Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Èwe Tí Wọ́n Dà Bí Ìrì Tó Ń Tuni Lára

Àwọn Èwe Tí Wọ́n Dà Bí Ìrì Tó Ń Tuni Lára

“Ẹ Wá Sọ́dọ̀ Mi, . . . Èmi Yóò Sì Tù Yín Lára”

Àwọn Èwe Tí Wọ́n Dà Bí Ìrì Tó Ń Tuni Lára

Ó DÁJÚ pé àwọn tó kéré lọ́jọ́ orí lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù wà lára àwọn tó sọ fún pé: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, . . . èmi yóò sì tù yín lára.” (Mátíù 11:28) Nígbà táwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí mú àwọn ọmọ wọn kéékèèké wá sọ́dọ̀ rẹ̀, àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ fẹ́ dá wọn lẹ́kun. Àmọ́ Jésù sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọ kékeré wá sọ́dọ̀ mi; ẹ má gbìyànjú láti dá wọn lẹ́kun.” Jésù tiẹ̀ “gbé àwọn ọmọ náà sí apá rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí súre fún wọn.” (Máàkù 10:14-16) Kò sí iyèméjì pé Jésù ka àwọn èwe sí èèyàn tó ṣeyebíye.

Bíbélì sọ nípa àwọn ọkùnrin àti obìnrin, èwe àtàwọn ọmọdé, tí wọ́n fi àpẹẹrẹ tó dára lélẹ̀ nípa jíjọ́sìn Ọlọ́run. Ìwé Sáàmù sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ‘àwùjọ àwọn ọ̀dọ́’ tí wọ́n ń tuni lára bí ìrì tí ń sẹ̀. Ó tún mẹ́nu kan àwọn “ọ̀dọ́kùnrin” àtàwọn “wúńdíá” tí wọ́n ń yin orúkọ Jèhófà.—Sáàmù 110:3; 148:12, 13.

Ibi Táwọn Èwe Ti Lè Ṣe Dáadáa

Fífi tá a fi àwọn èwe wé ìrì bá a mu gan-an, nítorí pé a máa ń fi ìrì ṣàpèjúwe nǹkan tó pọ̀, a tún fi ń ṣàpèjúwe ìbùkún. (Jẹ́nẹ́sísì 27:28) Wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́ ni ìrì máa ń sẹ̀, ó sì ń mára tuni. Lákòókò wíwàníhìn-ín Jésù yìí, àwọn Kristẹni ọ̀dọ́ tí iye wọ́n pọ̀ gan-an ń fínnú-fíndọ̀ yọ̀ǹda ara wọn. Ọ̀pọ̀ èwe lọ́kùnrin lóbìnrin tí wọ́n dà bí ìrì tó ń tuni lára, ni wọ́n ń fi tayọ̀tayọ̀ jọ́sìn Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń ran olùjọsìn ẹlẹgbẹ́ wọn lọ́wọ́.—Sáàmù 71:17.

Kì í ṣe kìkì àwọn ẹlòmíràn làwọn èwe Kristẹni ń tù lára o; àwọn fúnra wọn ń rí ìtura nínú iṣẹ́ ìsìn wọn. Ètò àjọ Ọlọ́run fún wọn láǹfààní láti máa tẹ̀ síwájú. Ìwà rere táwọn èwe lọ́kùnrin lóbìnrin ń hù ló jẹ́ kí wọ́n ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run. (Sáàmù 119:9) Wọ́n tún ń lọ́wọ́ nínú àwọn ìgbòkègbodò tó gbámúṣé nínú ìjọ, wọ́n sì ní àwọn ọ̀rẹ́ rere, nǹkan wọ̀nyí ló ń mú kí ìgbésí ayé dùn kó sì nítumọ̀.

‘Amúniláradá àti Ìtura’

Ǹjẹ́ àwọn èwe Kristẹni pàápàá mọ̀ pé àwọn dà bí “ìrì tí ń sẹ̀”? Wo Tania, ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń lọ́wọ́ nínú ìgbòkègbodò inú ìjọ, tó sì tún ń lo ohun tó lé ní àádọ́rin wákàtí lóṣù nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Báwo ni gbogbo èyí ṣe rí lára rẹ̀? Ó sọ pé: “Ńṣe ló ń tù mí lára tó sì ń gbé mi ró. Wíwà tí mo wà pẹ̀lú Jèhófà àti ètò àjọ rẹ̀ dà bí ohun ‘amúniláradá àti ìtura’ fún mi.”—Òwe 3:8.

Ariel, tóun náà jẹ́ èwe òjíṣẹ́ alákòókò kíkún mọrírì okun tó ń rí gbà nínú ìjọ. Ó sọ pé: “Tí mo bá lọ sípàdé Kristẹni, tàbí àpéjọ àgbègbè àtàwọn àpéjọ mìíràn, tí mo sì jẹun lórí tábìlì tẹ̀mí Jèhófà, èyí máa ń fún mi ní ìtura nípa tẹ̀mí. Mímọ̀ tí mo mọ̀ pé mo láwọn alábàáṣiṣẹ́ kárí ayé máa ń mú ara mi yá gágá.” Nígbà tó ń sọ orísun ìtura tó ṣe pàtàkì jù lọ, ó sọ pé: “Ó máa ń tuni lára gan-an láti jẹ́ ọ̀rẹ́ Jèhófà, pàápàá jù lọ nígbà tí mo bá rí tàbí tí mo bá gbọ́ nípa ọṣẹ́ tí ètò nǹkan yìí ń ṣe fáwọn èèyàn.”—Jákọ́bù 2:23.

Ọmọ ogún ọdún ni Abishai, ajíhìnrere alákòókò kíkún ni, ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ sì tún ni nínú ìjọ. Ohun tó sọ nípa ara rẹ̀ rèé: “Ohun tó ń fún mi ní ìtura ni pé mo mọ bí mo ṣe lè kojú ọ̀pọ̀ ìṣòro táwọn èwe ń dojú kọ lónìí. Òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì ti ràn mí lọ́wọ́ láti gbájú mọ́ ohun tó yẹ kí n ṣe láti sin Jèhófà tọkàntọkàn.”

Antoine tètè máa ń bínú nígbà tó ṣẹ̀sẹ̀ di ọ̀dọ́langba. Ó tiẹ̀ wó àga mọ́ akẹ́kọ̀ọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ nígbà kan, ó sì fi pẹ́ńsù gún akẹ́kọ̀ọ́ mìíràn. Antoine kì í ṣe ẹni tó dùn bá rìn rárá o! Àmọ́ àwọn ìtọ́ni látinú Bíbélì yí ìwà rẹ̀ padà. Ó ti pé ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún báyìí, ó sì ti di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ àti òjíṣẹ́ alákòókò kíkún nínú ìjọ. Ó wá sọ pé: “Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó jẹ́ kí n ní ìmọ̀ rẹ̀, tó sì jẹ́ kí n mọ̀ pé ó yẹ kí n ní ẹ̀mí ìkóra-ẹni-níjàánu, kí n sì yí ìwà mi padà. Èyí ló kó mi yọ nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣòro.”

Àwọn èèyàn máa ń kíyè sí ìwà tó ń tuni lára táwọn Kristẹni ọ̀dọ́ ń hù. Ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí ni Matteo ní Ítálì. Olùkọ́ rẹ̀ ṣòfin pé ẹnikẹ́ni tó bá sọ ọ̀rọ̀ rírùn nínú kíláàsì máa sanwó ìtanràn táṣẹ́rẹ́. Nígbà tó yá, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ sọ pé kí olùkọ́ wọ́gi lé òfin yìí. Wọ́n ní ìdí ni pé “kò sí béèyàn ṣe lè ṣe é kó má sọ̀rọ̀ rírùn.” Matteo sọ pé: “Àmọ́ olùkọ́ wa sọ pé ọ̀ràn ò rí bẹ́ẹ̀ rárá, ó sì fi èmi tí mo jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣàpẹẹrẹ fún wọn. Ó gbóríyìn fún mi níwájú gbogbo àwọn ọmọ kíláàsì, nítorí pé n kì í sọ̀rọ̀ rírùn.”

Láàárín àwọn akẹ́kọ̀ọ́ oníjàgídíjàgan ní Thailand, olùkọ́ pe Racha ọmọ ọdún mọ́kànlá síwájú gbogbo àwọn ọmọ kíláàsì, ó sì gbóríyìn fún un nítorí ìwà rere rẹ̀. Olùkọ́ náà sọ pé: “Kí ló dé tí gbogbo yín ò tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀? Ó kọjú mọ́ ẹ̀kọ́ rẹ̀, ọmọ dáadáa sì ni.” Lẹ́yìn náà ló sọ fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà pé: “Á dáa kí gbogbo yín lọ di Ẹlẹ́rìí Jèhófà bíi ti Racha, kí ẹ lè máa hùwà ọmọlúwàbí.”

Ó máa ń múnú ẹni dùn láti rí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Kristẹni ọ̀dọ́ tí wọ́n túbọ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà tí wọ́n sì ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Ọ̀dọ̀ àwọn àgbà la ti sábàá ń rí irú ọgbọ́n táwọn ọ̀dọ́ rere yìí ní. Ọlọ́run lè mú kí ìgbésí ayé wọn ìsinsìnyí yọrí sí rere, kó sì fún wọn ní ọjọ́ iwájú ológo nínú ayé tuntun tó ń bọ̀. (1 Tímótì 4:8) Nínú ètò àwọn nǹkan yìí tó ti di aṣálẹ̀ nípa tẹ̀mí, àwọn èwe ò nítẹ̀ẹ́lọ́rùn, ayé sì ti sú wọn. Àmọ́ tàwọn èwe Kristẹni ò rí bẹ́ẹ̀ o, wọ́n ń tuni lára!