“Mi Ò Ní Yí Ohunkóhun Padà!”
Ìtàn Ìgbésí Ayé
“Mi Ò Ní Yí Ohunkóhun Padà!”
GẸ́GẸ́ BÍ GLADYS ALLEN ṢE SỌ Ọ́
Wọ́n máa ń bi mí nígbà míì pé, “Ká ló o tún fẹ́ padà lo ìgbésí ayé rẹ lẹ́ẹ̀kan sí i, kí lo máa yí padà?” Mo lè fi tòótọ́tòótọ́ dáhùn pé, “Mi ò ní yí ohunkóhun padà!” Ẹ jẹ́ kí n ṣàlàyé ìdí tí mo fi sọ bẹ́ẹ̀.
OHUN àgbàyanu kan ṣẹlẹ̀ sí bàbá mi tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Matthew Allen nígbà ẹ̀ẹ̀rùn ọdún 1929 tí mo wà lọ́mọ ọdún méjì. Ó gba ìwé kékeré náà, Àràádọ́ta Ọ̀kẹ́ Tó Wà Láàyè Nísinsìnyí Kò Ní Kú Láé!, tí àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Kárí Ayé, ìyẹn orúkọ tí wọ́n ń pe àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà yẹn, tẹ̀ jáde lédè Gẹ̀ẹ́sì. Lẹ́yìn tí Dádì ka ojú ìwé bíi mélòó kan níbẹ̀, ńṣe ló figbe ta, tó sọ pé, “Mi ò ka nǹkan tó dáa tó báyìí rí o!”
Kété lẹ́yìn ìyẹn ni Dádì gba àwọn ìtẹ̀jáde mìíràn lọ́wọ́ àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà. Kíá ló bẹ̀rẹ̀ sí sọ àwọn nǹkan tó ń kọ́ fún gbogbo àwọn aládùúgbò rẹ̀. Àmọ́ kò sí ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lábúlé wa. Nígbà tí Dádì wá rí i pé o di dandan ká máa bá àwọn Kristẹni pé jọ pọ̀ déédéé, ó kó ìdílé wa lọ sí ìlú Orangeville, ní Ontario, Kánádà, lọ́dún 1935 nítorí pé ìjọ kan wà níbẹ̀.
Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, wọn kì í sábà jẹ́ káwọn ọmọdé wá sáwọn ìpàdé ìjọ; ìta ni wọ́n sábà máa ń wà tí wọ́n á máa ṣeré títí dìgbà táwọn àgbà fi máa parí ìpàdé. Èyí ò dùn mọ́ Dádì nínú rárá. Ó ronú pé, “Táwọn ìpàdé náà bá ń ṣe mí láǹfààní, a jẹ́ pé wọ́n lè ṣe àwọn ọmọ mi náà láǹfààní nìyẹn.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Dádì ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí dara pọ̀ mọ́ wọn ni, síbẹ̀ ó ní kí èmi àti Bob, ìyẹn ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin, àti Ella òun Ruby tí wọ́n jẹ́ ẹ̀gbọ́n mi obìnrin máa dara pọ̀ mọ́ àwọn àgbà láwọn ìpàdé wọ̀nyẹn, a sì ṣe bẹ́ẹ̀. Láìpẹ́ àwọn ọmọ àwọn Ẹlẹ́rìí yòókù náà bẹ̀rẹ̀ sí
wá sípàdé. Lílọ sípàdé àti dídáhùn wá di apá pàtàkì nínú ìgbésí ayé wa.Dádì fẹ́ràn Bíbélì gan-an ni, ó si ní ọ̀nà kan tó gbádùn mọ́ni tó máa ń gbà fara ṣàpèjúwe àwọn ìtàn inú Bíbélì. Àwọn ọ̀nà wọ̀nyí ló gbà gbin àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì sọ́kàn wa pẹ̀lú bá a ṣe jẹ́ ọmọdé tó nígbà yẹn lọ́hùn-ún. Ó ṣì máa ń múnú mi dùn nígbà tí mo bá rántí ìgbà yẹn. Èyí tí mo máa ń rántí jù ni pé Jèhófà ń bù kún àwọn tó bá ṣègbọràn sí i.
Dádì tún kọ́ wa bí a ó ṣe máa fi Bíbélì gbèjà ìgbàgbọ́ wa. A máa ń fìyẹn ṣeré àṣedárayá. Dádì lè sọ pé, “Mo gbà gbọ́ pé ọ̀run ni mò ń lọ nígbà tí mo bá kú. Ó yá ẹ wá ṣàlàyé fún mi pé ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀.” Èmi àti Ruby á wá bẹ̀rẹ̀ sí ṣèwádìí nínú ìwé atọ́ka ká lè rí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a lè lò láti já ẹ̀kọ́ yẹn ní koro. Lẹ́yìn tá a bá ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a rí tán, Dádì á wá sọ pé, “Ìyẹn dáa gan-an, ṣùgbọ́n mi ò tíì gba ohun tẹ́ ẹ sọ.” Àá tún padà sínú ìwé atọ́ka náà láti ṣèwádìí síwájú sí i. Èyí sábà máa ń gba ọ̀pọ̀ wákàtí kí Dádì tó sọ pé ìdáhùn wa ti tẹ́ òun lọ́rùn. Nítorí ìdí èyí, èmi àti Ruby wá dẹni tó gbára dì dáadáa láti ṣàlàyé ìgbàgbọ́ wa ká sì gbèjà ẹ̀sìn wa.
Mo Ṣẹ́pá Ìbẹ̀rù Ènìyàn
Pẹ̀lú gbogbo ẹ̀kọ́ tí mo gbà nílé àti láwọn ìpàdé ìjọ, mo gbọ́dọ̀ jẹ́wọ́ pé àwọn apá kan wà tó ṣòro fún mi gan-an nínú àwọn ìgbòkègbodò Kristẹni. Gẹ́gẹ́ bó ṣe máa ń rí lára ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́, kì í wu èmi náà kí n dá yàtọ̀ sáwọn ẹlòmíràn, àgàgà sí àwọn ọmọ kíláàsì mi. Ìdánwò ìgbàgbọ́ tí mo kọ́kọ́ dojú kọ ni èyí tó ní í ṣe pẹ̀lú ohun tá a máa ń pè ní gbígbé ìsọfúnni káàkiri ìgboro.
Ohun tá à ń pè bẹ́ẹ̀ ni pé kí àwùjọ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin kan rọra máa rìn gba òpópó ńláńlá tó wà láàárín ìlú kọjá, kí wọ́n sì gbé àwọn pátákó tá a kọ nǹkan sí lọ́wọ́. Gbogbo àwa ẹgbẹ̀ẹ́dógún [3,000] èèyàn tá a wà nílùú wa la sì mọ ara wa bí ẹní mowó. Nígbà kan tá à ń gbé ìsọfúnni kiri ìgboro, èmi ni mo wà lẹ́yìn pátápátá lórí ìlà tá a tò sí, tí mo gbé pátákò tá a kọ “Ìsìn Jẹ́ Ìdẹkùn àti Wàyó” sí. Àwọn kan lára àwọn ọmọ tá a jọ wà ní kíláàsì kan náà rí mi, ojú ẹsẹ̀ ni wọ́n tò tẹ̀ lé mi lẹ́yìn, tí wọ́n ń kọrin “God Save the King,” ìyẹn orin orílẹ̀-èdè, tẹ̀ lé mi lẹ́yìn. Kí ni mo wá ṣe? Mo fi tìtaratìtara gbàdúrà pé kí n lè ní okun láti máa bá iṣẹ́ náà lọ. Nígbà tá a ṣe tán, eré ni mo sá dé Gbọ̀ngàn Ìjọba pé kí n gbé pátákó ọwọ́ mi sílẹ̀ kí n sì padà sílé. Àmọ́ ẹni tó ń ṣe kòkáárí ètò náà sọ fún mi pé àkókò ti fẹ́ tó láti gbé ìsọfúnni mìíràn kiri àti pé ẹnì kan ṣoṣo ló kù táwọn ń wá láti gbé pátákó kan. Bí mo tún ṣe báwọn jáde nìyẹn o, tí mò ń fi tìtaratìtara gbàdúrà ju ti ìgbàkigbà rí lọ. Àmọ́ ó ti rẹ àwọn ọmọ kíláàsì mi lọ́tẹ̀ yìí wọ́n sì ti lọ sílé wọn. Bí àdúrà tí mo gbà pé kí n lè ní okun ṣe wá di àdúrà ìdúpẹ́ nìyẹn o!—Òwe 3:5.
Gbogbo ìgbà la máa ń gba àwọn ìránṣẹ́ alákòókò kíkún lálejò nílé wa. Àwọn èèyàn tó máa ń láyọ̀ ni wọ́n, inú èèyàn sì máa ń dùn láti ṣe wọ́n lálejò. Àtìgbà tí mo ti wà lọ́mọdé làwọn òbí wa ti máa ń sọ fún àwa ọmọ pé iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún ni iṣẹ́ tó dára jù lọ téèyàn lè ṣe.
Nítorí ìṣírí tí wọ́n fún wa, mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún lọ́dún 1945. Ìgbà tó yá ni mo lọ ba Ella ẹ̀gbọ́n mi obìnrin tó ń ṣíṣẹ aṣáájú ọ̀nà ní London, Ontario. Ibẹ̀ ni wọ́n ti fojú mi mọ apá fífanimọ́ra kan nínú iṣẹ́ ìsìn, èyí tí mo ronú tẹ́lẹ̀ pé mi ò ní lè ṣe láé. Àwọn arákùnrin máa
ń lọ láti tábìlì kan dé ìkejì láwọn ilé ọtí, tí wọ́n á máa pín àwọn ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ àti Consolation (tá à ń pè ní Jí! báyìí) fáwọn tó wá mutí. Ohun tó fi dára ni pé ọ̀sán ọjọ́ Sátidé ni wọ́n máa ń ṣe iṣẹ́ náà, ìyẹn jẹ́ kí n ráyè fi gbogbo ọ̀sẹ̀ gbàdúrà pé kí n lè ní okun láti lọ! Ká sọ tòótọ́, iṣẹ́ náà ò rọrùn fún mi rárá, àmọ́ ó lérè.Yàtọ̀ síyẹn, mo tún kọ́ bá a ṣe ń fúnni láwọn ẹ̀dà Consolation tó jẹ́ àkànṣe. Ìyẹn àwọn tó ń sọ nípa inúnibíni tí wọ́n ń ṣe sáwọn arákùnrin wa ní ọgbà ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ìjọba Násì. Àgàgà kí n máa mú wọn lọ sọ́dọ̀ àwọn oníṣòwò jàǹkànjàǹkàn ní Kánádà, títí kan àwọn ọ̀gá àgbà àwọn ilé iṣẹ́ ńláńlá. Láti àwọn ọdún wọ̀nyí wá ni mo ti rí i pé Jèhófà máa ń tì wá lẹ́yìn tá a bá ṣáà ti lè gbẹ́kẹ̀ lé e fún okun. Bí Dádì ṣe máa ń sọ ọ́ náà ló rí, pé Jèhófà máa ń bù kún àwọn tó bá ṣègbọràn sí I.
Mo Tẹ́wọ́ Gba Ìkésíni Láti Sìn Nílẹ̀ Quebec
July 4, 1940 ni wọ́n gbẹ́sẹ̀ lé iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Kánádà. Níkẹyìn, wọ́n mú ìfòfindè náà kúrò, àmọ́ wọ́n ṣì ń ṣe inúnibíni sí wa ni ìpínlẹ̀ Quebec táwọn Kátólíìkì wà. A fẹ́ ṣe ìkéde àrà ọ̀tọ̀ kan láti pe àfiyèsí àwọn èèyàn sí ìyà ti wọ́n fi ń jẹ àwọn arákùnrin wa níbẹ̀. Ìwé àṣàrò kúkúrú tọ́rọ̀ inú rẹ̀ tó lágbára gan-an kà pé, Quebec’s Burning Hate for God and Christ and Freedom Is the Shame of All Canada, la fẹ́ fi ṣe ìkéde náà. Nathan H. Knorr, tó jẹ́ ara Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn aṣáájú ọ̀nà tó wà nílùú Montreal ṣèpàdé láti jẹ́ kí wọ́n mọ ewu tó wà nínú ìgbésẹ̀ tí wọ́n fẹ́ gbé yẹn. Arákùnrin Knorr sọ fún wa pé bí a bá gbà láti ṣe irú ìkéde bẹ́ẹ̀, ká máa retí pé wọ́n lè mú wa kí wọ́n sì jù wá sẹ́wọ̀n. Ohun tó sì ṣẹlẹ̀ gẹ́lẹ́ nìyẹn! Ìgbà mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ni wọ́n mú mi láàárín sáà kan. Tá a bá ti ń lọ sóde ẹ̀rí, a máa ń rí i dájú pé a kó búrọ́ọ̀ṣì ìfọyín àti kóòmù ìyarun wa lọ́wọ́ tìtorí pé wọ́n lè mú wa kó sì jẹ́ pé ọgbà ẹ̀wọ̀n la máa sùn mọ́jú!
Alẹ́ la máa ń ṣe èyí tó pọ̀ jù lọ nínú iṣẹ́ náà káwọn èèyàn má bàá fojú sí wa lára. Mo máa ń kó àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú sínú àpò kan tí mo máa ń gbé sábẹ́ aṣọ àwọ̀lékè mi tí máa sì fi okùn rẹ̀ kọ́rùn. Àpò tí ìwé àṣàrò kúkúrú kún inú rẹ̀ yìí máa ń tóbi gan-an ni, ó sì máa ń jẹ́ kí n dà bí ẹni tó lóyún. Ìyẹn sì máa ń ṣe mí láǹfààní gan-an nígbà tí mo bá dénú ọkọ̀ tó kún bámúbámú tó máa gbé mi dé ìpínlẹ̀ tá a ti fẹ́ ṣiṣẹ́. Ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn ọkùnrin máa ń dìde tí wọ́n á sọ pé kí obìnrin “aboyún” yìí wá jókòó sáyè àwọn.
Bí àkókò ti ń lọ a bẹ̀rẹ̀ sí pín àwọn ìwé náà kiri lójú mọmọ. A máa ń pín ìwé àṣàrò kúkúrú náà láwọn ilé bíi mẹ́ta tàbí mẹ́rin, a ó sì kọrí sí ìpínlẹ̀ mìíràn. Ìyẹn sì gbéṣẹ́ gan-an. Àmọ́, bí àlùfáà kan bá ti lè mọ̀ pé a wà ládùúgbò yẹn, ká máa retí pé wàhálà lè ṣẹlẹ̀. Ìgbà kan wà tí àlùfáà kan ní kí nǹkan bí àádọ́ta tàbí ọgọ́ta àwọn jàǹdùkú àgbà àtọmọdé máa ju tòmátì àti ẹyin lù wá. Ilé Kristẹni arábìnrin kan la sá wọ̀, ibẹ̀ la sì ti lo gbogbo òru ọjọ́ yẹn tá a sùn sílẹ̀ẹ́lẹ̀.
A nílò àwọn aṣáájú ọ̀nà láti wàásù fáwọn èèyàn tó ń sọ èdè Faransé nílẹ̀ Quebec, ìdí nìyẹn tí èmi àti Ruby ẹ̀gbọ́n mi fi bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ èdè Faransé ní December 1958. Ẹ̀yìn ìyẹn ni wọ́n yàn wá sáwọn àgbègbè bíi mélòó kan tí wọ́n ti ń sọ èdè Faransé ní ẹkùn ìpínlẹ̀ náà. Ìrírí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ la ní ní gbogbo ibi tí wọ́n yàn wá sí. Ibì kan wà tó jẹ́ pé wákàtí mẹ́jọ la fi ń lọ láti ilé dé ilé lójoojúmọ́ fún odindi ọdún méjì gbáko láìsí ẹnì kankan tó dá wa lóhùn! Ńṣe làwọn èèyàn náà máa ń yọjú wò wá tí wọ́n á sì fá aṣọ tí wọ́n ta síbi ilẹ̀kùn wọn bò ó dáadáa. Àmọ́ a ò juwọ́ sílẹ̀. Àwọn ìjọ méjì tó ń gbèrú dáadáa ló wà nílùú yẹn báyìí.
Jèhófà Mẹ́sẹ̀ Wa Dúró ní Gbogbo Ọ̀nà
Ọdún 1965 la bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe. Ibi kan tí wọ́n yàn wá sí gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe la ti wá lóye ìjẹ́pàtàkì ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù tó wà nínú 1 Tímótì 6:8 pé: “Bí a bá ti ní ohun ìgbẹ́mìíró àti aṣọ, àwa yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú nǹkan wọ̀nyí.” A ní láti ṣọ́ owó ná gan-an ká lè gbọ́ bùkátà ara wa. Nítorí náà, a máa ń pín owó wa sọ́nà bíi mélòó kan, ìyẹn owó ohun èlò imúlé-móoru, owó ilé, owó iná mànàmáná, àti owó oúnjẹ. Lẹ́yìn tá a bá ṣèyẹn tán, owó táṣẹ́rẹ́ ló máa ń ṣẹ́ kù fún wa láti lò títí di ìparí oṣù náà.
Sáàmù 37:25 tó sọ pé: “Èmi kò tíì rí i kí a fi olódodo sílẹ̀ pátápátá, tàbí kí ọmọ rẹ̀ máa wá oúnjẹ kiri”!
Nítorí pé owó tá a ní ò pọ̀, ìwọ̀nba owó tá a ní ò ju èyí tá a fi lè lo ohun èèlò tó ń múlé móoru fún wákàtí bíi mélòó kan péré lóru. Nítorí náà, yàrá tá à ń sùn máa ń tutù gan-an. Tóò, ọmọ ọ̀kan nínú àwọn tí Ruby ń bá ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bẹ̀ wá wò lọ́jọ́ kan. Ó ti ní láti lọ sọ fún màmá rẹ̀ nílé pé òtútù ti fẹ́rẹ̀ẹ́ gbẹ̀mí wa, nítorí kò pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn tí màmá rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí fi dọ́là mẹ́wàá ránṣẹ́ sí wa lóṣooṣù pé ká máa fi ra epo ká lè máa tan ohun èlò ìmúlé-móoru wa sílẹ̀ ní gbogbo ìgbà. Ohunkóhun ò jẹ wá níyà mọ́. A ò lówó rẹpẹtẹ o, àmọ́ gbogbo ohun tó jẹ́ kòṣeémánìí ò wọ́n wa. A gbà pé ìbùkún ni ohunkóhun tó bá ṣẹ́ kù jẹ́. Ẹ ò rí i pé òótọ́ pọ́ńbélé lọ̀rọ̀ inúPẹ̀lú gbogbo àtakò tá a dojú kọ, inú mi dùn láti rí i pé àwọn bíi mélòó kan lára àwọn tí mo bá ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wá dẹni tó ní ìmọ̀ òtítọ́. Àwọn kan nínú wọn fi iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún ṣe iṣẹ́ ìgbésí ayé wọn, ìyẹn sì fún mi ní ayọ̀ tó ṣàrà ọ̀tọ̀.
Kíkojú Àwọn Ìṣòro Tó Yọjú
Cornwall, Ontario, ni ibi tuntun tí wọ́n yàn wá sí lọ́dún 1970. Nǹkan bí ọdún kan lẹ́yìn tá a dé sí Cornwall ni Mọ́mì dùbúlẹ̀ àìsàn. Dádì ti kú ní 1957, èmi àtàwọn ẹ̀gbọ́n mi méjèèjì wá bẹ̀rẹ̀ sí fi títọ́jú Mọ́mì ṣe àgbégbà títí tó fi kú ní 1972. Ella Lisitza àti Ann Kowalenko tá a jọ ń ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe dúró tì wá gbágbáágbá, wọ́n sì fún wa ní ìtìlẹ́yìn onífẹ̀ẹ́ lákòókò yìí. Wọ́n bá wa bójú tó àwọn tá a máa ń bá ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti àwọn ẹrù iṣẹ́ mìíràn láàárín àkókò tá a ò fi sí níbẹ̀. Òótọ́ pọ́ńbélé lọ̀rọ̀ inú Òwe 18:24 tó sọ pé: “Ọ̀rẹ́ kan wà tí ń fà mọ́ni tímọ́tímọ́ ju arákùnrin lọ”!
Ká sọ tòótọ́, ìgbésí ayé kún fún àwọn àdánwò líle koko. Pẹ̀lú ìtìlẹ́yìn onífẹ̀ẹ́ látọ̀dọ̀ Jèhófà, ó ti ṣeé ṣe fún mi láti kojú wọn. Mo ṣì ń fi tayọ̀tayọ̀ bá ìgbésí ayé iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún nìṣó. Bob, tó kú ní 1993, lo ohun tó lé lógún ọdún lẹ́nu iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà, ọdún mẹ́wàá alárinrin tí òun àti Doll, aya rẹ̀ fi jọ ṣiṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà pà pọ̀ sì wà lára àwọn ọdún wọ̀nyí. Ella, ẹ̀gbọ́n mi obìnrin tó kú ní October 1998, ṣe aṣáájú ọ̀nà fún ohun tó lé ní ọgbọ̀n ọdún, kò sì fìgbà kan ṣàìní ẹ̀mí aṣáájú ọ̀nà. Wọ́n ṣàyẹ̀wò ara Ruby, ẹ̀gbọ́n mi obìnrin
kan tó kù ní 1991, wọ́n sì rí i pé ó ní àrùn jẹjẹrẹ. Síbẹ̀, ó lo ìwọ̀nba okun tó ní láti wàásù ìhìn rere náà. Ńṣe ló ń báwọn èèyàn ṣàwàdà títí tó fi kú ní àárọ̀ September 26, 1999. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀gbọ́n mi obìnrin ti kú, síbẹ̀ mo ní ìdílé kan tó jẹ́ ti àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin mi nípa tẹ̀mí tí wọ́n ń jẹ́ kí n rẹ́ni bá ṣàwàdà.Nígbà tí mo bá wo bí mo ṣe lo ìgbésí ayé mi, kí ni kí n yí padà? Mi ò lọ́kọ rí, àmọ́ mo láwọn òbí tó nífẹ̀ẹ́, mo ní ẹ̀gbọ́n ọkùnrin kan, àtàwọn ẹ̀gbọ́n obìnrin tí wọ́n fi òtítọ́ sípò kìíní nínú ìgbésí ayé wọn. Mò ń wọ̀nà láti rí wọn láìpẹ́ nígbà àjíǹde. Mo tiẹ̀ ti ń fojú inú wo dádì mi tó ń gbá mi mọ́ra àti bí mọ́mì mi ṣe ń sun ẹkún ayọ̀ níbi tá a ti ń dì mọ́ra wa gbàgì. Ella, Ruby, àti Bob náà a máa fò sókè tìdùnnú-tìdùnnú.
Ní báyìí ná, gbogbo ohun tó wà lọ́kàn mi ni pé kí n máa bá a nìṣó ní fífi ìlera àti agbára tó kù fún mi yin Jèhófà, kí n sì máa bọlá fún un. Iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà alákòókò kíkún jẹ́ ọ̀nà ìgbésí ayé alárinrin, tó sì lérè nínú. Kódà, ńṣe ló dà bí ohun tí onísáàmù sọ nípa àwọn tó ń rìn ní ọ̀nà Jèhófà pé: “Aláyọ̀ ni ìwọ yóò jẹ́, yóò sì dára fún ọ.”—Sáàmù 128:1, 2.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Dádì fẹ́ràn Bíbélì. Ó kọ́ wa bá a ó ṣe lò ó láti gbèjà ìgbàgbọ́ wa
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Láti apá òsì sí apá ọ̀tún: Ruby, èmi, Bob, Ella, Mọ́mì, àti Dádì ní 1947
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Ní ìlà iwájú; láti ọwọ́ òsì sí ọwọ́ ọ̀tún: Èmi, Ruby, àti Ella ní àpéjọ àgbègbè, 1998