Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

‘Ẹ Pọkàn Pọ̀ Ju Ti Àtẹ̀yìnwá Lọ’

‘Ẹ Pọkàn Pọ̀ Ju Ti Àtẹ̀yìnwá Lọ’

‘Ẹ Pọkàn Pọ̀ Ju Ti Àtẹ̀yìnwá Lọ’

“Ó . . . pọndandan fún wa láti fún àwọn ohun tí a gbọ́ ní àfiyèsí tí ó ju ti àtẹ̀yìnwá lọ.”—HÉBÉRÙ 2:1.

1. Ṣàpèjúwe bí ìpínyà ọkàn ṣe lè yọrí sí jàǹbá?

 ÌJÀǸBÁ ohun ìrìnnà ń gbẹ̀mí àwọn èèyàn bí ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlógójì [37,000] lọ́dọọdún ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà nìkan ṣoṣo. Àwọn ògbógi sọ pé èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí ni ì bá máà wáyé tó bá jẹ́ pé àwọn awakọ̀ túbọ̀ fojú síbi tí wọ́n ń lọ. Ohun tó ń gba àfiyèsí àwọn awakọ̀ kan ni pátákó ìsọfúnni, pátákó ìpolówó ọjà tàbí fóònù alágbèérìn tí wọ́n ń lò. Àwọn kan tún máa ń jẹun nígbà tí wọ́n bá ń wakọ̀ lọ́wọ́. Ohun tí gbogbo èyí ń fi yéni ni pé ìpínyà ọkàn lè yọrí sí jàǹbá.

2, 3. Ọ̀rọ̀ ìṣílétí wo ni Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn Hébérù tó jẹ́ Kristẹni, kí sì nìdí tí ìmọ̀ràn rẹ̀ fi bọ́ sásìkò?

2 Nǹkan bí ẹgbàá ọdún ṣáájú àkókò tí wọ́n ṣe ohun ìrìnnà jáde ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ti mẹ́nu kan oríṣi ìpínyà ọkàn kan tó hàn pé ó kó jàǹbá bá àwọn kan lára àwọn Hébérù tó jẹ́ Kristẹni. Pọ́ọ̀lù tẹnu mọ́ ọn pé a ti gbé Jésù Kristi tó jíǹde sí ipò kan tó ga ju ti gbogbo àwọn áńgẹ́lì lọ, nítorí ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run ló jókòó sí. Àpọ́sítélì náà wá sọ pé: “Ìdí nìyẹn tí ó fi pọndandan fún wa láti fún àwọn ohun tí a gbọ́ ní àfiyèsí tí ó ju ti àtẹ̀yìnwá lọ, kí a má bàa sú lọ láé.”—Hébérù 2:1.

3 Kí nìdí táwọn Hébérù tó jẹ́ Kristẹni fi ní ‘láti fún àwọn ohun tí wọ́n gbọ́ nípa Jésù ní àfiyèsí tí ó ju ti àtẹ̀yìnwá lọ’? Ìdí ni pé nǹkan bí ọgbọ̀n ọdún ti kọjá lẹ́yìn tí Jésù kúrò lórí ilẹ̀ ayé. Àwọn Hébérù kan tó jẹ́ Kristẹni ti bẹ̀rẹ̀ sí sú lọ kúrò nínú ìgbàgbọ́ nítorí pé Ọ̀gá wọn ò sí lọ́dọ̀ wọn mọ́. Ìsìn àwọn Júù, tó jẹ́ ọ̀nà tí wọ́n ń gbà jọ́sìn tẹ́lẹ̀ ti ń pín ọkàn wọn níyà.

Wọ́n Ní Láti Túbọ̀ Pọkàn Pọ̀

4. Kí ló lè mú kó máa ṣe àwọn Hébérù kan tó jẹ́ Kristẹni bíi pé kí wọ́n padà sínú ìsìn àwọn Júù?

4 Kí nìdí tó fi lè máa ṣe àwọn Kristẹni kan bíi pé kí wọ́n padà sínú ìsìn àwọn Júù? Tóò, ọ̀nà tí wọ́n gbà ń jọ́sìn lábẹ́ Òfin jẹ mọ́ àwọn ohun tó ṣeé fojú rí. Àwọn èèyàn lè rí àwọn àlùfáà kí wọ́n sì gbóòórùn àwọn ẹbọ sísùn. Àmọ́ ìsìn Kristẹni yàtọ̀ pátápátá síyẹn láwọn ọ̀nà kan. Àwọn Kristẹni ní Àlùfáà Àgbà kan, ìyẹn Jésù Kristi, àmọ́ láti bí ọgbọ̀n ọdún sẹ́yìn làwọn èèyàn ìgbà yẹn ò tì rí i mọ́ lórí ilẹ̀ ayé. (Hébérù 4:14) Wọ́n ní tẹ́ńpìlì kan, àmọ́ ọ̀run ni ibi mímọ́ rẹ̀ wà. (Hébérù 9:24) Dípò ìdádọ̀dọ́ tó ṣeé fojú rí lábẹ́ Òfin, ìdádọ̀dọ́ Kristẹni jẹ́ “ti ọkàn-àyà nípasẹ̀ ẹ̀mí.” (Róòmù 2:29) Nítorí náà, ó ṣeé ṣe kí ìsìn Kristẹni ti bẹ̀rẹ̀ sí dà bí ohun tí kò nítumọ̀ mọ́ lójú àwọn Hébérù tó jẹ́ Kristẹni.

5. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe fi hàn pé ọ̀nà ìjọsìn tí Jésù gbé kalẹ̀ ga lọ́lá ju èyí tí ń bẹ lábẹ́ Òfin lọ?

5 Àwọn Hébérù tó jẹ́ Kristẹni ní láti mọ ohun kan tó ṣe pàtàkì gan-an nípa ọ̀nà ìjọsìn tí Kristi gbé kalẹ̀. Ó gbé e karí ìgbàgbọ́ ju orí ohun tó ṣeé fojú rí lọ, síbẹ̀ ó ga lọ́lá ju Òfin tá a fún wọn nípasẹ̀ wòlíì Mósè. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Bí ẹ̀jẹ̀ àwọn ewúrẹ́ àti ti àwọn akọ màlúù àti eérú ẹgbọrọ abo màlúù tí a fi wọ́n àwọn tí ó di ẹlẹ́gbin bá ń sọni di mímọ́ dé àyè ìmọ́tónítóní ara, mélòómélòó ni ẹ̀jẹ̀ Kristi, ẹni tí ó tipasẹ̀ ẹ̀mí àìnípẹ̀kun fi ara rẹ̀ rúbọ sí Ọlọ́run láìní àbààwọ́n, yóò wẹ ẹ̀rí-ọkàn wa mọ́ kúrò nínú àwọn òkú iṣẹ́ kí a lè ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún Ọlọ́run alààyè?” (Hébérù 9:13, 14) Bẹ́ẹ̀ ni o, ìdáríjì téèyàn ń rí gbà nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi ga lọ́lá gan-an ní ọ̀pọ̀ ọ̀nà ju èyí téèyàn ń rí gbà nípasẹ̀ ẹbọ tí wọ́n ń rú lábẹ́ Òfin.—Hébérù 7:26-28.

6, 7. (a) Ipò wo ló mú kó di ọ̀ràn kánjúkánjú pé káwọn Hébérù tó jẹ́ Kristẹni ‘fún àwọn ohun tí wọ́n gbọ́ ní àfiyèsí tí ó ju ti àtẹ̀yìnwá lọ’? (b) Báwo ni ìparun Jerúsálẹ́mù ṣe sún mọ́lé tó lákòókò tí Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà rẹ̀ sáwọn Hébérù? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)

6 Ìdí mìíràn tún wà táwọn Hébérù tó jẹ́ Kristẹni fi ní láti fún ohun tí wọ́n gbọ́ nípa Jésù ní àfiyèsí gidi. Ó ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé a óò pa Jerúsálẹ́mù run. Jésù sọ pé: “Àwọn ọjọ́ yóò dé bá ọ, nígbà tí àwọn ọ̀tá rẹ yóò fi àwọn òpó igi olórí ṣóńṣó ṣe odi yí ọ ká, wọn yóò sì ká ọ mọ́, wọn yóò sì wàhálà rẹ láti ìhà gbogbo, wọn yóò sì fọ́ ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ tí ń bẹ nínú rẹ mọ́lẹ̀, wọn kì yóò sì fi òkúta kan sílẹ̀ lórí òkúta kan nínú rẹ, nítorí pé ìwọ kò fi òye mọ àkókò tí a ó bẹ̀ ọ́ wò.”—Lúùkù 19:43, 44.

7 Ìgbà wo lèyí máa ṣẹlẹ̀? Jésù ò sọ ọjọ́ àti wákàtí náà. Dípò ìyẹn, ó fún wọn nítọ̀ọ́ni yìí pé: “Nígbà tí ẹ bá rí tí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun adótini bá yí Jerúsálẹ́mù ká, nígbà náà ni kí ẹ mọ̀ pé ìsọdahoro rẹ̀ ti sún mọ́lé. Nígbà náà ni kí àwọn tí ń bẹ ní Jùdíà bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ sí àwọn òkè ńlá, kí àwọn tí wọ́n sì wà ní àárín rẹ̀ fi ibẹ̀ sílẹ̀, kí àwọn tí wọ́n sì wà ní àwọn ibi ìgbèríko má ṣe wọ inú rẹ̀.” (Lúùkù 21:20, 21) Àwọn Kristẹni kan ní Jerúsálẹ́mù ti pàdánù ẹ̀mí pé ọ̀ràn jẹ́ kánjúkánjú tí wọ́n ní, ọkàn wọn sì ti pínyà ní ọgbọ̀n ọdún lẹ́yìn tí Jésù sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí. Ìyẹn ni pé wọ́n ti yíjú kúrò lójú ọ̀nà tí wọ́n ń gbà lọ. Bí wọn ò bá yí èrò wọn padà, ó dájú pé wọ́n á ko àgbákò. Yálà wọ́n rò bẹ́ẹ̀ o tàbí wọn ò rò bẹ́ẹ̀, ìparun ti rọ̀ dẹ̀dẹ̀ sórí Jerúsálẹ́mù! a Ó ṣeé ṣe kí ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù mú káwọn Kristẹni tó wà ní Jerúsálẹ́mù ta jí kúrò lójú oorun tẹ̀mí tí wọ́n ń sùn.

Pípọkànpọ̀ “Ju Ti Àtẹ̀yìnwá Lọ” Lónìí

8. Èé ṣe tá a fi ní láti “fún” òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run “ní àfiyèsí tó ju ti àtẹ̀yìnwá lọ”?

8 Bíi ti àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní, a ní láti “fún” òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run “ní àfiyèsí ju ti àtẹ̀yìnwá lọ.” Kí nìdí? Nítorí pé àwa náà dojú kọ ìparun kan tó sún mọ́lé, kì í ṣe ti orílẹ̀-èdè kan ṣoṣo bí kò ṣe ti ètò àwọn nǹkan látòkèdélẹ̀. (Ìṣípayá 11:18; 16:14, 16) Lóòótọ́, a ò mọ ọjọ́ náà gan-an àti wákàtí tí Jèhófà yóò gbé ìgbésẹ̀ yìí. (Mátíù 24:36) Síbẹ̀, à ń fojú ara wa rí ìmúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tó fi hàn pé “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” là ń gbé. (2 Tímótì 3:1-5) Nítorí náà, a gbọ́dọ̀ wà lójúfò láti dènà ohunkóhun tó lè pín ọkàn wa níyà. A ní láti máa fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láfiyèsí ká sì máa ní ẹ̀mí pé ọ̀ràn jẹ́ kánjúkánjú nìṣó. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀ nìkan la fi lè “kẹ́sẹ járí ní yíyèbọ́ nínú gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí a ti yàn tẹ́lẹ̀ láti ṣẹlẹ̀.”—Lúùkù 21:36.

9, 10. (a) Báwo la ṣe lè fi hàn pé à ń fiyè sí àwọn ọ̀ràn tẹ̀mí? (b) Báwo ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe jẹ́ ‘fìtílà sí ẹsẹ̀ wa’ àti ‘ìmọ́lẹ̀ sí òpópónà wa’?

9 Láwọn àkókò tó ṣe pàtàkì yìí, báwo la ṣe lè fi hàn pé à ń fún àwọn nǹkan tẹ̀mí “ní àfiyèsí tó ju ti àtẹ̀yìnwá lọ”? Ọ̀nà kan ni pé ká máa lọ sáwọn ìpàdé Kristẹni, àpéjọ àkànṣe, ti àyíká àti ti àgbègbè déédéé. A tún ní láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì dáadáa ká lè sún mọ́ Jèhófà tó jẹ́ Orísun rẹ̀. (Jákọ́bù 4:8) Bí a bá ń gba ìmọ̀ Jèhófà sínú nípa dídákẹ́kọ̀ọ́ àti lílọ sáwọn ìpàdé, a óò dà bí onísáàmù tó sọ fún Ọlọ́run pé: “Ọ̀rọ̀ rẹ jẹ́ fìtílà fún ẹsẹ̀ mi, àti ìmọ́lẹ̀ sí òpópónà mi.”—Sáàmù 119:105.

10 Bíbélì jẹ́ ‘ìmọ́lẹ̀ sí òpópónà wa’ nígbà tó bá ń sọ àwọn ohun tí Ọlọ́run máa ṣe lọ́jọ́ iwájú fún wa. Ó tún jẹ́ ‘fìtílà sí ẹsẹ̀ wa.’ Ìyẹn ni pé ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti mọ ìgbésẹ̀ tó yẹ ká gbé nígbà tá a bá dojú kọ àwọn ìṣòro líle koko nínú ìgbésí ayé. Ìdí nìyẹn tó fi ṣe pàtàkì pé ká ‘pọkàn pọ̀ ju ti àtẹ̀yìnwá lọ’ nígbà tí àwa àtàwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ bá péjọ pọ̀ láti gba ìtọ́ni àti nígbà tí àwa fúnra wa bá ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ìsọfúnni tá à ń gbà yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání tó sì ń ṣeni láǹfààní, èyí tí yóò múnú Jèhófà dùn tí yóò sì mú ọkàn-àyà rẹ̀ yọ̀. (Òwe 27:11; Aísáyà 48:17) Báwo la ṣe lè túbọ̀ fi kún bá a ṣe ń pọkàn pọ̀ láwọn ìpàdé àti nígbà tá a bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́ ká lè jàǹfààní púpọ̀ látinú ìpèsè tẹ̀mí tó ń ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá?

Túbọ̀ Máa Pọkàn Pọ̀ Sí I Láwọn Ìpàdé

11. Èé ṣe tí pípọkànpọ̀ láwọn ìpàdé Kristẹni fi máa ń ṣòro nígbà míì?

11 Ìgbà míì wa tí kì í rọrùn láti pọkàn pọ̀ láwọn ìpàdé Kristẹni. Igbe ọmọ kékeré jòjòló kan tàbí apẹ́lẹ́yìn kan tó ń wá ibi tó máa jókòó sí lè mú kí ọkàn èèyàn pínyà. Iṣẹ́ tá a ṣe lọ́jọ́ yẹn lè mú kó rẹ̀ wá tẹnutẹnu. Ẹni tó ń sọ̀rọ̀ lórí pèpéle lè jẹ́ ẹni tí kò fí bẹ́ẹ̀ lẹ́bùn ọ̀rọ̀ sísọ, ká tóó mọ̀, a lè bẹ̀rẹ̀ sí ronú nǹkan mìíràn tó ń múnú wa dùn—tàbí ká tiẹ̀ máa tòògbé pàápàá! Ì bá dára ká túbọ̀ máa pọkàn pọ̀ sí i láwọn ìpàdé ìjọ, nítorí àwọn ìsọfúnni pàtàkì tá a máa ń gbọ́ níbẹ̀. Àmọ́ báwo la ṣe lè ṣe èyí?

12. Kí ló lè mú kó rọrùn fún wa láti pọkàn pọ̀ láwọn ìpàdé?

12 Ó sábà máa ń rọrùn láti pọkàn pọ̀ láwọn ìpàdé tá a bá múra sílẹ̀ dáadáa. Nítorí náà, èé ṣe tá ò fi ya àkókò kan sọ́tọ̀ láti ronú lórí ohun tá a máa gbé yẹ̀ wò nípàdé? Ìṣẹ́jú díẹ̀ ló máa gbà wá lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan láti ka díẹ̀ lára àwọn orí tá a yàn fún Bíbélì kíkà ti ọ̀sẹ̀ náà, ká sì ṣàṣàrò lé e lórí. Tá a bá wéwèé dáadáa, a tún lè wá àkókò láti múra Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ àti Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ sílẹ̀. Ọ̀nà yòówù kí a gbé e gbà, ohun kan dájú pé: Ìmúrasílẹ̀ yóò ràn wá lọ́wọ́ láti pọkàn pọ̀ sórí àwọn ohun tá à ń gbé yẹ̀ wò láwọn ìpàdé ìjọ.

13. Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti pọkàn pọ̀ sórí àwọn ohun tá à ń jíròrò láwọn ìpàdé?

13 Ní àfikún sí mímúra sílẹ̀ dáadáa, àwọn kan ti rí i pé àwọn túbọ̀ máa ń pọkàn pọ̀ láwọn ìpàdé nígbà táwọn bá jókòó sọ́wọ́ iwájú nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba. Wíwo ojú olùbánisọ̀rọ̀, ṣíṣí Bíbélì rẹ kó o sì máa fojú bá a lọ nígbà tí wọ́n bá ń ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan, àti kíkọ nǹkan sílẹ̀ tún jẹ́ àwọn ọ̀nà mìíràn tá ò fi ní máa ro tìhín, ro tọ̀hún. Bó ti wù kó rí, níní ọkàn àyà tá a ti múra sílẹ̀ ṣe pàtàkì gan-an ju ọgbọ́n èyíkéyìí téèyàn lè dá láti pọkàn pọ̀ lọ. A ní láti mọyì ìdí tá a fi ń péjọ pọ̀. Ká lè jọ́sìn Jèhófà ni olórí ète tí àwa àtàwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ fi ń pàdé pọ̀. (Sáàmù 26:12; Lúùkù 2:36, 37) Àwọn ìpàdé jẹ́ ọ̀nà pàtàkì tá a gbà ń bọ́ wa nípa tẹ̀mí. (Mátíù 24:45-47) Láfikún sí i, wọ́n tún ń fún wa láǹfààní láti ‘ru ara wa sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà.’—Hébérù 10:24, 25.

14. Kí ni ohun tó máa ń mú kí ìpàdé dùn?

14 Àwọn kan lè máa fi agbára ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ àwọn tó níṣẹ́ díwọ̀n bí ìpàdé kan ṣe dùn tó. Bí àwọn olùbánisọ̀rọ̀ bá jẹ́ àwọn tó dáńgájíá, wọ́n lè sọ pé ìpàdé náà dùn. Àmọ́ tó bá dà bíi pé wọn ò fi bẹ́ẹ̀ kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà tó gbéṣẹ́, ó lè jẹ́ pé òdìkejì la ó máa sọ. Òótọ́ ni pé àwọn tó níṣẹ́ gbọ́dọ̀ sa gbogbo ipá wọn láti lo ọgbọ́n ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́, pàápàá láti lè dé inú ọkàn àwọn èèyàn. (1 Tímótì 4:16) Síbẹ̀, àwa tá à ń fetí sílẹ̀ ò gbọ́dọ̀ máa ṣe lámèyítọ́ ju bó ti yẹ lọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọgbọ́n ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ àwọn tó níṣẹ́ ṣe pàtàkì, síbẹ̀ ìyẹn nìkan kọ́ ni ìpàdé fi ń dùn. Ǹjẹ́ o gbà pé kì í ṣe bí olùbánisọ̀rọ̀ ṣe sọ̀rọ̀ rẹ̀ dáradára tó ló yẹ kó ká wa lára jù, bí ko ṣe bí àwa fúnra wa ṣe ń fetí sílẹ̀? Nígbà tá a bá wá sípàdé tá a sì fetí sí ohun tí wọ́n ń sọ níbẹ̀, à ń jọ́sìn Ọlọ́run ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ̀ nìyẹn. Ohun tó ń jẹ́ kí ìpàdé dùn sì nìyẹn. Bá a bá ń hára gàgà láti gba ìmọ̀ Ọlọ́run sínú, a ó jàǹfààní látinú àwọn ìpàdé, láìka bí olùbánisọ̀rọ̀ ṣe mọ̀rọ̀ sọ sí. (Òwe 2:1-5) Gbogbo ọgbọ́n tá a bá lè dá, ẹ jẹ́ ká pinnu láti ‘pọkàn pọ̀ ju ti àtẹ̀yìnwá lọ’ láwọn ìpàdé wa.

Jàǹfààní Kíkún Látinú Ìdákẹ́kọ̀ọ́

15. Báwo ni kíkẹ́kọ̀ọ́ àti ṣíṣàṣàrò ṣe lè ṣe wá láǹfààní?

15 À ń jàǹfààní gan-an látinú ‘pípọkànpọ̀ ju ti àtẹ̀yìnwá lọ’ nígbà tá a bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́ àti nígbà tá a bá ń ṣàṣàrò. Kíka Bíbélì àtàwọn ìwé táwa Kristẹni tẹ̀ jáde, ká sì ronú lé wọn lórí dáadáa yóò fún wa láǹfààní gidi láti fìdí òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run múlẹ̀ ṣinṣin nínú ọkàn-àyà wa. Èyí ló máa wá nípa tó dára lórí ọ̀nà tá a gbà ń ronú àti ọ̀nà tá a gbà ń hùwà. Láìsí àní-àní, yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ní inú dídùn nínú ṣíṣe ìfẹ́ Jèhófà. (Sáàmù 1:2; 40:8) Nítorí náà, a ní láti fi ìpọkànpọ̀ kọ́ra kó lè ṣe wá láǹfààní nígbà tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́. Ó rọrùn gan-an láti ní ìpínyà ọkàn! Àwọn ìdíwọ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́—bí ìpè lórí tẹlifóònù tàbí ariwo kan lè pín ọkàn wa níyà. Tàbí kó jẹ́ pé àwa fúnra wa ò lè pọkàn pọ̀ fúngbà pípẹ́. A lè jókòó ká sì ní i lọ́kàn pé a fẹ́ gbádùn oúnjẹ tẹ̀mí náà, àmọ́ ká tó pajú pẹ́ a lè rí i pé ọkàn wa ti bẹ̀rẹ̀ sí ronú lórí àwọn nǹkan mìíràn. Báwo la ṣe lè ‘pọkàn pọ̀ ju ti àtẹ̀yìnwá lọ’ nígbà tá a bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?

16. (a) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì láti ṣètò àkókò fún ìdákẹ́kọ̀ọ́? (b) Báwo lo ṣe ṣètò fún kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?

16 Ó dáa ká ṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ kan ká sì yan ọ̀nà kan tó rọrùn jù lọ láti kẹ́kọ̀ọ́. Ọ̀pọ̀ ju lọ wa ni ò fi bẹ́ẹ̀ ní àkókò tá a lè fi gbọ́ tara wa. Ó lè máa ṣe wá bíi pé àwọn kòókòó jàn-ánjàn-án ojoojúmọ́ ń gbé wa lọ bí ẹ̀ka igi tó wà lójú agbami. Ní tòótọ́, a gbọ́dọ̀ bá ìgbì omi náà wọ̀yá ìjà, ká sì wá erékùṣù kékeré kan tí a ó ti sinmi. A ò kàn lè máa dúró de ìgbà tí àyè ìkẹ́kọ̀ọ́ máa yọ fúnra rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, a ní láti bójú tó ipò náà fúnra wa nípa wíwá àkókò tí a ó fi kẹ́kọ̀ọ́. (Éfésù 5:15, 16) Àwọn kan máa ń ya àkókò sọ́tọ̀ láàárọ̀ nígbà tí kò sí ohun tó máa pín ọkàn wọn níyà. Àwọn mìíràn rí i pé ìrọ̀lẹ́ ni àǹfààní yẹn máa ń yọjú. Kókó tó wà níbẹ̀ ni pé a ò gbọ́dọ̀ fọwọ́ yẹpẹrẹ mú ìjẹ́pàtàkì gbígba ìmọ̀ pípéye ti Ọlọ́run àti Ọmọ rẹ̀ sínú. (Jòhánù 17:3) Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká ṣètò àkókò fún ìdákẹ́kọ̀ọ́ ká sì tẹ̀ lé ètò tá a ṣe yẹn dáadáa.

17. Kí ni ṣíṣe àṣàrò, báwo ló sì ṣe lè ṣe wá láǹfààní?

17 Kò sóhun tó dáa bíi pé ká ṣe àṣàrò—ìyẹn ni pé ká ronú lórí ohun tá a ti kọ́ nígbà tá a ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́. Ó ń ràn wá lọ́wọ́ láti rí èrò Ọlọ́run tó wà lákọsílẹ̀ fà yọ, kó sì wọ̀ wá lọ́kàn ṣinṣin. Ṣíṣe àṣàrò ń ràn wá lọ́wọ́ láti mọ bí a ó ṣe fi ìmọ̀ràn Bíbélì sílò kí a lè di “olùṣe ọ̀rọ̀ náà, kì í sì í ṣe olùgbọ́ nìkan.” (Jákọ́bù 1:22-25) Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ṣíṣe àṣàrò ń ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, nítorí pé yóò mú ká lè ronú jinlẹ̀ lórí àwọn ànímọ́ rẹ̀ àti lórí bí ibi tá a kà láwọn ìgbà tá à ń ṣèkẹ́kọ̀ọ́ ṣe tẹnu mọ́ wọn tó.

18. Àwọn ipò wo la nílò láti lè ṣe àṣàrò tó múná dóko?

18 Ká tó lè jàǹfààní kíkún látinú kíkẹ́kọ̀ọ́ àti ṣíṣe àṣàrò, a gbọ́dọ̀ rí i pé ohunkóhun kò pín ọkàn wa níyà. Tá a bá fẹ́ kí ìsọfúnni tó jẹ́ tuntun wọ̀ wá lọ́kàn nígbà tá a bá ń ṣàṣàrò, a ní láti gbàgbé àwọn ohun tó ń fa ìpínyà ọkàn lákòókò tá a wà yìí. Ṣíṣe èyí ń gba àkókò àti kéèyàn wà níbi tó jẹ́ àdádó, síbẹ̀, ẹ ò rí i pé ó ń tuni lára gan-an láti máa jẹ oúnjẹ tẹ̀mí, ká sì máa mu omi òtítọ́ tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run!

19. (a) Lórí ọ̀ràn ìdákẹ́kọ̀ọ́, kí ló ti ran àwọn kan lọ́wọ́ láti fi kún bí wọ́n ṣe ń pọkàn pọ̀? (b) Irú ẹ̀mí wo ló yẹ ká ní sí ìkẹ́kọ̀ọ́, àǹfààní wo la sì lè rí nínú ìgbòkègbodò pàtàkì yìí?

19 Tí àkókò tá a lè fi pọkàn pọ̀ bá kúrú gan-an ńkọ́, tí ọkàn wa yóò sì bẹ̀rẹ̀ sí í ro tìhín ro tọ̀hún láìpẹ́ lẹ́yìn tá a bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́? Àwọn kan ti rí i pé àwọn lè fi kún bí wọ́n ṣe ń pọkàn pọ̀ nígbà tí wọ́n bá ń ṣèkẹ́kọ̀ọ́ nípa lílo àkókò kúkúrú nígbà tí wọ́n bá kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀, lẹ́yìn náà kí wọ́n wá máa jẹ́ kí àkókò náà gùn sí i díẹ̀díẹ̀. Pípẹ́ nídìí ìkẹ́kọ̀ọ́ ló yẹ ká máa lépa dípò ká máa kánjú nídìí rẹ̀. A gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ tó jinlẹ̀ sí kókó tá à ń gbé yẹ̀ wò. A sì tún lè ṣèwádìí sí i nípa lílo àwọn ìtẹ̀jáde tí ẹrú olóòótọ́ àti olóye náà pèsè. Àǹfààní ńláǹlà wà nínú wíwá inú “àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run.” (1 Kọ́ríńtì 2:10) Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ ń ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ ní ìmọ̀ Ọlọ́run àti láti mú agbára ìwòye wa dàgbà. (Hébérù 5:14) Tá a bá ń fi taápọntaápọn kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, a ó tún di ẹni tó “tóótun tẹ́rùntẹ́rùn láti kọ́ àwọn ẹlòmíràn.”—2 Tímótì 2:2.

20. Báwo la ṣe lè máa ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run?

20 Lílọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni àti dídá kẹ́kọ̀ọ́ yóò ràn wá lọ́wọ́ gan-an láti ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà. Ó hàn gbangba pé bí ọ̀ràn náà ṣe rí pẹ̀lú onísáàmù nìyẹn, ẹni tó sọ fún Ọlọ́run pé: “Mo mà nífẹ̀ẹ́ òfin rẹ o! Òun ni mo fi ń ṣe ìdàníyàn mi láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀.” (Sáàmù 119:97) Nítorí náà, pẹ̀lú gbogbo ọgbọ́n tá a bá lè dá, ẹ jẹ́ ká máa lọ sí àwọn ìpàdé, àwọn àpéjọ àti àpéjọpọ̀ déédéé. Ǹjẹ́ kí a ra àkókò padà fún kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti ṣíṣe àṣàrò. A óò rí èrè jaburata gbà tá a bá ń tipa báyìí fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run “ní àfiyèsí tí ó ju ti àtẹ̀yìnwá lọ.”

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọdún 61 Sànmánì Tiwa ló kọ lẹ́tà náà sáwọn Hébérù. Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, nǹkan bí ọdún márùn-ún péré lẹ́yìn náà ni ẹgbẹ́ ọmọ ogun Cestius Gallus yí Jerúsálẹ́mù ká. Kò sì pẹ́ tí ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀hún fi káńgárá wọn, táwọn Kristẹni tó wà lójúfò fi lè sá lọ. Ọdún mẹ́rin lẹ́yìn ìyẹn ni ẹgbẹ́ ọmọ ogun Róòmù lábẹ́ Ọ̀gágun Titus wá pa ìlú ńlá náà run.

Ǹjẹ́ O Rántí?

• Èé ṣe táwọn Hébérù kan tó jẹ́ Kristẹni fi ń sú lọ kúrò nínú ìgbàgbọ́ tòótọ́?

• Báwo la ṣe lè pọkàn pọ̀ láwọn ìpàdé Kristẹni?

• Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti jàǹfààní nínú dídá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti ṣíṣe àṣàrò?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]

Àwọn Hébérù tó jẹ́ Kristẹni ní láti wà lójúfò bí wọ́n ti ń retí ìparun tó rọ̀ dẹ̀dẹ̀ sórí Jerúsálẹ́mù

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Àwọn òbí lè ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti jàǹfààní nínú àwọn ìpàdé Kristẹni