“Ènìyàn Mìíràn Kò Tíì Sọ̀rọ̀ Báyìí Rí”
“Ènìyàn Mìíràn Kò Tíì Sọ̀rọ̀ Báyìí Rí”
“Gbogbo wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹ́rìí rẹ̀ ní rere, ẹnu sì ń yà wọ́n nítorí àwọn ọ̀rọ̀ alárinrin tí ń jáde láti ẹnu rẹ̀.”—Lúùkù 4:22.
1, 2. (a) Kí ló dé táwọn onípò àṣẹ tí wọ́n rán lọ mú Jésù wá fi padà lọ́wọ́ òfo? (b) Kí ló jẹ́ ká mọ̀ pé kì í ṣe àwọn onípò àṣẹ náà nìkan ni ọ̀nà tí Jésù ń gbà kọ́ àwọn èèyàn wú lórí?
ÀWỌN onípò àṣẹ náà ò lè ṣe iṣẹ́ tá a rán wọn wá ṣe. Jésù Kristi la ní kí wọ́n lọ mú wá, àmọ́ ọwọ́ òfo ni wọ́n padà. Làwọn olórí àlùfáà àtàwọn Farisí bá ní kí wọ́n wá sọ ohun tí wọ́n rí lọ́bẹ̀ tí wọ́n fi warú sọ́wọ́. Wọ́n béèrè pé: “Èé ṣe tí ẹ kò fi mú un wá?” Àní sẹ́, kí ni ò jẹ́ káwọn aráabí yìí lè mú ọkùnrin tí ò bá wọn ṣagídí yìí? Àwọn onípò àṣẹ náà dáhùn pé: “Ènìyàn mìíràn kò tíì sọ̀rọ̀ báyìí rí.” Ọ̀nà tí Jésù ń gbà kọ́ àwọn èèyàn wú wọn lórí gan-an, ìdí rèé tí wọn ò fi mú ọkùnrin yìí tó jẹ́ èèyàn àlàáfíà. a—Jòhánù 7:32, 45, 46.
2 Kì í ṣe àwọn onípò àṣẹ yìí nìkan ni ọ̀nà tí Jésù ń gbà kọ́ àwọn èèyàn wú lórí o. Bíbélì sọ fún wa pé ńṣe làwọn èèyàn ń tú yááyáá láti wá gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀. Kódà ẹnu ya àwọn ará ìlú rẹ̀ “nítorí àwọn ọ̀rọ̀ alárinrin tí ń jáde láti ẹnu rẹ̀.” (Lúùkù 4:22) Ó ju ìgbà kan lọ tó tinú ọkọ̀ ojú omi bá ogunlọ́gọ̀ èèyàn tó kóra jọ sí etí Òkun Gálílì sọ̀rọ̀. (Máàkù 3:9; 4:1; Lúùkù 5:1-3) Ìgbà kan tiẹ̀ wà tí “ogunlọ́gọ̀ ńlá” wà lọ́dọ̀ọ́ rẹ̀ fún ọjọ́ mélòó kan láìjẹun.—Máàkù 8:1, 2.
3. Kí ni olórí ohun tó mú kí Jésù jẹ́ olùkọ́ tó ta yọ?
3 Èé ṣe tí Jésù fi jẹ́ olùkọ́ tó ta yọ? Ìfẹ́ ni olórí ohun tó fà á. b Jésù fẹ́ràn òtítọ́ tó fi ń kọ́ni, ó sì tún nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́. Àmọ́ Jésù tún mọ bá a ṣe ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ lóríṣiríṣi ọ̀nà tó mọ́yán lórí. Nínú àwọn àpilẹ̀kọ tó wà nínú ìtẹ̀jáde yìí, a óò jíròrò díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tó mọ́yán lórí tó lò àti bí àwa náà ṣe lè ṣe bíi tiẹ̀.
Ọ̀rọ̀ Tó Tètè Ń Yéni, Tó sì Ṣe Kedere
4, 5. (a) Èé ṣe tí Jésù fi lo àwọn èdè tó tètè ń yéni nígbà tó ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́, kí nìdí tíyẹn sì fi gba àfiyèsí? (b) Báwo ni Ìwàásù lórí Òkè ṣe jẹ́ àpẹẹrẹ kíkọ́ tí Jésù kọ́ni lọ́nà tó tètè ń yéni?
4 Ó jẹ́ àṣà àwọn ọ̀mọ̀wé láti máa pe èdè tó máa jẹ́ kí àwọn tó ń gbọ́ wọn dà bí aláìmọ̀kan. Àmọ́ báwo ni ìmọ̀ tá a ní ṣe lè ṣe àwọn èèyàn láǹfààní bí ohun tá à ń sọ kò bá yé wọn? Jésù kì í ṣe olùkọ́ tó máa ń sọ̀rọ̀ lọ́nà tó máa jẹ́ kí àwọn olùgbọ́ rẹ̀ dà bí òpè. Sì fojú inú wo omilẹgbẹ àkànlò èdè tí ń bẹ lẹ́nu Jésù. Síbẹ̀, pẹ̀lú bí ìmọ̀ rẹ̀ ṣe pọ̀ tó, kì í ṣe tara rẹ̀ ló ń rò bí kò ṣe tàwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ó mọ̀ pé àwọn “tí kò mọ̀wé àti gbáàtúù” ni ọ̀pọ̀ lára wọn. (Ìṣe 4:13) Ó lo èdè táwọn èèyàn á lóye kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ lè yé wọn. Òótọ́ ni pé àwọn ọ̀rọ̀ tó lò lè jẹ́ èyí tó ṣe tààràtà, àmọ́ òtítọ́ tó wà nínú rẹ̀ kò lẹ́gbẹ́.
5 Bí àpẹẹrẹ, wo Ìwàásù lórí Òkè tá a kọ sínú Mátíù 5:3 sí 7:27. Ó ṣeé ṣe kí ìwàásù yìí má gba Jésù ju ogún ìṣẹ́jú lọ. Àmọ́ àwọn ẹ̀kọ́ inú rẹ̀ jinlẹ̀ gan-an, ó sì tú iṣu dé ìsàlẹ̀ ìkòkò lórí àwọn ọ̀ràn bíi panṣágà, ìkọ̀sílẹ̀ àti ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́nì. (Mátíù 5:27-32; 6:19-34) Jésù kò da gírámà bolẹ̀, kó bẹ̀rẹ̀ sí sọ àwọn ọ̀rọ̀ kàǹkà-kàǹkà tí ò ní yé àwọn èèyàn. Kódà, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí ọ̀rọ̀ kan ṣoṣo tí ọmọ kékeré gan-an ò ní lóye nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀! Abájọ tí ‘háà fi ṣe’ ogunlọ́gọ̀ náà tó ṣeé ṣe kó ní nínú àwọn àgbẹ̀, àwọn olùṣọ́ àgùntàn àtàwọn apẹja, ‘sí ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀’ nígbà tó kọ́ wọn tán!—Mátíù 7:28.
6. Mú àpẹẹrẹ kan wá nípa bí Jésù ṣe sọ àwọn ọ̀rọ̀ tí kò lọ́jú pọ̀ àmọ́ tí nǹkan ki sínú rẹ̀.
6 Ọ̀rọ̀ tí kò lọ́jú pọ̀ tó sì ṣe ṣókí ni Jésù sábà máa ń lò, àmọ́ nǹkan ki sínú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí. Abájọ tí ọ̀rọ̀ Jésù fi wọ àwọn èèyàn lọ́kàn ṣinṣin, tí wọn kì í sì í gbàgbé. Àpẹẹrẹ bíi mélòó kan rèé: “Kò sí ẹnì kan tí ó lè sìnrú fún ọ̀gá méjì; . . . ẹ kò lè sìnrú fún Ọlọ́run àti fún Ọrọ̀.” “Ẹ dẹ́kun dídánilẹ́jọ́ kí a má bàa dá yín lẹ́jọ́.” “Nípa àwọn èso wọn ni ẹ ó fi dá àwọn ènìyàn wọnnì mọ̀.” “Àwọn ẹni tí ó ní ìlera kò nílò oníṣègùn, ṣùgbọ́n àwọn tí ń ṣòjòjò nílò rẹ̀.” “Gbogbo àwọn tí wọ́n bá ń mú idà yóò ṣègbé nípasẹ̀ idà.” “Ẹ san àwọn ohun ti Késárì padà fún Késárì, ṣùgbọ́n àwọn ohun ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.” “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.” c (Mátíù 6:24; 7:1, 20; 9:12; 26:52; Máàkù 12:17; Ìṣe 20:35) Àwọn èèyàn ṣì ń rántí àwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ títí di òní olónìí, tó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún ọdún méjì tó ti sọ ọ́.
Lílo Ìbéèrè
7. Èé ṣe tí Jésù fi máa ń béèrè ìbéèrè?
7 Ọ̀nà tí Jésù gbà lo ìbéèrè kàmàmà. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló máa béèrè ìbéèrè, kódà bó tiẹ̀ jọ pé ohun tí ì bá pé e jù ni pé kó kàn la kókó ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀, kó sì máa bá tiẹ̀ lọ. Kí ló wá dé tó fi ń béèrè ìbéèrè? Nígbà mìíràn, ó máa ń béèrè àwọn ìbéèrè gbankọgbì láti tú ète àwọn alátakò rẹ̀ fó, káwọn yẹn lè lọ mọ̀wọ̀n ara wọn. (Mátíù 12:24-30; 21:23-27; 22:41-46) Ṣùgbọ́n, ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jésù máa ń béèrè ìbéèrè láti mú kí òtítọ́ wọnú ọkàn àwọn èèyàn, láti mú káwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn jáde àti láti mú káwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ mọ bó ṣe yẹ kéèyàn máa ronú. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ méjì, tó dá lórí àpọ́sítélì Pétérù.
8, 9. Báwo ni Jésù ṣe fi ìbéèrè ran Pétérù lọ́wọ́ láti ní òye tó tọ́ nípa ọ̀ràn sísan owó orí tẹ́ńpìlì?
8 Àkọ́kọ́, rántí ìgbà táwọn tó ń gbowó orí béèrè lọ́wọ́ Pétérù bóyá Jésù ti san owó orí tẹ́ńpìlì. d Pétérù tó jẹ́ pé ìwàǹwára ló fi máa ń ṣe nǹkan nígbà míì, ti yára dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni.” Àmọ́ nígbà tó ṣe díẹ̀, Jésù bá a fèrò wérò, ó ní: “‘Kí ni ìwọ rò, Símónì? Lọ́wọ́ ta ni àwọn ọba ilẹ̀ ayé ti ń gba owó ibodè tàbí owó orí? Ṣé lọ́wọ́ àwọn ọmọ wọn ni tàbí lọ́wọ́ àwọn àjèjì?’ Nígbà tí ó sọ pé: ‘Lọ́wọ́ àwọn àjèjì,’ Jésù wí fún un pé: ‘Ní ti gidi, nígbà náà, àwọn ọmọ bọ́ lọ́wọ́ owó orí.’” (Mátíù 17:24-27) Ó yẹ kí kókó tí Jésù fẹ́ fà yọ nínú àwọn ìbéèrè yìí ti yé Pétérù yékéyéké. Kí nìdí tó fi yẹ kí ó yé e?
9 Nígbà tí Jésù wà láyé, àwọn èèyàn mọ̀ pé ẹni tó bá wá láti ìdílé ọba kì í sanwó orí. Fún ìdí yìí, kò yẹ kí ẹnì kan máa wá béèrè owó orí lọ́wọ́ Jésù, tí í ṣe Ọmọ bíbí kan ṣoṣo ti Ọba ọ̀run, tí àwọn èèyàn ń jọ́sìn nínú tẹ́ńpìlì náà. Kíyè sí i pé dípò tí Jésù ì bá kàn sọ òkodoro ọ̀rọ̀ fún Pétérù ní tààràtà, ńṣe ló fẹ̀sọ̀ bi í láwọn ìbéèrè tó gbéṣẹ́ tó mú kó lóye ọ̀rọ̀ náà bó ṣe yẹ. Ó tiẹ̀ ṣeé ṣe káwọn ìbéèrè náà tún ran Pétérù lọ́wọ́ láti rí i pé ó yẹ kéèyàn máa ronú dáadáa kó tó sọ̀rọ̀.
10, 11. Kí ni Jésù ṣe nígbà tí Pétérù gé etí ọ̀gbẹ́ni kan bọ́ọ́lẹ̀ lálẹ́ ọjọ́ Ìrékọjá ọdún 33 Sànmánì Tiwa, báwo lèyí sì ṣe fi hàn pé Jésù mọ̀ pé bíbéèrè ìbéèrè ṣe pàtàkì?
10 Àpẹẹrẹ kejì dá lórí ohun tó ṣẹlẹ̀ lálẹ́ ọjọ́ Ìrékọjá ọdún 33 Sànmánì Tiwa, nígbà táwọn jàǹdùkú wá mú Jésù. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn béèrè lọ́wọ́ Jésù pé ṣe káwọn gbèjà rẹ̀. (Lúùkù 22:49) Pétérù ò tiẹ̀ dúró kí Jésù dáhùn tó ti fi idà ré etí ọ̀gbẹ́ni kan bọ́ọ́lẹ̀ (ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọṣẹ́ tó jùyẹn lọ ni Pétérù ti ní lọ́kàn láti ṣe ọ̀gbẹ́ni yìí). Jésù kò fẹ́ ohun tí Pétérù ṣe yìí rárá nítorí pé ó ti múra tán láti tẹ̀ lé àwọn tó wá mú un. Kí ni Jésù wá ṣe? Gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀, ńṣe ló na sùúrù sí i. Ó béèrè ìbéèrè mẹ́ta lọ́wọ́ Pétérù, ó ní: “Ife tí Baba ti fi fún mi, èmi kò ha ní láti mu ún lọ́nàkọnà bí?” “Ìwọ ha rò pé èmi kò lè ké gbàjarè sí Baba mi láti pèsè àwọn áńgẹ́lì tí ó ju líjíónì méjìlá fún mi ní ìṣẹ́jú yìí? Bí ọ̀ràn bá rí bẹ́ẹ̀, báwo ni a ó ṣe mú Ìwé Mímọ́ ṣẹ pé ó gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ lọ́nà yìí?”—Jòhánù 18:11; Mátíù 26:52-54.
11 Ronú díẹ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí. Àwọn jàǹdùkú tínú ń bí burúkú burúkú ló yí Jésù ká yìí, ó mọ̀ pé ikú òun ló dé tán yìí, ó sì mọ̀ pé dídá orúkọ Bàbá òun láre àti ìgbàlà gbogbo ẹ̀dá èèyàn dọwọ́ òun. Pẹ̀lú gbogbo èyí, ó ṣì wá àyè lójú ẹsẹ̀ yẹn láti fi ìbéèrè tẹ àwọn òtítọ́ pàtàkì náà mọ́ Pétérù lọ́kàn. Ǹjẹ́ kò hàn gbangba pé Jésù mọ̀ pé bíbéèrè ìbéèrè ṣe pàtàkì?
Àbùmọ́ Tó Fa Kíki
12, 13. (a) Kí ni àbùmọ́? (b) Báwo ni Jésù ṣe fi àbùmọ́ tẹ̀ ẹ́ mọ́ni lọ́kàn pé ìwà òpònú ni láti máa ṣàríwísí nípa àwọn àṣìṣe kéékèèké àwọn arákùnrin wa?
12 Jésù tún lo ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ mìíràn tó gbéṣẹ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ìyẹn ni àkànlò èdè tí à ń pè ní àbùmọ́. Àbùmọ́ ni pé kéèyàn mọ̀ọ́mọ̀ sọ àsọrégèé láti fi gbé kókó inú ọ̀rọ̀ jáde dáadáa. Àbùmọ́ yìí ni Jésù fi gbé àwọn ọ̀rọ̀ kan kalẹ̀, tí àwọn èèyàn ò fi gbàgbé wọn. Ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀ wò.
13 Nígbà tí Jésù ń sọ ìdí tó fi yẹ kéèyàn ‘dẹ́kun dídá àwọn ẹlòmíràn lẹ́jọ́’ nínú Ìwàásù lórí Òkè, ó sọ pé: “Èé ṣe tí ìwọ fi wá ń wo èérún pòròpórò tí ó wà nínú ojú arákùnrin rẹ, ṣùgbọ́n tí o kò ronú nípa igi ìrólé tí ó wà nínú ojú ìwọ fúnra rẹ?” (Mátíù 7:1-3) Ǹjẹ́ o lè fojú inú yàwòrán ohun tó sọ yìí? Ẹnì kan tó fẹ́ràn láti máa ṣàríwísí sọ pé òun fẹ́ bá arákùnrin òun yọ èérún pòròpórò tó wà ní “ojú” rẹ̀. Alárìíwísí yìí sọ pé arákùnrin òun kò lè rí ọ̀ràn tó wà nílẹ̀ dáadáa, nítorí náà kò ní lè ṣèdájọ́ lọ́nà tó tọ́. Àmọ́ odindi “igi ìrólé,” ìyẹn ọ̀pá àjà tó wà lójú alárìíwísí yìí fúnra rẹ̀ kò jẹ́ kó lè ṣèdájọ́ bó ṣe tọ́. Ẹ ò rí i pé ọ̀nà mánigbàgbé ni Jésù gbà tẹ̀ ẹ́ mọ́ni lọ́kàn pé ìwà òpònú gbáà ni láti máa ṣàríwísí nípa àṣìṣe kéékèèké àwọn arákùnrin wa, nígbà táwa náà ní àwọn àléébù ńláńlá, ká wá sọ ara wa di arítẹni-mọ̀-ọ́n-wí tó ń fi àpáàdì jàn-ànràn bo tiẹ̀ mọ́lẹ̀!
14. Kí nìdí tí ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nípa àwọn tó ń sẹ́ kòkòrò kantíkantí àmọ́ tí wọ́n ń gbé ràkúnmí mì ṣe jẹ́ àbùmọ́ tó fakíki?
14 Ní àkókò mìíràn, Jésù pe àwọn Farisí ní “afọ́jú afinimọ̀nà, tí ń sẹ́ kòkòrò kantíkantí ṣùgbọ́n tí ń gbé ràkúnmí mì kàló!” (Mátíù 23:24) Àbùmọ́ tó fakíki lèyí. Báwo ló ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀? Ìyàtọ̀ ńláǹlà ló wà láàárín kòkòrò kantíkantí tí ò ju kékeré lọ àti ràkúnmí tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹranko tó tóbi jù lọ táwọn tí Jésù ń bá sọ̀rọ̀ mọ̀. Wọn tiẹ̀ fojú bù ú pé ìwọ̀n ràkúnmí kan ṣoṣo á tó ká pa nǹkan bí àádọ́rin mílíọ̀nù kòkòrò kantíkantí pọ̀! Bákan náà, Jésù mọ̀ pé asẹ́ aláṣọ làwọn Farisí fi ń sẹ́ wáìnì wọn. Ohun tó mú káwọn arinkinkin-mọ́lànà yìí ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé wọn ò fẹ́ gbé kòkòrò kantíkantí mì kí wọ́n má bàa di aláìmọ́. Ṣùgbọ́n, wọ́n ń gbé ràkúnmí, tóun náà jẹ́ ẹranko aláìmọ́, mì kàló lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ. (Léfítíkù 11:4, 21-24) Kedere lohun tí Jésù ń sọ yéni. Tìṣọ́ratìṣọ́ra làwọn Farisí fi ń pa èyí tó kéré jù lọ nínú Òfin mọ́, àmọ́ kò sóhun tó kàn wọ́n kan àwọn ọ̀ràn tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú Òfin, ìyẹn “ìdájọ́ òdodo àti àánú àti ìṣòtítọ́.” (Mátíù 23:23) Ẹ ò rí bí Jésù ṣe táṣìírí irú èèyàn tí wọ́n jẹ́ gan-an!
15. Sọ díẹ̀ lára àwọn ẹ̀kọ́ tí Jésù kọ́ni nípa lílo àbùmọ́.
15 Jésù lo àbùmọ́ ní gbogbo àkókò tó fi ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. Gbé àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀ wò. “Ìgbàgbọ́ ìwọ̀n hóró músítádì” bíńtín lè ṣí òkè nídìí—bóyá ni àpèjúwe mìíràn tún wà tó dáa jùyẹn lọ, tí Jésù fi lè fi hàn pé ìgbàgbọ́ kékeré lè dá bírà. (Mátíù 17:20) Ràkúnmí ńlá tó fẹ́ gba ihò ìdí abẹ́rẹ́ ìránṣọ kọjá—èyí ṣàpèjúwe bó ṣe máa ṣòro fún ọlọ́rọ̀ tó ní òun fẹ́ sin Ọlọ́run àmọ́ tó jẹ́ pé ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́nì ló gbà á lọ́kàn! (Mátíù 19:24) Ǹjẹ́ àwọn ẹwà èdè tó gbámúṣé tí Jésù lò yìí àti bó ṣe máa ń sọ ọ̀rọ̀ ṣókí tó ní ìtumọ̀ jíjinlẹ̀ kò wú ọ lórí?
Ọgbọ́n Ìrònú Tí Kò Ṣeé Já Ní Koro
16. Báwo ni Jésù ṣe sábà máa ń lo ọgbọ́n orí jíjí pépé tó ní?
16 Ọlọ́pọlọ pípé ni Jésù, ọ̀gá sì ni nínú bíbá àwọn èèyàn fèrò wérò lọ́nà tó bọ́gbọ́n mu. Síbẹ̀, kò sígbà kan tó lo ẹ̀bùn rẹ̀ yìí nílòkulò. Ní gbogbo ìgbà tó bá ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́, ńṣe ló máa ń fi ọpọlọ pípé tó ní gbé òtítọ́ lárugẹ. Láwọn ìgbà mìíràn, ó máa ń fi àwọn àlàyé tó fakíki paná àwọn ẹ̀sùn èké táwọn alátakò rẹ̀ fi kàn án. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló gbé ọ̀rọ̀ kalẹ̀ lọ́nà tó bá ọgbọ́n ìrònú mu kí ó lè kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láwọn ẹ̀kọ́ tó ṣe pàtàkì. Ẹ jẹ́ ká wo bí Jésù ṣe jẹ́ ọ̀gá nínú lílo ọgbọ́n ìrònú.
17, 18. Ọgbọ́n ìrònú tó fakíki wo ni Jésù fi já ẹ̀sùn èké táwọn Farisí fi kàn án ní koro?
17 Wo ìgbà tí Jésù ṣe ìwòsàn ọ̀gbẹ́ni kan tó lẹ́mìí èṣù, tí kò ríran, tí kò sì tún lè sọ̀rọ̀. Kí làwọn Farisí gbọ́ nípa èyí sí, kíá wọ́n dáhùn pé: “Àwé yìí kò lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde bí kò ṣe nípasẹ̀ Béélísébúbù [Sátánì], olùṣàkóso àwọn ẹ̀mí èṣù.” Kíyè sí i pé àwọn Farisí náà gbà pé agbára tó ju ti ẹ̀dá èèyàn lọ lèèyàn lè fi lé ẹ̀mí Èṣù jáde. Àmọ́, káwọn èèyàn má bàa gba Jésù gbọ́ ni wọ́n fi sọ pé agbára Èṣù ló ń lò. Jésù jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé wọn ò ro ohun tí wọ́n sọ yìí dáadáa. Ó sọ fún wọn pé: “Gbogbo ìjọba tí ó bá pínyà sí ara rẹ̀ a máa wá sí ìsọdahoro, gbogbo ìlú ńlá tàbí ilé tí ó bá sì pínyà sí ara rẹ̀ kì yóò dúró. Ní ọ̀nà kan náà, bí Sátánì bá ń lé Sátánì jáde, ó ti pínyà sí ara rẹ̀; báwo wá ni ìjọba rẹ̀ yóò ṣe dúró?” (Mátíù 12:22-26) Ohun tí Jésù ń sọ ni pé: ‘Tó bá jẹ́ pé ìránṣẹ́ Sátánì tẹ́ ẹ pè mí ni mo jẹ́ lóòótọ́, tí mo sì tún ń ba iṣẹ́ Sátánì jẹ́, a jẹ́ pé Sátánì ń gbéjà ko ara rẹ̀ nìyẹn, omi á sì gbẹ lẹ́yìn ẹja rẹ̀ láìpẹ́.’ Ọ̀rọ̀ pèsì jẹ, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?
18 Jésù ò fi ọ̀rọ̀ náà mọ síbẹ̀ yẹn o. Ó mọ̀ pé lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn àwọn Farisí yìí náà ti lé àwọn ẹ̀mí Èṣù jáde. Ni Jésù bá rọra yọ ìbéèrè kan lù wọ́n, èyí tó máa mú kí ẹnu wọ́n wọhò. Ó ní: “Bí mo bá ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde nípasẹ̀ Béélísébúbù, ta ni àwọn ọmọ [tàbí ọmọ ẹ̀yìn] yín fi ń lé wọn jáde?” (Mátíù 12:27) Lọ́nà kan, ohun tí Jésù ń sọ ni pé: ‘Ká ní lóòótọ́ ni mò ń fi agbára Sátánì lé ẹ̀mí Èṣù jáde, a jẹ́ pé agbára kan náà làwọn ọmọ ẹ̀yìn yín ń lò nìyẹn.’ Kí wá làwọn Farisí fẹ́ rí sọ? Wọn ò lè gbà láé pé agbára Sátánì làwọn ọmọ ẹ̀yìn àwọn ń lò. Ọgbọ́n ìrònú tí ò ṣeé já ní koro tí Jésù lò yìí sọ ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án di ọ̀rọ̀ tí ò mọ́gbọ́n dání.
19, 20. (a) Ọ̀nà dáradára wo ni Jésù gbà lo ọgbọ́n ìrònú? (b) Ọ̀nà wo ni Jésù gbà lo ọ̀rọ̀ náà “mélòómélòó ni” nígbà tó ń dá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lóhùn lẹ́yìn táwọn yẹn sọ fún un pé kó kọ́ àwọn ní báwọn á ṣe máa gbàdúrà?
19 Yàtọ̀ sí pé Jésù máa ń fi ọ̀rọ̀ ọgbọ́n pa àwọn alátakò rẹ̀ lẹ́nu mọ́, ó tún máa ń fi àwọn àlàyé tó mọ́gbọ́n dání, tó sì ń yíni lérò padà kọ́ àwọn èèyàn ní òtítọ́ tó ń mọ́kàn yọ̀ nípa Jèhófà. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló lo ọ̀rọ̀ bíi “mélòómélòó ni” láti mú kí òtítọ́ táwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ túbọ̀ dá wọn lójú. Ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ méjì péré yẹ̀ wò.
20 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù sọ pé kó kọ́ àwọn ní báwọn á ṣe máa gbàdúrà, nígbà tí Jésù dá wọn lóhùn, ó lo àpèjúwe ọkùnrin kan tó jẹ́ pé “ìtẹpẹlẹ rẹ̀ aláìṣojo” ló mú kí ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí ò fẹ́ dá a lóhùn tẹ́lẹ̀ wá fún ọkùnrin yìí lóhun tó ń béèrè. Jésù tún sọ báwọn òbí kì í ṣe é jáfara láti “fi ẹ̀bùn rere fún” àwọn ọmọ wọn. Lẹ́yìn náà ló parí ọ̀rọ̀ pé: “Bí ẹ̀yin, tí ẹ tilẹ̀ jẹ́ ẹni burúkú, bá mọ bí ẹ ṣe ń fi ẹ̀bùn rere fún àwọn ọmọ yín, mélòómélòó ni Baba tí ń bẹ ní ọ̀run yóò fi ẹ̀mí mímọ́ fún àwọn tí ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀!” (Lúùkù 11:1-13) Kókó tí Jésù ń tọ́ka sí ni ìyàtọ̀ tó wà láàárín èèyàn àti Ọlọ́run. Bí ọ̀rẹ́ kan tí ò fẹ́ dá aládùúgbò rẹ̀ lóhùn tẹ́lẹ̀ bá wá dá a lóhùn lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn nígbà tíyẹn ò yéé rọ̀ ọ́, àti pé báwọn òbí tí wọ́n jẹ́ aláìpé bá ń gbọ́ bùkátà àwọn ọmọ wọn, mélòómélòó ni Bàbá wa onífẹ̀ẹ́ tó ń bẹ lọ́run á fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ tí wọ́n ń fi tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ gbàdúrà sí i ní ẹ̀mí mímọ́!
21, 22. (a) Ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ wo ni Jésù lò nígbà tó ń fúnni nímọ̀ràn nípa bíborí àníyàn nípa nǹkan tara? (b) Kí lohun tá a lè sọ lẹ́yìn tá a ti ṣàyẹ̀wò díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà tí Jésù gbà kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́?
21 Jésù tún lo ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ yìí nígbà tó ń fúnni nímọ̀ràn nípa béèyàn ṣe lè borí àníyàn nípa nǹkan tara. Ó sọ pé: “Ẹ ṣàkíyèsí dáadáa pé àwọn ẹyẹ ìwò kì í fún irúgbìn tàbí kárúgbìn, wọn kò sì ní yálà abà tàbí ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́, síbẹ̀ Ọlọ́run ń bọ́ wọn. Mélòómélòó ni ẹ fi níye lórí ju àwọn ẹyẹ? Ẹ ṣàkíyèsí dáadáa bí àwọn òdòdó lílì ṣe ń dàgbà; wọn kì í ṣe làálàá tàbí rànwú . . . Wàyí o, bí Ọlọ́run bá ṣe báyìí wọ ewéko tí ń bẹ nínú pápá ní aṣọ, èyí tí ó wà lónìí, tí a sì jù sínú ààrò lọ́la, mélòómélòó ni òun yóò kúkú wọ̀ yín ní aṣọ, ẹ̀yin tí ẹ ní ìgbàgbọ́ kíkéré!” (Lúùkù 12:24, 27, 28) Òdodo ọ̀rọ̀, bí Jèhófà bá ń tọ́jú ẹyẹ àti òdòdó, mélòómélòó wá ni tàwọn ìránṣẹ́ rẹ̀! Kò sí ni, irú ọ̀rọ̀ làákàyè tó lágbára báyìí máa wọ àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Jésù lákínyẹmí ara.
22 Lẹ́yìn tá a ti ṣàyẹ̀wò díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà tí Jésù gbà kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́, a lè wá fi gbogbo ẹnu sọ ọ́ pé àsọdùn kọ́ lọ̀rọ̀ táwọn onípò àṣẹ tá a ní kí wọ́n lọ mú Jésù wá sọ nígbà tí wọ́n padà lọ́wọ́ òfo tí wọ́n sì sọ pé: “Ènìyàn mìíràn kò tíì sọ̀rọ̀ báyìí rí.” Àmọ́ ṣá, ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tá a mọ̀ mọ́ Jésù jù lọ ni ti lílo àpèjúwe tàbí àkàwé. Èé ṣe tó fi kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà yìí? Kí ló sì mú kí àwọn àpèjúwe rẹ̀ múná dóko? Àpilẹ̀kọ tó kàn á dáhùn àwọn ìbéèrè yìí.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ó jọ pé ẹmẹ̀wà àwọn Sànhẹ́dírìn làwọn onípò àṣẹ yìí, àmọ́ ó ní láti jẹ́ pé wọ́n tún wà lábẹ́ àṣẹ àwọn olórí àlùfáà.
b Wo àpilẹ̀kọ náà “Mo Fi Àwòṣe Lélẹ̀ Fun Yín” àti “Máa Tọ̀ Mí Lẹ́yìn Nígbà Gbogbo” nínú Ilé Ìṣọ́ August 15, 2002.
c Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù nìkan ló ṣàyọlò ọ̀rọ̀ tá a fà yọ kẹ́yìn yìí tó wà nínú Ìṣe 20:35. Àmọ́ ṣá, ọ̀rọ̀ tó fara pẹ́ ẹ wà nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe ni Pọ́ọ̀lù gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí (bóyá látẹnu ọmọ ẹ̀yìn kan tó gbọ́ nígbà tí Jésù sọ ọ́ tàbí kó gbọ́ ọ látẹnu Jésù lẹ́yìn tá a jí i dìde) tàbí kó jẹ́ pé àtọ̀runwá la ti fi í hàn án.—Ìṣe 22:6-15; 1 Kọ́ríńtì 15:6, 8.
d Òfin sọ pé káwọn Júù máa san owó orí tẹ́ńpìlì lọ́dọọdún. Owó dírákímà méjì (nǹkan bí owó ọ̀yà ọjọ́ méjì) ni wọ́n á san. Owó orí yìí ni wọ́n fi ń ṣàtúnṣe tẹ́ńpìlì, òun ni wọ́n fi ń bójú tó àwọn iṣẹ́ kan níbẹ̀, òun sì ni wọ́n fi ń bójú tó ìnáwó àwọn ẹbọ ojoojúmọ́ tí wọ́n ń rú nítorí orílẹ̀-èdè náà.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Àwọn àpẹẹrẹ wo ló fi hàn pé ọ̀rọ̀ tó tètè ń yéni, tó sì ṣe kedere ni Jésù fi kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́?
• Kí nìdí tí Jésù fi lo ìbéèrè nígbà tó ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́?
• Kí là ń pè ní àbùmọ́, báwo sì ni Jésù ṣe lo ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ yìí?
• Báwo ni Jésù ṣe lo ọgbọ́n ìrònú nígbà tó ń kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láwọn òtítọ́ tó ń mọ́kàn yọ̀ nípa Jèhófà?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Jésù lo àwọn èdè táwọn gbáàtúù á lóye
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Àwọn Farisí ‘ń sẹ́ kòkòrò kantíkantí ṣùgbọ́n wọ́n ń gbé ràkúnmí mì’