‘Ẹ Máa Dárí Ji Ara Yín Fàlàlà’
‘Ẹ Máa Dárí Ji Ara Yín Fàlàlà’
ǸJẸ́ o gbà pé Ọlọ́run ti dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́? Ó dà bíi pé èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn àgbà tó wà ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ló gbà bẹ́ẹ̀. Ọ̀mọ̀wé Loren Toussaint tó kọ́kọ́ kọ̀wé nípa ìwádìí kan tí wọ́n ṣe ní Ẹ̀ka Ìṣèwádìí Nípa Àjọṣe Ẹ̀dá ní Yunifásítì Michigan ròyìn pé nínú àwọn ẹgbẹ̀rún kan àti irínwó lé mẹ́tàlélógún [1,423] àwọn ará Amẹ́ríkà tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò, nǹkan bí ìpín ọgọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn àgbà tó ti lé lẹ́ni ọdún márùnlélógójì ló sọ pé Ọlọ́run ti dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn jì àwọn.
Àmọ́, ó wá jọni lójú pé ìpín mẹ́tàdínlọ́gọ́ta péré lára àwọn tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò náà ló sọ pé àwọn ń dárí ji àwọn ẹlòmíràn. Ìsọfúnni oníṣirò yẹn rán wa létí ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nínú Ìwàásù Lórí Òkè pé: “Bí ẹ bá dárí àṣemáṣe àwọn ènìyàn jì wọ́n, Baba yín ọ̀run yóò dárí jì yín pẹ̀lú; nígbà tí ó jẹ́ pé, bí ẹ kò bá dárí àṣemáṣe àwọn ènìyàn jì wọ́n, Baba yín kì yóò dárí àwọn àṣemáṣe yín jì yín.” (Mátíù 6:14, 15) Bẹ́ẹ̀ ni o, ó sinmi lórí àwọn ohun kan kí Ọlọ́run tó lè dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, lára wọn ni bá a bá ṣe múra tán láti dárí jì àwọn ẹlòmíràn sí.
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rán àwọn Kristẹni tó wà ní Kólósè létí ìlànà yìí. Ó rọ̀ wọ́n pé: “Ẹ máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà lẹ́nì kìíní-kejì bí ẹnikẹ́ni bá ní ìdí fún ẹjọ́ lòdì sí ẹlòmíràn. Àní gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti dárí jì yín ní fàlàlà, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe.” (Kólósè 3:13) Ká sọ tòótọ́, èyí kì í sábà rọrùn láti ṣe. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tẹ́nì kan bá sọ ọ̀rọ̀ kòbákùngbé tàbí ọ̀rọ̀ tí kò dára nípa rẹ, ó lè má rọrùn fún ọ láti dárí ji onítọ̀hún.
Àmọ́, àǹfààní tó wà nínú dídárí jini pọ̀ gan-an ni. Ohun tí Ọ̀mọ̀wé David R. Williams, onímọ̀ ìbágbépọ̀ ẹ̀dá, sọ nípa ìwádìí tó ṣe ni pé: “A rí i pé àjọṣe kan tó lágbára wà láàárín dídárí ji àwọn ẹlòmíràn àti àrùn ọpọlọ tó máa ń ṣe àwọn tó ti ń sún mọ́ ẹni àádọ́ta ọdún àtàwọn tó ti dàgbà jù bẹ́ẹ̀ lọ lára àwọn ará Amẹ́ríkà.” Ìyẹn wà níbàámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Sólómọ́nì ọlọgbọ́n Ọba nì, ẹni tó kọ̀wé ní nǹkan bí ẹgbẹ̀ẹ́dógún [3,000] ọdún sẹ́yìn pé: “Ọkàn-àyà píparọ́rọ́ ni ìwàláàyè ẹ̀dá alààyè ẹlẹ́ran ara.” (Òwe 14:30) Níwọ̀n bí ẹ̀mí ìdáríjì ti ń jẹ́ kí àjọṣe àárín àwa àti Ọlọ́run àtàwọn aládùúgbò wa túbọ̀ sunwọ̀n sí i, kò sídìí tí ò fi yẹ ká máa dárí ji ara wa fàlàlà látọkàn wá.—Mátíù 18:35.