Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìmọ̀ Pípéye Nípa Ọlọ́run Ń Tù Wá Nínú

Ìmọ̀ Pípéye Nípa Ọlọ́run Ń Tù Wá Nínú

Ìmọ̀ Pípéye Nípa Ọlọ́run Ń Tù Wá Nínú

OHUN tí Bíbélì sọ nípa ìfẹ́ àti àánú Ọlọ́run ń mú kí àwọn ìbéèrè kan máa jà gùdù lọ́kàn àwọn èèyàn kan. Wọ́n ń béèrè pé: Bí Ọlọ́run bá fẹ́ mú ibi kúrò, tó mọ ọ̀nà tó lè gbà mú un kúrò, tó sì lágbára láti ṣe é, èé ṣe tí ibi fi ń pọ̀ sí i? Ohun tó jẹ́ ìṣòro wọn ni bí wọ́n ṣe fẹ́ mú kí èrò mẹ́ta kan tó dà bíi pé ó ta kora di èyí tó bára mu: (1) Ọlọ́run jẹ́ alágbára gbogbo; (2) Ọlọ́run jẹ́ onífẹ̀ẹ́ àti ẹni rere; àti (3) àwọn ohun búburú ń ṣẹlẹ̀. Wọ́n ronú pé níwọ̀n bí èrò kẹta yẹn ti jẹ́ òtítọ́ tí kò ṣeé já ní koro, a jẹ́ pé ó kéré tán ọ̀kan nínú àwọn méjì tó kù kò lè jóòótọ́. Lójú tiwọn, nínú kó jẹ́ pé ńṣe ni Ọlọ́run kò lè dáwọ́ ibi dúró tàbí kó jẹ́ pé kò bìkítà.

Ọjọ́ bíi mélòó kan lẹ́yìn tí wọ́n fọ́ ilé ìtajà tó tóbi jù lọ lágbàáyé túútúú, ìyẹn World Trade Center, ni aṣáájú ìsìn kan táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Àìmọye ìgbà láyé mi. . . làwọn èèyàn ti ń bi mí nípa ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba àjálù àti ìjìyà. Kí n sòótọ́, mi ò mọ ìdáhùn rẹ̀ délẹ̀délẹ̀, kódà mi ò mọ̀ ọ́n débi tó tẹ́ èmi alára lọ́rùn.”

Nígbà táwọn èèyàn ń sọ bí ohun tó wí yìí ṣe rí lára wọn, ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ẹ̀kọ́ ìsìn kan kọ̀wé pé inú òun dùn gan-an sí “ẹ̀kọ́ ìsìn tó múná dóko” tí aṣáájú ìsìn yìí ń wàásù. Ó tún fara mọ́ ojú ìwòye ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan tó kọ̀wé pé: “Bí kò ti ṣeé ṣe láti lóye ìdí téèyàn fi ń jìyà jẹ́ ara ohun tí kò fi ṣeé ṣe láti lóye Ọlọ́run.” Àmọ́ ṣé lóòótọ́ ni kò ṣeé ṣe láti mọ ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìwà ibi?

Ibi Tí Ìwà Ibi Ti Bẹ̀rẹ̀

Ní ìyàtọ̀ pátápátá sí ohun táwọn aṣáájú ìsìn lè sọ, Bíbélì ò sọ pé fífi tí Ọlọ́run fàyè gba ìwà ibi jẹ́ ohun tí kò ṣeé lóye. Kókó pàtàkì kan tá a fi lè lóye bí ìwà ìbi ṣe jẹ́ ni kéèyàn kọ́kọ́ mọ̀ pé Jèhófà kò dá ayé yìí láyé búburú. Ó dá tọkọtaya ẹ̀dá ènìyàn àkọ́kọ́ ní pípé, láìní ẹ̀ṣẹ̀ kankan. Jèhófà wo àwọn ohun tí ó dá, ó sì rí i pé “ó dára gan-an ni.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:26, 31) Ète rẹ̀ ni pé kí Ádámù àti Éfà mú Párádísè Édẹ́nì gbòòrò kárí ayé kí wọ́n sì fi àwọn ènìyàn aláyọ̀ kún inú rẹ̀ lábẹ́ ààbò ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ onífẹ̀ẹ́.—Aísáyà 45:18.

Ẹ̀dá ẹ̀mí kan ló dá ìwà ibi sílẹ̀. Olóòótọ́ ló jẹ́ sí Ọlọ́run tẹ́lẹ̀, àfìgbà tó yá tó di pé ó ń fẹ́ káwọn èèyàn máa jọ́sìn òun. (Jákọ́bù 1:14, 15) Ìwà ọ̀tẹ̀ rẹ̀ hàn lórí ilẹ̀ ayé nígbà tó kó tọkọtaya ẹ̀dá ènìyàn àkọ́kọ́ sọ̀dí láti ṣàtakò sí Ọlọ́run. Dípò tí Ádámù àti Éfà ì bá fi tẹ̀ lé ìtọ́ni kedere tí Ọlọ́run fún wọn pé wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ nínú èso igi ìmọ̀ rere àti búburú tàbí kí wọ́n fọwọ́ kàn án, ńṣe ni wọ́n mú lára èso náà ti wọ́n sì jẹ ẹ́. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6) Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, kì í ṣe pé wọ́n ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run nìkan ni, wọ́n tún fi hàn pé àwọn fẹ́ dá wà lómìnira ara àwọn.

Ó Gbé Ọ̀ràn Tó Jẹ Mọ́ Ìwà Rere Dìde

Ìṣọ̀tẹ̀ tó wáyé ní Édẹ́nì yìí gbé ọ̀ràn kan dìde, ìyẹn ni ìpèníjà kan tí ìjẹ́pàtàkì rẹ̀ kan ayé àtọ̀run. Àwọn ọlọ̀tẹ̀ èèyàn náà ń ṣiyèméjì bóyá ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń ṣàkóso lórí àwọn ìṣẹ̀dá rẹ̀ tọ́ tàbí kò tọ́. Ǹjẹ́ Ẹlẹ́dàá lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ pé kí ìran ènìyàn máa ṣègbọràn sí òun? Ṣé ìgbà táwọn èèyàn bá wà lómìnira ara wọn ni nǹkan máa ṣẹnuure fún wọn jù?

Jèhófà bójú tó ìpèníjà tí wọ́n gbé dìde sí ìṣàkóso rẹ̀ yìí lọ́nà tí ìfẹ́, ìdájọ́ òdodo, ọgbọ́n, àti agbára rẹ̀ kò fi ta kora rárá. Ó lè lo agbára rẹ̀ láti pa ọ̀tẹ̀ náà run lójú ẹsẹ̀. Ìyẹn ì bá sì bá ìdájọ́ òdodo mu, níwọ̀n bí ó ti lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́ ṣíṣe bẹ́ẹ̀ ì bá má yanjú kókó tí wọ́n gbé dìde. Òmíràn tún ni pé, Ọlọ́run lè wulẹ̀ gbójú fo ẹ̀ṣẹ̀ náà. Ìyẹn làwọn kan lóde òní ì bá gbà pé ó jẹ́ ọ̀nà tó fìfẹ́ hàn jù. Síbẹ̀, èyí ì bá má yanjú ìpèníjà Sátánì pé ìgbà táwọn èèyàn bá ń ṣàkóso ara wọn ni nǹkan máa ṣẹnuure fún wọn jù. Láfikún sí i, ǹjẹ́ ìyẹn ò ní fún àwọn ẹlòmíràn níṣìírí láti yapa kúrò lọ́nà Jèhófà? Ìyà tí kò lópin nìyẹn ì bá dá sílẹ̀.

Ọgbọ́n Jèhófà ti mú kó fàyè gba ẹ̀dá ènìyàn láti wà lómìnira ara wọn fún sáà kan. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí ti mú kó fàyè gba ìwà ibi láti wà fúngbà díẹ̀, síbẹ̀ ẹ̀dá ènìyàn ti tipa bẹ́ẹ̀ láǹfààní láti fi hàn bóyá àwọn lè ṣàkóso ara àwọn láìsí pé Ọlọ́run dá sí wọn, kí wọ́n máa tẹ̀ lé ìlànà ti ara wọn lórí ohun tí ó tọ́ àti èyí tí kò tọ́. Kí ló ti jẹ àbájáde rẹ̀? Ogun, ìwà ìrẹ́jẹ, ìnilára, àti ìjìyà ni ẹ̀dá ènìyàn ti ń kó sí látayébáyé di báyìí. Kíkùnà tí ọ̀tẹ̀ tí wọ́n ṣe sí Jèhófà bá kùnà níkẹyìn ló máa yanjú àwọn kókó tí wọ́n gbé dìde ní Édẹ́nì pátápátá.

Ní báyìí ná, Ọlọ́run ti fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn nípa pípèsè Ọmọ rẹ̀, Jésù Kristi, ẹni tó fi ìwàláàyè rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ènìyàn ṣe ẹbọ ìràpadà. Èyí mú kó ṣeé ṣe fún àwọn ẹ̀dá ènìyàn onígbọràn láti bọ́ lọ́wọ́ ìdálẹ́bi ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú tí àìgbọràn Ádámù fà. Ìràpadà náà ti ṣí ọ̀nà ìyè àìnípẹ̀kun sílẹ̀ fún gbogbo ẹni tó bá lo ìgbàgbọ́ nínú Jésù.—Jòhánù 3:16.

Jèhófà fún wa ní ìdánilójú tó ń tuni nínú pé ìyà tó ń jẹ ìran ènìyàn kò ní máa bá a lọ bẹ́ẹ̀. Onísáàmù náà kọ̀wé pé: “Ní ìgbà díẹ̀ sí i, ẹni burúkú kì yóò sì sí mọ́. Dájúdájú, ìwọ yóò sì fiyè sí ipò rẹ̀, òun kì yóò sì sí. Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.”—Sáàmù 37:10, 11.

Ọjọ́ Iwájú Aláàbò àti Ayọ̀

Ìmúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì fi hàn pé àkókò tí Ọlọ́run máa fòpin sí àìsàn, ìbànújẹ́ àti ikú ti sún mọ́lé. Kíyè sí àwọn nǹkan àgbàyanu tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú tá a fi han àpọ́sítélì Jòhánù nínú ìran. Ó kọ̀wé pé: “Mo sì rí ọ̀run tuntun kan àti ilẹ̀ ayé tuntun kan; nítorí ọ̀run ti ìṣáájú àti ilẹ̀ ayé ti ìṣáájú ti kọjá lọ, òkun kò sì sí mọ́. . . . Ọlọ́run fúnra rẹ̀ yóò sì wà pẹ̀lú [ìran ènìyàn]. Yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.” Nínú gbólóhùn kan tó tẹnu mọ́ bí àwọn ìlérí wọ̀nyí ti ṣe é gbára lé tó, a sọ fún Jòhánù pé: “Kọ̀wé rẹ̀, nítorí pé ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ṣeé gbíyè lé, wọ́n sì jẹ́ òótọ́.”—Ìṣípayá 21:1-5.

Ẹgbàágbèje àwọn aláìmọwọ́mẹsẹ̀ èèyàn tó ti kú látìgbà ọ̀tẹ̀ tó wáyé ní Édẹ́nì yẹn wá ńkọ́? Jèhófà ṣèlérí pé òun yóò mú gbogbo àwọn tó ń sùn nínú ikú báyìí padà bọ̀ sí ìyè. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Mo sì ní ìrètí sọ́dọ̀ Ọlọ́run . . . pé àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yóò wà.” (Ìṣe 24:15) Àwọn wọ̀nyí yóò ní ìrètí pé àwọn yóò gbé nínú ayé kan tí “òdodo yóò sì máa gbé.”—2 Pétérù 3:13.

Gẹ́gẹ́ bí baba onífẹ̀ẹ́ ṣe máa gbà kí a ṣe iṣẹ́ abẹ tó ń dunni fún ọmọ òun tó bá mọ̀ pé ìyẹn ni yóò ṣe ọmọ náà láǹfààní pípẹ́ títí, bẹ́ẹ̀ náà ni Jèhófà ṣe gbà kí ìran ènìyàn máa bá ìwà ibi inú ayé yí nìṣó fúngbà díẹ̀. Síbẹ̀, ìbùkún ayérayé ń dúró de gbogbo ẹni tó ń tiraka láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé: “A tẹ ìṣẹ̀dá lórí ba fún ìmúlẹ̀mófo, kì í ṣe nípasẹ̀ ìfẹ́ òun fúnra rẹ̀, ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ẹni tí ó tẹ̀ ẹ́ lórí ba, nítorí ìrètí pé a óò dá ìṣẹ̀dá tìkára rẹ̀ pẹ̀lú sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìsọdẹrú fún ìdíbàjẹ́, yóò sì ní òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run.”—Róòmù 8:20, 21.

Ìròyìn gidi lèyí—kì í ṣe irú èyí tá a máa ń gbọ́ lórí tẹlifíṣọ̀n tàbí èyí tá a máa ń kà nínú ìwé ìròyìn, bí kò ṣe ìhìn rere. Ó jẹ́ ìròyìn tó dára jù lọ látọ̀dọ̀ “Ọlọ́run ìtùnú gbogbo,” ẹni tó bìkítà nípa wa ní ti tòótọ́.—2 Kọ́ríńtì 1:3.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Àkókò ti fi hàn pé aráyé kò lè ṣàkóso ara wọn láṣeyọrí láìsí ọwọ́ Ọlọ́run níbẹ̀

[Àwọn Credit Line]

Ìdílé kan ní Somalia: FỌ́TÒ ÀJỌ UN 159849/M. GRANT; bọ́ǹbù: Fọ́tò USAF; àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́: Fọ́tò U.S. National Archives