. Ńṣe làwọn mìíràn yí ọ̀rọ̀ Stephen Decatur padà sí, ‘Ẹ̀sìn mi, ohun tó tọ́ láá máa ṣe nígbà gbogbo; àmọ́ ì báà jẹ́ ohun tó tọ́ tàbí ohun tí kò tọ́ ló ṣe, ẹ̀yìn rẹ̀ ni màá wà gbágbáágbá.’

Tá a bá fẹ́ sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, ibi tí wọ́n ti bí wa ló sábà máa ń pinnu orílẹ̀-èdè tàbí ẹ̀sìn tá a máa dúró ṣinṣin tì. Àmọ́ ọ̀ràn ṣíṣe ìpinnu nípa ẹni tá a máa dúró ṣinṣin tì kì í ṣe ọ̀ràn tó yẹ kéèyàn gbé ka àyíká tó ti bára rẹ̀. Àmọ́, ó béèrè ìgboyà kéèyàn tó lè gbé ìbéèrè dìde sí ohun àìgbọ́dọ̀máṣe tí wọ́n fi kọ́ ọ láti kékeré, ó sì máa ń fa ìpèníjà.

Ìdánwò Ìdúróṣinṣin

Obìnrin kan tí wọ́n tọ́ dàgbà ní Zambia sọ pé: “Láti pínníṣín ni mo ti lẹ́mìí ìsìn. Àtikékeré ni wọ́n ti kọ́ mi láti máa gbàdúrà lójoojúmọ́ nínú yàrá tá a ti ń gbàdúrà, kí n máa ṣe àwọn ayẹyẹ ìsìn, kí n sì máa lọ sí tẹ́ńpìlì déédéé. Ẹ̀sìn mi àti bí mo ṣe ń ṣe é wé mọ́ àṣà ìbílẹ̀ mi, ó wé mọ́ àgbègbè tí mo ti wá àti irú ilé tí mo ti jáde.”

Síbẹ̀, nígbà tí obìnrin yìí kù díẹ̀ kó pé ọmọ ogún ọdún, ó bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Kò pẹ́ sígbà náà ló pinnu pé òun á fi ẹ̀sìn tóun ń ṣe tẹ́lẹ̀ sílẹ̀. Ǹjẹ́ a lè pe ohun tó ṣe yìí ní ìwà àìdúróṣinṣin?

Bosnia ni wọ́n ti tọ́ Zlatko dàgbà. Àkókò kan sì wà tó bá wọn ja ogun tó bẹ́ sílẹ̀ lórílẹ̀-èdè rẹ̀. Òun náà bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ní báyìí, kì í báwọn lọ́wọ́ nínú ogun jíjà mọ́. Ṣé ìwà àìdúróṣinṣin lèyí tóun náà hù yìí?

Èrò tó o bá ní nípa ọ̀ràn yìí ló máa pinnu bó o ṣe máa dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí. Obìnrin tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lókè sọ pé: “Níbi tí mò ń gbé, ohun ìtìjú gbáà ni kí ẹnì kan fi ẹ̀sìn tó ń ṣe tẹ́lẹ̀ sílẹ̀. Ìwà àìdúróṣinṣin ni wọ́n kà á sí. Wọ́n tún kà á sí pé ńṣe lèèyàn dalẹ̀ ìdílé rẹ̀ àti ìlú rẹ̀.” Bákan náà làwọn ẹlẹgbẹ́ Zlatko tẹ́lẹ̀ ka ẹni tó bá lóun ò bá wọn lọ́wọ́ sí ogun jíjà mọ́ sí ọ̀dàlẹ̀. Àmọ́, obìnrin náà àti Zlatko sọ pé irú ìdúróṣinṣin kan tó tún ga jù—ìyẹn ìdúróṣinṣin sí Ọlọ́run—ló sún àwọn ṣe ohun táwọn ṣe. Ìbéèrè tó tiẹ̀ ṣe pàtàkì jù lọ ni pé, irú ojú wo ni Ọlọ́run fi ń wo àwọn tó fẹ́ jẹ́ adúróṣinṣin sí i?

Ìdúróṣinṣin Tòótọ́ Jẹ́ Àmì Ìfẹ́

Dáfídì Ọba sọ fún Jèhófà pé: “Ìwọ yóò hùwà lọ́nà ìdúróṣinṣin sí ẹni ìdúróṣinṣin.” (2 Sámúẹ́lì 22:26) Ọ̀rọ̀ Hébérù náà tá a tú sí “ìdúróṣinṣin” níbí túmọ̀ sí inú rere tí ń fi tìfẹ́tìfẹ́ rọ̀ mọ́ ohun kan, tí kò sì ní dẹ̀yìn títí ó fi máa mú ìdí tó fi rọ̀ mọ́ ohun náà ṣẹ. Bí ìyá tó ń tọ́mọ lọ́wọ́ ṣe ń fà mọ́ ọmọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni Jèhófà ṣe máa ń fi tìfẹ́tìfẹ́ fà mọ́ àwọn tó bá dúró ṣinṣin tì í. Jèhófà sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin ní Ísírẹ́lì ìgbàanì pé: “Aya ha lè gbàgbé ọmọ ẹnu ọmú rẹ̀ tí kì yóò fi ṣe ojú àánú sí ọmọ ikùn rẹ̀? Àní àwọn obìnrin wọ̀nyí lè gbàgbé, síbẹ̀, èmi kì yóò gbàgbé.” (Aísáyà 49:15) Ìdánilójú tí Ọlọ́run fún àwọn tó bá múra tán láti fi ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run sípò kìíní nínú ìgbésí ayé wọn ni pé òun á fi tìfẹ́tìfẹ́ bójú tó wọn.

Orí ìfẹ́ la gbé ìdúróṣinṣin sí Jèhófà kà. Èyí ló ń mú kí èèyàn nífẹ̀ẹ́ àwọn ohun tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ kó sì kórìíra àwọn ohun búburú tí Jèhófà kórìíra. (Sáàmù 97:10) Nígbà tó jẹ́ pé ìfẹ́ ló gbawájú nínú àwọn ànímọ́ Jèhófà, ìdúróṣinṣin wa sí Ọlọ́run kò ní jẹ́ ká hùwà àìnífẹ̀ẹ́ sáwọn ẹlòmíràn. (1 Jòhánù 4:8) Nítorí náà, bí ìdúróṣinṣin sí Ọlọ́run bá mú kí ẹnì kan fi ìsìn tó ń ṣe tẹ́lẹ̀ sílẹ̀, èyí kò túmọ̀ sí pé ẹni náà kò nífẹ̀ẹ́ ìdílé rẹ̀ mọ́.

Ìdúróṣinṣin sí Ọlọ́run Ń Ṣeni Láǹfààní

Àlàyé tí obìnrin tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lókè ṣe nípa àwọn ìgbésẹ̀ tó gbé rèé: “Nígbà tí mo kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mo wá rí i pé Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́, mo sì wá ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú rẹ̀. Jèhófà ò dà bí èyíkéyìí lára àwọn ọlọ́run tí mò ń jọ́sìn tẹ́lẹ̀. Ó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì nínú bó ṣe ń lo àwọn ànímọ́ rẹ̀ bí ìfẹ́, ìdájọ́ òdodo, ọgbọ́n àti agbára. Nígbà tó sì jẹ́ pé ìfọkànsìn tí a yà sọ́tọ̀ gedegbe ni Jèhófà ń fẹ́, ó di dandan kí n fi àwọn ọlọ́run mìíràn tí mò ń sìn tẹ́lẹ̀ sílẹ̀.

“Gbogbo ìgbà làwọn òbí mi ń sọ fún mi pé inú àwọn ò dùn sí mi rárá àti pé mo ń já àwọn kulẹ̀. Èyí kó ìbànújẹ́ bá mi, nítorí pé mi ò fẹ́ káwọn òbí mi bínú sí mi páàpáà. Àmọ́ bí ìmọ̀ mi nípa òtítọ́ inú Bíbélì ṣe ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ náà ni ìpinnu tó yẹ kí n ṣe túbọ̀ ń ṣe kedere sí mi. Mi ò lè kọ Jèhófà sílẹ̀.

“Bí mo ṣe pinnu láti dúró ṣinṣin ti Jèhófà, dípò títẹ̀lé àwọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ kò túmọ̀ sí pé mo jẹ́ aláìdúróṣinṣin sí ìdílé mi. Mo sapá láti jẹ́ kí wọ́n mọ̀ nípa ọ̀rọ̀ àti ìṣe mi pé mo mọ bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára wọn. Àmọ́ bí mi ò bá dúró ṣinṣin ti Jèhófà, mo lè tipa bẹ́ẹ̀ bẹ́gi dí ọ̀nà tí ìdílé mi ì bá gbà mọ̀ ọ́n, èyí gan-an sì ni ìwà àìdúróṣinṣin.”

Bákan náà, bí ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run bá mú kí ẹnì kan sọ pé òun ò ní dá sí tọ̀tùn-tòsì nínú ọ̀rọ̀ òṣèlú tàbí tó sọ pé òun ò ní jagun, èyí kò túmọ̀ sí pé irú ẹni bẹ́ẹ̀ jẹ́ ọ̀dàlẹ̀. Ẹ gbọ́ àlàyé Zlatko nípa ìgbésẹ̀ tó gbé, ó ní: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a tọ́ mi dàgbà bí aláfẹnujẹ́ Kristẹni, ìyàwó mi kì í ṣe Kristẹni. Nígbà tí ogun bẹ́ sílẹ̀, ìhà méjèèjì ń sọ pé tàwọn ni kí n ṣe. Ó wá di pé kí n yan apá ibì kan tí màá jà fún. Odidi ọdún mẹ́ta àtààbọ̀ ni mo fi jagun. Ìgbà tó yá, èmi àtìyàwó mi sá lọ sí Croatia, ibẹ̀ la ti pàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

“Inú ẹ̀kọ́ Bíbélì tá à ń kọ́ la ti wá rí i pé Jèhófà lẹ́ni pàtàkì tó yẹ ká dúró ṣinṣin tì àti pé ó fẹ́ ká nífẹ̀ẹ́ àwọn aládùúgbò wa láìka ẹ̀sìn èyíkéyìí tí wọ́n ń ṣe tàbí ìran wọn sí. Ní báyìí, èmi àti ìyàwó mi ń jọ́sìn Jèhófà pa pọ̀ ni, mo sì ti kẹ́kọ̀ọ́ pé mi ò lè sọ pé mo dúró ṣinṣin ti Ọlọ́run kí n tún máa gbógun ti àwọn aládùúgbò mi.”

Ìmọ̀ Pípéye Ń Nípa Lórí Ìdúróṣinṣin

Nígbà tó jẹ́ pé Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá wa, ìdúróṣinṣin wa sí i ló gbọ́dọ̀ gba ipò iwájú nínú àwọn ohun mìíràn tó ń béèrè ìdúróṣinṣin wa. (Ìṣípayá 4:11) Àmọ́ ṣá, a gbọ́dọ̀ ní ìmọ̀ pípéye kí ìdúróṣinṣin wa sí Ọlọ́run má bàa di ti agbawèrèmẹ́sìn, èyí tó lè múni hùwà ọ̀bàyéjẹ́. Bíbélì rọ̀ wá pé: ‘Ẹ di tuntun nínú ipá tí ń mú èrò inú yín ṣiṣẹ́, kí ẹ sì gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀, èyí tí a dá ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run nínú ìdúróṣinṣin tòótọ́.’ (Éfésù 4:23, 24) Ọkùnrin olókìkí tó kọ ọ̀rọ̀ onímìísí wọ̀nyẹn fi tìgboyàtìgboyà ṣàyẹ̀wò irú ìdúróṣinṣin tí wọ́n fi tọ́ ọ dàgbà. Àyẹ̀wò tó ṣe yìí ló jẹ́ kó lè ṣe àwọn àtúnṣe tó mú èrè wá fún un.

Àní a dán ìdúróṣinṣin Sọ́ọ̀lù náà wò gẹ́gẹ́ bá a ṣe dán ti ọ̀pọ̀ wò lákòókò tiwa. Ìdílé Sọ́ọ̀lù ní àwọn àṣà kan tí ò gba gbẹ̀rẹ́ tí wọ́n fi tọ́ ọ dàgbà, kò sì fọ̀rọ̀ ìdúróṣinṣin ti ẹ̀sìn tí wọ́n fi tọ́ ọ dàgbà ṣeré rárá. Kódà ìdúróṣinṣin ti ẹ̀sìn rẹ̀ mú kó hùwà òǹrorò sáwọn tí èrò wọn bá yàtọ̀ sí tiẹ̀. Àwọn èèyàn mọ Sọ́ọ̀lù mọ́ bó ṣe máa ń lọ gbógun ti àwọn Kristẹni nílé wọn, tá á lọ wọ́ wọn jáde, kí wọ́n lè fìyà jẹ wọ́n tàbí kí wọ́n tiẹ̀ pa wọ́n pàápàá.—Ìṣe 22:3-5; Fílípì 3:4-6.

Àmọ́ ṣá, gbàrà tí Sọ́ọ̀lù wá ní ìmọ̀ pípéye nípa Bíbélì, ó ṣe ohun táwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ kà sí nǹkan èèwọ̀. Ó pa ẹ̀sìn rẹ̀ dà. Sọ́ọ̀lù, tó wá di Pọ́ọ̀lù, yàn láti jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run dípò jíjẹ́ adúróṣinṣin sí àṣà àtọwọ́dọ́wọ́. Ìdúróṣinṣin sí Ọlọ́run, èyí tá a gbé karí ìmọ̀ pípéye mú kí Sọ́ọ̀lù wá dẹni tó ń rí ara gba nǹkan, ẹni tó nífẹ̀ẹ́, tó sì ń ṣe dáadáa sáwọn èèyàn. Èyí yàtọ̀ pátápátá sí ìwà ọ̀bàyéjẹ́ àti ìwà agbawèrèmẹ́sìn tó ń hù tẹ́lẹ̀.

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Jẹ́ Adúróṣinṣin?

Gbígbé ìdúróṣinṣin wa ka àwọn ìlànà Jèhófà ń mú èrè wá. Bí àpẹẹrẹ, ìròyìn kan tó jáde lọ́dún 1999 látọ̀dọ̀ Àjọ Tó Ń Rí sí Ọ̀ràn Ìdílé ní Ọsirélíà sọ pé “ìgbẹ́kẹ̀lé àti ìṣòtítọ́ . . . [àti] fífi àwọn ohun tẹ̀mí sọ́kàn” wà lára àwọn ohun tó ṣe kókó tó máa ń mú kí ìgbéyàwó wà pẹ́ títí, kó sì gbádùn mọ́ni. Àjọ yìí sọ pé “ìgbéyàwó tó dúró digbí, tó sì gbádùn mọ́ni” máa ń jẹ́ kí tọkùnrin tobìnrin túbọ̀ láyọ̀, kára wọn dá ṣáṣá, kẹ́mìí wọn sì gùn. Àti pé ìgbéyàwó tó bá dúró sán-ún tún máa ń fún àwọn ọmọ láǹfààní láti gbádùn ìgbésí ayé.

Nínú ayé àìdánilójú tá a wà yìí, ńṣe ni ìdúróṣinṣin dà bí okùn tí òmùwẹ̀ tí omi fẹ́ gbé lọ lè dìrọ̀ mọ́, tó máa gbé e dédìí ọkọ̀ ìgbàlà. Bí “òmùwẹ̀” náà kò bá jẹ́ adúróṣinṣin, ńṣe ni ìgbì òkun àti ẹ̀fúùfù á máa bì í síwá sẹ́yìn. Bó bá sì jẹ́ ohun tí kò tọ́ ló fún ní ìdúróṣinṣin rẹ̀, ńṣe ló máa dà bí ẹni pé ìdí ọkọ̀ ojú omi tó ń rì lọ ni wọ́n so okùn tí ọ̀gbẹ́ni yìí tòrò pinpin mọ́ mọ́. Ó lè dẹni tá a sún dé ọ̀nà ìparun bíi ti Sọ́ọ̀lù. Àmọ́, ìdúróṣinṣin ti Jèhófà, tá a gbé karí ìmọ̀ pípéye, ló dà bí okùn tí kì í jẹ́ kí ìgbì omi máa gbá èèyàn káàkiri, tó sì tún ń sìn wá lọ sí ìgbàlà.—Éfésù 4:13-15.

Jèhófà ṣèlérí fáwọn tó dúró ṣinṣin tì í pé: “Olùfẹ́ ìdájọ́ òdodo ni Jèhófà, òun kì yóò sì fi àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀ sílẹ̀. Fún àkókò tí ó lọ kánrin ni a óò máa ṣọ́ wọn dájúdájú.” (Sáàmù 37:28) Kò ní pẹ́ mọ́ tí Jèhófà á mú gbogbo àwọn tó bá jẹ́ adúróṣinṣin sí i wọnú Párádísè orí ilẹ̀ ayé. Ibẹ̀ ni wọ́n ti máa bọ́ lọ́wọ́ ìbànújẹ́ àti ìrora, wọ́n á sì máa gbádùn àjọṣe tó wà pẹ́ títí láìsí ìpínyà tí ọ̀ràn ẹ̀sìn àti ìṣèlú ń fà.—Ìṣípayá 7:9, 14; 21:3, 4.

Àní bá a ṣe ń sọ̀rọ̀ yìí, ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn èèyàn kárí ayé ti rí i pé ìdúróṣinṣin wọn sí Jèhófà nìkan ló lè fún wọn ní ayọ̀ tòótọ́. O ò ṣe jẹ́ káwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti fi òtítọ́ Bíbélì ṣàyẹ̀wò èrò rẹ nípa ìdúróṣinṣin? Bíbélì sọ fún wa pé: “Ẹ máa dán ara yín wò bóyá ẹ wà nínú ìgbàgbọ́, ẹ máa wádìí ohun tí ẹ̀yin fúnra yín jẹ́.”—2 Kọ́ríńtì 13:5.

Ó gba ìgboyà ká tó lè gbé ìbéèrè dìde sí ohun tá a gbà gbọ́ àti ìdí tá a fi rọ̀ mọ́ ọn. Àmọ́ tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, èrè ibẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ ó jù bẹ́ẹ̀ lọ nítorí pé ó máa mú ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà Ọlọ́run. Obìnrin tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣáájú gbẹnu sọ fún ọ̀pọ̀ èèyàn, nígbà tó sọ pé: “Mo ti wá rí i pé jíjẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà àtàwọn ìlànà rẹ̀ ń ràn wá lọ́wọ́ láti wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì nínú àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn ìdílé wa, ó sì tún ń sọ wá di ẹni rere ládùúgbò. Bó ti wù káwọn àdánwò náà le koko tó, tá a bá jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà, kò sí ni, òun náà á dúró ṣinṣin tì wá.”

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Ìmọ̀ pípéye ló mú kí Sọ́ọ̀lù yí ibi tó fi ìdúróṣinṣin rẹ̀ sí tẹ́lẹ̀ padà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

O ò ṣe fi òtítọ́ Bíbélì ṣàyẹ̀wò ìdúróṣinṣin rẹ?

[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 4]

Ọ̀gbẹ́ni Churchill, ló wà lọ́wọ́ òsì lápá òkè: fọ́tò U.S. National Archives; Joseph Göbbels, ló wà lápá ọ̀tún pátápátá: Library of Congress