Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Ìgbàlà Jẹ́ Ti Jèhófà”

“Ìgbàlà Jẹ́ Ti Jèhófà”

“Ìgbàlà Jẹ́ Ti Jèhófà”

LÁWỌN àkókò tí rògbòdìyàn bá bẹ́ sílẹ̀ lórílẹ̀-èdè, tí nǹkan ò sì fara rọ láyé, ìjọba làwọn èèyàn máa ń yíjú sí fún ààbò àti ìfọ̀kànbalẹ̀. Àwọn ìjọba náà máa ń ṣe àwọn ètò tí wọ́n fi máa fa ojú àwọn èèyàn mọ́ra kí wọ́n lè gbárùkù tì wọ́n. Bí ètò yẹn bá ṣe jẹ́ káwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ orílẹ̀-èdè wọn tó, bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ̀mí tí wọ́n fi ń ṣe àwọn ayẹyẹ tó ń fi ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni hàn àti iye ìgbà tí wọ́n ń ṣe àwọn ayẹyẹ náà yóò máa pọ̀ sí i.

Nígbà tí ìṣòro kan bá yọjú lórílẹ̀-èdè, àwọn tó nífẹ̀ẹ́ orílẹ̀-èdè wọn tọkàntọkàn sábà máa ń jẹ́ káwọn èèyàn ní ẹ̀mí ìṣọ̀kan àti okun, wọ́n sì tún máa ń gbé ẹ̀mí ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àti ẹ̀mí ìmúratán láti bójú tó àìní àwọn tó wà láwùjọ wọn lárugẹ. Àmọ́, àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn The New York Times Magazine sọ pé, “bí ìgbónára èyíkéyìí ṣe léwu nínú náà ni ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni ṣe lè dá rúgúdù sílẹ̀,” nítorí pé “bí ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni náà bá pọ̀ jù, ó lè di èyí téèyàn á máa fi hàn làwọn ọ̀nà tí kò bójú mu rárá.” Irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ lè di èyí tó nípa lórí òmìnira gbogbo gbòò tàbí òmìnira ìsìn àwọn èèyàn tó wà lórílẹ̀-èdè ọ̀hún. Ìyẹn sì lè fi àwọn Kristẹni tòótọ́ sínú pákáǹleke tó lè mú kí wọ́n juwọ́ sílẹ̀ nínú ìgbàgbọ́ wọn. Báwo ni wọ́n ṣe máa ń hùwà nígbà tí irú ipò bẹ́ẹ̀ bá dìde láyìíká wọn? Àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ wo ló ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti fi ìjìnlẹ̀ òye hùwà kí wọ́n sì pa ìwà títọ́ mọ́ sí Ọlọ́run?

“Ìwọ Kò Gbọ́dọ̀ Tẹrí Ba fún Wọn”

Láwọn ìgbà mìíràn, kíkí àsíá orílẹ̀-èdè ni ọ̀nà wíwọ́pọ̀ jù lọ táwọn èèyàn gbà ń fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ orílẹ̀-èdè àwọn. Àmọ́ ohun tí wọ́n sábà máa ń yà sára àsíá ní àwòrán àwọn ohun tó wà lọ́run, ìyẹn àwọn nǹkan bí òṣùpá, àti àwòrán àwọn ohun tó wà lórí ilẹ̀ ayé. Ọlọ́run jẹ́ ká mọ èrò òun nípa fíforí balẹ̀ fún irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ nígbà tó pàṣẹ fáwọn èèyàn rẹ̀ pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe ère gbígbẹ́ fún ara rẹ tàbí ìrísí tí ó dà bí ohunkóhun tí ó wà nínú ọ̀run lókè tàbí tí ó wà lábẹ́ ilẹ̀ tàbí tí ó wà nínú omi lábẹ́ ilẹ̀. Ìwọ kò gbọ́dọ̀ tẹrí ba fún wọn tàbí kí a sún ọ láti sìn wọ́n, nítorí èmi Jèhófà Ọlọ́run rẹ jẹ́ Ọlọ́run tí ń béèrè ìfọkànsìn tí a yà sọ́tọ̀ gedegbe.”—Ẹ́kísódù 20:4, 5.

Ṣé kíkí àsíá tó dúró fún Orílẹ̀-Èdè tàbí kéèyàn kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀ wá túmọ̀ sí pé onítọ̀hún ò pa àṣẹ tó sọ pé ká fún Jèhófà Ọlọ́run ní ìfọkànsìn tí a yà sọ́tọ̀ gedegbe mọ́ ni? Láìsí àní-àní, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì ní “àmì,” tàbí ọ̀págun tí àwọn ẹ̀yà mẹ́ta-mẹ́ta máa ń kóra wọn jọ yí ká rẹ̀ nígbà tí wọ́n wà nínú aginjù. (Númérì 2:1, 2) Nígbà tí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ McClintock and Strong’s Cyclopedia ń ṣàlàyé àwọn ọ̀rọ̀ Hébérù tó túmọ̀ sí irú àwọn ọ̀págun bẹ́ẹ̀, ó ní: “A sábà máa ń rò pé ‘ọ̀págun’ jẹ́ àsíá, ṣùgbọ́n kò sí èyíkéyìí nínú ọ̀rọ̀ Hébérù wọ̀nyí tó fi irú èrò yìí hàn.” Àti pé, àwọn èèyàn ò wo àwọn ọ̀págun Ísírẹ́lì bí ohun mímọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ayẹyẹ kankan tí wọ́n so pọ̀ mọ́ lílò wọn. Ohun tí wọ́n wà fún ò ju ohun tí pátákó ìsọfúnni wà fún, ìyẹn ni káwọn èèyàn náà lè mọ ibi tí wọ́n máa kóra jọ sí.

Àwòrán àwọn kérúbù tó wà nínú àgọ́ ìjọsìn àti nínú tẹ́ńpìlì Sólómọ́nì wulẹ̀ ń ṣàpẹẹrẹ àwọn kérúbù tó wà lọ́run ni. (Ẹ́kísódù 25:18; 26:1, 31, 33; 1 Àwọn Ọba 6:23, 28, 29; Hébérù 9:23, 24) Ohun tó fi hàn kedere pé àwọn àwòrán wọ̀nyí kì í ṣe ohun tí wọ́n ń jọ́sìn ni pé àwọn èèyàn náà lápapọ̀ kì í rí wọn àti pé àwọn áńgẹ́lì alára kì í ṣẹni téèyàn ń jọ́sìn.—Kólósè 2:18; Ìṣípayá 19:10; 22:8, 9.

Tún ronú nípa ère ejò bàbà tí wòlíì Mósè ṣe nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà nínú aginjù. Àwòrán, tàbí ère yẹn, dúró fún àmì kan, ó sì jẹ mọ́ ọ̀ràn àsọtẹ́lẹ̀. (Númérì 21:4-9; Jòhánù 3:14, 15) Wọn ò wárí fún un bẹ́ẹ̀ ni wọn ò lò ó nínú ìjọsìn wọn. Àmọ́ ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún lẹ́yìn ọjọ́ Mósè, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí fi àìtọ́ jọ́sìn ère kan náà yẹn, wọ́n tiẹ̀ ń fín tùràrí sí i pàápàá. Ìdí nìyẹn tí Hesekáyà Ọba Jùdíà fi fọ́ ọ sí wẹ́wẹ́.—2 Àwọn Ọba 18:1-4.

Ṣé àwọn àsíá orílẹ̀-èdè wulẹ̀ jẹ́ àmì tó wà fún àwọn ète pàtàkì kan ni? Kí ni wọ́n dúró fún? Òǹkọ̀wé J. Paul Williams sọ pé: “Olórí àmì ìgbàgbọ́ ti ìfẹ́ orílẹ̀-èdè àti ohun pàtàkì tó wà fún ìjọsìn ni àsíá jẹ́.” Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Encyclopedia Americana sọ pé: “Bí àgbélébùú ṣe jẹ́ mímọ́ náà ni àsíá ṣe jẹ́ mímọ́.” Àsíá ni àmì Orílẹ̀-Èdè. Nítorí náà, títẹrí ba fún un tàbí kíkí i jẹ́ ààtò ìsìn téèyàn fi ń júbà Orílẹ̀-Èdè. Irú àṣà bẹ́ẹ̀ ń fi hàn pé ìgbàlà jẹ́ ti Orílẹ̀-Èdè, ìyẹn sì lòdì lójú ìwòye ohun tí Bíbélì sọ nípa ìbọ̀rìṣà.

Ìwé Mímọ́ sọ ní kedere pé: “Ìgbàlà jẹ́ ti Jèhófà.” (Sáàmù 3:8) Ìgbàlà kì í ṣe ohun tá a lè sọ pé ó jẹ́ ti àjọ àwọn èèyàn tàbí ti àwọn àmì wọn. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni bíi tirẹ̀ níyànjú pé: “Ẹ̀yin olùfẹ́ mi ọ̀wọ́n, ẹ sá fún ìbọ̀rìṣà.” (1 Kọ́ríńtì 10:14) Àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ kì í kópa nínú ọ̀nà tí Orílẹ̀-èdè gbà ń jọ́sìn. Daniel P. Mannix sọ nínú ìwé náà, Those about to die, pé: “Àwọn Kristẹni kọ̀ láti . . . rúbọ sí ẹ̀mí àwọn baba ńlá olú Ọba [Róòmù]—tó fẹ́rẹ̀ẹ́ bá kíkọ̀ láti kí àsíá lọ́jọ́ òní dọ́gba. Bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn Kristẹni tòótọ́ ń ṣe lóde òní. Tìtorí àtifún Jèhófà ní ìfọkànsìn tí a yà sọ́tọ̀ gédégbé ni wọn ò ṣe ń kí àsíá orílẹ̀-èdè kankan. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n fi Ọlọ́run sí ipò kìíní, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń bọ̀wọ̀ fún ìjọba àtàwọn aláṣẹ wọn. Láìṣe àní-àní, wọ́n mọ̀ pé ojúṣe àwọn ni láti wà lábẹ́ ìjọba “àwọn aláṣẹ onípò gíga.” (Róòmù 13:1-7) Àmọ́, irú ojú wo ni Ìwé Mímọ́ fi wo kíkọ àwọn orin tó ń fi ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni hàn, irú bí àwọn orin orílẹ̀-èdè?

Kí Làwọn Orin Orílẹ̀-Èdè?

Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Encyclopedia Americana sọ pé: “Àwọn orin orílẹ̀-èdè jẹ́ orin tó ń fi hàn pé èèyàn nífẹ̀ẹ́ orílẹ̀-èdè rẹ̀, ó sì sábà máa ń wé mọ́ bíbéèrè fún ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run àti ààbò lórí àwọn èèyàn náà tàbí àwọn aláṣẹ wọn.” Lẹ́nu kan, orin orílẹ̀-èdè jẹ́ orin ìyìn tàbí àdúrà téèyàn gbà fún orílẹ̀-èdè kan. Ohun tó sábà máa ń sọ ni pé kí orílẹ̀-èdè náà ní aásìkí kó sì wà fún ìgbà pípẹ́. Ǹjẹ́ ó yẹ kí Kristẹni tòótọ́ bá wọn lọ́wọ́ nínú irú orin àdúrà bẹ́ẹ̀?

Wòlíì Jeremáyà gbé láàárín àwọn èèyàn tó sọ pé Ọlọ́run làwọn ń sìn. Síbẹ̀, Jèhófà pàṣẹ fún un pé: “Má ṣe gbàdúrà nítorí àwọn ènìyàn yìí, má sì ṣe gbé ohùn igbe ìpàrọwà sókè tàbí àdúrà tàbí kí o fi taratara bẹ̀ mí nítorí wọn, nítorí èmi kì yóò fetí sí ọ.” (Jeremáyà 7:16; 11:14; 14:11) Kí nìdí tá a fi pàṣẹ yìí fún Jeremáyà? Ìdí ni pé àwùjọ wọn kún fún olè jíjà, ìpànìyàn, ṣíṣe panṣágà, bíbúra èké, àti ìbọ̀rìṣà.—Jeremáyà 7:9.

Jésù Kristi fi àpẹẹrẹ ìṣáájú lélẹ̀ nígbà tó sọ pé: “Mo ṣe ìbéèrè nípa wọn; èmi ko ṣe ìbéèrè nípa ayé, bí kò ṣe nípa àwọn tí ìwọ ti fi fún mi.” (Jòhánù 17:9) Ìwé Mímọ́ sọ pé: “gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà” àti pé ayé yẹn sì “ń kọjá lọ.” (1 Jòhánù 2:17; 5:19) Báwo làwọn Kristẹni tòótọ́ á wá ṣe máa fi tọkàntọkàn gbàdúrà pé kí irú ètò bẹ́ẹ̀ ní aásìkí kó sì wà fún ìgbà pípẹ́?

Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe gbogbo orin orílẹ̀-èdè ló ní títọrọ nǹkan lọ́wọ́ Ọlọ́run nínú. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia Britannica, sọ pé: “Ohun táwọn orin orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan ń sọ yàtọ̀ síra wọn, látorí gbígbàdúrà fáwọn aláṣẹ dé orí sísọ̀rọ̀ nípa àwọn ogun pàtàkì tí orílẹ̀-èdè náà ń jà . . . títí dórí sísọ̀rọ̀ nípa ìfẹ́ téèyàn ní sí orílẹ̀-èdè rẹ̀.” Àmọ́ ǹjẹ́ ó yẹ káwọn tó fẹ́ múnú Ọlọ́run dùn máa yọ̀ lórí àwọn ogun àti ìyípadà tegbòtigaga orílẹ̀-èdè èyíkéyìí? Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ nípa àwọn olùjọsìn tòótọ́ pé: “Wọn yóò ní láti fi idà wọn rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀, wọn yóò sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ ọ̀bẹ ìrẹ́wọ́-ọ̀gbìn.” (Aísáyà 2:4) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Bí àwa tilẹ̀ ń rìn nínú ẹran ara, a kò ja ogun gẹ́gẹ́ bí ohun tí a jẹ́ nínú ẹran ara. Nítorí àwọn ohun ìjà ogun wa kì í ṣe ti ara.”—2 Kọ́ríńtì 10:3, 4.

Àwọn orin orílẹ̀-èdè sábà máa ń fi ẹ̀mí orílẹ̀-èdè tèmi lọ̀gá hàn. Ojú ìwòye yìí kò bá Ìwé Mímọ́ mu rárá. Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ ní Áréópágù, ó ní: “Láti ara ọkùnrin kan ni [Jèhófà Ọlọ́run] ti dá gbogbo orílẹ̀-èdè àwọn ènìyàn, láti máa gbé ní ojú gbogbo ilẹ̀ ayé pátá.” (Ìṣe 17:26) Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé: “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.”—Ìṣe 10:34, 35.

Òye Bíbélì tí ọ̀pọ̀ èèyàn ní ti mú kí wọ́n pinnu pé àwọn ò ní bá wọn lọ́wọ́ nínú kíkí àsíá àti kíkọ orin tó ń fi ìfẹ́ orílẹ̀-èdè hàn. Àmọ́, báwo ni wọ́n ṣe máa hùwà nígbà tí wọ́n bá bára wọn láwọn ipò tó mú kí wọ́n dojú kọ nǹkan wọ̀nyí?

Fi Tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ Yàgò fún Un

Nígbà tí Nebukadinésárì Ọba Bábílónì ìgbàanì ń sapá láti jẹ́ kí ìṣọ̀kan tó lágbára wà ní ilẹ̀ ọba òun, ó gbé ère oníwúrà fàkìàfakia kan kalẹ̀ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Dúrà. Ó wá ṣètò ayẹyẹ kan láti fi ṣí i. Ó pe àwọn baálẹ̀, aṣáájú, gómìnà, agbani-nímọ̀ràn, àtàwọn aláṣẹ mìíràn tó wà ní ipò gíga. Ó sì sọ pé tí wọ́n bá gbọ́ ohun orin, kí gbogbo àwọn tó péjọ síbẹ̀ wólẹ̀, kí wọ́n sì jọ́sìn ère náà. Àwọn ọ̀dọ́ Hébérù mẹ́ta nì—Ṣádírákì, Méṣákì, àti Àbẹ́dínígò wà lára àwọn tó pésẹ̀ síbẹ̀. Báwo ni wọ́n ṣe fi hàn pé àwọn ò lọ́wọ́ sí ayẹyẹ ìsìn yìí? Nígbà tí orin bẹ̀rẹ̀, tí gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ wólẹ̀ níwájú ère náà, orí ìdúró ni àwọn Hébérù mẹ́ta náà wà.—Dáníẹ́lì 3:1-12.

Lóde òní, ọwọ́ ni àwọn èèyàn máa ń nà sókè tàbí kí wọ́n fọwọ́ síwájú orí tàbí sí àyà wọn nígbà tí wọ́n bá ń kí àsíá. Nígbà mìíràn, ọ̀nà àkànṣe téèyàn gbà dúró máa ń fi hàn pẹ̀lú. Láwọn orílẹ̀-èdè kan, àwọn ọmọ ilé ìwé gbọ́dọ̀ kúnlẹ̀ kí wọ́n sì fẹnu gún àsíá náà. Táwọn Kristẹni tòótọ́ bá rọra dúró láìfọhùn nígbà táwọn tó kù bá ń kí àsíá, wọ́n ń fi hàn kedere pé òǹwòran tó nítẹríba làwọn.

Tí wọ́n bá wá ṣe ètò kíkí àsíá náà lọ́nà tó jẹ́ pé dídìde dúró lásán yóò fi hàn pé èèyàn ń bá wọn kópa ńkọ́? Bí àpẹẹrẹ, ká ní wọ́n yan akẹ́kọ̀ọ́ kan nílé ìwé kan pé kó ṣojú fún ilé ìwé náà, kó sì wá lọ kí àsíá náà lórí igi tí wọ́n gbé e kọ́ níta nígbà táwọn akẹ́kọ̀ọ́ yòókù gan bí ológun sínú kíláàsì. Dídìde dúró lásán nírú àkókò yìí á fi onítọ̀hún hàn gẹ́gẹ́ bí ẹni tó gbà pé akẹ́kọ̀ọ́ tó lọ kí àsíá níta ń ṣojú fún òun náà pẹ̀lú. Pé èèyàn tiẹ̀ dìde dúró lásán ti fi hàn pé ó ń kópa nínú ayẹyẹ náà. Tó bá jẹ́ pé báyìí lọ́ràn náà rí, á dáa káwọn tó bá fẹ́ jẹ́ òǹwòran tó ń fi ọ̀wọ̀ hàn lásán rọra wà lórí ìjókòó. Táwọn ọmọ kíláàsì náà bá ti wà lórí ìdúró kí ayẹyẹ náà tó bẹ̀rẹ̀ ńkọ́? Lọ́tẹ̀ yìí, wíwà lórí ìdúró kò ní túmọ̀ sí pé èèyàn báwọn lọ́wọ́ nínú rẹ̀.

Ká ní wọn ò sọ pé kéèyàn kí àsíá náà, àmọ́ tí wọ́n ní kó gbé e nígbà ìwọ́de kan tàbí nínú kíláàsì tàbí níbòmíràn, kí àwọn tó kù lè kí i. Dípò ‘sísá fún ìbọ̀rìṣà,’ gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti pa á láṣẹ, èyí yóò túmọ̀ sí pé onítọ̀hún gan-an ní baba ìsàlẹ̀ ayẹyẹ náà. Bákan náà lọ̀rọ̀ rí pẹ̀lú kéèyàn yan bí ológun nínú ìwọ́de tó fi ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni hàn. Àwọn Kristẹni tòótọ́ gbọ́dọ̀ fi tọkàntọkàn yẹra fún ìyẹn pẹ̀lú, nítorí pé ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yóò túmọ̀ sí pé èèyàn fara mọ́ ohun tí wọ́n ń fi ìwọ́de náà bọlá fún.

Nígbà tí wọ́n bá ń kọ orin orílẹ̀-èdè, ohun téèyàn sábà máa ń ṣe láti fi hàn pé òun fara mọ́ ohun tí wọ́n ń fi orin náà sọ ni pé kó dìde dúró. Ńṣe ló yẹ káwọn Kristẹni jókòó nírú àkókò yẹn. Àmọ́ ṣá o, tí wọ́n bá ti wà lórí ìdúró kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ sí kọ orin orílẹ̀-èdè náà, kò pọn dandan pé kí wọ́n jókòó nígbà yẹn. Kì í kúkú ṣe tìtorí orin náà ni wọ́n ṣe dídé dúró tẹ́lẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, bí wọ́n bá sọ pé kí àwùjọ kan dìde dúró kí wọ́n sì kọrin, béèyàn bá dìde dúró lásán láti fi ọ̀wọ̀ hàn nírú àkókò yẹn, àmọ́ téèyàn ò bá wọn kọrin, kò ní túmọ̀ sí pé èèyàn fara mọ́ ohun tí wọ́n ń fi orin náà sọ.

“Ẹ Di Ẹ̀rí-Ọkàn Rere Mú”

Lẹ́yìn tí onísáàmù náà ṣàpèjúwe bí ohun táwọn èèyàn fọwọ́ ara wọn ṣe tí wọ́n wá ń júbà rẹ̀ ṣe jẹ́ òtúbáńtẹ́ tó, ó sọ pé: “Àwọn tí ń ṣe wọ́n yóò dà bí àwọn gan-an, gbogbo àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀ lé wọn.” (Sáàmù 115:4-8) Ó hàn gbangba nígbà náà pé, àwọn olùjọsìn Jèhófà kò ní gbà láti ṣíṣẹ èyíkéyìí nílé iṣẹ́ tí wọ́n bá ti ń ṣe ohun táwọn èèyàn ń buyìn fún jáde, títí kan àsíá orílẹ̀-èdè. (1 Jòhánù 5:21) Ipò mìíràn tún lè dìde lẹ́nu iṣẹ́ tó máa mú káwọn Kristẹni fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé àwọn ò jọ́sìn àsíá tàbí ohun tó dúró fún, pé Jèhófà nìkan ṣoṣo làwọn ń jọ́sìn.

Bí àpẹẹrẹ, agbanisíṣẹ́ kan lè sọ pé kí òṣìṣẹ́ kan fa àsíá sókè tàbí kó fà á wálẹ̀ lára ilé kan tí wọ́n so ó mọ́. Yálà ẹnì kan máa ṣe bẹ́ẹ̀ tàbí kò ní ṣe bẹ́ẹ̀ sinmi lórí ojú tí onítọ̀hún fi wo ọ̀ràn náà. Bí fífa àsíá náà sókè tàbí fífà á wálẹ̀ bá jẹ́ ara àkànṣe ayẹyẹ kan, tí àwọn èèyàn gan bí ológun síwájú rẹ̀ tàbí tí wọ́n ń kí àsíá náà, á jẹ́ pé ṣíṣe irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ túmọ̀ sí pé èèyàn lọ́wọ́ nínú ayẹyẹ náà nìyẹn.

Ní ọ̀wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, tí kò bá sí ayẹyẹ kankan tí wọ́n fi fífa àsíá náà sókè tàbí fífà á wálẹ̀ ṣe, a jẹ́ pé ṣíṣe irú iṣẹ́ yìí kò yàtọ̀ sí ṣíṣe àwọn iṣẹ́ bíi títún ilé kan ṣe fún lílò, ṣíṣí ilẹ̀kùn àti títì í, ṣíṣí fèrèsé àti pípa á dé. Nírú ipò bẹ́ẹ̀ àsíá náà wulẹ̀ jẹ́ ohun ìṣàpẹẹrẹ Orílẹ̀-Èdè ni, fífà á sókè àti fífà á wálẹ̀ jẹ́ ọ̀ràn ara ẹni tó sinmi lórí ohun tí ẹ̀rí ọkàn tá a ti fi Bíbélì kọ́ bá sọ pé kí onítọ̀hún ṣe. (Gálátíà 6:5) Ẹ̀rí ọkàn ẹnì kan lè sún un láti sọ fún ọ̀gá rẹ̀ pé kó jọ̀ọ́ kó jẹ́ kí òṣìṣẹ́ mìíràn máa fa àsíá náà sókè kó sì máa fà á wálẹ̀. Kristẹni mìíràn lè sọ pé ẹ̀rí ọkàn òun ò sọ pé kí òun má ṣe irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ níwọ̀n bí kò ti ní ayẹyẹ kankan nínú. Ohun yòówù kí ìpinnu náà jẹ́, àwọn olùjọsìn tòótọ́ gbọ́dọ̀ “di ẹ̀rí-ọkàn rere mú” níwájú Ọlọ́run.—1 Pétérù 3:16.

Kò sí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó sọ pé èèyàn ò lè ṣíṣẹ láwọn ilé tó wà fún ìlò gbogbo ará ìlú, bí ilé iṣẹ́ afẹ́nifẹ́re àtàwọn ilé ìwé tí wọ́n so àsíá mọ́. Àsíá tún lè wà lára sítáǹpù, ó lè wà lára nọ́ńbà mọ́tò, tàbí lára àwọn nǹkan mìíràn tí ìjọba ṣe jáde. Lílo irú àwọn nǹkan wọ̀nyẹn kò túmọ̀ sí pé ẹnì kan ń kópa nínú ọ̀ràn ìfọkànsìn. Wíwà tí àsíá náà wà níbẹ̀ tàbí ohun tó dúró fún kọ́ ló ṣe pàtàkì níhìn-ín bí kò ṣe béèyàn ṣe ń ṣe sí i.

Wọ́n sábà máa ń gbé àsíá sí ojú fèrèsé, ẹnu ilẹ̀kùn, inú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́, orí tábìlì tàbí àwọn nǹkan mìíràn. Wọ́n tún ń ta àwọn aṣọ tí wọ́n ya àsíá sí lára. Ó lòdì sófin láti wọ irú aṣọ bẹ́ẹ̀ láwọn orílẹ̀-èdè kan. Ká tiẹ̀ sọ pé ṣíṣe bẹ́ẹ̀ kò túmọ̀ sí pé èèyàn rúfin, àmọ́ kí ló máa túmọ̀ sí tá a bá fi ojú ipò tí onítọ̀hún wà sí ayé wò ó? Ohun tí Jésù Kristi sọ nípa àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ni pé: “Wọn kì í ṣe apá kan ayé, gan-an gẹ́gẹ́ bí èmi kì í ti í ṣe apá kan ayé.” (Jòhánù 17:16) Ohun tá ò tún ní gbójú fò dá ni ipa tí irú ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀ máa ní lórí àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́. Ǹjẹ́ ó lè pa ẹ̀rí ọkàn àwọn kan lára? Ǹjẹ́ ó lè sọ ìpinnu tí wọ́n ti ṣe láti dúró gbọn-in nínú ìgbàgbọ́ di yẹpẹrẹ? Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni níyànjú pé: “Kí ẹ . . . máa wádìí dájú àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù, kí ẹ lè jẹ́ aláìní àbààwọ́n, kí ẹ má sì máa mú àwọn ẹlòmíràn kọsẹ̀.”—Fílípì 1:10.

“Jẹ́ Ẹni Pẹ̀lẹ́ sí Gbogbo Ènìyàn”

Bí ipò ayé ṣe túbọ̀ ń burú sí i láwọn “àkókò lílekoko” wọ̀nyí, ó ṣeé ṣe kí ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni túbọ̀ légbá kan sí i. (2 Tímótì 3:1) Ǹjẹ́ kí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run má ṣe gbàgbé láé pé ìgbàlà jẹ́ ti Jèhófà. Òun ló lẹ́tọ̀ọ́ láti gba ìfọkànsìn tí a yà sọ́tọ̀ gedegbe. Nígbà tí wọ́n sọ pé káwọn àpọ́sítélì Jésù ṣe ohun kan tó lòdì sí ìfẹ́ Jèhófà, wọ́n sọ pé: “Àwa gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.”—Ìṣe 5:29.

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Kò yẹ kí ẹrú Olúwa máa jà, ṣùgbọ́n ó yẹ kí ó jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́ sí gbogbo ènìyàn.” (2 Tímótì 2:24) Nítorí náà, àwọn Kristẹni ń làkàkà láti jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà, láti jẹ́ onítẹríba, kí wọ́n sì jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́ bí wọ́n ṣe ń gbára lé ẹ̀rí ọkàn wọn tá a ti fi Bíbélì kọ́ nínú ṣíṣe àwọn ìpinnu lórí kíkí àsíá àti kíkọ orin orílẹ̀-èdè.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Láìyẹsẹ̀, àwọn Hébérù mẹ́ta yàn láti múnú Ọlọ́run dùn, àmọ́ wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ìtẹríba

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Ìgbésẹ̀ wo ló yẹ kí Kristẹni kan gbé lákòókò ayẹyẹ tó ń fi ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni hàn?