Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Ọ̀dọ́ Tó Fẹ́ràn Òtítọ́

Àwọn Ọ̀dọ́ Tó Fẹ́ràn Òtítọ́

Àwọn Ọ̀dọ́ Tó Fẹ́ràn Òtítọ́

ONÍSÁÀMÙ kan tó jẹ́ Hébérù béèrè ìbéèrè kan ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn, pé: “Báwo ni ọ̀dọ́kùnrin ṣe lè mú ipa ọ̀nà rẹ̀ mọ́?” (Sáàmù 119:9) Ìbéèrè yìí ṣì bóde mu lónìí pẹ̀lú nítorí ọ̀pọ̀ ìṣòro làwọn ọ̀dọ́ ń dojú kọ nínú ayé. Ìṣekúṣe ti mú kí ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ kó àrùn éèdì, ìdajì àwọn tó ti kó àrùn búburú yìí jẹ́ àwọn tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sí mẹ́rìnlélógún. Ìjoògùnyó tún ń fa ọ̀pọ̀ ìṣòro, ó ti ṣekú pa ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ní rèwerèwe. Àwọn orinkórin; àwọn sinimá oníwà ipá àti ìṣekúṣe, àwọn àwòrán oníwà ìbàjẹ́ orí tẹlifíṣọ̀n àti fídíò, àti àwọn ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè tó wà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì ń kọ́ àwọn ọ̀dọ́ ní ìkọ́kúkọ̀ọ́. Nítorí náà, ìbéèrè tí onísáàmù náà béèrè ń ró kìì lọ́kàn ọ̀pọ̀ òbí àtàwọn ọ̀dọ́ gan-an lóde òní.

Onísáàmù yìí kan náà wá fúnra rẹ̀ dáhùn ìbéèrè ara rẹ̀, ó ní: “Nípa ṣíṣọ́ra ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ rẹ.” Dájúdájú, Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní ìtọ́sọ́nà àtàtà fún àwọn ọ̀dọ́, ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ tó sì ń tẹ̀ lé e ló ti ṣàṣeyọrí nínú ìgbésí ayé wọn. (Sáàmù 119:105) Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ àwọn ọ̀dọ́ bíi mélòó kan tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń sapá láti dúró sán-ún nípa tẹ̀mí nínú ayé onífẹ̀ẹ́ fàájì àti onífẹ̀ẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì yìí.

Wọ́n Mọyì Ìtọ́sọ́nà Àwọn Òbí

Jacob Emmanuel ti jẹ́ aṣáájú ọ̀nà alákòókò kíkún fún ọdún bíi mélòó kan kó tó lọ sìn ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Mẹ́síkò. Ó fi ìmọrírì rántí bí ìfẹ́ tí òun ní sí ìṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run ṣe bẹ̀rẹ̀, ó ní: “Àwọn òbí mi ló nípa lórí mi jù lọ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan lára àwọn arákùnrin tẹ̀mí tí mo bá dọ́rẹ̀ẹ́ tún ràn mí lọ́wọ́ gan-an. Wọ́n jẹ́ kí n fẹ́ràn iṣẹ́ ìwàásù. Wọ́n fi sùúrù darí mi sí ọ̀nà tí ó tọ́; kò sígbà kan tí mo lè sọ pé wọ́n fúngun mọ́ mi rí.”

David, tó ti sìn fún ọdún bíi mélòó kan nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, rántí bó ṣe wú u lórí tó pé àwọn òbí rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà àkànṣe nígbà tí òun àti àbúrò òun ṣì wà lọ́mọdé. Nígbà tí bàbá rẹ̀ kú, màmá rẹ̀ ń bá iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà àkànṣe náà lọ. Bó ṣe ń bójú tó wọn náà ló ń wàásù ìhìn rere. David sọ pé: “Wọn ò fagbára mú mi pé kí n di aṣáájú ọ̀nà rárá, àmọ́ ìdílé wa gbádùn iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà gan-an débi pé ìbákẹ́gbẹ́ àti ìgbésẹ̀ àwọn tó yí mi ká sún mi láti di aṣáájú ọ̀nà bákan náà.” Nígbà tí David ń sọ̀rọ̀ nípa ìjẹ́pàtàkì ìtọ́sọ́nà rere àti àfiyèsí táwọn òbí rẹ̀ fún un, ó ní: “Alaalẹ́ ni màmá mi máa ń ka àwọn ìtàn látinú ìwé Lati Paradise T’a Sọnu Si Paradise T’a Jere-Pada sí wa létí. a Ọ̀nà tó máa ń gbà sọ ìtàn náà fún wa mú ká fẹ́ràn àtimáa jẹ oúnjẹ tẹ̀mí.”

Mímọrírì Àwọn Ìpàdé

Ó ṣòro fáwọn ọ̀dọ́ kan láti mọrírì àwọn ìpàdé Kristẹni. Ńṣe ni wọ́n wulẹ̀ ń tẹ̀ lé àwọn òbí wọn wá. Àmọ́, bí wọ́n bá ń bá a lọ láti máa wá sípàdé, tó bá yá wọ́n lè wá dẹni tó mọyì àwọn ìpàdé. Gbé ọ̀ràn Alfredo, tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún nígbà tó wà lọ́mọ ọdún mọ́kànlá yẹ̀ wò. Ó ní ńṣe lòun máa ń fẹ́ sá fún ìpàdé nígbà tóun wà lọ́mọ ọdún márùn-ún nítorí pé oorun máa ń kun òun níbẹ̀, àwọn òbí òun kì í sì í jẹ́ kóun sùn tí ìpàdé bá ń lọ lọ́wọ́. Ó rántí pé: “Bí mo ṣe ń dàgbà, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ mo bẹ̀rẹ̀ sí nífẹ̀ẹ́ sí àwọn ìpàdé, àgàgà lẹ́yìn tí mo mọ̀wé kà tí mo sì mọ̀ ọ́n kọ́ nítorí ìgbà yẹn ni mo wá bẹ̀rẹ̀ sí dáhùn lọ́rọ̀ ara mi.”

Cintia, ọmọbìnrin kan tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún, tó ń sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà déédéé sọ bí ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ rere ṣe kó ipa pàtàkì nínú ìfẹ́ tí òun ní fún iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Ó sọ pé: “Níní àjọṣe tó dára pẹ̀lú àwọn ará àti lílọ sáwọn ìpàdé déédéé kò jẹ́ kí n ṣàárò àwọn ọ̀rẹ́ ayé tí mo ní àtàwọn ìgbòkègbodò tó wọ́pọ̀ láàárín àwọn èwe, irú bíi lílọ síbi ijó dísíkò. Fífetí sí báwọn èèyàn ṣe ń dáhùn àtàwọn ìrírí tí wọ́n máa ń sọ láwọn ìpàdé ti gbin ìfẹ́ láti fún Jèhófà ní gbogbo ohun tí mo ní sí mi lọ́kàn, mo sì rí i pé ohun tí mo ní jù lọ ni ìgbà èwe mi. Ìdí nìyẹn tí mo fi pinnu láti lò ó nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀.”

Àmọ́, ó ní: “Ìgbà kan wà, kí n tó ṣèrìbọmi, tó jẹ́ pé ńṣe ni mo máa ń pa ìpàdé jẹ bó ṣe wù mi, tí máa sọ pé mo fẹ́ fi àkókò yẹn ṣe iṣẹ́ àṣetiléwá tàbí àwọn ìgbòkègbodò mìíràn tó jẹ́ ti ilé ìwé. Mo pa àwọn ìpàdé bíi mélòó kan jẹ, èyí sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣàkóbá fún mi nípa tẹ̀mí. Mo wá bẹ̀rẹ̀ sí bá ọ̀dọ́mọkùnrin kan tí kò kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rìn. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, mo ṣàtúnṣe kó tó pẹ́ jù.”

Ìpinnu Ara Ẹni

Nígbà tí wọ́n béèrè lọ́wọ́ Pablo, ìyẹn ọ̀dọ́ mìíràn tó ń ṣe iṣẹ́ ìsìn Jèhófà lákòókò kíkún, nípa ohun tí ó gbà pé èèyàn nílò jù lọ kó tó lè fẹ́ràn òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó sọ pé: “Mo rò pé ohun méjì ni: dídákẹ́kọ̀ọ́ déédéé àti níní ìtara fún iṣẹ́ ìwàásù. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn òbí mi pé wọ́n kọ́ mi ní òtítọ́ nípa Jèhófà, mo si lérò pé èyí ló ṣe pàtàkì jù lọ nínú ohun tí wọ́n lè fún mi. Àmọ́, ìdí tí mo fi nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gbọ́dọ̀ dá èmi fúnra mi lójú. Nítorí ìdí èyí, ó pọn dandan kí n mọ ‘ìbú àti jíjìn’ òtítọ́ Bíbélì. Ọ̀nà yìí nìkan la fi lè máa yán hànhàn fún Ọ̀rọ̀ Jèhófà, èyí tó ń dà bi ‘iná tí ń jó’ lára wa, tó sún wa láti máa bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Ìtara tá a ní fún iṣẹ́ ìwàásù ló máa jẹ́ kí ìmọrírì tá a ní fún òtítọ́ túbọ̀ pọ̀ sí i.”—Éfésù 3:18; Jeremáyà 20:9.

Jacob Emmanuel, tá a mẹ́nu kan níṣàájú, náà rántí ìjẹ́pàtàkì fífúnra ẹni yàn láti sin Jèhófà. Ó ní àwọn òbí òun ò fagbára mú òun láti ṣèrìbọmi rárá. Ó ní: “Mo sì gbà pé ohun tó dára jù lọ ni wọ́n ṣe yẹn, nítorí mo rí i bó ṣe yọrí sí rere. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ọ̀dọ́ kan tá a jọ ń rìn pinnu pé àwọn máa ṣèrìbọmi pa pọ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìyẹn dára, àmọ́ mo rí i pé ẹgbẹ́ kíkó ló mú kí àwọn kan ṣe é, kò sì pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn tí ìtara wọn fún ìgbòkègbodò Ìjọba náà fi ń jó rẹ̀yìn. Ní tèmi, àwọn òbí mi ò fagbára mú mi ṣèpinnu láti ya ara mi sí mímọ́ fún Jèhófà. Èmi fúnra mi ni mo yàn láti ṣe bẹ́ẹ̀.”

Ipa Tí Ìjọ Ń Kó

Àwọn ọ̀dọ́ kan fúnra wọn kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, láìsí pé àwọn òbí wọn ràn wọ́n lọ́wọ́. Nínú irú ipò yẹn, kì í rọrùn rárá láti máa ṣe ohun tó tọ́, kéèyàn sì máa bá a lọ bẹ́ẹ̀.

Noé rántí bí òtítọ́ ṣe ṣe òun láǹfààní tó. Àtìgbà tó ti wà lọ́mọdé ló tí máa ń bínú sódì tó sì máa ń hu ìwà ipá. Nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́mọ ọdún mẹ́rìnlá, ìṣesí rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí yí padà débi pé inú àwọn òbí rẹ̀, tí wọn ò nífẹ̀ẹ́ sì Bíbélì lákòókò yẹn bẹ̀rẹ̀ sì dùn sí èyí gan-an. Bí Noé ṣe ń tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí, ó túbọ̀ fẹ́ lo ìgbésí ayé rẹ̀ ní kíkún nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Ó ti ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún báyìí.

Bákan náà ni Alejandro bẹ̀rẹ̀ sí fìfẹ́ hàn sí òtítọ́ Kristẹni nígbà tó ṣì kéré gan-an, bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú àwọn òbí rẹ̀ kò dùn sí i. Nígbà tó ń sọ bí òun ṣe mọrírì òtítọ́ náà tó, ó ní: “Agboolé àwọn tó jẹ́ Kátólíìkì hán-únhán-ún ni wọ́n ti tọ́ mi dàgbà. Àmọ́ mo wá di Kọ́múníìsì tí kò gbà pọ́lọ́run wà nítorí pé ṣọ́ọ̀ṣì ò lè dáhùn àwọn ìbéèrè tó ń dà mí láàmú látìgbà tí mo ti wà lọ́mọdé. Ètò àjọ Jèhófà ló ràn mí lọ́wọ́ láti gba ìmọ̀ Ọlọ́run. Ohun tó gba ẹ̀mí mi là nìyẹn o, nítorí pé ká ní mi ò kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni, ó ṣeé ṣe kí n ti lọ́wọ́ nínú ìṣekúṣe, ìmukúmu ọtí, tàbí oògùn líle. Ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kí n ti di ara ẹgbẹ́ àwọn afipágbàjọba kan, kí ọ̀rọ̀ wa sí ti bẹ́yìn yọ.”

Báwo ni ọ̀dọ́ kan ṣe lè tẹra mọ́ wíwá tó ń wá òtítọ́ kiri kó sì rọ̀ mọ́ òtítọ́ láìsí pé àwọn òbí rẹ̀ tì í lẹ́yìn? Ó hàn gbangba pé àwọn alàgbà àtàwọn mìíràn nínú ìjọ ń kó ipa tó ṣe pàtàkì gan-an nínú èyí. Noé rántí pé: “Kò tíì fìgbà kan rí ṣe mí bíi pé mo dá wà rí, nítorí pé gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń sún mọ́ mi pẹ́kípẹ́kí. Bákan náà ni mo tún ti rí ìtìlẹ́yìn àwọn arákùnrin àti arábìnrin onífẹ̀ẹ́ tí wọ́n ti di baba mi, ìyá mi, ẹ̀gbọ́n mi, àti àbúrò mi nípa tẹ̀mí.” Bẹ́tẹ́lì ló ti ń sìn báyìí, ó sì ń lo àkókò rẹ̀ fún iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Alejandro pẹ̀lú sọ pé: “Ohun kan tí n ó máa fi dúpẹ́ ni gbogbo ìgbà ni pé mo láǹfààní láti wà nínú ìjọ kan tí ẹgbẹ́ àwọn alàgbà ibẹ̀ ti fìfẹ́ hàn sí mi gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan. Mo dúpẹ́ fún èyí gan-an nítorí pé nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́mọ ọdún mẹ́rìndínlógún, hílàhílo táwọn ọ̀dọ́ máa ń kóra wọn sí nípa lórí èmi náà. Àwọn ìdílé tó wà nínú ìjọ ò pa mí tì rárá. Gbogbo ìgbà ni mo máa ń rẹ́ni gbà mí tọwọ́tẹsẹ̀ tó sì jẹ́ pé yàtọ̀ sí ilé àti oúnjẹ tí onítọ̀hún máa fún mi, á tún fún mi láfiyèsí àtọkànwá pẹ̀lú.” Alejandro ti wà nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún fún ohun tó lé lọ́dún mẹ́tàlá báyìí.

Àwọn kan máa ń rò pé àwọn àgbàlagbà nìkan ni ìsìn wà fún. Àmọ́ ṣá o, àìmọye ọ̀dọ́ ló ti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà tí wọ́n ṣì kéré gan-an, tí wọ́n dẹni tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, tí wọ́n sì jẹ́ olóòótọ́ sí i. Àwọn ọ̀dọ́ wọ̀nyí la lè sọ pé ọ̀rọ̀ tí Dáfídì sọ nínú Sáàmù 110:3 ṣẹ sí lára, èyí tó kà pé: “Àwọn ènìyàn rẹ yóò fi tinútinú yọ̀ǹda ara wọn ní ọjọ́ ẹgbẹ́ ológun rẹ. Nínú ọlá ńlá ìjẹ́mímọ́, láti inú ilé ọlẹ̀ ọ̀yẹ̀, ìwọ ní àwùjọ rẹ ti àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n rí bí ìrì tí ń sẹ̀.”

Ìpèníjà gidi ló jẹ́ fáwọn ọ̀dọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ kí wọ́n sì rọ̀ mọ́ ọn. Ó mà ń múnú ẹni dùn o, láti rí i pé ọ̀pọ̀ lára wọn ló ń fara mọ́ ètò àjọ Jèhófà pẹ́kípẹ́kí, tí wọ́n ń lọ sáwọn ìpàdé déédéé, tí wọ́n sì ń fi taápọntaápọn kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ ti mú kí wọ́n dẹni tó ní ojúlówó ìfẹ́ fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti iṣẹ́ ìsìn rẹ̀!—Sáàmù 119:15, 16.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde lọ́dún 1958; a ò tẹ̀ ẹ́ mọ́ báyìí.