Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ohun Iyebíye Làwọn Aládùúgbò Rere Jẹ́

Ohun Iyebíye Làwọn Aládùúgbò Rere Jẹ́

Ohun Iyebíye Làwọn Aládùúgbò Rere Jẹ́

“Aládùúgbò tí ó wà nítòsí sàn ju arákùnrin tí ó jìnnà réré.”—Òwe 27:10.

Ọ̀MỌ̀WÉ kan tó kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ ní ọ̀rúndún kìíní béèrè lọ́wọ́ Jésù pé: “Ní ti gidi ta ni aládùúgbò mi?” Nígbà tí Jésù fèsì, kò wulẹ̀ sọ ẹni tó jẹ́ aládùúgbò rẹ̀ fún un, bí kò ṣe ohun tí jíjẹ́ ojúlówó aládùúgbò túmọ̀ sí. Ó ṣeé ṣe kó o mọ àkàwé Jésù yẹn dáadáa. Ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ ọ́n sí ni ìtàn aláàánú ará Samáríà, àkọsílẹ̀ rẹ̀ sì wà nínú ìwé Ìhìn Rere Lúùkù. Bí Jésù ṣe sọ ìtàn náà nìyí.

“Ọkùnrin kan ń sọ̀ kalẹ̀ láti Jerúsálẹ́mù lọ sí Jẹ́ríkò, ó sì bọ́ sí àárín àwọn ọlọ́ṣà, àwọn tí wọ́n bọ́ ọ láṣọ, tí wọ́n sì lù ú, wọ́n sì lọ, ní fífi í sílẹ̀ láìkú tán. Wàyí o, ní ìṣekòńgẹ́, àlùfáà kan ń sọ̀ kalẹ̀ lọ ní ojú ọ̀nà yẹn, ṣùgbọ́n, nígbà tí ó rí i, ó gba ẹ̀gbẹ́ òdì-kejì kọjá lọ. Bákan náà, ọmọ Léfì kan pẹ̀lú, nígbà tí ó sọ̀ kalẹ̀ dé ibẹ̀, tí ó sì rí i, ó gba ẹ̀gbẹ́ òdì-kejì kọjá lọ. Ṣùgbọ́n ará Samáríà kan tí ó ń rin ìrìn àjò gba ojú ọ̀nà náà ṣàdédé bá a pàdé, bí ó sì ti rí i, àánú ṣe é. Nítorí náà, ó sún mọ́ ọn, ó sì di àwọn ọgbẹ́ rẹ̀, ó da òróró àti wáìnì sórí wọn. Lẹ́yìn náà, ó gbé e gun orí ẹranko tirẹ̀, ó sì gbé e wá sí ilé èrò kan, ó sì tọ́jú rẹ̀. Ó sì mú owó dínárì méjì jáde ní ọjọ́ kejì, ó fi fún olùtọ́jú ilé èrò náà, ó sì wí pé, ‘Tọ́jú rẹ̀, ohun yòówù tí ìwọ bá sì ná ní àfikún sí èyí, èmi yóò san án padà fún ọ nígbà tí mo bá padà wá síhìn-ín.’ Lójú tìrẹ, ta ni nínú àwọn mẹ́ta wọ̀nyí ni ó ṣe ara rẹ̀ ní aládùúgbò fún ọkùnrin tí ó bọ́ sí àárín àwọn ọlọ́ṣà?”—Lúùkù 10:29-36.

Ó dájú pé òye ọ̀rọ̀ náà yé ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ náà. Láìlọ́ tìkọ̀, ó sọ ẹni tó jẹ́ aládùúgbò ọkùnrin tó fara pa náà, ó ní: “Ẹni tí ó hùwà sí i tàánú-tàánú.” Jésù wá sọ fún un pé: “Máa bá ọ̀nà rẹ lọ, kí ìwọ alára sì máa ṣe bákan náà.” (Lúùkù 10:37) Àpèjúwe tó fa kíki gan-an mà lèyí o, nípa ohun tó túmọ̀ sí láti jẹ́ ojúlówó aládùúgbò! Òwe Jésù yìí tún lè mú ká bi ara wa pé: ‘Irú aládùúgbò wo ni mo jẹ́? Ṣé irú ẹ̀yà tí mo jẹ́ tàbí orílẹ̀-èdè tí mo ti wá ń nípa lórí bí mo ṣe ń pinnu àwọn tó jẹ́ aládùúgbò mi? Ǹjẹ́ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ń dín ìrànlọ́wọ́ tó yẹ kí n ṣe fún ẹnikẹ́ni tí mo bá rí nínú ìṣòro kù? Ǹjẹ́ mo máa ń sapá gidigidi láti jẹ́ aládùúgbò rere?’

Ibo Ni Ká Ti Bẹ̀rẹ̀?

Tá a bá rí i pé ó yẹ ká túbọ̀ ṣe ju bá a tí ń ṣe tẹ́lẹ̀ lórí ọ̀ràn yìí, ó yẹ ká bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú èrò inú wa. Ohun tó gbọ́dọ̀ jẹ́ olórí àníyàn wa ni bá a ṣe máa jẹ́ aládùúgbò rere. Èyí sì lè jẹ́ kí a ní àwọn aládùúgbò rere. Ní nǹkan bí ẹgbàá ọdún sẹ́yìn, Jésù tẹnu mọ́ ìlànà pàtàkì nípa àjọṣe ẹ̀dá nínú Ìwàásù rẹ̀ olókìkí Lórí Òkè. Ó ní: “Nítorí náà, gbogbo ohun tí ẹ bá fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín, kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sí wọn.” (Mátíù 7:12) Fífi ọ̀wọ̀ àwọn èèyàn wọ̀ wọ́n, bíbuyì fún wọn àti fífi inúure hàn sí wọn lè fún àwọn náà níṣìírí láti ṣe bákan náà sí ọ.

Lise Funderburg, tó jẹ́ oníròyìn àti òǹkọ̀wé, mẹ́nu ba àwọn nǹkan kéékèèké téèyàn lè ṣe láti jẹ́ aládùúgbò rere nínú àpilẹ̀kọ tó pè ní “Nínífẹ̀ẹ́ Aládùúgbò Rẹ,” èyí tó máa ń kọ sínú ìwé ìròyìn The Nation Since 1865. Ó kọ ọ́ pé: “Mo fẹ́ . . . kí àwọn kókó pàtàkì kan wà lára ẹgbàágbèje ọ̀nà táwọn aládùúgbò lè gbà fi inú rere hàn síra wọn—irú bíi bíbáni kó àwọn ìwé ìròyìn wọlé, bíbáni bójú tó àwọn ọmọ nígbà táwọn òbí kò bá sí nílé, lílọ báni ra nǹkan nílé ìtajà. Mo fẹ́ kí àjọṣe yìí wà nínú ayé kan táwọn èèyàn tí túbọ̀ ń sọra wọn dàjèjì sí ẹnì kejì wọn, níbi tí àwùjọ ẹ̀dá ti di èyí tí kò ní ìfọ̀kànbalẹ̀ mọ́ nítorí ìbẹ̀rù àti ìwà ọ̀daràn.” Obìnrin náà wá fi kún un pé: “O ní láti bẹ̀rẹ̀ níbì kan. Ó tiẹ̀ lè bẹ̀rẹ̀ lọ́dọ̀ ẹni tí yàrá rẹ̀ tẹ̀ lé tìrẹ pàápàá.”

Ìwé ìròyìn Canadian Geographic náà tún tọ́ka sí àwọn kókó pàtàkì kan tó lè ran àwọn aládùúgbò lọ́wọ́ láti ní ẹ̀mí tó dára sí ara wọn. Òǹkọ̀wé Marni Jackson sọ pé: “Bó ò ṣe lè yan ẹni tó máa jẹ́ òbí tàbí mọ̀lẹ́bí rẹ náà lo ò ṣe lè fúnra rẹ yan ẹni tó o fẹ́ kó jẹ́ aládùúgbò rẹ. Àjọṣe náà gba ọgbọ́n gidi àti kéèyàn lè mú nǹkan mọ́ra.”

Àwọn Aládùúgbò Rere —Máa Ń Jẹ́ Ọ̀làwọ́

Ká sọ tòótọ́, ó lè má rọrùn fún ọ̀pọ̀ lára wa láti tọ àwọn aládùúgbò wa lọ. Ó lè dà bíi pé ohun tó rọrùn jù lọ ni ká máà jẹ́ kí ohunkóhun da àwa àtàwọn ẹlòmíràn pọ̀ tàbí ká ya ara wa sọ́tọ̀ pátápátá. Àmọ́ Bíbélì sọ pé, “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.” (Ìṣe 20:35) Nítorí náà, aládùúgbò rere máa ń tiraka láti sa gbogbo ipá rẹ̀ kó lè sọ ara rẹ̀ di ojúlùmọ̀ àwọn tó wà láyìíká rẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè máà bá wọn ṣe ọ̀rẹ́ wọléwọ̀de, síbẹ̀ á sapá láti máa bá wọn sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ó lè fi ẹ̀rín múṣẹ́ tàbí jíju ọwọ́ sí wọn bẹ̀rẹ̀.

Gẹ́gẹ́ bí ohun tá a sọ ṣáájú, “ẹgbàágbèje àwọn ọ̀nà kéékèèké” táwọn aládùúgbò gbà “ń fi inú rere hàn” sí ara wọn ló ṣe pàtàkì jù lọ láti fìdí àjọṣe ọlọ́rẹ̀ẹ́sọ́rẹ̀ẹ́ múlẹ̀, kó sì máa bá a lọ bẹ́ẹ̀. Nítorí náà, ó yẹ kó o wá àwọn ọ̀nà kéékèèké tó o lè gbà fi inú rere hàn sí aládùúgbò rẹ, nítorí èyí sábà máa ń fi kún ẹ̀mí ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àti ọ̀wọ̀ fún tọ̀tún tòsì. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a óò máa tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì tó sọ pé: “Má fawọ́ ohun rere sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ ẹni tí ó yẹ kí o ṣe é fún, nígbà tí ó bá wà ní agbára ọwọ́ rẹ láti ṣe é.”—Òwe 3:27; Jákọ́bù 2:14-17.

Àwọn Aládùúgbò Rere —Máa Ń Moore

Ì bá dára ká sọ pé gbogbo èèyàn ló ń fi ẹ̀mí ìmoore gba ìrànwọ́ àtàwọn ẹ̀bùn tá a bá fún wọn. Ó dunni pé, èyí kì í sábà rí bẹ́ẹ̀. Ọ̀pọ̀ ìrànlọ́wọ́ téèyàn ti ṣe àti ọ̀pọ̀ ẹ̀bùn téèyàn ti fi tinútinú fúnni làwọn kan ti gbà lọ́nà tí kò fi ìmọrírì hàn rárá débi pé ẹni tó fi tinútinú ṣe irú oore bẹ́ẹ̀ lè ronú pé, ‘Mi ò tún ní ṣe irú oore bẹ́ẹ̀ mọ́ láé!’ Nígbà mìíràn, ó lè jẹ́ pé orí lásán ni aládùúgbò rẹ̀ máa rọra fi dáhùn gbogbo bó o ṣe ń fi tọ̀yàyàtọ̀yàyà kí i tó o sì ń juwọ́ sí i bí ọ̀rẹ́.

Àmọ́, ọ̀pọ̀ ìgbà ni kì í ṣe pé onítọ̀hún dìídì jẹ́ aláìmoore, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè dà bí aláìmoore lójú àwọn èèyàn. Ó lè jẹ́ pé bí wọ́n ṣe tọ́ ọ dàgbà ló sọ ọ́ di onítìjú, tíyẹn sì wá sọ ọ́ dẹni tó ń ṣe bíi pé kò ka èèyàn sí, tó wá dà bíi pé kò níwà bí ọ̀rẹ́. Yàtọ̀ síyẹn, nínú ayé aláìmoore yìí, àwọn kan lè máa wo ìwà bí ọ̀rẹ́ tó ò ń hù sí wọn bí ohun kan tó ṣàjèjì, tàbí kí wọ́n tiẹ̀ máa fura pé bóyá ó ní ètè búburú tó o fi ń ṣe bẹ́ẹ̀. Irú àwọn bẹ́ẹ̀ lè fẹ́ ká fi dá wọn lójú pé lóòótọ́ la fẹ́ràn wọn. Nítorí náà, mímú àjọṣe ọlọ́rẹ̀ẹ́sọ́rẹ̀ẹ́ dàgbà lè gba àkókò àti sùúrù. Bó ti wù kó rí, àwọn aládùúgbò tó jẹ́ ọ̀làwọ́ àtàwọn tó ń moore yóò ṣe ipa tiwọn láti sọ àdúgbò wọn di èyí tó dára tó ní àlàáfíà àti ayọ̀.

Nígbà Tí Ìjábá Bá Ṣẹlẹ̀

Ohun iyebíye gan-an ni aládùúgbò rere jẹ́ nígbà tí ìjábá bá ṣẹlẹ̀. Àkókò ìpọ́njú ni ojúlówó ẹ̀mí aládùúgbò máa ń hàn síta. Ọ̀pọ̀ ìròyìn la ti gbọ́ nípa bí àwọn aládùúgbò ṣe fi ẹ̀mí àìmọtara ẹni hàn nírú àkókò bẹ́ẹ̀. Ó dà bíi pé àwọn ọ̀ràn ìbìnújẹ́ tó ń ṣẹlẹ̀ máa ń mú káwọn aládùúgbò fi tọkàntọkàn ṣe nǹkan pọ̀, kí wọ́n si lo gbogbo okun wọn láti ran ẹnì kejì wọn lọ́wọ́. Kódà àwọn tójú ìwòye wọn ò bára mu pàápàá máa ń ṣe nǹkan pọ̀ lákòókò yẹn.

Bí àpẹẹrẹ, ìwé ìròyìn The New York Times ròyìn pé nígbà tí ìsẹ̀lẹ̀ runlérùnnà kan wáyé ní orílẹ̀-èdè Turkey lọ́dún 1999, àwọn tó ti jẹ́ ọ̀tá wọn látayébáyé wá ṣaájò wọn. Akọ̀ròyìn Anna Stergiou, tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì kọ ọ́ sínú ìwé ìròyìn ilẹ̀ Áténì pé: “Ọjọ́ ti pẹ́ tí wọ́n ti kọ́ wa pé ká kórìíra àwọn ọmọ ilẹ̀ Turkey. Àmọ́ wàhálà ńlá tó dé bá wọn kò múnú wa dùn rárá. Ọkàn wa gbọgbẹ́, a sọkún kíkorò bí ẹni pé ìkórìíra tó wà láàárín àwa àtàwọn ti pòórá nígbà tá a rí òkú àwọn ọmọ kéékèèké.” Nígbà tí ìjọba sọ pé káwọn tó ń kó àwọn èèyàn jáde ṣíwọ́ iṣẹ́, àwọn tó jẹ́ Gíríìkì ò dáwọ́ dúró, ńṣe ni wọ́n ń báṣẹ́ lọ láti wá àwọn tí kò tíì kú rí.

Kíkópa nínú iṣẹ́ ìgbẹ̀mílà lẹ́yìn tí ìjábá bá ṣẹlẹ̀ jẹ́ ọ̀nà wíwúnilórí, tó sì fi ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ hàn fún aládùúgbò ẹni. Síbẹ̀, ó dájú pé kéèyàn gbẹ̀mí aládùúgbò rẹ̀ là nípa kíkìlọ̀ fún un ṣáájú jàǹbá kan la lè kà sí ẹ̀mí aládùúgbò rere tó níye lórí jù. Ó dunni pé, inú àwọn èèyàn kì í sábà dùn sáwọn tó máa ń kìlọ̀ fáwọn aládùúgbò wọn pé jàǹbá ń bọ̀, nítorí pé wọn ò tíì rí jàǹbá tí wọ́n sọ pé ó ń bọ̀ náà lákòókò tónítọ̀hún ń kìlọ̀ fún wọn. Àwọn èèyàn kì í sábà gba àwọn tó ń kìlọ̀ fún wọn gbọ́. Ẹnikẹ́ni tó bá ń gbìyànjú láti ṣèrànwọ́ fáwọn tí ò mọ̀ pé ipò táwọn wà kò láyọ̀lé gbọ́dọ̀ ní ọ̀pọ̀ ìforítì àti ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ.

Ohun Tó Dára Jù Lọ Téèyàn Lè Ṣe fún Aládùúgbò Rẹ̀

Lóde òní, ohun tó lágbára gan-an ju àjálù ń bọ̀ sórí ìran èèyàn. Ohun náà ni èyí tá a sọ tẹ́lẹ̀ pé Ọlọ́run Olódùmarè máa ṣe láti mú ìwà ọ̀daràn, ìwà ibi, àtàwọn ìṣòro mìíràn kúrò lórí ilẹ̀ ayé. (Ìṣípayá 16:16; 21:3, 4) Ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì yìí kì í ṣe ohun tá à ń ṣiyèméjì nípa rẹ̀ bí kò ṣe ohun tó dájú hán-únhán-ún! Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fẹ́ kí ọ̀pọ̀ èèyàn bó bá ṣe lè ṣeé ṣe tó ní ìmọ̀ tó ṣe pàtàkì láti la ìṣẹ̀lẹ̀ tí yóò mi ayé tìtì náà já. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi ń bá iṣẹ́ ìwàásù wọn tá a mọ̀ bí ẹni mowó lọ jákèjádò ayé. (Mátíù 24:14) Tinútinú ni wọ́n fi ń ṣe èyí, nítorí ìfẹ́ tí wọ́n ní fún Ọlọ́run àtàwọn aládùúgbò wọn.

Nítorí náà, má ṣe jẹ́ kí ẹ̀tanú tàbí ìbínú mú kí o kọ̀ láti fetí sílẹ̀ nígbà táwọn Ẹlẹ́rìí bá wá sílé rẹ tàbí nígbà tí wọ́n bá fẹ́ bá ọ sọ̀rọ̀ níbòmíràn. Ńṣe ni wọ́n ń gbìyànjú láti jẹ́ aládùúgbò rere. Nítorí náà, tẹ́wọ́ gba ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n sọ pé àwọn fẹ́ máa bá ọ ṣe. Kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe mú un dá wa lójú pé ọjọ́ ọ̀la kan táwọn aládùúgbò yóò máa fi tayọ̀tayọ̀ gbé pa pọ̀ ti sún mọ́lé. Ní àkókò yẹn, kó ní sí kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà, kò ní sí ìsìn tó yàtọ̀ síra, tàbí kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ tí yóò ba àjọṣe ọlọ́rẹ̀ẹ́sọ́rẹ̀ẹ́ tí ọ̀pọ̀ jù lọ wa fẹ́ látọkànwá jẹ́.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6, 7]

Ó dáa kó o fi inú rere hàn sí aládùúgbò rẹ

[Credit Line]

Àgbáyé: Mountain High Maps® Copyright © 1997 Digital Wisdom, Inc.