Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Irú Ojú Wo Ló Yẹ Ká Máa Fi Wo Àdánwò?

Irú Ojú Wo Ló Yẹ Ká Máa Fi Wo Àdánwò?

Irú Ojú Wo Ló Yẹ Ká Máa Fi Wo Àdánwò?

ÌDÁNWÒ! Àdánwò! Gbogbo èèyàn ló gbọ́dọ̀ rí àdánwò. Àwọn ohun tó lè ṣokùnfà wọn ni èdè àìyedè, ìṣòro ìṣúnná owó, àìsàn, ìdẹwò, ẹ̀mí ṣe-ohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe tí kò tọ́, inúnibíni, àwọn ìpèníjà tó máa ń dìde nítorí àìdásí-tọ̀túntòsì wa tàbí nítorí pé a kì í bọ̀rìṣà, àti ọ̀pọ̀ nǹkan mìíràn. Ọ̀nà yòówù táwọn àdánwò lè gbà wá, wọ́n máa ń kóni sínú hílàhílo tó lé kenkà. Báwo la ṣe lè borí wọn? Ǹjẹ́ wọ́n tiẹ̀ ń ṣe wá láǹfààní kankan?

Ìtìlẹ́yìn Tó Dára Jù Lọ

Dáfídì Ọba ayé ìgbàanì dojú kọ àdánwò ní gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀, síbẹ̀ olóòótọ́ ni títí tó fi kú. Báwo ló ṣe fara dà á? Ó tọ́ka sí orísun okun rẹ̀ nígbà tó sọ pé: “Jèhófà ni Olùṣọ́ Àgùntàn mi. Èmi kì yóò ṣaláìní nǹkan kan.” Ó tún ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó ní: “Bí mo tilẹ̀ ń rìn ní àfonífojì ibú òjìji, èmi kò bẹ̀rù ohun búburú kankan, nítorí tí ìwọ wà pẹ̀lú mi; ọ̀pá rẹ àti ọ̀pá ìdaran rẹ ni àwọn nǹkan tí ń tù mí nínú.” (Sáàmù 23:1, 4) Dájúdájú, Jèhófà ni orísun ìtìlẹ́yìn tí kò láàlà. Ó ṣe olùṣọ́ Dáfídì ní gbogbo àkókò tó fi wà nínú ìṣòro, ó sì múra tán láti ṣe ohun kan náà fún wa nígbà tó bá yẹ kó ṣe bẹ́ẹ̀.

Báwo la ṣe lè rí ìtìlẹ́yìn Jèhófà? Bíbélì tọ́ka sí ọ̀nà náà, nígbà tó sọ pé: “Ẹ tọ́ ọ wò, kí ẹ sì rí i pé Jèhófà jẹ́ ẹni rere.” (Sáàmù 34:8) Ìkésíni àtọkànwá nìyẹn, àmọ́ kí ló túmọ̀ sí? Ó jẹ́ ọ̀rọ̀ ìṣírí pé ká sin Jèhófà, ká sì mú ìgbésí ayé wa bá ìfẹ́ rẹ̀ mu lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. Irú ipa ọ̀nà ìgbésí ayé bẹ́ẹ̀ túmọ̀ sí fífi àwọn nǹkan kan du ara ẹni. Ìgbà mìíràn wà tó tiẹ̀ lè yọrí sí àdánwò—ìyẹn inúnibíni àti ìjìyà. Àmọ́ àwọn tó fi tọkàntọkàn tẹ́wọ́ gba ìkésíni Jèhófà kò ní láti kábàámọ̀ pé àwọn ṣe bẹ́ẹ̀ láé. Jèhófà yóò jẹ́ ẹni rere gan-an sí wọn. Yóò tọ́ wọn sọ́nà, yóò sì bójú tó wọn nípa tẹ̀mí. Yóò lo Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, àti ìjọ Kristẹni láti mẹ́sẹ̀ wọn dúró nígbà tí wọ́n bá wà nínú àdánwò. Yóò sì fi ìyè àìnípẹ̀kun jíǹkí wọn ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀.—Sáàmù 23:6; 25:9; Aísáyà 30:21; Róòmù 15:5.

Àwọn tó ṣe ìpinnu tó ń yí ìgbésí ayé ẹni padà láti sin Jèhófà, tí wọ́n sì dúró lórí ìpinnu wọn ti rí i pé Jèhófà ń mú gbogbo ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Ohun táwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó tẹ̀ lé Jóṣúà wọ Ilẹ̀ Ìlérí rí nìyẹn. Gbàrà tí wọ́n kọjá Jọ́dánì ni wọ́n rí i pé àwọn àdánwò wà láti fara dà, àwọn ogun wà láti jà, àwọn ẹ̀kọ́ tó lágbára sì wà láti kọ́. Àmọ́ ìran yẹn ṣe olóòótọ́ ju àwọn baba wọn tó jáde ní ilẹ̀ Íjíbítì tí wọ́n sì kú sínú aginjù lọ. Nítorí náà, Jèhófà ti àwọn tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ lẹ́yìn. Ohun tí Bíbélì sì sọ nípa ipò tí wọ́n wà nígbà tó kù díẹ̀ kí Jóṣúà kú ni pé: “Jèhófà fún wọn ní ìsinmi yí ká, ní ìbámu pẹ̀lú ohun gbogbo tí ó búra fún àwọn baba ńlá wọn . . . Kò sí ìlérí kan tí ó kùnà nínú gbogbo ìlérí dáradára tí Jèhófà ti ṣe fún ilé Ísírẹ́lì; gbogbo rẹ̀ ni ó ṣẹ.” (Jóṣúà 21:44, 45) Ọ̀rọ̀ tàwa náà lè rí bẹ́ẹ̀ tá a bá gbára lé Jèhófà pátápátá nígbà tá a bá wà nínú àdánwò àti láwọn ìgbà mìíràn.

Kí ló lè sọ ìgbẹ́kẹ̀lé wa nínú Jèhófà di èyí tí kò lágbára mọ́? Jésù tọ́ka sí ohun kan nígbà tó sọ pé: “Kò sí ẹnì kan tí ó lè sìnrú fún ọ̀gá méjì . . . Ẹ kò lè sìnrú fún Ọlọ́run àti fún Ọrọ̀.” (Mátíù 6:24) Tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, a ò ní í máa wá ìfọ̀kànbalẹ̀ níbi tí ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ti ń wá a, ìyẹn nínú ọrọ̀ àlùmọ́nì. Jésù gba àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nímọ̀ràn pé: “Ẹ máa bá a nìṣó, nígbà náà, ní wíwá ìjọba náà àti òdodo Rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́, gbogbo nǹkan mìíràn wọ̀nyí ni a ó sì fi kún un fún yín.” (Mátíù 6:33) Kristẹni kan tí ò ka ohun ìní ti ara sí bàbàrà, tó sì ń fi Ìjọba Ọlọ́run sí ipò kìíní nínú ìgbésí ayé rẹ̀ ti yan ohun tó dára. (Oníwàásù 7:12) Lóòótọ́ ó lè ná an ni ohun kan. Ó lè gba pé kó fi nǹkan ìní du ara rẹ̀. Àmọ́ yóò rí èrè rẹpẹtẹ. Jèhófà yóò sì tì í lẹ́yìn.— Aísáyà 48:17, 18.

Ẹ̀kọ́ Tí Àdánwò Fi Ń Kọ́ Wa

Kì í wá ṣe pé yíyàn láti ‘tọ́ ọ wò, ká sì rí i pé Jèhófà jẹ́ ẹni rere’ kò ní jẹ́ ká fara gbá nínú ipò àìròtẹ́lẹ̀ tó ń dìde nínú ìgbésí ayé; bẹ́ẹ̀ ni kì í gbani tán pátápátá lọ́wọ́ ìkọlù Sátánì àtàwọn èèyàn tó jẹ́ aṣojú rẹ̀. (Oníwàásù 9:11) Nítorí ìdí èyí, a lè dán òótọ́ àti ìpinnu Kristẹni kan wò. Kí nìdí tí Jèhófà fi ń jẹ́ káwọn ìránṣẹ́ òun kó sínú irú àwọn àdánwò bẹ́ẹ̀? Àpọ́sítélì Pétérù sọ ìdí kan fún wa nígbà tó kọ̀wé pé: “Fún ìgbà díẹ̀ nísinsìnyí, bí ó bá gbọ́dọ̀ rí bẹ́ẹ̀, a ti fi onírúurú àdánwò kó ẹ̀dùn-ọkàn bá yín, kí ìjójúlówó ìgbàgbọ́ yín tí a ti dán wò, tí ó níye lórí púpọ̀púpọ̀ ju wúrà tí ń ṣègbé láìka fífi tí a fi iná dá an wò sí, lè jẹ́ èyí tí a rí gẹ́gẹ́ bí okùnfà fún ìyìn àti ògo àti ọlá nígbà ìṣípayá Jésù Kristi.” (1 Pétérù 1:6, 7) Bẹ́ẹ̀ ni o, àwọn àdánwò ń jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti fi bí ìgbàgbọ́ wa àti ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà ṣe jẹ́ ojúlówó tó hàn. Wọ́n sì tún ń pèsè èsì fún àwọn ìṣáátá àti ẹ̀sùn Sátánì Èṣù.—Òwe 27:11; Ìṣípayá 12:10.

Àwọn ìdánwò tún ń ràn wá lọ́wọ́ láti mú àwọn ànímọ́ Kristẹni mìíràn dàgbà. Bí àpẹẹrẹ, gbé ọ̀rọ̀ onísáàmù nì yẹ̀ wò, èyí tó sọ pé: “[Jèhófà] ń rí onírẹ̀lẹ̀; ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbé ara rẹ̀ ga fíofío ni òun mọ̀ kìkì láti òkèèrè.” (Sáàmù 138:6) Ọ̀pọ̀ lára wa ni kì í ṣe onírẹ̀lẹ̀ ènìyàn, àmọ́ àwọn àdánwò lè ràn wá lọ́wọ́ láti mú ànímọ́ pàtàkì yẹn dàgbà. Rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn nígbà ayé Mósè tí jíjẹ mánà lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ àti lóṣooṣù sú àwọn kan lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Dájúdájú, ìdánwò nìyẹn jẹ́ fún wọn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìpèsè lọ́nà ìyanu ni mánà náà jẹ́. Kí ni ète ìdánwò ọ̀hún? Mósè sọ fún wọn pé: “[Jèhófà] fi mánà bọ́ ọ nínú aginjù . . . kí ó bàa lè rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ àti kí ó bàa lè dán ọ wò.”—Diutarónómì 8:16.

A tún lè dán ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ wa wò pẹ̀lú. Lọ́nà wo? Àpẹẹrẹ kan rèé, báwo la ṣe máa ń ṣe nígbà táwọn àtúnṣe kan bá wáyé nínú ètò àjọ Jèhófà? (Aísáyà 60:17) Ǹjẹ́ a máa ń fi gbogbo ọkàn wa ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ ìwàásù àti ìkọ́ni? (Mátíù 24:14; 28:19, 20) Ǹjẹ́ a máa ń fi taratara tẹ́wọ́ gba àwọn àlàyé tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ṣe lórí òtítọ́ Bíbélì? (Mátíù 24:45-47; Òwe 4:18) Ǹjẹ́ a máa ń dènà ẹ̀mí fífẹ́ láti ní àwọn ohun èlò tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde, àwọn aṣọ tó lòde, tàbí ọkọ̀ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe jáde? Kíá lẹni tó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ máa sọ pé bẹ́ẹ̀ ni sírú àwọn ìbéèrè bẹ́ẹ̀.—1 Pétérù 1:14-16; 2 Pétérù 3:11.

Àdánwò tún máa ń jẹ́ ká ní ànímọ́ pàtàkì mìíràn—ìyẹn ni ìfaradà. Jákọ́bù tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn sọ pé: “Ẹ ka gbogbo rẹ̀ sí ìdùnnú, ẹ̀yin ará mi, nígbà tí ẹ bá ń bá onírúurú àdánwò pàdé, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti mọ̀ ní tòótọ́ pé ìjójúlówó ìgbàgbọ́ yín yìí tí a ti dán wò ń ṣiṣẹ́ yọrí sí ìfaradà.” (Jákọ́bù 1:2, 3) Fífarada onírúurú ìdánwò pẹ̀lú ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún nínú Jèhófà yóò jẹ́ ká mú ìdúróṣinṣin, àìyẹsẹ̀, àti ìwà títọ́ dàgbà. Ó ń fún wa lókun láti dènà àwọn àtakò tí Sátánì, ọlọ́run ayé yìí, tínú ń bí lè gbé dìde lọ́jọ́ iwájú.—1 Pétérù 5:8-10; 1 Jòhánù 5:19; Ìṣípayá 12:12.

Ní Èrò Tó Dára Nípa Àdánwò

Jésù Kristi, Ọmọ Ọlọ́run, tó jẹ́ ẹni pípé dojú kọ ọ̀pọ̀ àdánwò nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé, ó sì jàǹfààní tó ga nínú fífaradà wọ́n. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé Jésù “kọ́ ìgbọràn láti inú àwọn ohun tí ó jìyà rẹ̀.” (Hébérù 5:8) Bó ṣe dúró ṣinṣin títí dójú ikú mú ìyìn bá orúkọ Jèhófà ó sì jẹ́ kó ṣeé ṣe fún Jésù láti fi ìtóye ìwàláàyè rẹ̀ bí ènìyàn pípé lélẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìràpadà fún ìran ènìyàn. Ìyẹn ló jẹ́ káwọn tó lo ìgbàgbọ́ nínú Jésù lè máa fojú sọ́nà fún ìyè àìnípẹ̀kun. (Jòhánù 3:16) Nítorí pé Jésù dúró gẹ́gẹ́ bí olóòótọ́ lábẹ́ àdánwò, òun wá ni Àlùfáà Àgbà àti Ọba tá a gbé gorí ìtẹ́ báyìí.—Hébérù 7:26-28; 12:2.

Àwa náà ńkọ́? Bákan náà ni dídúró tá a bá dúró ṣinṣin lábẹ́ àwọn àdánwò yóò mú ìbùkún yàbùgà-yabuga wá. Ohun tí Bíbélì sọ nípa àwọn tó ní ìrètí ti ọ̀run ni pé: “Aláyọ̀ ni ẹni tí ń bá a nìṣó ní fífarada àdánwò, nítorí nígbà tí ó bá di ẹni tí a tẹ́wọ́ gbà, yóò gba adé ìyè, èyí tí Jèhófà ṣèlérí fún àwọn tí ń bá a lọ láti máa nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.” (Jákọ́bù 1:12) Àwọn tó ní ìrètí gbígbé lórí ilẹ̀ ayé ní ìdánilójú pé bí àwọn bá fara dà á láìjuwọ́sílẹ̀, àwọn á jogún ìyè àìnípẹ̀kun nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé. (Ìṣípayá 21:3-6) Ohun tó tún ṣe pàtàkì jùyẹn lọ ni pé, bí wọ́n ṣe ń fara dà á láìjuwọ́sílẹ̀ ń mú ìyìn bá orúkọ Jèhófà.

Bí a ṣe ń tẹ̀ lé ìṣísẹ̀ Jésù, ọkàn wa lè balẹ̀ pé gbogbo àdánwò tó bá dé bá wa nínú ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí la lè borí. (1 Kọ́ríńtì 10:13; 1 Pétérù 2:21) Lọ́nà wo? Nípa gbígbára lé Jèhófà, ẹni tí ń fún àwọn tó bá gbára lé e ní “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá.” (2 Kọ́ríńtì 4:7) Ǹjẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa dà bíi ti Jóòbù, ẹni tó jẹ́ pé nígbà tó ṣì ń fara da àdánwò líle koko pàápàá, ó sọ pẹ̀lú ìdánilójú pé: “Lẹ́yìn tí ó bá ti dán mi wò, èmi yóò jáde wá bí wúrà.”—Jóòbù 23:10.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Dídúró tí Jésù dúró ṣinṣin lábẹ́ àdánwò mú ìyìn bá orúkọ Jèhófà. Tiwa náà lè rí bẹ́ẹ̀