Máa Fara Wé Olùkọ́ Ńlá Náà
Máa Fara Wé Olùkọ́ Ńlá Náà
“Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn . . . , di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ fún yín mọ́.”—MÁTÍÙ 28:19, 20.
1, 2. (a) Báwo ni gbogbo wa ṣe jẹ́ olùkọ́ lọ́nà kan tàbí òmíràn? (b) Àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ wo làwọn Kristẹni tòótọ́ ní tó bá dọ̀ràn kíkọ́nilẹ́kọ̀ọ́?
ṢÉ OLÙKỌ́ ni ẹ́? Gbogbo èèyàn ni olùkọ́ lọ́nà kan tàbí òmíràn. Iṣẹ́ olùkọ́ lò ń ṣe nígbà tó o júwe ọ̀nà fún arìnrìn-àjò kan tó ṣìnà, nígbà tó o ṣàlàyé bí wọ́n ṣe ń ṣe iṣẹ́ kan fún ẹni tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ tàbí nígbà tó o kọ́ ọmọ kan bá á ṣe máa so okùn bàtà rẹ̀. Ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láwọn ọ̀nà báyìí máa ń múnú ẹni dùn, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?
2 Àǹfààní tí ò lẹ́gbẹ́ làwọn Kristẹni tòótọ́ ní tó bá dọ̀ràn kíkọ́ni lẹ́kọ̀ọ́. Iṣẹ́ tá a gbé lé wa lọ́wọ́ ni láti “máa sọ àwọn ènìyàn . . . , di ọmọ ẹ̀yìn, [ká sì] máa kọ́ wọn.” (Mátíù 28:19, 20) A tún ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ nínú ìjọ pàápàá. À ń yan àwọn ọkùnrin tí wọ́n tóótun láti sìn bí “olùṣọ́ àgùntàn àti olùkọ́,” láti gbé ìjọ ró. (Éfésù 4:11-13) À ń retí kí àwọn obìnrin tó dàgbà dénú jẹ́ “olùkọ́ni ní ohun rere” nínú ìgbòkègbodò wọn bíi Kristẹni lójoojúmọ́. (Títù 2:3-5) Gbogbo wa pátá la gbà níyànjú láti máa fún àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa níṣìírí, a sì lè ṣe èyí nípa fífi Bíbélì gbé àwọn ẹlòmíràn ró. (1 Tẹsalóníkà 5:11) Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá ló jẹ́ láti máa fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kọ́ àwọn èèyàn, ká sì máa ṣe ìpínfúnni àwọn nǹkan tẹ̀mí tó máa ṣe àwọn èèyàn láǹfààní títí láé!
3. Báwo la ṣe lè jẹ́ olùkọ́ tó túbọ̀ gbéṣẹ́?
3 Àmọ́, báwo la ṣe lè mú ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ wa sunwọ̀n sí i? Olórí ọ̀nà tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni fífarawé Jésù, Olùkọ́ Ńlá náà. Àwọn kan lè bẹ̀rẹ̀ sí ṣe kàyéfì pé: ‘Báwo la ṣe lè máa fara wé Jésù tó jẹ́ ẹni pípé?’ Òótọ́ ni pé a ò lè jẹ́ olùkọ́ tó gbọ́n tán tó mọ̀ tán. Síbẹ̀, bó ti wù kí agbára wa mọ, a ṣì lè sa gbogbo ipá wa láti fara wé ọ̀nà tí Jésù gbà kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́. Ẹ jẹ́ ká jíròrò bá a ṣe lè ṣàmúlò mẹ́rin nínú ọ̀nà tó lò—kíkọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà tó rọrùn, lílo àwọn ìbéèrè tó gbéṣẹ́, lílo ọgbọ́n ìrònú àti lílo àwọn àpèjúwe tó gbéṣẹ́.
Máa Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́ Lọ́nà Tó Rọrùn
4, 5. (a) Kí nìdí tí rírọrùn tí òtítọ́ inú Bíbélì rọrùn fi jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ohun pàtàkì jù lọ nípa rẹ̀? (b) Èé ṣe tó fi yẹ ká ṣọ́ra pẹ̀lú irú èdè tá à ń lò tá a bá fẹ́ kọ́ni lọ́nà tó rọrùn?
4 Àwọn òtítọ́ pàtàkì inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run rọrùn láti lóye. Nígbà tí Jésù ń gbàdúrà, ó sọ pé: “Mo yìn ọ́ ní gbangba, Baba, . . . nítorí pé ìwọ ti fi nǹkan wọ̀nyí pa mọ́ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n àti àwọn amòye, o sì ti ṣí wọn payá fún àwọn ìkókó.” (Mátíù 11:25) Jèhófà ti fi àwọn ète rẹ̀ han àwọn olóòótọ́ inú tí wọ́n sì jẹ́ onírẹ̀lẹ̀. (1 Kọ́ríńtì 1:26-28) Nítorí náà, ọ̀kan lára àwọn ohun pàtàkì jù lọ nípa òtítọ́ inú Bíbélì ni pé ó rọrùn láti lóye.
5 Báwo lo ṣe lè kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà tó rọrùn nígbà tó o bá ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tàbí tó o padà lọ bẹ àwọn tó fìfẹ́ hàn wò? Tiẹ̀ gbọ́ ná, ẹ̀kọ́ wo la kọ́ lára Olùkọ́ Ńlá náà? Àwọn èdè tó rọrùn láti tètè lóye ni Jésù lò kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ lè yé àwọn tó ń gbọ́ ọ, tí ọ̀pọ̀ lára wọn jẹ́ “àwọn ènìyàn tí kò mọ̀wé àti gbáàtúù.” (Ìṣe 4:13) Nítorí náà, tá a bá fẹ́ kọ́ni lọ́nà tó rọrùn, ohun àkọ́kọ́ ni pé ká ṣọ́ra pẹ̀lú irú àwọn èdè tá à ń lò. Kò dìgbà tá a bẹ̀rẹ̀ sí pe àwọn èdè kàǹkà-kàǹkà tàbí àwọn gbólóhùn gbankọgbì ká tó lè mú kí òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wọ àwọn èèyàn lọ́kàn. Irú “ọ̀rọ̀ àsọrégèé” bẹ́ẹ̀ lè kó àwọn èèyàn láyà jẹ, àgàgà àwọn tí ò kàwé púpọ̀. (1 Kọ́ríńtì 2:1, 2) Àpẹẹrẹ Jésù jẹ́ ká mọ̀ pé a lè fi àwọn ọ̀rọ̀ tí ò nira láti lóye sọ òtítọ́ náà fún àwọn èèyàn lọ́nà tó lágbára.
6. Báwo la ṣe lè yẹra fún rírọ́ ìsọfúnni tó pàpọ̀jù sí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lágbárí?
6 Láti kọ́ni lọ́nà tó rọrùn, a tún gbọ́dọ̀ ṣọ́ra fún rírọ́ ìsọfúnni tó pàpọ̀jù sí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lágbárí lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo. Jésù mọ ibi tágbára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ mọ. (Jòhánù 16:12) Àwa náà gbọ́dọ̀ mọ ibi tágbára akẹ́kọ̀ọ́ wa mọ. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá ń fi ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun bá ẹnì kan kẹ́kọ̀ọ́, kò pọn dandan kó jẹ́ pé gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ la fẹ́ ṣàlàyé dórí bíńtín. a Bẹ́ẹ̀ náà ni kò yẹ ká kàn máa ka gbogbo ohun tó wà níbẹ̀ lọ gbuurugbu, bí ẹni pé bí ibi tá a kà ṣe pọ̀ tó ló jà jù. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí akẹ́kọ̀ọ́ náà nílò àti ibi tí òye rẹ̀ mọ ló yẹ kó pinnu bí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà ṣe ń lọ sí. Góńgó wa ni láti jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ náà di ọmọlẹ́yìn Kristi àti olùjọ́sìn Jèhófà. A ní láti yọ̀ǹda àkókò tó pọ̀ tó láti ran akẹ́kọ̀ọ́ náà lọ́wọ́ kó lè lóye ohun tó ń kọ́ dáadáa. Èyí á jẹ́ kí òtítọ́ wọ ọkàn rẹ̀, kó sì gbé ìgbésẹ̀ tó yẹ.—Róòmù 12:2.
7. Àwọn àbá wo ló lè jẹ́ ká kọ́ni lọ́nà tó rọrùn nígbà tá a bá níṣẹ́ nípàdé?
7 Báwo la ṣe lè sọ̀rọ̀ lọ́nà tó “rọrùn láti lóye” nígbà tá a bá níṣẹ́ nípàdé, pàápàá nígbà táwọn ẹni tuntun bá wà láàárín wa? (1 Kọ́ríńtì 14:9) Wo àwọn àbá mẹ́ta tó lè ṣèrànwọ́. Ìkíní, ṣàlàyé àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣàjèjì tó o bá sọ. Òye wa nípa Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń mú ká máa lo àwọn ọ̀rọ̀ kan táwọn mìíràn kì í lò. Tá a bá lo àwọn ọ̀rọ̀ bíi “ẹrú olóòótọ́ àti olóye,” “àwọn àgùntàn mìíràn,” àti “Bábílónì Ńlá,” ó lè pọn dandan ká fi àwọn gbólóhùn tó rọrùn ṣàlàyé wọn kó lè yé àwọn èèyàn. Ìkejì, kí ọ̀rọ̀ rẹ má pọ̀ jù. Tí ọ̀rọ̀ bá lọ pọ̀ jù, tá à ń sọ àsọbóro, ńṣe ló máa sú àwùjọ. Tá a bá fẹ́ kí ọ̀rọ̀ yéni, kò sídìí fún fífi àtamọ́ mọ́ àtamọ̀. Ìkẹta, má ṣe jẹ́ kí ìsọfúnni tó o kó jọ pọ̀ jù. A lè rí ọ̀pọ̀ ìsọfúnni tó fani mọ́ra nínú àwọn ìwé tá a ti kó iṣẹ́ wa jọ. Àmọ́ ohun tó dára jù ni pé ká pa gbogbo wọn pọ̀ sí bíi kókó mélòó kan, ká sì lo kìkì ìsọfúnni tó máa ti ọ̀rọ̀ wa lẹ́yìn, tó sì máa ṣeé ṣàlàyé láàárín àkókò tí wọ́n yàn fún wa.
Lílo Ìbéèrè Lọ́nà Tó Gbéṣẹ́
8, 9. Báwo la ṣe lè mọ ìbéèrè tó máa bá ipò tí onílé wà mu? Mú àpẹẹrẹ wá.
8 Rántí pé Jésù mọ bó ṣe máa ń fi ìbéèrè mú káwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ èrò ọkàn wọn jáde àti láti mú kí wọ́n mọ bó ṣe yẹ kéèyàn máa ronú. Jésù fi pẹ̀lẹ́tù lo ìbéèrè láti mú kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ wọ̀ wọ́n lọ́kàn, kí ó sì ru wọ́n sókè. (Mátíù 16:13, 15; Jòhánù 11:26) Báwo làwa náà ṣe lè lo ìbéèrè lọ́nà tó gbéṣẹ́ bíi ti Jésù?
9 Nígbà tá a bá ń wàásù láti ojúlé dé ojúlé, a lè fi ìbéèrè ru ìfẹ́ àwọn èèyàn sókè, èyí á sì fún wa láǹfààní láti bá wọn sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run. Báwo la ṣe lè mọ ìbéèrè tó máa bá ipò tí onílé wà mu? Nípa jíjẹ́ alákìíyèsí ni. Bó o bá ti ń sún mọ́ ilé kan, wo gbogbo àyíká. Ṣé àwọn ohun ìṣeré ọmọdé wà nílẹ̀, tó jẹ́ àmì pé àwọn ọmọdé wà nílé náà? Tó bá wà, a lè bi onílé pé, ‘Ǹjẹ́ o tiẹ̀ ti ronú rí nípa bí ayé ṣe máa rí nígbà táwọn ọmọ rẹ bá dàgbà?’ (Sáàmù 37:10, 11) Ṣé àwọn àgádágodo bíi mélòó kan wà lẹ́nu ilẹ̀kùn, tàbí wọ́n ní ètò ààbò tí ń bá iná ṣiṣẹ́? Tó bá wà, a lè béèrè pé, ‘Ǹjẹ́ ẹ rò pé àkókò kan máa wà tí ààbò á wà fún wa nínú ilé àti ní ìgboro?’ (Míkà 4:3, 4) Ṣé ọ̀nà tí wọ́n máa ń ti àga àwọn abirùn gbà wà ní ilé náà? Tó bá wà, a lè béèrè pé, ‘Ǹjẹ́ àkókò kan máa wà tí ẹnikẹ́ni ò ní ṣàìsàn mọ́?’ (Aísáyà 33:24) A lè rí ọ̀pọ̀ ọ̀nà tá a lè gbà gbọ́rọ̀ kalẹ̀ nínú ìwé pẹlẹbẹ Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Awọn Ìjíròrò Bibeli Kí A Sì Máa Báa Nìṣó. b
10. Báwo la ṣe lè fi ìbéèrè “fa” èrò àti ìmọ̀lára akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan “jáde,” àmọ́ kí la gbọ́dọ̀ fi sọ́kàn?
10 Báwo la ṣe lè lo ìbéèrè lọ́nà tó gbéṣẹ́ tá a bá ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? A ò lè mọ ohun tó wà lọ́kàn àwọn èèyàn nítorí a kì í ṣe Jésù. Síbẹ̀, àwọn ìbéèrè ọlọgbọ́n tí ń lani lóye lè ràn wá lọ́wọ́ láti “fa” èrò àti ìmọ̀lára akẹ́kọ̀ọ́ náà “jáde.” (Òwe 20:5) Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé à ń kẹ́kọ̀ọ́ àkòrí tó sọ pé “Ìdí Tí Gbígbé Ìgbésí-Ayé Ìwà-Bí-Ọlọ́run Fi Ń Mú Ayọ̀ Wá,” nínú ìwé Ìmọ̀. Àkòrí náà sọ ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ìwà àìṣòótọ́, àgbèrè àtàwọn ìwà mìíràn. Akẹ́kọ̀ọ́ náà lè dáhùn ìbéèrè náà mọ̀ràn-ìn mọran-in gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú ìwé, àmọ́ ǹjẹ́ ó fara mọ́ ẹ̀kọ́ tó ń kọ́ yìí? A lè bi í pé: ‘Ṣé ojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn ọ̀ràn yìí tọ́ lójú ẹ?’ ‘Báwo lo ṣe lè fi àwọn ìlànà Bíbélì yìí sílò nínú ìgbésí ayé ẹ?’ Bó ti wù ó rí, má ṣe gbà gbé láti fi ọ̀wọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ náà wọ̀ ọ́, kó o sì fún un ní iyì tó tọ́ sí i. A ò ní fẹ́ béèrè àwọn ìbéèrè tó máa kó ìtìjú bá akẹ́kọ̀ọ́ náà tàbí èyí tó máa wọ́ ọ nílẹ̀.—Òwe 12:18.
11. Ọ̀nà wo làwọn tó ń bá àwùjọ sọ̀rọ̀ lè gbà lo ìbéèrè lọ́nà tó gbéṣẹ́?
11 Àwọn tó bá ń bá àwùjọ sọ̀rọ̀ pẹ̀lú lè lo ìbéèrè lọ́nà tó gbéṣẹ́. Àwọn ìbéèrè mọ̀-ọ́n-nú—tá ò retí pé káwọn tó ń gbọ́ wa dáhùn síta—lè ran àwùjọ lọ́wọ́ láti ronú. Jésù lo irú àwọn ìbéèrè yìí lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. (Mátíù 11:7-9) Síwájú sí i, lẹ́yìn tí olùbánisọ̀rọ̀ kan bá ti nasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ tán, ó lè fi ìbéèrè fa àwọn kókó inú ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ. Ó lè sọ pé, “Nínú ìjíròrò wa tòní, a máa wá ìdáhùn sáwọn ìbéèrè wọ̀nyí . . . ” Tó bá sì fẹ́ parí ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó lè tún àwọn ìbéèrè yẹn béèrè láti fi ṣe àkópọ̀ àwọn kókó inú ọ̀rọ̀ rẹ̀.
12. Mú àpẹẹrẹ kan wá tó fi hàn báwọn Kristẹni alàgbà ṣe lè fi ìbéèrè ran onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn lọ́wọ́ láti rí ìtùnú nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
12 Nígbà táwọn Kristẹni alàgbà bá ń ṣiṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn, wọ́n lè fi ìbéèrè ran “ọkàn tí ó soríkọ́” lọ́wọ́ láti rí ìtùnú nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (1 Tẹsalóníkà 5:14) Bí àpẹẹrẹ, tí alàgbà kan bá ń gba ẹnì kan tí ìbànújẹ́ dorí rẹ̀ kodò níyànjú, ó lè tọ́ka sí Sáàmù 34:18. Ibẹ̀ kà pé: “Jèhófà sún mọ́ àwọn oníròbìnújẹ́ ní ọkàn-àyà; ó sì ń gba àwọn tí a wó ẹ̀mí wọn palẹ̀ là.” Kí alàgbà yìí lè mọ̀ bóyá ẹni tí òun ń fún níṣìírí rí i pé ẹsẹ Bíbélì yìí kan òun, ó lè bi í pé: ‘Àwọn wo ni Jèhófà sún mọ́? Ǹjẹ́ àwọn àkókò kan wà tó o máa ń rí ara rẹ bí ẹni tó ní ‘ìròbìnújẹ́ ní ọkàn-àyà’ tá a sì ‘wó ẹ̀mí rẹ̀ palẹ̀’? Bí Jèhófà bá sún mọ́ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ bí Bíbélì ṣe sọ, ǹjẹ́ o ò rò pé á sún mọ́ ìwọ náà?’ Irú ọ̀rọ̀ ìfinilọ́kànbalẹ̀ bẹ́ẹ̀ lè mú kí oníròbìnújẹ́ túra ká.—Aísáyà 57:15.
Lílo Ọgbọ́n Ìrònú
13, 14. (a) Ọ̀nà wo la lè gbà fèrò wérò pẹ̀lú ẹnì kan tó lóun ò gbà pé Ọlọ́run wà nítorí òun ò lè rí i? (b) Kí nìdí tí ò fi yẹ ká máa retí pé gbogbo èèyàn ló máa gba ohun tá a bá sọ?
13 Nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, a fẹ́ fi ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tí ń yíni lérò padà bá àwọn èèyàn fèrò wérò láti lè dé inú ọkàn wọn. (Ìṣe 19:8; 28:23, 24) Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé a gbọ́dọ̀ lọ kọ́ bí wọ́n ṣe ń fagbárí gbé ọ̀rọ̀ jókòó, ká tó lè fi òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kọ́ àwọn èèyàn? Rárá o. Kò pọn dandan kí ọ̀rọ̀ tó bá ọgbọ́n ìrònú mu jẹ́ àdììtú. Àwọn àlàyé tó bá ọgbọ́n ìrònú mu tá a gbé kalẹ̀ lọ́nà tó rọrùn ló sábàá ń méso jáde jù. Gbé àpẹẹrẹ kan yẹ̀ wò.
14 Èsì wo la lè fún ẹnì kan tó sọ pé òun ò gbà pé Ọlọ́run wà nítorí pé òun ò lè rí i? A lè ṣàlàyé òfin àdánidá, tó fi hàn pé bí kò bá sóhun tó ṣe ẹ̀ṣẹ́, ẹ̀ṣẹ́ kì í ṣẹ́ lásán. A mọ̀ pé tí nǹkan kan bá ṣẹlẹ̀, kò lè ṣe kí ó máà nídìí. A lè sọ fún ẹni náà pé: ‘Ká ló o wà níbì kan tó jẹ́ àdádó, lo bá ṣàdédé kan ilé mèremère kan tí oúnjẹ kúnnú rẹ̀. Kò dìgbà téèyàn bá sọ fún ẹ kó o tó mọ̀ pé ilé náà kò ṣàdédé débẹ̀, ẹnì kan ló kọ́ ọ tó sì kó oúnjẹ kúnnú rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, tá a bá wá rí àwọn iṣẹ́ ọnà tó wà nínú ìṣẹ̀dá àti ọ̀pọ̀ oúnjẹ tó ń bẹ láyé, ṣé kò bọ́gbọ́n mu láti gbà pé Ẹnì kan ló dá àwọn nǹkan yìí?’ Àlàyé rírọrùn tí Bíbélì ṣe sojú abẹ níkòó. Ó sọ pé: “Dájúdájú, olúkúlùkù ilé ni a kọ́ láti ọwọ́ ẹnì kan, ṣùgbọ́n ẹni tí ó kọ́ ohun gbogbo ni Ọlọ́run.” (Hébérù 3:4) Àmọ́ ṣá, bó ti wù kí àlàyé wa gún régé tó, gbogbo èèyàn kọ́ ló máa gba ohun tá a sọ. Bíbélì sọ fún wa pé kìkì àwọn tó bá ní “ìtẹ̀sí-ọkàn títọ́” ló máa ń di onígbàgbọ́.—Ìṣe 13:48; 2 Tẹsalóníkà 3:2.
15. Ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ wo la lè lò láti ṣàlàyé àwọn ànímọ́ Jèhófà àti ọ̀nà tó gbà ń ṣe nǹkan, àpẹẹrẹ méjì wo ló sì fi bá a ṣe lè lo ọ̀nà yìí hàn?
15 Nígbà tá a bá ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́, bóyá lóde ẹ̀rí ni o tàbí nínú ìjọ, a lè lo ọgbọ́n ìrònú láti fi ṣàlàyé tó gún régé nípa àwọn ànímọ́ Jèhófà àti ọ̀nà tó gbà ń ṣe nǹkan. Èyí tó tiẹ̀ gbéṣẹ́ jù ni gbólóhùn náà ‘mélòómélòó ni’ tí Jésù fi ń gbé àlàyé rẹ̀ jókòó nígbà mìíràn. (Lúùkù 11:13; 12:24) Ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ yìí máa ń jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wọni lọ́kàn ṣinṣin, nítorí pé nǹkan méjì ló ń fi wéra. Láti fi hàn pé ẹ̀kọ́ iná ọ̀run àpáàdì kò bọ́gbọ́n mu rárá, a lè sọ pé: ‘Kò sí baba onífẹ̀ẹ́ kankan tó máa ki ọwọ́ ọmọ rẹ̀ bọ iná nítorí pé ó fẹ́ bá ọmọ náà wí. Mélòómélòó wá ni ẹ̀kọ́ iná ọ̀run àpáàdì máa burú tó lójú Bàbá wa ọ̀run tó jẹ́ onífẹ̀ẹ́!’ (Jeremáyà 7:31) Tá a bá fẹ́ kọ́ àwọn èèyàn pé Jèhófà bìkítà nípa àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, a lè sọ pé: ‘Níwọ̀n bí Jèhófà ti mọ orúkọ ọ̀kọ̀ọ̀kan ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù ìràwọ̀ tó wà, mélòómélòó wá ni yóò bìkítà nípa àwọn ẹ̀dá èèyàn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, tó sì fi ẹ̀jẹ̀ Ọmọ rẹ̀ tó ṣeyebíye rà!’ (Aísáyà 40:26; Ìṣe 20:28) Irú ọ̀nà ìrònú tó múná dóko bẹ́ẹ̀ lè jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wa wọ àwọn èèyàn lọ́kàn.
Àpèjúwe Tó Ṣe Rẹ́gí
16. Kí nìdí tí àpèjúwe fi ṣe pàtàkì nínú kíkọ́ni lẹ́kọ̀ọ́?
16 Ńṣe làwọn àpèjúwe tó gbéṣẹ́ dà bí èèlò amóúnjẹ dùn tó máa mú kí ẹ̀kọ́ tá à ń kọ́ àwọn èèyàn máa dá wọn lọ́fun tòótòó. Kí nìdí tí àpèjúwe fi ṣe pàtàkì nínú kíkọ́ni lẹ́kọ̀ọ́? Olùkọ́ni kan sọ pé: “Ọ̀kan lára àwọn ohun tó ṣòroó ṣe jù fún ẹ̀dá èèyàn ni pé kó máa ronú láìrí ohun gidi tó lè fi júwe.” Àpèjúwe máa ń jẹ́ kéèyàn lè fọkàn yàwòrán nǹkan kó sì yéni, ó sì ń jẹ́ kéèyàn túbọ̀ lóye èròǹgbà tuntun. Jésù kò kẹ̀rẹ̀ rárá nínú lílo àpèjúwe. (Máàkù 4:33, 34) Ẹ jẹ́ ká wo bá a ṣe lè lo ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ yìí.
17. Àwọn kókó mẹ́rin wo ló ń mú kí àpèjúwe gbéṣẹ́?
17 Kí ló ń mú kí àpèjúwe gbéṣẹ́? Ìkíní, ó gbọ́dọ̀ bá àwùjọ mu, kí ohun tá fi ṣàpèjúwe jẹ́ èyí táwọn tó ń gbọ́ wa á lè tètè lóye. Àá rántí pé ohun táwọn tó ń gbọ́rọ̀ Jésù ń ṣe nínú ìgbésí ayé wọn ojoojúmọ́ ló ń lò nínú àpèjúwe rẹ̀. Ìkejì, àpèjúwe gbọ́dọ̀ bá kókó ọ̀rọ̀ mu. Bí àfiwé kò bá bá ọ̀rọ̀ mu, ńṣe ni àpèjúwe wa máa da ọ̀rọ̀ rú mọ́ àwọn tó ń gbọ́ wa lójú. Ìkẹta, àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀rọ̀ tí ò pọn dandan kò gbọ́dọ̀ sí nínú àpèjúwe. Rántí pé àwọn kókó-kókó inú ọ̀rọ̀ ni Jésù mú jáde, ó sì fi àwọn tí ò pọn dandan sílẹ̀. Ìkẹrin, lẹ́yìn tá a bá ṣe àpèjúwe kan, ká rí i dájú pé àwọn èèyàn mọ bó ṣe kan àwọn. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, àwọn mìíràn lè má mọ bí wọ́n á ṣe fi àwọn kókó inú àpèjúwe náà sílò.
18. Báwo la ṣe lè ronú kan àwọn àpèjúwe tó ṣe rẹ́gí?
18 Báwo la ṣe lè ronú kan àwọn àpèjúwe tó ṣe rẹ́gí? Kò dìgbà tá a bá ronú àwọn ìtàn tó gùn jàn-ànràn jan-anran. Àwọn àpèjúwe tó ṣe ṣókí ló máa ń wọni lọ́kàn jù lọ. Ìwọ ṣáà ronú àwọn àpẹẹrẹ tó bá kókó tó ò ń jíròrò mu. Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé à ń jíròrò nípa bí Ọlọ́run ṣe ń dárí jini, tá a sì fẹ́ ṣàpèjúwe kókó tó wà nínú Ìṣe 3:19, tó sọ pé Jèhófà ‘ń pa’ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa ‘rẹ́’ tàbí nù ún dà nù. Àkànlò èdè lèyí fúnra rẹ̀, àmọ́ àpẹẹrẹ wo la lè mú wá láti fi ṣàpèjúwe kókó yìí. Ṣé a lè lo nǹkan ìpàwérẹ́? A lè sọ pé: ‘Bí Jèhófà bá dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, ńṣe ló dà bí ìgbà tó mú ohun ìpàwérẹ́ tó sì fi pa wọ́n rẹ́.’ Ṣàṣà lẹni tí kò ní lóye irú àpèjúwe rírọrùn yìí.
19, 20. (a) Ibo la ti lè rí àwọn àpèjúwe tó múná dóko? (b) Sọ díẹ̀ lára àwọn àpèjúwe tó gbéṣẹ́ tá a ti tẹ̀ jáde nínú àwọn ìwé wa. (Tún wo àpótí.)
19 Ibo lo ti lè ráwọn àpèjúwe tó ṣe rẹ́gí àtàwọn ìtàn ìgbésí ayé? Wo ti ìgbésí ayé ìwọ fúnra rẹ tàbí onírúurú ìrírí àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ. Èèyàn tún lè rí àwọn àpèjúwe níbòmíràn, láti ara àwọn ohun ẹlẹ́mìí àti aláìlẹ́mìí, àwọn nǹkan tó wà nínú ilé tàbí àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní lọ́ọ́lọ́ọ́ táwọn ará àdúgbò mọ̀ dáadáa. Ọ̀nà pàtàkì tá a lè gbà rí àwọn àpèjúwe tó dáa ni pé ká wà lójúfò, ká máa “fẹ̀sọ̀ kíyè sí” àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lágbègbè wa lójoojúmọ́. (Ìṣe 17:22, 23) Ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ nípa béèyàn ṣe lè di sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀, sọ pé: “Olùbánisọ̀rọ̀ tó bá ń kíyè sí ìgbésí ayé ẹ̀dá èèyàn àti iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe, tó ń fọ̀rọ̀ jomitoro ọ̀rọ̀ pẹ̀lú onírúurú èèyàn, tó ń wo nǹkan ní àwòfín, tó sì ń béèrè ìbéèrè títí tá á fi lóye wọn, máa ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan tó lè fi ṣàpèjúwe, èyí á sì ràn án lọ́wọ́ gan-an nígbàkigbà tó bá nílò rẹ̀.”
20 Èèyàn tún lè rí omilẹgbẹ àpèjúwe níbòmíràn, ìyẹn nínú Ilé Ìṣọ́, Jí!, àtàwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ mìíràn tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tẹ̀ jáde. O lè rí ọ̀pọ̀ nǹkan kọ́ tó o bá ṣàyẹ̀wò bí ìwé wọ̀nyí ṣe ń lo àpèjúwe. c Bí àpẹẹrẹ, wo àpèjúwe tó wà nínú ìwé Ìmọ̀ orí 17, ìpínrọ̀ 11. Ó fi bí ìwà onírúurú àwọn èèyàn tó wà nínú ìjọ ṣe yàtọ̀ síra wé oríṣiríṣi ọkọ̀ tó ń kọjá lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ lójú títì. Kí ló mú kí àkàwé yìí gbéṣẹ́? Wàá kíyè sí i pé ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lójoojúmọ́ ló dá lé lórí, ó bá kókó ọ̀rọ̀ mu, ìtumọ̀ rẹ̀ sì ṣe kedere. A lè lo àwọn àpèjúwe tó wà nínú àwọn ìwé wa nígbà tá a bá ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́, a tilẹ̀ lè ṣàlàyé rẹ̀ lọ́nà tí yóò fi bá ipò akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan mu tàbí ká lò ó nígbà tí wọ́n bá yan ọ̀rọ̀ fún wa láti sọ.
21. Àwọn èrè wo lèèyàn ń rí nínú jíjẹ́ olùkọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó múná dóko?
21 Èrè tó wà nídìí kéèyàn jẹ́ olùkọ́ tó múná dóko pọ̀ gan-an. Nígbà tá a bá ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́, ńṣe là ń fún àwọn èèyàn ní nǹkan; ńṣe là ń fún wọn lára ohun tá a ní, láti fi ràn wọ́n lọ́wọ́. Irú fífúnni yìí ń mú ayọ̀ wá. Bíbélì sọ pé: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.” (Ìṣe 20:35) Ní tàwọn tó ń fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kọ́ni, ayọ̀ yìí wé mọ́ ìdùnnú mímọ̀ pé ohun tó jẹ́ ojúlówó tó sì láǹfààní ayérayé là ń fún àwọn èèyàn, ìyẹn òtítọ́ nípa Jèhófà. Inú wa á tún máa dùn nítorí a mọ̀ pé Olùkọ́ Ńlá náà, ìyẹn Jésù Kristi là ń fara wé.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde.
b Wo àkòrí náà “Awọn Ìnasẹ̀-Ọ̀rọ̀ Fún Lílò Ninu Iṣẹ́-Ìsìn Pápá,” lójú ìwé 2-7.—Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde.
c Àwọn àpẹẹrẹ míì wà nínú ìwé Watch Tower Publications Index 1986-2000, lábẹ́ àkòrí náà “Illustrations.” [Àwọn Àpèjúwe]—Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde ní àwọn èdè mélòó kan.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Báwo la ṣe lè kọ́ni lọ́nà tó máa tètè yéni nígbà tá a bá ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? nígbà tá a bá níṣẹ́ nínú ìjọ?
• Báwo la ṣe lè lo ìbéèrè lọ́nà tó gbéṣẹ́ tá a bá ń wàásù láti ilé dé ilé?
• Báwo la ṣe lè lo ọgbọ́n ìrònú láti ṣàlàyé àwọn ànímọ́ Jèhófà àti ọ̀nà tó gbà ń ṣe nǹkan?
• Ibo la ti lè rí àwọn àpèjúwe tó ṣe rẹ́gí?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ǹjẹ́ O Rántí Àpèjúwe Wọ̀nyí?
Àwọn àpèjúwe mélòó kan tó gbéṣẹ́ ló wà nísàlẹ̀ yìí. O ò ṣe kúkú wo inú àwọn ìwé tá a ti mú àpèjúwe náà jáde, kó o sì wo bí wọ́n ṣe mú kí kókó ọ̀rọ̀ ṣe kedere?
• Bíi tàwọn kan tí ń kọrin tó dùn yùngbà-yungba àtàwọn ọkùnrin méjì tí ń já páálí ọjà tó wúwo látinú ọkọ̀ ńlá kan, àwọn tó ń fẹ́ kí ìgbéyàwó wọn yọrí sí rere nílò ọkọ rere àti aya rere.—Ilé Ìṣọ́, May 15, 2001, ojú ìwé 16.
• Ńṣe ni sísọ bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára rẹ dà bí ìgbà téèyàn bá ń ju bọ́ọ̀lù sí ẹlòmíràn. O lè rọra jù ú tàbí kó o fipá jù ú tó bẹ́ẹ̀ tá á fi pa ẹnì kejì lára.—Jí!, January 8, 2001, ojú ìwé 10.
• Kíkọ́ béèyàn ṣe ń fìfẹ́ hàn dà bí ìgbà téèyàn ń kọ́ èdè tuntun kan.—Ilé Ìṣọ́, February 15, 1999, ojú ìwé 18, 22-23.
• Ohun táwọn ọdẹ ń fi ìdẹ ṣe náà làwọn ẹ̀mí èṣù ń fi ìbẹ́mìílò ṣe: Ìbẹ́mìílò ń jẹ́ kéèyàn kó sínú pàkúté ẹ̀mí èṣù.—Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun, ojú ìwé 111.
• Gbígbà tí Jésù wá gba àwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù sílẹ̀ dà bí ẹlẹ́yinjú àánú kan tó lówó bíi ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀. Ó wá san gbogbo gbèsè tí ilé iṣẹ́ kan jẹ (alábòójútó ilé iṣẹ́ náà tẹ́lẹ̀ tó jẹ́ onímàkàrúrù ló fa gbèsè náà), tó sì ṣí ilé iṣẹ́ náà padà. Ọ̀pọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ ilé iṣẹ́ yìí ló sì jàǹfààní ohun tí ọkùnrin náà ṣe.—Ilé Ìṣọ́nà, February 15, 1991, ojú ìwé 13.
• Gẹ́gẹ́ bí àwọn tó fẹ́ràn iṣẹ́ ọnà ṣe máa sapá lákànṣe láti tún iṣẹ́ ọ̀nà kan tó bà jẹ́ gan-an ṣe, bẹ́ẹ̀ náà ni Jèhófà ṣe ń gbójú fo àwọn àléébù wa, ó ń rí dáadáa tá à ń ṣe, tó bá sì yá, ó máa fún wa ní ìjẹ́pípé tí Ádámù sọ nù.—Ilé Ìṣọ́nà, February 15, 1990, ojú ìwé 22.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Àwọn Kristẹni tòótọ́ ń kọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Àwọn alàgbà lè fi ìbéèrè ran onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn lọ́wọ́ láti rí ìtùnú nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run