Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
• Ṣé Sátánì ni Bíbélì ń pè ní Lúsíférì?
Ẹ̀ẹ̀kan péré ni orúkọ náà Lúsíférì fara hàn nínú Ìwé Mímọ́, kì í sì í ṣe inú gbogbo ìtumọ̀ Bíbélì ló wà. Àpẹẹrẹ èyí tó wà rèé, Bibeli Mimọ tú Aísáyà 14:12, báyìí: “Bawo ni iwọ ti ṣe ṣubu lati ọrun wá, Iwọ Lusiferi, iràwọ owurọ!”
Ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n tú sí “Lúsíférì” túmọ̀ sí “ẹni tí ń tàn.” Ìtumọ̀ Septuagint lo ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà tó túmọ̀ sí “ẹni tó ń mú kí ọ̀yẹ̀ là.” Ìdí rèé tí ọ̀pọ̀ Bíbélì fi lo ọ̀rọ̀ Hébérù ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà “ìràwọ̀ òwúrọ̀” tàbí “Ìràwọ̀ Ojúmọ́.” Àmọ́, ẹ̀dà Vulgate tí Jerome fi èdè Látìn kọ, lo ọ̀rọ̀ náà “Lúsíférì” (olùtan ìmọ́lẹ̀), ìdí rèé tí ọ̀rọ̀ yìí fi fara hàn nínú oríṣiríṣi ìtumọ̀ Bíbélì.
Ta tiẹ̀ ni Lúsíférì yìí? Inú “ọ̀rọ̀ òwe . . . lòdì sí ọba Bábílónì” tí Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé káwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ la ti rí ọ̀rọ̀ náà “ẹni tí ń tàn,” tàbí “Lúsíférì.” Nítorí náà, ọ̀rọ̀ yìí wà lára àwọn ọ̀rọ̀ tá a sọ sí àwọn ọba Bábílónì. Gbólóhùn náà pé: “Ṣìọ́ọ̀lù ni a óò mú ọ sọ̀ kalẹ̀ wá,” ló jẹ́ ká túbọ̀ lóye pé ẹ̀dá èèyàn la lo èdè àpèjúwe náà “ẹni tí ń tàn” fún, kì í ṣe ẹ̀dá ẹ̀mí. Isà òkú aráyé ni Ṣìọ́ọ̀lù túmọ̀ sí, kì í ṣe ibi tí Sátánì Èṣù ń gbé. Síwájú sí i, ńṣe làwọn tó rí bá a ṣe ju Lúsíférì sínú isà òkú bẹ̀rẹ̀ sí béèrè pé: “Ṣé ọkùnrin yìí ni ó ń kó ṣìbáṣìbo bá ilẹ̀ ayé?” Èyí mú kó hàn gbangba pé ẹ̀dá èèyàn ni ẹni náà tí à ń pè ní “Lúsíférì,” kì í ṣe ẹ̀dá ẹ̀mí.—Aísáyà 14:4, 15, 16.
Kí nìdí tá a fi fún àwọn ọba Bábílónì ní orúkọ ńlá yìí? Ẹ jẹ́ ká fi sọ́kàn pé ẹ̀yìn ìgbà tí ọba Bábílónì di ẹdun arinlẹ̀ ni wọ́n pè é ní ẹni tí ń tàn, èyí sì jẹ́ láti fi í ṣẹ̀sín. (Aísáyà 14:3) Ìwà ìgbéraga ló mú káwọn ọba Bábílónì máa fẹlá lórí àwọn ọmọ abẹ́ wọn. Ìwà ìjọra-ẹni-lójú náà tiẹ̀ sún ọba Bábílónì débi fífọ́nnu pé: “Ọ̀run ni èmi yóò gòkè lọ. Òkè àwọn ìràwọ̀ Ọlọ́run ni èmi yóò gbé ìtẹ́ mi sí, èmi yóò sì jókòó sórí òkè ńlá ìpàdé, ní àwọn apá jíjìnnàréré jù lọ ní àríwá. . . . Èmi yóò mú ara mi jọ Ẹni Gíga Jù Lọ.”—Aísáyà 14:13, 14.
Àwọn ọba tó wá láti ìlà ìdílé Dáfídì là ń pè ní “ìràwọ̀ Ọlọ́run.” (Númérì 24:17) Bẹ̀rẹ̀ látorí Dáfídì làwọn “ìràwọ̀” yìí ti ń ṣàkóso láti Òkè Síónì. Lẹ́yìn tí Sólómọ́nì kọ́ tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù la bẹ̀rẹ̀ sí pe gbogbo ìlú náà ní Síónì. Lábẹ́ májẹ̀mú Òfin, a pàṣẹ fún gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ ọkùnrin láti máa lọ sí Síónì lẹ́ẹ̀mẹta lọ́dún. Èyí la fi ń pe ibẹ̀ ní “òkè ńlá ìpàdé.” Níní tí Nebukadinésárì ní in lọ́kàn láti tẹ àwọn ọba Júdà lórí ba, kó sì mú wọn kúrò lórí òkè yìí, ló fi hàn pé lóòótọ́ ló fẹ́ gbé ara rẹ̀ ga ju àwọn “ìràwọ̀” wọ̀nyẹn lọ. Dípò tí ì bá fi gbà pé Jèhófà ló jẹ́ kóun ṣẹ́gun àwọn ọba Jùdíà, ńṣe ni ìgbéraga mú kó gbé ara rẹ̀ sípò Jèhófà. Ìgbà tá a wá rẹ ọba Bábílónì yìí sílẹ̀ làwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí fi í ṣẹ̀sín, tí wọ́n ń pè é ní “ẹni tí ń tàn.”
Ìwà ìgbéraga àwọn ọba Bábílónì kò yàtọ̀ sí ti “ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí”—ìyẹn Sátánì Èṣù. (2 Kọ́ríńtì 4:4) Òun náà ń lépa agbára lójú méjèèjì, ó sì ń fẹ́ gbé ara rẹ̀ ga ju Jèhófà Ọlọ́run. Àmọ́ Ìwé Mímọ́ kò pe Sátánì ní Lúsíférì.
• Kí nìdí tí 1 Kíróníkà 2:13-15 fi pe Dáfídì ní ọmọ keje tí Jésè bí, nígbà tí 1 Sámúẹ́lì 16:10, 11 sọ pé ọmọ kẹjọ ni?
Lẹ́yìn tí Sọ́ọ̀lù Ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì yà kúrò nínú ìjọsìn tòótọ́, Jèhófà Ọlọ́run rán wòlíì Sámúẹ́lì láti lọ fòróró yan ọ̀kan lára àwọn ọmọ Jésè ṣe ọba. Sámúẹ́lì fúnra rẹ̀ ló kọ àkọsílẹ̀ tí Ọlọ́run mí sí nípa ìṣẹ̀lẹ̀ mánigbàgbé yìí ní ọ̀rúndún kọkànlá Ṣáájú Sànmánì Tiwa. Àkọsílẹ̀ náà sì sọ pé Dáfídì ni ọmọ kẹjọ tí Jésè bí. (1 Sámúẹ́lì 16:10-13) Àmọ́ àkọsílẹ̀ tí Ẹ́sírà àlùfáà kọ ní nǹkan bí ẹgbẹ̀ta ọdún lẹ́yìn náà sọ pé: “Jésè, ẹ̀wẹ̀, bí àkọ́bí rẹ̀ Élíábù, àti Ábínádábù ìkejì, àti Ṣíméà ìkẹta, Nétánélì ìkẹrin, Rádáì ìkarùn-ún, Ósémù ìkẹfà, Dáfídì ìkeje.” (1 Kíróníkà 2:13-15) Ọ̀kan tó kù lára àwọn arákùnrin Dáfídì ńkọ́, kí ló dé tí Ẹ́sírà ò dárúkọ rẹ̀?
Ìwé Mímọ́ sọ pé Jésè “ní ọmọkùnrin mẹ́jọ.” (1 Sámúẹ́lì 17:12) Ẹ̀rí fi hàn pé ọ̀kan lára àwọn ọmọ rẹ̀ kò dàgbà tẹ́ni tó ń láya, kó sì bímọ tó fi dolóògbé. Ọmọ tí kò ní yìí ni kò lè jẹ́ kó ní ìpín kankan nínú ogún ẹ̀yà náà, ó sì lè jẹ́ èyí ló fà á tí orúkọ rẹ̀ kò fi wọ ìtàn ìlà ìran Jésè.
Ẹ jẹ́ ká wá ronú nípa ìgbà ayé Ẹ́sírà. Ronú nípa bí ipò nǹkan ṣe rí nígbà tó ń kọ ìwé Kíróníkà. Nǹkan bí ọdún mẹ́tàdínlọ́gọ́rin ṣáájú ìgbà yẹn ni wọ́n ti kúrò nígbèkùn Bábílónì, àwọn Júù sì padà sí ilẹ̀ wọn. Ọba Páṣíà fún Ẹ́sírà láṣẹ láti yan àwọn onídàájọ́ sípò àtàwọn tá á máa kọ́ àwọn èèyàn ní Òfin Ọlọ́run àti pé kó ṣe ilé Jèhófà lọ́ṣọ̀ọ́. Èyí béèrè fún àkọsílẹ̀ ìlà ìdílé tó pé pérépéré láti mọ àwọn tí ogún tọ́ sí àti láti rí i dájú pé kìkì àwọn tó lẹ́tọ̀ọ́ láti di àlùfáà la fún ní ipò náà. Èyí ló mú kí Ẹ́sírà kọ àkọsílẹ̀ tó pé pérépéré nípa ìtàn orílẹ̀-èdè náà, títí kan àkọsílẹ̀ tó ṣe sàn-án, tó sì ṣeé gbára lé nípa ìlà ìdílé Júdà àti ti Dáfídì. Orúkọ ọmọ Jésè tó kú láìlọ́mọ ò wúlò nínú irú àkọsílẹ̀ yẹn. Ìdí rèé tí Ẹ́sírà fi yọ orúkọ rẹ̀ kúrò.